Dáníẹ́lì
9 Ní ọdún kìíní Dáríúsì+ ọmọ Ahasuérúsì, àtọmọdọ́mọ àwọn ará Mídíà, ẹni tí wọ́n fi jọba lórí ìjọba àwọn ará Kálídíà,+ 2 ní ọdún kìíní ìjọba rẹ̀, èmi Dáníẹ́lì fi òye mọ̀ látinú ìwé,* iye ọdún tí Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà pé Jerúsálẹ́mù fi máa wà ní ahoro,+ ìyẹn àádọ́rin (70) ọdún.+ 3 Mo wá yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, mo bẹ̀ ẹ́ bí mo ṣe ń gbàdúrà sí i, pẹ̀lú ààwẹ̀,+ aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú. 4 Mo gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run mi, mo jẹ́wọ́, mo sì sọ pé:
“Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni ńlá, tó yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+ 5 a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe ohun tí kò dáa, a ti hùwà burúkú, a sì ti ṣọ̀tẹ̀;+ a ti kọ àwọn àṣẹ rẹ àti àwọn ìdájọ́ rẹ sílẹ̀. 6 A ò fetí sí àwọn wòlíì tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ,+ tí wọ́n bá àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa, àwọn baba ńlá wa àti gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ. 7 Jèhófà, tìrẹ ni òdodo, àmọ́ àwa ni ìtìjú bá, bó ṣe rí lónìí yìí, àwa èèyàn Júdà, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn tó wà nítòsí àti lọ́nà jíjìn, ní gbogbo ilẹ̀ tí o fọ́n wọn ká sí torí pé wọn ò jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.+
8 “Jèhófà, àwa ni ìtìjú bá, àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa àti àwọn baba ńlá wa, torí pé a ti ṣẹ̀ ọ́. 9 Àánú àti ìdáríjì jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run wa,+ torí a ti ṣọ̀tẹ̀ sí i.+ 10 A ò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa nípa títẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀ tó fún wa nípasẹ̀ àwọn wòlíì tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 11 Gbogbo Ísírẹ́lì ti tẹ Òfin rẹ lójú, wọ́n sì ti yà kúrò nínú rẹ̀ torí pé wọn ò ṣègbọràn sí ohùn rẹ, tí o fi da ègún àti ìbúra lé wa lórí, èyí tí wọ́n kọ sínú Òfin Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́,+ torí pé a ti ṣẹ̀ Ẹ́. 12 Ó ti ṣe ohun tó sọ lòdì sí àwa+ àti àwọn alákòóso wa tí wọ́n jọba lé wa lórí,* torí ó mú kí àjálù ńlá ṣẹlẹ̀ sí wa; ohunkóhun ò ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ gbogbo ọ̀run bí èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.+ 13 Bí a ṣe kọ ọ́ sínú Òfin Mósè, gbogbo àjálù yìí ti dé bá wa,+ síbẹ̀ a kò bẹ Jèhófà Ọlọ́run wa pé* kó ṣojúure sí wa, nípa yíyí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ ká sì fi ìjìnlẹ̀ òye hàn nínú òótọ́* rẹ.
14 “Torí náà, Jèhófà wà lójúfò, ó sì mú àjálù bá wa, torí Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ olódodo nínú gbogbo iṣẹ́ tó ti ṣe; síbẹ̀, a ò ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀.+
15 “Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run wa, Ìwọ tí o fi ọwọ́ agbára mú àwọn èèyàn rẹ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ tí o sì ṣe orúkọ fún ara rẹ títí di òní yìí,+ a ti ṣẹ̀, a sì ti hùwà burúkú. 16 Jèhófà, gẹ́gẹ́ bíi gbogbo ìṣe òdodo rẹ,+ jọ̀ọ́, dáwọ́ ìbínú àti ìrunú rẹ dúró lórí ìlú rẹ, Jerúsálẹ́mù, òkè mímọ́ rẹ; torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àṣìṣe àwọn baba ńlá wa, gbogbo àwọn tó yí wa ká ń gan Jerúsálẹ́mù àti àwọn èèyàn rẹ.+ 17 Ní báyìí, Ọlọ́run wa, fetí sílẹ̀ sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ tàn sára ibi mímọ́ rẹ+ tó ti di ahoro,+ torí tìẹ, Jèhófà. 18 Ọlọ́run mi, tẹ́tí sílẹ̀, kí o sì gbọ́! La ojú rẹ, kí o sì rí ìyà tó ń jẹ wá àti bí ìlú tí a fi orúkọ rẹ pè ṣe di ahoro; kì í ṣe torí àwọn ìṣe òdodo wa la ṣe ń bẹ̀ ọ́, torí àánú rẹ tó pọ̀ ni.+ 19 Jèhófà, jọ̀ọ́ tẹ́tí gbọ́. Jèhófà, jọ̀ọ́ dárí jì.+ Jèhófà, jọ̀ọ́ fiyè sí wa, kí o sì gbé ìgbésẹ̀! Má ṣe jẹ́ kó pẹ́, torí tìẹ, Ọlọ́run mi, torí orúkọ rẹ la fi pe ìlú rẹ àti àwọn èèyàn rẹ.”+
20 Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, tí mò ń gbàdúrà, tí mò ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì, tí mo sì ń bẹ̀bẹ̀ fún ojúure Jèhófà Ọlọ́run mi nítorí òkè mímọ́ Ọlọ́run mi,+ 21 àní, bí mo ṣe ń gbàdúrà lọ́wọ́, ọkùnrin náà Gébúrẹ́lì,+ ẹni tí mo ti rí nínú ìran tẹ́lẹ̀,+ wá sọ́dọ̀ mi nígbà tí okun ti tán nínú mi pátápátá, nígbà tí àkókò ọrẹ alẹ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó. 22 Ó sì là mí lóye, ó sọ pé:
“Ìwọ Dáníẹ́lì, mo wá láti fún ọ ní ìjìnlẹ̀ òye àti ìmọ̀. 23 Nígbà tí o bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀bẹ̀, ọ̀rọ̀ jáde lọ, mo sì wá ròyìn rẹ̀ fún ọ, torí o ṣeyebíye gan-an.*+ Torí náà, ro ọ̀rọ̀ náà, kí ìran náà sì yé ọ.
24 “A ti pinnu àádọ́rin (70) ọ̀sẹ̀* fún àwọn èèyàn rẹ àti ìlú mímọ́ rẹ,+ láti fòpin sí àṣìṣe, láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́,+ láti ṣe ètùtù torí ìṣìnà,+ láti mú òdodo tó máa wà títí láé wá,+ láti gbé èdìdì lé ìran náà àti àsọtẹ́lẹ̀*+ àti láti fòróró yan Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́.* 25 Mọ èyí, kó sì yé ọ pé látìgbà tí a bá ti pàṣẹ pé ká dá Jerúsálẹ́mù pa dà sí bó ṣe wà,+ ká sì tún un kọ́, títí di ìgbà Mèsáyà*+ Aṣáájú,+ ọ̀sẹ̀ méje máa wà àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta (62).+ Wọ́n máa mú kó pa dà sí bó ṣe wà, wọ́n sì máa tún un kọ́, ó máa ní ojúde ìlú, wọ́n sì máa gbẹ́ kòtò ńlá yí i ká, àmọ́ á jẹ́ ní àkókò wàhálà.
26 “Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta (62) náà, wọ́n máa pa Mèsáyà,*+ láìṣẹ́ ohunkóhun kù fún ara rẹ̀.+
“Àwọn èèyàn aṣáájú tó ń bọ̀ máa pa ìlú náà àti ibi mímọ́ náà run.+ Àkúnya omi ló sì máa fòpin sí i. Ogun á sì máa jà títí dé òpin; a ti pinnu pé ó máa di ahoro.+
27 “Ó máa mú kí májẹ̀mú náà wà lẹ́nu iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, fún ọ̀sẹ̀ kan; ní ìdajì ọ̀sẹ̀ náà, ó máa mú kí ẹbọ àti ọrẹ dópin.+
“Ẹni tó ń sọ nǹkan di ahoro máa wà lórí ìyẹ́ àwọn ohun ìríra;+ títí dìgbà ìparun, a máa da ohun tí a pinnu sórí ẹni tó ti di ahoro pẹ̀lú.”