Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Ń Fi Ìsìn Sílẹ̀?
NÍ ÀÁRÍN ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ó ṣàjèjì pátápátá láti gbọ́ kí olùgbé Prussia (tí ó ti wá di àríwá Germany báyìí) sọ pé òun kò ní ìsìn kan pàtó. Àní, wíwulẹ̀ fi àwùjọ ìsìn tí tẹrútọmọ mọ̀ sílẹ̀ láti lọ di mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì tí kì í tẹ̀ lé ìlànà gbogbogbòò lè mú kí onítọ̀hún di ẹni tí àwọn ọlọ́pàá ń dọdẹ kiri. Ìgbà mà ti yí padà o!
Lónìí, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ará Germany ń kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀. A gbọ́ pé, ẹnì 1 nínú ẹni 4 ń sọ pé òun kò ní ìsìn kankan. Bẹ́ẹ̀ náà ló ń dà báyìí ní Austria àti Switzerland. Bí ó bá jẹ́ pé jíjẹ́ mẹ́ńbà ni ó ń so ẹ̀mí ìsìn ró, a jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé tí í ṣe ará Germany náà, Reimer Gronemeyer, ti sọ, “ẹ̀mí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Yúróòpù ti fẹ́ pin.”
Ìdí Tí Wọ́n fi Ń Pa Ìsìn Tì
Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ fi ń pa ìsìn tí a fètò gbé kalẹ̀ tì? Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń jẹ́ nítorí ọ̀ràn owó, ní pàtàkì, ní àwọn ilẹ̀ tí a ti ń fi dandan lé e pé kí àwọn mẹ́ńbà máa san owó ṣọ́ọ̀ṣì. Ọ̀pọ̀ ń béèrè pé, ‘Èé ṣe tí owó ti mo làágùn kí n tó rí yóò fi máa lọ sínú àpò ṣọ́ọ̀ṣì?’ Ọrọ̀ rẹpẹtẹ pẹ̀lú àṣẹ tí ṣọ́ọ̀ṣì ní ló ń lé àwọn kan sá. Ó jọ pé wọ́n fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú Kádínà Joachim Meisner ti Cologne, Germany, ẹni tí ó sọ pé ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ọrọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ni ó sún un láti fi àfiyèsí púpọ̀ sórí nǹkan ti ara “dípò mímú níní ìgbàgbọ́ nínú Kristi ní ọ̀kúnkúndùn.”
Àwọn kan ń fi ṣọ́ọ̀ṣì wọn sílẹ̀ nítorí pé ó ti sú wọn, kò pèsè ohun tí ó fà wọ́n mọ́ra, kò rí nǹkan ṣe sí ebi tẹ̀mí tí ń pa wọ́n. “Ìyàn, tí kì í ṣe fún oúnjẹ, àti òùngbẹ, tí kì í ṣe fún omi, bí kò ṣe fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà,” tí wòlíì nì, Ámósì, sọ tẹ́lẹ̀ ni ó dé bá wọn. (Ámósì 8:11) Nítorí pé ohun ìgbẹ́mìíró tí wọ́n ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ ìsìn wọn kò tó nǹkan, wọ́n pa á tì.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọ́n ń dojú kọ àwọn ìṣòro wọ̀nyí, ṣé ohun tí ó kàn ni pé kí wọ́n pa gbogbo ìsìn tì? Fojú inú wo ọkùnrin kan tí ebi ń pa tí ó rí ohun kan tí ó jọ ègé búrẹ́dì. Ṣùgbọ́n, bí ó ṣe ń gbìyànjú láti jẹ ẹ́, ni ó wá mọ̀ pé lẹ́búlẹ́bú pákó ni a fi ṣe é. Ṣé kò ní ronú àtijẹun mọ́, kí ó sì wá nǹkan ṣe sí ebi tí ń pa á? Rárá o, yóò wá oúnjẹ gidi jẹ. Bákan náà, bí ìsìn kan kò bá lè wá nǹkan ṣe sí ebi tẹ̀mí tí ń pa àwọn mẹ́ńbà rẹ̀, ó ha yẹ kí wọ́n pa ìsìn tì bí? Àbí yóò ha bọ́gbọ́n mu fún wọn láti wá ọ̀nà tí wọn yóò gbà wá nǹkan ṣe sí ebi tẹ̀mí tí ń pa wọ́n? Ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ṣe nìyẹn, gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e ti fi hàn.