ORÍ 57
Jésù Wo Ọmọbìnrin Kan Àti Adití Kan Sàn
JÉSÙ MÚ ỌMỌ OBÌNRIN ARÁ FONÍṢÍÀ KAN LÁRA DÁ
Ó MÚ KÍ ỌKÙNRIN ADITÍ KAN SỌ̀RỌ̀
Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn Farisí lẹ́yìn tó dẹ́bi fún wọn nítorí ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan tí wọ́n ń hù. Ó lọ sí Tírè àti Sídónì ní agbègbè Foníṣíà tó wà ní ọ̀pọ̀ máìlì sí apá àríwá ìwọ̀ oòrùn.
Jésù dé sílé kan, kò sì fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun wà níbẹ̀, síbẹ̀ àwọn èèyàn mọ̀. Obìnrin ará Gíríìsì kan wà tí wọ́n bí sí agbègbè yẹn, ó wá Jésù lọ, ó sì ń bẹ̀ ẹ́ pé: “Ṣàánú mi, Olúwa, Ọmọ Dáfídì. Ẹ̀mí èṣù ń yọ ọmọbìnrin mi lẹ́nu gidigidi.”—Mátíù 15:22; Máàkù 7:26.
Nígbà tó ṣe díẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ ọ́ pé: “Ní kó máa lọ, torí kò yéé ké tẹ̀ lé wa.” Jésù wá sọ ìdí tóun ò fi dá obìnrin náà lóhùn, ó ní: “A kò rán mi sí ẹnikẹ́ni àfi àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù.” Àmọ́ obìnrin náà ò jẹ́ kó sú òun, ó wá tẹrí ba ó sì ń bẹ̀ ẹ́ pé: “Olúwa, ràn mí lọ́wọ́!”—Mátíù 15:23-25.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jésù fẹ́ dán ìgbàgbọ́ obìnrin náà wò nígbà tó sọ èrò tí kò tọ́ táwọn Júù ní nípa àwọn ẹ̀yà míì, ó ní: “Kò tọ́ ká mú búrẹ́dì àwọn ọmọ, ká sì jù ú sí àwọn ajá kéékèèké.” (Mátíù 15:26) Bí Jésù ṣe mẹ́nu kan “àwọn ajá kéékèèké” fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn tí kì í ṣe Júù. Kò sí àní-àní pé ìrísí ojú ẹ̀ àti ohùn tó fi sọ̀rọ̀ á túbọ̀ jẹ́ kí èyí ṣe kedere.
Dípò tí obìnrin náà á fi bínú, ṣe ló fìrẹ̀lẹ̀ tọ́ka sí ohun tí Jésù sọ, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, àmọ́ ká sòótọ́, àwọn ajá kéékèèké máa ń jẹ lára èérún tó ń já bọ́ látorí tábìlì àwọn ọ̀gá wọn.” Jésù rí i pé obìnrin náà ní ọkàn tó dáa, ó wá sọ pé: “Ìwọ obìnrin yìí, ìgbàgbọ́ rẹ lágbára gan-an; kó ṣẹlẹ̀ sí ọ bí o ṣe fẹ́.” (Mátíù 15:27, 28) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ obìnrin náà kò sí níbẹ̀, ohun tí Jésù sọ yẹn rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́! Nígbà tí obìnrin náà fi máa délé, ó rí i pé ọmọ náà dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn, “ẹ̀mí èṣù náà [sì] ti kúrò lára rẹ̀”!—Máàkù 7:30.
Láti agbègbè Foníṣíà, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rìnrìn àjò lọ sí apá òkè Odò Jọ́dánì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé apá àríwá Òkun Gálílì ni wọ́n ti sọdá Odò Jọ́dánì bọ́ sí agbègbè Dekapólì. Wọ́n lọ sórí òkè kan níbẹ̀, àmọ́ àwọn èèyàn wá wọn débẹ̀. Wọ́n mú àwọn aláàbọ̀ ara wá, wọ́n tẹ́ wọn síbi ẹsẹ̀ Jésù, ó sì wò wọ́n sàn. Ẹnu ya àwọn èrò náà, wọ́n sì ń yin Ọlọ́run Ísírẹ́lì lógo.
Jésù dìídì fún ọkùnrin kan tó wà níbẹ̀ ní àfiyèsí, adití ni ọkùnrin yìí kò sì lè sọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kẹ́yin náà mọ bí nǹkan ṣe máa rí lára ọkùnrin yìí láàárín èrò. Jésù lè ti kíyè sí i pé ẹ̀rù ń bà á, torí náà ó mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn. Nígbà tí wọ́n dá wà, Jésù jẹ́ kó mọ ohun tóun fẹ́ ṣe fún un. Ó ki ìka rẹ̀ bọ etí ọkùnrin náà méjèèjì, lẹ́yìn tó tutọ́, ó fọwọ́ kan ahọ́n rẹ̀. Ó gbójú sókè, ó wá sọ èdè kan tó jọ tàwọn Hébérù tó túmọ̀ sí “Là.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, etí ọkùnrin náà là, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀. Àmọ́ Jésù ò fẹ́ kí ọkùnrin náà sọ fún ẹnikẹ́ni, torí pé ó fẹ́ káwọn èèyàn gba òun gbọ́ nítorí ohun tí wọ́n rí tí wọ́n sì gbọ́ fúnra wọn.—Máàkù 7:32-36.
Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ó lágbára débi pé “ẹnu yà wọ́n kọjá sísọ.” Wọ́n sì ń sọ pé: “Gbogbo nǹkan ló ṣe dáadáa. Ó tiẹ̀ ń mú kí àwọn adití gbọ́ràn, kí àwọn tí kò lè sọ̀rọ̀ sì sọ̀rọ̀.”—Máàkù 7:37.