Bí Ìgbà Èwe Rẹ Ṣe Lè Dùn Bí Oyin
WỌ́N ní kí àwọn tó ń gbé orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù yan ọ̀kan nínú àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí: ẹwà, ọrọ̀, tàbí ìgbà èwe. Àwọn tó pọ̀ jù lọ ló mú ìgbà èwe. Dájúdájú, tọmọdé tàgbà ló ka ìgbà ọ̀dọ́langba àti ìgbà téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ogún ọdún sí àkókò kan tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú ìgbésí ayé ẹni. Gbogbo èèyàn ló sì ń fẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ ti orí ìgbà ọ̀dọ́mọdé tó mìrìngìndìn bọ́ sórí ìgbà àgbàlagbà tó dùn bí oyin. Àmọ́, lọ́nà wo?
Ǹjẹ́ Bíbélì lè ṣèrànwọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà méjì tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi lè ṣèrànwọ́ àrà ọ̀tọ̀ fáwọn ọ̀dọ́ yẹ̀ wò, ó ṣeé ṣe kó tiẹ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ ju àwọn ẹlòmíràn lọ.
Níní Àjọṣe Tó Dán Mọ́rán Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn
Jugend 2000 jẹ́ ìròyìn tí wọ́n ṣe lórí ìwádìí gbígbòòrò nípa èrò, ọ̀pá ìdiwọ̀n àti ìhùwàsí àwọn ọ̀dọ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún nílẹ̀ Jámánì. Ìwádìí náà fi hàn pé nígbà táwọn ọ̀dọ́ bá ń ṣe fàájì—bíi kí wọ́n máa gbọ́ orin, kí wọ́n máa kópa nínú eré ìdárayá, tàbí kí wọ́n wulẹ̀ rìn jáde—wọ́n sábà máa ń wà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ó dà bí ẹni pé àwọn ọ̀dọ́ ló sábà máa ń fẹ́ wà lọ́dọ̀ àwọn ojúgbà wọn ju ti àwọn ọlọ́jọ́ orí èyíkéyìí mìíràn lọ. Láìsí àní-àní, ó fi hàn pé lára ohun tó ń mú kí ìgbà èwe dùn bí oyin ni kéèyàn ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
Àmọ́, kì í sábà rọrùn láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ká sọ tòótọ́, àjọṣepọ̀ ẹ̀dá jẹ́ àgbègbè kan tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin gbà pé àwọn ti sábà máa ń níṣòro. Bíbélì lè jẹ́ ojúlówó ìrànlọ́wọ́ níhìn-ín. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn ọ̀dọ́ ní ojúlówó ìtọ́sọ́nà nípa bí wọ́n ṣe lè ní àjọṣe tó gún régé. Kí ni Bíbélì sọ?
Ọ̀kan lára àwọn ìlànà tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àjọṣepọ̀ ẹ̀dá la pè ní Òfin Oníwúrà, tó sọ pé: “Máa ṣe sí àwọn ẹlòmíràn bí o ṣe fẹ́ kí wọ́n ṣe sí ọ.” Bíbá àwọn ẹlòmíràn lò pẹ̀lú ọ̀wọ̀, iyì àti inú rere ń fún wọn níṣìírí láti bá ìwọ náà lò lọ́nà kan náà. Jíjẹ́ onínú-unre lè fòpin sí èdèkòyédè àti gbúngbùngbún. Bí gbogbo èèyàn bá mọ̀ ọ́ sẹ́ni tó ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò, ó ṣeé ṣe kóo di ẹni tí wọ́n kà sí, tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà. Ǹjẹ́ inú rẹ kò ní dùn pé àwọn ẹlòmíràn tẹ́wọ́ gbà ọ́?—Mátíù 7:12, Revised English Bible.
Bíbélì gbà ọ́ nímọ̀ràn pé kóo “nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” O gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ ní ti títọ́jú ara rẹ àti bíbọlá fún ara rẹ níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí ó má pọ̀ jù, kí ó má sì kéré jù. Kí nìdí tíyẹn fi lè ṣèrànwọ́? Tóò, bí o kò bá níyì lọ́wọ́ ara rẹ, o lè máa ṣe lámèyítọ́ àwọn ẹlòmíràn, èyí sì lè ba àjọṣe tó dán mọ́rán jẹ́. Àmọ́, gbígbé ara ẹni níyì níwọ̀ntúnwọ̀nsì yóò jẹ́ kí a ní àwọn ọ̀rẹ́ táa lè gbára lé.—Mátíù 22:39.
Gbàrà tí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ bá ti bẹ̀rẹ̀, ó di dandan kí àwọn méjèèjì tí ọ̀ràn náà kàn sapá láti fún un lókun. Lílo àkókò láti dọ́rẹ̀ẹ́ gbọ́dọ̀ mú inú rẹ dùn, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” Ọ̀nà kan láti fúnni ni pé ká dárí jini, èyí tó kan gbígbójúfo àwọn àṣìṣe kéékèèké dá, ká má sì máa retí ìjẹ́pípé látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” Ní ti gidi, “níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” Bí ọ̀rẹ́ kan bá wá tọ́ka sí ọ̀kan lára ìkùdíẹ̀ káàtó ìwọ alára ńkọ́? Kí lo máa ṣe? Gbé ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ látinú Bíbélì yìí yẹ̀ wò: “Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya,” nítorí pé “àwọn ọgbẹ́ tí olùfẹ́ dá síni lára jẹ́ ti ìṣòtítọ́.” Ǹjẹ́ kì í ṣe òótọ́ ni pé àwọn ọ̀rẹ́ ń nípa lórí èrò, ọ̀rọ̀ ẹnu, àti ìhùwàsí rẹ? Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi kìlọ̀ pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, “ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”—Ìṣe 20:35; Fílípì 4:5; Róòmù 12:17, 18; Oníwàásù 7:9; Òwe 13:20; 27:6; 1 Kọ́ríńtì 15:33.
Marco gbẹnu sọ fún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́kùnrin àtàwọn ọ̀dọ́bìnrin nígbà tó sọ pé: “Àwọn ìlànà Bíbélì jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá fún níní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Mo mọ àwọn èèyàn kan tí wọn ò mọ̀ ju ti ara wọn nìkan àtàwọn nǹkan tí wọ́n lè rí jẹ lérè nínú ìgbésí ayé. Bíbélì kọ́ wa pé ká má ṣe ronú púpọ̀ jù nípa ara wa, àmọ́ kí a máa ro ti àwọn ẹlòmíràn. Bó sì ṣe rí lójú tèmi, ọ̀nà tó dára jù lọ láti ní àjọse tó dán mọ́rán láàárín ẹ̀dá ènìyàn nìyẹn.”
Kì í ṣe ìgbà ọ̀dọ́ nìkan ni ohun tí àwọn ọ̀dọ́ bíi Marco kọ́ nínú Bíbélì ṣèrànwọ́ fún wọn, ó tún ń ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún tó ń bọ̀ níwájú. Tó bá sì jẹ́ nípa ti ọjọ́ iwájú ni, a rí ọ̀nà mìíràn tí Bíbélì lè gbà ṣèrànwọ́ àrà ọ̀tọ̀ fáwọn ọ̀dọ́.
Ṣíṣàníyàn Nípa Ọjọ́ Ọ̀la
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa ń wá fìn-ín ìdí kókò. Bóyá ju ti ẹnikẹ́ni mìíràn tí ọjọ́ orí rẹ̀ yàtọ̀ sí tiwọn, àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ àti ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Bíbélì sì ṣàlàyé àwọn ìdí tí ipò ayé fi rí bó ṣe rí, ó tún sọ ohun táa ní láti máa retí lọ́jọ́ iwájú fún wa, ju bí ìwé èyíkéyìí mìíràn ṣe sọ ọ́ lọ. Ohun tí àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ mọ̀ nìyí. Èé ṣe tó fi dá wa lójú pé ohun tí wọ́n fẹ́ mọ̀ nìyí?
Tóò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé àwọn ọ̀dọ́ máa ń gbé ìgbésí ayé màá-jayé-òní a ò mẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ìwádìí kan ti fi hàn pé ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ délẹ̀délẹ̀. Wọ́n fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ máa ń kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká wọn, wọ́n sì ń dé orí ìparí èrò tiwọn nípa bí ìgbésí ayé ṣe lè rí lọ́jọ́ iwájú. Ohun tó fi èyí hàn ni pé mẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn ọ̀dọ́kùnrin àtàwọn ọ̀dọ́bìnrin ló máa ń ronú nípa ọjọ́ ọ̀la “lọ́pọ̀ ìgbà” tàbí ní “gbogbo ìgbà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń ní ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀dọ́ ló ń ṣàníyàn gan-an nípa ọjọ́ iwájú.
Kí ló fa irú àníyàn bẹ́ẹ̀? Ọ̀pọ̀ àwọn tó máa di àgbà lọ́la wọ̀nyí ló ń lọ́wọ́ sí ìwà ọ̀daràn, ìwà ipá, àti ìjoògùnyó. Àwọn ọ̀dọ́ ń ṣàníyàn nípa rírí iṣẹ́ tó máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ nínú àwùjọ tíṣẹ́ ti ṣòro rí bí nǹkan míì. Pákáǹleke máa ń bá wọn nítorí àtigba máàkì tó dára nílé ìwé, tàbí kí wọ́n lè kẹ́sẹ járí níbi iṣẹ́. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan sọ pé: “Ayé bóo ba o pá, bóo ba o bù ú lẹ́sẹ̀ là ń gbé. Olúkúlùkù ló ń gbìyànjú àtiṣe ohun tó wù ú. O sáà gbọ́dọ̀ mọ nǹkan kan ṣe, tó máa mú káwọn èèyàn gbédìí fún ẹ, ìyẹn sì máa ń bà mí nínú jẹ́.” Ọ̀dọ́ mìíràn tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún sọ pé: “Àwọn tí ọwọ́ wọ́n ràn án ló máa ń kẹ́sẹ járí, àwọn nìkan sì ni ayé jíjẹ wà fún. Àwọn tí nǹkan kò ṣẹnu-unre fún, àwọn tí wọn kò lè kẹ́sẹ járí nítorí ìdí kan tàbí òmíràn wulẹ̀ máa ń di èrò ẹ̀yìn ṣáá ni.” Èé ṣe tí ìgbésí ayé fi kún fún ẹ̀mí ìbánidíje bẹ́ẹ̀? Ṣé bí ìgbésí ayé yóò ṣe máa wà títí lọ nìyí?
Àlàyé Tó Bọ́gbọ́n Mu
Nígbà tínú bá ń bí àwọn ọ̀dọ́ sí bí nǹkan ṣe ń lọ láwùjọ tàbí tí wọ́n ń ṣàníyàn nípa rẹ̀, wọ́n ń fara mọ́ ohun tí Bíbélì wí nìyẹn, yálà wọn mọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí wọn kò mọ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé “ayé bóo ba o pa, bóo ba o bù ú lẹ́sẹ̀” òde òní jẹ́ àmì àwọn àkókò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àkókò tiwa yìí sínú lẹ́tà kan tó kọ sí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Tímótì pé: “Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.” Kí nìdí tó fi le koko, tó sì nira láti bá lò? Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ síwájú si i nínú ìwé rẹ̀, àwọn ènìyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, . . . aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, . . . òǹrorò.” Ǹjẹ́ àpèjúwe yẹn kò bá ìwà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń hù lóde oní mu wẹ́kú?—2 Tímótì 3:1-3.
Bíbélì sọ pé àwọn àkókò líle koko wọ̀nyí yóò dé “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” kó tó di pé ìyípadà ńlá dé bá àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn. Àwọn ìyípadà wọ̀nyí yóò kan gbogbo èèyàn, lọ́mọdé lágbà. Irú ìyípadà wo nìyẹn? Láìpẹ́, ìjọba ọ̀run ni yóò bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn, àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba náà yóò sì gbádùn “ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà” níbi gbogbo. “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” Ṣíṣàníyàn àti bíbẹ̀rù yóò di ohun àtijọ́.—Sáàmù 37:11, 29.
Bíbélì nìkan ló fúnni ni ìjìnlẹ̀ òye nípa ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Nígbà tí ọ̀dọ́ kan bá ti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láwọn ọdún bíi mélòó kan síwájú, ó lè múra sílẹ̀ de àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, kó fi ọkàn ara rẹ̀ balẹ̀, kó sì túbọ̀ ṣàkóso ìgbésí ayé rẹ̀. Ìmọ̀lára yìí máa ń dín másùnmáwo àti àníyàn kù. Ní ọ̀nà yìí, àìní àrà ọ̀tọ̀ àwọn ọ̀dọ́—láti lóye àwùjọ àti láti mọ ohun tí ọjọ́ iwájú yóò mú wá—la ṣàlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú Bíbélì.
Ìgbà Ọ̀dọ́ Tó Dùn Bí Oyin
Kí la fi ń mọ ìgbà ọ̀dọ́ tó dùn bí oyin? Ṣé kíkàwé dójú àmì ni, tàbí kíkó nǹkan ìní jọ pelemọ, tàbí níní ọ̀rẹ́ tó pọ̀ rẹpẹtẹ? Ọ̀pọ̀ lè rò bẹ́ẹ̀? Àwọn ọdún ọ̀dọ́langba àti ìgbà téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lógún ọdún gbọ́dọ̀ múra ẹni sílẹ̀ de ọjọ́ ogbó. Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, kíkẹ́sẹ járí nígbà ọ̀dọ́ lè jẹ́ àmì tó ń fi bí nǹkan ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú hàn.
Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe rí i, Bíbélì lè ran ọ̀dọ́ kan lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ìgbà èwe rẹ̀ dùn bí oyin. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti rí i pé bó ṣe rí gan-an nínú ìgbésí ayé wọn nìyẹn. Wọ́n ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò. (Wo “Ìmọ̀ràn Tó Gbéṣẹ́ Látọ̀dọ̀ Ọ̀dọ́ Kan Tó Jẹ́ Ìránṣẹ́ Jèhófà,” ojú ìwé 6.) Láìsí àní-àní, Bíbélì jẹ́ ìwé kan tó dìídì wà fún àwọn ọ̀dọ́ lónìí, nítorí pé ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, 17.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Ọ̀kan lára ohun tó ń mú kí ìgbà ọ̀dọ́ dùn bí oyin ni kéèyàn ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Bóyá ju ti ẹnikẹ́ni mìíràn tí ọjọ́ orí rẹ̀ yàtọ̀ sí tiwọn, àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ àti ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6, 7]
Ìmọ̀ràn Tó Gbéṣẹ́ Látọ̀dọ̀ Ọ̀dọ́ Kan Tó Jẹ́ Ìránṣẹ́ Jèhófà
Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni Alexander. Inú ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, ó sì wù ú láti fi tọkàntọkàn ṣe ẹ̀sìn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Alexander ṣàlàyé pé:
“Ó lè ya ọ́ lẹ́nu pé mo dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ akéde tí kò ṣe batisí fún ohun tó lé ní ọdún méje. Lákòókò yẹn, ìjọsìn mi kì í ṣe èyí tó tọkàn wá rárá, ojú ayé lásán ni mo ń ṣe. Mó ṣáà rí i pé mi ò lẹ́mìí àtiyẹ ara mi wo láìṣàbòsí.”
Lẹ́yìn náà, ìwà Alexander yí padà. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní:
“Àwọn òbí mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi nínú ìjọ ń rọ̀ mí ṣáá pé kí n máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kí n lè mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Níkẹyìn, mo pinnu pé màá gbìyànjú. Nípa bẹ́ẹ̀, mo dín àkókò tí mo fi ń wo tẹlifíṣọ̀n kù, mo sì sọ Bíbélì kíkà di apá kan ohun tí mò ń ṣe lárààárọ̀. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo bẹ̀rẹ̀ sí lóye ohun náà gan-an tó wà nínú Bíbélì. Mo wá rí i bó ṣe lè ràn mí lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Àti pé—ju gbogbo rẹ̀ lọ—mo wá lóye pé Jèhófà fẹ́ kí n mọ òun. Gbàrà tí mo ti fi ìyẹn sọ́kàn ni àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i, tí mo sì wá láwọn ọ̀rẹ́ púpọ̀ sí i nínú ìjọ. Ẹ ò rí i bí Bíbélì ṣe yí ìgbésí ayé mi padà! Mo dá a lábàá pé kí gbogbo ọ̀dọ́ tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa ka Bíbélì lójoojúmọ́.”
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọ̀dọ́ káàkiri ayé ló ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣé o wà lára wọn? Ṣé wàá fẹ́ jàǹfààní nínú kíka Bíbélì déédéé? O ò ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Alexander? Dín àkókò tóo ń lò nídìí àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì kù, kí o sì sọ Bíbélì kíkà di ara ìgbòkègbodò rẹ ojoojúmọ́. Ó dájú pé yóò ṣe ọ́ láǹfààní