Ori 3
Ohun Tí Ijọba naa Tumọsi fun Ilẹ̀-ayé Wa
1, 2. Bawo ni dídé Ijọba naa ṣe fihan pe Ọlọrun bikita fun ilẹ̀-ayé ati awọn eniyan inu rẹ̀?
ADURA àwòṣe Jesu ń báa lọ pẹlu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi: “Jẹ́ kí ijọba rẹ dé. Jẹ́ kí ìfẹ́-inú rẹ ṣẹ, gẹgẹ bi ti ọrun, lori ilẹ̀-ayé pẹlu.” (Matteu 6:10, NW) Ọlọrun ń ṣaniyan gidigidi nipa ilẹ̀-ayé wa, ati pẹlu nipa gbogbo awọn tí ń gbé ati awọn tí wọn ti gbé níhìn-ín rí. Idi niyẹn tí Ijọba naa yoo fi dé, lati “run awọn tí ń pa ayé run,” lati pese fun ajinde awọn oku, lati mú ọ̀tá naa iku kuro ati lati sọ òbíríkítí ilẹ́-ayé wa di ile alayọ, alalaafia fun ibugbe araye.—Ìfihàn 11:15, 18; 21:1, 3, 4.
2 Nigba naa, bawo ni ó ti yẹ tó lati fi iharagaga fi awọn ọ̀rọ̀ wọnni gbadura, “Jẹ́ kí ijọba rẹ dé”! Eyi ni Ijọba Ọlọrun lọwọ Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi Oluwa. Nipasẹ rẹ̀ ifẹ-inu Jehofa ẹni tí oun fúnraarẹ̀ jẹ́ “Ọba ayeraye,” ni a ó sọ di ṣiṣe lori ilẹ̀-ayé yii. Ṣakiyesi ohun tí eyi yoo tumọsi fun awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede:
“ỌMỌ-ALÁDÉ ALAAFIA” NAA Ń ṢAKOSO
3, 4. (a) Iparapọ Awọn Orilẹ-ede ti kuna laika mímú awọn ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ wo ṣẹ si araarẹ̀, eesitiṣe? (b) Ohun èèlò kanṣoṣo wo ni ó lè pese alaafia pipẹtiti, nipasẹ ọ̀nà wo si ni?
3 Ní fifojusọna fun iṣakoso Ijọba Kristi, wolii Ọlọrun ṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi “Ọmọ-Aládé Alaafia,” ó sì fikun un pe, “Ijọba yoo bisii, alaafia ki yoo ní ìpẹ̀kun.” Wolii kan-naa mú un dá wa lójú pe: “Wọn yoo fi idà wọn rọ ohun-eelo ìtúlẹ̀, wọn yoo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; orilẹ-ede ki yoo gbé idà soke si orilẹ-ede; bẹẹ ni wọn ki yoo kọ́ ogun-jíjà mọ́.” Bi ó tilẹ jẹ́ pe awọn ọ̀rọ̀ tí ó gbẹ̀hìn wọnyi ni a kọ sara ògiri ibi gbalasa tí ó wà ní odikeji opopona ibi ti Iparapọ Awọn Orilẹ-ede wà, kii ṣe ẹgbẹ́ awọn orilẹ-ede yẹn tí rogbodiyan ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ni ó ń mú asọtẹlẹ naa ṣẹ. Nitori pe Iparapọ Awọn Orilẹ-ede ti kùnà bámúbámú gẹgẹ bi eto kan lati fidi alaafia ati ailewu múlẹ̀ laaarin awọn orilẹ-ede.—Isaiah 2:4; 9:6, 7.
4 Alaafia tootọ tí ó pẹtiti ń beere pe ki idajọ ododo wà fun gbogbo eniyan, ododo ti a fi ṣe ìwà-hù niti tootọ. Kìkì Ijọba “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa nikan ni ó lè mú eyi daju; a ó ‘fidi rẹ̀ mulẹ gbọnyin, a ó sì mú un duro nipasẹ ododo.’ Bẹẹni, Ijọba yẹn ni ohun èèlò Ọlọrun fun pipese “ni ayé alaafia, ifẹ inu rere si eniyan.”—Isaiah 9:7; 32:17; Luku 2:14.
5. Ní fifi idi alaafia gidi mulẹ, ki ni awọn ohun yiyanilẹnu tí Ijọba naa ṣaṣepari rẹ̀?
5 Bawo ni Ijọba naa yoo ṣe ṣe eyi? Lọna titayọ, yoo jẹ́ nipasẹ ‘dídé’ Ijọba Ọlọrun nipasẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia” rẹ̀ lodisi awọn orilẹ-ede ayé tí wọn ń jagun. Orin Dafidi 46:8, 9 késí wa pe: “Ẹ wá wò awọn iṣẹ Oluwa [“Jehofa,” NW], iru ahoro tí ó ṣe ní ayé. Ó mú ọ̀tẹ̀ [“ogun,” NW] tán dé opin ayé; ó ṣẹ́ ọrun, ó sì ké ọ̀kọ̀ meji; ó sì fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná.” Ijọba naa yoo fofinde gbogbo awọn ohun-ija ìwà-ipá. Siwaju sii, ki yoo fàyègba awọn jàǹdùkú oníwà-ibi ati awọn afipá-bánilòpọ̀ lati maa pá gúlọ́gúlọ́ kiri awọn ojú-pópó, nitori pe labẹ Ijọba Ọlọrun “awọn ọlọkan tutu ni yoo jogun ayé; wọn yoo sì maa ṣe inudidun ninu ọpọlọpọ alaafia.”—Orin Dafidi 37:9-11.
ÀKÀWÉ ALASỌTẸLẸ KAN
6. Imuṣẹ ológo wo ni asọtẹlẹ Bibeli ní ní ọ̀rúndún kẹfa B.C.E.?
6 Ọpọlọpọ asọtẹlẹ inu Bibeli ni ó tọkasi oko-òǹdè Israeli igbaani. Lẹhin ṣiṣiṣẹsin Babiloni fun 70 ọdun, iyoku awọn ọmọ Israeli olùṣòtítọ́ pada si ilẹ wọn ní 537 B.C.E. Ní gbogbo awọn ọdun wọnyẹn, ni ilẹ naa fi wà ní ahoro, aginjù kan. Ṣugbọn nisinsinyi, pẹlu ibukun Jehofa lori awọn eniyan rẹ̀, ìyípadà tí ó pẹtẹrí kan ṣẹlẹ. Asọtẹlẹ tí a kọ ní ọgọrọọrun ọdun ṣaaju wá ní imuṣẹ ologo:
“Aginjù ati ilẹ̀ gbígbẹ yoo yọ̀ fun wọn; ijù yoo yọ̀, yoo sì tanná bii lílì. Ni títanná yoo tanná; yoo si yọ̀ ani pẹlu ayọ̀ ati orin: ogo Lebanoni ni a o fi fun un, ẹwà Karmeli oun Ṣaroni; wọn o rí ogo Oluwa, ati ẹwà Ọlọrun wa.”—Isaiah 35:1, 2; tún wò Isaiah 65:18-25; Mika 4:4.
7. Nigba naa, ki ni a lè reti fun ilẹ̀-ayé wa nigba tí Ijọba Ọlọrun bá “dé”?
7 Gẹgẹ bi itan ti jẹrii, awọn asọtẹlẹ wọnyi ní imuṣẹ yiyanilẹnu sara awọn eniyan Ọlọrun tí a mú padabọsipo laaarin ọ̀rúndún naa tẹle itusilẹ wọn kuro ní Babiloni. Nigba tí Ijọba Ọlọrun bá sì “dé” fun bibukun gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun níhìn-ín lori ilẹ̀-ayé, yoo ha ṣe ohun tí ó dinku ní mímú awọn ipò paradise padabọsipo si òbíríkítí ilẹ̀-ayé wa bi? Idahun aláìyẹhùn naa ni Bẹẹkọ! Ijọba naa nitootọ yoo ríi pe àṣẹ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí Ọlọrun fun araye lati ‘ṣe ìkáwọ́ ilẹ̀-ayé,’ ní sisọ gbogbo rẹ̀ di paradise Edeni, ni a ó muṣẹ ní kíkún.—Genesisi 1:28; 2:8-14; Isaiah 45:18.
PARADISE YIKA ILẸ̀-AYÉ
8. Labẹ Ijọba naa, ki ni yoo ṣẹlẹ si ounjẹ ati ìpèsè epo, nitori ṣíṣàmúlò ofin wo si ni?
8 Nigba tí Ijọba Ọlọrun bá “dé,” àìtó ounjẹ ati ìfòsókè owó-ọjà yoo dàwátì, nitori pe “ìkúnwọ́ ọkà ni yoo maa wà lori ilẹ; lori awọn oke-nla ni eso rẹ̀ yoo maa mì.” Baba wa onifẹẹ yoo tún “mú ounjẹ jade lati ilẹ wá, ati ọti-waini tí ń mú inu eniyan dùn, ati òróró tí ń mú ojú rẹ̀ dán, ati ounjẹ tí ń mú eniyan ní àyà le.” (Orin Dafidi 72:16; 104:14, 15) Ki yoo si iṣoro nipa ipinkiri ounjẹ laaarin awọn orilẹ-ede, kò ní sí ìyínlénilọ́wọ́, kò ní sí títò fun ìpèsè epo. Awọn oníwọra ajèrè àjẹpajúdé yoo ti kasẹ nilẹ. Gbogbo araye ni yoo ṣègbọ́ràn si olu ofin naa, “Iwọ fẹ ẹnikeji rẹ bi araarẹ,” ní ṣiṣajọpin pẹlu araawa lẹnikinni-keji ní ibamu pẹlu aini naa.—Jakọbu 2:8.
9. Idaniloju wo ni a ní pe ko ni sí ohun tí yoo pa araye lara nigba naa?
9 Siwaju sii, awa lè fojúsọ́nà pe Ijọba naa yoo káḿbà awọn ìmìtìtì àdánidá, iru bi awọn ìsẹ̀lẹ̀ ati awọn àfẹ́yíká-ìjì lile. Jesu fihan bi eyi ṣe lè ṣeeṣe nigba tí o mú ki “ìjì ńláǹlà” dákẹ́ jẹ́ẹ́. Nipa bayii, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ṣakiyesi pe kódà “afẹfẹ ati òkun ń gbọ́ tirẹ̀.” (Marku 4:37-41) Ní gbogbo ilẹ-akoso ayé ti Ijọba Ọlọrun, kò ní si ohun kan tí yoo panilara, ṣenileṣe tabi mú iparun wá.—Fiwe Isaiah 11:6-9.
10. Ki ni awọn iṣẹ-iyanu rẹpẹtẹ ti Jesu fihan nipa Ijọba naa?
10 A kò ní nilo awọn ilé ìwòsan títóbi lati kó awọn alaisan ara ati ti ọpọlọ sí. Àrùn ọkan-àyà, jẹjẹrẹ ati awọn àmódi miiran tí ń sọnidi akúrẹtẹ̀ ni a ó ti mú kuro, nitori pe Ọ̀gá Oniṣegun naa, Jesu Kristi, yoo ṣàmúlò iniyelori ẹbọ irapada rẹ̀ “fun mímú awọn orilẹ-ede láradá.” Awọn iṣẹ iyanu rẹpẹtẹ ti Jesu ti ṣiṣe iwosan ati jíjí awọn òkú dide, tí o ṣe nigba tí o wà lori ilẹ̀-ayé, wulẹ jẹ́ kìkì ìfihàn kekere ohun tí oun yoo ṣe nipasẹ iṣakoso Ijọba rẹ̀ alagbara. Kódà iku tí araye jogun rẹ̀ ni a ó mú kuro, nitori a mú un dá wa lójú pe “ki yoo sì sí iku mọ́.”—Ìfihàn 21:4; 22:1, 2; Matteu 11:2-5; Marku 10:45; Romu 5:18, 19.
11. Laaarin iṣakoso Ijọba Jesu, ayọ wo ni yoo dé gbogbo rẹ̀ ládé?
11 Eyi ti o tún jẹ òtéńté ayọ!—awọn iboji oku kì yoo tabuku si oju-ilẹ mọ́, nitori pe awọn wọnyi paapaa ni yoo ti ṣofo. “Awọn eso akọso” ninu ajinde, awọn 144,000 ọmọ-ẹhin Jesu aduroṣinṣin, ni a ó sopọṣọkan pẹlu rẹ̀ ninu awọn ọrun gẹgẹ bi alabaakẹgbẹ rẹ̀ ninu Ijọba rẹ̀. Ileri agbayanu naa tí Jesu ṣe pe iyoku awọn òkú “tí ó wà ní isa-oku yoo gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yoo sì jade wá . . . si ajinde” ni a ó muṣẹ pẹlu. Awọn wọnyi yoo ní anfaani oninudidun naa lati di ẹni tí a mú wá si ijẹpipe eniyan gẹgẹ bi awọn ọmọ-abẹ Ijọba naa níhìn-ín lori ilẹ̀-ayé.—Johannu 5:28, 29; Ìfihàn 14:1-5; 20:4-6, 11, 12.
12. (a) Eeṣe tí ó fi yẹ ki o fẹ́ lati gbé titi ayeraye ninu paradise? (b) Ni ibamu pẹlu Johannu 17:3, ki ni a nilati ṣe ki a baa lè wà nibẹ?
12 Iwọ ha dàníyàn lati jẹ́ ọ̀kan lára awọn wọnni tí yoo walaaye lati rí ilẹ̀-ayé yii ti a wẹ̀ mọ́ kuro ninu gbogbo iwa-buruku tí a sì pilẹ̀yí i pada si paradise onídẹ̀ra bi? Iwọ ha dàníyàn lati wà níhìn-ín lati kí awọn oku tí a jí dide káàbọ̀ bi? Iwọ yoo ha fẹ́ lati walaaye titilae lori ilẹ̀-ayé kan tí a sọ di ológo—nibi tí ẹnikan kò ti ni di alailera nitori ọjọ́ ogbó tabi di ẹni tí awọn ohun amọkanyọ ojoojumọ inu igbesi-aye sú? Iwọ lè ṣe bẹẹ, bi iwọ bá tẹle awọn ohun tí Ọlọrun beere fún jijeere ìyè. Jesu sọ ọ lọna rirọrun, nigba tí oun wí ninu adura si Baba rẹ̀ pe: “Iye ainipẹkun naa si ni eyi, ki wọn ki o le mọ̀ ọ́, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹni ti iwọ rán.” (Johannu 17:3) Ẹ wo iru anfaani ti yoo jẹ́ lati walaaye títí ayeraye ninu paradise, nigba tí “ayé yoo kún fun imọ ògo Oluwa, bi omi ti bò òkun”!—Habakkuku 2:14.
“BÚRẸ́DÌ WA FÚN ỌJỌ́ ÒNÍ”
13. Eeṣe tí a lè fi pẹlu ìgbọ́kànlé gbadura fun “búrẹ́dì wa fún ọjọ́ òní”?
13 Bi ó ti wù ki ó rí, awa lonii ń ṣaniyan gidigidi nipa awọn aini wa ti isinsinyi. Fun pupọ ninu wa, níní awọn ohun kòṣeémánìí igbesi-aye ati pipese fun awọn idile wa ti di ìpènijà gidi. Nitori naa kò tó lati wulẹ gbadura si Baba pe ki ó ya orukọ ńlá rẹ̀ si mímọ́ ki o si mu ki ifẹ-inu rẹ di ṣiṣe lori ilẹ̀-ayé nipasẹ dídé Ijọba rẹ̀; awa tún nílò gbigbadura si Ọlọrun fun awọn ohun kòṣeémánìí wa ojoojumọ, fun “búrẹ́dì wa fún ọjọ́ òní.” Eyi ni a lè ṣe pẹlu ìgbọ́kànlé kíkún pe, bi a bá sapá lati gbé ní ibamu pẹlu awọn ilana ododo Ọlọrun tí a sì fi ire Ijọba rẹ̀ si ipò kìn-ín-ní ninu igbesi-aye wa, Ọlọrun yoo ṣe ipa tirẹ̀ gẹgẹ bi Olùpèsè Nla. Ó rí gan-an bi Jesu ti tẹsiwaju lati wi fun wa: “Ẹ máṣe ṣàníyàn lae ki ẹ sì wi pe, ‘Ki ni awa yoo jẹ?’ tabi, ‘Ki ni awa yoo mu?’ tabi, ‘Ki ni awa yoo wọ̀?’ Nitori gbogbo iwọnyi ni awọn nǹkan ti awọn orílẹ̀-èdè ń lépa pẹlu ìháragàgà. Nitori Baba yin ọ̀run mọ̀ pe, ẹ nilo gbogbo nǹkan wọnyi. Ẹ maa bá a lọ, nigba naa, ni wiwa ijọba naa ati òdodo [baba] lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo awọn nǹkan [miiran] wọnyi ni a óò sì fi kún un fun yin.”—Matteu 6:11, 31-33, NW.
“DÁRÍ AWỌN GBÈSÈ WA JÌ WA”
14, 15. (a) Ní fifi awọn ọ̀rọ̀ tí ó wà ninu Matteu 6:12 gbadura, bawo ni a ṣe gbọdọ muratan lati huwa? (b) Ninu eyi, awọn apẹẹrẹ àgbàyanu wo ni a lè ṣàfarawé?
14 Ní gbígbé ibatan tímọ́tímọ́ ró pẹlu Baba wa, o pọndandan pe ki a fi tọwọtọwọ gbà pe a jẹ ẹ ni gbese, ki a si jẹwọ awọn ẹ̀ṣẹ̀ ti a ṣẹ Ọlọrun ati awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa. Ó baamu, nigba naa, lati gbadura si Ọlọrun pe: “Dárí awọn gbèsè wa jì wa, gẹgẹ bi awa pẹlu ti dariji awọn ajigbèsè wa.”—Matteu 6:12, NW.
15 Gẹgẹ bi inurere agbayanu kan, tí a kò lẹtọ si rara, Ọlọrun rán Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu, wá si ayé, ki o baa lè “fi ẹmi rẹ̀ ṣe irapada ọpọlọpọ” ninu awa eniyan. Eyi pèsè ìpìlẹ̀ kan fun dídárí awọn ẹṣẹ wa jì wa. (Matteu 20:28) Bawo ni aanu Ọlọrun tí a tipa bayii fihan fun araye ẹlẹṣẹ ti tobi tó! Ẹ wo iru ìdí asunniṣiṣẹ ti a ní, nigba naa, fun gbígbójúfo ailera awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa dá! A gbọdọ muratan paapaa lati lọ jinna ju eyiini lọ: koda lati dárí awọn ẹṣẹ wiwuwo tí awọn eniyan ṣẹ̀ wa jì wọn. Lọna bayii awa lè fi animọ ifẹ gbigbonajanjan naa tí Jesu sọ pe yoo jẹ́ ami tí a fi ń dá awọn Kristian tootọ mọ̀yàtọ̀ hàn si awọn ẹlomiran.—Johannu 13:35; Kolosse 3:13; 1 Peteru 1:22.
“DÁ WA NÍDÈ KÚRÓ LỌ́WỌ́ ẸNI BURÚKÚ NAA”
16, 17. (a) Bawo ni o ṣe yẹ ki a loye awọn ọ̀rọ̀ naa, “Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò”? (b) Bawo ni a ṣe lè hùwà ní ibamu pẹlu adura naa ‘lati dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú naa’?
16 Lákòótán, Jesu fun wa ní itọni lati gbadura si Ọlọrun pe: “Má sì ṣe mú wa wá sinu ìdẹwò, ṣugbọn dá wa nídè kúró lọ́wọ́ ẹni burúkú naa.” (Matteu 6:13, NW) Ẹ maṣe jẹ ki a ronu pe Ọlọrun ń fi awọn ìdẹwò si ipa-ọna wa, tí ó ń mú ki a ṣubu. Kàkà bẹẹ, ọlọ̀tẹ̀ buburu naa tí ó lodisi Ọlọrun, Satani, ni ẹni tí ó fẹ́ yí wa pada kuro lọdọ Ọlọrun.
17 Bi ó ti wù ki ó rí, Baba ń mú wa gbaradì lati “lè duro gbọyingbọyin lodisi awọn ètekéte Eṣu,” bẹẹni, lati bá oun ati awọn agbara ẹmi buburu tí o ń dari jijakadi pẹlu àṣeyọrísírere. Nitori ki a má baa “mú wa wá sinu ìdẹwò,” Ọlọrun pese ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ihamọra ogun tẹmi fun wa, eyi tí a lè gbéwọ̀. Aposteli Paulu ṣapejuwe rẹ̀ ninu Efesu 6:10-18. Bi awa ti dúró gbọnyingbọnyin ní lilo ohun èèlò tí Ọlọrun pèsè yii, tí a ń gbadura láìsinmi, Baba yoo rí sii pe a kò “mú wa wá sinu ìdẹwò,” ṣugbọn pe a “dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú naa.”—1 Peteru 5:6-9.
18. Ní àkópọ̀, ki ni ó wà ninu Adura Àwòṣe naa?
18 Ǹjẹ́ ki orukọ olókìkí ti Jehofa di mímọ́ laipẹ nipa ‘dídé ijọba rẹ̀.’ Ki ifẹ-inu rẹ̀ di ṣiṣe lori ilẹ̀-ayé nipa gbígbá gbogbo ohun buburu kuro ati nipa sisọ ilẹ̀-ayé yii di paradise fun ìyìn rẹ̀. Niwọn igba tí eto-igbekalẹ buburu isinsinyi bá ṣì wà, ǹjẹ́ ki Baba wa ọrun onifẹẹ pese awọn ohun kòṣeémánìí igbesi-aye fun wa, ki ó ràn wa lọwọ lati pa ibatan rere mọ́ pẹlu awọn ẹlomiran ki ó sì gbà wa kuro lọwọ agbara Satani. Awọn ohun tí Jesu kọ́ wa lati maa gbadura fun ni iwọnyi. Adura àwòṣe rẹ̀ ní gbogbo rẹ̀ ninu.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]
OHUN TÍ IJỌBA ỌLỌRUN YOO ṢE
● Yoo gbé ipò ọba-aláṣẹ Jehofa lárugẹ, yoo fi opin sí iṣakoso Satani.
● Yoo palẹ̀ isin eke ati awọn olùṣàkóso aninilára mọ́ kuro lori ilẹ̀-ayé.
● Yoo mú akoso Kristi wọle dé bi “Ọmọ-Aládé Alaafia.”
● Yoo mú ki ilẹ̀-ayé gbèrú bi paradise ológo kan.
● Yoo mú gbogbo àìtó ilé gbígbé, ounjẹ, ati epo kuro.
● Yoo gbé ẹgbẹ awujọ kalẹ lori ipilẹ ifẹ aládùúgbò.
● Yoo káwọ́ awọn ipá iṣẹda, ṣe idiwọ fun ìjábá.
● Yoo mú másùnmáwo, wahala, ara dídùn, irora, ọjọ-ogbó kuro.
● Yoo pa ọ̀tá naa iku, aisan, ati gbogbo ibanujẹ run.
● Yoo jí ọpọ billion eniyan tí ó ti kú dide, lati walaaye titi lae lori ilẹ̀-ayé.