Àwọn Ọba Kìíní
1 Nígbà náà, Ọba Dáfídì ti darúgbó,+ ó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún* láyé, bí wọ́n tiẹ̀ ń fi aṣọ bò ó, òtútù ṣì máa ń mú un. 2 Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Jẹ́ kí a bá olúwa wa ọba wá ọmọbìnrin kan tó jẹ́ wúńdíá,* kó lè máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọba, kó sì máa tọ́jú rẹ̀. Ẹ̀gbẹ́ rẹ ni á máa sùn sí kí ara olúwa wa ọba lè móoru.” 3 Wọ́n wá ọmọbìnrin tó rẹwà kiri gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n rí Ábíṣágì+ ará Ṣúnémù,+ wọ́n sì mú un wá fún ọba. 4 Ọmọbìnrin náà lẹ́wà gan-an, ó di olùtọ́jú ọba, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ ọba kò bá a lò pọ̀.
5 Ní àkókò yìí, Ádóníjà+ ọmọkùnrin Hágítì ń gbé ara rẹ̀ ga, ó ń sọ pé: “Èmi ló máa di ọba!” Ó ní kí wọ́n ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún òun, ó kó àwọn agẹṣin jọ àti àádọ́ta (50) ọkùnrin tí á máa sáré níwájú rẹ̀.+ 6 Àmọ́ bàbá rẹ̀ kò bi í* pé: “Kí nìdí tí o fi ṣe báyìí?” Òun náà lẹ́wà gan-an, ìyá rẹ̀ sì bí i lẹ́yìn tí wọ́n bí Ábúsálómù. 7 Ó lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Jóábù ọmọ Seruáyà àti àlùfáà Ábíátárì,+ wọ́n ran Ádóníjà lọ́wọ́, wọ́n sì tì í lẹ́yìn.+ 8 Àmọ́ àlùfáà Sádókù,+ Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà, wòlíì Nátánì,+ Ṣíméì,+ Réì àti àwọn akíkanjú jagunjagun Dáfídì+ kò ti Ádóníjà lẹ́yìn.
9 Níkẹyìn, Ádóníjà fi àgùntàn àti màlúù pẹ̀lú ẹran àbọ́sanra rúbọ+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkúta Sóhélétì, èyí tó wà nítòsí Ẹn-rógélì, ó pe gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àwọn ọmọ ọba àti gbogbo ọkùnrin Júdà tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ ọba. 10 Àmọ́ kò pe wòlíì Nátánì àti Bẹnáyà àti àwọn jagunjagun tó lákíkanjú, bẹ́ẹ̀ ni kò pe Sólómọ́nì àbúrò rẹ̀. 11 Nátánì+ wá sọ fún Bátí-ṣébà,+ ìyá Sólómọ́nì+ pé: “Ṣé o kò tíì gbọ́ pé Ádóníjà+ ọmọ Hágítì ti di ọba, olúwa wa Dáfídì kò sì mọ nǹkan kan nípa rẹ̀? 12 Ní báyìí, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n gbà ọ́ nímọ̀ràn, kí o lè dá ẹ̀mí ara rẹ àti ti* Sólómọ́nì ọmọ rẹ sí.+ 13 Wọlé lọ bá Ọba Dáfídì, kí o sọ fún un pé, ‘Olúwa mi ọba, ṣebí ìwọ lo búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé: “Sólómọ́nì ọmọ rẹ ló máa di ọba lẹ́yìn mi, òun ló sì máa jókòó sórí ìtẹ́ mi”?+ Kí ló dé tí Ádóníjà fi wá di ọba?’ 14 Nígbà tí o bá ń bá ọba sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi náà á wọlé wá, màá sì jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ.”
15 Torí náà, Bátí-ṣébà wọlé lọ bá ọba nínú yàrá àdáni rẹ̀. Ọba ti darúgbó gan-an, Ábíṣágì+ ará Ṣúnémù sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba. 16 Ìgbà náà ni Bátí-ṣébà tẹrí ba, ó sì wólẹ̀ fún ọba, ọba wá sọ pé: “Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” 17 Ó dáhùn pé: “Olúwa mi, ìwọ lo fi Jèhófà Ọlọ́run rẹ búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé, ‘Sólómọ́nì ọmọ rẹ ló máa di ọba lẹ́yìn mi, òun ló sì máa jókòó sórí ìtẹ́ mi.’+ 18 Àmọ́ ní báyìí, Ádóníjà ti di ọba! Olúwa mi ọba kò sì mọ nǹkan kan nípa rẹ̀.+ 19 Ó fi akọ màlúù àti ẹran àbọ́sanra pẹ̀lú àgùntàn tó pọ̀ gan-an rúbọ, ó pe gbogbo ọmọ ọba àti àlùfáà Ábíátárì pẹ̀lú Jóábù olórí ọmọ ogun;+ àmọ́ kò pe Sólómọ́nì ìránṣẹ́ rẹ.+ 20 Ní báyìí, olúwa mi ọba, ojú rẹ ni gbogbo Ísírẹ́lì ń wò pé kí o sọ ẹni tó máa jókòó sórí ìtẹ́ olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ̀ fún wọn. 21 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ojú ọ̀dàlẹ̀ ni wọ́n máa fi wo èmi àti Sólómọ́nì ọmọ mi ní gbàrà tí olúwa mi ọba bá ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀.”
22 Nígbà tó ń bá ọba sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wòlíì Nátánì wọlé.+ 23 Ní kíá, wọ́n sọ fún ọba pé: “Wòlíì Nátánì ti dé!” Ó wọlé síwájú ọba, ó tẹrí ba, ó sì wólẹ̀. 24 Ìgbà náà ni Nátánì sọ pé: “Olúwa mi ọba, ṣé o sọ pé, ‘Ádóníjà ló máa di ọba lẹ́yìn mi, òun ló sì máa jókòó sórí ìtẹ́ mi’?+ 25 Torí pé lónìí, ó ti lọ fi akọ màlúù àti ẹran àbọ́sanra pẹ̀lú àgùntàn tó pọ̀ gan-an rúbọ,+ ó pe gbogbo ọmọ ọba àti àwọn olórí ọmọ ogun pẹ̀lú àlùfáà Ábíátárì.+ Wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí wọ́n ń jẹ, tí wọ́n sì ń mu, wọ́n ń sọ pé, ‘Kí ẹ̀mí Ọba Ádóníjà gùn o!’ 26 Ṣùgbọ́n kò pe èmi ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò pe àlùfáà Sádókù àti Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà àti Sólómọ́nì ìránṣẹ́ rẹ. 27 Ṣé olúwa mi ọba ti fàṣẹ sí ọ̀rọ̀ yìí láìjẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ mọ ẹni tó yẹ kó jókòó sórí ìtẹ́ olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ̀ ni?”
28 Ọba Dáfídì wá fèsì pé: “Ẹ pe Bátí-ṣébà wá fún mi.” Ni ó bá wọlé, ó sì dúró síwájú ọba. 29 Ìgbà náà ni ọba búra pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tó yọ mí* nínú gbogbo wàhálà,+ 30 bí mo ṣe fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra fún ọ, tí mo sọ pé: ‘Sólómọ́nì ọmọ rẹ ló máa di ọba lẹ́yìn mi, òun ló sì máa jókòó sórí ìtẹ́ mi ní ipò mi!’ ohun tí màá ṣe nìyẹn lónìí yìí.” 31 Ìgbà náà ni Bátí-ṣébà tẹrí ba, ó dojú bolẹ̀ fún ọba, ó sì sọ pé: “Kí olúwa mi Ọba Dáfídì wà títí láé!”
32 Ní kíá, Ọba Dáfídì sọ pé: “Ẹ pe àlùfáà Sádókù àti wòlíì Nátánì àti Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà+ wá fún mi.” Torí náà, wọ́n wọlé síwájú ọba. 33 Ọba sọ fún wọn pé: “Ẹ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa yín dání, kí ẹ sì ní kí Sólómọ́nì ọmọ mi gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* tèmi fúnra mi,+ kí ẹ wá mú un lọ sí Gíhónì.+ 34 Àlùfáà Sádókù àti wòlíì Nátánì yóò fòróró yàn án+ níbẹ̀ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì; lẹ́yìn náà kí ẹ fun ìwo, kí ẹ sì sọ pé, ‘Kí ẹ̀mí Ọba Sólómọ́nì gùn o!’+ 35 Lẹ́yìn náà, kí ẹ tẹ̀ lé e pa dà, kó sì wọlé wá jókòó sórí ìtẹ́ mi; òun ló máa jọba ní ipò mi, màá sì yàn án láti jẹ́ aṣáájú Ísírẹ́lì àti Júdà.” 36 Ní kíá, Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà sọ fún ọba pé: “Àmín! Kí Jèhófà Ọlọ́run olúwa mi ọba fọwọ́ sí i. 37 Bí Jèhófà ṣe wà pẹ̀lú olúwa mi ọba, bẹ́ẹ̀ ni kí ó wà pẹ̀lú Sólómọ́nì,+ kí ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ olúwa mi Ọba Dáfídì.”+
38 Lẹ́yìn náà, àlùfáà Sádókù àti wòlíì Nátánì àti Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà pẹ̀lú àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì+ jáde lọ, wọ́n ní kí Sólómọ́nì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* Ọba Dáfídì,+ wọ́n sì mú un wá sí Gíhónì.+ 39 Ni àlùfáà Sádókù bá mú ìwo òróró+ láti inú àgọ́,+ ó sì fòróró yan Sólómọ́nì,+ wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í fun ìwo, gbogbo èèyàn náà sì ń kígbe pé: “Kí ẹ̀mí Ọba Sólómọ́nì gùn o!” 40 Lẹ́yìn náà, gbogbo èèyàn náà tẹ̀ lé e lọ, wọ́n ń fun fèrè, inú wọn sì dùn gan-an débi pé ariwo wọn fa ilẹ̀ ya.*+
41 Ádóníjà àti gbogbo àwọn tí ó pè gbọ́ nígbà tí wọ́n jẹun tán.+ Gbàrà tí Jóábù gbọ́ ìró ìwo, ó sọ pé: “Kí nìdí tí ariwo fi gba gbogbo ìlú kan?” 42 Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Jónátánì+ ọmọ àlùfáà Ábíátárì dé. Ìgbà náà ni Ádóníjà sọ pé: “Wọlé wá, torí èèyàn dáadáa* ni ọ́, ó dájú pé ìròyìn ayọ̀ lo mú wá.” 43 Àmọ́ Jónátánì dá Ádóníjà lóhùn pé: “Rárá o! Ọba Dáfídì olúwa wa ti fi Sólómọ́nì jẹ ọba. 44 Ọba rán àlùfáà Sádókù àti wòlíì Nátánì àti Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà pẹ̀lú àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì tẹ̀ lé e, wọ́n sì ní kó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* ọba.+ 45 Lẹ́yìn náà, àlùfáà Sádókù àti wòlíì Nátánì fòróró yàn án ṣe ọba ní Gíhónì. Wọ́n wá kúrò níbẹ̀, inú wọn ń dùn, ariwo sì gba ìlú kan. Ariwo tí ẹ gbọ́ nìyẹn. 46 Yàtọ̀ síyẹn, Sólómọ́nì ti jókòó sórí ìtẹ́ ọba. 47 Ohun míì ni pé, àwọn ìránṣẹ́ ọba wọlé wá láti bá Ọba Dáfídì olúwa wa yọ̀, wọ́n sọ pé, ‘Kí Ọlọ́run rẹ mú kí orúkọ Sólómọ́nì gbayì ju orúkọ rẹ, kí ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ rẹ!’ Ni ọba bá tẹrí ba lórí ibùsùn. 48 Ọba sì sọ pé, ‘Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó fún mi ní ẹni tó máa jókòó sórí ìtẹ́ mi, tó sì jẹ́ kó ṣojú mi lónìí!’”
49 Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn tí Ádóníjà pè wá, kálukú wọn dìde, wọ́n sì bá tiwọn lọ. 50 Ẹ̀rù Sólómọ́nì ń ba Ádóníjà, torí náà, ó gbéra, ó sì lọ di àwọn ìwo pẹpẹ mú.+ 51 Wọ́n wá ròyìn fún Sólómọ́nì pé: “Wò ó, ẹ̀rù Ọba Sólómọ́nì ti ń ba Ádóníjà; ó sì ti lọ gbá àwọn ìwo pẹpẹ mú, ó sọ pé, ‘Kí Ọba Sólómọ́nì kọ́kọ́ búra fún mi pé òun ò ní fi idà pa ìránṣẹ́ rẹ̀.’” 52 Ni Sólómọ́nì bá sọ pé: “Tí kò bá kọjá àyè rẹ̀, kò sí ìkankan nínú irun orí rẹ̀ tó máa bọ́ sílẹ̀; àmọ́ tí a bá rí ohun tí kò dára lọ́wọ́ rẹ̀,+ ó gbọ́dọ̀ kú.” 53 Nítorí náà, Ọba Sólómọ́nì ní kí wọ́n lọ mú un wá láti ibi pẹpẹ. Lẹ́yìn náà, ó wọlé, ó sì tẹrí ba fún Ọba Sólómọ́nì, Sólómọ́nì wá sọ fún un pé: “Máa lọ sí ilé rẹ.”