Máa Fọkàn sí Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
“Ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà yín yóò wà pẹ̀lú.”—LÚÙKÙ 12:34.
1, 2. (a) Àwọn ìṣúra tẹ̀mí mẹ́ta wo ni Jèhófà fún wa? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
JÈHÓFÀ baba wa ọ̀run ló lọ́lá jù lọ láyé àti lọ́run. (1 Kíró. 29:11, 12) Torí pé ọ̀làwọ́ ni, tinútinú ló fi máa ń fáwa èèyàn lára ohun tó ní pàápàá jù lọ àwọn tó mọyì ọrọ̀ tẹ̀mí. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà fún wa láwọn ìṣúra tẹ̀mí! Lára wọn ni (1) Ìjọba Ọlọ́run, (2) iṣẹ́ ìwàásù tá a fi ń gbẹ̀mí là, àti (3) òtítọ́ tó ṣeyebíye tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́, tá ò bá kíyè sára, a lè má mọyì àwọn nǹkan yìí mọ́, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ pa wọ́n tì. Tá ò bá fẹ́ káwọn ìṣúra tẹ̀mí yìí bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ mọyì wọn, ká sì máa ṣìkẹ́ wọn nígbà gbogbo. Jésù sọ pé: “Ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà yín yóò wà pẹ̀lú.”—Lúùkù 12:34.
2 Ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, iṣẹ́ ìwàásù àti òtítọ́, àá sì tún jíròrò bá a ṣe lè mọyì wọn àti bá ò ṣe ní jẹ́ kí wọ́n bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, máa ronú lórí ohun tó o lè ṣe táá jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ìṣúra tẹ̀mí yìí.
ÌJỌBA ỌLỌ́RUN DÀ BÍI PÉÁLÌ TÓ ṢEYEBÍYE
3. Kí ni ọkùnrin oníṣòwò inú àkàwé Jésù múra tán láti ṣe kó lè rí péálì iyebíye náà rà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
3 Ka Mátíù 13:45, 46. Jésù ṣàkàwé nípa ọkùnrin oníṣòwò kan tó ń wá péálì. Ó dájú pé ọjọ́ pẹ́ tí oníṣòwò yìí ti máa ń ra ọ̀pọ̀lọpọ̀ péálì tó sì máa ń tà wọ́n. Àmọ́ ní báyìí, ó rí péálì kan tó ṣeyebíye gan-an débi pé nígbà tó fojú kàn án ṣe ló ń yọ̀. Àmọ́ tó bá máa rí péálì náà rà, ó máa ní láti ta gbogbo ohun tó ní. Ṣé ìwọ náà rí bí péálì tí ọkùnrin yẹn rí ti ṣeyebíye sí i tó?
4. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ìjọba Ọlọ́run bí oníṣòwò náà ṣe fẹ́ràn péálì yẹn, kí la ò ní ṣe?
4 Kí la rí kọ́ nínú àkàwé yìí? Òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run ló dà bíi péálì tó ṣeyebíye yẹn. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ìjọba Ọlọ́run bí oníṣòwò náà ṣe fẹ́ràn péálì yẹn, a ò ní gbà kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ àtidi ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, a ò sì ní kúrò lábẹ́ Ìjọba náà. (Ka Máàkù 10:28-30.) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn méjì tó ṣe bẹ́ẹ̀.
5. Kí ni Sákéù ṣe tó fi hàn pé ó fẹ́ jogún Ìjọba Ọlọ́run?
5 Ọ̀gá àwọn agbowó orí ni Sákéù, ó sì lówó gan-an torí pé ó máa ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ. (Lúùkù 19:1-9) Síbẹ̀, nígbà tí ọkùnrin aláìṣòótọ́ yẹn gbọ́ ìwàásù Jésù nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó mọyì ohun tó gbọ́ gan-an, ó sì gbé ìgbésẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó sọ pé: “Wò ó! Olúwa, ìdajì nǹkan ìní mi ni èmi yóò fi fún àwọn òtòṣì, ohun yòówù tí mo sì lọ́ ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ gbà nípasẹ̀ ẹ̀sùn èké ni èmi yóò dá padà ní ìlọ́po mẹ́rin.” Gbogbo nǹkan tó fèrú kó jọ ló fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda, ó sì jáwọ́ nínú ìgbésí ayé oníwọra tó ń gbé.
6. Àwọn ìyípadà wo ni obìnrin kan ṣe kó lè di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, kí sì nìdí tó sì fi ṣe bẹ́ẹ̀?
6 Kó tó di pé obìnrin kan bá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé, òun àti obìnrin míì jọ ń fẹ́ra. Kódà, òun ni ààrẹ ẹgbẹ́ kan tó ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Àmọ́ bó ṣe n bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ, ó wá mọ bí òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó. Ìyẹn mú kó rí i pé òun gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà tó lágbára. (1 Kọ́r. 6:9, 10) Torí náà, ó fi ẹgbẹ́ tó wà sílẹ̀, ó sì tún fi obìnrin tó ń fẹ́ sílẹ̀. Nígbà tó dọdún 2009, ó ṣèrìbọmi, ó sì di aṣáájú-ọ̀nà déédéé lọ́dún tó tẹ̀ lé e. Ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà àti Ìjọba Ọlọ́run mú kó borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó ní.—Máàkù 12:29, 30.
7. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí ìfẹ́ tá a ní fún Ìjọba Ọlọ́run má bàa di tútù?
7 Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ wa ti ṣe àwọn àyípadà kan ká lè di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Róòmù 12:2) Àmọ́ bíná ò bá tán láṣọ, ẹ̀jẹ̀ kì í tán léèékánná. A gbọ́dọ̀ kíyè sára kó má lọ di pé àwọn nǹkan bí ìfẹ́ ọrọ̀ tàbí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara máa gbà wá lọ́kàn débi tí ìfẹ́ tá a ní fún Ìjọba Ọlọ́run máa wá di tútù. (Òwe 4:23; Mát. 5:27-29) Kí èyí má bàa ṣẹlẹ̀, Jèhófà ti fún wa ní ìṣúra míì tí ò ṣeé fowó rà.
IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ TÁ A FI Ń GBẸ̀MÍ LÀ
8. (a) Kí nìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé iṣẹ́ ìwàásù dà bí ‘ìṣúra nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe’? (b) Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù?
8 Jésù pàṣẹ fún wa pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ká sì máa kọ́ni. (Mát. 28:19, 20) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà mọ̀ pé iṣẹ́ tó yẹ kéèyàn fọwọ́ pàtàkì mú ni iṣẹ́ ìwàásù. Ìdí nìyẹn tó fi ka àǹfààní tó ní láti wàásù nípa májẹ̀mú tuntun sí ‘ìṣúra nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe.’ (2 Kọ́r. 4:7; 1 Tím. 1:12) Lóòótọ́ aláìpé ni wá, a sì dà bí ohun èlò tá a fi amọ̀ ṣe. Síbẹ̀, ìhìn rere tá à ń polongo jẹ́ ìṣúra torí pé ó lè mú kí àwa àtàwọn tó ń tẹ́tí sí wa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Pọ́ọ̀lù náà mọ èyí, ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Mo ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.” (1 Kọ́r. 9:23) Torí pé Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Ka Róòmù 1:14, 15; 2 Tímótì 4:2.) Èyí mú kó lè fara da àwọn àtakò tó lékenkà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (1 Tẹs. 2:2) Báwo làwa náà ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù bíi ti Pọ́ọ̀lù?
9. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù?
9 Ọ̀nà kan tí Pọ́ọ̀lù gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù ni pé ó máa ń lo gbogbo àǹfààní tó bá yọjú láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Bíi tàwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni ìgbàanì, àwa náà máa ń wàásù láti ilé dé ilé, níbi térò pọ̀ sí àti lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. (Ìṣe 5:42; 20:20) Bí ipò wa bá ṣe gbà, àwa náà lè ronú lórí àwọn ọ̀nà tá a lè gbà ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, a lè gba aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí ká tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. A tún lè kọ́ èdè míì tàbí ká lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ lórílẹ̀-èdè wa tàbí lórílẹ̀-èdè míì.—Ìṣe 16:9, 10.
10. Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún Irene nítorí ìtara tó lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
10 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Irene. Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ń gbé, kò sì lọ́kọ. Ó wù ú gan-an pé kó máa wàásù fáwọn tó ń sọ èdè Rọ́ṣíà tí wọ́n ṣí wá sí Amẹ́ríkà. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún wọn lọ́dún 1993, nǹkan bí akéde ogún [20] péré ló wà nínú àwùjọ tó ń sọ èdè Rọ́ṣíà nílùú New York City. Nǹkan bí ogún [20] ọdún ni Irene fi ṣiṣẹ́ kára láti wàásù fáwọn tó ń sọ èdè yẹn. Síbẹ̀, ó sọ pé: “Mi ò tíì lè sọ èdè Rọ́ṣíà dáadáa.” Bó ti wù kó rí, Jèhófà bù kún iṣẹ́ tó ṣe àti tàwọn míì tó fi irú ẹ̀mí rere bẹ́ẹ̀ hàn. Ní báyìí, ìjọ mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ń sọ èdè Rọ́ṣíà ló wà nílùú New York City. Mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] nínú àwọn tí Irene kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ló ti ṣèrìbọmi. Àwọn kan nínú wọn ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, aṣáájú-ọ̀nà làwọn kan, àwọn míì sì jẹ́ alàgbà. Irene wá sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan míì ni mo lè fayé mi ṣe, àmọ́ kò séyìí tó lè fún mi láyọ̀ bí èyí tí mò ń ṣe yìí.” Ká sòótọ́, Irene mọyì iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe!
11. Kí ló máa yọrí sí tá ò bá juwọ́ sílẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa láìka àtakò sí?
11 Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, táwa náà bá mọyì iṣẹ́ ìwàásù, àá máa wàásù nìṣó láìka àtakò sí. (Ìṣe 14:19-22) Láwọn ọdún 1930 àti apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1940, àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kojú ọ̀pọ̀ àtakò àti inúnibíni. Àmọ́ bíi ti Pọ́ọ̀lù, wọ́n dúró gbọin láìyẹsẹ̀, wọ́n sì ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ. Ká lè gbèjà ẹ̀tọ́ tá a ní láti wàásù, àwọn arákùnrin máa ń lọ sí kóòtù. Lọ́dún 1943, Arákùnrin Nathan H. Knorr sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ẹjọ́ tá a jàre ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ó ní: “Ẹ̀yin lẹ jẹ́ ká jàre àwọn ẹjọ́ yìí. Ká ní ẹ̀yin akéde ti dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró ni, kò bá má sí ẹjọ́ tá a fẹ́ gbé lọ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, àmọ́ torí pé gbogbo ẹ̀yin akéde, àti gbogbo àwọn ará kárí ayé ń báṣẹ́ lọ láìjuwọ́ sílẹ̀ la fi ń jàre nílé ẹjọ́. Ìdúróṣinṣin àwọn èèyàn Ọlọ́run ló mú kí wọ́n dá wa láre.” Báwọn ará wa láwọn orílẹ̀-èdè yòókù ṣe dúró gbọin láìyẹsẹ̀ náà ti mú ká jàre àwọn ẹjọ́ míì. Torí náà, ó ṣe kedere pé tá ò bá jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún iṣẹ́ ìwàásù di tútù, a máa borí àtakò.
12. Kí lo pinnu pé wàá máa ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
12 Tá a bá ka iṣẹ́ ìwàásù sí ìṣúra tó ṣeyebíye tí Jèhófà fún wa, kì í ṣe wákàtí tá a fẹ́ ròyìn níparí oṣù ló máa ṣe pàtàkì jù sí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.” (Ìṣe 20:24; 2 Tím. 4:5) Àmọ́, kí la máa kọ́ àwọn èèyàn? Ẹ jẹ́ ká wo ìṣúra míì tí Ọlọ́run fún wa.
ÒTÍTỌ́ TÓ ṢEYEBÍYE TÍ JÈHÓFÀ KỌ́ WA
13, 14. Kí ni “ibi ìtọ́jú ìṣúra” tí Jésù sọ nínú Mátíù 13:52, báwo la sì ṣe máa kó nǹkan sínú rẹ̀?
13 Ìṣúra kẹta tí Jèhófà fún wa ni gbogbo òtítọ́ tá a ti kọ́. Jèhófà ni Ọlọ́run òtítọ́. (2 Sám. 7:28; Sm. 31:5) Torí pé ọ̀làwọ́ ni, ó máa ń jẹ́ káwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ mọ òtítọ́ inú Bíbélì. Àtìgbà tí wọ́n ti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ la ti ń ṣìkẹ́ àwọn ohun tá à ń kọ́, ì bá à jẹ́ látinú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí nínú àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, àwọn àpéjọ àgbègbè àti àyíká, tàbí láwọn ìpàdé ìjọ. Bá a ṣe ń gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ látìgbà yẹn la ti ní ohun tí Jésù pè ní “ibi ìtọ́jú ìṣúra,” ibẹ̀ la sì ń kó àwọn òtítọ́ tá a mọ̀ sí, yálà ògbólógbòó tàbí tuntun. (Ka Mátíù 13:52.) Tá a bá ń wá àwọn òtítọ́ náà kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti gba àwọn òtítọ́ tuntun tó ṣeyebíye sínú “ibi ìtọ́jú ìṣúra” wa. (Ka Òwe 2:4-7.) Àmọ́, báwo la ṣe máa ṣe bẹ́ẹ̀?
14 A gbọ́dọ̀ máa dá kẹ́kọ̀ọ́ ká sì máa ṣe ìwádìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde wa. Èyí ló máa jẹ́ ká ṣàwárí àwọn òtítọ́ tá a lè pè ní “tuntun” torí pé a ò lóye wọn tẹ́lẹ̀. (Jóṣ. 1:8, 9; Sm. 1:2, 3) Ẹ̀dà àkọ́kọ́ Ilé Ìṣọ́ tá a tẹ̀ ní July 1879 sọ pé: “Òtítọ́ dà bí òdòdó kékeré kan nínú aginjù tí àwọn ẹ̀kọ́ èké tó dà bí èpò yí ká, tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ fún òdòdó náà pa. Tó o bá fẹ́ já òdòdó náà, o gbọ́dọ̀ wà lójúfò. . . . Bí ìwọ bá fẹ́ rí i já, o ní láti lóṣòó. Má ṣe jẹ́ kí òdòdó kan ṣoṣo nípa òtítọ́ tẹ́ ọ lọ́rùn. . . . Túbọ̀ máa kó o jọ, kó o sì máa wá púpọ̀ sí i.” Torí náà, ó yẹ kó máa yá wa lára láti wá ìmọ̀ kún ìmọ̀ kí òtítọ́ tó wà nínú ìṣúra wa lè pọ̀ sí i.
15. Kí nìdí tá a fi lè pe àwọn òtítọ́ kan ní “ògbólógbòó,” èwo ló sì wọ̀ ẹ́ lọ́kàn jù nínú wọn?
15 Ìgbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run la túbọ̀ ń lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣeyebíye. A lè pe àwọn nǹkan tá a kọ́ nígbà yẹn ní “ògbólógbòó” torí pé ìbẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wa lójú ọ̀nà òtítọ́ la ti mọ̀ wọ́n, tá a sì mọyì wọn. Kí ni díẹ̀ lára àwọn òtítọ́ tó ṣeyebíye yìí? A kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, òun ni Olùfúnni-ní-ìyè, àti pé ó nídìí tó fi dá àwa èèyàn. A tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run tipasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ pèsè ìràpadà fún wa ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Láfikún síyẹn, a tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn, a sì nírètí àtigbé títí láé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run níbi tá a ti máa láyọ̀ tí àlàáfíà sì máa jọba.—Jòh. 3:16; Ìṣí. 4:11; 21:3, 4.
16. Kí ló yẹ ká ṣe tí àtúnṣe bá bá òye òtítọ́ tá a ní?
16 Látìgbàdégbà ni àtúnṣe máa ń bá òye tá a ní nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tàbí àwọn àlàyé tá a ṣe lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. Tírú ìlàlóye bẹ́ẹ̀ bá wáyé, ó yẹ ká fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ wọn, ká sì ṣàṣàrò nípa wọn. (Ìṣe 17:11; 1 Tím. 4:15) Bá a ṣe ń sapá láti lóye àwọn àtúnṣe tó ṣe gbòógì, bẹ́ẹ̀ náà làá gbìyànjú láti lóye àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ tó wà láàárín òye tá a ní tẹ́lẹ̀ àti òye tuntun. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fi àwọn òtítọ́ tuntun náà síbi ìṣúra wa, a sì ń dáàbò bò ó. Kí nìdí tíyẹn fi bọ́gbọ́n mu?
17, 18. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
17 Jésù sọ pé ẹ̀mí Ọlọ́run máa rán wa létí àwọn ohun tá a ti kọ́. (Jòh. 14:25, 26) Báwo nìyẹn ṣe máa ṣèrànwọ́ fún àwa tá à ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Peter. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] ni lọ́dún 1970, kò sì pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Lọ́jọ́ kan tó ń wàásù láti ilé dé ilé, ó pàdé aṣáájú ẹ̀sìn Júù kan. Peter béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin náà bóyá ó máa fẹ́ lóye Bíbélì. Ìbéèrè yìí ya ọkùnrin náà lẹ́nu, ó wá sọ pé ṣé o kò mọ̀ pé ilé àwọn rábì nìyí ni? Àmọ́ kó lè dán Peter wò, ó bi í pé: “Ọmọ dáadáa, èdè wo lo rò pé wọ́n fi kọ ìwé Dáníẹ́lì?” Peter sọ pé: “Èdè Árámáíkì ni wọ́n fi kọ apá kan nínú rẹ̀.” Peter wá sọ pé: “Ẹnu ya rábì náà gan-an pé mo mọ ìdáhùn, àmọ́ ẹnu kò yà á tó mi! Báwo ni mo ṣe mọ ìdáhùn ìbéèrè náà? Nígbà tí mo délé, mo lọ wo àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí mo ti kà láwọn oṣù mélòó kan sẹ́yìn, mo sì rí àpilẹ̀kọ kan tó sọ pé èdè Árámáíkì ni wọ́n fi kọ ìwé Dáníẹ́lì.” (Dán. 2:4) Ó ṣe kedere pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà lè mú ká rántí àwọn ohun tá a ti kọ́ tẹ́lẹ̀ tá a sì ti fi síbi ìṣúra wa.—Lúùkù 12:11, 12; 21:13-15.
18 Tá a bá mọyì òtítọ́ tí Jèhófà ń kọ́ wa, òye tá a ní á túbọ̀ máa pọ̀ sí i, yálà àwọn òye tuntun tá a ní tàbí àwọn òye tá a ti ní tẹ́lẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àá máa fi kún ìṣúra wa. Bá a bá sì ṣe ń nífẹ̀ẹ́ àwọn òtítọ́ yìí tá a sì ń mọyì wọn, ṣe la máa túbọ̀ jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
DÁÀBÒ BO ÌṢÚRA RẸ
19. Kí nìdí tó fi yẹ ká dáàbò bo ìṣúra tẹ̀mí wa?
19 Gbogbo ọ̀nà ni Sátánì àtàwọn èèyàn inú ayé búburú yìí ń wá láti mú ká dẹwọ́ ká má sì mọyì àwọn ìṣúra tẹ̀mí tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí. Torí náà, ká má ṣe ronú láé pé irú ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ sí wa. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa wù wá láti ṣe iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wọlé, ó sì lè máa wù wá pé lọ́jọ́ kan káwa náà máa náwó yàfùnyàfùn tàbí ká fẹ́ káwọn èèyàn máa kan sárá sí wa torí ohun tá a ní. Àmọ́, àpọ́sítélì Jòhánù rán wa létí pé ayé yìí ń kọjá lọ àtàwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1 Jòh. 2:15-17) Torí náà, a gbọ́dọ̀ sapá láti rí i pé a ò gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè, ká má sì jẹ́ kí ìmọrírì wa àti ìfẹ́ tá a ní fún àwọn ìṣúra tẹ̀mí yingin.
20. Kí lo pinnu pé wàá ṣe kó o lè dáàbò bo ìṣúra tẹ̀mí rẹ?
20 Já ara rẹ gbà lọ́wọ́ ohunkóhun tó lè mú kó o fi Ìjọba Ọlọ́run sípò kejì. Máa fìtara wàásù nìṣó, má sì jẹ́ kó sú ẹ láé torí pé iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà ni. Máa wá ìmọ̀ kún ìmọ̀ nínú Bíbélì. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa to ìṣúra jọ sí ọ̀run ‘níbi tí olè kò lè dé tàbí kí òólá jẹ run. Nítorí ibi tí ìṣúra rẹ bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà rẹ yóò wà pẹ̀lú.’—Lúùkù 12:33, 34.