Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Hágáì àti Ìwé Sekaráyà
ỌDÚN 520 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ìtàn yìí wáyé. Ó ti lé lọ́dún mẹ́rìndínlógún táwọn Júù tó dé láti ìgbèkùn Bábílónì ti fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì Jèhófà lélẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Síbẹ̀, wọn ò tíì kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí, àwọn ọ̀tá sì ti fòfin de iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Jèhófà wá yan wòlíì Hágáì láti sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì tún yan wòlíì Sekaráyà ní oṣù méjì lẹ́yìn ìyẹn.
Iṣẹ́ kan náà ni Ọlọ́run rán Hágáì àti Sekaráyà, iṣẹ́ ọ̀hún ni pé: Kí wọ́n fún àwọn èèyàn náà níṣìírí láti padà sẹ́nu iṣẹ́ títún tẹ́ńpìlì kọ́. Ìsapá àwọn wòlíì yìí yọrí sí rere, àwọn èèyàn náà sì kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí lọ́dún márùn-ún lẹ́yìn náà. Iṣẹ́ tí Hágáì àti Sekaráyà jẹ́ wà nínú àwọn ìwé tá a fi orúkọ wọn pè nínú Bíbélì. Hágáì parí kíkọ ìwé rẹ̀ ní ọdún 520 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Sekaráyà sì parí tirẹ̀ ní ọdún 518 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bíi táwọn wòlíì yìí, àwa náà ní iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wa, tá a ní láti parí kí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí tó dópin. Iṣẹ́ náà ni pé ká wàásù Ìjọba Ọlọ́run ká sì sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. Ẹ jẹ́ ká wo ìṣírí tá a lè rí gbà látinú ìwé Hágáì àti ìwé Sekaráyà.
“Ẹ FI ỌKÀN-ÀYÀ YÍN SÍ ÀWỌN Ọ̀NÀ YÍN”
Láàárín ọjọ́ méjìléláàádọ́fà [112] péré, Hágáì jẹ́ iṣẹ́ mẹ́rin tó ń múni jí gìrì. Iṣẹ́ àkọ́kọ́ ni pé: “‘Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí àwọn ọ̀nà yín. Ẹ gun orí òkè ńlá lọ, kí ẹ sì gbé igi gẹdú wá. Kí ẹ sì kọ́ ilé náà, kí n lè ní ìdùnnú nínú rẹ̀, kí a sì lè yìn mí lógo,’ ni Jèhófà wí.” (Hágáì 1:7, 8) Àwọn èèyàn náà ṣègbọràn. Ìlérí ni iṣẹ́ kejì jẹ́, ó ní: “Èmi [Jèhófà] yóò sì fi ògo kún ilé yìí.”—Hágáì 2:7.
Iṣẹ́ kẹta ni pé, báwọn èèyàn náà ṣe fi iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà sílẹ̀ láìṣe mú kí ‘àwọn àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn’ di aláìmọ́ lójú Jèhófà. Àmọ́ ṣá o, Jèhófà “yóò máa súre” fún wọn látọjọ́ tí iṣẹ́ àtúnṣe náà bá ti bẹ̀rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ kẹrin ti sọ, Jèhófà yóò “pa okun ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè rẹ́ ráúráú” yóò sì gbé Gómìnà Serubábélì kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “òrùka èdìdì.”—Hágáì 2:14, 19, 22, 23.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:6—Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn yìí, “ẹ ń mutí, ṣùgbọ́n kì í ṣe dórí mímu àmuyó”? Gbólóhùn yìí wulẹ̀ ń fi hàn pé ọtí wáìnì yóò ṣọ̀wọ́n. Nítorí pé Jèhófà kò bù kún àwọn èèyàn náà, wáìnì tí wọ́n ń ṣe kò ní pọ̀ tó. Dájúdájú wáìnì kò ní pọ̀ débi tí wọ́n á lè mu ún yó tí yòó sì máa pa wọ́n.
2:6, 7, 21, 22—Ta ni, tàbí kí ló fa ìmìjìgìjìgì, kí ló sì yọrí sí? Jèhófà ‘ń mi gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì’ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Iṣẹ́ ìwàásù náà tún mú kí “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” wá sínú ilé Jèhófà, tí wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ògo kún ilé náà. Láìpẹ́, “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” yóò mi “ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ jìgìjìgì,” èyí á sì mú kí gbogbo ètò àwọn nǹkan búburú yìí di èyí tí kò sí mọ́.—Hébérù 12:26, 27.
2:9—Àwọn ọ̀nà wo ni ‘ògo ilé ìkẹyìn fi pọ̀ ju ti àtijọ́’? Ó kéré tán, èyí jẹ́ ní ọ̀nà mẹ́ta: iye ọdún tí tẹ́ńpìlì náà fi wà, ẹni tó kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀, àtàwọn tó wá síbẹ̀ láti jọ́sìn Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́ńpìlì ológo tí Sólómọ́nì kọ́ wà fún okòó lé nírínwó [420] ọdún, ìyẹn láti ọdún 1027 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, síbẹ̀ iye ọdún tí wọ́n fi lo “ilé ìkẹyìn” lé ní okòó dín ní ẹgbẹ̀ta [580] ọdún, ìyẹn látìgbà tí wọ́n ti parí rẹ̀ lọ́dún 515 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ìgbà tó pa run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. Yàtọ̀ síyẹn, Mèsáyà, ìyẹn Jésù Kristi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nínú “ilé ìkẹyìn” náà, àwọn tó sì wá sínú rẹ̀ láti jọ́sìn Ọlọ́run pọ̀ ju àwọn tó wá sí ilé ti “àtijọ́” lọ.—Ìṣe 2:1-11.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:2-4. Kò yẹ kí àtakò sí iṣẹ́ ìwàásù wa mú ká lọ máa lépa àwọn nǹkan ti ara wa, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká gbájú mọ́ “wíwá ìjọba náà” “lákọ̀ọ́kọ́.”—Mátíù 6:33.
1:5, 7. Ó dára ká ‘fi ọkàn-àyà wa sí àwọn ọ̀nà wa’ ká sì máa ronú nípa bí ọ̀nà tá à ń gbà gbé ìgbésí ayé wa ṣe ń nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run.
1:6, 9-11; 2:14-17. Àwọn Júù ọjọ́ ayé Hágáì gbájú mọ́ iṣẹ́ tara wọn, síbẹ̀ wọn ò jẹ adùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọ́n pa iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì tì, nítorí náà wọn ò rí ìbùkún Ọlọ́run. A ní láti fi ìjọsìn wa sí Ọlọ́run ṣe ohun àkọ́kọ́ ká sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run tọkàntọkàn. Ká máa rántí pé yálà ohun díẹ̀ la ní tàbí ohun púpọ̀, ‘ìbùkún Jèhófà ni ń sọni di ọlọ́rọ̀.’—Òwe 10:22.
2:15, 18. Jèhófà rọ àwọn Júù láti fi ọkàn wọn sí iṣẹ́ títún tẹ́ńpìlì kọ́ láti ọjọ́ yẹn lọ, kì í ṣe pé kí wọ́n máa ronú nípa bí wọ́n ṣe pa iṣẹ́ náà tì tẹ́lẹ̀. Àwa náà ni láti sapá láti máa fi ọkàn wa sí ìjọsìn Jèhófà láti ìsinsìnyí lọ.
‘KÌ Í ṢE NÍPASẸ̀ AGBÁRA, BÍ KÒ ṢE NÍPASẸ̀ Ẹ̀MÍ MI’
Ohun tí Sekaráyà fi bẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tirẹ̀ ni pípe àwọn Júù láti ‘padà sọ́dọ̀ Jèhófà.’ (Sekaráyà 1:3) Ìran mẹ́jọ tí Sekaráyà rí lẹ́yìn náà fi hàn pé Ọlọ́run fọwọ́ sí iṣẹ́ títún tẹ́ńpìlì náà kọ́. (Wo àpótí náà, “Àpèjúwe Ni Ìran Mẹ́jọ Tí Sekaráyà Rí.”) Wọ́n á parí iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà, “kì í ṣe nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ológun, tàbí nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí [Jèhófà].” (Sekaráyà 4:6) Dájúdájú ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ìrújáde ‘yóò kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà,’ “yóò sì di àlùfáà lórí ìtẹ́ rẹ̀.”—Sekaráyà 6:12, 13.
Bẹ́tẹ́lì rán aṣojú lọ bá àwọn àlùfáà láti béèrè nípa ààwẹ̀ tí wọ́n máa ń fi ṣèrántí ìparun Jerúsálẹ́mù. Jèhófà sọ fún Sekaráyà pé ọ̀fọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe lákòókò ààwẹ̀ mẹ́rin tí wọ́n fi máa ń ṣe ìrántí àjálù tó bá Jerúsálẹ́mù yóò di “ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ àti àkókò àjọyọ̀ rere.” (Sekaráyà 7:2; 8:19) Àwọn ohun tó wà nínú ìkéde méjì tó tẹ̀ lé èyí ni ìdájọ́ tó máa wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn wòlíì èké, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà, àti ọ̀rọ̀ nípa mímú àwọn èèyàn Ọlọ́run padà bọ̀ sí ilẹ̀ wọn.—Sekaráyà 9:1; 12:1.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
2:1—Kí nìdí tí ọkùnrin kan fi ń fi okùn ìjàrá wọn Jerúsálẹ́mù? Ó dájú pé ohun tó ṣe yìí fi hàn pé wọ́n á kọ́ odi yí ìlú ńlá náà ká láti dáàbò bò ó. Áńgẹ́lì náà sọ fún ọkùnrin náà pé Jerúsálẹ́mù yóò fẹ̀ sí i, Jèhófà yóò sì dáàbò bò ó.—Sekaráyà 2:3-5.
6:11-13—Ǹjẹ́ fífi adé dé Jóṣúà Àlùfáà Àgbà lórí sọ ọ́ di ọba tó tún jẹ́ àlùfáà? Rárá o, Jóṣúà kò wá láti ìran Dáfídì tí wọ́n ti ń jọba. Àmọ́, fífi adé dé e lórí mú kó ṣàpẹẹrẹ Mèsáyà. (Hébérù 6:20) Àsọtẹ́lẹ̀ nípa “Ìrújáde” ní ìmúṣẹ sára Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba àti Àlùfáà lọ́run. (Jeremáyà 23:5) Nínú tẹ́ńpìlì tí wọ́n tún kọ́, Jóṣúà ṣiṣẹ́ àlùfáà àgbà fáwọn Júù tó ti ìgbèkùn dé, bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù Kristi ṣe jẹ́ Àlùfáà Àgbà fún ìjọsìn tòótọ́ nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tó jẹ́ ti Jèhófà.
8:1-23—Ìgbà wo ni ìkéde mẹ́wàá tó wà nínú àwọn ẹsẹ yìí nímùúṣẹ? Gbólóhùn tó ṣáájú ìkéde kọ̀ọ̀kan ni, “èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí” ó sì jẹ́ ìlérí àlàáfíà tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀. Àwọn kan lára àwọn ìkéde náà nímùúṣẹ ní ọ̀rúndún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ṣùgbọ́n gbogbo wọn ti ń nímùúṣẹ láti ọdún 1919 Sànmánì Kristẹni tàbí kí wọ́n máa nímùúṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.a
8:3—Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Jerúsálẹ́mù ní “ìlú ńlá òótọ́”? “Ìlú ńlá tí ń nini lára” ni Jerúsálẹ́mù kó tó pa run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn wòlíì àtàwọn àlùfáà rẹ̀ jẹ́ oníwà ìbàjẹ́, àwọn èèyàn ibẹ̀ sì jẹ́ aláìṣòótọ́. (Sefanáyà 3:1; Jeremáyà 6:13; 7:29-34) Àmọ́, nísinsìnyí tí wọ́n ti kọ́ tẹ́ńpìlì náà tán, táwọn èèyàn náà sì gbájú mọ́ ìjọsìn Jèhófà, ó dájú pé àwọn ohun tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ jẹ́ òtítọ́ nípa ìjọsìn mímọ́, wọ́n sì ń pe Jerúsálẹ́mù ní “ìlú ńlá òótọ́.”
11:7-14—Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Sekaráyà gé ọ̀pá tó pè ní “Adùn” àti èkejì tó pè ní “Ìrẹ́pọ̀” sí wẹ́wẹ́? Sekaráyà dúró fún ẹni tí wọ́n rán lọ láti “ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran tí a pète fún pípa,” ìyẹn àwọn èèyàn oníwà bí àgùntàn táwọn olórí wọn ń rẹ́ jẹ. Jíjẹ́ tí Sekaráyà jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ṣàpẹẹrẹ Jésù Kristi, tí Ọlọ́run rán sí àwọn èèyàn tó bá dá májẹ̀mú àmọ́ tí wọ́n kọ Jésù sílẹ̀. Gígé tó gé ọ̀pá tó ń jẹ́ “Adùn” sí wẹ́wẹ́ jẹ́ àmì pé Ọlọ́run yóò fòpin sí májẹ̀mú Òfin tó bá àwọn Júù dá, kò sì ní fìfẹ́ bá wọn lò mọ́. Gígé ọ̀pá tó ń jẹ́ “Ìrẹ́pọ̀” sí wẹ́wẹ́ túmọ̀ sí fífòpin sí àjọṣe tí ìjọsìn Jèhófà mú kó wà láàárín Júdà àti Ísírẹ́lì.
12:11—Kí ni “ìpohùnréré ẹkún Hadadirímónì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì Mẹ́gídò”? Wọ́n pa Jòsáyà Ọba Júdà nínú ìjà kan tó bá Fáráò Nékò ti Íjíbítì jà ní “pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì Mẹ́gídò,” ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n sì fi ‘kọrin arò’ láti ṣọ̀fọ̀ ikú rẹ̀. (2 Kíróníkà 35:25) Nítorí náà, “ìpohùnréré ẹkún Hadadirímónì” lè túmọ̀ sí bí wọ́n ṣe ṣọ̀fọ̀ ikú Jòsáyà.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:2-6; 7:11-14. Inú Jèhófà máa ń dùn láti padà sọ́dọ̀ àwọn tó bá ronú pìwà dà, tí wọ́n gba ìbáwí, tí wọ́n sì padà sọ́dọ̀ rẹ̀ nípa sísìn ín tọkàntọkàn. Àmọ́ ṣá o, Jèhófà kì í dáhùn nígbà táwọn tó ‘ń kọ̀ láti fiyè sílẹ̀, tí wọ́n ń bá a lọ láti gún èjìká, tí wọ́n sì mú etí wọn gíràn-án’ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá gbàdúrà sí i pé kó ran àwọn lọ́wọ́.
4:6, 7. Kò sí ìdènà kankan tí ẹ̀mí Jèhófà kò borí kí iṣẹ́ títún tẹ́ńpìlì náà kọ́ lè yọrí sí rere kó sì parí. Tá a bá nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, a lè borí ìṣòro èyíkéyìí tá a lè bá pàdé nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.—Mátíù 17:20.
4:10. Nítorí pé Serubábélì àtàwọn èèyàn rẹ̀ tẹ̀ lé ohun tí Jèhófà sọ, wọ́n parí iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà níbàámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run. Ṣíṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ kì í ṣe ohun tó nira jù fáwa èèyàn aláìpé.
7:8-10; 8:16, 17. Ká tó lè rí ojú rere Jèhófà, a ní láti ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu, ká ní inú rere onífẹ̀ẹ́, ká láàánú, ká sì máa sọ òtítọ́ fún ọmọnìkejì wa.
8:9-13. Jèhófà á fi ìbùkún sí iṣẹ́ wa bí ‘ọwọ́ wa bá lágbára’ nínú iṣẹ́ tó gbé fún wa láti ṣe. Lára àwọn ìbùkún yìí ni àlàáfíà, ààbò àti níní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run.
12:6. Ó yẹ káwọn tó jẹ́ alábòójútó láàárín àwọn èèyàn Jèhófà lónìí dà bí “ògùṣọ̀ oníná,” ìyẹn ni pé kí wọ́n ní ìtara tó ta yọ.
13:3. Ìṣòtítọ́ wa sí Ọlọ́run àti ètò rẹ̀ ní láti ju ìṣòtítọ́ wa sí ẹ̀dá èyíkéyìí lọ, bó ti wù kí ẹni náà sún mọ́ wa tó.
13:8, 9. Àwọn apẹ̀yìndà tí Jèhófà kọ̀ sílẹ̀ pọ̀ gan-an, ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ni wọ́n. Kìkì ìdá kan nínú mẹ́ta wọn ni a yọ́ mọ́ bíi pé iná ni a fi yọ́ wọn mọ́. Lákòókò tiwa yìí, Jèhófà kò tẹ́wọ́ gba àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ tó jẹ́ pé àwọn ló pọ̀ jù lára àwọn tó sọ pé Kristẹni làwọn. Kìkì àwọn díẹ̀, ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ‘ló ń ké pe orúkọ Jèhófà’ tí wọ́n sì gbà kí Jèhófà yọ́ àwọn mọ́. Àwọn ẹni àmì òróró yìí àtàwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ń fi hàn pé àwọn kì í ṣe ẹni tó ń fẹnu lásán jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ó Yẹ Ká Ní Ìtara
Báwo ni iṣẹ́ tí Hágáì àti Sekaráyà jẹ́ ṣe kàn wá lónìí? Tá a bá ronú lórí bí iṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ náà ṣe mú káwọn Júù gbájú mọ́ iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà, ǹjẹ́ kò yẹ kí èyí sún àwa náà láti fìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn?
Sekaráyà sàsọtẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà yóò “gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,” pé wọ́n á dà á ní “ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà,” pé wọ́n á lù ú, tí “agbo ẹran [yóò] sì tú ká.” (Sekaráyà 9:9; 11:12; 13:7) Ẹ ò rí i pé ṣíṣàṣàrò lórí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Sekaráyà sọ nípa Mèsáyà ń mú ìgbàgbọ́ wa lágbára! (Mátíù 21:1-9; 26:31, 56; 27:3-10) Ó mú kí ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Ọ̀rọ̀ Jèhófà àtàwọn ètò tó ṣe ká lè ní ìgbàlà túbọ̀ lágbára sí i.—Hébérù 4:12.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
ÀPÈJÚWE NI ÌRAN MẸ́JỌ TÍ SEKARÁYÀ RÍ
1:8-17: Ìran yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn Júù yóò kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà parí ó sì tún fi hàn pé Jèhófà yóò bù kún Jerúsálẹ́mù àtàwọn ìlú mìíràn nílẹ̀ Júdà.
1:18-21: Ìran yìí jẹ́ ìlérí pé ‘àwọn ìwo mẹ́rin tí ó fọ́n Júdà ká’ kò ní sí mọ́, ìyẹn gbogbo àwọn ìjọba tí kò fara mọ́ ìjọsìn Jèhófà.
2:1-13: Ìran yìí fi hàn pé Jerúsálẹ́mù yóò gbòòrò sí i àti pé Jèhófà yóò jẹ́ “ògiri iná fún un yí ká,” ìyẹn ni ààbò.
3:1-10: Ìran yìí fi hàn pé Sátánì ló wà nídìí àtakò tí wọ́n ṣe sí iṣẹ́ tẹ́ńpìlì náà àti pé Ọlọ́run dá Jóṣúà Àlùfáà Àgbà nídè ó sì wẹ̀ ẹ́ mọ́.
4:1-14: Ìran yìí mú un dá àwọn Júù lójú pé àwọn ìṣòro tó dà bí òkè yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti pé Gómìnà Serubábélì yóò parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà.
5:1-4: Ìran yìí gégùn-ún fún àwọn aṣebi tí wọ́n lọ láìjìyà.
5:5-11: Ìran yìí jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìwà ibi yóò dópin.
6:1-8: Ìran yìí jẹ́ ìlérí pé áńgẹ́lì yóò bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run, yóò sì dáàbò bò wọ́n.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Kí nìdí tí Hágáì àti Sekaráyà fi jẹ́ iṣẹ́ tí wọ́n jẹ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Báwo làwọn tó jẹ́ alábòójútó ṣe dà bí “ògùṣọ̀ oníná”?