Ọbadáyà
1 Ìran tí Ọbadáyà* rí:
Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nípa Édómù nìyí:+
“A ti gbọ́ ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Jèhófà,
Aṣojú kan ti lọ jíṣẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè pé:
‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká múra láti bá a jagun.’”+
2 “Wò ó! Mo ti sọ ọ́ di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan láàárín àwọn orílẹ̀-èdè;
O ti tẹ́ pátápátá.+
3 Ìgbéraga* ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ,+
Ìwọ tó ń gbé ihò inú àpáta,
Ìwọ tó ń gbé ibi gíga, tí o sì ń sọ nínú ọkàn rẹ pé,
‘Ta ló lè rẹ̀ mí wálẹ̀?’
4 Bí o bá tiẹ̀ kọ́lé sí ibi gíga* bí ẹyẹ idì,
Tàbí tí o kọ́ ìtẹ́ rẹ sáàárín àwọn ìràwọ̀,
Màá rẹ̀ ọ́ wálẹ̀ láti ibẹ̀,” ni Jèhófà wí.
Ṣebí ohun tí wọ́n bá fẹ́ nìkan ni wọ́n á kó?
6 Ẹ wo bí wọ́n ṣe wá Ísọ̀ kàn!
Gbogbo ìṣúra tó fi pa mọ́ ni wọ́n ti wá jáde!
7 Wọ́n ti lé ọ títí dé ẹnubodè.
Gbogbo àwọn tó bá ọ ṣàdéhùn* ti tàn ọ́ jẹ.
Àwọn tí ẹ jọ wà ní àlàáfíà ti borí rẹ.
Àwọn tí ẹ jọ ń jẹun* yóò dẹ àwọ̀n dè ọ́,
Àmọ́ ìwọ kò ní mọ̀.
8 Ní ọjọ́ yẹn,” ni Jèhófà wí,
“Èmi yóò pa àwọn ọlọ́gbọ́n run kúrò ní Édómù+
Èmi yóò sì pa òye run ní agbègbè olókè Ísọ̀.
9 Ẹ̀rù yóò ba àwọn jagunjagun rẹ,+ ìwọ Témánì,+
Torí gbogbo ẹni tó wà ní agbègbè olókè Ísọ̀ ni yóò ṣègbé nítorí ìpakúpa.+
11 Ní ọjọ́ tí ìwọ ta kété sí ẹ̀gbẹ́ kan,
Ní ọjọ́ tí àwọn àjèjì mú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lẹ́rú,+
Nígbà tí àwọn àjèjì gba ẹnubodè rẹ̀ wọlé, tí wọ́n sì ṣẹ́ kèké+ lórí Jerúsálẹ́mù,
Ìwọ náà ṣe bíi tiwọn.
12 Kò yẹ kí o fi ọmọ ìyá rẹ ṣe yẹ̀yẹ́ ní ọjọ́ tí àjálù bá a,+
Kò yẹ kí o yọ̀ lórí àwọn ọmọ Júdà ní ọjọ́ tí wọ́n ń ṣègbé lọ,+
Kò sì yẹ kí o máa fọ́nnu ní ọjọ́ wàhálà wọn.
13 Kò yẹ kí o wọ ìlú* àwọn èèyàn mi ní ọjọ́ àjálù wọn,+
Kò yẹ kí o fi í ṣe yẹ̀yẹ́ ní ọjọ́ àjálù rẹ̀,
Kò sì yẹ kí o fọwọ́ kan ohun ìní rẹ̀ ní ọjọ́ àjálù rẹ̀.+
14 Kò yẹ kí o dúró sí oríta láti pa àwọn èèyàn rẹ̀ tó ń sá lọ,+
Kò sì yẹ kí o fi àwọn èèyàn rẹ̀ tó yè bọ́ ní ọjọ́ wàhálà lé ọ̀tá lọ́wọ́.+
15 Nítorí ọjọ́ tí Jèhófà fẹ́ bá gbogbo orílẹ̀-èdè jà ti sún mọ́lé.+
Ohun tí o ṣe ni wọn yóò ṣe sí ọ.+
Ìwà tí o hù sí àwọn èèyàn ni wọn yóò hù sí ọ.
16 Bí o ṣe mu wáìnì lórí òkè mímọ́ mi,
Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò máa mu ìbínú mi nígbà gbogbo.+
Wọn yóò rọ́ ọ sí ọ̀fun, wọn yóò sì gbé e mì,
Yóò sì dà bíi pé wọn kò gbé ayé rí.
17 Àmọ́ àwọn tó sá àsálà yóò wà lórí Òkè Síónì,+
Yóò sì di mímọ́;+
Ilé Jékọ́bù yóò sì gba àwọn nǹkan tó jẹ́ tiwọn.+
18 Ilé Jékọ́bù yóò di iná,
Ilé Jósẹ́fù yóò di ọwọ́ iná,
Ilé Ísọ̀ yóò sì dà bí àgékù pòròpórò;
Wọn yóò ti iná bọ̀ wọ́n, wọn yóò sì run wọ́n,
Ẹnikẹ́ni kì yóò sì là á já ní ilé Ísọ̀,+
Torí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ọ́.
Wọn yóò gba ilẹ̀ Éfúrémù àti ilẹ̀ Samáríà,+
Bẹ́ńjámínì yóò sì gba Gílíádì.
20 Àwọn tó lọ sí ìgbèkùn látinú odi* yìí,+
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ni yóò gba ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì títí dé Sáréfátì.+
Àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù tó lọ sí ìgbèkùn ní Séfárádì ni yóò gba àwọn ìlú tó wà ní Négébù.+
21 Àwọn olùgbàlà yóò sì lọ sórí Òkè Síónì