Bí Àwọn Ìran Tí Sekaráyà Rí Ṣe Kàn Ẹ́
“Ẹ padà sọ́dọ̀ mi, . . . èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín.”—SEK. 1:3.
1-3. (a) Báwo ni nǹkan ṣe rí fún àwọn èèyàn Jèhófà lásìkò tí Sekaráyà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wòlíì? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘pa dà sọ́dọ̀ òun’?
JÈHÓFÀ fi ìran àgbàyanu kan han wòlíì Sekaráyà. Nínú ìran yẹn, wòlíì náà rí àkájọ ìwé kan tó ń fò lókè, ó tún rí obìnrin kan tí wọ́n dé mọ́nú apẹ̀rẹ̀ ńlá àtàwọn obìnrin méjì tí wọ́n ní ìyẹ́ apá bíi ti ẹyẹ àkọ̀, tí wọ́n sì ń fò lójú ọ̀run. (Sek. 5:1, 7-9) Kí nìdí tí Jèhófà fi fi ìran yìí han wòlíì náà? Báwo ni nǹkan ṣe rí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lásìkò yẹn? Báwo sì ni ìran tí Sekaráyà rí ṣe kàn wá lónìí?
2 Ọdún ayọ̀ ni ọdún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni jẹ́ fáwọn èèyàn Jèhófà. Ìdí sì ni pé ọdún yẹn ni wọ́n kúrò nígbèkùn Bábílónì lẹ́yìn àádọ́rin [70] ọdún tí wọ́n ti wà níbẹ̀. Inú wọn dùn gan-an lẹ́yìn tí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti kọ́ tẹ́ńpìlì kí wọ́n lè máa jọ́sìn Jèhófà. Nígbà tó di ọdún 536 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì náà lélẹ̀. Inú àwọn èèyàn náà dùn débi pé wọ́n ń yọ̀, wọ́n sì ń pariwo tó fi jẹ́ pé “ìró náà ni a sì gbọ́, àní ní ọ̀nà jíjìnréré.” (Ẹ́sírà 3:10-13) Àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kojú àwọn ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í takò wọ́n torí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, èyí sì kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. Bó ṣe di pé wọ́n pa iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà tì nìyẹn, wọ́n bá gbájú mọ́ kíkọ́ ilé tara wọn, wọ́n sì tara bọ iṣẹ́ oko wọn. Ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kọjá, iṣẹ́ tẹ́ńpìlì náà ṣì wà bó ṣe wà. Ó ṣe kedere pé àwọn èèyàn Ọlọ́run nílò ẹni tó máa ta wọ́n jí, kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, kí wọ́n sì ṣíwọ́ àtimáa fi ìfẹ́ tara wọn ṣáájú. Jèhófà fẹ́ kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ òun, kí wọ́n lo ìgboyà, kí wọ́n sì máa jọ́sìn òun bí wọ́n ti ń ṣe tẹ́lẹ̀.
3 Jèhófà rán wòlíì Sekaráyà sáwọn ọmọ Ísírélì lọ́dún 520 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni kó lè rán wọn létí ìdí tí òun fi dá wọn nídè kúrò ní Bábílónì. Ó ṣe tán, orúkọ Sekeráyà túmọ̀ sí “Jèhófà Ti Rántí,” ìyẹn á sì jẹ́ káwọn èèyàn náà rántí ohun kan tó ṣe pàtàkì. Ohun náà ni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn náà ti gbàgbé ìdí tí Jèhófà fi dá wọn nídè, Jèhófà ní tiẹ̀ kò gbàgbé wọn. (Ka Sekaráyà 1:3, 4.) Ó jẹ́ kó dá wọn lójú pé òun máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà máa jọ́sìn òun, àmọ́ ó jẹ́ kó ṣe kedere sí wọn pé òun kò ní gba ìjọsìn àfaraṣe-má-fọkàn-ṣe. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò bí Jèhófà ṣe lo ìran kẹfà àti keje tí Sekaráyà rí láti mú káwọn èèyàn náà pa dà sẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì. Bákan náà, a máa sọ àwọn ẹ̀kọ́ tí ìran náà kọ́ wa lónìí.
JÈHÓFÀ MÁA FÌYÀ JẸ ÀWỌN TÓ Ń JALÈ
4. Kí ni Sekaráyà rí nínú ìran kẹfà? Kí ló jọni lójú nípa bó ṣe jẹ́ pé tinú-tẹ̀yìn àkájọ ìwé náà ni wọ́n kọ̀rọ̀ sí? (Wo àwòrán àkọ́kọ́ tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
4 Ìran kan tó ṣàjèjì ló bẹ̀rẹ̀ orí 5 ìwé Sekaráyà. (Ka Sekaráyà 5:1, 2.) Sekaráyà rí àkájọ ìwé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan tó ń fò lójú òfuurufú, ìwé náà gùn tó mítà mẹ́sàn-án, ó sì fẹ̀ tó mítà mẹ́rin àtààbọ̀. Ìwé náà wà ní ṣíṣí, torí náà èèyàn lè ka ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀. Tinú-tẹ̀yìn ni wọ́n kọ̀rọ̀ sí, àwọn ọ̀rọ̀ ìdájọ́ ló sì kúnnú rẹ̀. (Sek. 5:3) Ojú kan ni wọ́n sábà máa ń kọ ọ̀rọ̀ sí nínú àkájọ ìwé, àmọ́ ti ìwé yìí yàtọ̀. Ó ṣe kedere nígbà náà pé àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré rárá.
5, 6. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo olè jíjà tàbí ìwà àìṣòótọ́ èyíkéyìí?
5 Ka Sekaráyà 5:3, 4. Gbogbo èèyàn ló máa jíhìn fún Ọlọ́run, pàápàá jù lọ àwọn èèyàn rẹ̀. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run mọ̀ pé olè jíjà máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. (Òwe 30:8, 9) Láìka ohun tó mú kẹ́nì kan jalè tàbí àròyé tẹ́ni náà ṣe, olè ni olè ń jẹ́. Ohun tó túmọ̀ si ni pé olójú kòkòrò ni onítọ̀hún, ó sì ka àwọn nǹkan tara sí pàtàkì ju Ọlọ́run lọ. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ka òfin Ọlọ́run sí, ó tàbùkù sí Ọlọ́run, ó sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ rẹ̀.
6 Sekaráyà 5:3, 4 sọ pé ‘ègún náà yóò wọnú ilé olè, yóò sì wọ̀ sí àárín ilé rẹ̀, yóò sì pa á run pátápátá.’ Ó túmọ̀ sí pé kò sóhun tó lè dènà ìdájọ́ Ọlọ́run. Ibi yòówù kí ìránṣẹ́ Jèhófà ti hu ìwàkíwà, kódà kó jẹ́ inú òkùnkùn, ìdájọ́ Ọlọ́run máa bá a. Ó ṣeé ṣe kéèyàn jalè kó sì fi bò fún àwọn aláṣẹ, àwọn agbanisíṣẹ́, àwọn alàgbà tàbí òbí. Àmọ́ kò sóhun tó bò lójú Jèhófà, torí ó jẹ́ kó ṣe kedere pé àṣírí gbogbo olè máa tú. (Héb. 4:13) Ẹ ò rí i pé ohun tó dáa jù ni pé ká má kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ká máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ “nínú ohun gbogbo”!—Héb. 13:18.
7. Kí la lè ṣe tá ò fi ní fara gbá nínú ègún tó wà nínú àkájọ ìwé náà?
7 Ọ̀nà yòówù kéèyàn gbà jalè àti ohun yòówù kéèyàn jí, ó dájú pé Jèhófà kórìíra olè jíjà. Ohun tó dáa jù ni pé ká máa tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, ká máa hùwà tó bójú mu, ká má sì kẹ́gàn bá orúkọ rẹ̀. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní jẹ lára ìyà tí Jèhófà fi máa jẹ àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ tẹ òfin rẹ̀ lójú.
BÁ A ṢE LÈ MÁA MÚ Ẹ̀JẸ́ WA ṢẸ LÓJOOJÚMỌ́
8-10. (a) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn búra? (b) Ẹ̀jẹ́ wo ni Ọba Sedekáyà kò mú ṣẹ?
8 Ọ̀rọ̀ míì tó wà nínú àkájọ ìwé tó ń fò náà kìlọ̀ fún àwọn tó ń ‘búra ní orúkọ Ọlọ́run lọ́nà èké.’ (Sek. 5:4) Téèyàn bá búra, ṣe ló ń fọwọ́ sọ̀yà pé òótọ́ lòun sọ, ó sì lè jẹ́ pé ṣe lẹni náà ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa ṣe ohun kan tàbí pé òun ò ní ṣe é.
9 Nǹkan ńlá ni téèyàn bá fi orúkọ Jèhófà búra. Ohun tí Ọba Sedekáyà tó jẹ kẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù ṣe nìyẹn. Ó fi Jèhófà búra pé òun ò ní ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì. Àmọ́ Sedekáyà kò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Torí náà, Jèhófà kéde ìdájọ́ lòdì sí i, ó ní: “Bí mo ti ń bẹ láàyè, . . . ní ọ̀dọ̀ ọba tí ó fi í jẹ ọba, ẹni tí òun tẹ́ńbẹ́lú ìbúra rẹ̀, tí òun sì da májẹ̀mú rẹ̀, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni òun yóò kú sí ní àárín Bábílónì.”—Ìsík. 17:16.
10 Orúkọ Ọlọ́run ni Sedekáyà fi búra, Jèhófà sì retí pé kó mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ. (2 Kíró. 36:13) Àmọ́ kò mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló ní kí Íjíbítì wá ran òun lọ́wọ́ kí òun lè bọ́ lábẹ́ àjàgà Bábílónì, àmọ́ pàbó ni ìránwọ́ náà já sí.—Ìsík. 17:11-15, 17, 18.
11, 12. (a) Ẹ̀jẹ́ wo ló ṣe pàtàkì jù? (b) Torí pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, báwo ló ṣe yẹ ká máa gbé ìgbésí ayé wa?
11 Jèhófà mọ gbogbo ìlérí tá a ṣe. Ojú kékeré kọ́ ló fi ń wo àwọn ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́, torí náà tá a bá fẹ́ rí ojúure rẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká mú àwọn ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. (Sm. 76:11) Nínú gbogbo ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́, èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa. Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ṣe la ṣèlérí pé bíná ń jó bíjì ń jà, òun nìkan la máa fayé wa sìn.
12 Báwo la ṣe lè mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ? Onírúurú àdánwò là ń kojú, àwọn kan máa ń le àwọn míì kò sì fi bẹ́ẹ̀ le. Torí náà, ohun tá a bá ṣe lójú àdánwò ló máa fi hàn bóyá a fọwọ́ gidi mú ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́ fún Jèhófà pé ìfẹ́ rẹ̀ la ó máa ṣe lójoojúmọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (Sm. 61:8) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹnì kan níbiṣẹ́ wa tàbí níléèwé wa ń bá wa tage, ṣé a máa yẹra fún onítọ̀hún, ká sì fi hàn pé lóòótọ́ la “ní ìdùnnú sí àwọn ọ̀nà” Jèhófà? (Òwe 23:26) Tó bá jẹ́ pé àwa nìkan ni Ẹlẹ́rìí nínú ìdílé wa, ṣé a máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa hùwà tó yẹ Kristẹni kódà báwọn míì kò bá tiẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé a máa ń gbàdúrà sí Jèhófà lójoojúmọ́, tá a sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìfẹ́ tó fi hàn sí wa àti bó ṣe mú wa wá sínú ètò rẹ̀? Ǹjẹ́ a máa ń wáyè ka Bíbélì lójoojúmọ́? Ó ṣe tan, àwọn nǹkan yìí wà lára ohun tá a ṣèlérí fún Jèhófà nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Torí náà, ó yẹ ká mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. Tá a bá ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà, tá a sì ń ṣègbọràn sí i, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé lóòótọ́ la ya ara wa sí mímọ́ fún un. Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé gbogbo apá ìgbésí ayé wa la ti ń fi hàn pé à ń jọ́sìn Jèhófà, kì í ṣe ìgbà tá a bá wà nípàdé tàbí òde ẹ̀rí nìkan. A máa jàǹfààní tá a bá mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ torí èyí á mú kí Jèhófà bù kún wa títí láé.—Diu. 10:12, 13.
13. Àwọn nǹkan wo la rí kọ́ nínú ìran kẹfà tí Sekaráyà rí?
13 Ìran kẹfà tí Sekaráyà rí ti jẹ́ ká rí i pé àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ò gbọ́dọ̀ jalè lọ́nà èyíkéyìí, a ò sì gbọ́dọ̀ búra èké. A kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ò jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sú òun bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ṣe ohun tó fẹ́. Bákan náà, Jèhófà mọ ìṣòro tí wọ́n ń kojú torí àwọn ọ̀tá tó yí wọn ká. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, èyí sì kọ́ wa pé káwa náà máa mú àwọn ìlérí tàbí ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. Ó jẹ́ kó dá wa lójú pé òun máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ torí ó ṣèlérí pé òun máa pa àwọn ẹni ibi run láìpẹ́. Ìran keje tí Sekaráyà rí mú kí èyí túbọ̀ dá wa lójú.
IBI TÓ TỌ́ NI WỌ́N GBÉ ÌWÀ BURÚKÚ LỌ
14, 15. (a) Kí ni Sekaráyà rí nínú ìran keje? (Wo àwòrán kejì tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí ni obìnrin tó wà nínú apẹ̀rẹ̀ yẹn dúró fún, kí sì nìdí tí wọ́n fi dé e mọ́nú apẹ̀rẹ̀ náà?
14 Lẹ́yìn tí Sekaráyà rí àkájọ ìwé tó ń fò, áńgẹ́lì kan sọ fún un pé, “gbé ojú rẹ sókè.” Kí ni Sekaráyà rí nínú ìran keje yìí? Ó rí apẹ̀rẹ̀ ńlá kan tí Bíbélì pè ní “òṣùwọ̀n eéfà” tí ń jáde lọ. (Ka Sekaráyà 5:5-8.) Apẹ̀rẹ̀ yìí ní “ọmọrí bìrìkìtì tí a fi òjé ṣe.” Nígbà tí wọ́n ṣí ọmọrí náà, Sekaráyà rí obìnrin kan tó jókòó sínú apẹ̀rẹ̀ náà. Áńgẹ́lì yẹn pe obìnrin náà ní “Ìwà Burúkú.” Kò sí àní-àní pé ẹ̀rù máa ba Sekaráyà nígbà tí obìnrin náà fẹ́ jáde nínú apẹ̀rẹ̀ náà. Kíá ni áńgẹ́lì yẹn tì í pa dà sínú apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọmọrí wíwúwo dé e pa. Kí ni ìran yìí túmọ̀ sí?
15 Ìran yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà kò ní fàyè gba ìwà burúkú èyíkéyìí láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. Kò ní jẹ́ kẹ́ni burúkú kó èèràn ran àwọn míì, kíá ló sì máa mú ìwà burúkú kúrò. (1 Kọ́r. 5:13) Bí áńgẹ́lì yẹn ṣe dé obìnrin náà mọ́nú apẹ̀rẹ̀ yẹn jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fàyè gba ìwà burúkú.
16. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí apẹ̀rẹ̀ òṣùwọ̀n eéfà tí Sekaráyà rí? (Wo àwòrán kẹta tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Ibo làwọn obìnrin tó ní ìyẹ́ lápá yẹn gbé apẹ̀rẹ̀ náà lọ?
16 Lẹ́yìn náà, Sekaráyà wá rí àwọn obìnrin méjì tí wọ́n ní ìyẹ́ apá bíi ti ẹyẹ àkọ̀. (Ka Sekaráyà 5:9-11.) Àwọn obìnrin yìí yàtọ̀ pátápátá sí obìnrin inú apẹ̀rẹ̀ yẹn. Àwọn obìnrin yìí fò lọ síbi tí apẹ̀rẹ̀ náà wà, wọ́n sì gbé apẹ̀rẹ̀ tí “Ìwà Burúkú” wà nínú rẹ̀. Ibo ni wọ́n ń gbé e lọ? “Ilẹ̀ Ṣínárì” tàbí Bábílónì ni wọ́n gbé e lọ. Àmọ́, kí nìdí tí wọ́n fi gbé apẹ̀rẹ̀ náà lọ sí Bábílónì?
17, 18. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ilẹ̀ Ṣínárì ló tọ́ kí “Ìwà Burúkú” máa gbé? (b) Kí ló yẹ ká pinnu tó bá kan ọ̀rọ̀ ìwà burúkú?
17 Lásìkò tí Sekaráyà gbáyé, ilẹ̀ Ṣínárì ló tọ́ kí Ìwà Burúkú máa gbé. Sekaráyà àtàwọn Júù bíi tiẹ̀ náà mọ̀ dáadáa pé ojúkò ìwà burúkú ni ìlú Bábílónì jẹ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ó ṣe tán, ibẹ̀ lọ̀pọ̀ wọn dàgbà sí, ìyẹn láàárín àwọn èèyàn tó ń bọ òrìṣà, tí ìwà búburú sì kún ọwọ́ wọn. Kódà, ojoojúmọ́ làwọn Júù yẹn ń sapá káwọn èèyàn náà má bàa kó èèràn ràn wọ́n. Ẹ wo bí ìran yẹn ṣe máa múnú wọn dùn tó! Jèhófà mú kó dá wọn lójú pé kò sí ohunkóhun tó máa ba ìjọsìn mímọ́ òun jẹ́!
18 Bó ti wù kó rí, ìran yẹn náà tún jẹ́ káwọn Júù mọ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ohunkóhun kò ba ìjọsìn mímọ́ wọn jẹ́. Ìwà burúkú èyíkéyìí kò gbọ́dọ̀ wáyé láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run, tó bá sì wáyé, wọn ò gbọ́dọ̀ fàyè gbà á. Ní báyìí táwa náà wà nínú ètò Jèhófà, tá a sì ń gbádùn ààbò àti ìfẹ́ rẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ẹ̀gbin èyíkéyìí nínú ètò náà. Ṣé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ kí ilé Jèhófà wà ní mímọ́? Kò sáyè fún ìwà burúkú èyíkéyìí nínú Párádísè tẹ̀mí tá a wà yìí.
ÀWỌN ÈÈYÀN MÍMỌ́ Ń BỌLÁ FÚN JÈHÓFÀ
19. Kí ni àwọn ìran tí Sekaráyà rí túmọ̀ sí fún wa lónìí?
19 Ìkìlọ̀ gidi ni ìran kẹfà àti keje tí Sekaráyà rí jẹ́ fún àwọn tó ń jalè tàbí tó ń hùwà àìṣòótọ́ èyíkéyìí. Ó tún rán wa létí pé Jèhófà kò ní fàyè gba ìwà burúkú èyíkéyìí. Bákan náà, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ kórìíra ìwà burúkú ní gbogbo ọ̀nà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìran yẹn tún jẹ́ káwọn ìlérí Baba wa ọ̀run túbọ̀ dá wa lójú. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti múnú Ọlọ́run dùn, a ò ní sí lára àwọn tí Jèhófà máa gégùn-ún fún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa dáàbò bò wá, á sì bù kún wa. Ká má ṣe jẹ́ kó sú wa bá a ṣe ń sapá láti wà ní mímọ́ nínú ayé búburú yìí torí pé ìsapá wa kò ní já sásán. Ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́ báwo la ṣe mọ̀ pé ìjọsìn tòótọ́ ló máa borí nínú ayé tó kún fún ìwà ìbàjẹ́ yìí? Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ bí ìpọ́njú ńlá ṣe ń sún mọ́lé? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.