Ògo Tí Ó Pọ̀ Ju Ti Ìṣáájú Lọ Tí Ilé Jèhófà Ní
“Èmi óò sì fi ògo kún ilé yìí, ni [Jèhófà, NW] àwọn ọmọ ogun wí.”—HÁGÁÌ 2:7.
1. Kí ni ìsopọ̀ tí ó wà láàárín ẹ̀mí mímọ́, ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́?
NÍGBÀ tí ó ń wàásù láti ilé dé ilé, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé obìnrin kan tí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Pentecostal, ẹni tí ó wí pé, ‘Àwa ni a ní ẹ̀mí mímọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ẹ ń ṣe iṣẹ́ náà.’ Lọ́nà ọgbọ́n, ó ṣàlàyé fún un pé, bí ẹnì kan bá ní ẹ̀mí mímọ́, kò sí àní-àní pé, a óò sún un láti ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. Jákọ́bù 2:17 sọ pé: “Ìgbàgbọ́, bí kò bá ní àwọn iṣẹ́, jẹ́ òkú nínú ara rẹ̀.” Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Jèhófà, Àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ti mú ìgbàgbọ́ lílágbára dàgbà, ó sì ti fi ‘ògo kún ilé rẹ̀’ nípa gbígbé wọn kalẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ òdodo—ní pàtàkì ‘wíwàásù ìhìn rere Ìjọba ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.’ Nígbà tí a bá ṣe iṣẹ́ yìí dé ibi tí ó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn, “nígbà náà ni òpin yóò . . . dé.”—Mátíù 24:14.
2. (a) Ìbùkún wo ni ríri ara wa bọ inú iṣẹ́ Jèhófà yóò mú wá? (b) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a láyọ̀ fún ‘pípẹ́’ èyíkéyìí tí ó bá dà bíi pé ‘ó pẹ́?’
2 Láti inú àwọn ọ̀rọ̀ Jésù wọ̀nyí, a rí i pé iṣẹ́ wa lónìí gbọ́dọ̀ darí àfiyèsí sí wíwàásù “ìhìn rere ológo ti Ọlọ́run aláyọ̀,” tí a gbé lé wa lọ́wọ́, fún àwọn ẹlòmíràn. (Tímótì Kíní 1:11) Bí a bá ṣe ń ri ara wa bọnú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tó, bẹ́ẹ̀ náà ni a óò ṣe máa rí i pé òpin náà ń yára sún mọ́lé tó. Nínú Hábákúkù 2:2, 3, a ka àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà pé: “Kọ ìran náà, kí o sì hàn án lára wàláà, kí ẹni tí ń kà á, lè máà sáré. Nítorí ìran náà jẹ́ ti ìgbà kan tí a yàn, yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn, kí yóò sì ṣèké, bí ó tilẹ̀ pẹ́, dúró dè é, nítorí ní dídé, yóò dé, kì yóò pẹ́.” Bẹ́ẹ̀ ni, “ìran náà” yóò ní ìmúṣẹ “bí ó tilẹ̀ pẹ́.” Níwọ̀n bí a ti wà ní ọdún kẹtàlélọ́gọ́rin tí Ìjọba Jésù ti ń ṣàkóso, àwọn kan lè rò pé àkókò ti ń pẹ́ jù nísinsìnyí. Ṣùgbọ́n, kò ha yẹ kí a láyọ̀ pé, òpin náà kò tí ì dé síbẹ̀? Ní àwọn ẹ̀wádún ti àwọn ọdún 1990 yìí, a tì gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí ìfòfinde wíwàásù ìhìn rere náà, ń ṣe ni ó dà bí iṣẹ́ ìyanu, ní Ìlà Oòrùn Europe, ní àwọn apá ibì kan ní Áfíríkà, àti ní àwọn ilẹ̀ míràn. ‘Pípẹ́’ tí ó dà bí ẹni pẹ́ náà ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti kó ọ̀pọ̀ “àwọn àgùntàn” jọ láti inú àwọn àgbègbè ìpínlẹ̀ wọ̀nyí, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí sílẹ̀.—Jòhánù 10:16.
3. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí ìmọ̀ wa lọ́ọ́lọ́ọ́ lórí “ìran yìí” ru wá sókè láti ṣiṣẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú ìjẹ́kánjúkánjú?
3 Wòlíì náà sọ pé: “Kì yóò pẹ́.” Jésù wí pé ìran burúkú ti ìsinsìnyí kì yóò kọjá lọ títí “gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀.” (Mátíù 24:34) Ìmọ̀ tí a ní ní lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ha túmọ̀ sí pé ìgbòkègbodò wa kò jẹ́ kánjúkánjú mọ́ bí?a Òkodoro òtítọ́ fi hàn pé òdì kejì pátápátá ni ọ̀ràn náà! Ìran wa ti ìsinsìnyí ń rì wọnú ipò ìwà burúkú àti ìwà ìbàjẹ́ tí kò sí irú rẹ̀ ní gbogbo ìtàn tí ó ti wà ṣáájú. (Fi wé Ìṣe 2:40.) Ó yẹ kí a wà lẹ́nu iṣẹ́ wa ní kánjúkánjú. (Tímótì Kejì 4:2) Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí ìpọ́njú ńlá náà yóò dé fi hàn pé yóò dé lójijì, lọ́gán, láìròtẹ́lẹ̀—gẹ́gẹ́ bí olè. (Tẹsalóníkà Kíní 5:1-4; Ìṣípayá 3:3; 16:15) “Ní tìtorí èyí ẹ̀yin pẹ̀lú ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ̀yin kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọkùnrin ènìyàn ń bọ̀.” (Mátíù 24:44) Níwọ̀n bí ìran aráyé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí ti ń rìn létí bèbè ìparun, ó dájú pé, àwa kì yóò fẹ́ láti sọ ìrètí ṣíṣeyebíye wa ti ìyè ayérayé nù nípa pípadà sí “yíyí gbiri nínú ẹrẹ̀” àwọn ohun ayé tí ń pín ọkàn níyà!—Pétérù Kejì 2:22; 3:10; Lúùkù 21:32-36.
4. Ipò wo ni ó ti béèrè fún ìpèsè tí ń pọ̀ sí i ní ti “oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” báwo sì ni a ti ṣe kúnjú àìní yìí?
4 Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù, ní 1914, “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìrora gógó wàhálà” jẹyọ bí aráyé ṣe wọnú “ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.” Ìbànújẹ́, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ alájàálù, àti ìwà àìlófin ti pọ̀ sí i títí di ọjọ́ òní. (Mátíù 24:3-8, 12) Ní àkókò kan náà, Jèhófà yan iṣẹ́ fún ẹgbẹ́ ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú láti pèsè “oúnjẹ” tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” fún agbo ilé Ọ̀gá wọn, Kristi. (Mátíù 24:45-47) Láti orí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run, nísinsìnyí, Mèsáyà Ọba yìí ń darí ètò ìpèsè oúnjẹ nípa tẹ̀mí jákèjádò ilẹ̀ ayé lọ́nà pípabanbarì.
“Àwọn Ìpèsè Oúnjẹ” Rẹpẹtẹ
5. Àfiyèsí wo ni lájorí “oúnjẹ” ń rí gbà?
5 Gbé mímúra “àwọn ìpèsè oúnjẹ” sílẹ̀ yẹ̀ wò. (Lúùkù 12:42) Lájorí oúnjẹ tí ó máa ń wà nínú ọ̀wọ́ ìpèsè oúnjẹ Kristẹni ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì. Láti fi Bíbélì kọ́ni lọ́nà gbígbéṣẹ́, ohun àkọ́kọ́ tí a nílò ni ìtúmọ̀ pípéye, tí ó sì rọrùn láti kà. Jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, a ti kúnjú àìní yìí ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, ní pàtàkì, bẹ̀rẹ̀ láti 1950 nígbà tí a mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Nígbà tí yóò fi di 1961, ìtúmọ̀ New World Translation ti odindi Bíbélì ti wà, kò sì pẹ́ tí àwọn ẹ̀dà ìtúmọ̀ fi wà ní àwọn èdè pàtàkì-pàtàkì. Ìdìpọ̀ 3 tí a mú jáde ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1996 mú àpapọ̀ iye rẹ̀ wá sí 27, nínú èyí tí 14 jẹ́ odindi Bíbélì. Láti lè bójú tó iṣẹ́ yìí lórí Bíbélì, àti lórí àwọn àrànṣe Bíbélì, nǹkan bí 1,174 àwọn Kristẹni olùṣèyàsímímọ́ ń ṣiṣẹ́ ní àkókò kíkún lórí ṣíṣe ìtumọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè 77.
6. Báwo ni Society ti ṣe kúnjú àìní fún àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì?
6 Ní ṣíṣe ìtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn olùtúmọ̀ wọ̀nyí, àwọn ẹ̀ka ìtẹ̀wé 24 tí ó jẹ́ ti Watch Tower Society ti tẹ ọ̀pọ̀ jaburata ìtẹ̀jáde. Láti lè ṣàṣeparí èyí, a ń bá a nìṣó ní gbígbé àwọn àfikún ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo ayára-bí-àṣá kalẹ̀ sí àwọn ẹ̀ka ńláńlá. Iye ìwé Ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí a ń tẹ̀ jáde ti pọ̀ sí i lóṣooṣù, ní dídé àpapọ̀ 943,892,500 ẹ̀dà, ìlọsókè ìpín 13.4 nínú ọgọ́rùn-ún fún ọdún yìí. Láti 1995, àpapọ̀ iye Bíbélì àti ìwé ẹlẹ́yìn líle tí a tẹ̀ ní United States, Brazil, Finland, Germany, Ítálì, Japan, Korea, àti Mexico nìkan ti lọ sókè ní ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún sí 76,760,098 ẹ̀dà ní 1996. Àwọn ẹ̀ka mìíràn tún ti fi kún àpapọ̀ ìlọsókè nínú iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a mú jáde.
7. Báwo ni Aísáyà 54:2 ṣe túbọ̀ jẹ́ kánjúkánjú nísinsìnyí?
7 Gbígbẹ́sẹ̀ kúrò lórí fífòfinde Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìlà Oòrùn Europe àti Áfíríkà ti mú kí èyí tí ó pọ̀ jù nínú ìlọsókè náà pọn dandan ní àwọn ọdún 1990. Ebi fún oúnjẹ tẹ̀mí ń pani gan-an ní àwọn ibi wọ̀nyí. Nítorí náà ìpè náà ń fi ìjẹ́kánjúkánjú ńláǹlà dún léraléra pé: “Sọ ibi àgọ́ rẹ di gbígbòòrò, sì jẹ́ kí wọ́n na aṣọ títa ibùgbé rẹ jáde: má ṣe dá sí, sọ okùn rẹ di gígùn, kí o sì mú èèkàn rẹ le.”—Aísáyà 54:2.
8. Ìdáhùnpadà ọlọ́làwọ́ wo ni ó ń ṣèrànwọ́ láti pèsè ìtìlẹ́yìn ìnáwó?
8 Nípa báyìí, ó ti di ohun tí ó pọn dandan láti mú àwọn ilé gbòòrò sí i ní ọ̀pọ̀ 104 ẹ̀ka Society. Nítorí ipò ọrọ̀ ajé tí kò fara rọ ní ọ̀pọ̀ àgbègbè ìpínlẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí sílẹ̀, apá tí ó pọ̀ jù nínú ìnáwó fún ìmúgbòòrò yí ni a ń mójú tó nípasẹ̀ ọrẹ fún iṣẹ́ yíká ayé láti àwọn ilẹ̀ tí nǹkan túbọ̀ rọ̀ṣọ̀mù fún. Ó múni láyọ̀ pé, àwọn ìjọ àti olúkúlùkù ti ń fi ẹ̀mí Ẹkísódù 35:21 dáhùn pa dà tọkàntọkàn pé: “Wọ́n sì wá, olúkúlùkù ẹni tí ọkàn rẹ̀ ru nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù ẹni tí ọkàn rẹ̀ mú un fẹ́, wọ́n sì mú ọrẹ OLÚWA wá fún iṣẹ́ àgọ́ àjọ náà.” A lo àǹfààní yìí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n ti nípìn-ín nínú irú ìfúnni ọlọ́làwọ́ yìí.—Kọ́ríńtì Kejì 9:11.
9. Báwo ni a ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ Róòmù 10:13, 18 ṣẹ lónìí?
9 Ní 1996, àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society ti yin orúkọ Jèhófà àti ète rẹ̀ lógo títí dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé. Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ó rí. Ní ṣíṣàyọlò àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì àti Orin Dáfídì ìkọkàndínlógún, ó kọ̀wé pé: “‘Olúkúlùkù ẹni tí ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a óò gbàlà.’ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ mo béèrè, Wọn kò kùnà láti gbọ́, àbí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Họ́wù, ní ti tòótọ́, ‘ìró wọ́n jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé, àti àwọn gbólóhùn àsọjáde wọn sí àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.’” (Róòmù 10:13, 18) Nípa títipa báyìí gbé orúkọ ṣíṣeyebíye náà, Jèhófà, ga, àwọn ènìyàn rẹ̀ ti kó ipa pàtàkì nínú fífi ògo kún ilé ìjọsìn rẹ̀. Ṣùgbọ́n, báwo ni ìpòkìkí yìí ti gbilẹ̀ tó ní pàtàkì ní 1996? Jọ̀wọ́, ṣàyẹ̀wò ṣáàtì tí ó tẹ̀ lé e ní ojú ìwé 18 sí 21.
Kíkórè Káàkiri Ayé
10. Apá títayọ lọ́lá wo ni o kíyè sí nínú ìgbòkègbodò àwọn ènìyàn Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàkópọ̀ rẹ̀ nínú ṣáàtì ojú ìwé 18 sí 21?
10 Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tí a rí nínú Lúùkù 10:2 kò tí ì ní ipá ìdarí ńláǹlà tó báyìí rí: “Ìkórè pọ̀, ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ jẹ́ ìwọ̀nba díẹ̀. Nítorí náà ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” Ìwọ ha ń dáhùn pa dà sí ìpè yẹn bí? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ kárí ayé ń ṣe bẹ́ẹ̀. Góńgó tuntun ti 5,413,769 akéde Ìjọba tí wọ́n ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ní 1996, jẹ́rìí sí èyí. Ní àfikún sí i, 366,579 àwọn arákùnrin àti arábìnrin tuntun ni a batisí. Ẹ wo bí a ṣe ṣìkẹ́ “àwọn ohun fífani lọ́kàn mọ́ra ti gbogbo orílẹ̀-èdè” wọ̀nyí tó, tí wọ́n ń nípìn-ín nínú ‘fífi ògo kún ilé ìjọsìn Jèhófà’!—Hágáì 2:7, NW.
11. Èé ṣe tí gbogbo wa fi ní ìdí láti kún fún ayọ̀?
11 Àwọn ìròyìn ìmúgbòòrò sí i ní àwọn pápá tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí sílẹ̀ jẹ́ ohun tí ó jọni lójú. Àwọn mìíràn lára wa ha ń ṣe ìlara àwọn tí ń gbádùn irú ìbísí bẹ́ẹ̀ bí? Ní òdì kejì pátápátá, a bá wọn yọ̀. Ibi kékeré ni gbogbo orílẹ̀-èdè ti bẹ̀rẹ̀. Wòlíì tí ó jẹ́ alájọgbáyé Hágáì, Sekaráyà, kọ̀wé pé: “Ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré?” (Sekaráyà 4:10) A kún fún ayọ̀ pé, ní àwọn ilẹ̀ tí iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà ti fìdí múlẹ̀ dáradára, a ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ akéde Ìjọba, a sì ń kárí àgbègbè ìpínlẹ̀ lóòrèkóòrè, kódà a ń kárí wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìlú ńlá. A ha ní ìdí èyíkéyìí láti dẹwọ́ nígbà tí Jèhófà nísinsìnyí ń nawọ́ àǹfààní fún ìgbàlà sí àwọn àgbègbè tí a ti fòfin de iṣẹ́ náà tẹ́lẹ̀ bí? Kí á má rí i! Jésù wí pé: “Pápá náà ni ayé.” (Mátíù 13:38) A gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó ní jíjẹ́rìí kúnnákúnná, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ìjímìjí ṣe jẹ́rìí kúnnákúnná ní òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti àwọn Júù.—Ìṣe 2:40; 10:42; 20:24; 28:23.
Títẹ̀síwájú Nígbà Gbogbo
12. Ìrànlọ́wọ́ wo ni a ní láti rìn ní “ọ̀kánkán gan-an”? (Ní àfikún sí i wo àpótí, “Kíkórè ‘Láti Òpin Ilẹ̀ Wá.’”)
12 Bẹ́ẹ̀ ni, a gbọ́dọ̀ máa rìn ní ìṣísẹ̀ kan náà pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹṣin òkè ọ̀run ti Jèhófà, ní rírìn pẹ̀lú rẹ̀ “ní ọ̀kánkán gan-an.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 1:12) A ní ọ̀rọ̀ Pétérù lọ́kàn pé: “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí awọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé òun kò ní ìfẹ́ ọkàn pé kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó ní ìfẹ́ ọkàn pé kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (Pétérù Kejì 3:9) Ẹ jẹ́ kí ìtara àwòfiṣàpẹẹrẹ tí àwọn ará wa ní àwọn ilẹ̀ òtòṣì ní sún wa ṣiṣẹ́. Ohunkóhun yòó wù tí ó lè dà bí ìdádúró ní ti dídé Amágẹ́dọ́nì ń yọ̀ǹda fún kíkó ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún jọ ní àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí àti ní àwọn àgbègbè ìpínlẹ̀ míràn tí a ti ṣe kúnná. Má ṣe àṣìṣe kankan nípa rẹ̀: “Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, ó kù sí dẹ̀dẹ̀, ó sì ń yára kánkán.” (Sefanáyà 1:14) Àwa pẹ̀lú ní láti yára kankan ní jíjẹ́rìí ìkẹyìn kúnnákúnná!
13, 14. (a) Kí ni a lè sọ nípa ìpínkiri àwọn ìtẹ̀jáde ní 1996? (b) Ètò àkànṣe wo ni àwọn ìjọ lè ṣe lọ́dọọdún, báwo sì ni o ṣe ń wéwèé láti nípìn-ín nínú rẹ̀?
13 Bí kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ kò tilẹ̀ fara hàn nínú ṣáàtì iṣẹ́ ìsìn, iye Bíbélì, ìwé ńlá, àti ìwé ìròyìn tí a pín kiri ní ọdún tí ó kọjá gbàfiyèsí. Fún àpẹẹrẹ, iye ìwé ìròyìn tí a fi sóde kárí ayé fi ìlọsókè ìpín 19 nínú ọgọ́rùn-ún hàn, a fi àpapọ̀ 543,667,923 ẹ̀dà sóde. Àwọn ìwé ìròyìn wa mú kí wíwàásù túbọ̀ rọrùn—ní òpópónà, ní gáréèjì, ní ibi ìdúrówọkọ̀, ní àgbègbè iṣẹ́ ajé. Ìròyìn fi hàn pé ní àwọn àgbègbè ìpínlẹ̀ kan tí àwọn oníwàásù Ìjọba ti ro kúnná, ìjójúlówó àwọn ìwé ìròyìn wa ti fa àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lọ́kàn mọ́ra, wọ́n sì ń tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
14 Lọ́dọọdún ní oṣù April, àwọn ìjọ sábà máa ń ṣètò àkànṣe ìgbòkègbodò fún ìwé ìròyìn, ní ṣíṣe ìgbétásì odindi ọjọ́ kan láti ilé dé ilé àti ní àwọn ibi ti èrò máà ń wà. Ìjọ rẹ yóò ha nípìn-ín nínú èyí ní April 1997 bí? A ti ṣètò àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ àti Jí! títayọ lọ́lá fún oṣù April sílẹ̀, fífi wọ́n lọ́ni nígbà kan náà kárí ayé sì yẹ kí ó fani lọ́kàn mọ́ra púpọ̀! Ní erékùṣù Kípírọ́sì, àwọn ìjọ, ní lílo ọ̀rọ̀ amóríwú yìí, “mú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ gbogbo ẹni tí o bá lè dè,” tẹ̀ lé irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ pínpín ìwé ìròyìn bẹ́ẹ̀ lóṣooṣù pàápàá, ní dídé góńgó tuntun ti 275,359 tí wọ́n fi sóde ní ọdún náà, ìlọsókè ìpín 54 nínú ọgọ́rùn-ún.
Àwọn Ìhìn Iṣẹ́ Tí Hágáì Sọ Kẹ́yìn
15. (a) Èé ṣe tí Jèhófà fi fi àfikún ìhìn iṣẹ́ ránṣẹ́ nípasẹ̀ Hágáì? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni ìhìn iṣẹ́ Hágáì ẹlẹ́ẹ̀kẹta ní fún wa?
15 Ọjọ́ 63 lẹ́yìn tí ó ti jíṣẹ́ rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì, Jèhófà fi ìkéde kẹta tí àwa pẹ̀lú lè fi sọ́kàn lónìí rán Hágáì. Hágáì sọ̀rọ̀ bí ẹni pé àwọn Júù ti ń fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì náà lélẹ̀ nígbà náà, èyí tí wọ́n ti fi lélẹ̀ ní ti gidi ní ọdún 17 ṣáájú. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà rí i pé ó yẹ láti ṣe ìwẹ̀mọ́ tónítóní. Àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ti dẹwọ́ nínú bíbójú tó iṣẹ́ wọn, wọ́n sì ti tipa bẹ́ẹ̀ di aláìmọ́ ní ojú Jèhófà. Ó ha lè jẹ́ pé, àwọn kan lára àwọn ènìyàn Jèhófà lónìí ti dẹwọ́ wọn, kódà tí wọ́n tilẹ̀ ń lọ́wọ́ nínú àwọn ọ̀nà onígbọ̀jẹ̀gẹ́ àti onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì ti ayé? Ó jẹ́ kánjúkánjú pé, kí gbogbo wa ronú “láti òní [àti sí ọjọ́ iwájú, NW]” lórí mímú ògo wá fún orúkọ Jèhófà, kí a ní ìgbọ́kànlé nínú ìlérí rẹ̀ pé: “Láti òní lọ ni èmi óò bù kún fún yín.”—Hágáì 2:10-19; Hébérù 6:11, 12.
16. ‘Mímì’ wo ni ó kù sí dẹ̀dẹ̀, kì ni yóò sì yọrí sí?
16 Ní ọjọ́ kan náà, ọ̀rọ̀ “[Jèhófà, NW] àwọn ọmọ ogun” wá sọ́dọ̀ Hágáì nígbà kẹ́rin àti fún ìgbà ìkẹyìn. Ó sọ ohun tí ‘mímì tí Òun ń mi gbogbo àwọn ọ̀run àti ayé’ ní nínú di mímọ̀, ní sísọ pé: “Èmi óò . . . bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, èmi óò sì pa agbára ìjọba kèfèrí run; èmi óò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ dé, àti àwọn tí ó gùn wọ́n; àti ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin yóò wá ilẹ̀; olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.” (Hágáì 2:6, 21, 22) ‘Mímì’ náà yóò tipa bẹ́ẹ̀ dé òtéńté rẹ̀ nígbà tí Jèhófà bá fọ ilẹ̀ ayé mọ́ tónítóní láìkù àbàwọ́n kankan, ní Amágẹ́dọ́nì. Nígbà náà, “àwọn ohun fífani lọ́kàn mọ́ra ti gbogbo orílẹ̀-èdè” yóò ti wọlé, láti para pọ̀ di apá pàtàkì nínú àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn fún ayé tuntun. Ẹ wo ọ̀pọ̀ ìdí tí a ní fún híhó ìhó ayọ̀ àti fún fífi ìyìn fún Jèhófà!—Hágáì 2:7, NW; Ìṣípayá 19:6, 7; 21:1-4.
17. Báwo ni a ti ṣe gbé Jésù kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “òrùka èdìdì”?
17 Nígbà tí ó ń mú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ wá sí òpin, Hágáì kọ̀wé pé: “Ní ọjọ́ náà, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, ni èmi óò mú ọ, Ìwọ Serubábélì, . . . èmi óò sì sọ ọ́ di òrùka èdìdì kan: nítorí tí mo ti yàn ọ́, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.” (Hágáì 2:23) Kristi Jésù ni Mèsáyà Ọba amápẹẹrẹṣẹ àti Àlùfáà Àgbà ti Jèhófà, ní ṣíṣe iṣẹ́ tí Gómìnà Serubábélì àti Àlùfáà Àgbà Jóṣúà ṣe lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní Jerúsálẹ́mù orí ilẹ̀ ayé, papọ̀ ní ọ̀run. Gẹ́gẹ́ bí òrùka ọlọ́lá àṣẹ ní ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà, Jésù ni ẹni náà tí ó di “Bẹ́ẹ̀ ni” gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ Jèhófà ní mímú “àwọn ìlérí Ọlọ́run” ṣẹ. (Kọ́ríńtì Kejì 1:20; Éfésù 3:10, 11; Ìṣípayá 19:10) Gbogbo ìhìn iṣẹ́ alásọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ darí àfiyèsí sórí pípèsè tí Jèhófà pèsè Kristi gẹ́gẹ́ bí Ọba àti àlùfáà Olùràpadà.—Jòhánù 18:37; Pétérù Kíní 1:18, 19.
18. Báwo ni èyí tí ó kẹ́yìn nínú ‘ohun tí Jèhófà àwọn ọmọ ogun’ wí yóò ṣe ní ìmúṣẹ tí yóò tuni lára?
18 Ní tòótọ́, ní ọjọ́ wa yìí, inú tẹ́ńpìlì Jèhófà nípa tẹ̀mí, tí ń dán gbinrin, ni a ti lè rí ògo títóbi jù lọ! Láìpẹ́, lẹ́yìn tí Jèhófà bá ti gbá gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ Sátánì kúrò, Hágáì 2:9 yóò ní ìmúṣẹ mìíràn tí yóò múni nínú dùn: “Níhìn-ín yìí ni èmi óò sì fi àlàáfíà fúnni, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.” Àlàáfíà nígbẹ̀yìngbẹ́yín!—àlàáfíà pípẹ́ títí, káàkiri àgbáyé, tí “òrùka èdìdì” ti Jèhófà, Kristi Jésù, “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” mú dáni lójú, ẹni tí a kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Ìjọba yóò sì bí sí i, àlàáfíà kì yóò ní ìpẹ̀kun . . . Ìtara [Jèhófà, NW] àwọn ọmọ ogun yóò ṣe èyí.” (Aísáyà 9:6, 7) Títí ayé fáàbàdà, ògo ilé ìjọsìn Jèhófà yóò tàn káàkiri ilẹ̀ àkóso alálàáfíà ti ipò ọba aláṣẹ àgbáyé rẹ̀. Ǹjẹ́ kí a wà nínú ilé náà títí láé!—Orin Dáfídì 27:4; 65:4; 84:10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo “A Gbà Wọ́n Là Láti Inú ‘Ìran Burúkú’” àti “Àkókò Láti Wà Lójúfò” nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti November 1, 1995.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Lónìí, báwo ni a ṣe ń fi “ògo kún” ilé Jèhófà?
◻ Èé ṣe tí kò fi tí ì jẹ́ kánjúkánjú tó báyìí rí láti wàásù ìhìn rere?
◻ Ìsúnniṣe wo láti wàásù pẹ̀lú ìjẹ́kánjúkánjú ni Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn 1996 fúnni?
◻ Báwo ni Kristi ṣe ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí “òrùka èdìdì” Jèhófà?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]
Kíkórè “Láti Òpin Ilẹ̀ Wá”
NÍNÚ Aísáyà 43:6, a kà nípa àṣẹ Jèhófà pé: “Má ṣe dá dúró; mú àwọn ọmọ mi ọkùnrin láti òkèèrè wá, àti àwọn ọmọ mi obìnrin láti òpin ilẹ̀ wá.” Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń ní ìmúṣẹ gígadabú lónìí ní Ìlà Oòrùn Europe. Gbé ọ̀ràn orílẹ̀-èdè oníjọba Kọ́múníìsì tẹ́lẹ̀ rí, Moldova, yẹ̀ wò. Àwọn ìletò kan ń bẹ tí ìlàjì àwọn olùgbé wọn nísinsìnyí jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Wọ́n ní láti rin ìrìn-àjò gígùn kí wọ́n tó lè rí àgbègbè ìpínlẹ̀ tí wọn yóò ti wàásù, ṣùgbọ́n wọ́n ń sapá! Ọ̀pọ̀ akéde nínú àwọn ìjọ wọ̀nyí jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn òbí tí a lé lọ sí Siberia ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950. Nísinsìnyí, ìdílé wọn ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìkórè náà. Lára 12,565 akéde, 1,917 ni a batisí ní èṣí. Mẹ́tàlélógójì nínú àwọn ìjọ náà ní nǹkan bíi 150 akéde, àyíká sì ti pọ̀ sí i láti orí mẹ́rin sí mẹ́jọ ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tuntun.
Èyí tí ó tún jọni lójú ni ìmúgbòòrò ní Albania. Níbẹ̀, ìwọ̀ǹba kéréje Àwọn Ẹlẹ́rìí adúróṣinṣin fara da ìṣàkóso bóo fẹ́ bóo kọ̀ oníwà òǹrorò jù lọ jálẹ̀ nǹkan bí 50 ọdún. A pa púpọ̀ lára wọn. Èyí mú wa rántí ìlérí Jésù pé: “Má ṣe fòyà àwọn ohun tí ìwọ máa tó jìyà rẹ̀. Wò ó! Èṣù yóò máa bá a nìṣó ní sísọ àwọn kan nínú yín sí ẹ̀wọ̀n kí a lè dán yín wò ní kíkún . . . Jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, dájúdájú èmi yóò sì fún ọ ní adé ìyè.” (Ìṣípayá 2:10; tún wo Jòhánù 5:28, 29; 11:24, 25.) Kí ni a rí nísinsìnyí ní Albania? Ní tòótọ́, a rí ìmúṣẹ tí ó gbàfiyèsí nípa ìlérí Jèhófà nínú Aísáyà 60:22 pé: “Ẹni kékeré kan ni yóò di ẹgbẹ̀rún”! Ní 1990, akéde kan ṣoṣo péré ni ó ròyìn iṣẹ́ ìsìn ní Albania. Ṣùgbọ́n, “àwọn òṣìṣẹ́” púpọ̀ sí i láti Ítálì àti àwọn ilẹ̀ míràn dáhùn ìpè Jésù pé: “Nítorí náà ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.” (Mátíù 28:19; Lúùkù 10:2) Nígbà tí a óò fi ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Jésù ní 1996, 773 akéde ti di ògbóṣáṣá nínú pápá, àwọn wọ̀nyí sí kó 6,523 ènìyàn jọ sí ibi ìpàdé fún Ìṣe Ìrántí wọn, iye tí ó ju ìlọ́po mẹ́jọ àwọn akéde! Láti àwọn àgbègbè àdádó, a ròyìn iye yíyanilẹ́nu ní ti àwọn tí ó pésẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí akéde kankan níbẹ̀, 192 pésẹ̀ ní ìlú Kukës, nígbà tí 230 pésẹ̀ sí Divjakë. Àwọn 212 pésẹ̀ ní Krujë, tí ó ní ẹyọ akéde kan ṣoṣo. Àwọn 30 akéde ní Korçë háyà ilé kan fún iye tí ó lé ní 300. Lẹ́yìn tí iye yẹn ti kún gbọ̀ngàn àpèjọ náà fọ́fọ́, a ní láti dá 200 pa dà nígbà tí kò sí àyè mọ́. Ní tòótọ́, àkókò ìkórè ti tó!
Ìròyìn yí wá láti Romania: “Nígbà tí a wà lẹ́nu iṣẹ́ ilé dé ilé, a bá ẹnì kan pàdé tí ó sọ pé òun jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ó sì ń gbé ní ìlú kékeré kan tí kò sí Ẹlẹ́rìí kankan, gẹ́gẹ́ bí àwa ṣe mọ̀. Ó sọ fún wa pé, yàtọ̀ sí òun àwọn ẹni 15 mìíràn ṣì wà tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé ní ọjọ́ Thursday àti Sunday fún ọ̀pọ̀ ọdún, àti pé wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé. Ní ọjọ́ kejì a lọ sí ìlú náà. A bá àwọn 15 nínú yàrá méjí tí wọ́n ti ń dúró dè wá, àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé, tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gba 20 ìwé ńlá àti 20 ìwé ìròyìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. A fi bí a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn wọ́n. A jùmọ̀ kọrin, a sì dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó jẹ́ wọ́n lọ́kàn jù lọ. Ẹni tí ń mú ipò iwájú nínú àwùjọ náà sọ pé: ‘Ní ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn, mo gbàdúrà sí Jèhófà pẹ̀lú omijé pé kí ó rán olùṣọ́ àgùntàn kan sí wa, a sì dáhùn àdúrà mí.’ Inú wa dùn jọjọ, nígbà tí a sì fẹ́ máa lọ, gẹ́gẹ́ bí ọmọ òrukàn tí ó rí bàbá rẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó wí pé: ‘Ẹ jọ̀wọ́ ẹ má gbàgbé wa o. Ẹ tún pa dà wá rí wa o!’ A ṣe bẹ́ẹ̀, nísinsìnyí, a ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méje ní ìlú yẹn. Ní ọ̀pọ̀ àwọn àgbègbè ìpínlẹ̀ tuntun, iṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ lọ́nà àgbàyanu pẹ̀lú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí tí a mọrírì gidigidi, èyí sì fi hàn pé iṣẹ́ náà wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 18-21]
ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 1996 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ
(Wo àdìpọ̀)
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
A ń kó “àwọn ohun fífani lọ́kàn mọ́ra ti gbogbo orílẹ̀-èdè” jọ ní àwọn Erékùṣù Òkun (1), Gúúsù America (2), Áfíríkà (3), Éṣíà (4), Àríwá America (5), àti Europe (6)