Orí Kejìlá
Ońṣẹ́ kan Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún un Lókun
1. Báwo ni a ṣe bù kún Dáníẹ́lì nítorí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí ó ní sí bí ète Jèhófà ṣe ń ní ìmúṣẹ?
DÁNÍẸ́LÌ rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè gbà nítorí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí ó ní sí bí ète Jèhófà ṣe ń ní ìmúṣẹ. A sọ àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá fún un nípa àádọ́rin ọ̀sẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àkókò tí Mèsáyà yóò fara hàn. A tún bù kún Dáníẹ́lì ní ti pé pípadà tí àṣẹ́kù àwọn olùṣòtítọ́ lára àwọn ènìyàn rẹ̀ padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn ṣojú rẹ̀. Ìyẹn ṣẹlẹ̀ ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, lápá ìparí “ọdún kìíní Kírúsì ọba Páṣíà.”—Ẹ́sírà 1:1-4.
2, 3. Èé ṣe tí ó fi lè ṣeé ṣe pé Dáníẹ́lì kò bá àṣẹ́kù àwọn Júù padà sí ilẹ̀ Júdà?
2 Dáníẹ́lì kò sí lára àwọn tí ó padà lọ sí ilẹ̀ Júdà. Níwọ̀n bí ó ti di arúgbó, rírin ìrìn àjò lè ti nira jù fún un. Àmọ́ ṣá, Ọlọ́run ṣì ní iṣẹ́ tí ó fẹ́ fún un ṣe síwájú sí i ní Bábílónì. Ọdún méjì kọjá lọ. Àkọsílẹ̀ náà wá sọ fún wa pé: “Ní ọdún kẹta Kírúsì, ọba Páṣíà, ọ̀ràn kan wà tí a ṣí payá fún Dáníẹ́lì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹlitéṣásárì; òótọ́ sì ni ọ̀ràn náà, iṣẹ́ ìsìn ológun ńláǹlà sì wà. Ó sì lóye ọ̀ràn náà, ó sì ní òye ohun tí ó rí.”—Dáníẹ́lì 10:1.
3 “Ọdún kẹta Kírúsì” yóò ṣe déédéé ọdún 536 tàbí 535 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ó ti ju ọgọ́rin ọdún lọ tí a ti kó Dáníẹ́lì àti àwọn ọmọ ọba àti àwọn èwe Júdà tí ó jẹ́ ọmọ ìdílé àwọn ọ̀tọ̀kùlú lẹ́rú wá sí Bábílónì. (Dáníẹ́lì 1:3) Ká ní ọ̀dọ́langba ni nígbà tí ó kọ́kọ́ dé Bábílónì, yóò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí. Ọdún tí ó ti fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn bọ̀ tòótọ́tòótọ́ mà pọ̀ gidigidi o!
4. Láìka ti pé Dáníẹ́lì ti darúgbó sí, ipa pàtàkì wo ni yóò ṣì kó nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?
4 Àmọ́, láìka ti pé Dáníẹ́lì ti darúgbó sí, ipa tí ó ń kó nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kò tí ì dópin. Àwọn ìhìn iṣẹ́ tí ìmúṣẹ rẹ̀ yóò rìn jìnnà réré ṣì wà tí Ọlọ́run fẹ́ tipasẹ̀ rẹ̀ gbé jáde. Yóò jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí yóò rìn jìnnà dé ìgbà tiwa tí yóò sì tún ré kọjá rẹ̀. Jèhófà rí i pé láti múra Dáníẹ́lì sílẹ̀ fún iṣẹ́ tí ń bẹ níwájú rẹ̀ yìí, yóò dára láti ràn án lọ́wọ́, láti lè fún un lókun tí yóò fi lè ṣe iṣẹ́ náà.
OHUN TÍ Ó FA ÌDÀÀMÚ
5. Àwọn ìròyìn wo ni ó ṣeé ṣe kí ó ti kó ìdààmú bá Dáníẹ́lì?
5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáníẹ́lì kò bá àṣẹ́kù àwọn Júù padà sí ilẹ̀ Júdà, ó nífẹ̀ẹ́ tí ó ga sí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́hùn-ún ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Àwọn ìròyìn tí ó ń tẹ Dáníẹ́lì lọ́wọ́ fi hàn pé nǹkan kò fara rọ fún wọn lọ́hùn-ún. A ti tún pẹpẹ gbé ró, a sì ti fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì sọlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. (Ẹ́sírà, orí kẹta) Ṣùgbọ́n àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká tako iṣẹ́ àtúnkọ́ tí wọ́n ń ṣe, wọ́n sì ń pa ètekéte sí àwọn Júù. (Ẹ́sírà 4:1-5) Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ni ó kúkú lè máa kó ìdààmú bá Dáníẹ́lì.
6. Èé ṣe tí ipò àwọn nǹkan ní Jerúsálẹ́mù fi ń kó ìdààmú bá Dáníẹ́lì?
6 Dáníẹ́lì mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà dáadáa. (Dáníẹ́lì 9:2) Ó mọ̀ pé títún tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù kọ́ àti mímú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò níbẹ̀ so pọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ohun tí Jèhófà pète lórí àwọn ènìyàn Rẹ̀ àti pé gbogbo ìwọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ kí Mèsáyà tí a ṣèlérí náà tó fara hàn. Ní tòótọ́, àǹfààní ńlá gidigidi ni ó jẹ́ fún Dáníẹ́lì pé òun ni Jèhófà fún ní àsọtẹ́lẹ̀ nípa “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” náà. Láti inú rẹ̀ ni ó ti lóye pé “ọ̀sẹ̀” mọ́kàndínláàádọ́rin lẹ́yìn ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́ ni Mèsáyà máa tó dé. (Dáníẹ́lì 9:24-27) Àmọ́, lójú ìwòye bí Jerúsálẹ́mù ṣe wà ní ipò ahoro àti bí ìfàsẹ́yìn ṣe bá iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì, ó rọrùn láti lóye ìdí tí ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ fi bá Dáníẹ́lì tí ó fi sorí kọ́.
7. Kí ni Dáníẹ́lì ṣe fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta?
7 Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ní ọjọ́ wọnnì, ó ṣẹlẹ̀ pé èmi fúnra mi, Dáníẹ́lì, ń ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko. Èmi kò jẹ oúnjẹ aládìídùn, ẹran tàbí wáìnì kò sì wọ ẹnu mi, lọ́nàkọnà èmi kò fi òróró para títí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko fi pé.” (Dáníẹ́lì 10:2, 3) Láti fi “ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko,” tàbí ọjọ́ mọ́kànlélógún, ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ààwẹ̀ gbígbà jẹ́ àkókò tí ó gùn kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Ó jọ pé “ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kìíní” ni ó parí sí. (Dáníẹ́lì 10:4) Nípa bẹ́ẹ̀, inú àkókò tí Dáníẹ́lì fi gbààwẹ̀ ni a ṣe Ìrékọjá, tí a ń ṣe ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní, Nísàn, àti ọjọ́ méje àjọyọ̀ búrẹ́dì aláìníwùúkàrà.
8. Àkókò wo tẹ́lẹ̀ rí ni Dáníẹ́lì ti fi taratara wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
8 Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí Dáníẹ́lì tẹ́lẹ̀ rí. Ní ìgbà yẹn, ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà nípa àádọ́rin ọdún ìdahoro Jerúsálẹ́mù ni ó kó ìdààmú bá a. Kí ni Dáníẹ́lì wá ṣe? Dáníẹ́lì sọ pé: “Mo sì ń bá a lọ láti kọjú mi sí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, láti lè wá a pẹ̀lú àdúrà àti pẹ̀lú ìpàrọwà, pẹ̀lú ààwẹ̀ gbígbà àti aṣọ àpò ìdọ̀họ àti eérú.” Jèhófà dáhùn àdúrà Dáníẹ́lì nípa pé ó fi ìhìn iṣẹ́ kan rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sí i, èyí sì jẹ́ ìṣírí fún un gan-an ni. (Dáníẹ́lì 9:3, 21, 22) Jèhófà yóò ha ṣe bákan náà nísinsìnyí kí ó sì fún Dáníẹ́lì ní ìṣírí tó ń fẹ́ gidigidi bí?
ÌRAN TÍ Ó BANI LẸ́RÙ
9, 10. (a) Ibo ni Dáníẹ́lì wà nígbà tí ó rí ìran kan? (b) Ṣàpèjúwe ohun tí Dáníẹ́lì rí lójú ìran náà.
9 A kò já Dáníẹ́lì kulẹ̀. Ó ń bá a lọ láti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà fún wa pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé èmi fúnra mi wà ní bèbè odò ńlá náà, èyíinì ni Hídẹ́kẹ́lì, mo sì ń bá a lọ láti gbé ojú mi sókè pẹ̀lú, mo sì rí, sì kíyè sí i, ọkùnrin kan tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, ó sì fi wúrà Úfásì di ìgbáròkó rẹ̀ ní àmùrè.” (Dáníẹ́lì 10:4, 5) Hídẹ́kẹ́lì jẹ́ ọ̀kan lára odò mẹ́rin tí ó ṣàn wá láti inú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́nẹ́sísì 2:10-14) Ní Páṣíà Àtijọ́, ohun tí a mọ Hídẹ́kẹ́lì sí ni Tigra, inú rẹ̀ ni orúkọ náà Tigris ní èdè Gíríìkì ti wá. Àgbègbè tí ó wà láàárín odò náà àti odò Yúfírétì ni a wá ń pè ní Mesopotámíà, tí ó túmọ̀ sí “Ilẹ̀ Tí Ó Wà Láàárín Àwọn Omi.” Èyí jẹ́rìí sí i pé ilẹ̀ Bábílónì ni Dáníẹ́lì ṣì wà nígbà tí ó rí ìran yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó má jẹ́ inú ìlú Bábílónì ni ó wà.
10 Ìran tí Dáníẹ́lì rí mà kàmàmà o! Ó dájú pé ènìyàn kan lásán kọ́ ni ó rí bí ó ṣe gbójú sókè. Dáníẹ́lì ṣàpèjúwe rẹ̀ kedere pé: “Ara rẹ̀ sì dà bí kírísóláítì, ojú rẹ̀ dà bí ìrísí mànàmáná, ẹyinjú rẹ̀ dà bí ògùṣọ̀ oníná, apá rẹ̀ àti ibi ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bí ojú bàbà tí a ha dán, ìró ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà bí ìró ogunlọ́gọ̀.”—Dáníẹ́lì 10:6.
11. Ipa wo ni ìran náà ní lórí Dáníẹ́lì àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀?
11 Bí ìran yẹn ṣe dán yanran tó yìí, Dáníẹ́lì sọ pé, ‘àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi kò rí ìrísí náà.’ Fún ìdí kan tí a kò ṣàlàyé, “ìwárìrì ńláǹlà bò wọ́n, tí wọ́n fi fẹsẹ̀ fẹ láti fi ara wọn pa mọ́.” Nítorí náà, ó ku Dáníẹ́lì nìkan sí ẹ̀bá odò náà. Rírí tí ó rí “ìrísí títóbi yìí” bà á lẹ́rù tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́wọ́ pé: “Agbára kankan kò sì ṣẹ́ kù sínú mi, iyì mi sì yí padà nínú mi di èyí tí ó bàjẹ́, èmi kò sì ní agbára mọ́.”—Dáníẹ́lì 10:7, 8.
12, 13. Kí ni (a) aṣọ ońṣẹ́ náà fi hàn nípa ẹni tí ó jẹ́? (b) ìrísí ońṣẹ́ náà fi hàn nípa ẹni tí ó jẹ́?
12 Ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ kíyè sí ońṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ yìí tí ó mú kí jìnnìjìnnì bo Dáníẹ́lì tó bẹ́ẹ̀. “Ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, ó sì fi wúrà Úfásì di ìgbáròkó rẹ̀ ní àmùrè.” Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́ tí a fi wúrà ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ni a fi ń ṣe àmùrè, éfódì, àti ìgbàyà olórí àlùfáà àti aṣọ àwọn àlùfáà yòókù. (Ẹ́kísódù 28:4-8; 39:27-29) Nípa bẹ́ẹ̀, ìmúra ońṣẹ́ náà fi hàn pé ó jẹ́ mímọ́ àti pé ipò ńlá ni ó wà.
13 Ìrísí ońṣẹ́ náà tún ba Dáníẹ́lì lẹ́rù, ìyẹn ni bí ara rẹ̀ tí ó rí bí òkúta iyebíye ṣe ń tàn yinrin yinrin, ìrànyòò ojú rẹ̀ dídán tí ó lè múni lójú, bí ìbẹ́ṣẹ̀ṣẹ̀ ẹyinjú rẹ̀ tí ó rí bí iná ṣe ń wọni lára, àti bí apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ alágbára ṣe ń dán gbinrin. Kódà ìró ohùn rẹ̀ alágbára ń kó jìnnìjìnnì báni. Gbogbo èyí fi hàn dájúdájú pé kì í ṣe ènìyàn ẹlẹ́ran ara lásán. Áńgẹ́lì onípò gíga kan, tí ó ń sìn ní ibi mímọ́ níwájú Jèhófà, ni ẹni tí “ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀” yìí ní láti jẹ́, kò lè jẹ́ ẹlòmíràn, ibẹ̀ ni ó sì ti mú ìsọfúnni kan wá.a
A FÚN “ỌKÙNRIN FÍFANI-LỌ́KÀN-MỌ́RA GIDIGIDI” KAN LÓKUN
14. Ìrànlọ́wọ́ wo ni Dáníẹ́lì nílò kí ó bàa lè gbọ́ ìsọfúnni tí áńgẹ́lì náà mú wá?
14 Iṣẹ́ ńlá tí ó sì díjú pọ̀ gan-an ni áńgẹ́lì Jèhófà fẹ́ jẹ́ fún Dáníẹ́lì. Dáníẹ́lì nílò ìrànwọ́ kí ṣìbáṣìbo tí ó bá ara àti ìrònú rẹ̀ lè lọ, kí ó tó lè gbọ́ ìsọfúnni náà. Ó dájú pé áńgẹ́lì yìí mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sì fi tìfẹ́tìfẹ́ fún Dáníẹ́lì ní ìrànwọ́ àti ìṣírí tí ó nílò. Ẹ jẹ́ kí a gbọ́ bí Dáníẹ́lì ṣe fúnra rẹ̀ sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀.
15. Kí ni áńgẹ́lì náà ṣe láti fi ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́?
15 “Bí mo sì ti ń gbọ́ ìró ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì ṣẹlẹ̀ pé èmi fúnra mi sùn lọ fọnfọn ní ìdojúbolẹ̀, tí mo dojú kọ ilẹ̀.” Bóyá ìbẹ̀rù àti ṣìbáṣìbo ti mú kí iyè Dáníẹ́lì fò lọ. Kí ni áńgẹ́lì náà wá ṣe láti ràn án lọ́wọ́? Dáníẹ́lì sọ pé: “Wò ó! ọwọ́ kan kàn mí, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó ru mí sókè láti dìde dúró lórí eékún mi àti àtẹ́lẹwọ́ mi.” Síwájú sí i, áńgẹ́lì náà fún wòlíì náà níṣìírí pé: “Dáníẹ́lì, ìwọ ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi, ní òye ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ fún ọ, sì dìde dúró níbi tí o ti dúró sí tẹ́lẹ̀, nítorí a ti rán mi sí ọ nísinsìnyí.” Ìrànwọ́ àti ọ̀rọ̀ atuni-nínú yẹn mú Dáníẹ́lì sọ jí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáníẹ́lì “ń gbọ̀n,” ó “dìde dúró.”—Dáníẹ́lì 10:9-11.
16. (a) Báwo ni a ṣe lè rí i pé Jèhófà máa ń tètè dáhùn àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀? (b) Kí ni kò jẹ́ kí áńgẹ́lì náà tètè dé láti wá ṣèrànwọ́ fún Dáníẹ́lì? (Fi àpótí kún un.) (d) Iṣẹ́ wo ni áńgẹ́lì náà fẹ́ jẹ́ fún Dáníẹ́lì?
16 Áńgẹ́lì náà sọ pé ìdí gan-an tí òun fi wá ni láti fún Dáníẹ́lì lókun. Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Má fòyà, ìwọ Dáníẹ́lì, nítorí láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí o ti fi ọkàn-àyà rẹ fún òye, tí o sì ti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ, a ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, èmi fúnra mi sì ti wá nítorí ọ̀rọ̀ rẹ.” Áńgẹ́lì náà wá ṣàlàyé ìdí tí kò fi tètè dé. Ó sọ pé: “Ṣùgbọ́n ọmọ aládé ilẹ̀ ọba Páṣíà dúró ní ìlòdìsí mi fún ọjọ́ mọ́kànlélógún, sì wò ó! Máíkẹ́lì, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tí ó wà ní ipò iwájú pátápátá, wá láti ràn mí lọ́wọ́; ní tèmi, mo wà níbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọba Páṣíà.” Bí Máíkẹ́lì ṣe ran áńgẹ́lì náà lọ́wọ́, ó wá ṣeé ṣe fún un láti jẹ́ iṣẹ́ tí a rán an, ó mú ìsọfúnni tí ó jẹ́ kánjúkánjú jù lọ yìí wá fún Dáníẹ́lì pé: “Mo . . . ti wá láti mú kí o fi òye mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́, nítorí ó jẹ́ ìran kan fún àwọn ọjọ́ tí ó ṣì ń bọ̀.”—Dáníẹ́lì 10:12-14.
17, 18. Báwo ni a ṣe ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kejì, kí ni èyí sì jẹ́ kí ó lè ṣe?
17 Dípò tí ara Dáníẹ́lì ì bá fi yá gágá pé a fẹ́ jẹ́ irú iṣẹ́ tí ó gbani láfiyèsí bẹ́ẹ̀ fún òun, ó dà bí pé ńṣe ni ohun tó gbọ́ gbòdì lára rẹ̀. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Wàyí o, nígbà tí ó sọ irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún mi, mo gbé ojú mi sí ilẹ̀ mo sì di aláìlèsọ̀rọ̀.” Ṣùgbọ́n, áńgẹ́lì ońṣẹ́ náà múra tán láti ṣèrànwọ́ tìfẹ́tìfẹ́—lẹ́ẹ̀kejì. Dáníẹ́lì sọ pé: “Wò ó! ẹnì kan tí ìrí rẹ̀ dà bí ti ọmọ aráyé fọwọ́ kan ètè mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí la ẹnu mi, mo sì sọ̀rọ̀.”b—Dáníẹ́lì 10:15, 16a.
18 A fún Dáníẹ́lì lókun nígbà tí áńgẹ́lì náà fọwọ́ kan ètè rẹ̀. (Fi wé Aísáyà 6:7.) Bí ohùn Dáníẹ́lì ṣe tún là padà, ó wá lè ṣàlàyé fún áńgẹ́lì ońṣẹ́ náà nípa ìṣòro tí ó ń bá òun fínra. Dáníẹ́lì sọ pé: “Olúwa mi, nítorí ìrísí náà, ìsúnkì iṣan mú mi, èmi kò sì ní agbára kankan. Nítorí náà, báwo ni ìránṣẹ́ olúwa mi yìí ṣe lè bá olúwa mi yìí sọ̀rọ̀? Ní tèmi, títí di ìsinsìnyí, kò sí agbára kankan nínú mi, kò sì sí èémí kankan tí ó ṣẹ́ kù sínú mi.”—Dáníẹ́lì 10:16b, 17.
19. Báwo ni a ṣe ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kẹta, kí sì ni ìyọrísí èyí?
19 Kì í ṣe pé Dáníẹ́lì ń ráhùn tàbí pé ó ń ṣàwáwí. Ńṣe ló wulẹ̀ ń sọ ìṣòro rẹ̀, áńgẹ́lì náà sì gba ohun tí ó wí. Bí áńgẹ́lì ońṣẹ́ náà ṣe tún ṣèrànwọ́ fún Dáníẹ́lì lẹ́ẹ̀kẹta nìyẹn. Wòlíì náà sọ pé: “Ẹni náà tí ó ní ìrísí ará ayé sì bẹ̀rẹ̀ sí tún fọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi lókun.” Ońṣẹ́ náà tún sọ ọ̀rọ̀ atunilára yìí lẹ́yìn tí ó fọwọ́ kàn án lọ́nà tí ó fún un lágbára, ó wí pé: “Má fòyà, ìwọ ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi. Kí o ní àlàáfíà. Jẹ́ alágbára, bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ alágbára.” Ó dà bí pé ìfọwọ́kanni onífẹ̀ẹ́ yẹn àti ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró wọ̀nyẹn ni ohun tí Dáníẹ́lì nílò gẹ́lẹ́. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Dáníẹ́lì ṣàlàyé pé: “Kété tí ó . . . bá mi sọ̀rọ̀, mo sa okun mi, níkẹyìn mo wí pé: ‘Kí olúwa mi sọ̀rọ̀, nítorí ìwọ ti fún mi lókun.’” Dáníẹ́lì ti ṣe tán wàyí láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ takuntakun mìíràn.—Dáníẹ́lì 10:18, 19.
20. Èé ṣe tí ó fi béèrè ìṣapá lọ́dọ̀ áńgẹ́lì ońṣẹ́ náà kí ó tó lè ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un?
20 Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì náà ti fún Dáníẹ́lì lókun, tí ó ti bá a mú iyè rẹ̀ sọ jí, tí ó sì ti fún un lágbára, ó tún sọ ète tí ó fi wá lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sọ pé: “O ha mọ ìdí tí mo fi wá sọ́dọ̀ rẹ bí? Nísinsìnyí, èmi yóò padà lọ bá ọmọ aládé Páṣíà jà. Nígbà tí mo bá jáde lọ, wò ó! ọmọ aládé ilẹ̀ Gíríìsì yóò wá pẹ̀lú. Bí ó ti wù kí ó rí, èmi yóò sọ àwọn nǹkan tí a ti kọ sínú ìwé òtítọ́ fún ọ, kò sì sí ẹni tí ó tì mí lẹ́yìn gbágbáágbá nínú nǹkan wọ̀nyí bí kò ṣe Máíkẹ́lì, ọmọ aládé yín.”—Dáníẹ́lì 10:20, 21.
21, 22. (a) Láti inú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Dáníẹ́lì, kí ni a lè rí kọ́ nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò? (b) Kí ni a wá fún Dáníẹ́lì lókun láti lè ṣe wàyí?
21 Jèhófà mà jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú o! Ó ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní iṣẹ́ ṣe ní ìbámu pẹ̀lú bí agbára wọn bá ṣe mọ àti ohun tí apá wọn bá ká. Àmọ́, iṣẹ́ tí ó máa ń pín fún wọn jẹ́ èyí tí ó mọ̀ pé wọ́n lè ṣe láṣeparí, bí wọ́n tilẹ̀ rò pé àwọn kò ní lè ṣe é. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ó ṣe tán láti fetí sí wọn, kí ó sì pèsè ohun tí wọ́n bá nílò láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí iṣẹ́ tí ó yàn fún wọn. Ǹjẹ́ kí a dà bí Jèhófà, Baba wa ọ̀run, nípa fífún àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa níṣìírí kí a sì máa fún wọn lókun tìfẹ́tìfẹ́.—Hébérù 10:24.
22 Ìsọfúnni atuni-nínú tí áńgẹ́lì náà mú wá jẹ́ ìṣírí ńláǹlà fún Dáníẹ́lì. Láìka bí Dáníẹ́lì ṣe di arúgbó tó sí, a ti fún un lókun wàyí, ó sì ti gbára dì láti gba àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan síwájú sí i kí ó sì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ fún àǹfààní wa.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò dárúkọ áńgẹ́lì yìí, ó dà bí pé òun kan náà ni ẹni tí a gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ó ń sọ fún Gébúrẹ́lì pé kí ó ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ nípa ìran tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí nígbà yẹn. (Fi Dáníẹ́lì 8:2, 15, 16 wé Da 12:7, 8.) Síwájú sí i, Dáníẹ́lì 10:13 fi hàn pé Máíkẹ́lì, “ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tí ó wà ní ipò iwájú pátápátá,” wá ran áńgẹ́lì yìí lọ́wọ́. Nípa báyìí, áńgẹ́lì tí a kò dárúkọ rẹ̀ yìí ti ní àǹfààní láti bá Gébúrẹ́lì àti Máíkẹ́lì ṣiṣẹ́ pọ̀ tímọ́tímọ́.
b Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ áńgẹ́lì kan náà tí ń bá Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ ni ó fọwọ́ kan ètè rẹ̀ tí ó sì mú un sọ jí, ọ̀nà tí a gbà sọ̀rọ̀ níhìn-ín ṣì lè fàyè gba pé kí ó jẹ́ áńgẹ́lì mìíràn, bóyá Gébúrẹ́lì, ni ó ṣe èyí. Bí ó ti wù kí ó jẹ́, áńgẹ́lì ońṣẹ́ kan ni ó fún Dáníẹ́lì lókun.
KÍ LO LÓYE?
• Èé ṣe tí áńgẹ́lì Jèhófà kò fi lè tètè dé láti wá ṣèrànwọ́ fún Dáníẹ́lì ní ọdún 536 tàbí 535 ṣááju Sànmánì Tiwa?
• Kí ni aṣọ àti ìrísí áńgẹ́lì ońṣẹ́ Ọlọ́run fi hàn nípa irú ẹni tí ó jẹ́?
• Ìrànlọ́wọ́ wo ni Dáníẹ́lì nílò, báwo sì ni áńgẹ́lì náà ṣe pèsè rẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹta?
• Iṣẹ́ wo ni áńgẹ́lì náà fẹ́ jẹ́ fún Dáníẹ́lì?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 204, 205]
Ṣé Áńgẹ́lì Adáàbòboni Ni Wọ́n Ni Tàbí Ẹ̀mí Èṣù Tí Ń Ṣàkóso?
OHUN púpọ̀ ni a lè rí kọ́ láti inú ohun tí ìwé Dáníẹ́lì sọ nípa àwọn áńgẹ́lì. Ó sọ fún wa nípa ipa tí wọ́n ń kó nínú ṣíṣe ohun tí Jèhófà bá sọ àti ìsapá tí wọ́n máa ń ṣe láti rí i pé àwọn ṣe iṣẹ́ tí a bá yàn fún wọn.
Áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ pé bí òun ṣe ń bọ̀ láti wá bá Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀, “ọmọ aládé ilẹ̀ ọba Páṣíà” ṣèdíwọ́ fún òun. Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì ońṣẹ́ náà ti bá a jà fún ọjọ́ mọ́kànlélógún, “Máíkẹ́lì, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tí ó wà ní ipò iwájú pátápátá,” wá ṣèrànwọ́ fún áńgẹ́lì ońṣẹ́ náà, ìgbà náà ni ó sì tó lè tẹ̀ síwájú. Áńgẹ́lì náà tún sọ pé òun yóò ní láti tún padà bá ọ̀tá yẹn jà, bóyá àti “ọmọ aládé ilẹ̀ Gíríìsì” pẹ̀lú. (Dáníẹ́lì 10:13, 20) Iṣẹ́ yìí kò rọrùn, àní fún áńgẹ́lì kan pàápàá! Àmọ́, àwọn wo wá ni ọmọ aládé ilẹ̀ Páṣíà àti ti Gíríìsì wọ̀nyí?
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a ṣàkíyèsí pé a pe Máíkẹ́lì ní “ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tí ó wà ní ipò iwájú pátápátá,” àti “ọmọ aládé yín.” Lẹ́yìn ìyẹn, a tọ́ka sí Máíkẹ́lì gẹ́gẹ́ bí “ọmọ aládé ńlá tí ó dúró nítorí àwọn ọmọ àwọn ènìyàn [Dáníẹ́lì].” (Dáníẹ́lì 10:21; 12:1) Èyí fi Máíkẹ́lì hàn gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì tí Jèhófà yàn pé kí ó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la aginjù kọjá.—Ẹ́kísódù 23:20-23; 32:34; 33:2.
Gbólóhùn tí ọmọ ẹ̀yìn náà, Júúdà, sọ pé “Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì ní aáwọ̀ pẹ̀lú Èṣù, tí ó sì ń ṣe awuyewuye nípa òkú Mósè,” ti ohun tí a sọ yìí lẹ́yìn. (Júúdà 9) Ipò, agbára, àti ọlá àṣẹ Máíkẹ́lì yìí, ni ó fi jẹ́ “olú-áńgẹ́lì” lóòótọ́, èyí tí ó túmọ̀ sí “olórí àwọn áńgẹ́lì,” tàbí “ọ̀gá àwọn áńgẹ́lì.” Kò sí ẹlòmíràn tí ipò gíga fíofío yìí tọ́ sí lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú jù lọ, àyàfi Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ṣáájú kí ó tó wá gbé láyé àti lẹ́yìn ìgbà yẹn.—1 Tẹsalóníkà 4:16; Ìṣípayá 12:7-9.
Èyí ha wá túmọ̀ sí pé ńṣe ni Jèhófà tún yan àwọn áńgẹ́lì sórí àwọn orílẹ̀-èdè bíi Páṣíà àti Gíríìsì, kí wọ́n lè máa darí wọn nínú àwọn àlámọ̀rí wọn bí? Tóò, Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, sọ ọ́ gbangba gbàǹgbà pé: ‘Olùṣàkóso ayé kò ní ìdìmú kankan lórí mi.’ Jésù tún sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí . . . ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.” (Jòhánù 14:30; 18:36) Àpọ́sítélì Jòhánù kéde pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Ó dájú pé àwọn orílẹ̀-èdè ayé kò fìgbà kankan rí wà lábẹ́ ìdarí tàbí àkóso Ọlọ́run tàbí ti Kristi, wọn kò sì sí níbẹ̀ nísinsìnyí pẹ̀lú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà gba “àwọn aláṣẹ onípò gíga” láàyè láti wà kí wọ́n sì máa ṣàkóso ọ̀ràn ìjọba ayé, kò yan àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sórí wọn. (Róòmù 13:1-7) Sátánì Èṣù, “olùṣàkóso ayé,” nìkan ni ẹni tí ó máa ń yan “àwọn ọmọ aládé” tàbí “olùṣàkóso” èyíkéyìí tí ó bá jẹ lé wọn lórí. Àwọn ẹ̀mí èṣù tí ń ṣàkóso ni ìwọ̀nyí yóò jẹ́ dípò áńgẹ́lì adáàbòboni. Nígbà náà, àwọn ẹ̀mí èṣù tàbí “àwọn ọmọ aládé” tí a kò lè fojú rí ni ó wà lẹ́yìn àwọn alákòóso tí a lè fojú rí, ọ̀ràn ìjà láàárín orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn sì ré kọjá kìkì ìjà láàárín ènìyàn sí ènìyàn lásán.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 199]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 207]