Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Dáníẹ́lì
ÌWÉ atúmọ̀ èdè kan tó ń jẹ́ Holman Illustrated Bible Dictionary sọ pé: “Ìwé Dáníẹ́lì wà lára àwọn ìwé inú Bíbélì tó gbàfiyèsí ẹni jù lọ. Àwọn ọ̀rọ̀ tí òtítọ́ inú wọn ò ṣeé já ní koro ló kúnnú ẹ̀.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 618 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ló bẹ̀rẹ̀ ìtàn inú ìwé Dáníẹ́lì, ìgbà yẹn ni Nebukadinésárì Ọba Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù, tó sàga tì í, tó sì kó “àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì” nígbèkùn lọ sí Bábílónì. (Dáníẹ́lì 1:1-3) Dáníẹ́lì wà lára àwọn tó kó lọ, ó sì lè máa tíì tó ọmọ ogún ọdún nígbà yẹn. Ibi tí ìtàn inú ìwé náà parí sí ni pé Dáníẹ́lì ṣì wà ní Bábílónì. Dáníẹ́lì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún nígbà tí Ọlọ́run ṣèlérí fún un pé: “Ìwọ yóò sì sinmi, ṣùgbọ́n ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.”—Dáníẹ́lì 12:13.
Níbẹ̀rẹ̀ ìwé náà, Dáníẹ́lì kọ ìtàn yẹn bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, ó sì kọ ọ́ bíi pé ẹlòmíì táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ṣojú ẹ̀ ló kọ ọ́; àmọ́ ó kọ apá ìparí rẹ̀ bí ìgbà téèyàn ń sọ ìtàn ara ẹ̀. Ìwé náà sọ nípa bí àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso ayé á ṣe máa dìde àti bí wọ́n á ṣe máa ṣubú, ó tún sọ nípa dídé Mèsáyà, ó sì sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ táá máa ṣẹlẹ̀ lákòókò tiwa.a Àgbàlagbà wòlíì yìí tún mẹ́nu ba àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ níṣojú ẹ̀mí ẹ̀, ó wá sọ àwọn ìtàn tó lè mú kí gbogbo wa dúró gbọn-in gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ lójú Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì yè ó sì ń sa agbára.—Hébérù 4:12.
KÍ NI APÁ IBI TÓ JẸ́ ÌTÀN NÍNÚ ÌWÉ NÁÀ KỌ́ WA?
Ọdún 617 ṣáájú Sànmánì Kristẹni lohun tá a fẹ́ sọ yìí ṣẹlẹ̀. Ààfin ọba Bábílónì ni Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n ń jẹ́ Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò wà. Láàárín ọdún mẹ́ta tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọ̀dọ́ yìí lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe láàfin ọba Bábílónì, wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀. Nígbà tó di bí ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn náà, Nebukadinésárì Ọba lá àlá abàmì kan. Dáníẹ́lì ló rọ́ àlá náà tó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún un. Ọba wá gbà pé Jèhófà ni “Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn ọba, ó sì jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá.” (Dáníẹ́lì 2:47) Àmọ́, kò pẹ́ sígbà yẹn tó fi dà bíi pé Nebukadinésárì ti gbàgbé ẹ̀kọ́ tó kọ́ yẹn. Nígbà táwọn ọ̀rẹ́ Dáníẹ́lì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kọ̀ láti jọ́sìn ère ńlá kan, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n jù wọ́n sínú ìléru oníná. Ọlọ́run tòótọ́ kó àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yọ, kò sì sóhun tí Nebukadinésárì lè ṣe ju kó gbà pé kò sí “ọlọ́run mìíràn tí ó lè dáni nídè bí èyí.”—Dáníẹ́lì 3:29.
Nebukadinésárì tún lá àlá mìíràn tó ní ìtumọ̀ pàtàkì kan. Lójú àlá yẹn, ó rí arabaríbí igi kan, wọ́n wá gé igi náà lulẹ̀ wọ́n sì dè é mọ́lẹ̀ kó má bàa rúwé. Dáníẹ́lì tún sọ ìtumọ̀ àlá yẹn. Àlá náà kọ́kọ́ ṣẹ nígbà tí orí Nebukadinésárì dàrú tí orí ẹ̀ sì tún wálé. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Bẹliṣásárì Ọba se àsè kan tó pe àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn rẹ̀ sí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ohun èlò tí wọ́n kó ní tẹ́ńpìlì Jèhófà níbi àsè yẹn, èyí tí kò yẹ kó lò. Lóru ọjọ́ yẹn gan-an, wọ́n pa Bẹliṣásárì, Dáríúsì ará Mídíà sì gba ìjọba. (Dáníẹ́lì 5:30, 31) Nígbà ìṣàkóso Dáríúsì, tí Dáníẹ́lì ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún ọdún, àwọn òṣìṣẹ́ ọba tó ń jowú wòlíì tó ti darúgbó yìí dìtẹ̀ mọ́ ọn kí wọ́n bàa lè rí i pa. Àmọ́ Jèhófà gbà á sílẹ̀ “kúrò ní àtẹ́sẹ̀ àwọn kìnnìún.”—Dáníẹ́lì 6:27.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:11-15—Ṣé jíjẹ táwọn ọ̀dọ́ mẹ́rin ará Jùdíà yẹn ń jẹ irè oko lásán ló mú kójú wọn máa dán ju tàwọn tó kù lọ? Òun kọ́ ló fà á. Kò sírú àṣàyàn oúnjẹ téèyàn lè fi ọjọ́ mẹ́wàá péré jẹ tó lè mú kéèyàn yàtọ̀ bẹ́ẹ̀ yẹn. Sísan tí Jèhófà san àwọn ọ̀dọ́ Hébérù yìí lẹ́san nítorí bí wọ́n ṣe gbẹ́kẹ̀ lé e ló mú kójú wọn máa dán.—Òwe 10:22.
2:1—Ìgbà wo ni Nebukadinésárì lá àlá nípa arabaríbí ère? Àkọsílẹ̀ yẹn sọ pé “ní ọdún kejì ìgbà àkóso Nebukadinésárì” ni. Ọdún 624 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Nebukadinésárì jọba. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ọdún kejì ìṣàkóso rẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 623 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọ̀pọ̀ ọdún sì kọjá lẹ́yìn ìgbà yẹn kó tó wá gbéjà ko Júdà. Kò sí bí Dáníẹ́lì ṣe fẹ́ wà ní Bábílónì lákòókò yẹn débi táá fi lè túmọ̀ àlá Nebukadinésárì. “Ọdún kejì” yẹn ní láti jẹ́ èyí tá a máa bẹ̀rẹ̀ kíkà rẹ̀ láti ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ìgbà tí ọba Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run tó sì di alákòóso ayé.
2:32, 39—Lọ́nà wo ni ìjọba fàdákà gbà rẹlẹ̀ sí ìjọba ti orí wúrà, báwo sì ni ìjọba bàbà ṣe rẹlẹ̀ sí ìjọba ti fàdákà? Ìṣàkóso Mídíà òun Páṣíà, tí apá tó jẹ́ fàdákà lára ère yẹn dúró fún, rẹlẹ̀ sí Bábílónì tó jẹ́ orí wúrà ní ti pé òun kọ́ ló láǹfààní láti pa Júdà run. Ìṣàkóso Gíríìsì tí bàbà dúró fún ló tẹ̀ lé ìṣàkóso Mídíà òun Páṣíà. Ìjọba Gíríìsì yìí tún wá rẹlẹ̀ sí ti Mídíà òun Páṣíà gẹ́gẹ́ bí bàbà ṣe rẹlẹ̀ sí fàdákà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí Ìṣàkóso Gíríìsì nasẹ̀ dé fẹ̀ gan-an, síbẹ̀ kò ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tí ìṣàkóso Mídíà òun Páṣíà ní, ìyẹn àǹfààní láti tú àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀ ní ìgbèkùn.
4:8, 9—Ṣé lóòótọ́ ni Dáníẹ́lì di àlùfáà pidánpidán? Rárá o. Ohun tí gbólóhùn náà “olórí àwọn àlùfáà pidánpidán” wulẹ̀ ń tọ́ka sí ni ipò Dáníẹ́lì gẹ́gẹ́ bí “olórí pátápátá lórí gbogbo ọlọ́gbọ́n Bábílónì.”—Dáníẹ́lì 2:48.
4:10, 11, 20-22—Kí ni arabaríbí igi inú àlá Nebukadinésárì dúró fún? Nebukadinésárì tó jẹ́ olùṣàkóso ìjọba ayé ni igi yẹn kọ́kọ́ dúró fún. Àmọ́ níwọ̀n bí ìṣàkóso yẹn ti gbilẹ̀ dé “ìkángun gbogbo ilẹ̀ ayé,” igi yẹn ní láti dúró fún ohun kan tó ju Nebukadinésárì lọ fíìfíì. Ohun tó wà nínú Dáníẹ́lì 4:17 jẹ́ ká mọ̀ pé àlá yẹn kan ìṣàkóso “Ẹni Gíga Jù Lọ” lórí aráyé. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, igi yẹn tún dúró fún ìṣàkóso Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba láyé àtọ̀run, pàápàá bó ṣe ń ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé. Èyí wá túmọ̀ sí pé ẹ̀ẹ̀mejì ni àlá yẹn ní ìmúṣẹ. Ó ṣẹ lákọ̀ọ́kọ́ sórí ìṣàkóso Nebukadinésárì, ìmúṣẹ ẹ̀ẹ̀kejì sì jẹ́ sórí ìṣàkóso Jèhófà gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ láyé àtọ̀run.
4:16, 23, 25, 32, 33—Báwo ni “ìgbà méje” yẹn ṣe gùn tó? Ó máa gbà ju ọjọ́ méje lọ fíìfíì kí ìrísí Nebukadinésárì Ọba tó lè yí padà. Torí náà, “ìgbà méje” yẹn gbọ́dọ̀ ju ọjọ́ méje lọ. Nínú ọ̀ràn ti Nebukadinésárì, ìgbà méje yẹn túmọ̀ sí ọdún méje, tí ọdún kọ̀ọ̀kan jẹ́ òjìdínnírínwó [360] ọjọ́, àròpọ̀ gbogbo ọjọ́ tó wà nínú ọdún méjèèje sì wá jẹ́ okòó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,520]. Nínú ìmúṣẹ tó tún jùyẹn lọ, “ìgbà méje” yẹn jẹ́ okòó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,520] ọdún. (Ìsíkíẹ́lì 4:6, 7) Ìgbà méje náà bẹ̀rẹ̀ nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún [607] ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó sì parí nígbà tí Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba lọ́run lọ́dún 1914 Sànmánì Kristẹni.—Lúùkù 21:24.
6:6-10—Nígbà tó jẹ́ pé kò sí béèyàn ṣe dúró tí kò lè gbàdúrà sí Jèhófà, ṣé kò ní bọ́gbọ́n mu ká ní Dáníẹ́lì gbàdúrà ẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ fún ọgbọ̀n ọjọ́? Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́ ni Dáníẹ́lì máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn táwọn ọlọ̀tẹ̀ ṣe wá ọgbọ́n bí wọ́n ṣe máa rí òfin tí ò ní jẹ́ kéèyàn gbàdúrà bó ṣe fẹ́. Tí Dáníẹ́lì bá wá lọ yí bó ṣe ń gbàdúrà padà, ohun tó máa jọ lójú àwọn èèyàn ni pé ó ti pa ìlànà tó ń tẹ̀ lé tì, ìyẹn á sì fi hàn pé kò fi gbogbo ọkàn rẹ̀ jọ́sìn Jèhófà.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:3-8. Bí Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe pinnu láti dúró ṣinṣin ti Jèhófà fi hàn kedere pé àwọn òbí wọn ti ní láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tó múná dóko. Táwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run bá fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn ọmọ wọn náà láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ wọn dúró gbọn-in láìyẹsẹ̀ nígbà tí àdánwò bá dé bá wọn tàbí tẹ́nikẹ́ni bá fẹ́ mú wọ́n ṣe ohun tí kò dáa nílé ìwé tàbí níbòmíì.
1:10-12. Dáníẹ́lì mọ̀dí tí “sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin” fi bẹ̀rù ọba, kò sì wulẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ náà déwájú ẹ̀ mọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, Dáníẹ́lì lọ bá “olùtọ́jú,” tó ṣeé ṣe kó lágbára láti ṣe ohun tí Dáníẹ́lì fẹ́. Táwa náà bá ń bójú tó ọ̀ràn kan tó nira, ó yẹ ká fojú inú wo ipò yẹn bíi ti Dáníẹ́lì ká sì lo irú ọgbọ́n àti òye tó lò.
2:29, 30. Bíi ti Dáníẹ́lì, Jèhófà ni ká máa gbé gbogbo ògo fún nítorí ìmọ̀, ànímọ́ tàbí agbára èyíkéyìí tó wù ká ní nítorí ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́.
3:16-18. Kò dájú pé àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yẹn á lè fìgboyà dáhùn bẹ́ẹ̀ yẹn, ká ní ṣáájú ìgbà yẹn wọ́n ti jẹ oúnjẹ tí òfin Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ. Àwa náà ní láti sapá ká lè jẹ́ “olùṣòtítọ́ nínú ohun gbogbo.”—1 Tímótì 3:11.
4:24-27. Ó gba ìgbàgbọ́ àti ìgboyà kí Dáníẹ́lì tó lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Nebukadinésárì àtohun tí ọba náà ní láti ṣe tó bá fẹ́ kí ‘aásìkí rẹ̀ gùn sí i.’ Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe gba ìgbàgbọ́ láti polongo ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, títí kan ìdájọ́ Ọlọ́run lórí àwọn aṣebi.
5:30, 31. “Ọ̀rọ̀ òwe” nípa “ọba Bábílónì” ṣẹ sórí ọba náà. (Aísáyà 14:3, 4, 12-15) Sátánì Èṣù, tí ìgbéraga rẹ̀ dà bíi tàwọn ọba tó máa ń jẹ látìrandíran ní Bábílónì, máa kú ikú ẹ̀sín gbẹ̀yìn ni.—Dáníẹ́lì 4:30; 5:2-4, 23.
KÍ LÀWỌN ÌRAN TÍ DÁNÍẸ́LÌ RÍ FI HÀN?
Dáníẹ́lì ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún nígbà tó rí ìràn àkọ́kọ́ tó rí lójú àlá lọ́dún 553 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Dáníẹ́lì rí ẹranko fàkìàfakia mẹ́rin tí wọ́n dúró fún ìjọba mẹ́rin tó máa ṣàkóso ayé bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ayé rẹ̀ títí di àkókò tiwa. Nínú ìran kan tó rí nípa ọ̀run, ó rí “ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn” tí wọ́n fún ní “agbára ìṣàkóso tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Ní ọdún méjì lẹ́yìn ìyẹn, Dáníẹ́lì rí ìran kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣàkóso Mídíà òun Páṣíà, àti ti Gíríìsì àti ìṣàkóso kan tó di “ọba kan . . . tí ó rorò ní ojú.”—Dáníẹ́lì 8:23.
A ti bá àlàyé wa dé ọdún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni wàyí. Ìjọba Bábílónì ti dojú dé, Dáríúsì ará Mídíà sì ti di alákòóso lórí àwọn ará Kálídíà. Dáníẹ́lì gbàdúrà sí Jèhófà nípa bí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ á ṣe padà sípò. Bó ṣe ń gbàdúrà lọ́wọ́, Jèhófà rán áńgẹ́lì tó ń jẹ́ Gébúrẹ́lì pé kó lọ mú kí Dáníẹ́lì “ní ìjìnlẹ̀ òye pẹ̀lú ìmọ̀” nípa bíbọ̀ Mèsáyà. (Dáníẹ́lì 9:20-25) Nígbà tó fi máa di ọdún 536 sí 535 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, díẹ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti padà sí Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ àwọn alátakò ò jẹ́ kí wọ́n ráyè kọ́ tẹ́ńpìlì. Ẹ̀dùn ọkàn lọ̀rọ̀ yìí jẹ́ fún Dáníẹ́lì. Ló bá fi ọ̀rọ̀ ọ̀hún sínú àdúrà, Jèhófà sì rán áńgẹ́lì onípò gíga kan sí Dáníẹ́lì. Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì yẹn ti fi Dáníẹ́lì lọ́kàn balẹ̀ tó sì gbà á níyànjú, áńgẹ́lì náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fi hàn bí ọba àríwá àti ọba gúúsù á ṣe máa bá ara wọn ja ìjà àjàmọ̀gá. Ìjà náà bẹ̀rẹ̀ látìgbà tí ìṣàkóso Alẹkisáńdà Ńlá pín sí mẹ́rin táwọn ọ̀gágun mẹ́rin sì pín ìṣàkóso náà mọ́ra wọn lọ́wọ́ lọ́kọ̀ọ̀kan, ìjà náà á sì máa bá a lọ títí dìgbà tí Ọmọ Aládé Ńlá náà, Máíkẹ́lì, “yóò dìde dúró.”—Dáníẹ́lì 12:1.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
8:9—Kí ni “Ìṣelóge” ṣàpẹẹrẹ? Nínú ẹsẹ yìí, “ìṣelóge” ṣàpẹẹrẹ ipò táwọn ẹni àmì òróró wà lórí ilẹ̀ ayé lákòókò tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ń ṣàkóso ayé.
8:25—Ta ni “Olórí àwọn ọmọ aládé”? Ọ̀rọ̀ Hébérù náà sar, tá a tú sí “olórí ọmọ aládé,” dìídì túmọ̀ sí “olóyè” tàbí “olórí.” Ẹnì kan ṣoṣo tí òye náà, “Olórí àwọn ọmọ aládé” tọ́ sí ni Jèhófà Ọlọ́run, ìyẹn Olórí gbogbo àwọn áńgẹ́lì ọmọ aládé, tó fi mọ́ “Máíkẹ́lì, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tí ó wà ní ipò iwájú.”—Dáníẹ́lì 10:13.
9:21—Kí nìdí tí Dáníẹ́lì fi pe áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ní “ọkùnrin náà”? Ìdí ni pé nígbà tí Gébúrẹ́lì wá bá a, ńṣe ló dà bí èèyàn, gẹ́gẹ́ bó ṣe fara hàn án nígbà kan rí.—Dáníẹ́lì 8:15-17.
9:27—Májẹ̀mú wo ló ń “ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀” títi di òpin àádọ́rin ọ̀sẹ̀, tó jẹ́ ọdún 36 Sànmánì Kristẹni? Nígbà tí wọ́n kan Jésù mọ́gi lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, Jèhófà kásẹ̀ májẹ̀mú Òfin ńlẹ̀. Àmọ́, Jèhófà mú kí májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá máa báṣẹ́ lọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí di ọdún 36 Sànmánì Kristẹni, ó tipa báyìí fi kún àkókò tó fi ṣe ojúure àrà ọ̀tọ̀ sáwọn Júù nítorí jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. Májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá ṣì ń báṣẹ́ lọ fún “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—Gálátíà 3:7-9, 14-18, 29; 6:16.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
9:1-23; 10:11. Nítorí pé Dáníẹ́lì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Ọlọ́run, tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó sì tún tẹpẹlẹ mọ́ àdúrà gbígbà, ó jẹ́ ẹni “fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.” Àwọn ànímọ́ tó ní yìí sì ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí di òpin ìgbésí ayé rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká pinnu láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáníẹ́lì.
9:17-19. Bá a bá tiẹ̀ ń gbàdúrà pé kí ayé tuntun Ọlọ́run nínú èyí tí ‘òdodo yóò máa gbé’ dé, ṣé kì í ṣe bí orúkọ Jèhófà ṣe máa di mímọ́ tí gbogbo ayé àtọ̀run á sì gbà pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ ló yẹ kó ká wa lára ju bí ìyà àti ìṣòro wa ṣe máa dópin?—2 Pétérù 3:13.
10:9-11, 18, 19. Ó yẹ ká máa fara wé áńgẹ́lì tó wá bá Dáníẹ́lì nípa fífún ọmọnìkejì wa níṣìírí, fífi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ àti fífi ọ̀rọ̀ wa tù wọ́n nínú.
12:3. Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, “àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye,” ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ń “tàn bí ìtànyòò” wọ́n sì ti “mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo,” tó fi mọ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó jẹ́ ara “àwọn àgùntàn mìíràn.” (Fílípì 2:15; Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16) Títàn táwọn ẹni àmì òróró ń ‘tàn bí ìràwọ̀’ á wá túbọ̀ mọ́lẹ̀ rekete nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún ti Kristi, nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jésù láti mú káwọn ọmọ aráyé tó bá jẹ́ onígbọràn jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. “Àwọn àgùntàn mìíràn” ní láti dúró ti àwọn ẹni àmì òróró láìyẹsẹ̀, kí wọ́n sì máa fi gbogbo ọkàn tì wọ́n lẹ́yìn ní gbogbo ọ̀nà.
Jèhófà Ń ‘Bù Kún Àwọn Tó Bẹ̀rù Rẹ̀’
Kí ni ìwé Dáníẹ́lì kọ́ wa nípa Ọlọ́run tá à ń sìn? Ìwọ wo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé yẹn ná, ìyẹn àwọn tó ti nímùúṣẹ àtàwọn tí kò tíì nímùúṣẹ. Àbó ò rí i bí wọ́n ṣe fi hàn pé Awímáyẹhùn ni Jèhófà!—Aísáyà 55:11.
Kí làwọn ìtàn inú ìwé Dáníẹ́lì kọ́ wa nípa Ọlọ́run wa? Àwọn ọ̀dọ́ mẹ́rin tí wọ́n jẹ́ Hébérù ò gbà kí wọ́n sọ àwọn dẹni tó ń gbé irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé ní ààfin Bábílónì. Ọlọ́run sì fún wọn ní ‘ìmọ̀, ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n.’ (Dáníẹ́lì 1:17) Ọlọ́run tòótọ́ rán áńgẹ́lì rẹ̀ láti yọ Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò nínú ìléru oníná. Ó yọ Dáníẹ́lì nínú ihò kìnnìún. Jèhófà máa ń ‘ran àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e lọ́wọ́,’ ó máa ń dáàbò bò wọ́n, ó sì tún máa ń ‘bù kún àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.’—Sáàmù 115:9, 13.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ ka àlàyé tá a ṣe lórí ẹsẹ kọ̀ọ̀kan nínú ìwé Dáníẹ́lì, wàá rí i nínú ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Kí nìdí tí Dáníẹ́lì fi jẹ́ “ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi”?