Ẹ̀KỌ́ 36
Ṣíṣàlàyé Ẹṣin Ọ̀rọ̀
ÀWỌN tí wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu ọ̀rọ̀ sísọ mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí ọ̀rọ̀ ẹni ní ẹṣin ọ̀rọ̀. Bí wọ́n bá ń múra ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa sọ, ẹṣin ọ̀rọ̀ máa ń jẹ́ kí wọ́n lè pọkàn pọ̀ sórí kókó mélòó kan tí wọ́n máa ṣàlàyé, kí wọ́n sì ronú jinlẹ̀ lé e lórí. Àǹfààní rẹ̀ ni pé wọ́n á lè ṣàlàyé ọ̀rọ̀ wọn dáadáa fún àwùjọ dípò tí wọ́n á fi kó àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó pọ̀ jọ, tí wọn kò sì ní lè ṣàlàyé wọn tó bó ṣe yẹ. Tí kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan bá so pọ̀ mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ ní tààràtà, tó sì jẹ́ ká lè ṣàlàyé nípa ẹṣin ọ̀rọ̀ yẹn síwájú sí i, ó máa ń jẹ́ kí àwùjọ lè rántí kókó wọ̀nyẹn kí wọ́n sì tún rí bí ó ti ṣe pàtàkì tó.
Lóòótọ́ a lè sọ pé ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ ni kókó ẹ̀kọ́ tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí, àmọ́ wàá rí i pé bí ìwọ fúnra rẹ bá fi sọ́kàn pé ńṣe ni ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ àlàyé ọ̀nà kan pàtó tí o gbà ń wo kókó ẹ̀kọ́ tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí, wàá lè sọ ọ̀rọ̀ yẹn lọ́nà tó túbọ̀ dára sí i. Ìjọba Ọlọ́run, Bíbélì àti àjíǹde jẹ́ kókó ẹ̀kọ́ tó gbòòrò. Oríṣiríṣi ẹṣin ọ̀rọ̀ la lè fà jáde látinú àwọn kókó ẹ̀kọ́ wọ̀nyí. Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ nìyí: “Ìjọba Ọlọ́run Jẹ́ Ìṣàkóso Gidi Kan,” “Ìjọba Ọlọ́run Yóò Sọ Ayé Di Párádísè,” “Bíbélì Ni Ọlọ́run Mí Sí,” “Bíbélì Jẹ́ Amọ̀nà Tó Wúlò fún Wa Lóde Òní,” “Àjíǹde Mú Kí Àwọn Tí Ọ̀fọ̀ Ṣẹ̀ Nírètí” àti “Ìrètí Àjíǹde Ń Mú Kí A Lè Dúró Lórí Òtítọ́ Lójú Inúnibíni.” Bí a bá fẹ́ sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ó gbà ṣàlàyé gbogbo wọn.
Ẹṣin ọ̀rọ̀ tó wà níbàámu pẹ̀lú lájorí ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì ni Jésù Kristi tẹnu mọ́ nínú ìwàásù rẹ̀ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ẹṣin ọ̀rọ̀ ọ̀hún ni: “Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” (Mát. 4:17) Àlàyé wo ló ṣe lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí? Ó ju àádọ́fà [110] ìgbà lọ tí ó fi sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba yẹn nínú ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé Jésù kàn ń pe ọ̀rọ̀ náà “ìjọba” ní àpètúnpè ṣáá. Jésù tipa ohun tó fi kọ́ni àti àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe mú kó ṣe kedere pé òun tóun wà láàárín wọn yìí ni Ọmọ Ọlọ́run, òun ni Mèsáyà, ẹni tí Jèhófà yóò gbé Ìjọba yẹn lé lọ́wọ́. Jésù tún fi hàn pé ọ̀nà tipasẹ̀ òun là fún àwọn mìíràn láti wá kópa nínú Ìjọba yẹn. Ó sọ àwọn ànímọ́ tí ẹni tí Ọlọ́run bá máa fún láǹfààní láti kópa nínú rẹ̀ gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ní. Jésù lo ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ni àti àwọn iṣẹ́ àrà tó ṣe láti fi mú kí ohun tí Ìjọba Ọlọ́run yóò gbé ṣe ní ìgbésí ayé àwọn èèyàn ṣe kedere. Ó sì tún fi hàn kedere pé fífi tí òun ń fi ẹ̀mí Ọlọ́run lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde fi hàn pé ‘ìjọba Ọlọ́run ti dé bá’ àwọn tí òun bá sọ̀rọ̀ yẹn lójijì ní ti tòótọ́. (Lúùkù 11:20) Iṣẹ́ ìwàásù nípa Ìjọba yẹn sì ni Jésù gbé lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe.—Mát. 10:7; 24:14.
Lílo Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Tó Ba A Mu. Ohun tí à ń sọ níbí kì í ṣe pé kí o máa ṣàlàyé ẹṣin ọ̀rọ̀ lọ́nà tó jinlẹ̀ bíi ti Bíbélì gẹ́lẹ́, ṣùgbọ́n bí Bíbélì ṣe lẹ́ṣin ọ̀rọ̀ tó bá a mu ni ìwọ pẹ̀lú ṣe ní láti ní in.
Bó bá jẹ́ pé fúnra rẹ lo máa yan ẹṣin ọ̀rọ̀ tó o máa lò, kọ́kọ́ ronú nípa iṣẹ́ tó o fẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe. Lẹ́yìn náà, bí o ṣe ń yan àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó o máa kọ sínú ìlapa èrò rẹ, rí i dájú pé kókó wọ̀nyẹn ti ẹṣin ọ̀rọ̀ tó o yàn lẹ́yìn ní ti gidi.
Bí a bá ti yan ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ síbẹ̀ tẹ́lẹ̀, fara balẹ̀ gbé ohun tí ẹṣin ọ̀rọ̀ yẹn fi hàn yẹ̀ wò láti mọ̀ nípa ọ̀nà tó yẹ kó o gbé àlàyé ọ̀rọ̀ rẹ gbà. Ó lè gba ìsapá kó o tó lè rí bí ẹṣin ọ̀rọ̀ yẹn ṣe wúlò tó àti iṣẹ́ ribiribi tó o lè fi ṣe o. Bó bá jẹ́ pé ìwọ lo máa wá ìsọfúnni tó o máa fi sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn fún ọ, ńṣe ni kó o fara balẹ̀ yan èyí tí wàá lò kí o má bàa yà kúrò lórí ohun tí ẹṣin ọ̀rọ̀ ọ̀hún dá lé lórí. Bó bá sì jẹ́ pé a ti pèsè ìsọfúnni tó o máa fi ṣàlàyé rẹ̀, ó ṣì yẹ kí o wo ọ̀nà tó o máa gbà lò ó tá á fi bá ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ mu. Ó sì tún yẹ kí o ronú nípa ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwùjọ gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn àti nǹkan tó yẹ kí o fi ọ̀rọ̀ yẹn sún wọn ṣe. Èyí yóò jẹ́ kí o lè mọ ohun tó yẹ kí o tẹnu mọ́ nígbà tó o bá ń sọ ọ́.
Bí O Ṣe Lè Tẹnu Mọ́ Ẹṣin Ọ̀rọ̀. Láti lè tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ, ìgbà tó o bá ń yan ọ̀rọ̀ tó o máa lò títí kan ìgbà tó o bá ń kó ọ̀rọ̀ yẹn jọ ni kí o ti fi ìpìlẹ̀ bó o ṣe máa tẹnu mọ́ ọn lélẹ̀. Bí o bá yan kìkì ọ̀rọ̀ tó ti ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́yìn, tí o sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà nípa bí o ṣe lè ṣètò ìlapa èrò tó dára, kò sí bó ò ṣe ní tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ yẹn.
Àsọtúnsọ lè túbọ̀ gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ yọ dáadáa. Nínú orin ewì, ohun tó máa ń jẹ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ ewì sábà máa ń jẹ́ ọ̀rọ̀ tí akéwì yóò sọ lásọtúnsọ débi pé òun ló máa hàn gedegbe jálẹ̀ orin ewì yẹn. Kì í ṣe ọ̀nà kan náà ló máa ń gbà sọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ yìí lásọtúnsọ jálẹ̀ ewì náà. Nígbà mìíràn ó kàn lè jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tàbí méjì lára gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà ni yóò fara hàn láàárín kan nínú ewì náà, tàbí kó tiẹ̀ fi ọ̀rọ̀ mìíràn gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ yẹn yọ nígbà mìíràn, ṣùgbọ́n lóríṣiríṣi ọ̀nà, akéwì á fi òye wé kókó yẹn mọ́nú ewì rẹ̀ títí tí á fi hàn jálẹ̀ gbogbo rẹ̀. Bó ṣe yẹ kí ẹṣin ọ̀rọ̀ kan rí nìyẹn. Títún ọ̀rọ̀ pàtàkì nínú ẹṣin ọ̀rọ̀ sọ ló dà bí ìgbà tí gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan ń fara hàn léraléra nínú ewì. Lílo ọ̀rọ̀ tó jọ gbólóhùn yìí tàbí fífi gbólóhùn mìíràn tún ẹṣin ọ̀rọ̀ yẹn sọ jẹ́ ọ̀nà mìíràn láti gbà gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ yọ. Lílo onírúurú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ni yóò jẹ́ kí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ di ohun pàtàkì tí àwùjọ yóò máa rántí nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
Ọ̀rọ̀ tí a máa sọ lórí pèpéle nìkan kọ́ la lè lo ìlànà yìí fún, ó kan ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wa lóde ẹ̀rí pẹ̀lú. Bí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kúkúrú kan bá lẹ́ṣin ọ̀rọ̀ tó hàn gedegbe, á di ọ̀rọ̀ tí kò ṣeé gbàgbé. Tí a bá tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ kan pàtó nígbà tí a bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa ń jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ lè máa rántí ìtọ́ni tí a fún un. Bí o bá ṣe ń ṣakitiyan tó láti rí i pé o yan ẹṣin ọ̀rọ̀ tó bá a mu àti láti rí i pé o ṣàlàyé rẹ̀ bó ṣe yẹ ni yóò jẹ́ kí o di olùbánisọ̀rọ̀ àti olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó múná dóko.