Àkọsílẹ̀ Máàkù
10 Ó gbéra níbẹ̀ wá sí ààlà ilẹ̀ Jùdíà ní òdìkejì Jọ́dánì, àwọn èrò tún kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn, bó ṣe máa ń ṣe.+ 2 Àwọn Farisí wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n fẹ́ dán an wò, wọ́n sì bi í bóyá ó bófin mu fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀.+ 3 Ó dá wọn lóhùn pé: “Kí ni Mósè pa láṣẹ fún yín?” 4 Wọ́n sọ pé: “Mósè fàyè gba ká kọ ìwé ẹ̀rí láti lé e lọ, ká sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”+ 5 Àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé: “Torí pé ọkàn yín le+ ló ṣe kọ àṣẹ yìí fún yín.+ 6 Ṣùgbọ́n ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá, ‘Ó dá wọn ní akọ àti abo.+ 7 Torí èyí, ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀,+ 8 àwọn méjèèjì á sì di ara kan,’+ tó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, àmọ́ wọ́n jẹ́ ara kan. 9 Torí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á.”+ 10 Nígbà tí wọ́n tún wà nínú ilé, àwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í bi í nípa ọ̀rọ̀ yìí. 11 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè,+ ó ti da obìnrin náà, 12 tí obìnrin kan bá sì lọ fẹ́ ọkùnrin míì, lẹ́yìn tó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, ó ti ṣe àgbèrè.”+
13 Àwọn èèyàn wá bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kó lè fọwọ́ kàn wọ́n, àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn bá wọn wí.+ 14 Nígbà tí Jésù rí èyí, inú bí i, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má sì dá wọn dúró, torí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irú wọn.+ 15 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé ẹnikẹ́ni tí kò bá gba Ìjọba Ọlọ́run bí ọmọdé kò ní wọnú rẹ̀.”+ 16 Ó wá gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í súre fún wọn, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.+
17 Bó ṣe ń lọ, ọkùnrin kan sáré wá, ó sì kúnlẹ̀ síwájú rẹ̀, ó bi í pé: “Olùkọ́ Rere, kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 18 Jésù sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kankan, àfi Ọlọ́run nìkan.+ 19 O mọ àwọn àṣẹ náà pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ pààyàn,+ o ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,+ o ò gbọ́dọ̀ jalè,+ o ò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké,+ o ò gbọ́dọ̀ lu jìbìtì,+ bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ.’”+ 20 Ọkùnrin náà sọ fún un pé: “Olùkọ́, gbogbo nǹkan yìí ni mo ti ń ṣe láti ìgbà ọ̀dọ́ mi.” 21 Jésù wò ó, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó wá sọ fún un pé, “Ohun kan wà tí o ò tíì ṣe: Lọ, kí o ta àwọn ohun tí o ní, kí o fún àwọn aláìní, wàá sì ní ìṣúra ní ọ̀run; kí o wá máa tẹ̀ lé mi.”+ 22 Àmọ́ inú ọkùnrin náà ò dùn torí èsì tó fún un, ó sì fi ìbànújẹ́ kúrò, torí ohun ìní rẹ̀ pọ̀.+
23 Lẹ́yìn tí Jésù wò yí ká, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ wo bó ṣe máa ṣòro tó fún àwọn olówó láti wọ Ìjọba Ọlọ́run!”+ 24 Àmọ́ ohun tó sọ ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́nu. Jésù wá sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ wo bó ṣe ṣòro tó láti wọ Ìjọba Ọlọ́run! 25 Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá ju fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run.”+ 26 Ẹnu túbọ̀ yà wọ́n, wọ́n sì sọ fún un* pé: “Ta ló máa wá lè rígbàlà?”+ 27 Jésù wò wọ́n tààrà, ó sì sọ pé: “Lójú èèyàn, kò ṣeé ṣe, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ lójú Ọlọ́run, torí ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”+ 28 Pétérù wá sọ fún un pé: “Wò ó! A ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì ti tẹ̀ lé ọ.”+ 29 Jésù sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, kò sí ẹni tó fi ilé tàbí àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, ìyá, bàbá, àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá sílẹ̀ nítorí mi àti nítorí ìhìn rere,+ 30 tí kò ní gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100) àwọn ilé, àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, àwọn ìyá, àwọn ọmọ àti àwọn pápá, pẹ̀lú àwọn inúnibíni ní báyìí+ àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀.* 31 Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ máa di ẹni ìkẹyìn, àwọn ẹni ìkẹyìn sì máa di ẹni àkọ́kọ́.”+
32 Bí wọ́n ṣe ń lọ lójú ọ̀nà sí Jerúsálẹ́mù, Jésù ń lọ níwájú wọn, ẹnu yà wọ́n, àwọn tí wọ́n tẹ̀ lé e bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù. Ló bá tún pe àwọn Méjìlá náà sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn nǹkan tó máa tó ṣẹlẹ̀ sí i fún wọn, ó ní:+ 33 “Ẹ wò ó! À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì máa fa Ọmọ èèyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́. Wọ́n máa dájọ́ ikú fún un, wọ́n sì máa fà á lé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, 34 àwọn yìí máa fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n máa tutọ́ sí i lára, wọ́n máa nà án, wọ́n á sì pa á, àmọ́ ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà ló máa dìde.”+
35 Jémíìsì àti Jòhánù, àwọn ọmọ Sébédè,+ wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: “Olùkọ́, a fẹ́ kí o ṣe ohunkóhun tí a bá béèrè lọ́wọ́ rẹ fún wa.”+ 36 Ó sọ fún wọn pé: “Kí lẹ fẹ́ kí n ṣe fún yín?” 37 Wọ́n fèsì pé: “Gbà wá láyè ká jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ, nínú ògo rẹ.”+ 38 Àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ ò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè. Ṣé ẹ lè mu ife tí mò ń mu àbí a lè batisí yín bí a ṣe ń batisí mi?”+ 39 Wọ́n sọ fún un pé: “A lè mu ún.” Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa mu ife tí mò ń mu, a sì máa batisí yín bí a ṣe ń batisí mi.+ 40 Àmọ́ èmi kọ́ ló máa sọ ẹni tó máa jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi tàbí sí òsì mi, ṣùgbọ́n ó máa wà fún àwọn tí a ti ṣètò rẹ̀ fún.”
41 Nígbà tí àwọn mẹ́wàá yòókù gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n bínú sí Jémíìsì àti Jòhánù.+ 42 Àmọ́ Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ mọ̀ pé àwọn tí wọ́n kà sí* àwọn alákòóso orílẹ̀-èdè máa ń jẹ ọ̀gá lé àwọn èèyàn lórí, àwọn èèyàn ńlá wọn sì máa ń lo àṣẹ lórí wọn.+ 43 Kò gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀ láàárín yín; àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ yín,+ 44 ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú gbogbo yín. 45 Torí Ọmọ èèyàn pàápàá kò wá ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ kó lè ṣe ìránṣẹ́,+ kó sì fi ẹ̀mí* rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”+
46 Wọ́n wá dé Jẹ́ríkò. Àmọ́ bí òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń kúrò ní Jẹ́ríkò, Báátíméù (ọmọ Tíméù), afọ́jú tó ń ṣe agbe, jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà.+ 47 Nígbà tó gbọ́ pé Jésù ará Násárẹ́tì ni, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe, ó sì ń sọ pé: “Ọmọ Dáfídì,+ Jésù, ṣàánú mi!”+ 48 Ni ọ̀pọ̀ èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí, wọ́n ní kó dákẹ́, àmọ́ ṣe ló túbọ̀ ń kígbe pé: “Ọmọ Dáfídì, ṣàánú mi!” 49 Torí náà, Jésù dúró, ó sì sọ pé: “Ẹ pè é wá sọ́dọ̀ mi.” Wọ́n wá pe ọkùnrin afọ́jú náà, wọ́n sọ fún un pé: “Mọ́kàn le! Dìde; ó ń pè ọ́.” 50 Ló bá bọ́ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ dà nù, ó fò dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Jésù. 51 Jésù wá sọ fún un pé: “Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” Ọkùnrin afọ́jú náà sọ fún un pé: “Rábónì,* jẹ́ kí n pa dà ríran.” 52 Jésù sì sọ fún un pé: “Máa lọ. Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó pa dà ríran,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e lójú ọ̀nà.