ORÍ KEJÌLÁ
“Máa Bá a Nìṣó Ní Fífojú Sọ́nà Fún Un”
1, 2. (a) Àwọn ìbéèrè wo lo lè bi ara rẹ? (b) Báwo ni nǹkan ti rí nígbà ayé àwọn kan lára àwọn wòlíì méjìlá náà, irú ẹ̀mí wo sì ni Míkà ní?
BÁWO ló ṣe pẹ́ tó tó o ti ń retí pé kí ọjọ́ Jèhófà dé láti fòpin sí ìwà ibi lórí ilẹ̀ ayé? Ìgbà wo lo lè dúró dè é dà? Ní báyìí ná, ẹ̀mí wo ló yẹ kó o ní, kí ló sì yẹ kó mú kó o máa ṣe? Ó hàn gbangba pé ìdáhùn rẹ á yàtọ̀ sí tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ pé bó ṣe wù wọ́n ni wọ́n ń gbé ìgbésí ayé wọn, tí wọ́n ń retí àtilọ sọ́run.
2 Bó o ṣe ń dúró de ọjọ́ ńlá yẹn, ìwé táwọn wòlíì méjìlá náà kọ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ gidigidi. Àkókò tí ìdájọ́ Ọlọ́run rọ̀ dẹ̀dẹ̀ ni ọ̀pọ̀ lára àwọn wòlíì náà gbé ayé. Bí àpẹẹrẹ, Míkà sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì nígbà tó kù díẹ̀ kí palaba ìyà tí Samáríà jẹ lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni wáyé. (Wo àtẹ ìsọfúnni àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀, tó wà lójú ìwé 20 àti 21.) Lẹ́yìn náà, bí àkókò ṣe ń lọ, ọjọ́ Jèhófà dé bá Júdà láìkùnà bó ṣe dé bá Samáríà. Ǹjẹ́ Míkà torí pé òun ò mọ ọjọ́ náà gan-an tí Ọlọ́run yóò mú ìdájọ́ rẹ̀ wá, kó wá jókòó tẹtẹrẹ, kó kàn máa retí pé Ọlọ́run á ṣe ohun tó fẹ́ ṣe láìpẹ́? Ohun tí Míkà sọ rèé: “Ní tèmi, Jèhófà ni èmi yóò máa wá. Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi. Ọlọ́run mi yóò gbọ́ mi.” (Míkà 7:7) Èyí fi hàn pé bí ohun tó ń bọ̀ ṣe dá Míkà lójú, kò jókòó tẹtẹrẹ, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń ṣe bí olùṣọ́ tó wà lórí ilé ìṣọ́, tó ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́.—2 Sámúẹ́lì 18:24-27; Míkà 1:3, 4.
3. Bí ìparun Jerúsálẹ́mù ti sún mọ́lé, ànímọ́ wo ni Hábákúkù àti Sefanáyà fi hàn?
3 Wo ibi tí orúkọ Sefanáyà àti Hábákúkù wà nínú àtẹ ìsọfúnni àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ṣó o rí i pé àkókò tí ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni rọ̀ dẹ̀dẹ̀ làwọn méjèèjì ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn? Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọn ò mọ̀ bóyá díẹ̀ ló kù kí ìdájọ́ Ọlọ́run dé tàbí ó ṣì máa pẹ́. (Hábákúkù 1:2; Sefanáyà 1:7, 14-18) Sefanáyà kọ̀wé pé: “‘Ẹ máa wà ní ìfojúsọ́nà fún mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘títí di ọjọ́ tí èmi yóò dìde sí ẹrù àkótogunbọ̀, nítorí ìpinnu ìdájọ́ mi ni láti . . . da ìdálẹ́bi tí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá jáde sórí wọn, gbogbo ìbínú jíjófòfò mi.’” (Sefanáyà 3:8) Hábákúkù ńkọ́, ẹni tó gbé ayé ní kò pẹ́ lẹ́yìn Sefanáyà? Òun náà kọ̀wé pé: “Ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, ó sì ń sáré lọ ní mímí hẹlẹhẹlẹ sí òpin, kì yóò sì purọ́. Bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀, máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.”—Hábákúkù 2:3.
4. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ lákòókò tí Sefanáyà àti Hábákúkù ń sọ tẹ́lẹ̀, kí sì làwọn méjèèjì ń ṣe bí wọ́n ṣe ń sọ tẹ́lẹ̀?
4 Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò tí Sefanáyà àti Hábákúkù kéde ohun tó wà ní Sefanáyà 3:8 àti Hábákúkù 2:3 jẹ́ ká lóye nǹkan kan. Lákòókò táwọn Júù kan ń sọ pé, “Jèhófà kì yóò ṣe rere, kì yóò sì ṣe búburú,” Sefanáyà kéde “ọjọ́ ìbínú Jèhófà.” Lọ́jọ́ ìbínú yẹn, àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá àtàwọn Júù oníwàkiwà yóò rí ìbínú Ọlọ́run. (Sefanáyà 1:4, 12; 2:2, 4, 13; 3:3, 4) Àbí o rò pé ẹ̀rù ìbáwí Ọlọ́run ló ń ba Sefanáyà? Ẹ̀rù ò bà á o, ohun tí Ọlọ́run sọ fún un ni pé kó máa “wà ní ìfojúsọ́nà,” ìyẹn ni pé kó máa retí òun. Ó ṣeé ṣe kó o béèrè pé, ‘Hábákúkù ńkọ́ ní tiẹ̀?’ Òun náà ní láti “máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un.” O tọ̀nà bó o bá gbà pé wòlíì Sefanáyà àti Hábákúkù ò wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú bí ohun tí kò ṣe pàtàkì, wọn ò gbé ìgbé ayé wọn bí ẹni tó rò pé nǹkan ò ní yí padà. (Hábákúkù 3:16; 2 Pétérù 3:4) Kàkà bẹ́ẹ̀, nǹkan kan pàtàkì tá a kíyè sí nípa wọn ni pé, àwọn méjèèjì ni wọ́n “wà ní ìfojúsọ́nà.” Kó o sì máa wò ó o, ohun táwọn méjèèjì ń retí wáyé lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nítorí náà, ìwà ọgbọ́n ni bí wọ́n ṣe ń bá a nìṣó láti “wà ní ìfojúsọ́nà.”
5, 6. Pẹ̀lú àkókò tá a wà báyìí bí àwọn ohun ti Ọlọ́run ní lọ́kàn ṣe ń nímùúṣẹ, irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní?
5 Jẹ́ kó dá ọ lójú pé bẹ́ẹ̀ gan-an ni “ọjọ́ ìbínú Jèhófà” yóò ṣe dé bá ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí; kò ní ṣàìdé, yóò wáyé gan-an bí Ọlọ́run ṣe sọ. Ó dájú pé o ò ṣiyèméjì kankan nípa ìyẹn. Bíi ti Sefanáyà àti Hábákúkù, ìwọ náà ò mọ ọjọ́ náà gan-an tí yóò dé. (Máàkù 13:32) Síbẹ̀, yóò dé dájúdájú, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ń nímùúṣẹ lákòókò yìí sì fi hàn pé yóò dé láìpẹ́. Nítorí náà, kókó tí Jèhófà tẹnu mọ́ fún àwọn wòlíì náà kàn ọ́, kókó ọ̀hún sì ni pé, “máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un.” Sì rántí òótọ́ pọ́ńbélé yìí, pé: Ọlọ́run wa ni Ọlọ́run kan ṣoṣo tó “ń gbé ìgbésẹ̀ ní tìtorí ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.”—Aísáyà 64:4.
6 Ó yẹ kó o ní ẹ̀mí ìfojúsọ́nà tó yẹ, kó o máa jẹ́ káwọn ohun tó ò ń ṣe fi hàn pé ó dá ọ lójú pé àkókò tí Jèhófà là kalẹ̀ gan-an ni “ọjọ́ ìbínú Jèhófà” yóò dé. Tó o bá ní ìdánilójú yìí tó o sì ń ṣe àwọn ohun yíyẹ tó máa fi ìdánilójú náà hàn, nǹkan kan tí Jésù rọ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àti gbogbo àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró pé kí wọ́n máa ṣe lò ń ṣe yẹn. Kí ni nǹkan náà? Jésù ní: “Ẹ jẹ́ kí abẹ́nú yín wà ní dídì ní àmùrè, kí àwọn fìtílà yín sì máa jó, kí ẹ̀yin fúnra yín sì dà bí àwọn ọkùnrin tí ń dúró de ọ̀gá wọn . . . Aláyọ̀ ni ẹrú wọnnì tí ọ̀gá náà bá tí ń ṣọ́nà nígbà tí ó dé! Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Yóò di ara rẹ̀ lámùrè, yóò sì mú kí wọ́n rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì, yóò sì bọ́ sí tòsí, yóò sì ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.” (Lúùkù 12:35-37) Tẹ́nì kan bá ní ẹ̀mí ìdúródeni tó yẹ, á fí hàn pé ó dá ẹni náà lójú pé ọjọ́ ńlá Jèhófà ò ní fi ìṣẹ́jú kan kọjá àkókò tí Jèhófà là kalẹ̀.
‘MÁA FOJÚ SỌ́NÀ FÚN UN’ KÓ O SÌ “WÀ NÍ ÌMÚRATÁN”
7, 8. (a) Kí làǹfààní sùúrù tí Ọlọ́run ní? (b) Kí ni Pétérù rọ̀ wá pé ká máa ṣe?
7 Kí Ìjọba Ọlọ́run tó bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀run lọ́dún 1914 làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run òde òní ti ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ Jèhófà, wọn ò sì yéé retí rẹ̀ látìgbà yẹn. Àmọ́ wọn ò kàn káwọ́ gbera bí wọ́n ṣe ń retí rẹ̀ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìjẹ́rìí tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ láìdáwọ́dúró. (Ìṣe 1:8) Àmọ́ rò ó wò ná: Ká sọ pé ọjọ́ ńlá Jèhófà dé lọ́dún 1914 lọ́hùn-ún, ibo lò bá wà báyìí? Tó bá sì jẹ́ pé nǹkan bí ogójì ọdún sẹ́yìn ló ti dé, ǹjẹ́ o jẹ́ ẹni “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” nígbà yẹn? (2 Pétérù 3:11) Àwọn ará ilé rẹ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ńkọ́, tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìjọ? Ó hàn gbangba pé àkókò tá a fi ń retí ọjọ́ Jèhófà yìí fún ìwọ àtàwọn ẹlòmíràn láǹfààní láti rí ìgbàlà, bí 2 Pétérù 3:9 ṣe fi hàn. Pípa tí Jèhófà kò pa gbogbo ètò àwọn nǹkan búburú run ní gbàrà tó fìdí Ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ló jẹ́ kí ọ̀pọ̀ láǹfààní láti ronú pìwà dà, bí àwọn ará Nínéfè ṣe láǹfààní láti ronú pìwà dà tí Ọlọ́run sì dá ẹ̀mí wọn sí. Nítorí náà, ìdí wà tó fi yẹ kí gbogbo wa gba ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ, pé: “Ẹ ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà.” (2 Pétérù 3:15) Àkókò tá a wà yìí ṣì ń jẹ́ káwọn èèyàn láǹfààní láti ronú pìwà dà tàbí kí wọ́n ṣàtúnṣe ìgbésí ayé wọn kí wọ́n sì tún ìrònú wọn ṣe.
8 Ká sòótọ́, Kristẹni kan lè ronú nípa bí nǹkan ṣe rí nígbà ayé Míkà, Sefanáyà, àti Hábákúkù, àmọ́ kó má kà á sí. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó sọ pé, “Ìtàn ayé ọjọ́un nìyẹn o jàre.” Àmọ́ a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú rẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo? Rántí pé a ti mẹ́nu kan ohun tí Pétérù sọ, pé àwa Kristẹni ní láti jẹ́ ẹni “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” Bí Pétérù ṣe sọ èyí tán, ó tún tẹnu mọ́ ohun mìíràn tá a ní láti ṣe, ìyẹn ni pé ká máa ‘dúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà ká sì máa fi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.’ (2 Pétérù 3:11, 12) Nítorí náà, a ní láti máa ‘fi ọjọ́ yẹn sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí,’ ká máa ‘fojú sọ́nà fún un.’
9. Kí nìdí tó fi jẹ́ ohun tó yẹ pé ká máa bá a nìṣó láti fojú sọ́nà?
9 Yálà ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà tàbí ṣe la ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ǹjẹ́ à ń bá a nìṣó láti fojú sọ́nà tá a sì ‘ní irú ẹ̀mí ìdúródeni’ tí Míkà fi hàn? (Róòmù 13:11) Òótọ́ ni pé, níwọ̀n bá a ti jẹ́ ẹ̀dá èèyàn, ó lè máa wù wá gidigidi láti mọ ìgbà tí òpin yóò dé àti bí yóò ṣe pẹ́ tó kó tó dé. Àmọ́ kò sí bá a ṣe lè mọ̀. Rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ká ní baálé ilé mọ ìṣọ́ tí olè ń bọ̀ ni, ì bá wà lójúfò, kì bá sì ti yọ̀ǹda kí a fọ́ ilé rẹ̀. Ní tìtorí èyí, ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.”—Mátíù 24:43, 44.
10. Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú ìgbésí ayé àpọ́sítélì Jòhánù àti bó ṣe wà ní ìmúratán tó sì ń retí ọjọ́ Jèhófà?
10 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Jésù sọ yìí dà bí ohun tí Míkà, Sefanáyà àti Hábákúkù ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀, síbẹ̀, kì í ṣe àwọn èèyàn ayé ọjọ́un ni Jésù sọ̀rọ̀ náà fún, bí kò ṣe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn àwa. Ọ̀pọ̀ Kristẹni olùfọkànsìn ni wọ́n ti fi ọ̀rọ̀ Jésù sílò; wọ́n “wà ní ìmúratán,” wọn ò yéé retí. Àpẹẹrẹ rere ni àpọ́sítélì Jòhánù jẹ́ lórí èyí. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn mẹ́rin tí wọ́n lọ bá Jésù lórí Òkè Ólífì tí wọ́n sì bi í ní ìbéèrè nípa òpin ètò àwọn nǹkan. (Mátíù 24:3; Máàkù 13:3, 4) Ìyẹn jẹ́ ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àmọ́ kò sí ohun tí Jòhánù lè wò láti fi mọ àkókò náà gan-an tí òpin á dé. Fojú inú wò ó pé nǹkan bí ọgọ́ta ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí Jòhánù bi Jésù ní ìbéèrè nípa òpin ètò àwọn nǹkan. Jòhánù ọ̀hún ti darúgbó, síbẹ̀, kò rẹ̀ ẹ́ kò sì sọ pé ó ti sú òun láti máa retí. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tó gbọ́ tí Jésù sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni; mo ń bọ̀ kíákíá,” ńṣe ló fèsì pé: “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.” Jòhánù ò kábàámọ̀ ohun tó fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Ó dá a lójú pé nígbà tí Jèhófà bá mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ, yóò san án fún olúkúlùkù níbàámu pẹ̀lú iṣẹ́ rẹ̀. (Ìṣípayá 22:12, 20) Ìgbàkigbà tó wù kí ìdájọ́ yẹn dé, Jòhánù fẹ́ láti wà ní “ìmúratán,” gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn Jésù Olúwa. Ṣé ìwọ náà fẹ́ láti wà ní ìmúratán?
ṢÉ Ò Ń ‘FOJÚ SỌ́NÀ FÚN UN’ NI ÀBÍ ‘O TI YÓ’?
11. Báwo làwọn èèyàn tí wọ́n gbé ayé lákòókò Míkà àti Hóséà ṣe yàtọ̀ sí Míkà àti Hóséà?
11 Tún wo ẹ̀kọ́ mìíràn tá a lè rí kọ́ lọ́dọ̀ àwọn wòlíì tí wọ́n gbé ayé lákòókò tí ìdájọ́ Jèhófà rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí Ísírẹ́lì, àti lẹ́yìn náà, sórí Júdà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Míkà ń bá a nìṣó láti fojú sọ́nà tó sì ‘fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn,’ ọ̀pọ̀ àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ò ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n di “olùkórìíra ohun rere àti olùfẹ́ ìwà búburú.” Míkà kìlọ̀ fún wọn pé tí wọn ò bá yí padà, tí wọ́n bá ‘ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́, kò ní dá wọn lóhùn.’ (Míkà 3:2, 4; 7:7) Hóséà tó gbé ayé lákòókò kan náà pẹ̀lú Míkà lo àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ nígbà tó ń rọ àwọn tó wà ní ìjọba àríwá Ísírẹ́lì. Ó ní: “Ẹ fún irúgbìn fún ara yín ní òdodo; ẹ kárúgbìn ní ìbámu pẹ̀lú inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Ẹ ro ilẹ̀ adárafọ́gbìn fún ara yín nígbà tí àkókò wà fún wíwá Jèhófà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Hóséà rọ̀ wọ́n, létí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn, ajá ló ń gbó. Nítorí pé wọ́n “túlẹ̀ ìwà burúkú,” àìṣòdodo ni wọ́n ká. (Hóséà 10:12, 13) Ńṣe ni wọ́n ń fàyè gba ìwà ìbàjẹ́ tàbí kí wọ́n lọ́wọ́ nínú rẹ̀, dípò kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀nà Jèhófà, ‘ọ̀nà ara wọn ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé.’ Lónìí, àwọn kan lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn olùjọsìn Jèhófà tó jẹ́ pé Ilẹ̀ Ìlérí ni wọ́n ń gbé?’ Hóséà fi hàn pé nǹkan kan tá a ní láti máa ṣọ́ra fún kó tó lè ṣeé ṣe fún wa láti máa fojú sọ́nà fún ọjọ́ Jèhófà ló fa ìṣòro wọn. Kí ni nǹkan ọ̀hún? Ó jẹ́ dídi ẹni tó ń gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ tó sì “yó.”
12. (a) Ohun tí kò dára wo ni Hóséà fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kó tó di ọdún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni? (b) Àwọn nǹkan wo ló fi hàn pé àwọn èèyàn náà ti “yó”?
12 Lẹ́yìn táwọn èèyàn Ọlọ́run dé Ilẹ̀ Ìlérí, ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, wọ́n ní aásìkí tó pọ̀ díẹ̀. Kí wá ní wọ́n ṣe pẹ̀lú aásìkí tí wọ́n ní yẹn? Hóséà sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ó ní: “Ní ìbámu pẹ̀lú pápá ìjẹko wọn, wọ́n sì yó. Wọ́n yó, ọkàn-àyà wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ga. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbàgbé mi.” (Hóséà 13:6) Ọlọ́run ti kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ nípa ewu yẹn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn. (Diutarónómì 8:11-14; 32:15) Síbẹ̀, nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Hóséà àti Ámósì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti gbàgbé Jèhófà àti àṣẹ rẹ̀ torí pé “wọ́n yó.” Ámósì mẹ́nu kan àwọn nǹkan kan pàtó tí wọ́n ń ṣe. Ó sọ pé àwọn kan lára wọn ní àwọn ohun ọ̀ṣọ́ nínú ilé wọn, kódà àwọn ìdílé míì ní ilé méjì. Oúnjẹ tó dára jù ni wọ́n ń jẹ, ife tírú rẹ̀ ò wọ́pọ̀ ni wọ́n fi ń mu wáìnì, “òróró tí í ṣe ààyò jù lọ,” bóyá irú èyí tí wọ́n fi èròjà atasánsán sí, ni wọ́n fi ń para. (Ámósì 3:12, 15; 6:4-6) Ká sòótọ́, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyẹn tó burú, àmọ́ ó burú tó bá jẹ́ pé àwọn lèèyàn kà sí pàtàkì jù.
13. Yálà ọlọ́rọ̀ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tàbí òtòṣì, àbùkù wo ni wọ́n ní?
13 Ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn tó wà ní ìjọba àríwá ló láásìkí tó sì “yó.” Òtòṣì làwọn kan lára wọn, wọ́n sì gbọ́dọ̀ tiraka kí awọ tó lè kájú ìlù fún ìdílé wọn. (Ámósì 2:6; 4:1; 8:4-6) Bó ṣe rí ní ọ̀pọ̀ ibi lórí ilẹ̀ ayé lónìí nìyẹn. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Hóséà 13:6 kan àwọn òtòṣì ní Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, ṣé ó sì kan àwọn òtòṣì lóde òní? Dájúdájú, ó kàn wọ́n. Ohun tí Jèhófà ń fi hàn ni pé, yálà olùjọsìn tòótọ́ jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí òtòṣì, ó gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má bàa máa fìgbésí ayé rẹ̀ wá àwọn ohun ìní tara débi táá fi ‘gbàgbé Ọlọ́run.’—Lúùkù 12:22-30.
14. Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú lórí bá a ṣe ń retí ọjọ́ Jèhófà sí?
14 Ní àkókò tá a wà yìí, a lè wẹ̀yìn wò ká sì rí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló sì ti nímùúṣẹ. Ìyẹn jẹ́ ìdí mìíràn tó fi yẹ ká máa wà lójúfò, ká wà ní ìmúrasílẹ̀, ká máa fojú sọ́nà. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ó ti pẹ́ díẹ̀ tá a ti ń fojú sọ́nà ńkọ́? Bóyá ní ìgbà tó ti kọjá, a lo ara wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, a sì ṣe àwọn ìpinnu tó fi hàn pé ó dá wa lójú pé ọjọ́ Jèhófà ò ní pẹ́ dé. Síbẹ̀, kò tíì dé títí di báyìí. Ǹjẹ́ a ṣì ń retí? Kálukú wa tiẹ̀ lè dojú ìbéèrè yẹn kọ ara rẹ̀, pé, ‘Ǹjẹ́ mo ṣì ń fi gbogbo ọkàn retí ọjọ́ Jèhófà, àbí mi ò fi gbogbo ọkàn retí rẹ̀ mọ́?’—Ìṣípayá 2:4.
15. Kí làwọn nǹkan tó lè fi hàn pé a ò fi bẹ́ẹ̀ retí ọjọ́ Jèhófà mọ́?
15 Ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà díwọ̀n bá a ṣe ń retí ọjọ́ Jèhófà sí. Àmọ́ ẹ jẹ́ ká lo ohun tí Ámósì sọ nípa àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀, ìyẹn ni pé, wọ́n “yó.” Bá a ṣe ń gbé ìyẹn yẹ̀ wò, a ó lè mọ̀ bóyá ó ti ń ṣe àwa náà bíi pé ká máa wá bí a ó ṣe “yó.” Bí àpẹẹrẹ, Kristẹni kan tó fi hàn nínú èrò rẹ̀ àti ìṣe rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn pé òun ń retí ọjọ́ Jèhófà lè bẹ̀rẹ̀ sí í forí ṣe fọrùn ṣe kó lè túbọ̀ ní ọ̀pọ̀ nǹkan amáyédẹrùn nínú ilé rẹ̀ tàbí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ olówó ńlá, aṣọ ìgbàlódé, àwọn ohun èlò ìṣaralóge tó gbówó lórí, tàbí ọtí tí irú rẹ̀ ò wọ́pọ̀ àti oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀. Ká sòótọ́, kò síbì kankan tí Bíbélì ti sọ pé ká máa fi adùn tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì du ara wa. Ó ṣe tán, ẹni tó bá ń ṣiṣẹ́ kára ní láti ‘máa jẹ, kó máa mu, kó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.’ (Oníwàásù 3:13) Àmọ́, tó bá jẹ́ pé oúnjẹ, ohun mímu, àti ìmúra ló gba Kristẹni kan lọ́kàn, ewu wà ńbẹ̀ o. (1 Pétérù 3:3) Jésù sọ pé àwọn ẹni àmì òróró kan ní Éṣíà Kékeré ti gbé ọkàn wọn lọ sórí nǹkan mìíràn, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ewu nìyẹn jẹ́ fún Kristẹni. (Ìṣípayá 3:14-17) Ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ti ṣẹlẹ̀ sí wa? Ṣé kì í ṣe pé ‘a ti ń yó,’ bóyá tí àwọn ohun tara ti ń gbà wá lọ́kàn? Ṣé kì í ṣe pé a ò retí ọjọ́ Jèhófà tó bá a ṣe ń retí rẹ̀ tẹ́lẹ̀ mọ́?—Róòmù 8:5-8.
16. Kí nìdí tí kò fi ní ṣe àwọn ọmọ wa láǹfààní tá a bá ń fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n máa lépa ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ?
16 Tá ò bá fi gbogbo ọkàn retí ọjọ́ Jèhófà mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, ó lè hàn nínú ìmọ̀ràn tá à ń gba àwọn ọmọ wa àtàwọn ẹlòmíì. Kristẹni kan lè ronú pé: ‘Mo rò pé òpin ti sún mọ́lé, mo pinnu pé mi ò ní lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tàbí kí n lépa iṣẹ́ olówó ńlá nígbèésí ayé. Àmọ́ ní báyìí tí òpin ò tíì dé, mo gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn ọmọ mi kàwé kí wọ́n lè gbé ìgbé ayé ìdẹ̀rùn.’ Ó ṣeé ṣe káwọn kan nígbà ayé Hóséà ní irú èrò yẹn. Tó bá jẹ́ pé wọ́n ní irú èrò yẹn, tó sì jẹ́ pé ìmọ̀ràn kan ṣoṣo tí wọ́n ń gba àwọn ọmọ wọn ni pé kí wọ́n máa lépa bí wọ́n á ṣe “yó” nígbèésí ayé, ìyẹn bí wọ́n á ṣe máa gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ, àǹfààní wo ni àwọn ọmọ wọn á rí nínú ìyẹn? Tó bá sì jẹ́ pé àwọn ọmọ wọn nígbà yẹn lépa ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ, báwo ni nǹkan á ṣe rí fún wọn lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn ará Ásíríà pa Samáríà run?—Hóséà 13:16; Sefanáyà 1:12, 13.
OHUN TÍ YÓÒ ṢẸLẸ̀ LÓÒÓTỌ́ NI KÓ O MÁA RETÍ
17. Ọ̀nà wo ló yẹ ká gbà fara wé Míkà?
17 Bíi tàwọn olùjọsìn ayé ìgbà láéláé, àwa náà lè ní ìdánilójú pé ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò nímùúṣẹ lásìkò tí Ọlọ́run là kalẹ̀. (Jóṣúà 23:14) Ìwà ọgbọ́n ni wòlíì Míkà hù bó ṣe dúró de Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀. Tá a bá wo àtẹ ìsọfúnni àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀, a óò rí i pé ìparun Samáríà ti sún mọ́lé gan-an lákòókò tí Míkà gbé láyé. Àwa náà ńkọ́ lákòókò tá a wà yìí? Tá a bá wo ohun tá a ti ń fi ìgbésí ayé wa ṣe bọ̀, ǹjẹ́ a máa rí i pé a ti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nínú ọ̀ràn ẹ̀kọ́ tàbí iṣẹ́ tá a yàn, ọ̀nà tá à ń gbà gbé ìgbé ayé wa àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún? Òótọ́ ni pé a ò mọ “ọjọ́ àti wákàtí yẹn.” (Mátíù 24:36-42) Àmọ́ kò sí àní-àní pé ìwà ọgbọ́n là ń hù tá a bá ń retí ọjọ́ yẹn bíi ti Míkà tá a sì ń hùwà tó bá ohun tá à ń retí mu. Nígbà tí Ọlọ́run bá sì fi ìyè san Míkà lẹ́san nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, ó dájú pé inú rẹ̀ á dùn gan-an tó bá mọ̀ pé a jàǹfààní nínú iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ òun àti àpẹẹrẹ rere òun. Wíwà tá a bá wà láàyè nígbà yẹn á jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà ni Ọlọ́run ìgbàlà!
18, 19. (a) Àgbákò wo ni Ọbadáyà sọ tẹ́lẹ̀? (b) Báwo ni Ọbadáyà ṣe sọ̀rọ̀ ìrètí fún Ísírẹ́lì?
18 Ìdí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà tá a fi ní ìdánilójú. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ìwé àsọtẹ́lẹ̀ Ọbadáyà tí kò gùn rárá. Àkọsílẹ̀ rẹ̀ dá lórí orílẹ̀-èdè Édómù ayé ọjọ́un, ó sọ ìdájọ́ tí Jèhófà yóò ṣe fún àwọn ọmọ Édómù tó ṣàìdáa sí Ísírẹ́lì “arákùnrin” wọn. (Ọbadáyà 12) Àgbákò tó sì sọ tẹ́lẹ̀ wáyé lóòótọ́ bá a ṣe gbé e yẹ̀ wò ní Orí Kẹwàá ìwé yìí. Àwọn ará Bábílónì lábẹ́ àṣẹ Nábónídọ́sì ṣẹ́gun Édómù ní ìdajì ọ̀rúndún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni, orílẹ̀-èdè Édómù sì pa rẹ́ ráúráú. Àmọ́ kókó mìíràn tún wà nínú iṣẹ́ tí Ọbadáyà jẹ́, kókó náà sì ní nǹkan kan án ṣe pẹ̀lú bíbá a nìṣó tá à ń bá a nìṣó láti retí ọjọ́ ńlá Jèhófà.
19 O mọ̀ pé orílẹ̀-èdè ọ̀tá (ìyẹn Bábílónì) tó sọ Édómù dahoro tún fìyà tí Ọlọ́run ní lọ́kàn jẹ àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ aláìgbọràn. Lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run wọ́n sì kó àwọn Júù lọ sí ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, ilẹ̀ náà dahoro, tí ẹnì kankan ò gbébẹ̀ mọ́. Àmọ́ ṣé ibẹ̀ lọ̀ràn náà parí sí ni? Rárá o. Jèhófà gbẹnu Ọbadáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò tún padà sí ilẹ̀ wọn. Ìlérí amóríyá tó wà ní Ọbadáyà ẹsẹ 17 kà pé: “Òkè Ńlá Síónì sì ni ibi tí àwọn tí ó sá àsálà yóò wà, yóò sì di ohun mímọ́; ilé Jékọ́bù yóò sì gba àwọn nǹkan tí ó jẹ́ tiwọn láti ní.”
20, 21. Kí nìdí tó fi yẹ kí ohun tó wà ní Ọbadáyà ẹsẹ 17 fi wá lọ́kàn balẹ̀?
20 Ìtàn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ohun tí Ọlọ́run gbẹnu Ọbadáyà sọ nímùúṣẹ lóòótọ́. Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló sì rí. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìgbèkùn Júdà àti Ísírẹ́lì padà sí ilẹ̀ wọn lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, wọ́n ṣàtúnṣe ilẹ̀ wọn. Ibi tó ti dahoro tẹ́lẹ̀ bá yí padà di àgbègbè ẹlẹ́wà. O ti ka àsọtẹ́lẹ̀ ìyípadà tó pabanbarì yẹn nínú Aísáyà 11:6-9 àti Aísáyà 35:1-7. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ níbẹ̀ ni pé àwọn Júù tún padà bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn tòótọ́ tó fìdí kalẹ̀ sí tẹ́ńpìlì Jèhófà tí wọ́n tún kọ́. Nípa báyìí, Ọbadáyà ẹsẹ 17 tún jẹ́ ẹ̀rí mìíràn tó fi hàn wá pé àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣeé gbára lé. Wọ́n kì í ṣàì ṣẹ.
21 Gbólóhùn tí Ọbadáyà tẹnu mọ́ tó fi parí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ni pé: “Ipò ọba yóò sì di ti Jèhófà.” (Ọbadáyà 21) Bó o ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí yẹn, ò ń retí àkókò ológo tí Jèhófà yóò tipasẹ̀ Jésù Kristi ṣàkóso, tí àkóso rẹ̀ ò sì ní ní alátakò kankan láyé àti lọ́run. Ì báà jẹ́ ọ̀pọ̀ ọdún lo ti fi ń retí ọjọ́ ńlá Jèhófà àti ìbùkún tí yóò mú wá, tàbí o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í retí rẹ̀, jẹ́ kó dá ọ lójú pátápátá pé àwọn ohun tó ò ń retí yóò nímùúṣẹ dájúdájú, ó ṣe tán, Bíbélì ló sọ ọ́.
22. Kí nìdí tó o fi fẹ́ kí èrò rẹ nípa ọjọ́ ọ̀la jọ ohun tó wà nínú Hábákúkù 2:3 àti Míkà 4:5?
22 Nítorí náà, ó bá a mu pé ká tún sọ ọ̀rọ̀ ìdánilójú Hábákúkù lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó dájú pé ọ̀rọ̀ náà kan àkókò tá a wà yìí. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún ni pé: “Ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, ó sì ń sáré lọ ní mímí hẹlẹhẹlẹ sí òpin, kì yóò sì purọ́. Bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀, máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.” (Hábákúkù 2:3) Kódà tó bá jẹ́ pé lójú àwa èèyàn, ó dà bíi pé ọjọ́ ńlá Jèhófà ń falẹ̀, kò ní ṣaláì dé lákòókò tí Jèhófà là kalẹ̀. Jèhófà ní ká má mikàn, pé bẹ́ẹ̀ ló máa rí. Nítorí náà, kí àwọn tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́tipẹ́ àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sínú ìjọsìn tòótọ́ jọ máa tẹ̀ síwájú pẹ̀lú irú ìdánilójú tá a rí nínú Míkà 4:5, tó kà pé: “Àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”