Ta Ni Yóò “Yè Bọ́”?
“Olúkúlùkù ẹni tí ó bá . . . ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.”—ÌṢE 2:21.
1. Èé ṣe tí Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa fi jẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé nínú ìtàn ayé?
PẸ́ŃTÍKỌ́SÌ ọdún 33 Sànmánì Tiwa jẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé nínú ìtàn àgbáyé. Èé ṣe? Nítorí pé a bí orílẹ̀-èdè tuntun kan lọ́jọ́ yẹn. Lákọ̀ọ́kọ́, kì í ṣe orílẹ̀-èdè kan tí ó fi bẹ́ẹ̀ tóbi púpọ̀—kìkì 120 ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n kóra jọ sínú yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n lónìí, tí a ti gbàgbé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà nígbà náà lọ́hùn-ún, orílẹ̀-èdè tí a bí ní yàrá òkè yẹn ṣì wà pẹ̀lú wa. Òtítọ́ yìí ṣe pàtàkì gan-an fún gbogbo wa, níwọ̀n bí èyí ti jẹ́ orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run yàn láti jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ níwájú aráyé.
2. Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ ìyanu wo ni ó sàmì sí ìbí orílẹ̀-èdè tuntun náà?
2 Nígbà tí orílẹ̀-èdè tuntun yẹn bẹ̀rẹ̀, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan wáyé, tí ó mú àwọn ọ̀rọ̀ asọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ṣẹ. A kà nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí nínú Ìṣe 2:2-4 pé: “Lójijì, ariwo kan dún láti ọ̀run gan-an gẹ́gẹ́ bí ti atẹ́gùn líle tí ń rọ́ yìì, ó sì kún inú gbogbo ilé tí wọ́n jókòó sí. Àwọn ahọ́n bí ti iná sì di rírí fún wọn, ó sì pín káàkiri, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì bà lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, gbogbo wọ́n sì wá kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ti ń yọ̀ǹda fún wọn láti sọ̀rọ̀ jáde.” Lọ́nà yìí, àwọn 120 olùṣòtítọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin wọ̀nyẹn di orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lẹ́yìn náà pe àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ àkọ́kọ́ ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—Gálátíà 6:16.
3. Àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì wo ni ó nímùúṣẹ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 sànmánì Tiwa?
3 Àwọn èrò kóra jọ láti ṣèwádìí nípa “atẹ́gùn líle tí ń rọ́ yìì” náà, àpọ́sítélì Pétérù sì ṣàlàyé fún wọn pé, ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ló ń ní ìmúṣẹ. Àsọtẹ́lẹ̀ wo? Ó dára, tẹ́tí sí ohun tí ó sọ: “‘Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,’ ni Ọlọ́run wí, ‘èmi yóò sì tú lára ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín yóò sì máa rí ìran, àwọn àgbà ọkùnrin yín yóò sì máa lá àlá; ṣe ni èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi jáde àní sára àwọn ẹrúkùnrin mi àti sára àwọn ẹrúbìnrin mi ní ọjọ́ wọnnì, wọn yóò sì sọ tẹ́lẹ̀. Ṣe ni èmi yóò fúnni ní àwọn àmì àgbàyanu ní ọ̀run lókè àti àwọn iṣẹ́ àmì ní ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àti iná àti ìkùukùu èéfín; a óò yí oòrùn padà di òkùnkùn, a ó sì yí òṣùpá padà di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ olókìkí ti Jèhófà tó dé. Olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.’” (Ìṣe 2:17-21) A rí àwọn ọ̀rọ̀ tí Pétérù yọ lò náà nínú Jóẹ́lì 2:28-32, ìmúṣẹ wọn sì túmọ̀ sí pé àkókò ti ń tán lọ fún orílẹ̀-èdè àwọn Júù. “Ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ olókìkí ti Jèhófà,” àkókò tí Ísírẹ́lì aláìṣòtítọ́ yóò jíhìn, ti sún mọ́lé. Ṣùgbọ́n ta ni yóò là á já, tàbí yè bọ́? Kí sì ni èyí ń ṣàpẹẹrẹ?
Ìmúṣẹ Alápá Méjì fún Àsọtẹ́lẹ̀
4, 5. Lójú ìwòye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bọ̀, ìmọ̀ràn wo ni Pétérù fúnni, èé sì ti ṣe tí ìmọ̀ràn yẹn fi wúlò rékọjá ọjọ́ rẹ̀?
4 Ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀ lé ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Ísírẹ́lì tẹ̀mí ti Ọlọ́run gbilẹ̀, ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti ara kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa, Ísírẹ́lì ti ara ń bá Róòmù jagun. Ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, Ísírẹ́lì fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí mọ́, wọ́n dáná sun Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ ráúráú. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Pétérù pèsè àmọ̀ràn tí ó dára nítorí ọ̀ràn ìbànújẹ́ tí ń bọ̀ yẹn. Ní ṣíṣàyọlò ọ̀rọ̀ Jóẹ́lì lẹ́ẹ̀kan sí i, ó wí pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá . . . ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a óò gbà là.” Júù kọ̀ọ̀kan ní láti pinnu nínú ọkàn rẹ̀ láti ké pe orúkọ Jèhófà. Èyí kan ṣíṣègbọràn sí ìtọ́ni tí Pétérù fúnni síwájú sí i, pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín ní orúkọ Jésù Kristi fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.” (Ìṣe 2:38) Àwọn olùgbọ́ Pétérù ní láti tẹ́wọ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bí i Mèsáyà náà, tí Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, ti kọ̀ sílẹ̀.
5 Àwọn ọ̀rọ̀ asọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì wọ̀nyẹn ní ipa ńlá lórí àwọn onínú tútù ní ọ̀rúndún kìíní. Ṣùgbọ́n wọ́n ní ipa tí ó túbọ̀ pọ̀ lónìí nítorí pé, bí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún ti fi hàn, àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ti ní ìmúṣẹ kejì. Ẹ jẹ́ kí a wo bí ó ṣe rí bẹ́ẹ̀.
6. Báwo ni dídá Ísírẹ́lì Ọlọ́run mọ̀ ṣe túbọ̀ ṣe kedere sí i, bí ọdún 1914 ti ń sún mọ́lé?
6 Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, àwọn èpò ẹ̀sìn Kristẹni èké kò jẹ́ kí a rí Ísírẹ́lì Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ní àkókò òpin, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914, a tún dá orílẹ̀-èdè tẹ̀mí yìí mọ̀ lọ́nà tí ó ṣe kedere lẹ́ẹ̀kan sí i. Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ní ìmúṣẹ àkàwé Jésù nípa àlìkámà àti èpò. (Mátíù 13:24-30, 36-43) Bí ọdún 1914 ti ń sún mọ́lé, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bẹ̀rẹ̀ sí ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára Kirisẹ́ńdọ̀mù aláìṣòótọ́, wọ́n ń kọ àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ èké rẹ̀ sílẹ̀ láìṣojo, wọ́n sì ń wàásù òpin “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè,” tí ń bọ̀. (Lúùkù 21:24) Ṣùgbọ́n Ogun Àgbáyé Kìíní, tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 1914, gbé àwọn ọ̀ràn tí wọn kò múra sílẹ̀ fún dìde. Lábẹ́ pákáǹleke líle koko, ọ̀pọ̀ jó rẹ̀yìn, àwọn kan sì juwọ́ sílẹ̀. Nígbà tí yóò fi di ọdún 1918, ìgbòkègbodò ìwàásù wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kógbá sílé.
7. (a) Ìṣẹ̀lẹ̀ wo tí ó jọ ti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni ó wáyé ní ọdún 1919? (b) Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1919, ipa wo ni títú ẹ̀mí Ọlọ́run jáde ní lórí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà?
7 Síbẹ̀, ìyẹn kò wà pẹ́ púpọ̀. Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1919, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí tú ẹ̀mí rẹ̀ sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́nà kan tí ó múni rántí Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Àmọ́ ṣáá o, ní ọdún 1919, kò sí fífahọ́n sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí atẹ́gùn líle tí ń rọ́ yìì. A lóye láti inú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù nínú 1 Kọ́ríńtì 13:8 pé, àkókò ṣíṣe iṣẹ́ ìyanu ti kọjá lọ tipẹ́tipẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀rí ẹ̀mí Ọlọ́run hàn kedere ní ọdún 1919, ní àpéjọpọ̀ kan ní Cedar Point, Ohio, U.S.A., nígbà tí a sọ okun àwọn Kristẹni olóòótọ́ dọ̀tun, tí wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Ní ọdún 1922, wọ́n padà sí Cedar Point, a sì tún ru wọ́n sókè sí iṣẹ́ nípasẹ̀ ìpè náà pé, “Ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.” Bí ó ti ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, a fipá mú ayé láti ṣàkíyèsí àwọn àbájáde tí ìtújáde ẹ̀mí Ọlọ́run mú wá. Gbogbo Kristẹni tí ó ti ṣèyàsímímọ́—lọ́kùnrin àti lóbìnrin, lọ́mọdé lágbà—bẹ̀rẹ̀ sí “sọ tẹ́lẹ̀,” ìyẹn ni pé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí polongo “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.” (Ìṣe 2:11) Bí Pétérù, wọ́n ń gba àwọn onínú tútù níyànjú pé: “Ẹ gba ara yín là kúrò lọ́wọ́ ìran oníwà wíwọ́ yìí.” (Ìṣe 2:40) Báwo ni àwọn tí ń dáhùn padà ṣe lè ṣe ìyẹn? Nípa fífiyèsí àwọn ọ̀rọ̀ Jóẹ́lì tí a rí nínú Jóẹ́lì 2:32 pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.”
8. Báwo ni àwọn nǹkan ti tẹ̀ síwájú fún Ísírẹ́lì Ọlọ́run láti ọdún 1919?
8 Láti àwọn ọdún ìjímìjí wọ̀nyẹn wá, àwọn àlámọ̀rí Ísírẹ́lì Ọlọ́run ti ń tẹ̀ síwájú. Ìfèdìdì di àwọn ẹni àmì òróró jọ bi pé ó ti lọ jìnnà, láti àwọn ọdún 1930 wá sì ni ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn onínú tútù tí wọ́n ní ìrètí wíwà lórí ilẹ̀ ayé ti fara hàn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. (Ìṣípayá 7:3, 9) Gbogbo wọn nímọ̀lára ìjẹ́kánjúkánjú, nítorí pé ìmúṣẹ ẹlẹ́ẹ̀kejì ti Jóẹ́lì 2:28, 29 fi hàn pé a ti sún mọ́ ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà tí ó túbọ̀ tóbilọ́lá, nígbà tí a óò pa ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsìn, ìṣèlú, àti ìṣòwò kárí ayé run. A ní ìdí tí ó lágbára láti “ké pe orúkọ Jèhófà” ní gbígbàgbọ́ ní kíkún pé òun yóò gbà wá!
Báwo Ni A Óò Ṣe Ké Pe Orúkọ Jèhófà?
9. Kí ni díẹ̀ lára ohun tí kíképe orúkọ Jèhófà ní nínú?
9 Kí ni kíképe orúkọ Jèhófà ní nínú? Àyíká ọ̀rọ̀ Jóẹ́lì 2:28, 29 ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè yẹn. Fún àpẹẹrẹ, kì í ṣe gbogbo ẹni tí ń ké pe Jèhófà ni òun máa ń fetí sí. Nípasẹ̀ wòlíì mìíràn, Aísáyà, Jèhófà wí fún Ísírẹ́lì pé: “Nígbà tí ẹ bá sì tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ yín, èmi yóò fi ojú mi pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ yín. Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀.” Kí ní fà á tí Jèhófà fi kọ̀ láti fetí sí orílẹ̀-èdè rẹ̀? Òun fúnra rẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ọwọ́ yín kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.” (Aísáyà 1:15) Jèhófà kò ní fetí sí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tàbí tí ó sọ ẹ̀ṣẹ̀ di àṣà. Ìdí nìyẹn tí Pétérù fi sọ fún àwọn Júù ní Pẹ́ńtíkọ́sì pé kí wọ́n ronú pìwà dà. Nínú àyíká ọ̀rọ̀ Jóẹ́lì 2:28, 29, a rí i pé Jóẹ́lì pẹ̀lú tẹnu mọ́ ìrònúpìwàdà. Fún àpẹẹrẹ, ní Jóẹ́lì 2:12, 13, a kà pé: “‘Àti nísinsìnyí pẹ̀lú,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘ẹ padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà yín, àti pẹ̀lú ààwẹ̀ gbígbà àti pẹ̀lú ẹkún sísun àti pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún. Kí ẹ sì fa ọkàn-àyà yín ya, kì í sì í ṣe ẹ̀wù yín; ẹ sì padà wá sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run yín, nítorí ó jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.’” Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1919, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Wọ́n ronú pìwà dà nítorí àwọn àṣìṣe wọn, wọ́n sì pinnu láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ tàbí jó rẹ̀yìn mọ́ láé. Èyí ṣínà sílẹ̀ fún títú ẹ̀mí Ọlọ́run jáde. Olúkúlùkù ẹni tí ó bá fẹ́ láti ké pe orúkọ Jèhófà, kí a sì gbọ́ ọ, gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ipa ọ̀nà kan náà.
10. (a) Kí ni ìrònúpìwàdà tòótọ́? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe dàhún padà sí ìrònúpìwàdà tòótọ́?
10 Rántí pé, ìrònúpìwàdà tòótọ́ ju wíwulẹ̀ sọ pé, “Mo tọrọ àforíjì” lọ. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fa ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn ya láti fi bí ìmọ̀lára wọn ti jinlẹ̀ tó hàn. Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ pé: “Ẹ . . . fa ọkàn-àyà yín ya, kì í sì í ṣe ẹ̀wù yín.” Ìrònúpìwàdà tòótọ́ máa ń ti inú ọkàn-àyà wá, láti ibi jíjinlẹ̀ inú ara wa. Ó kan kíkẹ̀yìn wa sí ìwà àìtọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kà nínú Aísáyà 55:7 pé: “Kí ènìyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, kí apanilára sì fi ìrònú rẹ̀ sílẹ̀; kí ó sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà.” Ó kan kíkórìíra ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. (Hébérù 1:9) Lẹ́yìn náà, a óò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láti dárí jì wá lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà, nítorí pé Jèhófà jẹ́ “olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” Òun yóò tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, ọrẹ ẹbọ ọkà àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu tẹ̀mí wa. Òun yóò fetí sílẹ̀ nígbà tí a bá ké pe orúkọ rẹ̀.—Jóẹ́lì 2:14.
11. Ipò wo ni ó yẹ kí ìjọsìn tòótọ́ mú nínú ìgbésí ayé wa?
11 Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù fún wa ní ohun mìíràn tí a ní láti fi sọ́kàn, nígbà tí ó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.” (Mátíù 6:33) A kò ní láti fi ojú kékeré wo ìjọsìn wa, bí ohun tí a ṣe ní ṣákálá láti fi dá ẹ̀rí ọkàn wa láre. Sísin Ọlọ́run ni ó yẹ kí ó gba ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa. Nípa báyìí, nípasẹ̀ Jóẹ́lì, Jèhófà ń bá a lọ láti wí pé: “Ẹ fun ìwo ní Síónì . . . Ẹ kó àwọn ènìyàn náà jọpọ̀. Ẹ sọ ìjọ kan di mímọ́. Ẹ kó àwọn àgbààgbà jọpọ̀. Ẹ kó àwọn ọmọdé àti àwọn tí ń mu ọmú jọpọ̀. Kí ọkọ ìyàwó jáde kúrò ní inú yàrá rẹ̀ inú lọ́hùn-ún, àti ìyàwó kúrò ní inú ìyẹ̀wù ìgbà ìgbéyàwó rẹ̀.” (Jóẹ́lì 2:15, 16) Ó bá ìwà ẹ̀dá mu kí ọkàn àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó pínyà, kí wọ́n máa fiyè sí kìkì ẹnì kìíní kejì wọn. Ṣùgbọ́n nípa tiwọn pàápàá, sísin Jèhófà gbọ́dọ̀ gba ipò kìíní. Ohunkóhun kò gbọ́dọ̀ gba ipò iwájú lọ́wọ́ kíkórajọpọ̀ fún ìjọsìn Ọlọ́run wa, kíké pe orúkọ rẹ̀.
12. Ìbísí tí ó ṣeé ṣe wo ni a rí nínú ìròyìn Ìṣe Ìrántí ọdún tí ó kọjá?
12 Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, ẹ jẹ́ kí a gbé ìsọfúnni oníṣirò kan tí a fi hàn nínú Ìròyìn Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn 1997 ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹ̀ wò. Lọ́dún tó kọjá, a ní góńgó gíga 5,599,931 ti àwọn akéde Ìjọba—wọ́n jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá olùyìn ní tòótọ́! Iye àwọn tí wọ́n wá sí Ìṣe Ìrántí jẹ́ 14,322,226—ó fi ohun tí ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ àti àbọ̀ pọ̀ ju iye àwọn akéde lọ. Iye yẹn fi hàn pé wọ́n lè pọ̀ si lọ́nà àgbàyanu. Ọ̀pọ̀ lára àwọn mílíọ̀nù mẹ́jọ àti àbọ̀ wọ̀nyẹn ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí olùfìfẹ́hàn tàbí ọmọ àwọn òbí tí wọ́n ti ṣèrìbọmi. Ìpàdé tí púpọ̀ lára wọn kọ́kọ́ lọ nìyẹn. Wíwà tí wọ́n wà níbẹ̀ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àǹfààní dáradára láti mọ̀ wọ́n, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú si. Lẹ́yìn náà, àwọn kan wà lára wọn tí wọ́n máa ń wá sí Ìṣe Ìrántí lọ́dọọdún, bóyá tí wọ́n tilẹ̀ máa ń wá sí àwọn ìpàdé bi mélòó kan mìíràn, ṣùgbọ́n tí wọn kò tẹ̀ síwájú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Dájúdájú, a ké sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti pàdé pọ̀ pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n a rọ̀ wọ́n láti ṣàṣàrò kínníkínní lórí àwọn ọ̀rọ̀ asọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì, kí wọ́n sì ronú lórí ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbọ́dọ̀ gbé tẹ̀ le, kí Jèhófà lè fetí sí wọn bí wọ́n bá ké pe orúkọ rẹ̀.
13. Bí a bá ti ń ké pe orúkọ Jèhófà, ẹrù iṣẹ́ wo ni a ní fún àwọn ẹlòmíràn?
13 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ apá mìíràn nínú kíké pe orúkọ Ọlọ́run. Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará ní Róòmù, ó ṣàyọlò ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a óò gbà là.” Lẹ́yìn náà, ó tẹnu bọ̀rọ̀ pé: “Báwo ni wọn yóò ṣe ké pe ẹni tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù?” (Róòmù 10:13, 14) Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ mìíràn tí wọn kò tí ì mọ Jèhófà títí di ìsinsìnyí, ní láti ké pe orúkọ rẹ̀. Àwọn tí wọ́n ti mọ Jèhófà ní ẹrù iṣẹ́, kì í ṣe kìkì láti wàásù fún wọn, ṣùgbọ́n láti wá wọn rí pẹ̀lú, kí wọ́n sì ṣèrànlọ́wọ́ yẹn fún wọn.
Párádìsé Tẹ̀mí
14, 15. Àwọn ìbùkún ipò ti párádísè wo ni àwọn ènìyàn Jèhófà ń gbádùn nítorí pé wọ́n ń ké pe orúkọ rẹ̀ ní ọ̀nà tí ó dùn mọ́ ọn nínú?
14 Ojú tí àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn mìíràn fi ń wo nǹkan nìyẹn, Jèhófà sì ń bù kún wọn nítorí èyí. “Jèhófà yóò sì kún fún ìtara fún ilẹ̀ rẹ̀, yóò sì fi ìyọ́nú hàn sí àwọn ènìyàn rẹ̀.” (Jóẹ́lì 2:18) Ní ọdún 1919, Jèhófà fi ìtara àti ìyọ́nú hàn sí àwọn ènìyàn rẹ̀ nígbà tí ó mú wọn padà bọ̀ sípò, tí ó sì mú wọn wọnú ìgbòkègbodò párádísè tẹ̀mí rẹ̀. Párádísè tẹ̀mi tòótọ́ ni èyí jẹ́, tí Jóẹ́lì ṣàpèjúwe dáradára pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ wọ̀nyí: “Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀. Kún fún ìdùnnú, kí o sì máa yọ̀; nítorí Jèhófà yóò ṣe ohun ńlá nínú ohun tí Ó ń ṣe ní ti tòótọ́. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹranko inú pápá gbalasa, nítorí àwọn ilẹ̀ ìjẹko tí ó wà ní aginjù yóò hu ewéko tútù dájúdájú. Nítorí igi yóò mú èso rẹ̀ jáde. Igi ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà yóò sì fúnni ní ìmí wọn. Àti ẹ̀yin, ọmọ Síónì, ẹ kún fún ìdùnnú, kí ẹ sì máa yọ̀ nínú Jèhófà Ọlọ́run yín; nítorí yóò fún yín ní òjò ìgbà ìkórè ní ìwọ̀n tí ó tọ́ dájúdájú, yóò sì rọ eji wọwọ lé yín lórí, òjò ìgbà ìkórè àti òjò ìgbà ìrúwé, gẹ́gẹ́ bí ti àkọ́kọ́. Àwọn ilẹ̀ ìpakà yóò sì kún fún ọkà tí a fọ̀ mọ́, àwọn ẹkù ìfúntí yóò sì kún àkúnwọ́sílẹ̀ pẹ̀lú wáìnì tuntun àti òróró.”—Jóẹ́lì 2:21-24.
15 Ẹ wo irú àpèjúwe amọ́kànyọ̀ tí èyí jẹ́! Àwọn lájorí oúnjẹ mẹ́ta agbẹ́mìíró ní Ísírẹ́lì—ọkà, òróró ólífì àti wáìnì—ni a óò pèsè lọ́pọ̀ yanturu pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ agbo ẹran. Ní ọjọ́ wa, a ń mú àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn ṣẹ lọ́nà tẹ̀mí. Jèhófà ń fún wa ní gbogbo oúnjẹ tẹ̀mí tí a nílò. Inú gbogbo wa kò ha dùn sí irú ọ̀pọ̀ yanturu tí Ọlọ́run ń fúnni bẹ́ẹ̀ bí? Ní tòótọ́, bí Málákì ti sọ tẹ́lẹ̀, Ọlọ́run wa ti ‘ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún wa, ó sì tú ìbùkún dà sórí wa títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’—Málákì 3:10.
Òpin Ètò Àwọn Nǹkan
16. (a) Kí ni ìtújáde ẹ̀mí Jèhófà dúró fún ní ọjọ́ wa? (b) Kí ni ọjọ́ ọ̀la ní ní ìpamọ́ fún wa?
16 Lẹ́yìn sísọtẹ́lẹ̀ nípa ipò bi ti párádísè tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run wà ni Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa títú ẹ̀mí Jèhófà jáde. Nígbà tí Pétérù ṣàyọlò ọ̀rọ̀ yìí ní Pẹ́ńtíkọ́sì, ó sọ pé, ó ní ìmúṣẹ “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (Ìṣe 2:17) Títú ẹ̀mí Ọlọ́run jáde nígbà náà túmọ̀ sí pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ti bẹ̀rẹ̀ fún ètò àwọn nǹkan ti àwọn Júù. Títú ẹ̀mí Ọlọ́run sórí Ísírẹ́lì Ọlọ́run ní ọ̀rúndún ogún túmọ̀ sí pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan jákèjádò ayé. Nítorí èyí, kí ni ó wà ní ọjọ́ ọ̀la fún wa? Àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ń bá a lọ láti sọ fún wa pé: “Èmi yóò fúnni ní àwọn àmì àgbàyanu ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, ẹ̀jẹ̀ àti iná àti àwọn ìṣùpọ̀ èéfín adúró-bí-ọwọ̀n. A óò yí oòrùn padà di òkùnkùn, a ó sì yí òṣùpá padà di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà tó dé.”—Jóẹ́lì 2:30, 31.
17, 18. (a) Ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà wo ni ó dé sórí Jerúsálẹ́mù? (b) Ìdánilójú ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà ń sún wa láti ṣe kí ni?
17 Ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa, àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ ní Jùdíà bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti ń lọ láìdábọ̀ sí òtéńté ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tó láti wà lára àwọn tí wọn kì í ké pe orúkọ Jèhófà lákòókò yẹn! Lónìí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ wà níwájú, nígbà tí Jèhófà yóò fi ọwọ́ rẹ̀ pa gbogbo ètò àwọn nǹkan ayé yìí run. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣì ṣeé ṣe láti sá là. Àsọtẹ́lẹ̀ náà ń bá a lọ láti wí pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́; nítorí pé àwọn tí ó sá àsálà yóò wà ní Òkè Ńlá Síónì àti ní Jerúsálẹ́mù, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ, àti lára àwọn olùlàájá, àwọn tí Jèhófà ń pè.” (Jóẹ́lì 2:32) Ní tòótọ́, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣọpẹ́ fún mímọ orúkọ Jèhófà, wọ́n sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé òun yóò dáàbò bò wọ́n nígbà tí wọ́n bá ké pè é.
18 Ṣùgbọ́n, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ olókìkí ti Jèhófà bá dé bá ayé yìí nínú gbogbo ìkannú rẹ̀? A óò jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó kẹ́yìn.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Nígbà wo ni Jèhófà kọ́kọ́ tú ẹ̀mí rẹ̀ sórí àwọn ènìyàn rẹ̀?
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí kíképe orúkọ Jèhófà ní nínú?
◻ Nígbà wo ni ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ olókìkí ti Jèhófà dé sórí Ísírẹ́lì ti ara?
◻ Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún àwọn tí ó ké pe orúkọ rẹ̀ lónìí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
A bí orílẹ̀-èdè tuntun ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, Jèhófà tún tú ẹ̀mí rẹ̀ sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní mímú Jóẹ́lì 2:28, 29 ṣẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
A gbọ́dọ̀ ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti ké pe orúkọ Jèhófà