Àwọn Ènìyàn Jèhófà Tí a Mú Bọ̀ Sípò Ń yìn Ín Jákèjádò Ayé
“Èmi yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́ gaara, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà.”—SEFANÁYÀ 3:9.
1. Èé ṣe tí àwọn iṣẹ́ ìparun táa kéde fi ṣẹ sí Júdà àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lára?
IṢẸ́ ìdájọ́ tí Jèhófà mí sí Sefanáyà láti jẹ́ yìí le kú o! Àwọn ọ̀rọ̀ ègbé yẹn ṣẹ sí orílẹ̀-èdè Júdà àti Jerúsálẹ́mù olú ìlú rẹ̀ lára, nítorí pé àwọn aṣáájú àti àwọn èèyàn ibẹ̀ lápapọ̀ kò ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí wọn, bíi Filísíà, Móábù, àti Ámónì pẹ̀lú yóò rí ìbínú Ọlọ́run. Èwo wá ni tiwọn ńbẹ̀? Nítorí ìwà òǹrorò tí wọ́n ti hù sáwọn èèyàn Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni. Ìdí yẹn kan náà ni yóò mú kí ìparun dé bá agbára ayé Ásíríà, kò sì ní gbérí mọ́ láé.
2. Àwọn wo ló dájú pé ọ̀rọ̀ inú Sefanáyà 3:8 ń bá wí?
2 Ṣùgbọ́n o, àwọn kan wà ní Júdà nígbà yẹn lọ́hùn-ún tí wọ́n ní ọkàn rere. Àwọn wọ̀nyí ń retí ìmúṣẹ ìdájọ́ Ọlọ́run lórí àwọn èèyàn burúkú, ó sì dájú pé àwọn ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ń bá wí, èyí tó sọ pé: “‘Ẹ máa wà ní ìfojúsọ́nà fún mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘títí di ọjọ́ tí èmi yóò dìde sí ẹrù àkótogunbọ̀, nítorí ìpinnu ìdájọ́ mi ni láti kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ, kí n kó àwọn ìjọba jọpọ̀, kí n lè da ìdálẹ́bi tí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá jáde sórí wọn, gbogbo ìbínú jíjófòfò mi; nítorí nípa iná ìtara mi, gbogbo ilẹ̀ ayé ni a ó jẹ run.’”—Sefanáyà 3:8.
“Èdè Mímọ́ Gaara” fún Àwọn Wo?
3. Iṣẹ́ ìrètí wo ni a mí sí Sefanáyà láti jẹ́?
3 Bẹ́ẹ̀ ni, Sefanáyà jíṣẹ́ ìparun tí Jèhófà rán an. Ṣùgbọ́n a tún mí sí wòlíì náà pé kí ó fi iṣẹ́ ìrètí àgbàyanu kan kún un—èyí tí yóò jẹ́ ìtùnú ńlá fáwọn tí ń pa ìṣòtítọ́ mọ́ sí Jèhófà. Gẹ́gẹ́ bí Sefanáyà 3:9 ti kà, Jèhófà Ọlọ́run sọ pé: “Nígbà náà ni èmi yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́ gaara, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà, kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.”
4, 5. (a) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sáwọn aláìṣòdodo? (b) Àwọn wo ni yóò jàǹfààní nínú èyí, èé sì ti ṣe?
4 Àmọ́, àwọn èèyàn kan wà tí a kò ní fún ní èdè mímọ́ gaara náà. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ nípa wọn pé: “Èmi yóò mú àwọn tìrẹ tí ń fi ìrera yọ ayọ̀ ńláǹlà kúrò ní àárín rẹ.” (Sefanáyà 3:11) Nítorí náà, àwọn onírera tí wọ́n ń pẹ̀gàn àwọn òfin Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe àìṣòdodo ni a óò mú kúrò. Àwọn wo ni yóò sì jàǹfààní nínú èyí? Sefanáyà 3:12, 13 kà pé: “Dájúdájú, èmi [Jèhófà] yóò sì jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni rírẹlẹ̀ ṣẹ́ kù sí àárín rẹ, wọn yóò sì sá di orúkọ Jèhófà ní ti tòótọ́. Ní ti àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì, wọn kì yóò ṣe àìṣòdodo, tàbí kí wọ́n pa irọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àgálámàṣà ní ẹnu wọn; nítorí àwọn fúnra wọn yóò jẹun, wọn yóò sì nà gbalaja ní ti tòótọ́, kò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”
5 Àwọn olùṣòtítọ́ tó ṣẹ́ kù ní Júdà ìgbàanì yóò jàǹfààní. Èé ṣe? Nítorí pé wọ́n ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, pé: “Ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé, tí ń fi ìpinnu ìdájọ́ Tirẹ̀ ṣe ìwà hù. Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù. Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.”—Sefanáyà 2:3.
6. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà kọ́kọ́ nímùúṣẹ?
6 Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà kọ́kọ́ nímùúṣẹ, Ọlọ́run fìyà jẹ Júdà aláìnígbàgbọ́ nípa jíjẹ́ kí Bábílónì, tó jẹ́ Agbára Ayé nígbà yẹn, ṣẹ́gun rẹ̀, kí ó sì kó àwọn èèyàn rẹ̀ nígbèkùn lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Wọ́n fi àwọn kan, bíi wòlíì Jeremáyà, sílẹ̀, àwọn yòókù sì ń bá ìṣòtítọ́ wọn sí Jèhófà nìṣó ní ìgbèkùn tí wọ́n wà. Lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn ará Mídíà àti Páṣíà, lábẹ́ Kírúsì Ọba, gbàjọba lọ́wọ́ Bábílónì. Ní nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn náà, Kírúsì pàṣẹ pé kí àwọn Júù tó ṣẹ́ kù padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Láìpẹ́, wọ́n tún tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù kọ́, ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sì tún padà sẹ́nu iṣẹ́ wọn láti máa fi Òfin kọ́ àwọn èèyàn náà. (Málákì 2:7) Nítorí náà, Jèhófà mú kí àwọn àṣẹ́kù tó padà wálé láásìkí—ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ṣe olóòótọ́.
7, 8. Àwọn wo ni ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà 3:14-17 ń bá wí, èé sì ti ṣe tí o fi dáhùn bẹ́ẹ̀?
7 Sefanáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn tí yóò gbádùn ìmúbọ̀sípò yẹn pé: “Fi ìdùnnú ké jáde, ìwọ ọmọbìnrin Síónì! Bú jáde nínú ìmóríyá gágá, ìwọ Ísírẹ́lì! Máa yọ̀, kí o sì fi gbogbo ọkàn-àyà yọ ayọ̀ ńláǹlà, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù! Jèhófà ti mú ìdájọ́ wọnnì kúrò lórí rẹ. Ó ti lé ọ̀tá rẹ padà. Ọba Ísírẹ́lì, Jèhófà, wà ní àárín rẹ. Ìwọ kì yóò tún bẹ̀rù ìyọnu àjálù mọ́. Ní ọjọ́ yẹn, a óò wí fún Jerúsálẹ́mù pé: ‘Má fòyà, ìwọ Síónì. Kí ọwọ́ rẹ má rọ jọwọrọ. Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà ní àárín rẹ. Bí Ẹni tí ó ní agbára ńlá, òun yóò gbà là. Òun yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí rẹ pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀. Òun yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́ nínú ìfẹ́ rẹ̀. Òun yóò kún fún ìdùnnú pẹ̀lú igbe ayọ̀ lórí rẹ.’”—Sefanáyà 3:14-17.
8 Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí tọ́ka sí àwọn àṣẹ́kù tó jáde wá látinú ìgbèkùn Bábílónì, tí a sì mú padà wá sí ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Sefanáyà 3:18-20 fi èyí hàn, ó sọ pé: “‘Àwọn tí ẹ̀dùn ọkàn kọlù nítorí àìsí níbẹ̀ ní àkókò àjọyọ̀ rẹ ni èmi [Jèhófà] yóò kó jọpọ̀ dájúdájú; ó ṣẹlẹ̀ pé wọn kò sí lọ́dọ̀ rẹ, nítorí ríru ẹ̀gàn ní tìtorí rẹ̀. Kíyè sí i, èmi yóò gbé ìgbésẹ̀ láti dojú ìjà kọ gbogbo àwọn tí ń ṣẹ́ ọ níṣẹ̀ẹ́, ní àkókò yẹn; èmi yóò sì gba ẹni tí ń tiro là, èmi yóò sì kó ẹni tí a fọ́n ká jọpọ̀. Dájúdájú, èmi yóò sì gbé wọn kalẹ̀ bí ìyìn àti bí orúkọ ní gbogbo ilẹ̀ ìtìjú wọn. Ní àkókò yẹn, èmi yóò mú yín wọlé, àní ní àkókò tí èmi yóò kó yín jọpọ̀. Nítorí tí èmi yóò ṣe yín ní orúkọ àti ìyìn láàárín gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé, nígbà tí mo bá kó àwọn òǹdè yín jọ padà ní ojú yín,’ ni Jèhófà wí.”
9. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣorúkọ fún ara rẹ̀ nínú ọ̀ràn Júdà?
9 Fojú inú wo bí ẹnu yóò ṣe ya àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká tó, ìyẹn àwọn tó jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run! Bábílónì alágbára ti kó àwọn olùgbé Júdà nígbèkùn, kò sì sí ìrètí pé wọ́n á gbòmìnira láé. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ilẹ̀ wọn tún ti dahoro. Ṣùgbọ́n lágbára Ọlọ́run, a mú wọn padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn lẹ́yìn àádọ́rin ọdún, àmọ́ ìparun dé bá àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá. Ẹ wo orúkọ ńlá tí Jèhófà ṣe fún ara rẹ̀, nípa mímú kí àṣẹ́kù tó jẹ́ olóòótọ́ wọ̀nyẹn padà wálé! Ó mú kí wọ́n jẹ́ “orúkọ àti ìyìn láàárín gbogbo àwọn ènìyàn.” Ìyìn ńláǹlà mà lèyí jẹ́ fún Jèhófà àtàwọn tí ń jẹ́ orúkọ rẹ̀ o!
A Gbé Ìjọsìn Jèhófà Ga
10, 11. Nígbà wo ni lájorí ìmúbọ̀sípò tí Sefanáyà sọ tẹ́lẹ̀ yóò nímùúṣẹ, báwo la sì ṣe mọ èyí?
10 Ìmúbọ̀sípò mìíràn ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, nígbà tí Jésù Kristi kó àṣẹ́kù Ísírẹ́lì jọ sínú ìjọsìn tòótọ́. Ìyẹn jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, nítorí pé lájorí ìmúṣẹ ìmúbọ̀sípò náà yóò jẹ́ lọ́jọ́ iwájú. Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ síbẹ̀.”—Míkà 4:1.
11 Ìgbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ti wí, yóò jẹ́ “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́”—bẹ́ẹ̀ ni, ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí. (2 Tímótì 3:1) Èyí yóò ṣẹlẹ̀ kí ètò àwọn nǹkan yìí tó dé òpin, nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè ṣì ń sin àwọn ọlọ́run èké. Míkà 4:5 sọ pé: “Gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀.” Àwọn tí ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ wá ńkọ́ o? Àsọtẹ́lẹ̀ Míkà dáhùn pé: “Ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”
12. Báwo la ṣe gbé ìjọsìn tòótọ́ lékè lọ́jọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí?
12 Nítorí náà, lọ́jọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, “òkè ńlá ilé Jèhófà [ti] di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá.” Ìjọsìn tòótọ́ gíga lọ́lá fún Jèhófà ti padà bọ̀ sípò, ó ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ó sì ti lékè gbogbo ẹ̀sìn yòókù pátá. Gẹ́gẹ́ bí Míkà tún ṣe sọ, “àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ síbẹ̀.” Àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ yóò sì “máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run [wọn] fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”
13, 14. Ìgbà wo ni ayé yìí wọ “apá ìkẹyìn àwọn ọjọ́,” kí ló sì ti ń ṣẹlẹ̀ sí ìjọsìn tòótọ́ látìgbà yẹn?
13 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ fi hàn pé ayé yìí ti wọ “apá ìkẹyìn àwọn ọjọ́,”—ìyẹn, àwọn ọjọ́ ìkẹyìn rẹ̀—ní ọdún 1914. (Máàkù 13:4-10) Ìtàn fi hàn pé ìgbà yẹn ni Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn olóòótọ́ àṣẹ́kù ẹni àmì òróró, tí ìrètí wọ́n jẹ́ ti ọ̀run, jọ sínú ìjọsìn tòótọ́. Ẹ̀yìn ìyẹn ló kan kíkó “ogunlọ́gọ̀ ńlá” jọ láti inú “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n,”—ìyẹn, àwọn tí ìrètí wọ́n jẹ́ láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 7:9.
14 Látìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní títí dòní, ìjọsìn tí àwọn tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà ń fún un, ń tẹ̀ síwájú gan-an lábẹ́ ìdarí rẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ̀rún mélòó kan làwọn olùjọsìn Jèhófà jẹ́ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, àmọ́ nísinsìnyí wọ́n ti tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà, wọ́n sì ń pé jọ pọ̀ nínú nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kànléláàádọ́rùn-ún [91,000] ìjọ ní igba ó lé márùnlélọ́gbọ̀n [235] ilẹ̀. Ọdọọdún làwọn olùpòkìkí Ìjọba náà ń fi iye wákàtí tó lé ní bílíọ̀nù kan yin Jèhófà ní gbangba. Ó ṣe kedere pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí ló ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ, pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.
15. Báwo ni Sefanáyà 2:3 ṣe ń nímùúṣẹ nísinsìnyí?
15 Sefanáyà 3:17 sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà ní àárín rẹ. Bí Ẹni tí ó ní agbára ńlá, òun yóò gbà là.” Aásìkí tẹ̀mí táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń ní lọ́jọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí jẹ́ nítorí pé ó ‘wà ní àárín wọn’ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run wọn alágbára gbogbo. Bó ṣe rí nígbà ìmúbọ̀sípò Júdà ìgbàanì, lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, bẹ́ẹ̀ náà ló rí lónìí. Nípa báyìí, a lè rí bí Sefanáyà 2:3 ṣe ní ìmúṣẹ pàtàkì ní àkókò wa nígbà tó sọ pé: “Ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé.” Lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn àṣẹ́kù Júù tó padà dé láti ìgbèkùn Bábílónì wà lára àwọn tí a lo ọ̀rọ̀ náà “gbogbo” fún. Àmọ́ ní báyìí o, a lò ó fáwọn ọlọ́kàn tútù gbogbo orílẹ̀-èdè jákèjádò ilẹ̀ ayé, àwọn tó fi ọkàn rere gbọ́ ìwàásù Ìjọba náà jákèjádò ayé, tí wọ́n sì ń wọ́ tìrítìrí lọ sí “òkè ńlá ilé Jèhófà.”
Ìjọsìn Tòótọ́ Ń Gbèrú
16. Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ìhùwàpadà àwọn ọ̀tá wa sí aásìkí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní?
16 Lẹ́yìn ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, ẹnu ya ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyìíká nígbà tí wọ́n rí bí a ṣe mú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run padà bọ̀ sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn àti sínú ìjọsìn tòótọ́. Àmọ́ ní ìfiwéra, ìmúbọ̀sípò yẹn ò tó nǹkan. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tó ṣeé ṣe kí àwọn kan—àgàgà àwọn tó jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run, máa sọ nísinsìnyí tí wọ́n ń rí ìdàgbàsókè pípabanbarì, aásìkí, àti ìtẹ̀síwájú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní? Àfàìmọ̀ ni àwọn kan lára ọ̀tá wọ̀nyí kò ní máa ronú bí àwọn Farisí ṣe ronú nígbà tí wọ́n rí i bí àwọn èèyàn ṣe ń wọ́ tọ Jésù. Wọ́n kígbe pé: “Wò ó! Ayé ti wọ́ tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”—Jòhánù 12:19.
17. Kí ni òǹkọ̀wé kan sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìbísí wo ni wọ́n sì ti ní?
17 Nínú ìwé náà, These Also Believe, tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Charles S. Braden kọ, ó sọ pé: ‘Ní ti gidi, iṣẹ́ ìjẹ́rìí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kárí ilẹ̀ ayé. A lè sọ ní tòótọ́ pé kò tíì sí ẹ̀sìn èyíkéyìí láyé yìí tó tíì fi ìtara hàn tàbí tó tíì tẹra mọ́ iṣẹ́ sísọ ìhìn rere Ìjọba náà fáwọn èèyàn bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò sì sí àní-àní pé ńṣe ni ìgbòkègbodò yìí yóò máa gbèrú sí i.’ Òdodo ọ̀rọ̀! Nígbà tó kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn, ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] péré ni iye àwa Ẹlẹ́rìí tí ń wàásù kárí ayé. Kí ló máa wá sọ lónìí, tí iye àwa tí ń wàásù ìhìn rere ti tó ìlọ́po ogún iye ìyẹn—táa jẹ́ nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà?
18. Kí ni èdè mímọ́ gaara náà, àwọn wo sì ni Ọlọ́run fi èdè náà fún?
18 Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ ṣèlérí pé: “Èmi yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́ gaara, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà, kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” (Sefanáyà 3:9) Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ké pe orúkọ Jèhófà, àwọn ló ń sìn ín ní ìṣọ̀kan nínú ìdè ìfẹ́ tí kò ṣeé já, àní “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” Àwọn ni Jèhófà fún ní èdè mímọ́ gaara. Èdè mímọ́ gaara yìí kan níní òye kíkún ti òtítọ́ nípa Ọlọ́run àtàwọn ète rẹ̀. Jèhófà nìkan ló lè fúnni ní òye yìí nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 2:10) Àwọn wo ni Jèhófà ń fún ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀? Kìkì “àwọn tí ń ṣègbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso” ló ń fún. (Ìṣe 5:32) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló ṣe tán láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Olùṣàkóso nínú ohun gbogbo. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn ni Ọlọ́run fún ní ẹ̀mí rẹ̀ àti sísọ èdè mímọ́ gaara, sísọ òtítọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ète àgbàyanu rẹ̀. Wọ́n sì ń fi èdè mímọ́ gaara yìí yin Jèhófà lógo jákèjádò ayé lọ́nà tí ń gbilẹ̀ sí i.
19. Kí ni sísọ èdè mímọ́ gaara wé mọ́?
19 Sísọ èdè mímọ́ gaara náà kì í ṣe kìkì wíwulẹ̀ gba òtítọ́ gbọ́, ká sì máa fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn, àmọ́ ó tún kan mímú ìwà ẹni bá àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run mu. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti mú ipò iwájú nínú wíwá Jèhófà àti sísọ èdè mímọ́ gaara náà. Sì wo ohun tí wọ́n ti gbé ṣe! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn ẹni àmì òróró kò tó ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [8,700] mọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn mìíràn, tó ń fara wé ìgbàgbọ́ wọn, tí wọ́n ń wá Jèhófà, tí wọ́n sì ń sọ èdè mímọ́ gaara náà. Àwọn wọ̀nyí ni ogunlọ́gọ̀ ńlá tí iye wọn ń pọ̀ sí i láti orílẹ̀-èdè gbogbo, tí wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí Ọlọ́run tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé, tí wọn yóò sì la “ìpọ́njú ńlá” tí yóò dé láìpẹ́ sórí ayé aláìṣòótọ́ yìí já.—Ìṣípayá 7:9, 14, 15.
20. Kí ní ń bẹ níwájú fún àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró àti fún àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá?
20 A óò mú ogunlọ́gọ̀ ńlá náà wọ ayé tuntun òdodo Ọlọ́run. (2 Pétérù 3:13) Jésù Kristi àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ẹni àmì òróró tí a ti jí dìde sí ìyè ti ọ̀run láti lọ sìn gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà pẹ̀lú rẹ̀ ni yóò para pọ̀ di ẹgbẹ́ tuntun tó ń ṣàkóso ayé. (Róòmù 8:16, 17; Ìṣípayá 7:4; 20:6) Àwọn tó bá la ìpọ́njú ńlá já yóò wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sísọ ilẹ̀ ayé di párádísè, wọn yóò sì máa bá a nìṣó ní sísọ èdè mímọ́ gaara tí Ọlọ́run fi fún wọn. Títí dé àyè kan, ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé lò fún wọn, pé: “Gbogbo ọmọ rẹ yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀ yanturu. A ó fìdí rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú òdodo.”—Aísáyà 54:13, 14.
Iṣẹ́ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Tó Ga Jù Lọ Nínú Ìtàn
21, 22. (a) Gẹ́gẹ́ bí Ìṣe 24:15 ti fi hàn, àwọn wo la óò tún kọ́ ní èdè mímọ́ gaara? (b) Iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ aláìlẹ́gbẹ́ wo ni a ó ṣe lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba náà?
21 Àwùjọ ńlá kan tí a óò fún láǹfààní láti kọ́ èdè mímọ́ gaara nínú ayé tuntun ni àwọn táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ìwé Ìṣe 24:15, tó kà pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” Láyé àtijọ́, ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù èèyàn ló gbé ayé, tí wọ́n sì kú láìní ìmọ̀ pípé nípa Jèhófà. Létòlétò ni òun yóò mú wọn padà wá sí ìyè. A ó sì kọ́ àwọn táa bá jí dìde wọ̀nyí ní èdè mímọ́ gaara.
22 Àǹfààní ńláǹlà ni yóò mà jẹ́ o, láti kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ gígadabú yẹn! Yóò jẹ́ iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó ga jù lọ nínú ìtàn aráyé. A ó ṣe gbogbo rẹ̀ láṣepé nígbà tí Kristi Jésù bá ń ṣàkóso nínú agbára Ìjọba náà. Àbájáde rẹ̀ ni pé, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, aráyé yóò rí ìmúṣẹ Aísáyà 11:9, tó sọ pé: “Ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”
23. Èé ṣe tóo fi lè sọ pé àǹfààní ńláǹlà làwa èèyàn Jèhófà ní?
23 Àǹfààní ńláǹlà la mà ní láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí o, láti máa múra sílẹ̀ de àkókò àgbàyanu yẹn nígbà tí ìmọ̀ Jèhófà yóò kún ilẹ̀ ayé lóòótọ́! Ẹ sì tún wo àǹfààní ńlá táa ní nísinsìnyí láti jẹ́ èèyàn Ọlọ́run, àwọn tí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sefanáyà 3:20 ń ṣẹ sí lára! Jèhófà mú un dá wa lójú níbẹ̀ pé: “Èmi yóò ṣe yín ní orúkọ àti ìyìn láàárín gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé.”
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Kí ni àwọn ìmúṣẹ tí àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà nípa ìmúbọ̀sípò ti ní?
• Báwo ni ìjọsìn tòótọ́ ṣe ń láásìkí ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?
• Iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ńlá wo ni yóò wáyé nínú ayé tuntun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn èèyàn Jèhófà padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn láti lọ fìdí ìjọsìn mímọ́ múlẹ̀ padà. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí èyí túmọ̀ sí lóde òní?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Nípa sísọ “èdè mímọ́ gaara” náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú Bíbélì fáwọn èèyàn