Dáníẹ́lì
11 “Ní tèmi, ní ọdún kìíní Dáríúsì+ ará Mídíà, mo dìde láti fún un lókun, kí n sì fún un lágbára.* 2 Òótọ́ ni ohun tí mo fẹ́ sọ fún ọ báyìí:
“Wò ó! Ọba mẹ́ta míì máa dìde fún Páṣíà, ìkẹrin máa kó ọrọ̀ tó pọ̀ jọ ju ti gbogbo àwọn yòókù lọ. Tí ọrọ̀ rẹ̀ bá sì ti mú kó di alágbára, ó máa gbé ohun gbogbo dìde sí ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì.+
3 “Ọba kan tó lágbára máa dìde, ìṣàkóso rẹ̀ máa gbilẹ̀,+ á sì máa ṣe ohun tó wù ú. 4 Àmọ́ tó bá ti dìde, ìjọba rẹ̀ máa fọ́, ó sì máa pín sí ọ̀nà atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run,+ àmọ́ kì í ṣe fún àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀,* àkóso wọn ò sì ní lágbára bíi tiẹ̀; torí a máa fa ìjọba rẹ̀ tu, ó sì máa di ti àwọn míì yàtọ̀ sí àwọn yìí.
5 “Ọba gúúsù máa di alágbára, ìyẹn ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè rẹ̀; àmọ́ ọ̀kan máa borí rẹ̀, ìṣàkóso rẹ̀ máa gbilẹ̀, ó sì máa lágbára ju ti ẹni yẹn lọ.
6 “Lẹ́yìn ọdún mélòó kan, wọ́n máa lẹ̀dí àpò pọ̀, ọmọbìnrin ọba gúúsù máa wá bá ọba àríwá láti ṣètò nǹkan lọ́gbọọgba.* Àmọ́ kò ní sí agbára ní apá ọmọbìnrin náà mọ́; ọkùnrin náà ò ní dúró, bẹ́ẹ̀ sì ni apá rẹ̀; a sì máa fi ọmọbìnrin náà léni lọ́wọ́, òun àti àwọn tó ń mú un wọlé, ẹni tó bí i àti ẹni tó ń fún un lágbára ní àkókò yẹn. 7 Ọ̀kan nínú àwọn tó hù látinú gbòǹgbò rẹ̀ máa dìde ní ipò ọkùnrin náà, ó máa wá bá àwọn ọmọ ogun, ó sì máa dìde sí ibi ààbò ọba àríwá, ó máa gbéjà kò wọ́n, ó sì máa borí. 8 Ó tún máa wá sí Íjíbítì pẹ̀lú àwọn ọlọ́run wọn, ère onírin* wọn, àwọn ohun èlò fàdákà àti wúrà wọn tó fani mọ́ra* àti àwọn ẹrú. Ó máa ta kété sí ọba àríwá fún ọdún mélòó kan, 9 ẹni tó máa wá gbéjà ko ìjọba ọba gúúsù, àmọ́ ó máa pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀.
10 “Ní ti àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n máa múra ogun, wọ́n sì máa kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọmọ ogun jọ. Ó dájú pé ó máa gbéra, ó sì máa rọ́ lọ bí àkúnya omi. Àmọ́ ó máa pa dà, ó sì máa jagun títí dé ibi ààbò rẹ̀.
11 “Inú máa bí ọba gúúsù, ó sì máa lọ bá a jà, ìyẹn, ọba àríwá; ó máa kó èrò púpọ̀ jọ, àmọ́ a máa fi àwọn èrò náà lé ẹni yẹn lọ́wọ́. 12 Wọ́n máa kó àwọn èrò náà lọ. Ó máa gbé ọkàn rẹ̀ ga, ó sì máa mú kí ẹgbẹẹgbàárùn-ún ṣubú; àmọ́ kò ní lo ipò gíga rẹ̀.
13 “Ọba àríwá máa wá pa dà, ó sì máa kó èrò tó pọ̀ ju ti àkọ́kọ́ jọ; ní òpin àwọn àkókò, lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ó dájú pé ó máa kó ọ̀pọ̀ ọmọ ogun àti ẹrù tó pọ̀ wá. 14 Ní àkókò yẹn, ọ̀pọ̀ máa dìde sí ọba gúúsù.
“A sì máa gbé àwọn oníwà ipá* lára àwọn èèyàn rẹ lọ, kí wọ́n lè gbìyànjú láti mú kí ìran kan ṣẹ; àmọ́ wọ́n máa kọsẹ̀.
15 “Ọba àríwá máa wá, ó máa mọ òkìtì láti gbógun tì í, ó sì máa gba ìlú olódi. Àwọn apá* gúúsù kò ní dúró, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ ààyò; wọn ò sì ní lágbára láti dúró. 16 Ẹni tó ń bọ̀ láti gbéjà kò ó máa ṣe ohun tó wù ú, kò sì ní sẹ́ni tó máa dúró níwájú rẹ̀. Ó máa dúró ní ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́,*+ agbára láti pani run sì máa wà ní ọwọ́ rẹ̀. 17 Ó máa pinnu láti wá* pẹ̀lú gbogbo agbára ìjọba rẹ̀, ó máa bá a ṣètò nǹkan lọ́gbọọgba;* ó sì máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́. Ní ti ọmọbìnrin àwọn obìnrin, a máa gbà kí ọkùnrin náà pa á run. Ọmọbìnrin náà ò ní dúró, kò sì ní jẹ́ ti ọkùnrin náà mọ́. 18 Ó máa yíjú pa dà sí àwọn ilẹ̀ etíkun, ó sì máa kó ọ̀pọ̀ lẹ́rú. Ọ̀gágun kan máa mú kí ẹ̀gàn rẹ̀ dópin lórí ara rẹ̀, kí ẹ̀gàn rẹ̀ má bàa sí mọ́. Ó máa mú kó yí pa dà sórí ẹni yẹn. 19 Ó máa wá yí ojú rẹ̀ pa dà sí àwọn ibi ààbò ilẹ̀ rẹ̀, ó máa kọsẹ̀, ó sì máa ṣubú, a ò sì ní rí i.
20 “Ẹnì kan tó ń mú kí afipámúni* la ìjọba ọlọ́lá náà kọjá máa rọ́pò rẹ̀, àmọ́ láàárín ọjọ́ mélòó kan, a máa ṣẹ́ ẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe nínú ìbínú tàbí nípa ogun.
21 “Ẹnì tí a fojú àbùkù wò* máa rọ́pò rẹ̀, wọn ò sì ní fún un ní ọlá ìjọba náà; ó máa wọlé wá ní àkókò ààbò,* ó sì máa fi ọ̀rọ̀ dídùn* gba ìjọba náà. 22 A máa gbá àwọn apá* àkúnya omi náà lọ nítorí rẹ̀, a sì máa ṣẹ́ wọn; bí a ṣe máa ṣe sí Aṣáájú+ májẹ̀mú náà.+ 23 Torí bí wọ́n ṣe bá a lẹ̀dí àpò pọ̀, á máa ṣe ẹ̀tàn, ó máa dìde, ó sì máa di alágbára nípasẹ̀ orílẹ̀-èdè kékeré. 24 Ní àkókò ààbò,* ó máa wá sí àwọn ibi tó dáa jù* ní ìpínlẹ̀* náà, ó sì máa ṣe ohun tí àwọn bàbá rẹ̀ àti àwọn bàbá wọn ò ṣe. Ó máa pín ẹrù ogun, àwọn ohun ìní àti ẹrù láàárín wọn; ó sì máa gbèrò ibi sí àwọn ibi olódi, àmọ́ ó máa jẹ́ fún àkókò kan.
25 “Ó máa fi agbára rẹ̀ àti ọkàn rẹ̀ dojú kọ ọba gúúsù pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun, ọba gúúsù sì máa múra sílẹ̀ fún ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun tó lágbára lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Kò sì ní dúró, torí wọ́n máa gbèrò ibi sí i. 26 Àwọn tó ń jẹ oúnjẹ aládùn rẹ̀ máa fa ìṣubú rẹ̀.
“Ní ti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, a máa gbá wọn lọ,* a sì máa pa ọ̀pọ̀ nínú wọn run.
27 “Ní ti ọba méjì yìí, èrò burúkú máa wà lọ́kàn wọn, wọ́n sì máa jókòó sídìí tábìlì kan náà, wọ́n á máa parọ́ fúnra wọn. Àmọ́ kò sóhun tó máa yọrí sí rere, torí kò tíì tó àkókò tí a yàn pé kí òpin dé.+
28 “Ó máa kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrù pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀, ọkàn rẹ̀ sì máa ta ko májẹ̀mú mímọ́. Ó máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́, ó sì máa pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀.
29 “Ní àkókò tí a yàn, ó máa pa dà, ó sì máa wá dojú kọ gúúsù. Àmọ́ ti ọ̀tẹ̀ yìí kò ní rí bíi ti tẹ́lẹ̀, 30 torí àwọn ọkọ̀ òkun Kítímù+ máa wá gbéjà kò ó, a sì máa rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀.
“Ó máa pa dà, ó sì máa dá májẹ̀mú mímọ́ náà lẹ́bi,*+ ó máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́; ó máa pa dà, ó sì máa fiyè sí àwọn tó ń fi májẹ̀mú mímọ́ náà sílẹ̀. 31 Àwọn ọmọ ogun* máa dìde, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀; wọ́n máa sọ ibi mímọ́, ibi ààbò, di aláìmọ́,+ wọ́n sì máa mú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo* kúrò.+
“Wọ́n máa gbé ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀.+
32 “Ó máa fi ọ̀rọ̀ dídùn* mú kí àwọn tó ń ṣe ohun tó lòdì sí májẹ̀mú náà di apẹ̀yìndà. Àmọ́ àwọn tó mọ Ọlọ́run wọn máa borí, wọ́n sì máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́. 33 Àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye+ lára àwọn èèyàn náà máa la ọ̀pọ̀ lóye. A sì máa mú kí wọ́n kọsẹ̀ nípa idà àti ọwọ́ iná, wọ́n á kó wọn lẹ́rú, wọ́n á sì kó wọn lẹ́rù, fún ọjọ́ mélòó kan. 34 Àmọ́ tí a bá ti mú wọn kọsẹ̀, a máa ràn wọ́n lọ́wọ́ díẹ̀; ọ̀pọ̀ sì máa fi ọ̀rọ̀ dídùn* dara pọ̀ mọ́ wọn. 35 A máa mú kí àwọn kan lára àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye kọsẹ̀, ká lè yọ́ wọn mọ́ nítorí wọn, ká wẹ̀ wọ́n mọ́, ká sì sọ wọ́n di funfun+ títí di àkókò òpin; torí pé àkókò tí a yàn kò tíì tó.
36 “Ọba náà máa ṣe ohun tó wù ú, ó máa gbé ara rẹ̀ ga, ó sì máa gbé ara rẹ̀ lékè ju gbogbo ọlọ́run lọ; ó máa sọ àwọn ohun tó yani lẹ́nu sí Ọlọ́run àwọn ọlọ́run.+ Ó máa ṣàṣeyọrí títí ìdálẹ́bi náà fi máa dópin; nítorí ohun tí a ti pinnu gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀. 37 Kò ní ka Ọlọ́run àwọn bàbá rẹ̀ sí; kò ní ka ohun tí àwọn obìnrin fẹ́ tàbí ọlọ́run èyíkéyìí míì sí, ṣùgbọ́n ó máa gbé ara rẹ̀ ga lórí ẹni gbogbo. 38 Àmọ́ dípò ìyẹn,* ó máa yin ọlọ́run ibi ààbò lógo; ọlọ́run tí àwọn bàbá rẹ̀ kò mọ̀ ló máa fi wúrà, fàdákà, àwọn òkúta iyebíye àtàwọn ohun tó fani mọ́ra* yìn lógo. 39 Ó máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́ lòdì sí àwọn ibi ààbò tó lágbára jù, pẹ̀lú* ọlọ́run àjèjì. Ó máa fi ògo ńlá fún àwọn tó kà á sí,* ó sì máa mú kí wọ́n ṣàkóso láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀; ó máa pín ilẹ̀ ní iye kan.
40 “Ní àkókò òpin, ọba gúúsù máa kọ lù ú,* ọba àríwá sì máa fi àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn agẹṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ òkun rọ́ lù ú; ó máa wọ ilẹ̀ náà, ó sì máa rọ́ kọjá bí àkúnya omi. 41 Ó tún máa wọ ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́,*+ a sì máa mú ọ̀pọ̀ ilẹ̀ kọsẹ̀. Àmọ́ àwọn tó máa bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nìyí: Édómù, Móábù àti èyí tó ṣe pàtàkì jù lára àwọn ọmọ Ámónì. 42 Á máa na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí àwọn ilẹ̀ náà; ní ti ilẹ̀ Íjíbítì, kò ní yè bọ́. 43 Ó máa jọba lórí àwọn ìṣúra wúrà àti fàdákà tó fara sin àti lórí gbogbo ohun tó fani mọ́ra* ní Íjíbítì. Àwọn ará Líbíà àti àwọn ará Etiópíà á sì máa tẹ̀ lé e.*
44 “Àmọ́ ìròyìn láti ìlà oòrùn* àti àríwá máa yọ ọ́ lẹ́nu, ó sì máa fi ìbínú tó le gan-an jáde lọ láti pani rẹ́ ráúráú, kó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ run. 45 Ó máa pa àwọn àgọ́ ọba rẹ̀* sáàárín òkun ńlá àti òkè mímọ́ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́;*+ ó máa wá pa run, kò sì ní sẹ́ni tó máa ràn án lọ́wọ́.