Ẹ̀yin Arákùnrin, Ẹ Fúnrúgbìn Nípa Tẹ̀mí, Kẹ́ Ẹ Sì Máa Wá Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn!
“Ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn yóò ká ìyè àìnípẹ̀kun láti inú ẹ̀mí.”—GÁL. 6:8.
1, 2. Báwo ni ọ̀rọ̀ inú ìwé Mátíù 9:37, 38 ṣe ń ní ìmúṣẹ lónìí, kí ni èyí sì mú ká nílò nínú àwọn ìjọ?
Ọ̀PỌ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ló ń ní ìmúṣẹ lójú wa báyìí! Iṣẹ́ tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ń bá a lọ ní pẹrẹu. Jésù sọ pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mát. 9:37, 38) Jèhófà Ọlọ́run ń dáhùn irú àdúrà yìí lọ́nà tí a kò tíì rí irú rẹ̀ rí. Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2009, iye ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé fi òjì-lé-lẹ́gbàá ó dín mẹ́sàn-án [2,031] pọ̀ sí i, ó sì ti di ọ̀kẹ́ márùn-ún àti ọ̀ọ́dúnrún lé lẹ́gbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ó dín méjì [105,298] báyìí. Iye èèyàn tó tó ọ̀tàlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́tà [757] ló sì ń ṣe ìrìbọmi lójoojúmọ́!
2 Ìbísí yìí wá mú ká nílò àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n tí á máa mú ipò iwájú nínú kíkọ́ni àti ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ. (Éfé. 4:11) Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni Jèhófà ti ń lo àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti máa bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀, ó sì dá wa lójú pé yóò máa bá a nìṣó. Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Míkà 5:5, mú kó dá wa lójú pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn èèyàn Jèhófà yóò ní “olùṣọ́ àgùntàn méje” àti “mọ́gàjí mẹ́jọ,” èyí tó ṣàpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin tó pọ̀ tó táá máa mú ipò iwájú láàárín wọn.
3. Sọ ohun tó túmọ̀ sí láti “fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn.”
3 Tó o bá jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́kùnrin tó o sì ti ṣe ìrìbọmi, kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa wá àǹfààní iṣẹ́ ìsìn? Ohun pàtàkì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o máa “fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn.” (Gál. 6:8) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa darí ìgbésí ayé rẹ. Pinnu pé o kò ní máa “fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹran ara . . . lọ́kàn.” Má ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan bí adùn ayé, fàájì àti eré ìnàjú bomi paná ìfẹ́ ọkàn rẹ láti fi taratara ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Gbogbo Kristẹni ló gbọ́dọ̀ máa “fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn,” àmọ́ bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn ọkùnrin tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ lè kúnjú ìwọ̀n láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Torí pé a nílò àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àtàwọn alàgbà gan-an lásìkò yìí, àwọn arákùnrin la dìídì darí àpilẹ̀kọ yìí sí. Torí náà, a rọ ẹ̀yin arákùnrin láti fún ọ̀rọ̀ yìí ní àfiyèsí, kẹ́ ẹ sì gbàdúrà nípa rẹ̀.
Ẹ Máa Wá Iṣẹ́ Àtàtà
4, 5. (a) Àǹfààní wo la rọ àwọn ọkùnrin tó ti ṣe ìrìbọmi láti máa wá nínú ìjọ? (b) Báwo ni ẹnì kan ṣe ń wá àǹfààní iṣẹ́ ìsìn?
4 Kristẹni kan tó jẹ́ ọkùnrin kì í ṣàdédé di alábòójútó nínú ìjọ. Ńṣe ló gbọ́dọ̀ wá “iṣẹ́ àtàtà” yìí. (1 Tím. 3:1) Ó sì kan ṣíṣiṣẹ́ sin àwọn ará, kó sì máa bójú tó àìní wọn tọkàntọkàn. (Ka Aísáyà 32:1, 2.) Bí arákùnrin kan bá ń wá iṣẹ́ yìí tọkàntọkàn, kì í ṣe ipò ọlá ló ń wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó gbà á lọ́kàn ni bí kò ṣe ní jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, àmọ́ táá máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nínú ìjọ.
5 Ọ̀nà tí ẹnì kan ń gbà láti kúnjú ìwọ̀n láti sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, kó sì tún wá ọ̀nà láti di alábòójútó ni pé, kó máa sapá láti dójú ìlà àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ là kalẹ̀. (1 Tím. 3:1-10, 12, 13; Títù 1:5-9) Tó o bá jẹ́ ọkùnrin tó ti ṣe ìyàsímímọ́, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mò ń kópa kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù, ṣé mo sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé mo máa ń gbé àwọn olùjọsìn bíi tèmi ró nípa fífihàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ mí lógún? Ṣé àwọn ará mọ̀ mí sí ẹni tó máa ń fi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ṣé mò ń mú kí ìdáhùn mi ní ìpàdé sunwọ̀n sí i? Ṣé mò ń bójú tó iṣẹ́ tí àwọn alàgbà yàn fún mi nínú ìjọ dáadáa?’ (2 Tím. 4:5) Ó yẹ ká ronú jinlẹ̀ lórí irú àwọn ìbéèrè yìí.
6. Kí ni ohun pàtàkì kan tó ń múni kúnjú ìwọ̀n fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ?
6 Ọ̀nà míì tó o tún lè gbà kúnjú ìwọ̀n fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ ni pé kí o “di alágbára ńlá nínú ẹni tí [o] jẹ́ ní inú pẹ̀lú agbára nípasẹ̀ ẹ̀mí [Ọlọ́run].” (Éfé. 3:16) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ fífi ìbò yanni sípò lọ̀rọ̀ dídi ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà nínú ìjọ. Kìkì àwọn tó bá dàgbà nípa tẹ̀mí ló máa ń ní àǹfààní yẹn. Báwo lèèyàn ṣe lè dẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí? Ọ̀nà kan ni pé kó o “máa rìn nípa ẹ̀mí,” kó o sì máa fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù. (Gál. 5:16, 22, 23) Bí o ṣe ń fi hàn pé o ní àwọn ànímọ́ tẹ̀mí láti bójú tó àfikún iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n bá gbé lé ẹ lọ́wọ́ tó o sì ń fi àwọn ìmọ̀ràn tó lè mú kó o ṣe dáadáa sí i tí wọ́n ń fún ẹ sílò, ‘ìlọsíwájú rẹ á fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.’—1 Tím. 4:15.
O Nílò Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ
7. Kí ni ṣíṣe iṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíì gba pé ká máa ṣe?
7 Ṣíṣe iṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíì gba pé ká máa ṣiṣẹ́ kára, ká sì ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Torí pé olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí ni àwọn Kristẹni alábòójútó jẹ́, àwọn ìṣòro tí agbo ní kàn wọ́n gbọ̀ngbọ̀n. Wo bí ojúṣe tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe nípa lórí rẹ̀. Ó sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé: “Nínú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú àti làásìgbò ọkàn-àyà ni mo kọ̀wé sí yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ omijé, kì í ṣe pé kí a lè bà yín nínú jẹ́, bí kò ṣe kí ẹ lè mọ ìfẹ́ tí mo ní pàápàá jù lọ fún yín.” (2 Kọ́r. 2:4) Ẹ̀rí fi hàn pé Pọ́ọ̀lù ṣe iṣẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn.
8, 9. Sọ àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó fi hàn bí àwọn ọkùnrin ṣe bójú tó àìní àwọn ẹlòmíì.
8 Ọjọ́ pẹ́ tí ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ ti jẹ́ àmì tá a fi ń dá àwọn ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ kára nítorí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, a mọ̀ pé Nóà kò jẹ́ jókòó gẹlẹtẹ kó wá máa sọ fún àwọn ará ilé rẹ̀ pé: ‘Tí ẹ bá ti kan ọkọ̀ áàkì yẹn tán kẹ́ ẹ sọ fún mi kí n lè wá báa yín.’ Mósè ò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní Íjíbítì pé: ‘Màá báa yín létí Òkun Pupa. Ẹ ṣáà wá bẹ́ ẹ ṣe máa débẹ̀.’ Jóṣúà kò sọ pé: ‘Ẹ jẹ́ kí n mọ̀ tí ògiri Jẹ́ríkò bá ti wó.’ Ní ti Aísáyà, kò tọ́ka sí ẹlòmíì, kó sì sọ pé ‘Òun nìyẹn! Rán an.’—Aísá. 6:8.
9 Ọkùnrin tó jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára jù lọ fún wa, tó gba ẹ̀mí Ọlọ́run láyè láti sún òun ṣiṣẹ́ ni Jésù Kristi. Ó fínnúfíndọ̀ tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an láti jẹ́ Olùgbàlà aráyé. (Jòh. 3:16) Ǹjẹ́ kò yẹ kí ìfẹ́ tí Jésù ní láti fi ara rẹ̀ rúbọ sún àwa náà láti ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ? Nígbà tí alàgbà kan tó ti ń sìn látọjọ́ pípẹ́ ń sọ nípa bí ọ̀rọ̀ agbo Ọlọ́run ṣe máa ń rí lára rẹ̀, ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún Pétérù pé, máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn mi, wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Mo ti wá rí i pé sísọ ọ̀rọ̀ tó fìfẹ́ hàn àti jíjẹ́ onínúure sí àwọn èèyàn lè fún wọn ní ìṣírí. Mo gbádùn iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn gan-an.”—Jòh. 21:16.
10. Kí ló lè mú kí àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Kristẹni máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù bó bá di pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ sin àwọn èèyàn?
10 Tó bá dọ̀rọ̀ agbo Ọlọ́run, ó dájú pé àwọn ọkùnrin tó ti ya ara wọn sí mímọ́ nínú ìjọ máa ń fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó sọ pé: “Èmi yóò sì tù yín lára.” (Mát. 11:28) Ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti ìfẹ́ fún ìjọ ló máa ń mú kí àwọn arákùnrin fẹ́ láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àtàtà yìí, wọn kì í sì í ronú pé iṣẹ́ náà ti nira jù tàbí pé ó máa ná àwọn ní nǹkan tó pọ̀. Àmọ́ bí kò bá wu ẹnì kan pé kóun gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ńkọ́? Báwo ni arákùnrin kan ṣe lè dẹni tó ń wù láti ṣiṣẹ́ sìn nínú ìjọ?
Jẹ́ Kó Máa Wù Ẹ́ Láti Sìn
11. Báwo lẹnì kan ṣe lè jẹ́ kó máa wu òun láti ṣiṣẹ́ sin àwọn èèyàn?
11 Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o kò kúnjú ìwọ̀n tó, tí ìyẹn sì mú kó o máa fà sẹ́yìn láti gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, ó yẹ kó o gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́. (Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ohun tó lè máa jẹ ẹ́ lọ́kàn lórí ọ̀ràn yìí. Ọlọ́run ló ń mú kó wu èèyàn láti sin òun, torí pé ẹ̀mí Jèhófà ló ń mú kí arákùnrin kan fẹ́ láti sìn, tó sì tún ń fún un lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́. (Fílí. 2:13; 4:13) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kó o bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó ti ọkàn rẹ̀ wá láti gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn.—Ka Sáàmù 25:4, 5.
12. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè ní ọgbọ́n tó pọ̀ tó láti bójú tó ojúṣe rẹ̀ nínú ìjọ?
12 Kristẹni kan lè máà fẹ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn bó bá kíyè sí i pé kò rọrùn láti bójú tó agbo àti pé iṣẹ́ náà máa ń gba àkókò. Ó sì tún lè máa ronú pé òun kò ní ọgbọ́n tó pọ̀ tó láti bójú tó iṣẹ́ náà. Tó bá jẹ́ bọ́rọ̀ ṣe rí nìyí, ó lè jèrè ọgbọ́n nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì déédéé. Ó sì lè béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé mò ń ya àkókò sọ́tọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣé mo sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún mi ní ọgbọ́n?’ Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un.” (Ják. 1:5) Ǹjẹ́ o gba ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí gbọ́? Nígbà tí Ọlọ́run dáhùn àdúrà Sólómọ́nì, ó fún un ní “ọkàn-àyà ọgbọ́n àti òye” èyí tó ń jẹ́ kó fòye mọ ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́ nígbà tó bá ń ṣe ìdájọ́. (1 Ọba 3:7-14) Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ ti Sólómọ́nì yàtọ̀ sí tiwa. Síbẹ̀, ó yẹ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa fún àwọn ọkùnrin tó ní ojúṣe nínú ìjọ ní ọgbọ́n tí wọ́n á fi máa bójú tó àwọn àgùntàn Ọlọ́run bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.—Òwe 2:6.
13, 14. (a) Ṣàlàyé bí “ìfẹ́ tí Kristi ní” ṣe nípa lórí Pọ́ọ̀lù. (b) Báwo ló ṣe yẹ kí “ìfẹ́ tí Kristi ní” nípa lórí wa?
13 Ohun míì tó tún lè mú kí èèyàn ní ìfẹ́ láti sin àwọn ẹlòmíì ni ríronú jinlẹ̀ lórí gbogbo ohun tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ti ṣe fún wa. Bí àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15. (Kà á.) Ọ̀nà wo ni “ìfẹ́ tí Kristi ní gbà sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa” láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíì? Ìfẹ́ tí Kristi fi hàn nípa fífi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọrun jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ débi pé bí ìmọrírì wa ṣe ń pọ̀ sí i, á túbọ̀ máa wù wá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí ìfẹ́ Kristi máa darí òun. Kò jẹ́ kó di onímọtara-ẹni-nìkan, ó sì jẹ́ kó pọkàn pọ̀ sórí sísin Ọlọ́run àti àwọn èèyàn, yálà nínú ìjọ tàbí lẹ́yìn òde ìjọ.
14 Tá a bá ń ronú lórí ìfẹ́ tí Kristi ní fún àwọn èèyàn, ìyẹn á mú ká mọ ọpẹ́ dá. Nípa bẹ́ẹ̀, a ó wá rí i pé kò bọ́gbọ́n mu fún wa láti máa bá a lọ ní ‘fífúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹran ara lọ́kàn,’ nípa lílépa ìfẹ́ ti ara àti gbígbé ìgbé ayé wa lọ́nà tí a ó fi máa tẹ́ ara wa nìkan lọ́rùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó ṣètò ara wa láti fi iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ sí ipò àkọ́kọ́. A ó sì tipa bẹ́ẹ̀ sún wa láti máa “sìnrú” fún àwọn ará wa nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. (Ka Gálátíà 5:13.) Tí a bá ń wo ara wa bí ẹrú tó ń fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe iṣẹ́ fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣe ìyàsímímọ́, a ó máa fi ọ̀wọ̀ wọ̀ wọ́n, a ó sì máa fi hàn pé a mọyì wọn. Ó ṣe kedere pé a ò ní máa fara wé Sátánì nínú ìwà àríwísí àti ẹ̀mí ìfẹ̀sùnkanni tó ń gbé lárugẹ.—Ìṣí. 12:10.
Ipa Tí Ìdílé Lè Kó
15, 16. Ipa wo ni ìdílé máa kó, kí ọkùnrin kan tó lè kúnjú ìwọ̀n láti dẹni tá a yàn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà?
15 Bí arákùnrin kan bá ti ṣe ìgbéyàwó tó sì láwọn ọmọ, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé rẹ̀ wà lára ohun tí wọ́n máa wò láti pinnu bóyá ó kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. Ká sòótọ́, ipò tẹ̀mí ìdílé arákùnrin kan àti ojú tí àwọn èèyàn fi ń wò wọ́n lè mú kí wọ́n yàn án tàbí kí wọ́n má yàn án. Èyí fi hàn pé ó ṣe pàtàkì pé kí ìdílé fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ àti bàbá wọn bó ṣe ń sapá láti sìn nínú ìjọ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà.—Ka 1 Tímótì 3:4, 5, 12.
16 Inú Jèhófà máa ń dùn tí àwọn tó jẹ́ ara ìdílé Kristẹni bá jọ fọwọ́ sowọ́ pọ̀. (Éfé. 3:14, 15) Ó gba kí olórí ìdílé kan wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì kó lè máa bójú tó ojúṣe rẹ̀ nínú ìjọ, kó sì tún máa ṣe àbójútó agbo ilé rẹ̀ “lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.” Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí alàgbà kan tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí gbogbo wọn lè máa jàǹfààní látinú Ìjọsìn Ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó ní láti máa jáde òde ẹ̀rí pẹ̀lú wọn déédéé. Fún ìdí yìí, ó ṣe pàtàkì fún àwọn tó wà nínú ìdílé láti kọ́wọ́ ti olórí ìdílé wọn lẹ́yìn nínú ìsapá rẹ̀.
Ṣé Wàá Tún Pa Dà Sìn?
17, 18. (a) Bí arákùnrin kan kò bá kúnjú ìwọ̀n mọ́ láti sìn, kí ló yẹ kó ṣe? (b) Èrò wo ni àwọn arákùnrin tó ti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nígbà kan rí lè ní?
17 Ó ṣeé ṣe kó o ti jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nígbà kan rí, àmọ́ kó jẹ́ pé o kò sìn nípò yẹn mọ́ báyìí. O nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì yẹ kó dá ẹ lójú pé ó bìkítà nípa rẹ. (1 Pét. 5:6, 7) Ṣé wọ́n sọ fún ẹ pé o ní láti ṣe àwọn àtúnṣe kan? Múra tán láti gba àṣìṣe rẹ, kó o sì ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Ṣọ́ra kó o má ṣe jẹ́ kí ìyẹn bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ. Jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kó o sì lẹ́mìí pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa. Alàgbà kan tó ti sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún àmọ́ tó pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sọ pé: “Mo pinnu pé màá máa lọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí déédéé bí mo ṣe máa ń ṣe nígbà tí mo ṣì jẹ́ alàgbà, mi ò sì ní dáwọ́ kíka Bíbélì dúró, ọwọ́ mi sì tẹ àfojúsùn yẹn. Mo kọ́ láti jẹ́ onísùúrù, torí pé èrò mi ni pé mo máa pa dà di alàgbà láàárín ọdún kan tàbí méjì, àmọ́ ó tó nǹkan bí ọdún méje kí n tó pa dà di alàgbà. Láàárín gbogbo àkókò yìí, ìṣírí tí mò ń rí gbà pé kí n má ṣe jẹ́ kó sú mi àti pé kí n máa wá àǹfààní náà nìṣó, ló ràn mí lọ́wọ́ gan-an.”
18 Tó o bá jẹ́ arákùnrin, tó o sì wà ní irú ipò tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Máa ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ àti ìdílé rẹ. Máa gbé ìdílé rẹ ró nípa tẹ̀mí, máa bẹ àwọn aláìsàn wò, kó o sì máa fún àwọn aláìlera ní ìṣírí. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mọyì àǹfààní tó o ní láti máa yin Ọlọ́run àti láti máa polongo ìhìn rere Ìjọba rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.a—Sm. 145:1, 2; Aísá. 43:10-12.
Tún Ipò Rẹ Gbé Yẹ̀ Wò
19, 20. (a) Kí la rọ gbogbo àwọn ọkùnrin tó ti ṣe ìrìbọmi láti ṣe? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
19 A nílò àwọn alábòójútó àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ gan-an báyìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Torí náà, à ń rọ gbogbo àwọn ọkùnrin tó ti ṣe ìrìbọmi pé kí wọ́n tún ipò wọn gbé yẹ̀ wò, kí wọ́n sì bi ara wọn pé: ‘Ti mi ò bá jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà, ṣé mo lè ṣe àgbéyẹ̀wò ìdí tí mi ò fi tíì máa sìn?’ Jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fojú tó tọ́ wo ọ̀ràn pàtàkì yìí.
20 Gbogbo ará ìjọ ló máa ń jàǹfààní nínú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ àti ìsapá àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Tí a bá jẹ́ onínúure, tí a kì í sì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan, a máa rí ayọ̀ tó ń wá látinú ṣíṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíì àti fífúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn. Àmọ́ bí àpilẹ̀kọ tó kàn ṣe fi hàn, a kò gbọ́dọ̀ máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè yẹra fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Míkà 5:5 mú dá wa lójú?
• Ṣàlàyé ohun tí ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ ní nínú.
• Báwo lẹnì kan ṣe lè jẹ́ kó máa wu òun láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíì?
• Báwo ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìdílé ti ṣe pàtàkì tó tí ọkùnrin kan bá fẹ́ kúnjú ìwọ̀n láti sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Kí lo lè ṣe láti wá àǹfààní iṣẹ́ ìsìn?