Hábákúkù
Èmi yóò máa ṣọ́nà kí n lè mọ ohun tí yóò sọ nípasẹ̀ mi
Àti ohun tí èmi yóò sọ nígbà tó bá bá mi wí.
2 Jèhófà wá dá mi lóhùn pé:
“Kọ ìran náà sílẹ̀, kí o sì kọ ọ́ sára wàláà,+ kó hàn kedere,
Tó bá tiẹ̀ falẹ̀,* ṣáà máa retí rẹ̀!*+
Torí yóò ṣẹ láìkùnà.
Kò ní pẹ́ rárá!
Àmọ́ ìṣòtítọ́* yóò mú kí olódodo wà láàyè.+
5 Torí pé wáìnì ń tanni jẹ lóòótọ́,
Ọwọ́ ẹni tó jọ ara rẹ̀ lójú kò ní tẹ àfojúsùn rẹ̀.
Ó ń kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ,
Ó sì ń kó gbogbo èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀.+
6 Ṣé kì í ṣe gbogbo wọn ló máa pa òwe, àṣamọ̀ àti àlọ́ láti bá a jà?+
Wọ́n á sọ pé:
‘Ẹni tó ń kó ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ jọ gbé!
Tó sì ń mú kí gbèsè ọrùn rẹ̀ pọ̀ sí i.
Ìgbà wo ló máa ṣe èyí dà?
7 Ǹjẹ́ àwọn tó yá ọ lówó kò ní dìde sí ọ lójijì?
Wọ́n á ta jí, wọ́n á sì fipá mì ọ́ jìgìjìgì,
Wọ́n á sì kó ọ bí ẹrù tí wọ́n kó dé látojú ogun.+
8 Torí ìwọ náà ti kó ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lẹ́rù,
Gbogbo èèyàn yóò kó ọ lẹ́rù,+
Nítorí ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn tí o ta sílẹ̀
Àti ìwà ipá tí o hù sí ayé,
Sí àwọn ìlú àti àwọn tó ń gbé inú wọn.+
9 Ẹni tó ń kó èrè tí kò tọ́ jọ fún ilé rẹ̀ gbé!
Kó lè kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ibi gíga,
Kó má bàa kó sínú àjálù.
10 O ti gbèrò ohun tó kó ìtìjú bá ilé rẹ.
O ṣẹ̀ sí ara* rẹ bí o ṣe pa ọ̀pọ̀ èèyàn run.+
11 Òkúta yóò ké jáde láti inú ògiri,
Igi ìrólé yóò sì dá a lóhùn látorí àjà.
12 Ẹni tó ń fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ kọ́ ìlú gbé,
Àti ẹni tó ń fi àìṣòdodo tẹ ìlú dó!
13 Wò ó! Ṣé kì í ṣe Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló ń mú kí àwọn èèyàn ṣiṣẹ́ kára fún ohun tó ṣì máa jóná,
Tó sì ń mú kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe wàhálà lásán?+
14 Torí gbogbo ayé yóò ní ìmọ̀ nípa ògo Jèhófà
Bí ìgbà tí omi bo òkun.+
15 Ẹni tó ń fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní nǹkan mu gbé!
Tó ń fi ìbínú àti ìkanra ṣe é, kó lè mú kí wọ́n yó,
Kó lè wo ìhòòhò wọn!
16 Àbùkù ni wọn yóò fi kàn ọ́ dípò ògo.
Ìwọ náà mu ún, kí o sì ṣí adọ̀dọ́ rẹ tí wọn ò dá sí gbangba.*
Ife ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà yóò dé ọ̀dọ̀ rẹ,+
Ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ mọ́lẹ̀;
17 Torí ìwà ipá tí o hù sí Lẹ́bánónì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀,
Ìparun tó dẹ́rù ba àwọn ẹranko yóò dé bá ọ,
Nítorí ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn tí o ta sílẹ̀
Àti ìwà ipá tí o hù sí ayé,
Sí àwọn ìlú àti àwọn tó ń gbé inú wọn.+
18 Kí ni àǹfààní ère,
Nígbà tó jẹ́ pé èèyàn ló gbẹ́ ẹ?
Kí ni àǹfààní ère onírin* àti olùkọ́ èké,
Tí ẹni tó ṣe é bá tiẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e,
Tó ṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí, tí kò lè sọ̀rọ̀?+
19 O gbé, ìwọ tí ò ń sọ fún igi pé: “Dìde!”
Tàbí fún òkúta tí kò lè sọ̀rọ̀ pé: “Gbéra nílẹ̀! Máa kọ́ wa!”
20 Àmọ́ Jèhófà wà nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀.+
Gbogbo ayé, ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú rẹ̀!’”+