Sefanáyà
3 Ìlú tó ń ṣọ̀tẹ̀ gbé! Ó ti di ẹlẹ́gbin, ó sì ń ni àwọn èèyàn rẹ̀ lára.+
2 Kò ṣègbọràn;+ kò gba ìbáwí.+
Kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà;+ kò sì sún mọ́ Ọlọ́run rẹ̀.+
3 Àwọn olórí tó wà nínú rẹ̀ jẹ́ kìnnìún tó ń ké ramúramù.+
Àwọn onídàájọ́ rẹ̀ jẹ́ ìkookò ní alẹ́;
Wọn kì í jẹ egungun kankan kù di òwúrọ̀.
4 Aláfojúdi ni àwọn wòlíì rẹ̀, oníbékebèke ni wọ́n.+
5 Jèhófà jẹ́ olódodo ní àárín rẹ̀;+ kò ní ṣe àìtọ́.
Àràárọ̀ ló ń jẹ́ ká mọ ìdájọ́ rẹ̀,+
Kì í yẹ̀ bí ojúmọ́ kì í ti í yẹ̀.
Ṣùgbọ́n àwọn aláìṣòdodo kò ní ìtìjú.+
6 “Mo pa àwọn orílẹ̀-èdè run; àwọn ilé gogoro tó wà ní àwọn ìkángun odi wọn ti di ahoro.
Mo pa àwọn ojú ọ̀nà wọn run, tí kò fi sí ẹni tó ń gbà á kọjá.
Àwọn ìlú wọn ti di àwókù tí kò sí ẹnì kankan níbẹ̀, tí kò sì ní olùgbé kankan.+
7 Mo sọ pé, ‘Dájúdájú, wàá bẹ̀rù mi, wàá sì gba ìbáwí,’*+
Kí ibùgbé rẹ̀ má bàa pa run+
Màá pè é wá jíhìn* nítorí gbogbo nǹkan yìí.
Síbẹ̀, ara túbọ̀ ń yá wọn láti hùwàkiwà.+
8 ‘Nítorí náà, ẹ máa retí mi,’*+ ni Jèhófà wí,
‘Títí di ọjọ́ tí màá wá gba* ohun tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn,
Nítorí ìdájọ́ mi ni láti kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ, kí n sì kó àwọn ìjọba jọ,
Kí n lè da ìrunú mi sórí wọn, gbogbo ìbínú mi tó ń jó fòfò;+
Torí ìtara mi tó ń jó bí iná máa jó gbogbo ayé run.+
9 Nígbà náà, màá yí èdè àwọn èèyàn pa dà sí èdè mímọ́,
Kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà,
10 Láti agbègbè àwọn odò tó wà ní Etiópíà,
Ni àwọn tó ń pàrọwà sí mi, ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi tí wọ́n tú ká, ti máa mú ẹ̀bùn wá fún mi.+
11 Ní ọjọ́ yẹn, ojú ò ní tì ọ́
Nítorí gbogbo ohun tí o ṣe láti fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi,+
Torí nígbà náà, màá mú àwọn agbéraga tó ń fọ́nnu kúrò láàárín rẹ;
O ò sì ní gbéra ga mọ́ ní òkè mímọ́ mi.+
13 Àwọn tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì+ kò ní hùwà àìṣòdodo;+
Wọn kò ní parọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní fi ahọ́n wọn tanni jẹ;
Wọ́n á jẹun,* wọ́n á sì dùbúlẹ̀, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”+
14 Kígbe ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Síónì!
Kígbe ìṣẹ́gun, ìwọ Ísírẹ́lì!+
Máa yọ̀, sì jẹ́ kí ayọ̀ kún inú ọkàn rẹ, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù!+
15 Jèhófà ti mú àwọn ìdájọ́ kúrò lórí rẹ.+
Ó ti lé ọ̀tá rẹ dà nù.+
Ọba Ísírẹ́lì, Jèhófà, wà ní àárín rẹ.+
Ìwọ kò ní bẹ̀rù àjálù mọ́.+
16 Ní ọjọ́ yẹn, a ó sọ fún Jerúsálẹ́mù pé:
“Má bẹ̀rù, ìwọ Síónì.+
Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ domi.*
17 Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà ní àárín rẹ.+
Ó máa gbani là bí Alágbára ńlá.
Ó máa yọ̀ gidigidi nítorí rẹ.+
Á dákẹ́ jẹ́ẹ́* nínú ìfẹ́ rẹ̀.
Á dunnú nítorí rẹ pẹ̀lú igbe ayọ̀.
18 Àwọn tí ẹ̀dùn ọkàn bá torí pé wọn ò wá sí àwọn àjọyọ̀ rẹ ni màá kó jọ;+
Wọn ò sí lọ́dọ̀ rẹ torí pé wọ́n wà ní ìgbèkùn, níbi tí wọ́n ti ń kẹ́gàn wọn.+
19 Wò ó! Ní àkókò yẹn, màá dojú ìjà kọ gbogbo àwọn tó ń pọ́n ọ lójú;+
Màá gba ẹni tó ń tiro là,+
Màá sì kó àwọn tó ti fọ́n ká jọ.+
Màá sọ wọ́n di ẹni iyì àti olókìkí*
Ní gbogbo ilẹ̀ tí ìtìjú ti bá wọn.
20 Ní àkókò yẹn, màá mú yín wọlé,
Ní àkókò tí mo kó yín jọ.