Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ṣé lóòótọ́ la lè pe àwọn oníṣòwò tó ń tajà nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ní “ọlọ́ṣà”?
ÌWÉ Ìhìn Rere Mátíù sọ pé, “Jésù sì wọ inú tẹ́ńpìlì, ó sì lé gbogbo àwọn tí ń tà, tí wọ́n sì ń rà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì sojú tábìlì àwọn olùpààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tí ń ta àdàbà. Ó sì wí fún wọn pé: ‘A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, “Ilé mi ni a óò máa pè ní ilé àdúrà,” ṣùgbọ́n ẹ ń sọ ọ́ di hòrò àwọn ọlọ́ṣà.’”—Mát. 21:12, 13.
Ìwé ìtàn àwọn Júù kan fi hàn pé lóòótọ́ làwọn tó ń ṣòwò nínú tẹ́ńpìlì máa ń bu owó gegere sórí àwọn ọjà wọn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìtàn àwọn Júù kan sọ pé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, wọ́n ń ta ẹyẹlé méjì ní owó dínárì wúrà kan. Ìyẹn sì jẹ́ owó tí lébìrà kan máa gbà fún iṣẹ́ ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. Òfin Mósè sọ pé àwọn tálákà lè fi ẹyẹlé tàbí àdàbà rúbọ, síbẹ̀ owó gegere tí apá mẹ̀kúnnù ò lè ká ni wọ́n ń ta àwọn ẹyẹ náà. (Léf. 1:14; 5:7; 12:6-8) Inú bí Rábì kan tó ń jẹ́ Simeon ben Gamaliel sí ohun tí wọ́n ń ṣe yìí, torí náà ó mú kí iye ìrúbọ tó yẹ káwọn èèyàn náà máa rú dín kù. Èyí wá mú kí iye tí wọ́n ń ta ẹyẹlé méjì já wálẹ̀ gan-an.
Àwọn nǹkan yìí jẹ́ ká rí i pé bí Jésù ṣe pe àwọn oníṣòwò inú tẹ́ńpìlì ní “ọlọ́ṣà” bá a mu lóòótọ́ torí pé olójúkòkòrò ni wọ́n, wọ́n sì máa ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ.