ORÍ 10
Ọba Náà Yọ́ Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Mọ́ Nípa Tẹ̀mí
1-3. Kí ni Jésù ṣe nígbà tó rí i pé wọ́n ti sọ tẹ́ńpìlì di ẹlẹ́gbin?
ỌWỌ́ pàtàkì ni Jésù fi mú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, torí pé ó mọ ohun tí tẹ́ńpìlì náà dúró fún. Ọjọ́ pẹ́ tí tẹ́ńpìlì náà ti jẹ́ ojúkò ìjọsìn tòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́, torí pé ìjọsìn Ọlọ́run mímọ́ náà, Jèhófà, ni tẹ́ńpìlì náà wà fún, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ àti aláìlábàwọ́n. Wá wo bó ṣe rí lára Jésù nígbà tó wọ tẹ́ńpìlì náà ní Nísàn 10, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, tí ó sì rí i pé wọ́n ti sọ tẹ́ńpìlì náà di ẹlẹ́gbin. Kí ló fà á?—Ka Mátíù 21:12, 13.
2 Ó ṣẹlẹ̀ pé, nínú Àgbàlá àwọn Kèfèrí, àwọn olówò tí wọ́n jẹ́ oníwọra àtàwọn tó ń pààrọ̀ owó ń rẹ́ àwọn tó wá rúbọ sí Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì jẹ.a Jésù “lé gbogbo àwọn tí ń tà, tí wọ́n sì ń rà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì sojú tábìlì àwọn olùpààrọ̀ owó dé.” (Fi wé Nehemáyà 13:7-9.) Ó bá àwọn onímọtara-ẹni-nìkan yẹn wí, torí pé wọ́n sọ ilé Baba rẹ̀ di “hòrò àwọn ọlọ́ṣà.” Jésù tipa báyìí fi hàn pé ọwọ́ pàtàkì ni òun fi mú tẹ́ńpìlì náà àti ohun tó dúró fún. Ìjọsìn Baba rẹ̀ gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́!
3 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn tí Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba, ó tún fọ tẹ́ńpìlì míì mọ́. Tẹ́ńpìlì náà sì kan gbogbo àwa tòde òní tá a fẹ́ máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. Tẹ́ńpìlì wo nìyẹn?
A Fọ “Àwọn Ọmọ Léfì” Mọ́
4, 5. (a) Láti ọdún 1914 sí apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919, báwo ni Jésù ṣe yọ́ àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ́ tó sì fọ̀ wọ́n mọ́? (b) Ǹjẹ́ ibi tí ìyọ́mọ́ àti ìfọ̀mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run parí sí nìyẹn? Ṣàlàyé.
4 Bá a ṣe ṣàlàyé ní Orí 2 ìwé yìí, lẹ́yìn tí Jésù gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914, òun àti Baba rẹ̀ wá ṣèbẹ̀wò sí tẹ́ńpìlì tẹ̀mí náà, ìyẹn ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn mímọ́.b Nígbà ìbẹ̀wò yẹn Ọba náà rí i pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ìyẹn “àwọn ọmọ Léfì,” nílò ìyọ́mọ́ àti ìfọ̀mọ́. (Mál. 3:1-3) Láti ọdún 1914 sí apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919, Jèhófà gbà kí àwọn ìṣòro àti onírúurú àdánwò dojú kọ àwọn èèyàn rẹ̀, kó lè yọ́ wọn mọ́ kó sì fọ̀ wọ́n mọ́. Inú wá dùn pé àwọn ẹni àmì òróró yìí yege àdánwò líle tí a fi yọ́ wọn mọ́ yìí, wọ́n sì múra tán láti kọ́wọ́ ti Mèsáyà Ọba!
5 Ǹjẹ́ ibi tí ìyọ́mọ́ àti ìfọ̀mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run parí sí nìyẹn? Rárá o. Jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ ìkẹyìn, Jèhófà ń lo Mèsáyà Ọba náà láti ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa jẹ́ mímọ́ nìṣó, kí wọ́n bàa lè máa wà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀. Nínú orí méjì tó kàn, a máa rí bí ó ṣe yọ́ wọn mọ́ kúrò nínú àwọn àṣà àtàwọn ìwà kan àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣètò nǹkan. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò bí ó ṣe fọ̀ wọ́n mọ́ nípa tẹ̀mí. Ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára gan-an tá a bá ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tí Jésù ṣe kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí, èyí ní nínú àwọn nǹkan tó ṣeé fojú rí àtàwọn nǹkan tí kò ṣeé fojú rí.
“Ẹ Wẹ Ara Yín Mọ́”
6. Báwo ni àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà fún àwọn Júù tó wà ní ìgbèkùn ṣe jẹ́ ká lóye ohun tó túmọ̀ sí láti mọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí?
6 Kí ló túmọ̀ sí láti mọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí? Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Jèhófà sọ fún àwọn Júù tó wà ní ìgbèkùn nígbà tí wọ́n fẹ́ kúrò ní ìlú Bábílónì lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Ka Aísáyà 52:11.) Olórí ìdí tí wọ́n fi ń pa dà sí Jerúsálẹ́mù ni pé, kí wọ́n lè tún tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ kọ́, kí wọ́n sì mú ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò. (Ẹ́sírà 1:2-4) Jèhófà fẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ pa gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Bábílónì tì pátápátá. Kíyè sí àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà fún wọn. Ó sọ pé: “Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan,” “ẹ jáde kúrò ní àárín rẹ̀.” Ó tún sọ pé “ẹ wẹ ara yín mọ́.” Ìjọsìn èké kò gbọ́dọ̀ kó àbàwọ́n bá ìjọsìn mímọ́ Jèhófà. Nítorí náà, kí ló wá túmọ̀ sí láti mọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí? Ohun tó túmọ̀ sí láti mọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí ni pé kéèyàn má ṣe lọ́wọ́ sí àwọn ẹ̀kọ́ àtàwọn àṣà ìsìn èké lọ́nà èyíkéyìí.
7. Ta ni Jésù yàn láti ran àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí?
7 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba, ó ṣètò ohun tó máa jẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè máa wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí. Ohun tó ṣe ni pé lọ́dún 1919 ó yan ẹrú olóòótọ́ àti olóye. Kò ṣòro rárá láti dá ẹrú náà mọ̀. (Mát. 24:45) Nígbà tó fi máa di ọdún yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti fọ ara wọn mọ́ kúrò nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ èké. Síbẹ̀, wọ́n ṣì nílò ìfọ̀mọ́ síwájú sí i nípa tẹ̀mí. Kristi sì ti lo ẹrú olóòótọ́ náà láti la àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lóye ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nípa àwọn ayẹyẹ àtàwọn àṣà tó yẹ kí wọ́n pa tì. (Òwe 4:18) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀.
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Ṣayẹyẹ Kérésìmesì?
8. Kí làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti mọ̀ tipẹ́ nípa Kérésìmesì, síbẹ̀ kí ni kò tíì ṣe kedere sí wọn?
8 Tipẹ́tipẹ́ làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti gbà pé ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà ni Kérésìmesì ti ṣẹ̀ wá àti pé December 25 kọ́ ni wọ́n bí Jésù. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti oṣù December ọdún 1881 lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló jẹ́ abọ̀rìṣà tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Àmọ́, orúkọ ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe nìkan ló yí pa dà, torí pé àwọn àwòrò wọn náà ló wá di àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi orúkọ Kristẹni pe àwọn ayẹyẹ táwọn abọ̀rìṣà ń ṣe. Kérésìmesì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ayẹyẹ yìí.” Lọ́dún 1883, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ gbé àpilẹ̀kọ kan jáde tí wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní, “Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù?” Níbẹ̀ wọ́n ṣàlàyé pé apá ìbẹ̀rẹ̀ oṣù October ni wọ́n bí Jésù.c Síbẹ̀, kò tíì ṣe kedere sí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn pé ó yẹ káwọn jáwọ́ nínú ṣíṣe ayẹyẹ Kérésìmesì. Kódà, ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn ṣì ń ṣe ayẹyẹ yìí. Àmọ́, lẹ́yìn ọdún 1926, nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Kí nìdí?
9. Kí ló pa dà wá yé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa Kérésìmesì?
9 Lẹ́yìn tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí kínníkínní, ó wá yé wọn pé ibi tí Kérésìmesì ti ṣẹ̀ wá àti gbogbo àṣà tó rọ̀ mọ́ ayẹyẹ yìí kò gbé Ọlọ́run ga. Àpilẹ̀kọ tó ní àkòrí náà “Ibi Tí Kérésìmesì Ti Ṣẹ̀ Wá,” nínú ìwé ìròyìn The Golden Age, ti December 14 ọdún 1927, sọ pé ayẹyẹ àwọn abọ̀rìṣà ni Kérésìmesì jẹ́, fàájì ló dá lé lórí, ó sì ní àṣà ìbọ̀rìṣà nínú. Àpilẹ̀kọ yẹn jẹ́ kó ṣe kedere pé Kristi kọ́ ló pàṣẹ pé ká máa ṣe ayẹyẹ yìí. Ní ìparí àpilẹ̀kọ náà, ó sọ òkodoro òtítọ́ yìí pé: “Bó ṣe jẹ́ pé ayé yìí, ẹran ara ẹlẹ́ṣẹ̀ àti Èṣù kọ́wọ́ ti ayẹyẹ yìí àti gbogbo àṣà rẹ̀ . . . mú kó dá wa lójú pé kò yẹ kí àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà máa ṣe ayẹyẹ yìí.” Ìdí nìyẹn tí ìdílé Bẹ́tẹ́lì kò fi ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì ní oṣù December ọdún yẹn, wọn kò sì tún ṣe é mọ́!
10. (a) Ní December 1928 àlàyé kíkún wo ló jẹ́ kí àwọn Kristẹni mọ̀ pé kò yẹ kí wọ́n máa ṣayẹyẹ Kérésìmesì? (Tún wo àpótí tá a pè ní “Ibi Tí Kérésìmesì Ti Ṣẹ̀ Wá àti Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Ṣe É.”) (b) Báwo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run tún ṣe mọ àwọn ayẹyẹ mìíràn tí kò yẹ kí wọ́n lọ́wọ́ sí? (Tún wo àpótí tá a pè ní “Àwọn Ayẹyẹ Mìíràn Tí Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu.”)
10 Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tún rí àlàyé kíkún síwájú sí i nípa ìdí tí kò fi yẹ kí wọ́n máa ṣe Kérésìmesì. Ní December 12, 1928, Arákùnrin Richard H. Barber, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ sọ àsọyé kan lórí rédíò, tó mú kó ṣe kedere pé ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà ni ayẹyẹ yìí ti ṣẹ̀ wá. Kí ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìtọ́ni tó ṣe kedere tó wá láti oríléeṣẹ́? Arákùnrin Charles Brandlein rántí ìgbà tí òun àti ìdílé rẹ̀ ò ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì mọ́, ó ní: “Ǹjẹ́ ó ṣòro fún wa láti pa àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà tì? Rárá o! . . . Ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bọ́ aṣọ tó ti di ẹlẹ́gbin téèyàn sì sọ ọ́ nù.” Bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe rí náà nìyẹn lára Arákùnrin Henry A. Cantwell, tó sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò nígbà tó yá, ó sọ pé: “Inú wa dùn pé a lè fi àwọn nǹkan kan sílẹ̀, ká lè fi hàn pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.” Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ múra tán láti ṣe àwọn àtúnṣe tó pọn dandan kí wọ́n sì yọwọ́ pátápátá nínú ayẹyẹ tó ṣẹ̀ wá látinú ìjọsìn tí kò mọ́.d—Jòh. 15:19; 17:14.
11. Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé à ń kọ́wọ́ ti Mèsáyà Ọba?
11 Àpẹẹrẹ rere làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ yìí jẹ́ fún wa! Bí a ṣe ń ronú lórí àpẹẹrẹ wọn, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Irú ọwọ́ wo ni mo fi ń mú àwọn ìtọ́ni tí à ń gbà láti orílé-iṣẹ́? Ǹjẹ́ mò ń fi ìmọrírì tẹ́wọ́ gbà á tí mo sì ń fi ohun tí mò ń kọ́ sílò?’ Tí a bá ń ṣègbọràn tọkàntọkàn, ṣe là ń fi hàn pé a kọ́wọ́ ti Mèsáyà Ọba náà tó ń lo ẹrú olóòótọ́ láti fún wa ní oúnjẹ tẹ̀mí ní àsìkò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.—Ìṣe 16:4, 5.
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Lo Àgbélébùú?
12. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, èrò wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní nípa àgbélébùú?
12 Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi gbà pé àgbélébùú wà lára àmì tí wọ́n fi ń dá àwọn Kristẹni mọ̀. Àmọ́, wọn kò gbà pé ó yẹ kéèyàn máa jọ́sìn àgbélébùú, torí wọ́n mọ̀ pé ìbọ̀rìṣà kò dára. (1 Kọ́r. 10:14; 1 Jòh. 5:21) Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1883, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ jẹ́ kó ṣe kedere pé “ìbọ̀rìṣà jẹ́ ohun ìríra lójú Ọlọ́run.” Síbẹ̀, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò rí ohun tó burú nínú lílo àgbélébùú láwọn ọ̀nà kan tí wọ́n ronú pé ó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n ń fi ohun ọ̀ṣọ́ kan tó ní àgbélébùú àti adé há àyà wọn gẹ́gẹ́ bí àmì ìdánimọ̀. Lójú wọn, ohun tí àmì yẹn dúró fún ni pé, tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú, wọ́n máa gba adé ìyè. Láti ọdún 1891, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi àmì àgbélébùú àti adé sára èèpo iwájú Ilé Ìṣọ́.
13. Ìlàlóye wo ni àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi rí gbà nípa lílo àgbélébùú? (Tún wo àpótí tá a pè ní “Wọ́n Rí Ìlàlóye Gbà Ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀lé Nípa Àgbélébùú.”)
13 Ọwọ́ pàtàkì ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi mú àmì àgbélébùú àti adé yìí. Àmọ́, nígbà tó fi máa di àárín ọdún 1927 sí ọdún 1929, àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìlàlóye gbà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé lórí ọ̀rọ̀ lílo àgbélébùú. Arákùnrin Grant Suiter tó sìn nígbà tó yá gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí rántí ìpàdé kan tí wọ́n ṣe lọ́dún 1928 ní ìlú Detroit, ní ìpínlẹ̀ Michigan, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó sọ pé: “Ní ìpàdé yẹn, wọ́n mú kó ṣe kedere pé, yàtọ̀ sí pé àmì àgbélébùú àti adé yẹn kò pọn dandan, kò bójú mu rárá.” Láwọn ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, wọ́n rí ìlàlóye síwájú sí i. Ó wá túbọ̀ yé wọn pé àmì àgbélébùú kò bójú mu rárá nínú ìjọsìn mímọ́.
14. Kí ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe bí wọ́n ṣe ń rí ìlàlóye gbà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nípa àgbélébùú?
14 Kí ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe lẹ́yìn tí wọ́n rí ìlàlóye gbà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nípa àgbélébùú? Ǹjẹ́ wọ́n ń bá a nìṣó láti máa lo àmì àgbélébùú àti adé tí wọ́n kà sí nǹkan pàtàkì yẹn? Arákùnrin Lela Roberts tó ti ń sin Jèhófà láti ọjọ́ pípẹ́ sọ pé: “Nígbà tí a ti mọ ohun tí àmì náà dúró fún, kò nira rárá fún wa láti ṣíwọ́ lílò ó.” Arábìnrin Ursula Serenco tóun náà ń ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ọ̀pọ̀ nínú wọn, ó ní: “A wá rí i pé ikú Olúwa wa àti ìfọkànsìn Kristẹni kọ́ ni àmì tí a kà sí pàtàkì tẹ́lẹ̀ yìí dúró fún, àṣé àmì àwọn abọ̀rìṣà ni. Inú wa dùn pé ipa ọ̀nà wa ń mọ́lẹ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ nínú ìwé Òwe 4:18.” Àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Kristi kò fẹ́ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn àṣà eléèérí tó kún inú ìjọsìn èké!
15, 16. Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a ti pinnu láti mú kí àwọn àgbàlá orí ilẹ̀ ayé ti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí Jèhófà máa wà ní mímọ́?
15 Ohun tí àwa náà pinnu láti ṣe lónìí nìyẹn. A gbà pé Kristi ń lo ẹrú olóòótọ́ àti olóye láti ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí. Kò sì ṣòro rárá láti dá ẹrú yìí mọ̀. Torí náà, tí ẹrú náà bá tipasẹ̀ oúnjẹ tẹ̀mí tí à ń rí gbà kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ayẹyẹ tàbí àwọn àṣà kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn èké, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la máa ń ṣègbọràn. Bíi ti àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí wọ́n gbé láyé nígbà tí wíwàníhìn-ín Kristi ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, a ti pinnu láti mú kí àwọn àgbàlá orí ilẹ̀ ayé ti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí Jèhófà máa wà ní mímọ́.
16 Látìgbà tí ọjọ́ ìkẹyìn ti bẹ̀rẹ̀ títí di báyìí ni Kristi ti ń ṣe àwọn iṣẹ́ kan táwọn èèyàn kò lè rí láti dáàbò bo ìjọ àwọn èèyàn Jèhófà lọ́wọ́ àwọn tó lè sọ ìjọsìn wọn di eléèérí nípa tẹ̀mí. Báwo ni Jésù ṣe ń ṣe èyí? Ẹ jẹ́ kí á wò ó ná.
Yíya “Àwọn Ẹni Burúkú Sọ́tọ̀ Kúrò Láàárín Àwọn Olódodo”
17, 18. Nínú àpèjúwe àwọ̀n ńlá, kí ni ìtumọ̀ (a) jíju àwọ̀n ńlá sínú òkun, (b) ‘kíkó ẹja onírúurú jọ,’ (d) kíkó àwọn ẹja àtàtà sínú àwọn ohun èlò, àti (e) kíkó àwọn ẹja tí kò yẹ dà nù?
17 Ọba náà Jésù Kristi ń dáàbò bo ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run kárí ayé. Òun àti àwọn áńgẹ́lì ti ń ṣe iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ láwọn ọ̀nà tí a kò lè rí. Jésù sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ yìí nínú àpèjúwe tó ṣe nípa àwọ̀n ńlá. (Ka Mátíù 13:47-50.) Kí ni àpèjúwe yìí túmọ̀ sí?
18 Jíju “àwọ̀n ńlá kan . . . sínú òkun.” Àwọ̀n ńlá náà ṣàpẹẹrẹ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tí à ń ṣe kárí ayé. ‘Kíkó ẹja onírúurú jọ.’ Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ń fa onírúurú èèyàn mọ́ra, ìyẹn àwọn tó ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, kí wọ́n lè di Kristẹni tòótọ́, tó fi mọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tó dà bíi pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere náà àmọ́ tí wọn kò ṣe tán láti jọ́sìn Jèhófà.e Kíkó àwọn èyí tó jẹ́ “àtàtà sínú àwọn ohun èlò.” À ń kó àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ jọ sínú àwọn ohun èlò, ìyẹn àwọn ìjọ, níbi tí wọ́n á ti lè máa fi ọkàn mímọ́ sin Jèhófà. Jíju àwọn ẹja “tí kò yẹ” dà nù. Látìgbà tí ọjọ́ ìkẹyìn ti bẹ̀rẹ̀ títí di báyìí, Kristi àtàwọn áńgẹ́lì ti ń ya “àwọn ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn olódodo.”f Ìdí nìyẹn tí àwọn tí kò ní ọkàn títọ́, ìyẹn àwọn tó lè máà fẹ́ pa àwọn ẹ̀kọ́ tàbí àṣà tí kò tọ̀nà tì, kò fi lè ba ìjọ Ọlọ́run jẹ́.g
19. Báwo ni àwọn ohun tí Kristi ti ń ṣe kí àwọn èèyàn Ọlọ́run lè wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí, kí ìjọsìn tòótọ́ sì wà láì lábàwọ́n ṣe rí lára rẹ?
19 Ǹjẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé Ọba wa, Jésù Kristi ń dáàbò bo àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀ kò fini lọ́kàn balẹ̀? Ǹjẹ́ kò sì tuni nínú bí a ṣe mọ̀ pé ìtara tó ní fún ìjọsìn tòótọ́ àtàwọn tó ń fòótọ́ sin Ọlọ́run ṣì lágbára gan-an bíi ti ìgbà tó fọ tẹ́ńpìlì mọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni? Inú wa mà dùn o, pé Kristi ń ṣe iṣẹ́ takuntakun láti rí i dájú pé àwọn èèyàn Ọlọ́run wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí, ó sì tún ń mú kí ìjọsìn tòótọ́ wà láìlábàwọ́n! Tí a bá fẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ là ń kọ́wọ́ ti Ọba náà àti Ìjọba rẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn èké.
a Ó ní irú ẹyọ owó tí àwọn Júù tó wá láti ìlú míì gbọ́dọ̀ fi san owó orí ọdọọdún ní tẹ́ńpìlì. Torí náà, àwọn tó ń pààrọ̀ owó ní tẹ́ńpìlì máa ń gba owó lọ́wọ́ wọn kí wọ́n tó lè bá wọn ṣẹ́ ẹyọ owó tí wọ́n ní lọ́wọ́ sí irú owó tí wọ́n lé lò ní tẹ́ńpìlì. Yàtọ̀ síyẹn, ó lè pọn dandan pé káwọn àlejò ra àwọn ẹran tí wọ́n máa fi rúbọ. Ó lè jẹ́ owó gọbọi tí àwọn oníṣòwò náà máa ń fi lé ọjà tàbí iye tí wọ́n ń gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn ló mú kí Jésù pè wọ́n ní “ọlọ́ṣà.”
b Àwọn èèyàn Jèhófà tó wà lórí ilẹ̀ ayé ń jọ́sìn rẹ̀ nínú àwọn àgbàlá orí ilẹ̀ ayé ti tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí.
c Àpilẹ̀kọ yẹn sọ pé ọjọ́ ìbí Jésù táwọn kan sọ pé ó bọ́ sí ìgbà òtútù “ta ko ìtàn Bíbélì tó sọ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn wà níta pẹ̀lú àwọn agbo ẹran wọn.”—Lúùkù 2:8.
d Nínú lẹ́tà kan tí Arákùnrin Frederick W. Franz kọ ní November 14, ọdún 1927, ó sọ pé: “A kò ní ṣe Kérésìmesì lọ́dún yìí. Gbogbo ìdílé Bẹ́tẹ́lì ló fara mọ́ ọn pé a kò ní ṣe Kérésìmesì mọ́.” Oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà arákùnrin Franz tún kọ lẹ́tà míì ní February 6, ọdún 1928, ó ní: “Díẹ̀díẹ̀ ni Olúwa ń fọ̀ wá mọ́ kúrò nínú ẹ̀gbin Bábílónì Ńlá tí Èṣù ń darí.”
e Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2013, iye àwọn akéde tó mílíọ̀nù méje, ọ̀kẹ́ méjìdínláàádọ́ta àti ẹgbàáta dín mẹ́rìndínláàádọ́ta [7,965,954], àwọn tó sì wá síbi Ìrántí Ikú Kristi sì jẹ́ mílíọ̀nù mọ́kàndínlógún, ẹgbẹ̀rún mọ́kànlé-ní-òjìlérúgba, igba àti méjìléláàádọ́ta [19,241,252].
f Yíya ẹja àtàtà àti èyí tí kò yẹ sọ́tọ̀ yàtọ̀ sí yíya àgùntàn àti ewúrẹ́ sọ́tọ̀. (Mát. 25:31-46) Ìyàsọ́tọ̀ tàbí ìdájọ́ ìkẹyìn ti àgùntàn àti ewúrẹ́ yóò wáyé nígbà ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀. Títí di ìgbà yẹn, àwọn tó dà bí ẹja tí kò yẹ ṣì lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà kí a sì kó wọn jọ sínú ìjọ Ọlọ́run.—Mál. 3:7.
g Tó bá yá, àwọn tí kò yẹ ni a óò jù sínú iná ìṣàpẹẹrẹ tó ń jó fòfò, tó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run máa pa wọ́n run lọ́jọ́ iwájú.