Fara Mọ́ Ìṣàkóso Jèhófà!
“Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo.”—ÌṢÍ. 4:11.
1, 2. Kí ló yẹ kó dá ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lójú? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
BÁ A ṣe jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Èṣù fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso àti pé ó sàn káwa èèyàn máa ṣàkóso ara wa. Ṣé òótọ́ ni Sátánì sọ? Ká sọ pé àwọn èèyàn tó fẹ́ máa ṣàkóso ara wọn lè wà láàyè títí láé, ǹjẹ́ nǹkan á sàn fún wọn tí wọn ò bá sí lábẹ́ àkóso Ọlọ́run? Ká tiẹ̀ sọ pé o wà láàyè títí láé, ǹjẹ́ o rò pé nǹkan máa sàn fún ẹ tí o kò bá fi ti Ọlọ́run ṣe?
2 Kò sẹ́ni tó lè dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn fún ẹ. Oníkálukú wa gbọ́dọ̀ ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á dá wa lójú pé ọ̀nà tó tọ́ ni Jèhófà ń gbà ṣàkóso àti pé ìṣàkóso rẹ̀ ló dáa jù. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀. Bíbélì sọ ìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso.
JÈHÓFÀ LÓ LẸ́TỌ̀Ọ́ LÁTI ṢÀKÓSO
3. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run?
3 Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run torí pé òun ni Ọlọ́run Olódùmarè àti Ẹlẹ́dàá. (1 Kíró. 29:11; Ìṣe 4:24) Nínú Ìṣípayá 4:11, Jòhánù rí ìran kan níbi táwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tó máa bá Jésù jọba ti ń sọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Torí pé Jèhófà ló dá ohun gbogbo, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso gbogbo èèyàn àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì.
4. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àṣìlò òmìnira ni téèyàn bá kọ ìṣàkóso Jèhófà sílẹ̀?
4 Sátánì ò dá ohunkóhun. Torí náà, kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. Ìwà ọ̀yájú gbáà ni òun àti tọkọtaya àkọ́kọ́ hù bí wọ́n ṣe tako ìṣàkóso Jèhófà. (Jer. 10:23) Òótọ́ ni pé ẹ̀dá tó lómìnira ni wọ́n, àmọ́ ṣé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ ìṣàkóso Jèhófà sílẹ̀? Rárá o. Lóòótọ́, òmìnira tí ẹ̀dá èèyàn ní lè jẹ́ kí wọ́n yan ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe. Àmọ́, ìyẹn ò ní kí wọ́n kẹ̀yìn sí Ẹlẹ́dàá wọn. Ó ṣe kedere pé, wọ́n ṣi òmìnira wọn lò bí wọ́n ṣe kọ ìṣàkóso Jèhófà sílẹ̀. Torí náà, abẹ́ ìṣàkóso Jèhófà ló yẹ kí gbogbo èèyàn pátápátá fi ara wọn sí.
5. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá ṣe ló tọ́?
5 Ìdí míì tí Jèhófà fi lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso ayé àtọ̀run ni pé ó máa ń ṣe ìdájọ́ òdodo. Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi ni Jèhófà, Ẹni tí ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ìdájọ́ òdodo àti òdodo ní ilẹ̀ ayé; nítorí nǹkan wọ̀nyí ni mo ní inú dídùn sí.” (Jer. 9:24) Kì í ṣe òfin táwọn èèyàn aláìpé gbé kalẹ̀ ni Jèhófà ń wò kó tó pinnu ohun tó tọ́. Òun fúnra rẹ̀ ló máa ń pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ torí pé onídàájọ́ òdodo ni, ìdí nìyẹn tó fi gbé òfin kalẹ̀ fáwa èèyàn. Bíbélì sọ pé: “Òdodo àti ìdájọ́ ni ibi àfìdímúlẹ̀ ìtẹ́ [rẹ̀],” torí náà ọkàn wa balẹ̀ pé gbogbo òfin àti ìlànà tó fún wa ló tọ̀nà. (Sm. 89:14; 119:128) Lọ́wọ́ kejì, pẹ̀lú gbogbo atótónu Sátánì pé ìṣàkóso Jèhófà ò dáa, títí di báyìí, àìṣòdodo ló kún inú ayé Sátánì.
6. Kí nìdí míì tí Jèhófà fi lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé yìí?
6 Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso ayé àtọ̀run torí pé ó ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ táá fi bojú tó gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀ lágbára láti wo àwọn àìsàn táwọn dókítà ò lè wò sàn. (Mát. 4:23, 24; Máàkù 5:25-29) Àwọn nǹkan yìí kì í ṣe iṣẹ́ ìyanu lójú Jèhófà torí pé ó mọ bí gbogbo ẹ̀yà ara wa ṣe ń ṣiṣẹ́, ó sì lè tún ohun tó bá bà jẹ́ lára wa ṣe. Ó tún lágbára láti jí òkú dìde kó sì dènà àwọn àjálù bí ìmìtìtì ilẹ̀, omíyalé àtàwọn àjálù míì.
7. Kí ló fi hàn pé ọgbọ́n Jèhófà ju ti ayé yìí lọ fíìfíì?
7 Ayé tó wà lábẹ́ àkóso Sátánì yìí kò lè yanjú rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín ìlú àtèyí to ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Jèhófà nìkan ló ní ọgbọ́n tó lè fi mú kí àlàáfíà jọba kárí ayé. (Aísá. 2:3, 4; 54:13) Kò sígbà tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀ Jèhófà tí kì í jọ wá lójú. Ó sì máa ń ṣe wá bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ lábẹ́ ìmísí pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!”—Róòmù 11:33.
ÌṢÀKÓSO JÈHÓFÀ LÓ DÁA JÙ
8. Kí ló ń múnú rẹ dùn nípa bí Jèhófà ṣe ń ṣàkóso?
8 Yàtọ̀ sí pé Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, ó tún sọ ìdí tó fi jẹ́ pé ìṣàkóso Jèhófà ló dáa jù. Ìdí kan ni pé ìfẹ́ ló fi ń ṣàkóso. Ká sòótọ́, bí Jèhófà ṣe ń ṣàkóso máa ń múnú wa dùn gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà jẹ́ “aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” (Ẹ́kís. 34:6) Ọlọ́run máa ń buyì kún àwa èèyàn tá à ń sìn ín, ó sì máa ń pọ́n wa lé. Ó ń bójú tó wa ju bá a ṣe lè bójú tó ara wa lọ. Torí náà, irọ́ gbuu lẹ̀sùn tí Èṣù fi kan Ọlọ́run torí pé Jèhófà kì í fohun rere du àwọn tó ń sìn ín tọkàntọkàn. Kódà, ó nífẹ̀ẹ́ wa débi pé ó fi Ọmọ rẹ̀ fún wa ká lè rí ìyè àìnípẹ̀kun!—Ka Sáàmù 84:11; Róòmù 8:32.
9. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa?
9 Kì í ṣe pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn rẹ̀ lápapọ̀ nìkan, ó tún nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gan-an. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ọdún ni Jèhófà fi yan àwọn onídàájọ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì fún wọn lágbára láti dá àwọn èèyàn náà nídè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan nira fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo ìgbà yẹn, síbẹ̀ Jèhófà kíyè sí Rúùtù ọmọ ilẹ̀ Móábù tó fi ẹbí àtọ̀rẹ́ sílẹ̀ kó lè di olùjọsìn Jèhófà. Jèhófà bù kún Rúùtù, ó rọ́kọ fẹ́, ó sì tún bí ọmọkùnrin kan. Kò tán síbẹ̀ o. Nígbà tí Rúùtù bá jíǹde, ó máa gbọ́ pé àtọmọdọ́mọ òun ló di Mèsáyà. Ẹ wo bí inú rẹ̀ ti máa dùn tó nígbà tó bá wá mọ̀ pé ìtàn ìgbésí ayé òun wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì àti pé orúkọ òun ni ìwé náà ń jẹ́!—Rúùtù 4:13; Mát. 1:5, 16.
10. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà kì í ni àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lára?
10 Jèhófà kì í ni àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lára, kì í sì í ṣe apàṣẹwàá. Ó fún àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lómìnira, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n láyọ̀. (2 Kọ́r. 3:17) Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì sọ pé: “Iyì àti ọlá ńlá ń bẹ níwájú [Ọlọ́run], okun àti ìdùnnú ń bẹ ní ipò rẹ̀.” (1 Kíró. 16:7, 27) Étánì tóun náà kọ Sáàmù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí ó mọ igbe ìdùnnú. Jèhófà, inú ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ ni wọ́n ti ń rìn. Wọ́n ń kún fún ìdùnnú láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ní orúkọ rẹ, a sì gbé wọn ga nínú òdodo rẹ.”—Sm. 89:15, 16.
11. Ki la lè ṣe táá mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé ìṣàkóso Jèhófà ló dáa jù?
11 Tá a bá ń ṣàṣàrò déédéé lórí bí Jèhófà ṣe jẹ́ onínúure, á mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé ìṣàkóso rẹ̀ ló dáa jù. Àwa náà á sọ bíi ti onísáàmù pé: “Ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ níbòmíràn!” (Sm. 84:10) Ẹ ò rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé nìyẹn! Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, ó mọ àwọn ohun táá jẹ́ ká láyọ̀, ó sì ń fún wa láwọn nǹkan náà lọ́pọ̀ yanturu. Kò sóhun tí Jèhófà ní ká ṣe tí kì í ṣe fún àǹfààní wa, kódà tó bá tiẹ̀ gba pé ká yááfì àwọn nǹkan kan. Tá a bá ṣe ohun tó fẹ́, á ṣe wá láǹfààní, àá sì láyọ̀.—Ka Aísáyà 48:17.
12. Kí nìdí tá a fi ń fara wa sábẹ́ àkóso Jèhófà?
12 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kan ṣì máa ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. (Ìṣí. 20:7, 8) Kí ló máa mú kí wọ́n ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀? Lẹ́yìn tí Jésù bá tú Èṣù sílẹ̀, Èṣù máa wá báá ṣe ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Á mú kí wọ́n ṣe tinú ara wọn torí pé ọjọ́ pẹ́ tó ti máa ń lo ìdẹkùn yìí. Ó lè fẹ́ yí àwọn èèyàn lérò pa dà pé kò di dandan kí wọ́n ṣe ìfẹ́ Jèhófà kí wọ́n tó wà láàyè títí láé. Àmọ́ ó ṣe kedere pé irọ́ nìyẹn. Ìbéèrè náà ni pé: Ṣé a máa gba irọ́ bẹ́ẹ̀ gbọ́? Ó dájú pé a ò ní gba irọ́ yẹn gbọ́ tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tá a sì ń sìn ín torí pé ó jẹ́ onínúure àti pé òun nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. Àwa ò ní ronú ẹ̀ láé pé a fẹ́ máa wà láàyè nìṣó láìfi ara wa sábẹ́ àkóso Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́.
FARA MỌ́ ÌṢÀKÓSO JÈHÓFÀ LÁÌYẸHÙN
13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà?
13 Ó ṣe kedere pé ó yẹ ká fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà láìyẹhùn. A ti rí i pé Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, àkóso rẹ̀ ló sì dáa jù. A lè fi hàn pé a fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà tá a bá ń pa ìwà títọ́ wa mọ́, tá a sì ń fòótọ́ ọkàn sìn ín. Kí lohun míì tá a tún lè ṣe? Ó ṣe pàtàkì pé ká máa fi àwọn ìlànà òdodo Jèhófà sílò. Tá a bá ń ṣe nǹkan bí Jèhófà ṣe fẹ́, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé a fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀.—Ka Éfésù 5:1, 2.
14. Báwo làwọn olórí ìdílé àtàwọn alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà?
14 A kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a sì mọ̀ pé tìfẹ́tìfẹ́ ni Jèhófà máa ń lo agbára rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn olórí ìdílé àtàwọn alàgbà tó mọyì ìṣàkóso Jèhófà kì í jẹ gàba lé àwọn tó wà lábẹ́ wọn lórí, bí ẹni pé wọ́n gbé ìjọba tiwọn kalẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Jèhófà ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù, ọ̀kan ni Pọ́ọ̀lù. (1 Kọ́r. 11:1) Pọ́ọ̀lù kì í dójú ti àwọn èèyàn, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í fipá mú wọn ṣe ohun tó tọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń rọ̀ wọ́n. (Róòmù 12:1; Éfé. 4:1; Fílém. 8-10) Bí Jèhófà ṣe máa ń ṣe nǹkan nìyẹn. Torí náà, bó ṣe yẹ kí gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀ máa ṣe nìyẹn.
15. Báwo la ṣe ń fi hàn pé a fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà?
15 Báwo ló ṣe yẹ ká hùwà sáwọn tí Jèhófà yàn sípò? Ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún wọn, ká sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn. À ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà. Ká tiẹ̀ sọ pé a ò fi bẹ́ẹ̀ lóye ìpinnu tí wọ́n ṣe tàbí pé ìpinnu náà kò tẹ́ wa lọ́rùn, ẹ jẹ́ ká ṣègbọràn torí pé Jèhófà ló yàn wọ́n sípò. Ṣe làwọn èèyàn inú ayé máa ń fàáké kọ́rí tí wọn ò bá fara mọ́ ìpinnu táwọn aláṣẹ bá ṣe, àmọ́ tiwa ò rí bẹ́ẹ̀ torí pé Jèhófà ló ń ṣàkóso wa. (Éfé. 5:22, 23; 6:1-3; Héb. 13:17) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, à ń jàǹfààní bá a ṣe fara wa sábẹ́ àkóso rẹ̀.
16. Báwo làwọn tó fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà ṣe máa ń ṣèpinnu?
16 A tún lè fi hàn pé a fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà nínú àwọn ìpinnu tá à ń ṣe. Jèhófà kì í ṣe alákòóso tó máa ń ṣòfin lórí gbogbo nǹkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń tọ́ wa sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, kò ṣe òfin jàn-ànràn jan-anran nípa irú aṣọ tó yẹ káwa Kristẹni máa wọ̀. Ṣe ló ń rọ̀ wá pé ká jẹ́ kí aṣọ wa àti ìmúra wa wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí ó sì yẹ Kristẹni tòótọ́. (1 Tím. 2:9, 10) Bákan náà, Ọlọ́run ò fẹ́ ká ṣe ohunkóhun tó máa mú káwọn míì kọsẹ̀ tàbí tó máa da ẹ̀rí ọkàn wọn láàmú. (1 Kọ́r. 10:31-33) Tá a bá ń fi ìlànà Jèhófà sílò, tá a jẹ́ kí èrò rẹ̀ máa darí wa dípò ká máa ṣe tinú wa, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀.
17, 18. Báwo làwọn tọkọtaya ṣe lè fi hàn pé àwọn fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà?
17 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa báwọn tọkọtaya Kristẹni ṣe lè máa fi ìlànà Jèhófà sílò, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀. Kí ni wọ́n lè ṣe tí ìgbéyàwó wọn ò bá rí bí wọ́n ṣe rò tàbí tí àárín wọn ò wọ̀ rárá? Á dáa kí wọ́n ronú jinlẹ̀ nípa àjọṣe àárín Jèhófà àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́. Jèhófà fi ara rẹ̀ wé ọkọ orílẹ̀-èdè náà. (Aísá. 54:5; 62:4) Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì da ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ fún Jèhófà. Síbẹ̀, Jèhófà mú sùúrù fún wọn. Léraléra ló ń fàánú hàn sí wọn, tó sì ń rántí májẹ̀mú tó bá wọn dá. (Ka Sáàmù 106:43-45.) Ǹjẹ́ ìfẹ́ alọ́májàá tí Jèhófà ní yìí kò wú ẹ lórí?
18 Torí náà, àwọn tọkọtaya tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Wọn kì í wá bí wọ́n ṣe máa kọ ara wọn sílẹ̀ lọ́nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ló so àwọn pọ̀, ó sì fẹ́ káwọn fà mọ́ ara wọn. Ìṣekúṣe nìkan ni Ìwé Mímọ́ sọ pé ó lè mú kí tọkọtaya yàn láti kọ ara wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì fẹ́ ẹlòmíì. (Mát. 19:5, 6, 9) Bí tọkọtaya bá ń sapá láti yanjú ìṣòro wọn, ṣe ni wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà.
19. Tá a bá ṣẹ Jèhófà, kí ló yẹ ká ṣe?
19 Torí pé a jẹ́ aláìpé, a máa ń ṣẹ Jèhófà. Jèhófà náà mọ̀ bẹ́ẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi pèsè ẹbọ ìràpadà Kristi. Torí náà, tá a bá ṣàṣìṣe, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wá. (1 Jòh. 2:1, 2) Tá a bá ṣàṣìṣe, dípò ká máa dá ara wa lẹ́bi ṣáá, ṣe ni ká kẹ́kọ̀ọ́ nínú wọn. Tá ò bá fi Jèhófà sílẹ̀, á dárí jì wá, á jẹ́ ká borí ẹ̀dùn ọkàn wa, á sì ràn wá lọ́wọ́ ká lè yẹra fún irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.—Sm. 103:3.
20. Kí nìdí tó fi yẹ ká fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà nísinsìnyí?
20 Nínú ayé tuntun, gbogbo wa la máa wà lábẹ́ àkóso Jèhófà, àá sì túbọ̀ lóye àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. (Aísá. 11:9) Àmọ́ ní báyìí, àwa ti ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe máa gbé nígbà yẹn. Láìpẹ́, Jèhófà máa jẹ́ kó ṣe kedere pé òun nìkan lòun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. Nítorí náà, ìsinsìnyí ló yẹ ká fi hàn pé a fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà, ká jẹ́ olóòótọ́, ká máa fìtara ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, ká sì máa fara wé e nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe.