Ẹ̀KỌ́ 42
Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Tó Lọ́kọ Tàbí Aya Àtàwọn Tí Kò Ní
Àwọn kan gbà pé ìgbà téèyàn bá ní ọkọ tàbí aya ló máa tó láyọ̀. Ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn tó ṣègbéyàwó kọ́ ló ń láyọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo àwọn tí kò ṣègbéyàwó ni kì í láyọ̀. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà fáwọn tó ní ọkọ tàbí aya àtàwọn tí kò ní.
1. Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn wà láìní ọkọ tàbí aya?
Bíbélì sọ pé: “Ẹni tó bá gbéyàwó ṣe dáadáa, àmọ́ ẹni tí kò bá gbéyàwó ṣe dáadáa jù.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 7:32, 33, 38.) Ọ̀nà wo làwọn tí kò ṣègbéyàwó gbà “ṣe dáadáa jù”? Wọn ò lọ́kọ tàbí aya tí wọ́n fẹ́ tọ́jú, torí náà wọ́n máa ń lómìnira ju àwọn tó ti ṣègbéyàwó. Èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ ráyè fún iṣẹ́ Jèhófà, bíi kí wọ́n lọ wàásù lórílẹ̀-èdè míì. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wọ́n á túbọ̀ ráyè láti ṣe àwọn nǹkan míì táá mú kí wọ́n sún mọ́ Jèhófà.
2. Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn ṣègbéyàwó lọ́nà tó bófin mu?
Àwọn tó ti ṣègbéyàwó náà máa ń rí ọ̀pọ̀ àǹfààní. Bíbélì sọ pé “ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ.” (Oníwàásù 4:9) Òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, ní pàtàkì tí tọkọtaya bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. Ṣe làwọn tó ṣègbéyàwó lọ́nà tó bófin mu ṣèlérí pé àwọn á máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn, àwọn á máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, àwọn á sì máa ṣìkẹ́ ara wọn. Èyí á jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀ ju àwọn tó kàn ń gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó. Ìyẹn á tún jẹ́ kí ọkàn àwọn ọmọ wọn balẹ̀, kí ara sì tù wọ́n.
3. Kí ni Jèhófà sọ nípa ìgbéyàwó?
Nígbà tí Jèhófà so ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ pọ̀, ó ní: ‘Ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́ ìyàwó rẹ̀.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Jèhófà fẹ́ kí tọkọtaya nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì wà pa pọ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Àgbèrè nìkan ló lè mú kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀. Kódà, tẹ́nì kan bá ṣàgbèrè, Jèhófà ṣì fún ẹnì kejì láyè láti pinnu bóyá òun á kọ ẹni tó ṣàgbèrè náà sílẹ̀ àbí òun á dárí jì í.a (Mátíù 19:9) Bákan náà, Jèhófà ò fẹ́ káwọn Kristẹni fẹ́ ju ìyàwó kan lọ.—1 Tímótì 3:2.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o máa láyọ̀ kó o sì máa múnú Jèhófà dùn, yálà o ti ní ọkọ tàbí aya àbí o ò ní.
4. Lo ẹ̀bùn wíwà láìní ọkọ tàbí aya lọ́nà tó dáa
Jésù náà gbà pé ẹ̀bùn ni wíwà láìṣègbéyàwó jẹ́. (Mátíù 19:11, 12) Ka Mátíù 4:23, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ni Jésù ṣe lo ẹ̀bùn wíwà láìní aya láti fi sin Jèhófà kó sì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?
Wo fídíò yìí kó o lè rí báwọn Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kí wọ́n sì lo ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó dáa jù lọ. Wo FÍDÍÒ yìí, kó o sì dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Àwọn ọ̀nà tó dáa wo làwọn Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó lè gbà lo ìgbésí ayé wọn?
Ǹjẹ́ o mọ̀?
Bíbélì ò sọ iye ọjọ́ orí téèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ kó tó lè ṣègbéyàwó. Àmọ́, ó gbà wá níyànjú pé kéèyàn ní sùúrù dìgbà tó máa “kọjá ìgbà ìtànná èwe,” ìyẹn ìgbà tó máa ń wu èèyàn gan-an láti ní ìbálòpọ̀. Nírú àkókò yìí, àwọn ọ̀dọ́ kì í lè fara balẹ̀ ṣe ìpinnu tó dáa nípa irú ẹni tó yẹ kí wọ́n fẹ́.—1 Kọ́ríńtì 7:36.
5. Fara balẹ̀ yan ẹni tó o máa fẹ́
Ọ̀kan lára àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ tó o máa ṣe láyé ẹ ni pé kó o yan ẹni tó o máa fẹ́. Ka Mátíù 19:4-6, 9, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tó fi yẹ kí Kristẹni kan ṣe sùúrù kó tó ṣègbéyàwó?
Bíbélì á jẹ́ kó o mọ àwọn ìwà àti ìṣe tó yẹ kó o máa wá lára ẹni tó o máa fi ṣe ọkọ tàbí aya. Èyí tó sì ṣe pàtàkì jù lára àwọn nǹkan yẹn ni pé kí ẹni náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.b Ka 1 Kọ́ríńtì 7:39 àti 2 Kọ́ríńtì 6:14. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tó fi yẹ kí Kristẹni kan fẹ́ Kristẹni bíi tiẹ̀?
Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà tí Kristẹni kan bá fẹ́ ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
6. Ohun tí Jèhófà sọ nípa ìgbéyàwó ni kó o tẹ̀ lé
Nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, àwọn ọkùnrin kan máa ń kọ ìyàwó wọn sílẹ̀ lọ́nà àìtọ́ torí pé tara wọn nìkan ni wọ́n ń rò. Ka Málákì 2:13, 14, 16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tí Jèhófà fi kórìíra káwọn tọkọtaya máa kọ ara wọn sílẹ̀ torí àwọn ẹ̀sùn tí kò bá Bíbélì mu?
Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Tó bá jẹ́ pé ọkọ tàbí ìyàwó ẹ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí lo lè ṣe kí ìdílé rẹ lè láyọ̀?
7. Máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nínú ìgbéyàwó rẹ
Ó lè má rọrùn láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìdílé.c Àmọ́ tí tọkọtaya bá ń sapá láti fi àwọn ìlànà yẹn sílò, wọ́n máa rí ìbùkún Jèhófà. Wo FÍDÍÒ yìí.
Ka Hébérù 13:4, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé o gbà pé àwọn ìlànà Jèhófà nípa ìgbéyàwó bọ́gbọ́n mu? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Jèhófà retí pé káwọn Kristẹni ṣègbéyàwó lọ́nà tó bá òfin ìjọba mu, bákan náà, tí wọ́n bá fẹ́ kọ ara wọn sílẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó bá òfin ìjọba mu. Ìdí ni pé láwọn orílẹ̀-èdè tó pọ̀ jù, ìjọba ló ń bójú tó àwọn nǹkan yìí. Ka Títù 3:1, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Tó o bá ti ṣègbéyàwó, ṣé ó dá ẹ lójú pé o ní ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó tí ìjọba fi òǹtẹ̀ lù?
ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Kí lèèyàn ń ṣègbéyàwó fún? Ṣé obìnrin àtọkùnrin ò kàn lè máa gbé pọ̀ ni?”
Kí lo máa sọ?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀bùn ni kéèyàn wà láìní ọkọ tàbí aya, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbéyàwó ṣe jẹ́ ẹ̀bùn. Yálà a ní ọkọ tàbí aya àbí a ò ní, tá a bá ṣáà ti ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, a máa láyọ̀, ọkàn wa sì máa balẹ̀.
Kí lo rí kọ́?
Báwo lẹnì kan ṣe lè lo ẹ̀bùn wíwà láìní ọkọ tàbí aya lọ́nà tó dáa?
Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé kí Kristẹni kan fẹ́ Kristẹni bíi tiẹ̀?
Kí ni ìdí kan ṣoṣo tí Bíbélì sọ pé ó lè mú kẹ́nì kan kọ ọkọ tàbí aya ẹ̀ sílẹ̀?
ṢÈWÁDÌÍ
Kí ló túmọ̀ sí láti gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa”?
Wo àṣefihàn méjì táá ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó dáa tó o bá ń ronú láti fẹ́ ẹnì kan sọ́nà tàbí ṣègbéyàwó.
Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó mú kí arákùnrin kan gbà pé àwọn nǹkan tí Jèhófà ti fún òun ṣeyebíye ju àwọn nǹkan tí òun yááfì lọ.
Kí ló yẹ kí ẹnì kan fi sọ́kàn tó bá fẹ́ kọ ìyàwó tàbí ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ tàbí tó fẹ́ pínyà?
“Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú ‘Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀’” (Ilé Ìṣọ́, December 2018)
a Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 4 kó o lè mọ ohun tó lè mú kí tọkọtaya kan pínyà láìjẹ́ pé ẹnì kan nínú wọn ṣàgbèrè.
b Láwọn ìlú kan, àwọn òbí ló máa ń wá ọkọ tàbí ìyàwó fáwọn ọmọ wọn. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn ò ní wo bẹ́nì kan ṣe lówó tó tàbí bó ṣe lẹ́nu tó láwùjọ láti pinnu ẹni tí wọ́n máa fẹ́ fún ọmọ wọn, dípò ìyẹn ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wọn ni pé ki onítọ̀hún nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.
c Tí ìwọ àti ẹni tẹ́ ẹ̀ jọ ń gbé báyìí ò bá ṣègbéyàwó lọ́nà tó bófin mu, ìwọ fúnra ẹ lo máa pinnu bóyá kó o ṣègbéyàwó pẹ̀lú onítọ̀hún àbí kó o fi sílẹ̀.