ORÍ 109
Ó Dẹ́bi Fáwọn Aṣáájú Ẹ̀sìn Tó ń ta Kò Ó
MÁTÍÙ 22:41–23:24 MÁÀKÙ 12:35-40 LÚÙKÙ 20:41-47
ỌMỌ TA NI KRISTI?
JÉSÙ TÚ ÀṢÍRÍ ÀWỌN ALÁGÀBÀGEBÈ TÓ Ń TA KÒ Ó
Oríṣiríṣi ọgbọ́n làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti dá kí wọ́n lè mú Jésù, kí wọ́n sì fà á lé àwọn ará Róòmù lọ́wọ́, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ ń já sí. (Lúùkù 20:20) Inú tẹ́ńpìlì ni Jésù ṣì wà ní Nísàn 11. Àwọn alátakò yẹn ti ń béèrè oríṣiríṣi ìbéèrè, Jésù náà wá bi wọ́n ní ìbéèrè kí wọ́n lè mọ ẹni tó jẹ́ gan-an. Ó ní: “Kí lèrò yín nípa Kristi? Ọmọ ta ni?” (Mátíù 22:42) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ìlà ìdílé Dáfídì ni Kristi tàbí Mèsáyà á ti wá. Ohun táwọn náà sọ fún Jésù nìyẹn.—Mátíù 9:27; 12:23; Jòhánù 7:42.
Jésù béèrè pé: “Kí wá nìdí tí Dáfídì fi pè é ní Olúwa nípasẹ̀ ìmísí, tó sọ pé, ‘Jèhófà sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi, títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ”’? Tí Dáfídì bá pè é ní Olúwa, báwo ló ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”—Mátíù 22:43-45.
Àwọn Farisí yẹn ò rí nǹkan sọ, wọ́n gbà pé ẹnì kan máa wá láti ìran Dáfídì tó máa gbà wọ́n sílẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso Róòmù. Àmọ́ bí Jésù ṣe fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ohun tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 110:1, 2 jẹ́ kó hàn pé Mèsáyà kì í ṣe èèyàn lásán kan, ìjọba ẹ̀ ò sì ní dà bíi tàwọn èèyàn. Olúwa ni Mèsáyà jẹ́ fún Dáfídì, lẹ́yìn tó bá sì ti jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó máa lo agbára tó ní láti ṣàkóso. Ṣe ni ìdáhùn Jésù yìí tún pa àwọn alátakò yẹn lẹ́nu mọ́.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn àtàwọn èrò tó wà níbẹ̀ náà ń gbọ́ ohun tí Jésù ń sọ. Jésù wá yíjú sí wọn kó lè kìlọ̀ fún wọn nípa ìwà àwọn akọ̀wé òfin yẹn àtàwọn Farisí. Àwọn ọkùnrin yẹn ti “fi ara wọn sí orí ìjókòó Mósè” kí wọ́n lè kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Ọlọ́run. Jésù sọ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ pé: “Gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ fún yín ni kí ẹ ṣe, kí ẹ sì máa pa mọ́, àmọ́ ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe, torí tí wọ́n bá sọ̀rọ̀, wọn kì í ṣe ohun tí wọ́n sọ.”—Mátíù 23:2, 3.
Jésù sọ díẹ̀ lára ohun tí wọ́n ń ṣe tó fi hàn pé alábòsí ni wọ́n, ó ní: “Wọ́n fẹ àwọn akóló tí wọ́n ń kó ìwé mímọ́ sí, èyí tí wọ́n ń dè mọ́ra láti dáàbò bo ara wọn.” Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló ní akóló tí wọ́n máa ń kó ìwé mímọ́ sí, wọ́n sì máa ń dè é mọ́ ìwájú orí tàbí apá wọn. Àmọ́, àwọn Farisí jẹ́ kí akóló tiwọn tóbi dáadáa, kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn nítara. Wọ́n tún “mú kí wajawaja etí aṣọ wọn gùn.” Lóòótọ́, Òfin Ọlọ́run ló ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe wajawaja sí etí aṣọ wọn, àmọ́ ṣe làwọn Farisí yẹn mú kí wajawaja tó wà létí aṣọ wọn gùn dáadáa. (Nọ́ńbà 15:38-40) “Kí àwọn èèyàn lè rí wọn” ni wọ́n ṣe ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn.—Mátíù 23:5.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í wá ipò ọlá fún ara wọn, ìdí nìyẹn tó fi gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Kí wọ́n má pè yín ní Rábì, torí Olùkọ́ kan lẹ ní, arákùnrin sì ni gbogbo yín. Bákan náà, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ní ayé, torí Baba kan lẹ ní, Ẹni tó wà ní ọ̀run. Kí wọ́n má sì pè yín ní aṣáájú, torí Aṣáájú kan lẹ ní, Kristi.” Ojú wo ló wá yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn máa fi wo ara wọn, irú ìwà wo ló sì yẹ kí wọ́n máa hù? Jésù sọ fún wọn pé: “Kí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín yín jẹ́ ìránṣẹ́ yín. Ẹnikẹ́ni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.”—Mátíù 23:8-12.
Lẹ́yìn náà, Jésù kéde ègbé lé àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí tí wọ́n jẹ́ alágàbàgebè yẹn, ó ní: “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè! torí pé ẹ ti Ìjọba ọ̀run pa mọ́ àwọn èèyàn; ẹ̀yin fúnra yín ò wọlé, ẹ ò sì jẹ́ kí àwọn tó fẹ́ wọlé ráyè wọlé.”—Mátíù 23:13.
Jésù dẹ́bi fáwọn Farisí yẹn torí pé dípò kí wọ́n mọyì ohun tí Jèhófà kà sí pàtàkì, ohun tí ò pọn dandan ni wọ́n kà sí pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fi tẹ́ńpìlì búra, kò ṣe nǹkan kan; àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà tẹ́ńpìlì búra, dandan ni kó ṣe ohun tó búra.” Èyí fi hàn pé wọn ò ronú lọ́nà tó tọ́ mọ́, torí pé àwọn wúrà tó wà nínú tẹ́ńpìlì ni wọ́n kà sí pàtàkì jù, dípò kí wọ́n máa rí tẹ́ńpìlì yẹn bí ilé ìjọsìn Jèhófà àti pé ibẹ̀ làwọn èèyàn ti lè wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Wọn ò sì “ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù nínú Òfin sí, ìyẹn ìdájọ́ òdodo, àánú àti òtítọ́.”—Mátíù 23:16, 23; Lúùkù 11:42.
Jésù fi àwọn Farisí yẹn wé “afọ́jú tó ń fini mọ̀nà, tó ń sẹ́ kòkòrò tín-tìn-tín, àmọ́ tó ń gbé ràkúnmí mì káló!” (Mátíù 23:24) Wọ́n ń sẹ́ kòkòrò tín-tìn-tín kúrò nínú wáìnì wọn torí pé lábẹ́ Òfin Mósè ohun àìmọ́ ni kòkòrò yìí. Àmọ́ bí wọn ò ṣe ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù nínú Òfin sí dà bí ìgbà tí wọ́n bá gbé ràkúnmí mì káló. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ohun àìmọ́ náà ni ràkúnmí lábẹ́ Òfin Mósè, ó sì tóbi ju kòkòrò tín-tìn-tín tí wọ́n ń sẹ́ kúrò lọ.—Léfítíkù 11:4, 21-24.