Ọba kan Sọ Ibùjọsìn Jehofa Di Aláìmọ́
“Níti àwọn ènìyàn tí wọn ń mọ Ọlọrun wọn, wọn yóò borí.”—DANIELI 11:32, NW.
1, 2. Ìforígbárí tí ń múnijígìrì wo ni ó ti sàmì sí ọ̀rọ̀-ìtan ènìyàn fún ohun tí ó ju ẹgbàá ọdún lọ?
ÀWỌN ọba méjì tí ń báradíje dìjọ wàákò nínú ìjàkadì àrúnpárúnsẹ̀sí fún ipò àjùlọ. Èyí àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà èkejì, rí ìgòkè sí ipò-ọba gbà, bí ó ti jẹ́ pé fún èyí tí ó rékọjá ẹgbàá ọdún ìjà ogun náà ń bá a lọ. Ní ọjọ́ wa ìjàkadì náà ti nípa lórí ọ̀pọ̀ jùlọ ènìyàn lórí ilẹ̀-ayé ó sì ti pe ìwàtítọ́ àwọn ènìyàn Ọlọrun níjà. Ó wá sópin pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti èyíkéyìí nínú àwọn agbára méjèèjì kò rí tẹ́lẹ̀. Ọ̀rọ̀-ìtàn amúnijígìrì yìí ni a ti ṣípayá rẹ̀ ṣáájú fún wòlíì ìgbàanì náà Danieli.—Danieli, orí 10 sí 12.
2 Àsọtẹ́lẹ̀ náà níí ṣe pẹ̀lú ipò ọ̀tá tí ń báa lọ láàárín ọba àríwá àti ọba gúúsù a sì jíròrò kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ nínú ìwé náà “Ifẹ Tirẹ Ni Ki A Ṣe Li Aiye.”a A fihàn nínú ìwé yẹn pé Siria, ní ìhà àríwá Israeli, ni ọba àríwá ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Lẹ́yìnwá ìgbà náà, Romu ni ó gba ojúṣe náà ṣe. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Egipti ni ọba gúúsù.
Ìforígbárí ní Àkókò Òpin
3. Gẹ́gẹ́ bí angeli náà ti wí, nígbà wo ni a óò tó lóye àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọba àríwá àti ọba gúúsù, àti lọ́nà wo?
3 Angeli náà tí ń ṣípayá àwọn nǹkan wọ̀nyí fún Danieli sọ pé: “Ṣùgbọ́n ìwọ, Danieli sé ọ̀rọ̀ náà mọ́hùn-ún, kí o sì fi èdìdì di ìwé náà, títí fi di ìgbà ìkẹyìn: ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò máa wádìí rẹ̀ [“lọ síwá-sẹ́yìn káàkiri,” NW], ìmọ̀ yóò sì di púpọ̀.” (Danieli 12:4) Bẹ́ẹ̀ni, àsọtẹ́lẹ̀ náà níí ṣe pẹ̀lú àkókò òpin—sáà àkókò kan tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 1914. Láàárín àkókò abàmì yẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò “lọ síwá-sẹ́yìn káàkiri” nínú Ìwé Mímọ́, àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, ìmọ̀ tòótọ́, títíkan òye àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli, yóò di púpọ̀. (Owe 4:18) Bí a ti túbọ̀ ń rìn jìnnà wọnú àkókò yẹn, kúlẹ̀kúlẹ̀ púpọ̀ púpọ̀ síi nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Danieli ni a ti mú ṣe kedere. Báwo, nígbà náà, ni a ṣe níláti lóye àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọba àríwá àti ọba gúúsù ní 1993, ọdún márùndínlógójì nísinsìnyí lẹ́yìn ìmújáde “Ifẹ Tirẹ Ni Ki A Ṣe Li Aiye”?
4, 5. (a) Níbo nínú àsọtẹ́lẹ̀ Danieli nípa ọba àríwá àti ọba gúúsù ni a ti lè wá ọdún 1914 rí? (b) Gẹ́gẹ́ bí angeli náà ti wi, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ ní 1914?
4 Ìbẹ̀rẹ̀ àkókò òpin ní 1914 ni ogun àgbáyé kìn-ín-ní àti àwọn ìdààmú ayé mìíràn tí Jesu sọtẹ́lẹ̀ sàmì sí. (Matteu 24:3, 7, 8) A ha lè wá ọdún yẹn rí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Danieli bí? Bẹ́ẹ̀ni. Ìbẹ̀rẹ̀ àkókò òpin ni “àkókò tí a yànkalẹ̀” tí a tọ́ka sí ní Danieli 11:29. (Wo “Ifẹ Tirẹ Ni Ki A Ṣe Li Aiye,” ojú-ìwé 248.) Ó jẹ́ àkókò kan ti Jehofa ti yànkalẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Danieli, níwọ̀n bí ó ti dé ní òpin 2,520 ọdún tí a fihàn nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Danieli orí 4 tí wọ́n ní ìjẹ́pàtàkì níti àsọtẹ́lẹ̀.
5 Àwọn 2,520 ọdún wọ̀nyẹn, láti ìgbà ìparun Jerusalemu ní 607 B.C.E. nígbà ti Danieli ṣì wà ní èwe títí di 1914 C.E., ni a pè ní “àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Luku 21:24, NW) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti òṣèlú wo ni yóò sàmìsí òpin wọn? Angeli kan ṣí èyí payá fún Danieli. Angeli náà sọ pé: “Yóò [ọba àríwá] sì padà wá ní àkókò tí a yànkalẹ̀, yóò sì wá sí ìhà gúúsù; ṣùgbọ́n kì yóò rí bíi ti ìṣáájú, ní ìkẹyìn.”—Danieli 11:29.
Ọba náà Pàdánù Ogun Kan
6. Ní 1914, ta ní ọba àríwá, ta sì ni ọba gúúsù?
6 Ní 1914 ipa iṣẹ́ ọba àríwá ni Germany tí Kaiser Wilhelm jẹ́ aṣáájú fún ti gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀. (“Kaiser,” láti inu orúkọ oyè Romu náà “Kesari.”) Ìbẹ́sílẹ̀ ìkóguntini ní Europe tún jẹ́ òmíràn nínú ọ̀wọ́ àwọn ìjà àjàmọ̀gá láàárín ọba àríwá àti ọba gúúsù. Ipa iṣẹ́ èyí tí a mẹ́nukàn gbẹ̀yìn yìí, ọba gúúsù, ni Britain, tí ó yára gba Egipti, pápá àkóso ọba gúúsù ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ń gbéṣe nísinsìnyí. Bí ogun náà ti ń báa lọ, Britain ni ìpínlẹ̀ tí ó ń ṣàkóso látòkèèrè tẹ́lẹ̀rí, United States of America darapọ̀ mọ́. Ọba gúúsù di Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì-òun-America, ilẹ̀-ọba tí ó lágbára jùlọ nínú ọ̀rọ̀-ìtàn.
7, 8. (a) Nínú ogun àgbáyé kìn-ín-ní, ní ọ̀nà wo ni àwọn nǹkan kò gba rí ‘bíi ti ìṣáájú’? (b) Kí ni àbájáde ogun àgbáyé kìn-ín-ní, ṣùgbọ́n ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ náà, báwo ni ọba àríwá ṣe hùwàpadà?
7 Nínú àwọn ìforígbárí tí ó ti wà ṣáájú láàárín àwọn ọba méjèèjì náà, Ilẹ̀-Ọba Romu, gẹ́gẹ́ bí ọba àríwá, ti ń fìgbà gbogbo jagunmólú. Ní àkókò yìí, ‘àwọn nǹkan kò rí bíi ti ìṣáájú.’ Èéṣe tí kò fi rí bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ọba àríwá pàdánù ogun náà. Ìdí kan ni pé “ọkọ̀ àwọn ará Kittimu” wá gbéjàko ọba àríwá. (Danieli 11:30) Kí ni àwọn ọkọ̀ wọ̀nyí jẹ́? Ní àkókò Danieli, Kittimu ni Kipru, nígbà tí ogun àgbáyé kìn-ín-ní sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, Kipru ni Britain gba ìpínlẹ̀ rẹ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí ìwé The Zondervan Pictorial Encyclopedia of the Bible ti wí, orúkọ náà Kittimu “gbòòrò débi tí ó fi ní Ìwọ̀-Oòrùn lápapọ̀ nínú, ṣùgbọ́n ní pàtàkì Ìwọ̀-Oòrùn àwọn arìnrìn-àjò ojú òkun.” Bibeli New International Version túmọ̀ gbólóhùn-ọ̀rọ̀ náà “ọkọ̀ àwọn ará Kittimu” sí “ọkọ̀ àwọn ilẹ̀-bèbè-etíkun ìhà ìwọ̀-oòrùn.” Nínú ogun àgbáyé kìn-ín-ní, ẹ̀rí fihàn pé ọkọ̀ àwọn ará Kittimu ni ọkọ̀ àwọn ará Britain, tí ó wà ní ìhà ìwọ̀-oòrùn bèbè-etíkun Europe. Nígbà tí ó yá, àwọn Ọmọ-Ogun ojú omi ti ilẹ̀ Britain ni a fún lókun nípasẹ̀ ọkọ̀ láti ilẹ̀ ìhà ìwọ̀-oòrùn ti North America.
8 Lábẹ́ ìkọlù òjijì yìí, “ìdààmú” bá ọba àríwá ó sì gbà pé a ti ṣẹ́gun òun ní 1918. Ṣùgbọ́n ṣíṣe ṣì kù. “Yóò sì yípadà, yóò sì ní ìbínú sí májẹ̀mú mímọ́ nì; bẹ́ẹ̀ni yóò [gbégbèésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́, NW]; àní òun óò yípadà, yóò sì tún ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó kọ májẹ̀mú mímọ́ náà sílẹ̀.” (Danieli 11:30) Bẹ́ẹ̀ ni angeli náà ṣe sọtẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ó sì rí.
Ọba náà Gbégbèésẹ̀ Lọ́nà Gbígbéṣẹ́
9. Kí ni ó ṣamọ̀nà sí ìdìde Adolf Hitler, báwo ni ó sì ṣe “gbégbèésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́”?
9 Lẹ́yìn ogun, ní 1918, àwọn Apawọ́pọ̀jagun tí wọ́n jagunmólú náà gbé ìmùlẹ̀-àdéhùn àlàáfíà ti ìfìyàjẹni karí Germany, èyí tí ó ṣe kedere pé wọ́n wéwèé láti dọ́gbọ́n febi pa àwọn ènìyàn ìlú Germany títílọ gbére. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí, lẹ́yìn títa gọ̀ọ́gọ̀ọ́ nínú ìdààmú lílégbákan fún àwọn ọdún díẹ̀, Germany wà ní sẹpẹ́ fún ìdìde Adolf Hitler. Ọwọ́ rẹ̀ tẹ agbára gíga jùlọ ní 1933 ó sì dojú àtakò rírorò kọ “májẹ̀mú mímọ́ náà,” tí àwọn ẹni-àmì-òróró arákùnrin Jesu Kristi dúró fún lọ́gán. Nínú èyí ó gbégbèésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́ lòdìsí àwọn Kristian adúróṣinṣin wọ̀nyí, ní ṣíṣenúnibíni sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn lọ́nà ìkà.
10. Ní wíwá ìtìlẹyìn kiri, ta ni Hitler wá àjọṣepọ̀ rẹ̀, pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni?
10 Hitler gbádùn àwọn àṣeyọrí ti ọrọ̀-ajé àti ti ọgbọ́n ìṣèlú, ó gbégbèésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́ nínú pápá yẹn pẹ̀lú. Láàárín ìwọ̀nba ọdún díẹ̀, ó sọ Germany di agbára kan tí kò ṣée fọwọ́ rọ́tì sẹ́yìn, níwọ̀n bí “àwọn tí ó kọ májẹ̀mú mímọ́ náà sílẹ̀” ti ń ràn án lọ́wọ́ nínú ìsapá yìí. Àwọn wo nìwọ̀nyí? Ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀rí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, àwọn aṣáájú Kristẹndọm, tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn wà nínú ipò-ìbátan onímájẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọrun ṣùgbọ́n tí wọ́n ti ṣíwọ́ jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu Kristi tipẹ́tipẹ́ ni. Hitler ṣàṣeyọrí nínú kíkésí “àwọn tí ó kọ májẹ̀mú mímọ́ náà sílẹ̀” fún ìtìlẹ́yìn wọn. Poopu tí ó wà ní Romu wọnú àdéhùn ìmùlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Katoliki, àti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Protẹstanti ní Germany, sì ṣètìlẹ́yìn fún Hitler jálẹ̀ gbogbo ọdún méjìlá ìṣàkóso onípayà rẹ̀.
11. Báwo ni ọba àríwá ṣe “sọ ibùjọsìn di aláìmọ́” báwo ni ó sì ṣe “mú apá-ẹ̀ka ìgbà gbogbo kúrò”?
11 Hitler ṣàṣeyọrí tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi tí ó fi lọ sógun, gẹ́gẹ́ bí angeli náà ti sọtẹ́lẹ̀ lọ́nà títọ́. “Agbára ogun yóò sì dúró ní apá tirẹ̀, wọn ó sì sọ ibi mímọ́ [“ibùjọsìn,” NW], àní ìlú olódi náà di àìmọ́, wọ́n ó sì mú ẹbọ ojoojúmọ́ [“apá-ẹ̀ka ìgbà gbogbo,” NW] kúrò.” (Danieli 11:31a) Ní Israeli ìgbàanì, ibùjọsìn jẹ́ apákan tẹ́ḿpìlì ní Jerusalemu. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí àwọn Ju kọ Jesu sílẹ̀, Jehofa kọ àwọn àti tẹ́ḿpìlì wọ́n sílẹ̀. (Matteu 23:37–24:2) Láti ọ̀rúndún kìn-ín-ní wá, tẹ́ḿpìlì Jehofa ti jẹ́ tẹ̀mí níti gàsíkíyá, tí ìbi mímọ́ nínú àwọn ibi mímọ́ rẹ̀ wà nínú àwọn ọ̀run tí ó sì ní àgbàlá tẹ̀mí kan lórí ilẹ̀-ayé nínú èyí tí àwọn ẹni-àmì-òróró arákùnrin Jesu, Àlùfáà Àgbà náà, ti ń jọ́sìn. Láti àwọn ọdún 1930, ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ti ṣiṣẹ́sìn ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró; fún ìdí yìí, a sọ pé wọ́n ń ṣiṣẹ́sìn ‘nínú tẹ́ḿpìlì Ọlọrun.’ (Ìfihàn 7:9, 15; 11:1, 2; Heberu 9:11, 12, 24) Àgbàlá tẹ́ḿpìlì náà ti orí ilẹ̀-ayé ni a sọ di aláìmọ́ nípasẹ̀ inúnibíni àìdábọ̀ tí a ń ṣe sí àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró náà àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ní àwọn ilẹ̀ tí ọba àríwá ti ń lo àṣẹ ìṣàkóso. Inúnibíni náà múná tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi pé apá-ẹ̀ka ìgbà gbogbo—ẹbọ ìyìn ní gbangba sí orúkọ Jehofa—ni a mú kúrò. (Heberu 13:15) Síbẹ̀ ọ̀rọ̀-ìtàn fihàn pé láìka àwọn ìjìyà ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ sí, àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, papọ̀ pẹ̀lú “àgùtàn mìíràn,” ń báa lọ láti máa wàásù lábẹ́lẹ̀.—Johannu 10:16.
“Ohun Ìsúni-fún-Ìríra”
12, 13. Kí ni “ohun ìsúni-fún-ìríra” náà, àti pé—gẹ́gẹ́ bí ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú náà ti ríi tẹ́lẹ̀—nígbà wo àti báwo ní a ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi?
12 Nígbà tí òpin ogun àgbáyé kejì súnmọ́tòsí, ìdàgbàsókè mìíràn wà. “Wọ́n ó sì gbé ìríra ìsọdahoro nì [“ohun ìsúni-fún-ìríra,” NW] kalẹ̀.” (Danieli 11:31b) “Ohun ìsúni-fún-ìríra” yìí, èyí ti Jesu pẹ̀lú mẹ́nukàn, ni a ti mọ̀ ṣáájú gẹ́gẹ́ bí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí ó lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwé Ìfihàn ti wí. (Matteu 24:15; Ìfihàn 17:8; wo Light, Ìwé Kejì, ojú-ìwé 94.) Ó ṣe èyí nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ní Àpéjọ Ìṣàkóso Ọlọrun ti Ayé Titun ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní 1942, Nathan H. Knorr, ààrẹ kẹta ti Watch Tower Bible and Tract Society, jíròrò àsọtẹ́lẹ̀ Ìfihàn 17 ó sì kìlọ̀ pé ẹranko náà yóò ti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ jáde wá lẹ́ẹ̀kan síi.
13 Ọ̀rọ̀-ìtàn jẹ́rìí sí òtítọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Láàárín August àti October 1944, ní Dumbarton Oaks ní United States, iṣẹ́ ni a bẹ̀rẹ̀ lórí ìwé-àṣẹ ìdásílẹ̀ ohun tí a ó pè ní Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Àwọn orílẹ̀-èdè mọ́kànléláàádọ́ta, títíkan Soviet Union tẹ́lẹ̀rí ni wọ́n fọwọ́sí ìwé-àṣẹ ìdásílẹ̀ náà, nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní October 24, 1945, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí ó ti kógbásílé náà ti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ jáde wá nítòótọ́.
14. Nígbà wo àti báwo ni ìdánimọ̀ ọba àríwá ṣe yípadà?
14 Germany ti jẹ́ olórí ọ̀tá ọba gúúsù nígbà àwọn ogun àgbáyé méjèèjì. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, apákan Germany tún araawọn ṣètò láti di apawọ́pọ̀jagun pẹ̀lú ọba gúúsù. Ṣùgbọ́n apá yòókù Germany wá da araawọn pọ̀ mọ́ ilẹ̀-ọba alágbára gíga mìíràn. Àpapọ̀ ẹgbẹ́ Kọmunist, tí ó ní apákan Germany nínú nísinsìnyí, gbé àtakò lílekoko dìde sí àjọṣepọ̀ Gẹ̀ẹ́sì-òun-America, ìbáradíje tí ó wà láàárín àwọn ọba méjèèjì náà sì di Ogun Tútù.—Wo “Ifẹ Tirẹ Ni Ki A Ṣe Li Aiye,” ojú-ìwé 243 sí 262.
Ọba náà àti Májẹ̀mú Nì
15. Àwọn wo ni “ń ṣe búburú sí májẹ̀mú nì,” irú ipò-ìbátan wo ni wọ́n sì ti ní pẹ̀lú ọba àríwá?
15 Angeli náà sọ nísinsìnyí pé: “Irú àwọn tí ń ṣe búburú sí májẹ̀mú nì ni yóò fi ọ̀rọ̀ ìpọ́nni mú ṣọ̀tẹ̀.” (Danieli 11:32a) Àwọn wo nìwọ̀nyí tí wọ́n ń ṣe búburú sí májẹ̀mú nì? Lẹ́ẹ̀kan síi, kò ju kìkì àwọn aṣáájú Kristẹndọm lọ, àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ pé Kristian ni àwọn ṣùgbọ́n tí wọ́n tipasẹ̀ ìṣe wọn sọ orúkọ náà gan-an tí ìsìn Kristian ń jẹ́ di aláìmọ́. Nígbà ogun àgbáyé kejì, “Ìjọba Soviet sapá láti rí ìtìlẹyìn àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì gbà lọ́nà ti ohun ti ara àti ti ìfúniníṣìírí fún ìgbèjà ilẹ̀ ìbílẹ̀.” (Religion in the Soviet Union, láti ọwọ́ Walter Kolarz) Lẹ́yìn ogun náà, àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣí gbìyànjú láti máa bá ipò ìbáṣọ̀rẹ́ yẹn lọ láìka ìlànà-ètò àìgbọlọ́rungbọ́ tí ó jẹ́ ti agbára tíí ṣe ọba àríwá nísinsìnyí sí.b Nípa báyìí, Kristẹndọm di apákan ayé yìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ—ìpẹ̀yìndà kan tí ń súni-fún-ìríra ni ojú Jehofa.—Johannu 17:14; Jakọbu 4:4.
16, 17. Àwọn wo ni “àwọn tí ó mòye,” báwo sì ni nǹkan ti rí fún wọn lábẹ́ ọba àríwá?
16 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ojúlówó Kristian ń kọ́? “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí ó mọ Ọlọrun yóò mú ọkàn le, wọn ó sì máa ṣe iṣẹ́ agbára. Àwọn tí ó mòye nínú àwọn ènìyàn yóò máa kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀: ṣùgbọ́n wọn ó máa ti ipa ojú idà ṣubú, àti nípa iná, àti nípa ìgbèkùn, àti nípa ìkógun níjọ́ mélòó kan.” (Danieli 11:32b, 33) Nígbà tí àwọn Kristian tí wọ́n ń gbé lábẹ́ ọba àríwá, wà “ní ìtẹríba fún àwọn aláṣẹ onípò-gíga jù” lọ́nà yíyẹ, wọ́n kò tíì jẹ́ apákan ayé yìí rí. (Romu 13:1, NW; Johannu 18:36) Bí wọ́n ti lo ìṣọ́ra láti fi ohun tíí ṣe ti Kesari fún Kesari, wọ́n tún fi “ohun tíí ṣe ti Ọlọrun fún Ọlọrun.” (Matteu 22:21) Nítorí èyí, ìwàtítọ́ wọn ni a pèníjà.—2 Timoteu 3:12.
17 Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Wọ́n ‘borí’ wọ́n sì tún ‘kọsẹ̀.’ Wọ́n kọsẹ̀ níti pé a ṣenúnibíni sí wọn wọ́n sì jìyà lọ́nà mímúná, tí a tilẹ̀ pa àwọn kan pàápàá. Ṣùgbọ́n wọ́n borí níti pé, fún apá tí ó pọ̀ jùlọ, wọ́n dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́. Bẹ́ẹ̀ni, wọ́n ṣẹ́gun ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣẹ́gun ayé. (Johannu 16:33) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọn kò dáwọ́ wíwàásù dúró rí, àní bí wọ́n tilẹ̀ bá araawọn nínú ẹ̀wọ̀n tàbí nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n “kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀.” Láìka inúnibíni sí, ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tí ọba àríwá ń ṣàkóso lè lórí, iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ga sí i. Ọpẹ́lọpẹ́ ìṣòtítọ́ “àwọn tí ó mòye,” apákan tí ń gbòòrò síwájú àti síwájú síí ti àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti farahàn ní àwọn ilẹ̀ wọ̀nyẹn.—Ìfihàn 7:9-14, NW.
18. “Ìrànlọ́wọ́ díẹ̀” wo ni àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró tí ń gbé lábẹ́ ọba àríwá rígbà?
18 Ní sísọ̀rọ̀ nípa inúnibíni sí àwọn ènìyàn Ọlọrun, angeli náà sọtẹ́lẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ nísinsìnyí, nígbà tí wọn ó ṣubú, a ó fi ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́.” (Danieli 11:34a) Báwo ni èyí ṣe ṣẹlẹ̀? Ohun kan ni pé, ayọ̀-ìṣẹ́gun ọba gúúsù nínú ogun àgbáyé kejì yọrísí ìtura ńláǹlà fún àwọn Kristian tí wọ́n ń gbé lábẹ́ agbègbè ìpínlẹ̀ ìṣàkóso ọba àríwá. (Fiwé Ìfihàn 12:15, 16.) Lẹ́yìn náà, àwọn wọnnì tí ọba olùgbapò ṣenúnibíni sí nírìírí ìtura láti ìgbà dé ìgbà, bí Ogun Tútù sì ti dópin ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú òṣèlú wá mọ̀ lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ pé àwọn Kristian olùṣòtítọ́ kìí ṣe ahalẹ̀mọ́ni rárá wọ́n sì wá tipa bẹ́ẹ̀ fún wọn ní ìdánimọ̀ lábẹ́ òfin.c Ìrànlọ́wọ́ ńlá ti wá, pẹ̀lú, nínú iye àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ń pọ̀ síi ṣáá, tí wọ́n ti dáhùnpadà sí ìwàásù àfitọkàntọkàn ṣe ti àwọn ẹni-àmì-òróró tí wọ́n sì ti ràn wọ́n lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Matteu 25:34-40.
Ìwẹ̀nùmọ́ kan fún Àwọn Ènìyàn Ọlọrun
19. (a) Báwo ni àwọn kan ṣe “fi ẹ̀tàn fi ara mọ́ wọn”? (b) Kí ni gbólóhùn-ọ̀rọ̀ náà “títí fi di àkókò òpin” túmọ̀sí? (Wo àkíyèsí ẹsẹ̀-ìwé.)
19 Kìí ṣe gbogbo àwọn tí ó fìfẹ́hàn nínú ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọrun ní àkókò yìí ní wọ́n ní ìsúnniṣe rere. Angeli náà kìlọ̀ pe: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò fi ẹ̀tàn fi ara mọ́ wọn. Àwọn ẹlòmíràn nínú àwọn tí ó mòye yóò sì ṣubú, láti dán wọn wò, àti láti wẹ̀ wọ́n mọ́, àti láti sọ wọ́n di funfun, àní títí fi di àkókò òpin: nítorí pé yóò wá ní àkókò tí a [yànkalẹ̀, NW].”d (Danieli 11:34b, 35) Àwọn kan fi ìfẹ́-ọkàn hàn nínú òtítọ́ ṣùgbọ́n wọn kò múratán láti ṣe ojúlówó ìyàsímímọ́ láti ṣiṣẹ́sin Ọlọrun. Àwọn mìíràn tí ó dàbí ẹni pé wọ́n tẹ́wọ́gba ìhìnrere náà níti gidi jẹ́ amí fún àwọn aláṣẹ. Ìròyìn láti ilẹ̀ kan kà pé: “Díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn aláìtẹ̀lé ìlànà wọ̀nyí jẹ́ àwọn tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti jẹ́ Kọmunist tí wọ́n ti yọ́ wọnú ètò-àjọ Oluwa wá, tí wọ́n fi ìtara ńlá hàn, tí a sì tilẹ̀ yàn wọ́n sí àwọn ipò iṣẹ́-ìsìn gíga pẹ̀lú.”
20. Èéṣe ti Jehofa fi yọ̀ọ̀da kí àwọn Kristian olùṣòtítọ́ kan “kọsẹ̀” nítorí àwọn àsáwọ̀ alágàbàgebè?
20 Àwọn àsáwọ̀ náà mú kí àwọn olùṣòtítọ̀ díẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ àwọn aláṣẹ. Èéṣe ti Jehofa fi yọ̀ǹda kí irúfẹ́ àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀? Fún ìyọ́mọ́, ìwẹ̀nùmọ́ kan ni. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jesu ti “kọ́ ìgbọràn nípa ohun tí ó jìyà,” bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkàn olùṣòtítọ́ wọ̀nyí ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ìfaradà láti inú ìdánwò ìgbàgbọ́ wọn. (Heberu 5:8; Jakọbu 1:2, 3; fiwé Malaki 3:3.) Àwọn ni a tipa bẹ́ẹ̀ ‘yọ́mọ́, wẹ̀nùmọ́, tí a sì sọ di funfun.’ Ayọ̀ ńláǹlà ń dúró de irúfẹ́ àwọn olùṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ nígbà tí àkókò tí a yànkalẹ̀ náà bá dé fún àtisan èrè fún ìfaradà wọn. Èyí ni a óò rí nígbà tí a bá jíròrò díẹ̀ síi nínú àsọtẹ́lẹ̀ Danieli.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., a sì mú un jáde ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ní 1958 níbi Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Àtọ̀runwá” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
b Ìwé-ìròyìn World Press Review ti November 1992 gbé ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan jáde láti inú The Toronto Star tí ó sọ pé: “Ní àwọn ọdún mélòókan tí ó ti kọjá sẹ́yìn, àwọn ará Russia ti rí bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìtànjẹ tí ó ti fìgbà kan rí dàbí aláìṣeégbébèéèrè dìde sí nípa ọ̀rọ̀-ìtàn orílẹ̀-èdè wọn tí ń di èyí tí kò lè dúró lójú àwọn òtítọ́. Ṣùgbọ́n ìsọdimímọ̀ nípa àjùmọ̀ṣiṣẹ́pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì pẹ̀lú ètò-ìjọba kọmunist ni ó dúró fún ìyọnu àgbálù tí ń kódààmú báni jùlọ.”
c Wo Ilé-Ìṣọ́nà, July 15, 1991, ojú-ìwé 8 sí 11.
d “Títí fi di àkókò òpin” lè túmọ̀sí “nígba àkókò òpin.” Ọ̀rọ̀ náà tí a túmọ̀ sí “títí” níhìn-ín farahàn nínú ọ̀rọ̀-ẹsẹ̀-ìwé èdè Aramaic fún Danieli 7:25 ó sì túmọ̀sí “nígbà” tàbí “fún” níbẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà ní irúfẹ́ ìtumọ̀ kan-náà nínú ọ̀rọ̀-ẹsẹ̀-ìwé èdè Heberu fún 2 Ọba 9:22, Jobu 20:5, àti Awọn Onidajọ 3:26. Bí ó ti wù kí ó rí, nínú ìtumọ̀ Danieli 11:35 tí ó pọ̀ jùlọ, a túmọ̀ rẹ̀ sí “títí,” bí ó bá sì jẹ́ pé èyí ni òye tí ó tọ̀nà, nígbà náà “àkókò òpin” níhìn-ín gbọ́dọ̀ jẹ́ àkókò òpin ìfaradà àwọn ènìyàn Ọlọrun.—Fiwé “Ifẹ Tirẹ Ni Ki A Ṣe Li Aiye,” ojú-ìwé 263.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Èéṣe tí àwa lónìí fi níláti retí láti ní òye tí ó túbọ̀ ṣe kedere nípa àsọtẹ́lẹ̀ Danieli?
◻ Báwo ni ọba àríwá ṣe ‘sọ̀kò ọ̀rọ̀ ìfibú tí ó sì gbégbèésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́’?
◻ Báwo ni ẹgbẹ́ ẹrú náà ṣe rí àrítẹ́lẹ̀ ìtúnfarahàn “ohun ìsúni-fún-ìríra náà”?
◻ Báwo ni àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró ṣe ‘kọsẹ̀, borí, tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ gbà’?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Lábẹ́ Hitler, ọba àríwá jèrè okun rẹ̀ padà ní kíkún láti inú ṣíṣẹ́gun tí ọba gúúsù ṣẹ́gun rẹ̀ ní 1918
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn aṣáájú Kristẹndọm gbìyànjú láti mú ipò-ìbátan dàgbà pẹ̀lú ọba àríwá
[Credit Line]
Zoran/Sipa Press