Jèhófà Kò Ní Fi Nǹkan Falẹ̀
“Bí [ìran náà] bá tilẹ̀ falẹ̀, máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.”—HÁBÁKÚKÙ 2:3.
1. Ìpinnu wo làwọn èèyàn Jèhófà ti ṣe, kí sì ni èyí ti sún wọn láti ṣe?
“IBI ìṣọ́ mi ni èmi yóò dúró sí.” Ìpinnu tí Hábákúkù, wòlíì Ọlọ́run ṣe nìyẹn. (Hábákúkù 2:1) Àwọn èèyàn Jèhófà ní ọ̀rúndún yìí ti ṣe irú ìpinnu kan náà. Látàrí èyí, wọ́n ti fi tìtaratìtara dáhùn sí ìpè tó dún nígbà àpéjọpọ̀ àgbègbè mánigbàgbé táa ṣe ní September 1922, pé: “Ọjọ́ ńlá lọjọ́ yìí o. Ẹ wò ó, Ọba náà ti jẹ! Ẹ̀yin ni agbẹnusọ tí ó jẹ́ aṣojú rẹ̀. Nítorí náà, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.”
2. Nígbà táa dá àwọn ẹni àmì òróró padà sẹ́nu iṣẹ́ pẹrẹu lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, kí ni wọ́n polongo?
2 Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, Jèhófà mú àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró rẹ̀ padà sẹ́nu iṣẹ́ ní pẹrẹu. Gẹ́gẹ́ bíi ti Hábákúkù, olúkúlùkù wọn lè polongo pé: “Ibi ìṣọ́ mi ni èmi yóò dúró sí, èmi yóò sì mú ìdúró mi lórí odi ààbò; èmi yóò sì máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́, láti rí ohun tí yóò sọ nípasẹ̀ mi.” A lo àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù náà fún “ìṣọ́” àti “ẹ̀ṣọ́” léraléra nínú ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀.
“Kì Yóò Pẹ́”
3. Èé ṣe táa fi gbọ́dọ̀ máa báa nìṣó ní ṣíṣọ́nà?
3 Báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń polongo ìkìlọ̀ Ọlọ́run lónìí, wọ́n gbọ́dọ̀ wà lójúfò nígbà gbogbo láti máa kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ àsọparí tí Jésù sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì náà pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí ọ̀gá ilé náà ń bọ̀, yálà nígbà tí alẹ́ ti lẹ́ tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru tàbí ìgbà kíkọ àkùkọ tàbí ní kùtùkùtù òwúrọ̀; kí ó bàa lè jẹ́ pé, nígbà tí ó bá dé lójijì, òun kò ní bá yín lójú oorun. Ṣùgbọ́n ohun tí mo sọ fún yín ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn, Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Máàkù 13:35-37) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Hábákúkù, àti ti Jésù, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà!
4. Báwo ni ipò tiwa lónìí ṣe bá ti Hábákúkù mu ní nǹkan bí ọdún 628 ṣááju Sànmánì Tiwa?
4 Ó ṣeé ṣe kí Hábákúkù ti kọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 628 ṣááju Sànmánì Tiwa, àní kí Bábílónì tó di agbára ayé pàápàá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni wọ́n ti fi polongo pé ìdájọ́ Jèhófà ń bọ̀ wá sórí Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà. Síbẹ̀, wọn ò lè sọ àkókò pàtó tí ìdájọ́ yẹn yóò dé. Ta ló mọ̀ pé ọdún mọ́kànlélógún péré ló kù tí yóò dé, àti pé Bábílónì ni Jèhófà yóò lò láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ? Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lónìí, a kò mọ ‘ọjọ́ àti wákàtí náà’ tí ètò yìí yóò lọ sópin, àmọ́, Jésù kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.”—Mátíù 24: 36, 44.
5. Ní pàtàkì, kí ló fini lọ́kàn balẹ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Hábákúkù orí kejì, ẹsẹ ìkejì àti ìkẹta?
5 Ìdí tó múná dóko wà tí Jèhófà fi fún Hábákúkù ní iṣẹ́ amóríyá yìí pé: “Kọ ìran náà sílẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe kedere sára àwọn wàláà, kí ẹni tí ń kà á sókè lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí ó já geere. Nítorí ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, ó sì ń sáré lọ ní mímí hẹlẹhẹlẹ sí òpin, kì yóò sì purọ́. Bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀, máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.” (Hábákúkù 2:2, 3) Lónìí, ńṣe ni ìwà ibi àti ìwà ipá ń gogò sí i jákèjádò ayé, èyí tó fi hàn pé, a ti wà ní ọ̀gẹ́gẹ́rẹ́ “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà.” (Jóẹ́lì 2:31) Ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Jèhófà sọ yìí mà fini lọ́kàn balẹ̀ o, ó ní “Kì yóò pẹ́”!
6. Báwo la ṣe lè la ọjọ́ ìdájọ́ tí ń bọ̀ já?
6 Nígbà náà, báwo la ṣe lè la ọjọ́ ìdájọ́ tó ń bọ̀ yẹn já? Jèhófà dáhùn ìbéèrè yìí nípa fífi ìyàtọ̀ tó wà láàárín olódodo àti aláìṣòdodo hàn, ó ní: “Wò ó! Ọkàn rẹ̀ ti gbé fùkẹ̀; kò dúró ṣánṣán nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ti olódodo, òun yóò máa wà láàyè nìṣó nípa ìṣòtítọ́ rẹ̀.” (Hábákúkù 2:4) Àwọn alákòóso, àwọn agbéraga, tí wọ́n tún lẹ́mìí ìwọra ti fi ẹ̀jẹ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ tí wọ́n ṣekú pa kó ẹ̀gàn bá ìtàn ènìyàn, pàápàá nínú ogun àgbáyé méjì tó ti jà àti àwọn ogun kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tí ẹ̀jẹ̀ ti ń ṣàn bí ọ̀gbàrá. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà ti fi ìṣòtítọ́ lo ìfaradà. Àwọn ni “orílẹ̀-èdè òdodo tí ń pa ìwà ìṣòtítọ́ mọ́.” Orílẹ̀-èdè yìí àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ìyẹn “àwọn àgùntàn mìíràn” ń tẹ̀ lé ìṣílétí yìí pé: “Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní ìgbà gbogbo, nítorí pé inú Jáà Jèhófà ni Àpáta àkókò tí ó lọ kánrin wà.”—Aísáyà 26:2-4; Jòhánù 10:16.
7. Láti lè tẹ̀ lé bí Pọ́ọ̀lù ṣe lo Hábákúkù orí kejì, ẹsẹ ìkẹrin, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
7 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù, ó fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Hábákúkù orí kejì, ẹsẹ ìkẹrin, tó sọ fáwọn ènìyàn Jèhófà pé: “Ẹ nílò ìfaradà, kí ó lè jẹ́ pé, lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tán, kí ẹ lè rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà. Nítorí ní ‘ìgbà díẹ̀ kíún sí i,’ àti pé ‘ẹni tí ń bọ̀ yóò dé, kì yóò sì pẹ́.’ ‘Ṣùgbọ́n olódodo mi yóò yè nítorí ìgbàgbọ́,’ àti pé, ‘bí ó bá fà sẹ́yìn, ọkàn mi kò ní ìdùnnú nínú rẹ̀.’” (Hébérù 10:36-38) Àkókò táa wà yìí kọ́ ló yẹ ká dẹwọ́ tàbí ká dẹni tó kó sínú ìdẹkùn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì àti fífi torí tọrùn wá fàájì ayé Sátánì. Kí ló yẹ ká ṣe kí “ìgbà díẹ̀ kíún sí i” yẹn tó dópin? Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù, àwa táa jẹ́ orílẹ̀-èdè mímọ́ ti Jèhófà gbọ́dọ̀ máa ‘nàgà sáwọn ohun tí ń bẹ níwájú, ká máa lépa góńgó’ ìyè àìnípẹ̀kun ‘nìṣó.’ (Fílípì 3:13, 14) Gẹ́gẹ́ bí Jésù, a gbọ́dọ̀ ‘fara dà á nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú wa.’—Hébérù 12:2.
8. Ta ní “ọkùnrin” táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Hábákúkù orí kejì, ẹsẹ ìkarùn-ún, èé sì ti ṣe tí kò fi lè rí bátiṣé?
8 Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, Hábákúkù orí kejì, ẹsẹ ìkarùn-ún ṣàpèjúwe “abarapá ọkùnrin” tó kùnà láti lé góńgó rẹ̀ bá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó “mú kí ọkàn rẹ̀ ní àyè gbígbòòrò bí Ṣìọ́ọ̀lù.” Ta lọ́kùnrin tí a ‘kò lè tẹ́ lọ́rùn’ yìí? Pẹ̀lú ìwà ọ̀yánnú bíi ti Bábílónì ti ìgbà ayé Hábákúkù, “ọkùnrin,” tí kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo gíro yìí dúró fún àpapọ̀ agbára òṣèlú—yálà ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀, ti ìjọba Násì, ti Kọ́múníìsì, tàbí èyí tí wọ́n ń pè ní ìjọba tiwa-n-tiwa pàápàá—ti jagun láti lè mú kí ilẹ̀ rẹ̀ gbòòrò sí i. Ọkùnrin yìí tún ti rán àìmọye ẹ̀mí àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ sí Ṣìọ́ọ̀lù, ìyẹn sàréè. Ṣùgbọ́n, “ọkùnrin” tí kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo gíro yìí, tó jẹ́ aládàkàdekè nínú ayé Sátánì, ọkùnrin tí ìgbéraga ti kó sí lórí yìí, kò rí bátiṣé nínú akitiyan rẹ̀ láti ‘kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ, kó sì kó gbogbo ènìyàn jọpọ̀.’ Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè mú gbogbo aráyé ṣọ̀kan, yóò sì ṣe é nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà náà.—Mátíù 6:9, 10.
Àkọ́kọ́ Nínú Àwọn Ègbé Márùn-ún Tó Múni Gbọ̀n Rìrì
9, 10. (a) Kí ni Jèhófà ń bá a lọ láti tipasẹ̀ Hábákúkù kéde? (b) Ní ti ọrọ̀ táa fi èrú kó jọ, kí ló ń ṣẹlẹ̀ lónìí?
9 Nípasẹ̀ Hábákúkù wòlíì rẹ̀, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí kéde ọ̀wọ́ àwọn ègbé márùn-ún, ìdájọ́ tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láti jẹ́ kí ilẹ̀ ayé wà ní sẹpẹ́ fún àwọn olùṣòtítọ́ tí ń jọ́sìn Ọlọ́run. Àwọn ọlọ́kàn títọ́ bẹ́ẹ̀ ‘tẹnu bọ òwe’ tí Jèhófà pa. A kà á nínú Hábákúkù orí kejì ẹsẹ ìkẹfà pé: “Ègbé ni fún ẹni tí ń sọ ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ di púpọ̀—yóò ti pẹ́ tó!—tí ó sì ń mú gbèsè wúwo sí ara rẹ̀ lọ́rùn!”
10 Ohun tí à ń sọ níbí yìí gan-an ni ọrọ̀ táa fi èrú kó jọ. Nínú ayé tó yí wa ká, àwọn ọlọ́rọ̀ túbọ̀ ń lọ́rọ̀ sí i, nígbà táwọn òtòṣì túbọ̀ ń tòṣì. Ibi táwọn oníṣòwò oògùn olóró àti àwọn gbájú-ẹ̀ ti ń kó ọrọ̀ jọ pitimu, ibẹ̀ ni ebi ti fẹ́ máa yọjú àwọn mẹ̀kúnnù jẹ. Ìdámẹ́rin àwọn olùgbé ayé la gbọ́ pé wọ́n jẹ́ òtòṣì paraku. Ńṣe ni ipò nǹkan túbọ̀ ń burú sí i ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Àwọn tó sì jẹ́ pé òdodo làwọ́n ń yán hànhàn fún, wá ń kígbe pé: “Yóò ti pẹ́ tó” tí ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí yóò fi máa di púpọ̀! Ṣùgbọ́n, òpin náà kù sí dẹ̀dẹ̀! Ní tòótọ́, ìran náà “kì yóò pẹ́.”
11. Kí ni Hábákúkù sọ nípa títa ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, èé sì ti ṣe táa fi lè sọ pé ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ lórí ilẹ̀ ayé lónìí?
11 Wòlíì náà sọ fún àwọn olubi pé: “Nítorí tí ìwọ alára fi àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ ṣe ìjẹ, gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ènìyàn yóò fi ọ́ ṣe ìjẹ, nítorí títa ẹ̀jẹ̀ aráyé sílẹ̀ àti ìwà ipá sí ilẹ̀ ayé, ìlú náà àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.” (Hábákúkù 2:8) Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ táa rí nínú ayé lónìí mà ga o! Jésù là á mọ́lẹ̀ ní kedere pé: “Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) Síbẹ̀, ní ọ̀rúndún ogún yìí nìkan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ẹ̀yà tí wọ́n ti jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ti pa àwọn ènìyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù. Ègbé ni fáwọn tó lọ́wọ́ nínú ìpakúpa ọlọ́gbàrá ẹ̀jẹ̀ yìí!
Ègbé Kejì
12. Kí ni ègbé kejì tí Hábákúkù kọ sílẹ̀, báwo ló sì ṣe dá wa lójú pé òfo ní ọrọ̀ táa bá fi èrú kó jọ yóò já sí?
12 Ègbé kejì, tó wà nínú Hábákúkù orí kejì, ẹsẹ ìkẹsàn-án sí ìkọkànlá, dé sórí “ẹni tí ń jèrè ibi fún ilé ara rẹ̀, kí ó bàa lè gbé ìtẹ́ rẹ̀ ka ibi gíga, kí a bàa lè dá a nídè kúrò lọ́wọ́ ìgbámú ohun tí ó kún fún ìyọnu àjálù!” Òfo ni ọrọ̀ táa fi èrú kó jọ máa já sí, onísáàmù náà mú èyí ṣe kedere nígbà tó wí pé: “Má fòyà nítorí pé ẹnì kan ń jèrè ọrọ̀, nítorí pé ògo ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i, nítorí pé nígbà ikú rẹ̀, kò lè mú nǹkan kan dání rárá; ògo rẹ̀ kì yóò bá òun alára sọ̀ kalẹ̀.” (Sáàmù 49:16, 17) Nítorí náà, ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Pọ́ọ̀lù fúnni yìí ṣe pàtàkì, ó ní: “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga, kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.”—1 Tímótì 6:17.
13. Èé ṣe tó fi yẹ ká máa báa nìṣó ní pípolongo ìkìlọ̀ Ọlọ́run?
13 Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká polongo iṣẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run lónìí! Nígbà táwọn Farisí tako báwọn èèyàn ṣe ń kókìkí Jésù gẹ́gẹ́ bí “Ẹni tí ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba ní orúkọ Jèhófà,” ó wí pé: “Mo sọ fún yín, Bí àwọn wọ̀nyí bá dákẹ́, àwọn òkúta yóò ké jáde.” (Lúùkù 19:38-40) Bákan náà, báwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní bá kọ̀ láti táṣìírí ìwà ibi tó ń lọ nínú ayé yìí, ‘òkúta yóò fi ohùn arò ké jáde láti inú ògiri.’ (Hábákúkù 2:11) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa báa nìṣó ní pípolongo ìkìlọ̀ Ọlọ́run!
Ègbé Kẹta àti Ọ̀ràn Ẹ̀bi Ẹ̀jẹ̀
14. Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wo ni àwọn ìsìn ayé jẹ?
14 Ègbé kẹta tó ti ẹnu Hábákúkù jáde jẹ mọ́ ọ̀ràn ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Hábákúkù orí kejì, ẹsẹ ìkejìlá sọ pé: “Ègbé ni fún ẹni tí ń fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ tẹ ìlú ńlá dó, tí ó sì ti fi àìṣòdodo fìdí ìlú múlẹ̀ gbọn-in!” Nínú ètò àwọn nǹkan yìí, àìṣòdodo àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ sábà máa ń rìn pọ̀ ni. Lọ́nà tó gbàfiyèsí, àwọn ẹ̀sìn ayé ló fa ìpakúpa ọlọ́gbàrá ẹ̀jẹ̀, tó burú jù lọ nínú ìtàn. Èyí táa fẹ́ sọ nínú wọn ni Ogun Ẹ̀sìn, èyí tó mú kí àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ wọ̀yá ìjà pẹ̀lú àwọn Mùsùlùmí; Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ tí Kátólíìkì ṣe ní Sípéènì àti Látìn Amẹ́ríkà; Ogun Ọlọ́gbọ̀n Ọdún ní Yúróòpù, èyí tó wáyé láàárín àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì àti àwọn Kátólíìkì, èyí tí ọ̀gbàrá ẹ̀jẹ̀ sì ti ṣàn jù lọ nínú wọn ni ogun àgbáyé méjèèjì tó jà ní ọ̀rúndún tiwa yìí, ilẹ̀ àwọn Kirisẹ́ńdọ̀mù sì ni méjèèjì ti jà.
15. (a) Kí ni àwọn orílẹ̀-èdè ń báa nìṣó láti máa ṣe nítorí ìtìlẹ́yìn àti ìfọwọ́sí ṣọ́ọ̀ṣì? (b) Ǹjẹ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lè fòpin sí kíkó tí ayé ń kó ohun ìjà ogun jọ?
15 Apá tó burú jù lọ nínú Ogun Àgbáyé Kejì ni Ìpakúpa Rẹpẹtẹ tí ìjọba Násì dá sílẹ̀, èyí tí wọ́n fi gbẹ̀mí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Júù àtàwọn mìíràn tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ ní Yúróòpù. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni ẹgbẹ́ alákòóso ẹ̀sìn Kátólíìkì nílẹ̀ Faransé ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ́wọ́ pé, àwọn ò tako rírán tí ìjọba Násì rán ẹgbàágbèje àwọn èèyàn lọ sínú yàrá kótópó tí wọ́n ti ṣekú pa wọ́n. Síbẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè ṣì ń gbára dì láti tàjẹ̀ sílẹ̀, nítorí tí ṣọ́ọ̀ṣì ṣe tán láti tì wọ́n lẹ́yìn tàbí láti fọwọ́ sí ohun tí wọ́n bá ṣe. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ìwé ìròyìn Time, (ẹ̀dà tí à ń pín lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè) sọ láìpẹ́ yìí pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì náà tí a mú sọjí tún ti lo agbára púpọ̀ ní àwọn ọ̀nà kan tí a kò ronú kàn tẹ́lẹ̀: ó ti ń lo agbára lórí ilẹ̀ Rọ́ṣíà nínú ọ̀ràn ogun. . . . Gbígbàdúrà sórí àwọn ọkọ̀ òfuurufú tó wà fún ogun jíjà àti sórí àwọn ibùdó ológun ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di àṣà ìgbà gbogbo. Àní ní November, ní Ilé Àwọn Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Anìkàngbé ti Danilovsky ní Moscow, tó jẹ́ Orílé Iṣẹ́ wọn ní Rọ́ṣíà, ṣọ́ọ̀ṣì náà lọ jìnnà débi pé ó ṣe ìyàsímímọ́ ibi tí ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń kó ohun ìjà runlérùnnà pa mọ́ sí.” Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ha lè fòpin sí kíkó tí ayé yìí ń kó àwọn ohun ìjà abèṣe jọ bí? Wọn ò tó bẹ́ẹ̀! Agbẹ̀bùn Ẹ̀yẹ Àlàáfíà ti Nobel kan sọ nínú ìwé ìròyìn The Guardian ti London, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, pé: “Ohun tí ń kóni láyà sókè gan-an ni pé, àwọn márùn-ún tó jẹ́ òpómúléró nínú mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Aláàbò ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni wọ́n tún jẹ́ orílẹ̀-èdè márùn-ún tó lórúkọ jù lọ nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ṣòwò ohun ìjà ogun lágbàáyé.”
16. Kí ni Jèhófà yóò ṣe fún àwọn orílẹ̀-èdè arógunyọ̀?
16 Ǹjẹ́ Jèhófà yóò mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè arógunyọ̀? Hábákúkù orí kejì, ẹsẹ ìkẹtàlá sọ pé: “Wò ó! Kì í ha ṣe láti ọ̀dọ̀ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni àwọn ènìyàn yóò ti máa ṣe làálàá kìkì fún iná, tí àwùjọ àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kó àárẹ̀ bá ara wọn kìkì fún asán?” “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” ni! Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ní àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun lókè ọ̀run, àwọn ni yóò sì lò láti sọ àwọn ènìyàn àti àwọn orílẹ̀-èdè arógunyọ̀ di asán!
17. Lẹ́yìn ìgbà tí Jèhófà bá mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè oníwà ipá, báwo ni ìmọ̀ rẹ̀ yóò ti kún ayé tó?
17 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Jèhófà bá ti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè oníwà ipá wọ̀nyẹn? Hábákúkù orí kejì, ẹsẹ ìkẹrìnlá fún wa ní ìdáhùn rẹ̀, ó ní: “Ilẹ̀ ayé yóò kún fún mímọ ògo Jèhófà bí omi ti bo òkun.” Ìrètí kíkọyọyọ mà lèyí o! Ní Amágẹ́dọ́nì, a óò dá ipò ọba aláṣẹ Jèhófà láre títí láé. (Ìṣípayá 16:16) Ó mú un dá wa lójú pé, òun yóò ‘ṣe àyè ẹsẹ̀ rẹ̀ gan-an lógo,’ ìyẹn ayé tí à ń gbé yìí. (Aísáyà 60:13) A óò kọ́ gbogbo aráyé ni ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́, títí tí ìmọ̀ wọn nípa àwọn ète ológo tí Jèhófà ní yóò fi kún ilẹ̀ ayé bí ìgbà tí alagbalúgbú omi bo òkun.
Ègbé Kẹrin àti Ìkarùn-Ún
18. Kí ni ègbé kẹrin tí Hábákúkù kéde rẹ̀, báwo ló sì ṣe hàn nínú bí ìwà ayé yìí ti rí lónìí?
18 A lo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti ṣàpèjúwe ègbé kẹrin nínú ìwé Hábákúkù orí kejì, ẹsẹ ìkẹẹ̀ẹ́dógún pé: “Ègbé ni fún ẹni tí ń fún alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní nǹkan mu, ní síso ìhónú àti ìbínú rẹ mọ́ ọn, kí o bàa lè mú kí wọ́n mu àmupara, fún ète wíwo àwọn apá ìtìjú wọn.” Èyí fi hàn bí ìwà ìbàjẹ́ àti ìwàkiwà ti pọ̀ tó nínú ayé òde òní. Ìṣekúṣe tó kún inú ayé, èyí tí àwọn ẹ̀sìn tó gbàgbàkugbà ń gbé lárugẹ, wá ń gogò sí i. Àwọn àjàkálẹ̀ àrùn, irú bí àrùn éèdì àti àwọn àrùn mìíràn tí ìbálòpọ̀ ń tàtaré rẹ̀, ń gbèèràn kárí ayé bí iná ọyẹ́. Dípò kí ìran ènìyàn ẹlẹ́mìí tèmi-làkọ́kọ́ tó wà lóde òní máa gbé “ògo Jèhófà” yọ, ńṣe nìwà wọn túbọ̀ ń burú sí i, ọ̀nà tí wọn fi máa gba ìdájọ́ Ọlọ́run sì ni wọ́n ń forí lé. Láìpẹ́, ayé tó ti ya pòkíì yìí, tí a sì ti fi “àbùkù bọ́ . . . dípò ògo” yóò mu nínú àwokòtò ìhónú Jèhófà, èyí tó dúró fún bó ṣe fẹ́ kó rí fún un. ‘Ojútì yóò dé bá ògo rẹ̀.’—Hábákúkù 2:16.
19. Kí ni ọ̀rọ̀ tó ṣáájú ègbé karùn-ún jẹ mọ́, èé sì ti ṣe tí irú àwọn ọ̀rọ̀ yẹn fi ṣe pàtàkì láyé òde òní?
19 Ọ̀rọ̀ táa sọ ṣáájú kíké ègbé karùn-ún kìlọ̀ gbọnmọgbọnmọ nípa jíjọ́sìn ère gbígbẹ́. Jèhófà ní kí wòlíì náà polongo àwọn gbankọgbì ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Ègbé ni fún ẹni tí ń wí fún igi pé: ‘Jí!’ fún òkúta tí ó yadi pé: ‘Jí! Òun fúnra rẹ̀ yóò fúnni ní ìtọ́ni’! Wò ó! Wúrà àti fàdákà ni a fi bò ó yí ká, kò sì sí èémí kankan rárá ní inú rẹ̀.” (Hábákúkù 2:19) Títí dòní olónìí, Kirisẹ́ńdọ̀mù àti àwọn táa mọ̀ sí kèfèrí ṣì ń forí balẹ̀ fún àgbélébùú, ère Màríà, onírúurú ère, èyí tí wọ́n ṣe ní ìrísí ènìyàn àti ti ẹranko. Kò sí ìkankan nínú àwọn wọ̀nyí tó lè jí láti wá gba àwọn tí ń jọ́sìn wọn là nígbà tí Jèhófà bá dé láti mú ìdájọ́ ṣẹ. Wúrà àti fàdákà tí wọ́n fi bò wọ́n kò já mọ́ nǹkankan rárá báa bá fi wé ọlá ńlá Jèhófà, Ọlọ́run ayérayé, àti ògo àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ alààyè. Ǹjẹ́ ká máa gbé orúkọ rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ ga títí láé!
20. Inú ètò tẹ́ńpìlì wo la ti láǹfààní láti fi tayọ̀tayọ̀ sìn?
20 Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà, Ọlọ́run wa, ni gbogbo ìyìn yẹ. Ẹ jẹ́ kí ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ táa ní fún un sún wa láti kọbi ara sí ìkìlọ̀ gbọnmọgbọnmọ yẹn, pé kí a sá fún ìbọ̀rìṣà. Ṣùgbọ́n, ẹ tẹ́tí sílẹ̀ o! Jèhófà ṣì ń sọ̀rọ̀: “Jèhófà ń bẹ nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀. Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú rẹ̀, gbogbo ilẹ̀ ayé!” (Hábákúkù 2:20) Láìsí àní-àní, tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ni wòlíì náà ní lọ́kàn. Ṣùgbọ́n, lóde òní, a láǹfààní láti máa jọ́sìn nínú ètò tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, èyí tó tóbi ju ti ìṣáájú lọ, níbi táa ti fi Jésù Kristi, Olúwa wa joyè Àlùfáà Àgbà. Níhìn-ín, nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì yẹn tó wà lórí ilẹ̀ ayé, à ń pàdé pọ̀, à ń sin Jèhófà, à ń gbàdúrà sí i, a sì ń bọlá tó yẹ orúkọ rẹ̀ ológo fún un. Ẹ sì wo bí inú wa ti dùn tó láti máa fi tọkàntọkàn jọ́sìn Baba wa onífẹ̀ẹ́, tí ń bẹ lọ́run!
Ṣé O Rántí?
• Ojú wo lo fi ń wo ọ̀rọ̀ Jèhófà tó sọ pé: “Kì yóò pẹ́”?
• Báwo ni àwọn ègbé táa tipasẹ̀ Hábákúkù ké ti ṣe pàtàkì tó lóde òní?
• Èé ṣe tó fi yẹ ká máa báa lọ láti máa kéde ìkìlọ̀ Jèhófà?
• Inú àgbàlá tẹ́ńpìlì wo la ti láǹfààní láti sìn?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Gẹ́gẹ́ bí Hábákúkù, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní mọ̀ pé Jèhófà kò ní fi nǹkan falẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ǹjẹ́ o mọyì àǹfààní tóo ní láti máa jọ́sìn Jèhófà nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì rẹ̀ nípa tẹ̀mí?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]
Fọ́tò U.S. Army