ORÍ 43
Àwọn Àpèjúwe Nípa Ìjọba Ọlọ́run
MÁTÍÙ 13:1-53 MÁÀKÙ 4:1-34 LÚÙKÙ 8:4-18
JÉSÙ ṢE ÀWỌN ÀPÈJÚWE NÍPA ÌJỌBA ỌLỌ́RUN
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Kápánáúmù ni Jésù wà lọ́jọ́ tó bá àwọn Farisí wí. Nígbà tó yá, ó kúrò nílé ó sì lọ sí etíkun Gálílì níbi táwọn èrò péjọ sí. Ó wọnú ọkọ̀ ojú omi kan, ó ní kí wọ́n wa ọkọ̀ náà sínú díẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn náà nípa Ìjọba ọ̀run. Ó lo onírúurú àkàwé tàbí àpèjúwe nígbà tó ń kọ́ wọn. Àwọn ohun tí Jésù fi ṣàkàwé ò ṣàjèjì sáwọn èèyàn, torí náà ó rọrùn fún wọn láti lóye àwọn àpèjúwe tó ṣe nípa Ìjọba Ọlọ́run.
Lákọ̀ọ́kọ́, ó ṣàpèjúwe nípa afúnrúgbìn kan tó jáde lọ fún irúgbìn. Lára irúgbìn náà já bọ́ sí etí ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì ṣà á jẹ. Àwọn míì já bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí iyẹ̀pẹ̀. Gbòǹgbò ẹ̀ ò wọnú ilẹ̀ dáadáa, torí náà ó rọ nígbà tí oòrùn ràn. Àwọn míì já bọ́ sáàárín ẹ̀gún, wọ́n sì fún irúgbìn náà pa. Níkẹyìn, àwọn kan já bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í so èso, “eléyìí so ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100), ìyẹn ọgọ́ta (60), òmíràn ọgbọ̀n (30).”—Mátíù 13:8.
Nínú àpèjúwe míì, Jésù fi Ìjọba Ọlọ́run wé ọkùnrin kan tó ń fún irúgbìn. Yálà ọkùnrin náà sùn tàbí kò sùn, irúgbìn náà hù. Àmọ́ báwo ló ṣe hù? Ọkùnrin náà “kò mọ bó ṣe ṣẹlẹ̀.” (Máàkù 4:27) Àwọn irúgbìn náà hù fúnra wọn, wọ́n sì so èso tí ọkùnrin náà máa kórè.
Àpèjúwe kẹta tí Jésù ṣe tún dá lórí ẹni tó fúnrúgbìn. Ó ní, ọkùnrin kan fún irúgbìn tó dáa, àmọ́ “nígbà tí àwọn èèyàn ń sùn,” ọ̀tá rẹ̀ wá, ó sì gbin èpò sí àárín àlìkámà tó gbìn. Àwọn ẹrú ọkùnrin náà bí i pé ṣé káwọn lọ fa èpò náà tu. Ó wá sọ fún wọn pé: “Rárá, torí kí ẹ má bàa hú àlìkámà pẹ̀lú èpò nígbà tí ẹ bá ń kó èpò jọ. Ẹ jẹ́ kí méjèèjì jọ dàgbà títí dìgbà ìkórè, tó bá wá dìgbà ìkórè, màá sọ fún àwọn tó ń kórè pé: Ẹ kọ́kọ́ kó àwọn èpò jọ, kí ẹ sì dì wọ́n ní ìdìpọ̀-ìdìpọ̀ láti sun wọ́n; kí ẹ wá kó àlìkámà jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí mi.”—Mátíù 13:24-30.
Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń tẹ́tí sí Jésù ló mọ̀ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀. Torí náà, ó tún sọ nǹkan míì tí wọ́n mọ̀ dáadáa, ìyẹn hóró músítádì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó kéré gan-an, ó máa ń dàgbà di igi ńlá, débi pé àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run máa ń gbé láàárín àwọn ẹ̀ka rẹ̀. Jésù sọ pé: “Ìjọba ọ̀run dà bíi hóró músítádì kan, tí ọkùnrin kan mú, tó sì gbìn sínú pápá rẹ̀.” (Mátíù 13:31) Àmọ́ kì í ṣe ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ewéko ni Jésù ń kọ́ wọn o. Ó wulẹ̀ ń ṣàlàyé bí nǹkan tó kéré gan-an ṣe lè di ńlá.
Jésù tún sọ̀rọ̀ nípa nǹkan míì táwọn tó ń gbọ́ ọ mọ̀ dáadáa. Ó fi Ìjọba Ọlọ́run wé “ìwúkàrà, èyí tí obìnrin kan mú, tó sì pò mọ́ ìyẹ̀fun tó kún òṣùwọ̀n ńlá mẹ́ta.” (Mátíù 13:33) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èèyàn ò lè rí bí ìwúkàrà náà ṣe ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n bá ti pò ó mọ́ ìyẹ̀fun, gbogbo ìyẹ̀fun náà ló máa wú. Ó máa ń mú kí nǹkan pọ̀, ó sì lè yí nǹkan pa dà lọ́nà táwọn èèyàn ò ní tètè kíyè sí.
Lẹ́yìn tí Jésù sọ àwọn àpèjúwe yìí tán, ó ní káwọn èèyàn náà máa lọ, ó sì pa dà síbi tó dé sí. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn làwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé kó ṣàlàyé ohun táwọn àpèjúwe náà túmọ̀ sí fún wọn.
WỌ́N KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ ÀPÈJÚWE JÉSÙ
Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọ ẹ̀yìn ti gbọ́ àwọn àpèjúwe tí Jésù ṣe, àmọ́ kò lo àpèjúwe tó pọ̀ tó báyìí rí. Wọ́n wá bi í pé: “Kí ló dé tí ò ń fi àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀?”—Mátíù 13:10.
Ìdí kan ni pé ó fẹ́ mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Nínú àkọsílẹ̀ Mátíù, a kà pé: “Kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìlo àpèjúwe, kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé: ‘Màá la ẹnu mi láti sọ àpèjúwe; màá kéde àwọn ohun tó pa mọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀.’”—Mátíù 13:34, 35; Sáàmù 78:2.
Àmọ́ ìdí míì tún wà tó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ó máa ń lo àpèjúwe kó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn gan-an. Ohun tó fa ọ̀pọ̀ èèyàn mọ́ra ò ju bí Jésù ṣe ń sọ ìtàn, tó sì ń ṣiṣẹ́ ìyanu. Wọn ò gbà pé òun ni Olúwa tó yẹ káwọn máa ṣègbọràn sí, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé. (Lúùkù 6:46, 47) Wọn ò fẹ́ yí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ pa dà, wọn ò sì gbà pé ó yẹ káwọn ṣàtúnṣe sí ọ̀nà táwọn gbà ń gbé ìgbésí ayé àwọn. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé wọn ò jẹ́ kí ìhìn rere náà wọ àwọn lọ́kàn.
Jésù wá sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Ìdí nìyẹn tí mo fi ń fi àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀; torí ní ti bí wọ́n ṣe ń wò, lásán ni wọ́n ń wò, ní ti bí wọ́n ṣe ń gbọ́, lásán ni wọ́n ń gbọ́, kò sì yé wọn. Àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà sì ṣẹ sí wọn lára. Ó sọ pé: ‘. . . Ọkàn àwọn èèyàn yìí ti yigbì.’”—Mátíù 13:13-15; Àìsáyà 6:9, 10.
Àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù ni ọkàn wọn yigbì. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni ojú yín torí wọ́n rí àti etí yín torí wọ́n gbọ́. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ó wu ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn olódodo pé kí wọ́n rí àwọn ohun tí ẹ̀ ń rí, àmọ́ wọn ò rí i, ó wù wọ́n kí wọ́n gbọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́, àmọ́ wọn ò gbọ́ ọ.”—Mátíù 13:16, 17.
Àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn olóòótọ́ yòókù ní ọkàn tó dáa. Torí náà, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin la yọ̀ǹda fún pé kí ẹ lóye àwọn àṣírí mímọ́ Ìjọba ọ̀run, àmọ́ a ò yọ̀ǹda fún wọn.” (Mátíù 13:11) Jésù mọ̀ pé wọ́n fẹ́ mọ̀ sí i lóòótọ́, torí náà ó ṣàlàyé àpèjúwe afúnrúgbìn náà fún wọn.
Jésù wá sọ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kí wọ́n lóye àpèjúwe náà, ó ní: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni irúgbìn náà.” (Lúùkù 8:11) Iyẹ̀pẹ̀ náà sì ni ọkàn àwọn èèyàn.
Jésù sọ nípa èso tó já bọ́ sí etí ọ̀nà pé: ‘Èṣù wá lẹ́yìn náà, ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò nínú ọkàn wọn, kí wọ́n má bàa gbà gbọ́, kí wọ́n sì rí ìgbàlà.’ (Lúùkù 8:12) Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó já bọ́ sórí àpáta, ó ní nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n fi ayọ̀ tẹ́wọ́ gbà á, àmọ́ kò ta gbòǹgbò lọ́kàn wọn, “lẹ́yìn tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni sì dé nítorí ọ̀rọ̀ náà,” wọ́n kọsẹ̀. Nígbà tí “àsìkò ìdánwò” dé, bóyá látọ̀dọ̀ ìdílé tàbí látọ̀dọ̀ àwọn míì, wọ́n yẹsẹ̀.—Mátíù 13:21; Lúùkù 8:13.
Àwọn tó bọ́ sáàárín ẹ̀gún ńkọ́? Jésù sọ pé àwọn yìí gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́, wọ́n jẹ́ kí “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀” borí wọn. (Mátíù 13:22) Ọ̀rọ̀ náà wọ̀ wọ́n lọ́kàn, àmọ́ wọ́n jẹ́ kí àwọn nǹkan míì fún un pa débi pé kò so èso.
Àwọn tó dà bí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa ni Jésù sọ kẹ́yìn. Ìyẹn ni àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n fi sọ́kàn, tí wọ́n sì lóye ẹ̀. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Wọ́n “so èso.” Torí ipò, ọjọ́ orí àti ìlera wọn tó yàtọ̀ síra, kì í ṣe gbogbo wọn ló lè ṣe bákan náà. Àmọ́ bí ọ̀kan ṣe ń so ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100), ni òmíì ń so ìlọ́po ọgọ́ta (60), tí òmíì sì ń so ní ìlọ́po ọgbọ̀n (30). Ọlọ́run máa ń bù kún àwọn tó jẹ́ pé “lẹ́yìn tí wọ́n fi ọkàn tó tọ́, tó sì dáa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n fi sọ́kàn, wọ́n sì ń fi ìfaradà so èso.”—Lúùkù 8:15.
Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí máa wọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ́kàn gan-an, ẹ̀kọ́ náà sì máa yé wọn dáadáa torí pé wọ́n fara balẹ̀ ṣèwádìí lọ́dọ̀ Jésù. Jésù fẹ́ kí wọ́n lóye àwọn àpèjúwe yìí káwọn náà lè kọ́ àwọn míì. Jésù bi wọ́n pé: “A kì í gbé fìtílà wá, ká wá gbé e sábẹ́ apẹ̀rẹ̀ tàbí sábẹ́ ibùsùn, àbí? Ṣebí tí wọ́n bá gbé e wá, orí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n máa ń gbé e sí?” Ó wá kìlọ̀ fún wọn pé: “Kí ẹnikẹ́ni tó bá ní etí láti gbọ́, fetí sílẹ̀.”—Máàkù 4:21-23.
JÉSÙ TÚN ṢE ÀLÀYÉ KÍKÚN NÍPA ÌJỌBA ỌLỌ́RUN
Lẹ́yìn tí Jésù ṣàlàyé àpèjúwe afúnrúgbìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣì fẹ́ mọ̀ sí i. Torí náà, wọ́n sọ fún un pé: “Ṣàlàyé àpèjúwe àwọn èpò inú pápá fún wa.”—Mátíù 13:36.
Ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn béèrè yìí fi hàn pé wọ́n yàtọ̀ sáwọn èrò tí Jésù bá sọ̀rọ̀ ní etíkun. Ó ṣe kedere pé àwọn èrò yẹn gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù àmọ́ kò wù wọ́n láti mọ ìtumọ̀ àwọn àpèjúwe náà àti bí wọ́n ṣe lè fi wọ́n sílò. Àwọn àpèjúwe tí Jésù sọ tẹ̀ léra ti tẹ́ wọn lọ́rùn. Jésù sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn tó gbọ́rọ̀ ẹ̀ létíkun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tó wá bá a kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i nígbà tó sọ pé:
“Ẹ fiyè sí ohun tí ẹ̀ ń gbọ́. Òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n la máa fi díwọ̀n fún yín, àní, a máa fi kún un fún yín.” (Máàkù 4:24) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń fiyè sí ohun tí Jésù ń sọ fún wọn. Wọ́n ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ Jésù, wọ́n ń fọkàn sí i, Jésù sì túbọ̀ ṣàlàyé ohun táwọn àpèjúwe náà túmọ̀ sí fún wọn. Kó lè dáhùn ìbéèrè tí wọ́n bí i nípa àlìkámà àti èpò náà, ó sọ pé:
“Ọmọ èèyàn ni ẹni tó fún irúgbìn tó dáa; ayé ni pápá náà. Ní ti irúgbìn tó dáa, àwọn yìí ni àwọn ọmọ Ìjọba náà, àmọ́ àwọn ọmọ ẹni burúkú náà ni èpò, Èṣù sì ni ọ̀tá tó gbìn wọ́n. Ìparí ètò àwọn nǹkan ni ìgbà ìkórè, àwọn áńgẹ́lì sì ni olùkórè.”—Mátíù 13:37-39.
Lẹ́yìn tí Jésù ṣàlàyé àwọn ohun tó mẹ́nu bà nínú àpèjúwe náà, ó wá sọ ohun tó máa yọrí sí. Ó sọ pé ní ìparí ètò àwọn nǹkan, àwọn olùkórè tàbí àwọn áńgẹ́lì máa kó àwọn Kristẹni tó dà bí èpò kúrò lára “àwọn ọmọ Ìjọba náà.” A máa kó “àwọn olódodo” jọ, wọ́n sì máa tàn yòò bí oòrùn “nínú Ìjọba Baba wọn.” Àmọ́ “àwọn ọmọ ẹni burúkú náà” ńkọ́? Ìparun ayérayé ló máa gbẹ̀yìn wọn, ohun tó sì yẹ wọ́n nìyẹn kódà, wọ́n máa ‘sunkún, wọ́n á sì payín keke.’—Mátíù 13:41-43.
Jésù tún sọ àpèjúwe mẹ́ta míì fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ó sọ pé: “Ìjọba ọ̀run dà bí ìṣúra tí a fi pa mọ́ sínú pápá, èyí tí ọkùnrin kan rí, tó sì fi pa mọ́; torí pé inú rẹ̀ ń dùn, ó lọ ta gbogbo ohun tó ní, ó sì ra pápá yẹn.”—Mátíù 13:44.
Lẹ́yìn ìyẹn, ó sọ pé: “Ìjọba ọ̀run tún dà bí oníṣòwò kan tó ń rìnrìn àjò, tó ń wá àwọn péálì tó dáa. Nígbà tó rí péálì kan tó níye lórí gan-an, ó lọ, ó sì yára ta gbogbo ohun tó ní, ó sì rà á.”—Mátíù 13:45, 46.
Nínú àpèjúwe méjèèjì yìí, Jésù tẹnu mọ́ ọn pé èèyàn gbọ́dọ̀ múra tán láti yááfì àwọn nǹkan kan kó lè rí ohun tó ṣeyebíye. Ọkùnrin oníṣòwò inú àpèjúwe yẹn tètè ta “gbogbo ohun tó ní” kó lè ra péálì tó níye lórí gan-an. Ó dájú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa lóye àpèjúwe péálì tó ṣeyebíye náà dáadáa. Bákan náà, ọkùnrin tó rí ìṣúra tí a fi pa mọ́ sínú pápá “ta gbogbo ohun” tó ní kó lè rà á. Nínú àpèjúwe méjèèjì, ohun tó ṣeyebíye làwọn méjèèjì fẹ́ rà, kí wọ́n sì tọ́jú. A lè fi wé àwọn nǹkan téèyàn ń yááfì kó lè wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. (Mátíù 5:3) Àwọn kan lára àwọn tó ń fetí sí àpèjúwe yìí ti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí wọ́n lè máa wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.—Mátíù 4:19, 20; 19:27.
Níkẹyìn, Jésù fi Ìjọba ọ̀run wé àwọ̀n ńlá kan tó kó oríṣiríṣi ẹja. (Mátíù 13:47) Nígbà tí wọ́n ya àwọn ẹja náà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n kó àwọn tó dáa sínú ohun èlò, àmọ́ wọ́n da àwọn tí kò dáa nù. Jésù sọ pé bó ṣe máa rí ní ìparí ètò àwọn nǹkan nìyẹn, àwọn áńgẹ́lì máa ya àwọn ẹni burúkú kúrò lára àwọn olódodo.
Apẹja nípa tẹ̀mí ni Jésù, ohun tó sì sọ fáwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni pé kí wọ́n wá di “apẹja èèyàn.” (Máàkù 1:17) Àmọ́, ó sọ pé ọjọ́ iwájú ni àpèjúwe nípa àwọ̀n ńlá náà ń tọ́ka sí, ìyẹn ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 13:49) Torí náà, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù tó ń fetí sí Jésù mọ̀ pé àwọn ohun àgbàyanu máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Jésù ṣe àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ fáwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wá bá a. Ó sì fi hàn pé òun ṣe tán láti “ṣàlàyé gbogbo nǹkan fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láwọn nìkan.” (Máàkù 4:34) Jésù “dà bí ọkùnrin kan tó jẹ́ baálé ilé, tó kó àwọn ohun tuntun àti ohun àtijọ́ jáde látinú ibi tó ń kó ìṣúra sí.” (Mátíù 13:52) Kì í ṣe torí kí wọ́n lè máa kan sáárá sí i ló ṣe ń lo oríṣiríṣi àpèjúwe. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láwọn òtítọ́ tó dà bí ìṣura iyebíye. Kò sí àní-àní pé “ẹni tó ń kọ́ni ní gbangba” ni Jésù, kódà ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.