Jona Kọ́ Nípa Àánú Jehofa
JEHOFA ní iṣẹ́ àyànfúnni kan fún wòlíì rẹ̀, Jona. Àkókò náà jẹ́ ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Tiwa, Jeroboamu Kejì sì ń jọba ní Israeli. Ará Gat-heferi, ìlú àwọn ọmọ Zebuluni, ni Jona. (Joṣua 19:10, 13; 2 Awọn Ọba 14:25) Ọlọrun fẹ́ rán Jona lọ sí Ninefe, olú ìlú Asiria, tí ó wà ní èyí tí ó ju kìlómítà 800 lọ sí ìhà àríwá ìlà oòrùn ìlú rẹ̀. Ó ní láti kìlọ̀ fún àwọn ará Ninefe pé Ọlọrun ń fẹ́ pa wọ́n run.
Jona ti lè ronú pé: ‘Èé ṣe tí mo fi ní láti lọ sí ìlú àti orílẹ̀-èdè yẹn? Wọn kò kúkú ní ìfọkànsìn sí Ọlọrun. Àwọn ará Asiria tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ yẹn kò fìgbà kankan wọnú májẹ̀mú pẹ̀lú Jehofa bí àwọn ọmọ Israeli ti ṣe. Họ́wù, àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè búburú yẹn lè ka ìkìlọ̀ mi sí ewu kan, wọ́n sì lè ṣẹ́gun Israeli! Èmi kọ́! N kò ní lọ. Èmi yóò sá lọ sí Joppa, n óò sì wọkọ̀ òkun bá ibòmíràn lọ—lọ jìnnà sí Tarṣiṣi, lódì kejì Òkun Ńlá lọ́hùn-ún. Ohun tí n óò ṣe nìyẹn!’—Jona 1:1-3.
Ewu Lórí Òkun!
Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, Jona ti dé Joppa létíkun Meditarenia. Ó sanwó ọkọ̀ rẹ̀, ó sì wọkọ̀ ojú omi tí ń lọ sí Tarṣiṣi, tí a mọ̀ ní gbogbogbòò sí Spain, èyí tí ó ju kìlómítà 3,500 lọ síhà ìwọ̀ oòrùn Ninefe. Gbàrà tí ó ti dórí òkun ní wòlíì tí ó ti rẹ̀ náà ti bọ́ sísàlẹ̀ ọkọ̀, tí ó sì sùn lọ. Kò pẹ́ kò jìnnà, Jehofa rán ẹ̀fúùfù líle sójú òkun, olúkúlùkù àwọn atukọ̀ tí jìnnìjìnnì ti mú sì ń ké pe ọlọrun rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. Ọkọ̀ ojú omi náà bẹ̀rẹ̀ sí í yí síhìn-ín sọ́hùn-ún tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kó àwọn ẹrù dà nù láti mú kí ọkọ̀ fúyẹ́. Síbẹ̀, ó dà bíi pé ìjàm̀bá ọkọ̀ dájú, Jona sì gbọ́ tí ọ̀gákọ̀ onígbòónára náà kígbe pé: “Kí ni ìwọ́ rò, ìwọ olóorun? Dìde, ké pe Ọlọrun rẹ, bóyá Ọlọrun yóò ro tiwa, kí àwa kí ó má baà ṣègbé.” Jona dìde, ó sì gun òkè ọkọ̀ lọ.—Jona 1:4-6.
Àwọn atukọ̀ náà sọ pé: “Wá, ẹ sì jẹ́ ká ṣẹ́ kèké, kí àwa kí ó lè mọ̀ ìtorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa.” Kèké mú Jona. Ẹ wo bí ìpáyà rẹ̀ yóò ti tó bí àwọn atukọ̀ náà ti ń sọ pé: “Sọ fún wa, àwá bẹ̀ ọ́, nítorí ti ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa? kí ni iṣẹ́ rẹ? níbo ni ìwọ́ sì ti wá? orúkọ ìlú rẹ? orílẹ̀-èdè wo ni ìwọ́ sì í ṣe?” Jona sọ pé òún jẹ́ Heberu kan tí ń jọ́sìn “Oluwa, Ọlọrun ọ̀run” àti pé òún ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún ‘Ẹni náà tí ó dá òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀.’ Ìjì náà dé bá wọn nítorí pé òún ń sá lọ kúrò níwájú Jehofa dípo fífi ìgbọràn mú ìhìn iṣẹ́ Ọlọrun lọ sí Ninefe.—Jona 1:7-10.
Àwọn atukọ̀ náà béèrè pé: “Kí ni kí a ṣe sí ọ, kí òkun lè dákẹ́ fún wa?” Bí òkun ṣe túbọ̀ ń ru gùdù sí i, Jona sọ pé: “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì sọ mí sínú òkun; bẹ́ẹ̀ ni òkun yóò sì dákẹ́ fún yín: nítorí èmí mọ̀ pé nítorí mi ni ẹ̀fúùfù líle yìí ṣe dé bá a yín.” Bí àwọn ọkùnrin náà kò ti fẹ́ láti gbé ìránṣẹ́ Jehofa sọ sínú òkun, kí ikú sì gbé e hánu, wọ́n gbìyànjú láti tukọ̀ lọ sí ìyàngbẹ ilẹ̀. Nígbà tí ìgbìyànjú wọn já sí pàbó, àwọn atukọ̀ náà kígbe pé: “Àwá bẹ̀ ọ́, Oluwa àwá bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí àwá ṣègbé nítorí ẹ̀mí ọkùnrin yìí, má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa ní ọrùn: nítorí ìwọ, Oluwa, ti ṣe bí ó ti wù ọ́.”—Jona 1:11-14.
Jùà Nínú Òkun!
Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn atukọ̀ náà ju Jona sínú òkun. Bí ó ti ń rì sínú òkun tí ń ru náà, ìrugùdù rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dáwọ́ dúró. Ní rírí èyí, “àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù Oluwa gidigidi, wọ́n sì rúbọ sí Oluwa, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́.”—Jona 1:15, 16.
Ó dájú pé Jona ń gbàdúrà bí omi náà ti ń bò ó mọ́lẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó nímọ̀lára pé òún ń yọ̀ tẹ̀rẹ́ lọ sínú ihò múlọ́múlọ́ kan bí òún ti ń ṣe tìnrín lọ sínú káà kan. Sí ìyàlẹ́nu rẹ̀, ó ṣì lè mí! Ní mímú àwọn ewé odò kúrò lórí rẹ̀, Jona bá ara rẹ̀ ní ibì kan tí kò láfiwé ní tòótọ́. Èyí jẹ́ nítorí pé “Oluwa ti pèsè ẹja ńlá kan láti gbé Jona mì. Jona sì wà nínú ẹja náà ní ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.”—Jona 1:17.
Àdúrà Onígbòóná Ọkàn Jona
Jona ní àkókò láti gbàdúrà nínú ikùn ẹja mùmùrara náà. Díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ fara jọ àwọn psalmu kan. Lẹ́yìn náà, Jona ṣàkọsílẹ̀ àdúrà rẹ̀ tí ń fi àìnírètí àti ìrònúpìwàdà hàn. Fún àpẹẹrẹ, lójú rẹ̀, ó dà bíi pé ikùn ẹja náà yóò di Ṣìọ́ọ̀lù, ibojì rẹ̀. Nítorí náà, ó gbàdúrà pé: “Èmí kígbe nítorí ìpọ́njú mi sí Oluwa, òún sì gbóhùn mi; mo kígbe láti inú ipò òkú, ìwọ́ sì ti gbóhùn mi.” (Jona 2:1, 2) Méjì nínú Orin Àkọgòkè—tí ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ Israeli tí ń gòkè lọ sí Jerusalemu fún àjọyọ̀ ọdọọdún kọ—sọ èrò tí ó jọra jáde.—Orin Dafidi 120:1; 130:1, 2.
Ní ríronú lórí rírì rẹ̀ sínú òkun, Jona gbàdúrà pé: “Nítorí tí ìwọ [Jehofa] ti sọ mí sínú ibú, láàárín [gbùngbùn] òkun; ìṣàn omi sì yí mi káàkiri; gbogbo bíbì omi àti ríru omi ré kọjá lórí mi.”—Jona 2:3; fi wé Orin Dafidi 42:7; 69:2.
Jona bẹ̀rù pé àìgbọràn òun yóò mú kí òún pàdánù ojú rere àtọ̀runwá àti pé, òun kì yóò tún rí tẹ́ḿpìlì Ọlọrun mọ́ láé. Ó gbàdúrà pé: “Ní ti èmi, mo wí pé, ‘A ti lé mí kúrò níwájú ojú ìríran rẹ! Báwo ni èmi óò tún ṣe rí tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ?’” (Jona 2:4, NW; fi wé Orin Dafidi 31:22.) Ipò Jona dà bí èyí tí ó burú débi tí ó fi sọ pé: “Omí yí mi káàkiri, àni títi dé ọkàn [ní fífi ìwàláàyè rẹ̀ sínú ewu]; ibú yí mi káàkiri, a fi koríko odò [tí ó wà nínú òkun] wé mi lórí.” (Jona 2:5; fi wé Orin Dafidi 69:1.) Ronú wòye ipò búburú Jona, nítorí tí ó sọ pé: “Èmí sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè ńlá [nínú ẹja]; ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ [bíi ti ibojì] wà yí mi ká títí: ṣùgbọ́n ìwọ́ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá [ní ọjọ́ kẹta], Oluwa Ọlọrun mi.”—Jona 2:6; fi wé Orin Dafidi 30:3.
Bí ó tilẹ̀ wà nínú ikùn ẹja, Jona kò ronú pé: ‘Mo sorí kọ́ débi tí èmi kò fi lè gbàdúrà.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbàdúrà pé: “Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi [ní bèbè ikú], èmí rántí Oluwa [nínú ìgbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Ẹni tí agbára àti àánú rẹ̀ kò láfiwé]: àdúrà mi sì wá sọ́dọ̀ rẹ sínú [tẹ́ḿpìlì] mímọ́ rẹ.” (Jona 2:7) Láti inú tẹ́ḿpìlì ti ọ̀run, Ọlọrun gbóhùn Jona, ó sì gbà á là.
Ní paríparí rẹ̀, Jona gbàdúrà pé: “Àwọn tí ń kíyè sí èké asán [nípa gbígbẹ́kẹ̀lé àwọn ère aláìlẹ́mìí ti àwọn ọlọrun èké] kọ àánú ara wọn sílẹ̀ [ní kíkọ Ẹni tí ń fi ànímọ́ yìí hàn sílẹ̀]. Ṣùgbọ́n èmi óò fi ohùn ìdúpẹ́ rúbọ sí ọ [Jehofa Ọlọrun]; èmi óò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́ [nígbà ìrírí yìí tàbí ní àwọn àkókò míràn]. Ti Oluwa ni ìgbàlà.” (Jona 2:8, 9; fi wé Orin Dafidi 31:6; 50:14.) Ní mímọ̀ pé Ọlọrun nìkan ni ó lè gba òun sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, wòlíì olùronúpìwàdà (bíi ti Ọba Dafidi àti Solomoni tí ó ṣáájú rẹ̀) pe ìgbàlà ní ti Jehofa.—Orin Dafidi 3:8; Owe 21:31.
Jona Ṣègbọràn
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìrònú àti àdúrà onítara ọkàn, Jona rí i pé a ń ti òun jáde gba inú ihò tí ó gbà wọlé. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, a gbé e jù sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀. (Jona 2:10) Bí Jona ti kún fún ìmoore fún ìgbàlà rẹ̀, ó ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun pé: “Dìde, lọ sí Ninefe, ìlú ńlá nì, kí o sì kéde sí i ìkéde tí mo sọ fún ọ.” (Jona 3:1, 2) Jona bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ sí olú ìlú Asiria. Nígbà tí ó mọ ọjọ́ tí ó jẹ́, ó mọ̀ pé òún wà níkùn ẹja náà fún ọjọ́ mẹ́ta. Wòlíì náà ré kọjá Odò Eufrate ní ìṣẹ́kọ́rọ́ rẹ̀ tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, ó rìnrìn àjò gba ìlà oòrùn rẹ̀ kọjá ní àríwá Mesopotamia, ó dé Odò Tigris, ó sì dé ìlú ńlá náà níkẹyìn.—Jona 3:3.
Jona wọnú Ninefe, ìlú ńlá kan. Ó yí ìlú náà kiri fún ọjọ́ kan, ó sì polongo lẹ́yìn náà pé: “Níwọ̀n ogójì ọjọ́ sí i, a óò bi Ninefe wó.” A ha ti fi ìmọ̀ nípa èdè àwọn ara Asiria jíǹkí Jona lọ́nà iṣẹ́ ìyanu bí? A kò mọ̀. Ṣùgbọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ èdè Heberu ni ó fi ń sọ̀rọ̀, tí ẹnì kan sì ń gbúfọ̀ rẹ̀ pàápàá, ìpolongo rẹ̀ ṣiṣẹ́. Àwọn ará Ninefe bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun. Wọ́n kéde ààwẹ̀, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, láti ẹni ńlá títí de ẹni tí ó kéré jù nínú wọn. Nígbà tí ọba Ninefe gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó dìde kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó bọ́ aṣọ oyè rẹ̀, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara rẹ̀, ó sì jókòó sínú eérú.—Jona 3:4-6.
Ẹ wo bí ẹnú yóò ti ya Jona tó! Ọba àwọn ará Asiria ránṣẹ́ jáde pẹ̀lú igbe náà pé: “Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn, tàbí ẹranko, ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran, tọ́ ohunkóhun wò: máà jẹ́ kí wọ́n jẹun, máà jẹ́ kí wọ́n mu omi. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn àti ẹranko fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, kí wọ́n sì kígbe kíkan sí Ọlọrun: sì jẹ́ kí wọ́n yí padà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀, àti kúrò ní ìwà agbára tí ó wà lọ́wọ́ wọn. Ta ní lè mọ̀ bí Ọlọrun yóò yí padà kí ó sì ronú pìwà dà, kí ó sì yí padà kúrò ní ìbínú gbígbóná rẹ̀, kí àwá má ṣègbé?”—Jona 3:7-9.
Àwọn ará Ninefe ṣègbọràn sí àṣẹ ọba wọn. Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn, ó káàánú nípa àjálù tí o ti sọ pé òun yóò mú wá bá wọn, nítorí náà, kò mú un wá mọ́. (Jona 3:10) Nítorí ìrònúpìwàdà, ìrẹ̀lẹ̀, àti ìgbàgbọ́ wọn, Jehofa pinnu láti má ṣe mú ìdájọ́ tí òún ti pinnu wá sórí wọn.
Wòlíì Tí Ó Ṣu Ẹnu Jọ
Ogójì ọjọ́ kọjá, kò sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Ninefe. (Jona 3:4) Ní mímọ̀ pé àwọn ará Ninefe kì yóò parun, inú Jona bàjẹ́ gidigidi, inú sì bí i púpọ̀, ó sì gbàdúrà pé: “Èmí bẹ̀ ọ́, Oluwa, ọ̀rọ̀ mi kọ́ yìí nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi? nítorí náà ni mo ṣe sá lọ sí Tarṣiṣi ní ìṣáájú: nítorí èmí mọ̀ pé, Ọlọrun olóore ọ̀fẹ́ ni ìwọ, àti aláàánú, o lọ́ra láti bínú, o sì ṣeun púpọ̀, o sì ronú pìwà dà ibi náà. Ǹjẹ́ nítorí náà, Oluwa, èmí bẹ̀ ọ́, gba ẹ̀mí mi kúrò lọ́wọ́ mi nítorí ó sàn fún mi láti kú ju àtiwà láàyè.” Ọlọrun fèsì padà pẹ̀lú ìbéèrè yìí pé: “Ìwọ́ ha ṣe rere láti bínú?”—Jona 4:1-4.
Nítorí ìyẹn, Jona bínú jáde kúrò nínú ìlú náà. Bí ó ti ń lọ sí ìlà oòrùn, ó pàgọ́ kan kí ó baà lè jókòó lábẹ́ ìbòji rẹ̀, títí tí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà. Nígbà náà, Jehofa fi ìyọ́nú ‘pèsè ìtàkùn kan, láti gòkè wá sórí Jona, kí ó lè ṣíji bò ó lórí, kí ó sì gbà á kúrò nínú ìbànújẹ́ rẹ̀.’ Inú Jona mà dùn sí ìtàkùn yí o! Ṣùgbọ́n Ọlọrun ṣètò pé kí kòkòrò kan jẹ ìtàkùn náà nígbà tí ọ̀yẹ̀ là, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rọ. Ká wí ká fọ̀, gbogbo rẹ̀ ti gbẹ dà nù. Ọlọrun tún rán ẹ̀fúùfù gbígbóná ti ìlà oòrùn. Oòrùn wá ń pa wòlíì náà lórí wàyí, tó bẹ́ẹ̀ tí agbára rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tán. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í tọrọ ikú. Bẹ́ẹ̀ ni, Jona sọ léraléra pé: “Ó sàn fún mi láti kú ju àtiwà láàyè lọ.”—Jona 4:5-8.
Nísinsìnyí, Jehofa sọ̀rọ̀. Ó béèrè lọ́wọ́ Jona pé: “Ó ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?” Jona dáhùn pé: “Ó tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú.” Ní ti gidi, ohun tí Jehofa ń sọ fún wòlíì náà nísinsìnyí ni pé: ‘Ìwọ́ ń kẹ́dùn nítorí ìtàkùn náà. Ṣùgbọ́n ìwọ kò ṣiṣẹ́ fún un, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò mú un dàgbà. Ó hù jáde ní òru kan, ó sì kú ní òru kan.’ Ọlọrun sọ síwájú sí i pé: ‘Kò ha yẹ kí n dá Ninefe ìlú ńlá nì sí, níbi tí èyí tí ó ju 120,000 ènìyàn ń gbé, tí wọn kò mọ ọ̀tún yàtọ̀ sí òsì, kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọ̀sìn?’ (Jona 4:9-11) Ìdáhùn tí ó tọ̀nà ṣe kedere.
Jona ronú pìwà dà, ó sì wà láàyè láti kọ ìwé Bibeli tí ń jẹ́ orúkọ rẹ̀. Báwo ni ó ṣe mọ̀ pé àwọn atukọ̀ náà bẹ̀rù Jehofa, pé wọ́n rúbọ sí I, pé wọ́n sì jẹ́jẹ̀ẹ́? Ó ti lè mọ èyí nípasẹ̀ ìmísí àtọ̀runwá tàbí bóyá ó gbọ́ ọ ní tẹ́ḿpìlì láti ẹnu ọ̀kan lára àwọn atukọ̀ náà tàbí lára àwọn èrò ọkọ̀.—Jona 1:16; 2:4.
“Àmì Jona”
Nígbà tí àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi béèrè fún àmì lọ́wọ́ Jesu Kristi, ó sọ pé: “Ìran burúkú ati panṣágà tẹramọ́ wíwá àmì, ṣugbọn a kì yoo fi àmì kankan fún un àyàfi àmì Jona wòlíì.” Jesu fi kún un pé: “Nitori gan-an gẹ́gẹ́ bí Jona ti wà ninu ikùn ẹja mùmùrara naa fún ọ̀sán mẹ́ta ati òru mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ naa ni Ọmọkùnrin ènìyàn yoo wà ninu ọkàn-àyà ilẹ̀-ayé fún ọ̀sán mẹ́ta ati òru mẹ́ta.” (Matteu 12:38-40) Ọjọ́ àwọn Júù ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn bá wọ̀. Kristi kú ní ọ̀sán Friday, Nisan 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa. A gbé òkú rẹ̀ sínú ibojì ṣáájú kí oòrùn tó wọ̀ ní ọjọ́ yẹn. Nisan 15 bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ yẹn títí dé ìgbà tí oòrùn wọ̀ ní Saturday, ọjọ́ keje, tí ó sì jẹ́ ọjọ́ tí ó kẹ́yìn nínú ọ̀sẹ̀. Nisan 16 bẹ̀rẹ̀ ní àkókò yẹn títí dé ìgbà tí oòrùn wọ̀, tí a ń pè ní Sunday. Lójú ìwòye èyí, Jesu kú, ó sì wà nínú ibojì fún ó kéré tán, sáà àkókò kan ní Nisan 14, ó wà nínú ibojì fún gbogbo Nisan 15, ó sì lo àwọn wákàtí àṣálẹ́ Nisan 16 nínú ibojì. Nígbà tí àwọn obìnrin kan wá sí ibi ibojì ní òwúrọ̀ Sunday, a ti jí i dìde.—Matteu 27:57-61; 28:1-7.
Jesu wà nínú ibojì fún ìgbà díẹ̀ ní ọjọ́ kẹta. Àwọn ọ̀tá rẹ̀ tipa báyìí gba “àmì Jona,” ṣùgbọ́n Kristi sọ pé: “Awọn ènìyàn Ninefe yoo dìde ní ìdájọ́ pẹlu ìran yii wọn yoo sì dá a lẹ́bi; nitori pé wọ́n ronúpìwàdà lórí ohun tí Jona wàásù, ṣugbọn, wò ó! ohun kan tí ó ju Jona lọ wà níhìn-ín.” (Matteu 12:41) Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ òtítọ́ tó! Àwọn Júù ní Jesu Kristi láàárín wọn—wòlíì tí ó tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀ ju Jona lọ. Bí Jona tilẹ̀ jẹ́ àmì tí ó tó tẹ́rùntẹ́rùn fún àwọn ará Ninefe, Jesu wàásù pẹ̀lú ọlá àṣẹ àti àwọn ẹ̀rí ìtìlẹyìn tí ó pọ̀ jọjọ jù bí wòlíì yẹ́n ti ṣe. Síbẹ̀, àwọn Júù ní gbogbogbòò kò gbà gbọ́.—Johannu 4:48.
Gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, àwọn Júù kò fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba Wòlíì náà tí ó tóbi ju Jona, wọn kò sì lo ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn baba ńlá wọn ń kọ́? Àwọn pẹ̀lú kò ní ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ní tòótọ́, Jehofa ní kedere rán Jona lọ sí Ninefe, kí ó baà lè fi ìyàtọ̀ hàn láàárín àwọn ará Ninefe olùronúpìwàdà àti àwọn ọmọ Israeli olùwarùnkì, tí wọ́n ṣàìní ìgbàgbọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ lọ́nà yíyọyẹ́.—Fi wé Deuteronomi 9:6, 13.
Jona fúnra rẹ̀ ń kọ́? Ó kọ́ bí àánú Ọlọrun ti tóbi tó. Ní àfikún sí i, ìhùwàpadà Jehofa sí ìráhùn Jona nípa àánú tí a fi hàn sí àwọn ará Ninefe olùronúpìwàdà yẹ kí ó mú wa yàgò fún ṣíṣàròyé nígbà tí Bàbá wa ọ̀run bá fi àánú hàn sí àwọn ènìyàn ní ọjọ́ wa. Ní ti gidi, ẹ jẹ́ kí a máa yọ̀ pé lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń wá sọ́dọ̀ Jehofa nínú ìgbàgbọ́ àti pẹ̀lú ọkàn ìrẹ̀lẹ̀.