Ori 4
Ijọba naa “Dé”—Lati Ibo?
1. Lori ìpìlẹ̀ ohun tí ó wà ninu 1 Timoteu 1:17 ati Ìfihàn 15:3, awọn ibeere pataki wo ni a gbé dide?
NIWỌN bi Bibeli ti ṣapejuwe Jehofa gẹgẹ bi “Ọba ayeraye,” eeṣe tí ijọba kan fi nilati “dé” lati sọ orukọ rẹ̀ di mímọ́? (1 Timoteu 1:17; Ìfihàn 15:3) Lati ibo ni o sì ti wá?
2. Awọn ipò wo ninu ijọba ni ó ti mú ẹ̀gàn wá sori orukọ Ọlọrun, lọna wo sì ni?
2 Lakọọkọ ná, ó ṣe kedere pe iyipada ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kan nilati ṣẹlẹ̀ ki a baa lè mú ododo, alaafia, ati ayọ padabọ si ilẹ̀-ayé yii. Kii ṣe kiki pe ijọba kọọkan ti kuna lọpọlọpọ ọna lati bojuto ire awọn ọmọ-abẹ wọn nikan ni, ṣugbọn awọn orilẹ-ede ń dá araawọn lagara. Ikoriira, ìbánidíje, ati awọn ẹ̀tanú orilẹ-ede ti pín awọn eniyan ati ìran yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Awọn ipò wọnyi lọna gbígbòòrò ṣojú lọna òdì fun ete Ẹlẹ́dàá naa, ó sì ti ṣokunfa ọpọlọpọ ẹ̀gàn tí a kójọ sori orukọ rẹ̀.—Romu 2:24; Esekieli 9:9.
3. (a) Bawo ni Ijọba Ọlọrun ṣe “wá” sinu aworan yii? (b) Ki ni ohun tí ó jẹ́ àkànṣe tobẹẹ nipa Ijọba naa?
3 Lati tún ipò yii ṣe, a nílò ijọba akanṣe kan. Eyi sì ni ohun tí Jehofa pese. Lati ibo ni o ti wá? Lati ọ̀dọ̀ Jehofa fúnraarẹ̀ ni, ẹni tí ó ń gbé ninu awọn ọrun. Ó jẹ́ ijọba kan ti kò dádúró fúnraarẹ̀ tí ń fi ipò ọba-aláṣẹ agbaye ti Jehofa fúnraarẹ̀ hàn. Ó rí ọla-aṣẹ rẹ̀ gbà lati inu ipò ọba tí Jehofa ti lò lati ibẹrẹ, tipẹ́tipẹ́ kí a tó dá awọn ọrun ati ilẹ̀-ayé wa. Niwọn bi ó ti jẹ́ pe lati inu eto-ajọ Ọlọrun ti ọrun ni a ti bí i, akoso àkànṣe atọrunwa yii jogún awọn animọ agbayanu ti ipò ọba-aláṣẹ àtọdúnmọ́dún ti Jehofa.—Ìfihàn 12:1, 2, 5.
IPÒ ỌBA-ALÁṢẸ AGBAYE JEHOFA
4. Ọ̀rọ̀ asọjade wo ninu Ìfihàn 4:11 ni ó ṣapejuwe ipò ọba-aláṣẹ Jehofa lọna tí ó ṣe wẹ́kú?
4 Nitori pe oun “dá ohun gbogbo” Ọlọrun ni Ọba-aláṣẹ tí ó ni ẹ̀tọ́ lori gbogbo ẹda tí ń bẹ láàyè. Kódà awọn wọnni tí Ọlọrun gbega si ipò-ọba ninu awọn ọrun gbọdọ “wólẹ̀ niwaju ẹni tí ó jokoo lori ìtẹ́,” ki wọn “sì tẹriba fun ẹni tí ń bẹ láàyè lae ati laelae.” Awọn wọnyi fi ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́wọ́ ipò ọba-aláṣẹ gigajulọ ti “Ọba ayeraye” naa—gẹgẹ bi a ti fihan ninu apejuwe yii ti a ṣe nipa wọn siwaju sii:
“Wọn si fi ade wọn lelẹ niwaju ìtẹ́ naa, wi pe, Oluwa, iwọ ni o yẹ lati gba ogo ati ọla ati agbara: nitori pe iwọ ni o da ohun gbogbo, ati nitori ifẹ inu rẹ ni wọn fi wà ti a si dá wọn.” (Ìfihàn 4:10, 11; Efesu 3:9)
Eyiini ha ni ojú tí iwọ fi ń wò ipò ọba-aláṣẹ Ọlọrun bi? Ó yẹ ki ó jẹ́ bẹẹ.
5. Ní ifiwera pẹlu awọn ijọba eniyan, bawo ni ipò ọba Jehofa ṣe jẹ́ eyi ti o ni gbogbo nǹkan ni ànípé?
5 Laaarin awọn eniyan ijọba kan maa ń ṣakoso ní ibamu pẹlu ofin. Eyi pọndandan fun pipa ètò mọ́. Bi ó ti saba maa ń rí, ètò ijọba maa ń ní ninu awọn onidaajọ tí ń ṣẹjọ awọn ọ̀ràn labẹ ofin, awọn igbimọ aṣofin ti ń ṣofin, ati ọba kan tabi ààrẹ kan tí ń mú ofin ṣẹ. Ninu agbaye tí ó dá, Jehofa Ọlọrun di gbogbo irúfẹ́ awọn ipò mẹtẹẹta bẹẹ mú gẹgẹ bi wolii Isaiah ti fihan, nigba tí ó wi pe: “Oluwa ni onidajọ wa, Oluwa ni Olofin wa, Oluwa ni ọba wa.” (Isaiah 33:22) Nipa eyi ni Ọba Dafidi fi awọn ọ̀rọ̀ wọnyi kún un pe: “Oluwa ti pese ìtẹ́ rẹ̀ ni ọrun; ijọba rẹ̀ ni o si bori ohun gbogbo.” (Orin Dafidi 103:19) Ẹ jẹ́ ki a ṣe ayẹwo awọn apá diẹ ninu ipò ọba naa.
AWỌN OFIN AGBAYE TI ỌLỌRUN
6. Ki ni fi ìlọ́lájù awọn ofin Ọlọrun hàn?
6 Awọn ijọba eniyan ń wá ọ̀nà lati ṣakoso ìṣesí awọn eniyan ọmọ-abẹ wọn, ṣugbọn wọn kò lè ṣèkáwọ́ awọn ipá àdánidá eyi tí ó kan igbesi-aye wọn lọna jijinlẹ tobẹẹ. Jehofa, Ọba-aláṣẹ Agbaye, lè ṣe bẹẹ, ó sì ń ṣe bẹẹ. Awọn eniyan onimọ-ijinlẹ ti ṣe kayefi nipa iṣedeedee awọn ofin nipasẹ eyi tí a fi ń ṣakoso agbaye wa tí a lè fojuri. Awọn wọnyi jẹ́ ofin Ọlọrun. Ó jẹ́ nitori pe iru awọn ofin bẹẹ ń ṣiṣẹ laisi àyídà ni ó mú ki ó ṣeeṣe fun awọn eniyan lati gúnlẹ̀ sori oṣupa, lati banisọrọ nipasẹ awọn satẹlaiti, lati sọtẹlẹ nipa iyipada ojú-ọjọ́ ati lati hùmọ̀ ẹgbẹẹgbẹrun awọn ohun dídíjú. Awọn ofin Ọlọrun pẹlu tún ń ṣakoso oòrùn ati òjò, oun sì lè ṣakoso iwọnyi fun ibukun awọn wọnni tí wọn ṣègbọ́ràn si i.—Orin Dafidi 89:8, 11-13; Jobu 38:33, 34; Sekariah 14:17.
7. (a) Bawo ni awọn ofin Jehofa ṣe jẹrii si jíjẹ́-ọlọrun rẹ̀? (b) Gẹgẹ bi Jobu, bawo ni o ṣe yẹ ki a ka awọn ọna Ọlọrun sí?
7 Pẹlu itọkasi awọn ẹda ọrun tí a ṣeto nigínnigín, wolii Ọlọrun wi pe: ‘Ẹ gbe ojú yin soke ki ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọnyi, ti ń mu ogun wọn jade wá ni iye: o ń pe gbogbo wọn ni orukọ nipa titobi ipa rẹ̀, nitori pe oun le ni ipá; kò si ọkan ti o kù. Iwọ kò tíì mọ̀? iwọ kò tíì gbọ́ pe, Ọlọrun ayeraye, Oluwa, ni ẹlẹdaa gbogbo ipẹkun ayé.’ (Isaiah 40:26, 28) Là ọpọ billion ọdun já ni Jehofa ti ṣakoso agbaye rẹ̀ salalu nipasẹ ohun tí a ń pè ní ofin “àdánidá.” Awọn eniyan ti gbiyanju lati rí ojútùú aṣiri awọn ofin wọnyi, ṣugbọn pupọpupọ ṣì ń bẹ tí wọn nilati kẹkọọ rẹ̀! Iwọn bín-ín-tín ni wọn fi lọ siwaju jù ọkunrin olùṣòtítọ́ naa ti 3,500 ọdun sẹhin, ẹni tí ó kede pe: “Kiyesii, eyi ni opin ọ̀nà rẹ̀. Ohùn eyi tí a gbọ́ ti kere tó! Ṣugbọn ààrá ipá rẹ̀ ta ni òye rẹ̀ lè yé?”—Jobu 26:14.
8. Awọn ànímọ́ Ọlọrun miiran wo ni ó sopọṣọkan, tí ó ń fi i hàn gẹgẹ bi Olùpèsè Atobilọla?
8 Bi ó ti wù ki ó rí, ní dídá ilẹ̀-ayé wa, Jehofa ṣe pupọ jù wiwulẹ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lori ìpìlẹ̀ awọn ofin iṣẹda rẹ̀ aṣeéfojúrí. Àwámáridìí ọgbọn ati ifẹ aláìṣeédíwọ̀n rẹ̀ ni a sopọṣọkan pẹlu agbára rẹ̀ ati awọn ofin rẹ̀, ní ṣiṣe imurasilẹ agbayanu fun awọn olugbe ilẹ̀-ayé ní ẹ̀hìn-ọ̀la. Ẹ wo iru ìríran jinna onínúrere, òye-iṣẹ́ tí ń ṣeni-ní-hàá, ti a kíyèsí ninu iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Ọlọrun níhìn-ín lori ilẹ̀-ayé! (1 Johannu 4:8; Orin Dafidi 104:24; 145:3-5, 13) Gẹgẹ bi a ti ṣakiyesi ninu ori iṣaaju kan, Jehofa dajudaju jẹ́ Olùpèsè Atobilọla!
9. Ki ni diẹ ninu awọn ohun tí o yẹ ki a dupẹ lọwọ Ọlọrun fun?
9 Awa nilati dupẹ lọwọ Ọlọrun fun gbogbo awọn ìpèsè agbayanu rẹ̀. Pẹlupẹlu, a nilati dupẹ lọwọ rẹ̀ fun ọna tí oun gbà ṣiṣẹ-ọnà tí ó sì dá awa eniyan, pẹlu agbara wa nipa ti ara ati ti ọpọlọ ati awọn làákàyè wa nipa eyi tí a lè gbà rí ayọ ninu awọn iṣẹda rẹ̀. Bẹẹni, a nilati múratán lati jẹ́wọ́ fun Ọlọrun, gẹgẹ bi olorin naa ti ṣe pe: “Emi yoo yìn ọ; nitori tẹ̀rùtẹ̀rù ati tiyanutiyanu ni a dá mi; iyanu ni iṣẹ rẹ; eyi nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dajudaju. Ẹ̀dá ara mi kò pamọ kuro lọdọ rẹ, nigba tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀, tí a sì ń ṣiṣẹ mi ní àràbárà ní ìhà isalẹ ilẹ̀-ayé. Ojú rẹ ti rí ohun ara mi tí ó wà láìpé: ati ninu ìwé [iṣẹ́-ọnà] rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn sí, ní ojoojumọ ni a ń dá wọn, nigba tí ọ̀kan wọn kò tíì sí.”—Orin Dafidi 139:14-16.
10. Ki ni fi Jehofa hàn pe o dáńgájíá ní kíkún lati mú awọn ọ̀ràn tọ́ lori ilẹ̀-ayé?
10 Jehofa Oluwa Ọba-aláṣẹ, ẹni tí ó dá agbaye ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, tí ó fìdí eto-igbekalẹ awọn nǹkan múlẹ̀ lati inu ifẹ ati ọgbọn rẹ̀, ati ní ibamu pẹlu awọn ofin ododo rẹ̀, ni ẹni naa tí Bibeli tún sọrọ nipa rẹ̀ pe: “Otitọ ati ẹ̀tọ́ ni ibujokoo ìtẹ́ rẹ: aanu ati otitọ yoo maa lọ siwaju rẹ.” (Orin Dafidi 89:14) Dajudaju Jehofa wà ní ipò lati mú akoso Ijọba kan jade tí yoo tún awọn nǹkan ṣe ní ilẹ̀-ayé. (Orin Dafidi 40:4, 5) Ṣugbọn bawo ni oun ṣe ṣe eyi?
ṢÍṢÍ ÀṢÍRÍ KAN PAYÁ
11. (a) Eeṣe, lonii, tí awa fi nilati layọ pe imọ tootọ wà larọwọọto? (b) Bawo ni awa ṣe lè dá “Mikaeli” mọ̀yàtọ̀, kí sì ni orukọ rẹ̀ tumọsi?
11 Ninu Bibeli a rí ọpọlọpọ asọtẹlẹ tí ó tọkasi gbigbe ti Ọlọrun gbé ijọba kan kalẹ tí yoo yà orukọ rẹ̀ si mímọ́ tí yoo sì mú ki a ṣe ifẹ-inu rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé. Ọ̀kan ninu awọn wọnyi ni asọtẹlẹ Danieli, eyi tí ó tọkasi “igba ikẹhin” nigba tí “ìmọ̀ yoo si di pupọ.” Awa lè layọ pe irúfẹ́ imọ bẹẹ wà larọwọọto wa lonii. Nitori pe Danieli sọ fun wa pe:
“Akoko wahala yoo si wà, iru eyi ti kò tii si rí, lati igba ti orilẹ-ede ti wà titi fi di igba akoko yi, ati ni igba akoko naa ni a o gba awọn eniyan rẹ là.”
Gẹgẹ bi Danieli ti wí, eyi yoo jẹ́ ní akoko naa nigba tí Mikaeli ọmọ-alade nla naa bá dide fun ire awọn eniyan Ọlọrun. Bibeli fihan pe Jesu Kristi ni Mikaeli, ẹni tí ó bá awọn ọ̀tá Ọlọrun jagun ki o baa lè yà orukọ Jehofa sí mímọ́. Lọna tí ó bamu, nigba naa, orukọ naa, “Mikaeli” tumọsi “Ta Ni Ó Dabi Ọlọrun?” nitori pe Mikaeli ni ó fẹ̀rí hàn pe kò si ẹnikan tí ó lè fi iyọrisirere pe ipò ọba-aláṣẹ Jehofa níjà.—Danieli 12:1, 4; Ìfihàn 12:7-10.
12. Ki ni àlá naa tí a yaworan rẹ̀ ninu Danieli 2:31-33, eeṣe tí ó fi yẹ ki a ní ifẹ ninu rẹ̀ lonii?
12 Asọtẹlẹ Danieli tún sọ fun wa pẹlu nipa àlá kan tí Ọba Nebukadnessari ti Babiloni lá, àlá kan nipa ìdìde awọn ijọba. Kiakia ni ọba naa gbagbe ohun tí àlá naa jẹ́, bi ó tilẹ jẹ́ pe ó daamu rẹ̀ gidigidi. Nikẹhin, Jehofa Ọlọrun, “ẹni ti o ń fi àṣírí hàn funni,” lò Danieli lati mú ki ó di mímọ̀ fun ọba, kii ṣe àlá naa nikan ni ṣugbọn itumọ rẹ̀ pẹlu. (Danieli 2:29) Niwọn bi imuṣẹ àlá alasọtẹlẹ yii ti nasẹ̀ titi dé ati rekọja ọjọ wa, o yẹ ki a ni ifẹ jijinlẹ si itumọ rẹ̀. Àlá naa jẹ́ nipa “èrè nla” kan tí ó ní irisi eniyan—ìrí rẹ̀ dẹ́rù ba ni. Iwọ lè kà nipa rẹ̀ ninu Danieli 2:31-33. Ki ni ère naa yàwòrán rẹ̀?
13. Ki ni awọn oniruuru apá tí ń bẹ lara ère naa yàwòrán rẹ̀?
13 Danieli sọ ọ di mímọ̀ fun Nebukadnessari pe ori wúrà rẹ̀ duro fun “ọba” Babiloni, ati pe awọn apá isalẹ ara rẹ̀ duro fun awọn ijọba miiran tí yoo dide lẹhin Babiloni. Lonii, awa mọ̀ awọn wọnyi si awọn ilẹ-ọba alágbára ńlá ti Medo-Persia, Griki, ati Romu, pẹlu “awọn ẹsẹ̀” tí ó nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ Agbara Ayé aláwẹ́-méjì ti Gẹẹsi ati America ti ode-oni. Ṣugbọn ki ni nipa ti ẹsẹ̀, tí ó jẹ́ “apakan amọ̀ ati apakan irin”? Ní awọn ọdun lọwọlọwọ yii, awọn ẹgbẹ eleto akoso afẹ́nifẹ́re tí ó gbajúmọ̀ ti sọ ọla-aṣẹ tí ó dabi irin tí ó wà ninu Agbara Ayé Gẹẹsi ati America di aláìlágbára lọna ti o kọyọyọ, àní gẹgẹ bi awọn ẹsẹ̀ ère nla naa ti di ẹlẹgẹ́ nitori pe irin “kò dàpọ̀ mọ́ amọ̀.” Nipa bayii, ère bibanilẹru yii duro fun ìtòtẹ̀léra “awọn ọba” eniyan, tabi awọn agbára ayé tí yoo kásẹ̀nílẹ̀ nigba tí Ijọba Ọlọrun bá pa wọn run.—Danieli 2:36-44.
14, 15. Ki ni “okuta” naa ṣe sí ère naa, bawo ni a sì ṣe lè dá “okuta” naa mọ̀yàtọ̀?
14 Ẹ wò ó! “Okuta” kan ni a gé lọna iyanu lati ara òkè-ńlá kan, “laisi ọwọ́.” Kò si irinṣẹ eniyan kankan tí a lè fojuri tí a lò lati mu iṣẹ yii ṣe. Kaka bẹẹ, Jehofa fúnraarẹ̀ ni ó mú un wáyé, ní ibamu pẹlu ifẹ-inu rẹ̀ mímọ́. Ní yíyí bìríbìrí lọ síhà ère ragaji naa, okuta naa kọlu awọn ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó tẹ̀ gbogbo igbekalẹ iṣakoso eniyan ní àtẹ̀rẹ́, tí ó fi jẹ pe iyoku ni a fọ́nká bi ìyàngbò sinu afẹfẹ. Okuta naa fúnraarẹ̀ wá di òkè-ńlá kan tí ó kún gbogbo ayé.—Danieli 2:34, 35.
15 Ki ni “okuta” yii lè jẹ́? Asọtẹlẹ naa mú gbogbo iyemeji kuro nigba tí ó wi pe:
“Ní ọjọ awọn ọba wọnyi [agbara ayé Gẹẹsi ati America ati awọn àṣẹ́kù tí wọn là á já lara awọn agbara ayé tí wọn ti wà ṣaaju rẹ̀] ni Ọlọrun ọrun yoo gbé ijọba kan kalẹ̀, eyi ti a kì yoo lè parun titi lae: a kì yoo si fi ijọba naa lè orilẹ-ede miiran lọwọ, yoo sì fọ́ tutu, yoo si pa gbogbo ijọba wọnyi run, ṣugbọn oun o duro títí laelae.”—Danieli 2:44.
16. Ní gbigbadura pe, “Jẹ́ kí ijọba rẹ dé,” awọn ohun wo ni awa ń béèrè fun?
16 Ki ni eyi tumọsi fun wa lonii? Ó tumọsi pe nigba tí a bá ń gbadura pe ki Ijọba Ọlọrun “dé,” niti tootọ awa ń béèrè pe ki Ijọba ọrun naa lò agbara iparun rẹ̀ ní títẹ gbogbo awọn ijọba araye ní àtẹ̀pa, eyi tí ó ti kùnà lọna tí ó bani-ninu-jẹ lati mú alaafia ati aásìkí wá. Lọna ti o dunmọni-ninu, “okuta” naa, lẹhin tí ó bá ti pari iṣẹ iparun rẹ̀ tán, oun fúnraarẹ̀ yoo dagba di òkè-ńlá kan ti ijọba tí ó kún gbogbo ilẹ̀-ayé. Yoo mú alaafia wá, iru eyi tí araye kò tíì mọ̀ rí lati igba ọjọ Ọba Solomoni, “ọpọlọpọ alaafia niwọn bi oṣupa yoo ti pẹ́ tó”—eyi tí ó tumọsi titilae!—Orin Dafidi 72:7.
17. (a) Eeṣe tí ipò ìbátan “okuta” naa si “òkè-ńlá” ìpilẹ̀ṣẹ̀ naa ṣe yẹ ki o fun wa ní ìgbọ́kànlé? (b) Ìgbésẹ̀ siwaju sii wo ni Ijọba naa gbé? (c) Gẹgẹ bi a ti sọ ọ ninu Orin Dafidi 85:8-12, ìgbọ́kànlé wo ni ó yẹ ki a ní?
17 Bi ó ti wù ki ó rí, ki ni nipa ti “òkè-ńlá” naa, lati inu eyi tí a ti gé “okuta” Ijọba yii? (Danieli 2:45) “Okuta” naa gbọdọ gbáralé, ki ó sì jẹ́ eyi tí a fi ohun-èèlò kan-naa ṣe bii ti òkè-ńlá naa, ó sì rí bẹẹ nitootọ. Iṣakoso Ijọba yii ni a gé lati inu apapọ gbogbo ipò ọba-aláṣẹ Ọba ayeraye naa—Jehofa Ọlọrun. Gan-an gẹgẹ bi ipò ọba-aláṣẹ agbaye Jehofa ti gbé gbogbo animọ rere rẹ̀ yọ, bẹẹ gẹ́gẹ́ ni Ijọba naa tí a gé lati inu ipò ọba-aláṣẹ yẹn gbọdọ gbé Jehofa Ọlọrun ati awọn ète atobilọla rẹ̀ ga. Yoo sọ orukọ rẹ̀ di mímọ́ nipa títẹ awọn ọ̀tá rẹ̀ rẹ́, ní fifihan pe oun kii ṣe alatilẹhin awọn iṣẹ́ buruku wọn. Lẹhin naa ni Ijọba yii lati ọwọ́ Kristi Jesu yoo kún ilẹ̀-ayé pẹlu ofin ati ètò, ati pẹlu ifẹ ati ìdùnnú, ni yiyí i pada di ibi ododo ati alalaafia tí Ọlọrun ti pete lati ibẹrẹ. Nitootọ, a gbọdọ maa gbadura pe ki ‘Ijọba naa dé’!—Orin Dafidi 85:8-12.