Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
A Kókìkí Jésù Gẹ́gẹ́ Bíi Mèsáyà àti Ọba!
OGUNLỌ́GỌ̀ tí ń pariwo wọ Jerúsálẹ́mù ní Nísàn 9, 33 Sànmánì Tiwa, ya àwọn ará Jùdíà lẹ́nu. Bí kò tilẹ̀ ṣàjèjì láti rí àwọn ènìyàn tí ń rọ́ wọ inú ilù náà ṣáájú Àjọ Ìrékọjá, àwọn àlejò wọ̀nyí yàtọ̀. Ọkùnrin tí ń gun agódóńgbó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ẹni pàtàkì náà láàárín wọn. Jésù Kristi ni ọkùnrin náà, àwọn ènìyàn náà sì ń tẹ́ aṣọ àti imọ̀ ọ̀pẹ síwájú rẹ̀, bí wọ́n ti ń kígbe pé: “Gba Ọmọkùnrin Dáfídì là, ni àwa bẹ̀bẹ̀! Alábùkún fún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà! Gbà á là, ni àwa bẹ̀bẹ̀, ní àwọn ibi gíga lókè!” Ní rírí ogunlọ́gọ̀ náà, a sún ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ti wà ní Jerúsálẹ́mù ṣáájú láti dara pọ̀ mọ́ ìtọ́wọ̀ọ́rìn náà.—Mátíù 21:7-9; Jòhánù 12:12, 13.
Bí a tilẹ̀ ń kókìkí rẹ̀ nísinsìnyí, Jésù mọ̀ pé àdánwò ń dúró de òun. Họ́wù, ní ọjọ́ márùn-ún péré sí i, a óò ṣekú pa á ní ìlú yìí kan náà! Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù mọ̀ pé Jerúsálẹ́mù jẹ́ àgbègbè tí àwọn ènìyàn kò ti níwà bí ọ̀rẹ́, pẹ̀lú èrò yẹn gan-an lọ́kàn ni ó sì fi wọnú ìlú náà lọ lọ́nà tí ó gbàfiyèsí.
A Mú Àsọtẹ́lẹ̀ Ìgbàanì Ṣẹ
Ní 518 ṣááju Sànmánì Tiwa, Sekaráyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí Jésù yóò ṣe fi ayọ̀ ìṣẹ́gun wọnú Jerúsálẹ́mù. Ó kọ̀wé pé: “Hó, Ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù: kíyè sí i, Ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ: òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà; ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kétẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. . . . Yóò sì sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí àwọn kèfèrí: ìjọba rẹ̀ yóò sì jẹ́ láti òkun dé òkun, àti láti odò títí dé òpin ayé.”—Sekaráyà 9:9, 10.
Nítorí náà, wíwọ̀ tí Jésù wọnú Jerúsálẹ́mù ní Nísàn 9 mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Kì í ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀, bí kò ṣe èyí tí a wéwèé ṣáájú dáradára. Ṣáájú ìgbà yẹn, nígbà tí wọ́n sún mọ́ Jerúsálẹ́mù, Jésù ti fún méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nítọ̀ọ́ni pé: “Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n lọ sínú abúlé tí ẹ ń wò yí, ní kíá másá ni ẹ̀yin yóò sì rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, àti agódóńgbó kan pẹ̀lú rẹ̀; ẹ tú wọn kí ẹ sì mú wọn wá fún mi. Bí ẹnì kan bá sì wí ohunkóhun fún yín, ẹ gbọ́dọ̀ wí pé, ‘Olúwa nílò wọn.’ Látàrí ìyẹn òun yóò fi wọ́n ránṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.” (Mátíù 21:1-3) Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí Jésù fi fẹ́ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá sí Jerúsálẹ́mù, kí sì ni ìjẹ́pàtàkì ìhùwàpadà ogunlọ́gọ̀ náà?
Ìhìn Iṣẹ́ Tí Ó Ní Í Ṣe Pẹ̀lú Ipò Ọba
Ìran tí a lè fojú rí sábà máa ń lágbára ju ọ̀rọ̀ tí a sọ lẹ́nu lọ. Nípa báyìí, nígbà míràn, Jèhófà máa ń jẹ́ kí àwọn wòlíì rẹ̀ ṣàṣefihàn ìhìn iṣẹ́ wọn láti lè mú ìhìn iṣẹ́ alásọtẹ́lẹ̀ wọn lágbára sí i. (Àwọn Ọba Kìíní 11:29-32; Jeremáyà 27:1-6; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 4:1-17) Ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tí a lè fojú rí dáradára yìí, fi èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn tí kò ṣeé parẹ́ sí ọkàn olùwòran tí ọkàn rẹ̀ yigbì jù lọ pàápàá. Ní ọ̀nà kan náà, Jésù ṣàṣefihàn ìhìn iṣẹ́ lílágbára kan nípa gígun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan wọnú ìlú Jerúsálẹ́mù. Báwo?
Ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, a máa ń lo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ fún àwọn ète ọlọ́lá. Fún àpẹẹrẹ, Sólómọ́nì gun “ìbaaka,” àdàmọ̀dì akọ ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ti bàbá rẹ̀ lọ sí ibi tí a ti fòróró yàn án gẹ́gẹ́ bí ọba. (Àwọn Ọba Kìíní 1:33-40) Nítorí náà, fún Jésù láti gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnú Jerúsálẹ́mù yóò túmọ̀ sí pé ó ń fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ọba.a Ìgbésẹ̀ ogunlọ́gọ̀ náà fìdí ìhìn iṣẹ́ yìí múlẹ̀. Àwùjọ náà, tí ó dájú pé àwọn ará Gálílì ni ó pọ̀ jù nínú wọn, tẹ́ aṣọ wọn síwájú Jésù—ìgbésẹ̀ tí ó ránni létí ìkéde ìtagbangba ìfọbajẹ Jéhù. (Àwọn Ọba Kejì 9:13) Títọ́ka tí wọ́n tọ́ka sí Jésù gẹ́gẹ́ bí “Ọmọkùnrin Dáfídì,” tẹnu mọ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀ sí agbára ìṣàkóso lọ́nà tí ó bófin mu. (Lúùkù 1:31-33) Lílò tí wọ́n sì lo imọ̀ ọ̀pẹ fi hàn kedere pé wọ́n mú ara wọn wá sábẹ́ ọlá àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.—Fi wé Ìṣípayá 7:9, 10.
Nítorí náà, àwùjọ àwọn àtọ́wọ̀ọ́rìn tí ó wọnú Jerúsálẹ́mù ní Nísàn 9 fi ìhìn iṣẹ́ tí ó ṣe kedere náà hàn pé Jésù ni Mèsáyà àti Ọba tí Ọlọ́run yàn sípò. Àmọ́ ṣáá o, kì í ṣe gbogbo wọn ni inú wọ́n dùn láti rí i kí Jésù fara hàn lọ́nà yí. Àwọn Farisí ní pàtàkì ronú pé kò tọ́ rárá láti fún Jésù ní irú iyì ọba tí a fún un. Wọ́n fi dandan gbọ̀n béèrè, tìbínútìbínú pé: “Olùkọ́, bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ wí lọ́nà mímúná.” Jésù fèsì pé: “Mo sọ fún yín, Bí àwọn wọ̀nyí bá dákẹ́, àwọn òkúta yóò ké jáde.” (Lúùkù 19:39, 40) Bẹ́ẹ̀ ni, Ìjọba Ọlọ́run ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìwàásù Jésù. Òun yóò fi ìgboyà polongo ìhìn iṣẹ́ yìí yálà àwọn ènìyàn tẹ́wọ́ gbà á tàbí wọn kò tẹ́wọ́ gbà á.
Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
Ó gba ìgboyà ńlá fún Jésù láti wọ Jerúsálẹ́mù ní ọ̀nà tí wòlíì Sekaráyà sọ tẹ́lẹ̀. Ó mọ̀ pé nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ òun ń wá ìrunú àwọn ọ̀tá òun. Ṣáájú ìgòkè re ọ̀run rẹ̀, Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kí wọ́n sì “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Láti ṣàṣeparí iṣẹ́ yìí pẹ̀lú ń béèrè ìgboyà. Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni inú wọ́n dùn láti gbọ́ ìhìn iṣẹ́ náà. Àwọn kan ṣàìbìkítà nípa rẹ̀, nígbà tí àwọn mìíràn ń ta kò ó. Àwọn ìjọba kan ti ka iṣẹ́ ìwàásù náà léèwọ̀ tàbí kí wọ́n tilẹ̀ gbẹ́sẹ̀ lé e pátápátá.
Síbẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé, àwọn ní láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀, yálà àwọn ènìyàn fetí sílẹ̀ tàbí wọ́n kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 2:7) Bí wọ́n ti ń bá a lọ láti ṣe iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yí, a ń mú ìlérí Jésù dá wọn lójú pé: “Wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.”—Mátíù 28:20.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àkọsílẹ̀ ìròyìn Máàkù fi kún un pé, agódóńgbó náà jẹ́ ọ̀kan “lórí èyí tí ọ̀kankan nínú aráyé kò tí ì jókòó rí.” (Máàkù 11:2) Ní kedere, ẹranko tí a kò tí ì lò rí, yẹ dáradára fún ète mímọ́ ọlọ́wọ̀.—Fi wé Númérì 19:2; Diutarónómì 21:3; Sámúẹ́lì Kíní 6:7.