Òfin Àtẹnudẹ́nu—Èé Ṣe Tí A Fi Kọ Ọ́ Sílẹ̀?
ÈÉ ṢE tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní kò fi tẹ́wọ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà? Ẹnì kan tí ọ̀ràn náà ṣojú rẹ̀ ròyìn pé: “Lẹ́yìn tí [Jésù] lọ sínú tẹ́ńpìlì, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin àwọn ènìyàn náà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó ń kọ́ni, wọ́n sì wí pé: ‘Ọlá àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ta ní sì fún ọ ní ọlá àṣẹ yìí?’” (Mátíù 21:23) Lójú tiwọn, Olódùmarè ti fún orílẹ̀-èdè Júù ní Tórà (Òfin), èyí sì sọ àwọn ọkùnrin kan di ẹni tí ó ní ọlá àṣẹ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ Jésù ní irú ọlá àṣẹ bẹ́ẹ̀?
Jésù fi ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ hàn fún Tórà àti àwọn tí òfin náà fún ní ojúlówó ọlá àṣẹ. (Mátíù 5:17-20; Lúùkù 5:14; 17:14) Ṣùgbọ́n, léraléra ni ó ń fi àwọn tí wọ́n ré àṣẹ Ọlọ́run kọjá bú. (Mátíù 15:3-9; 23:2-28) Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí a wá mọ̀ sí òfin àtẹnudẹ́nu. Jésù kò tẹ́wọ́ gba ọlá àṣẹ òfin yìí. Ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ kọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé, kìkì ẹni tí ó bá ń tẹ̀ lé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí àwọn aláṣẹ tó wà láàárín wọn fi lélẹ̀ nìkan ni Ọlọ́run lè tì lẹ́yìn.
Ibo ni òfin àtẹnudẹ́nu yìí tilẹ̀ ti pilẹ̀? Báwo ni àwọn Júù ṣe wá gbà pé ó ní ọlá àṣẹ kan náà bíi ti Òfin alákọsílẹ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́? Bó bá sì jẹ́ pé òfin àtẹnudẹ́nu ni a fẹ́ kó jẹ́ tẹ́lẹ̀, èé ṣe tí a fi wá kọ ọ́ sílẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn?
Ibo Ni Òfin Àtọwọ́dọ́wọ́ Ti Pilẹ̀?
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè tí Jèhófà Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú ní Òkè Sínáì ní ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa. Nípasẹ̀ Mósè, wọ́n gba àwọn òfin inú májẹ̀mú náà. (Ẹ́kísódù 24:3) Bí wọ́n bá tẹ̀ lé àwọn àṣẹ wọ̀nyí, wọn yóò lè ‘jẹ́ mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run wọn ti jẹ́ mímọ́.’ (Léfítíkù 11:44) Lábẹ́ májẹ̀mú Òfin, ìjọsìn Jèhófà ní àwọn ìrúbọ tí àwọn àlùfáà tí a yàn ń ṣe nínú. Ojúkò fún ìjọsìn gbọ́dọ̀ wà—èyí sì wá wà ní tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—Diutarónómì 12:5-7; 2 Kíróníkà 6:4-6.
Òfin Mósè pèsè àkópọ̀ ọ̀nà tí Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, yóò máa gbà jọ́sìn Jèhófà. Àmọ́ ṣá o, àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan wà tí òfin náà kò sọ ní kedere. Bí àpẹẹrẹ, Òfin náà ka ṣíṣiṣẹ́ ní Sábáàtì léèwọ̀, ṣùgbọ́n kò sọ ìyàtọ̀ pàtó tó wà láàárín iṣẹ́ àti àwọn ìgbòkègbodò mìíràn.—Ẹ́kísódù 20:10.
Ká ní Jèhófà bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀, òun ì bá ti pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ àṣẹ tó kárí gbogbo ìbéèrè tó lè wá síni lọ́kàn. Ṣùgbọ́n ó dá ẹ̀rí-ọkàn mọ́ ènìyàn, ọ̀nà tí ó sì gbà gbé òfin rẹ̀ kalẹ̀ sì fún wọn lómìnira dé àyè kan tí ó yọ̀ọ̀da fún wọn láti lo àtinúdá láti sìn ín. Òfin náà fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àti àwọn onídàájọ́ láṣẹ láti bójú tó ọ̀ràn ìdájọ́. (Diutarónómì 17:8-11) Bí ẹjọ́ ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé àwọn ìpinnu tó ṣeé tẹ̀ lé kalẹ̀, ó sì dájú pé wọ́n tàtaré àwọn kan lára ìwọ̀nyí láti ìran kan sí ìkejì. Àwọn baba tún ń sọ ọ̀nà tí àwọn àlùfáà gbà ń ṣiṣẹ́ wọn nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà fún àwọn ọmọ wọn. Bí ìrírí orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ rẹ̀ ń pọ̀ sí i.
Ṣùgbọ́n, Òfin alákọsílẹ̀ tí a fún Mósè ṣì wà gẹ́gẹ́ bí apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìjọsìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹ́kísódù 24:3, 4 sọ pé: “Mósè dé, ó sì ṣèròyìn gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà àti gbogbo ìpinnu ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn náà, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dáhùn ní ohùn kan, wọ́n sì wí pé: ‘Gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ ni àwa múra tán láti ṣe.’ Nítorí náà, Mósè ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà.” Gbígbà láti tẹ̀ lé àwọn àṣẹ tí a kọ sílẹ̀ ni Ọlọ́run fi gbẹ̀yìn májẹ̀mú rẹ̀ tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá. (Ẹ́kísódù 34:27) Ní tòótọ́, kò síbì kan tí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé òfin kan wà tí a ń pè ní òfin àtẹnudẹ́nu.
‘Ta Ní Fún Ọ Ní Ọlá Àṣẹ Yìí?’
Ó ṣe kedere pé Òfin Mósè fi ọlá àṣẹ àti ìtọ́ni pàtàkì tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ẹ̀sìn lé àwọn àlùfáà, àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì, lọ́wọ́. (Léfítíkù 10:8-11; Diutarónómì 24:8; 2 Kíróníkà 26:16-20; Málákì 2:7) Ṣùgbọ́n, jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwọn àlùfáà kan di aláìṣòótọ́ àti oníwà ìbàjẹ́. (1 Sámúẹ́lì 2:12-17, 22-29; Jeremáyà 5:31; Málákì 2:8, 9) Ní sànmánì tí ilẹ̀ Gíríìsì jọba lé aráyé lórí, ọ̀pọ̀ àlùfáà ló fi ọ̀ràn ẹ̀sìn wọn báni dọ́rẹ̀ẹ́. Ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, àwọn Farisí—ẹgbẹ́ tuntun láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Júù tí ó sọ iṣẹ́ àlùfáà dìdàkidà—bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ kan kalẹ̀, èyí tó lè mú kí ẹnì kan tí a kò bí nídìílé àlùfáà wá ka ara rẹ̀ sí ẹni mímọ́ bí tiwọn. Àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ wọ̀nyí mà fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ́ra o, ṣùgbọ́n àfikún lásán ni wọ́n jẹ́ sí Òfin, a kò sì tẹ́wọ́ gbà wọ́n.—Diutarónómì 4:2; 12:32 (13:1 nínú ìtumọ̀ ti àwọn Júù).
Báyìí ni àwọn Farisí ṣe wá di ọ̀mọ̀wé tuntun nínú Òfin, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì ṣiṣẹ́ tí wọ́n rò pé àwọn àlùfáà fi sílẹ̀ láìṣe. Níwọ̀n bí Òfin Mósè kò ti fún wọn ní ọlá àṣẹ tí wọ́n ń lò yìí, wọ́n gbé àwọn ọ̀nà tuntun kalẹ̀, èyí tí wọ́n lè máa fi túmọ̀ Ìwé Mímọ́ nípa fífọgbọ́n tọ́ka sí àwọn nǹkan tí kò ṣe kedere àti nípa lílo àwọn ọ̀nà mìíràn tó fẹ́ ti èrò wọn lẹ́yìn.a Gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn tí ń bójú tó òfin àtọwọ́dọ́wọ́, tí wọ́n sì ń gbé e lárugẹ, wọ́n gbé ipò ọlá àṣẹ tuntun kalẹ̀ ní Ísírẹ́lì. Ìgbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, àwọn Farisí ti wá di ògúnná gbòǹgbò nínú ẹ̀sìn àwọn Júù.
Bí wọ́n ti ń ṣàkójọ àwọn òfin àtẹnudẹ́nu tó wà nílẹ̀, tí wọ́n sì ń wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jọ pé ó so mọ́ ọn, kí wọ́n bàa lè ráyè túbọ̀ gbé àwọn èyí tó jẹ́ tiwọn kalẹ̀, àwọn Farisí rí i pé ó ṣe pàtàkì fún wọn láti túbọ̀ fi ọlá àṣẹ ti ìgbòkègbodò wọn lẹ́yìn. Wọ́n gbé èrò tuntun nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ wọ̀nyí kalẹ̀. Àwọn rábì wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni pé: “Mósè gba Tórà ní Sínáì ó sì fi lé Jóṣúà lọ́wọ́, Jóṣúà fi lé àwọn àgbààgbà lọ́wọ́, àwọn àgbààgbà fi lé àwọn wòlíì lọ́wọ́. Àwọn wòlíì sì fi lé àwọn ọkùnrin òléwájú nínú àpéjọ pàtàkì lọ́wọ́.”—Avot 1:1, nínú Mishnah.
Nígbà tí àwọn rábì sọ pé “Mósè gba Tórà,” kì í ṣe àwọn òfin tí a kọ sílẹ̀ nìkan ni wọ́n ní lọ́kàn, wọ́n tún ní àwọn òfin àtẹnudẹ́nu pẹ̀lú lọ́kàn. Wọ́n ní Ọlọ́run ló fún Mósè ní àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ wọ̀nyí ní Sínáì—àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tó jẹ́ pé àwọn èèyàn ló hùmọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì wá sọ ọ́ di nǹkan bàbàrà. Wọ́n tún kọ́ni pé, Ọlọ́run kò fi lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti ṣàlàyé àwọn ohun tí kò sọ, ṣùgbọ́n pé ó ti fẹnu ara rẹ̀ ṣàlàyé àwọn ohun tí Òfin alákọsílẹ̀ kò mẹ́nu kàn. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti sọ, láti ìran kan sí èkejì ni Mósè tàtaré òfin àtẹnudẹ́nu wọ̀nyí, kò tàtaré rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn àlùfáà, ó tàtaré rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn aṣáájú mìíràn. Àwọn Farisí fúnra wọn sọ pé àwọn làwọ́n jogún ọlá àṣẹ àtìrandíran “tí yóò wà títí kánrin” yìí.
Ọ̀ràn Dé Bá Òfin—Ojútùú Tuntun
Jésù, ẹni tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ṣiyèméjì nípa ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fún un, ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun tẹ́ńpìlì. (Mátíù 23:37–24:2) Lẹ́yìn tí àwọn ará Róòmù pa tẹ́ńpìlì náà run ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, kò ṣeé ṣe láti kúnjú àwọn ohun tí Òfin Mósè ń béèrè mọ́, àwọn ohun tó wé mọ́ ìrúbọ àti iṣẹ́ àlùfáà. Ọlọ́run sì ti gbé májẹ̀mú tuntun kan kalẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù. (Lúùkù 22:20) A ti mú májẹ̀mú Òfin Mósè wá sí òpin.—Hébérù 8:7-13.
Kàkà tí àwọn Farisí ì bá fi rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé Jésù ni Mèsáyà náà, ojútùú mìíràn ni wọ́n ń wá kiri. Ṣé wọ́n kúkú ti gba ọlá àṣẹ àwọn àlùfáà mọ́ wọn lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀. Ìgbà tó sì kúkú jẹ́ pé tẹ́ńpìlì ti pa run, àrà mìíràn ń bẹ tí wọ́n lè dá. Ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì tó wà ní Yavneh di ojúkò fún Sànhẹ́dírìn tí a ti tún tò—ilé ẹjọ́ gíga ti àwọn Júù. Lábẹ́ ìdarí Yohanan ben Zakkai àti Gamaliel Kejì ní Yavneh, a tún ẹ̀sìn àwọn Júù tò pátápátá. Ààtò nínú sínágọ́gù, tí àwọn rábì máa ń darí, rọ́pò ìjọsìn ní tẹ́ńpìlì, tí àwọn àlùfáà máa ń darí. Wọ́n fi àdúrà rọ́pò ìrúbọ, ní pàtàkì, àdúrà Ọjọ́ Ètùtù. Àwọn Farisí ronú pé òfin àtẹnudẹ́nu tí a fún Mósè ní Sínáì ti rí èyí tẹ́lẹ̀, ó sì ti ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀.
Ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì ń lókìkí sí i. Lájorí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ wọn ni ìjíròrò jíjinlẹ̀, àkọ́sórí, àti ìlò òfin àtẹnudẹ́nu. Tẹ́lẹ̀ rí, wọ́n gbé ìpìlẹ̀ òfin àtẹnudẹ́nu ka ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́—Midrash. Wàyí o, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn àkójọ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí ń pọ̀ sí i kọ́ni, wọ́n sì ṣètò wọn sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Wọ́n gé òfin àtẹnudẹ́nu kọ̀ọ̀kan kúrú sí gbólóhùn ṣókí, tí ó rọrùn láti há sórí, tí wọ́n sábà máa ń fi ṣorin kọ.
Èé Ṣe Tí A Fi Ń Kọ Òfin Àtẹnudẹ́nu Sílẹ̀?
Ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì tó pọ̀ rẹpẹtẹ àti òfin àwọn rábì tó ń pọ̀ sí i dá ìṣòro tuntun sílẹ̀. Rábì tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, Adin Steinsaltz, ṣàlàyé pé: “Olùkọ́ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà ìgbàkọ́ni tirẹ̀, ó sì máa ń gbé òfin àtẹnudẹ́nu tirẹ̀ kalẹ̀ lọ́nà tirẹ̀. . . . Nígbà tó yá, mímọ kìkì ẹ̀kọ́ olùkọ́ ẹni nìkan kò tó, ó di dandan fún akẹ́kọ̀ọ́ láti mọ iṣẹ́ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mìíràn . . . Nípa báyìí, a fipá mú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti há ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀kọ́ sórí nítorí ‘ìmọ̀ tó pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ.’” Níbi táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ń rọ́ omilẹgbẹ ìsọfúnni yìí sọ́pọlọ, díẹ̀ ló kù kí ìsọfúnni tí kò lórí tí kò nídìí yìí dà wọ́n lórí rú.
Ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, ọ̀tẹ̀ Júù lòdì sí Róòmù, tí Bar Kokhba ṣáájú rẹ̀, yọrí sí ṣíṣe inúnibíni gbígbóná janjan sí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí wọ́n jẹ́ rábì. Akiba—rábì tó gbajúmọ̀ jù lọ, tí òun pẹ̀lú wà lẹ́yìn Bar Kokhba—àti ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mìíràn ni a pa. Ẹ̀rù wá ń ba àwọn rábì pé inúnibíni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ yìí lè sọ òfin àtẹnudẹ́nu di ohun ìgbàgbé. Ìgbàgbọ́ wọn tẹ́lẹ̀ ni pé ọ̀nà dídára jù lọ láti gbà tàtaré òfin àtẹnudẹ́nu ni kí ọ̀gá fẹnu sọ ọ́ fún ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n ipò tó wá ń yí padà yìí mú kí ó pọndandan fún wọn láti túbọ̀ sapá láti rí i pé àwọn gbé ètò kan kalẹ̀ tí kò ní jẹ́ kí ẹ̀kọ́ àwọn amòye run, kí ẹ̀kọ́ náà má bàa di ohun ìgbàgbé títí láé.
Nígbà tí àlàáfíà díẹ̀ fi wà ní Róòmù, Judah Ha-Nasi, òléwájú rábì ti ọ̀rúndún kejì àti ìbẹ̀rẹ̀ ìkẹta, kó ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ jọ, ó ṣàyẹ̀wò, ó sì ṣètò ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ òfin àtẹnudẹ́nu sínú ìdìpọ̀ kan ṣoṣo tí a pín sí Abala mẹ́fà, ọ̀kọ̀ọ̀kan abala náà sì tún pín sí àpilẹ̀kọ kéékèèké—gbogbo rẹ̀ jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́ta. Ìwé yìí ni a wá mọ̀ sí Mishnah. Ephraim Urbach, ògbógi nínú òfin àtẹnudẹ́nu, ṣàlàyé pé: “Mishnah di ìwé tí a fọwọ́ sí . . . tí a sì fún ní ọlá àṣẹ ju ìwé èyíkéyìí mìíràn lọ àyàfi Tórà fúnra rẹ̀ nìkan.” Wọ́n kúkú ti kọ Mèsáyà sílẹ̀, tẹ́ńpìlì sì ti di òkìtì àlàpà, ṣùgbọ́n nítorí pé wọ́n wá kọ òfin àtẹnudẹ́nu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Mishnah ló mú kí ẹ̀sìn àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sànmánì tuntun.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Irú ọ̀nà ìgbàtúmọ̀ Ìwé Mímọ́ yìí ni a ń pè ní midrash.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù fi kọ ọlá àṣẹ Jésù?