“Bí Ọlọ́run Bá Wà Fún Wa, Ta Ni Yóò Wà Lòdì Sí Wa?”
“Kí wá ni àwa yóò sọ sí nǹkan wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà fún wa, ta ni yóò wà lòdì sí wa?”—RÓÒMÙ 8:31.
1. Àwọn wo ló tẹ̀ lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, kí ló sì sún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀?
NÍGBÀ tó kù díẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba òmìnira lẹ́yìn tí wọ́n ti lo igba ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [215] ọdún ní ilẹ̀ Íjíbítì, tí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àkókò yẹn sì jẹ́ lábẹ́ ìsìnrú, “àwùjọ onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata . . . tún gòkè lọ pẹ̀lú wọn.” (Ẹ́kísódù 12:38) Àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyí ti rí ọṣẹ́ tí àjàkálẹ̀ àrùn mẹ́wàá ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀ náà ṣe ní ilẹ̀ Íjíbítì, tó sì sọ àwọn ọlọ́run èké wọn di ẹni ẹ̀sín. Lákòókò kan náà, wọ́n ti rí agbára tí Jèhófà ní láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀—àgàgà látorí àjàkálẹ̀ àrùn kẹrin síwájú. (Ẹ́kísódù 8:23, 24) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ gbogbo ète Jèhófà, síbẹ̀ ohun kan dá wọn lójú: Àwọn ọlọ́run Íjíbítì ti kùnà láti dáàbò bo àwọn ará Íjíbítì, nígbà tí Jèhófà sì fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí alágbára fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
2. Kí nìdí tí Ráhábù fi ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wá ṣe amí lẹ́yìn, èé sì ti ṣe tí ìgbọ́kànlé rẹ̀ nínú Ọlọ́run wọn kì í fi í ṣe àṣìṣe?
2 Ogójì ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tó kù díẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Ìlérí, Jóṣúà, tó rọ́pò Mósè, rán àwọn ọkùnrin méjì jáde láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà. Ibẹ̀ ni wọ́n ti rí Ráhábù, tó ń gbé Jẹ́ríkò. Nítorí ohun tó ti gbọ́ nípa agbára ńlá tí Jèhófà fi dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láàárín ogójì ọdún tí wọ́n ti kúrò ní Íjíbítì, ó mọ̀ pé bí òun bá fẹ́ rí ìbùkún Ọlọ́run, òun gbọ́dọ̀ ti àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́yìn. Nítorí ìpinnu ọlọgbọ́n tó ṣe yìí, òun àti ìdílé rẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ ìparun nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ṣẹ́gun ìlú ńlá náà lẹ́yìn náà. Ọ̀nà ìyanu táa gbà dáàbò bò wọ́n fi hàn kedere pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ìgbọ́kànlé tí Ráhábù ní nínú Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í ṣe àṣìṣe.—Jóṣúà 2:1, 9-13; 6:15-17, 25.
3. (a) Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jésù ṣe nítòsí ìlú ńlá Jẹ́ríkò táa tún kọ́, kí sì ni àwọn àlùfáà Júù ṣe nípa rẹ̀? (b) Kí ni àwọn Júù kan, àti lẹ́yìn náà ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Júù, wá mọ̀?
3 Ọ̀rúndún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn náà, Jésù Kristi wo afọ́jú kan tó ń ṣagbe sàn nítòsí ìlú ńlá Jẹ́ríkò tí wọ́n tún kọ́ náà. (Máàkù 10:46-52; Lúùkù 18:35-43) Ọkùnrin náà bẹ Jésù pé kó ṣàánú òun, tó fi hàn pé ó mọ̀ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn Jésù. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ìyẹn, àwọn aṣáájú ìsìn Júù àtàwọn ọmọlẹ́yìn wọn kọ̀ láti wo àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tó fi hàn pé iṣẹ́ Ọlọ́run lòun ń ṣe. Dípò ìyẹn, ẹ̀sùn ni wọ́n ń wá sí i lẹ́sẹ̀. (Máàkù 2:15, 16; 3:1-6; Lúùkù 7:31-35) Kódà nígbà tí wọ́n rí i pé Jésù jíǹde lẹ́yìn tí wọ́n pa á, wọn ò fẹ́ gbà pé iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run lèyí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n mú ipò iwájú nínú ṣíṣe inúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ ‘pípolongo ìhìn rere Jésù Olúwa’ tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́ àwọn Júù kan, àti lẹ́yìn náà ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Júù, fiyè sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, wọ́n sì ní èrò tó tọ̀nà nípa wọn. Lójú wọn, ó hàn gbangba pé Ọlọ́run ti kọ àwọn aṣáájú ìsìn Júù olódodo àṣelékè sílẹ̀, ó sì ń ti àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi lẹ́yìn.—Ìṣe 11:19-21.
Àwọn Wo Ni Ọlọ́run Ń Tì Lẹ́yìn Lóde Òní?
4, 5. (a) Báwo làwọn kan ṣe máa ń ronú nípa irú ẹ̀sìn tí wọ́n máa yàn? (b) Nígbà táa bá fẹ́ mọ ìsìn tòótọ́, kí ni ìbéèrè pàtàkì tó yẹ láti gbé yẹ̀ wò?
4 Nígbà tí wọ́n béèrè ọ̀rọ̀ nípa ìsìn tòótọ́ nínú ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò kan tí wọ́n ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan sọ pé: “Màá gbà pé ẹ̀sìn kan jẹ́ òótọ́ tó bá lè sọ ẹnì kan di ẹni tó túbọ̀ sunwọ̀n sí i nígbà tí onítọ̀hún bá ń gbé níbàámu pẹ̀lú rẹ̀.” Lóòótọ́, ìsìn tòótọ́ máa ń mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Àmọ́, ṣé kìkì òtítọ́ náà pé ẹ̀sìn kan ń mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ sunwọ̀n sí i fi hàn pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn ẹ̀sìn náà? Ṣé ìyẹn nìkan la fi ń pinnu bóyá ẹ̀sìn kan jẹ́ òótọ́?
5 Olúkúlùkù ló mọyì àǹfààní náà pé ó ṣeé ṣe láti yan ohun tó wuni, títí kan yíyan ìsìn tó wuni. Ṣùgbọ́n pé èèyàn ní òmìnira láti yan ohun to wù ú kò túmọ̀ sí pé èèyàn á yan èyí tó tọ̀nà. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan ń yan ẹ̀sìn nítorí bí àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn yẹn ṣe pọ̀ tó, bí ẹ̀sìn náà ṣe lówó tó, bó ṣe máa ń ṣe àwọn àríyá aláyẹyẹ gígọntíọ tó tàbí nítorí pé ó jẹ́ ẹ̀sìn tí ìdílé wọn ń ṣe. Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí tó ṣeé pinnu bóyá ẹ̀sìn kan jẹ́ òótọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìbéèrè pàtàkì náà lórí ọ̀ràn yìí ni pé: Ìsìn wo ló ń rọ àwọn èèyàn rẹ̀ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, tó sì fi ẹ̀rí tó lágbára hàn pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn òun débi pé àwọn onísìn náà lè fi ìdánilójú sọ pé “Ọlọ́run wà fún wa”?
6. Ọ̀rọ̀ Jésù wo ló tan ìmọ́lẹ̀ sórí ọ̀ràn nípa ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké?
6 Jésù fi ìlànà táa fi lè mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké lélẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tí ń wá sọ́dọ̀ yín nínú aṣọ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n jẹ́ ọ̀yánnú ìkookò. Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀.” (Mátíù 7:15, 16; Málákì 3:18) Ẹ jẹ́ ká tún díẹ̀ yẹ̀ wò lára “àwọn èso” náà, tàbí àwọn àmì táa fi lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀, ká lè fi àìṣẹ̀tàn pinnu ẹni tí Ọlọ́run wà lẹ́yìn rẹ̀ lónìí.
Àwọn Àmì Táa Fi Ń Dá Àwọn Tí Ọlọ́run Ń Tì Lẹ́yìn Mọ̀
7. Kí ló túmọ̀ sí láti fi kìkì ohun táa gbé ka Bíbélì kọ́ni?
7 Wọ́n gbé ẹ̀kọ́ wọn ka Bíbélì. Jésù sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi. Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìfẹ́-ọkàn láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀, yóò mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ náà bóyá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni tàbí mo ń sọ̀rọ̀ láti inú àpilẹ̀ṣe ti ara mi.” Ó tún sọ pé: “Ẹni tí ó bá ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń fetí sí àwọn àsọjáde Ọlọ́run.” (Jòhánù 7:16, 17; 8:47) Lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, kí Ọlọ́run tó lè ti ẹnì kan lẹ́yìn, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ fi kìkì ohun tí Ọlọ́run ṣí payá nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kọ́ni, kó sì yẹra fún ẹ̀kọ́ táa gbé ka ọgbọ́n ènìyàn tàbí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́.—Aísáyà 29:13; Mátíù 15:3-9; Kólósè 2:8.
8. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti lo orúkọ Ọlọ́run nínú ìjọsìn?
8 Wọ́n ń lo Jèhófà, tí í ṣe orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì ń polongo rẹ̀. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Dájúdájú, ẹ ó sọ ní ọjọ́ yẹn pé: ‘Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà! Ẹ ké pe orúkọ rẹ̀. Ẹ sọ àwọn ìbánilò rẹ̀ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn. Ẹ mẹ́nu kàn án pé orúkọ rẹ̀ ni a gbé ga. Ẹ kọ orin atunilára sí Jèhófà, nítorí pé ó ti ṣe ohun tí ó ta yọ ré kọjá. Èyí ni a sọ di mímọ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé.’” (Aísáyà 12:4, 5) Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Nítorí náà, yálà àwọn Júù tàbí àwọn tí kì í ṣe Júù ni o, àwọn Kristẹni yóò máa sìn gẹ́gẹ́ bí “ènìyàn kan fún orúkọ [Ọlọ́run].” (Ìṣe 15:14) Ó hàn gbangba pé ó dùn mọ́ Ọlọ́run nínú láti ṣètìlẹyìn fún àwọn tó kà á sí nǹkan iyì láti jẹ́ “ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀.”
9. (a) Èé ṣe tí ayọ̀ ṣe jẹ́ ohun táa fi ń dá àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ mọ̀? (b) Báwo ni Aísáyà ṣe fìyàtọ̀ tó wà láàárín ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké hàn?
9 Wọ́n jẹ́ aláyọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ aláyọ̀. Gẹ́gẹ́ bí orísun “ìhìn rere,” Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Nítorí náà, báwo ni àwọn olùjọsìn rẹ̀ yóò ṣe wá jẹ́ aláìláyọ̀ tàbí ẹni tí kì í gbà pé ọjọ́ ọlà yóò dára? Láìka wàhálà ayé àti ìṣòro ẹnì kọ̀ọ̀kan sí, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń yọ̀ nítorí wọ́n ń jẹ oúnjẹ tó rọ̀ ṣọ̀mù nípa tẹ̀mí déédéé. Aísáyà fi bí wọ́n ṣe yàtọ̀ sí àwọn tó ń ṣe ìsìn èké hàn, ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: ‘Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò jẹun, ṣùgbọ́n ebi yóò pa ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò mu, ṣùgbọ́n òùngbẹ yóò gbẹ ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò yọ̀, ṣùgbọ́n ojú yóò ti ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe ẹkún nítorí ìrora ọkàn-àyà, ẹ ó sì hu nítorí ìrẹ̀wẹ̀sì tí ó bùáyà.’”—Aísáyà 65:13, 14.
10. Báwo làwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ ṣe ń yẹra fún kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà èyí-jẹ-èyí-ò-jẹ?
10 Wọ́n gbé ìwà wọn àti àwọn ìpinnu wọn karí àwọn ìlànà Bíbélì. Ẹni tó kọ ìwé Òwe gbà wá nímọ̀ràn pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ, ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn tó ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ dípò tí wọn ì bá fi máa tẹ̀ lé àbá èrò orí tó ta kora ti àwọn èèyàn tí kò ka ọgbọ́n Ọlọ́run sí. Bí ẹnì kan bá ṣe gbé ìgbésí ayé rẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ni yóò ṣe máa yẹra fún kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà èyí-jẹ-èyí-ò-jẹ.—Sáàmù 119:33; 1 Kọ́ríńtì 1:19-21.
11. (a) Èé ṣe tí àwọn mẹ́ńbà ìsìn tòótọ́ kò fi gbọ́dọ̀ ní ẹgbẹ́ àlùfáà àti ti ọmọ ìjọ? (b) Àpẹẹrẹ wo ni àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń fi lélẹ̀ fún agbo?
11 A ṣètò wọn bíi ti ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Jésù ló gbé ìlànà náà kalẹ̀ pé: “Kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín, Ẹni ti ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni kí a má pè yín ní ‘aṣáájú,’ nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi. Ṣùgbọ́n kí ẹni tí ó tóbi jù lọ láàárín yín jẹ́ òjíṣẹ́ yín.” (Mátíù 23:8-11) Ìjọ àwọn ará kò fàyè gba ẹgbẹ́ àlùfáà kan tó ń wú fùkẹ̀, tó ń fi àwọn orúkọ òye ńláńlá dá ara rẹ̀ lọ́lá, tó sì ń fẹlá lé àwọn ọmọ ìjọ lórí. (Jóòbù 32:21, 22) A sọ fún àwọn tí ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run pé kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ “kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹní ń jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí, ṣùgbọ́n kí [wọ́n] di àpẹẹrẹ fún agbo.” (1 Pétérù 5:2, 3) Àwọn ojúlówó Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn máa ń yẹra fún fífẹ́ láti fi ara wọn ṣe ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn. Gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ ń sapá láti fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 1:24.
12. Ipò ìwọ̀ntúnwọ̀nsì wo ni Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn tó fẹ́ kí ó ti àwọn lẹ́yìn dì mú nípa ìjọba ẹ̀dá ènìyàn?
12 Wọ́n ń tẹrí ba fún ìjọba ẹ̀dá ènìyàn, síbẹ̀ wọn kì í dá sí tọ̀tún tòsì. Ẹnikẹ́ni tó bá kùnà láti “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga” kò lè retí pé kí Ọlọ́run wà lẹ́yìn òun. Kí nìdí? Nítorí pe “àwọn ọlá àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹni tí ó bá tako ọlá àṣẹ ti mú ìdúró kan lòdì sí ìṣètò Ọlọ́run.” (Róòmù 13:1, 2) Àmọ́ ṣá o, Jésù mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ìforígbárí wà nígbà tó sọ pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Máàkù 12:17) Àwọn tó fẹ́ kí Ọlọ́run máa ti àwọn lẹ́yìn gbọ́dọ̀ “máa bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba [Ọlọ́run] àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́,” nígbà kan náà, kí wọ́n máa ṣègbọràn sí àwọn òfin orílẹ̀-èdè tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ojúṣe wọn gíga sí Ọlọ́run. (Mátíù 6:33; Ìṣe 5:29) Jésù tẹnu mọ́ àìdásí-tọ̀túntòsì nígbà tó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” Ó wá fi kún un lẹ́yìn náà pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.”—Jòhánù 17:16; 18:36.
13. Ipa wo ni ìfẹ́ ń kó nínú dídá àwọn ènìyàn Ọlọ́run mọ̀?
13 Wọ́n kì í ṣe ojúsàájú nínú ṣíṣe “ohun rere sí gbogbo ènìyàn.” (Gálátíà 6:10) Ìfẹ́ Kristẹni kì í ṣe ojúsàájú, ó ń gba gbogbo èèyàn mọ́ra láìka àwọ̀ ara, ipò ìṣúnná owó tàbí ìmọ̀ ẹ̀kọ́, orílẹ̀-èdè, tàbí èdè sí. Ṣíṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ní pàtàkì sí àwọn tó bá wọn tan nínú ìgbàgbọ́ ń jẹ́ kí a mọ àwọn tí Ọlọ́run ń tì lẹ́yìn. Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”— Jòhánù 13:35; Ìṣe 10:34, 35.
14. Ǹjẹ́ ó pọndandan kí gbogbo gbòò tẹ́wọ́ gba àwọn tí inú Ọlọ́run dùn sí? Ṣàlàyé.
14 Wọ́n ṣe tán láti fojú winá inúnibíni fún ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Jésù ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣáájú pé: “Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú; bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọn yóò pa tiyín mọ́ pẹ̀lú.” (Jòhánù 15:20; Mátíù 5:11, 12; 2 Tímótì 3:12) Àwọn èèyàn sábà máa ń fojú burúkú wo àwọn tí Ọlọ́run ń tì lẹ́yìn, bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Nóà, ẹni tó dá ayé lẹ́bi nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀. (Hébérù 11:7) Lóde òní, àwọn tó fẹ́ kí Ọlọ́run máa ti àwọn lẹ́yìn kò jẹ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di yẹpẹrẹ tàbí kí wọ́n fi àwọn ìlànà Ọlọ́run báni dọ́rẹ̀ẹ́ nítorí kí a má bàa ṣe inúnibíni sí wọn. Níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti ń fi òtítọ́ sin Ọlọ́run, wọ́n mọ̀ pé yóò máa ‘rú àwọn èèyàn lójú, wọn ó sì máa bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ wọn tèébútèébú.’—1 Pétérù 2:12; 3:16; 4:4.
Àkókò Láti Gbé Òkodoro Òtítọ́ Yẹ̀ Wò
15, 16. (a) Àwọn ìbéèrè wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ètò ẹ̀sìn tí Ọlọ́run ń tì lẹ́yìn? (b) Kí ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ti parí èrò sí, èé sì ti ṣe?
15 Bí ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Àwọn ẹlẹ́sìn wo la mọ̀ tó rọ̀ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kódà nígbà ti ẹ̀kọ́ rẹ̀ yàtọ̀ sí ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn? Àwọn wo ló ń tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì orúkọ Ọlọ́run, tí wọ́n tilẹ̀ fi ń pe ara wọn? Àwọn wo ló ń fi ìdánilójú tọ́ka sí Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojútùú kan ṣoṣo sí gbogbo ìṣòro ẹ̀dá ènìyàn? Àwọn wo ló ń hu ìwà tó bá ọ̀pá ìdíwọ̀n Bíbélì mu, láìfi bí àwọn èèyàn ṣe máa kà wọ́n sí ẹni tí kò rọ́ọ̀ọ́kán pè? Àwọn wo la mọ̀ pé wọn kò ní ẹgbẹ́ àlùfáà tí wọ́n ń sanwó fún, tó jẹ́ pé gbogbo mẹ́ńbà wọn ló ń wàásù? Àwọn wo làwọn èèyàn máa ń yìn pé wọ́n ń pa òfin mọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í kópa nínú ọ̀ràn ìṣèlú? Àwọn wo ló máa ń fi tìfẹ́tìfẹ́ lo àkókò wọn, tí wọ́n sì ń fi owó wọn ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àtàwọn ète rẹ̀? Àwọn wo ló jẹ́ pé pẹ̀lú gbogbo ohun tó yẹ fún ìyìn tí wọ́n ń ṣe wọ̀nyí, àwọn èèyàn ṣì ń fojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, wọ́n ń fi wọ́n ṣẹ̀sín, wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wọn?’
16 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn jákèjádò ayé ló ti gbé òkodoro òtítọ́ náà yẹ̀ wò tí wọ́n sì ti rí i dájú pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ṣoṣo ló ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́. Wọ́n ti dé orí ìpinnu yìí nítorí ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni, àti nítorí ìwà wọn, títí kan àwọn àǹfààní tí ẹ̀sìn wọn ti mú wá. (Aísáyà 48:17) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ń sọ ohun tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà 8:23 pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”
17. Èé ṣe tí kì í fi í ṣe ìwà ọ̀yájú ló mú káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé àwọn ló ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́?
17 Ṣé ìwà ọ̀yájú ló mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé àwọn nìkan ni Ọlọ́run ń tì lẹ́yìn? Ní ti gidi, ohun tí wọ́n sọ yìí kò yàtọ̀ sí bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe sọ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn ní Íjíbítì láìka ìgbàgbọ́ àwọn ará Íjíbítì sí, tàbí nígbà tí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní sọ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn, pé kò sí lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́sìn Júù. Òótọ́ ọ̀rọ̀ ò ní ká má sọ òun. Igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe iṣẹ́ tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun tòótọ́ yóò máa ṣe ní àkókò òpin: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.
18, 19. (a) Èé ṣe tí kò fi sí ìdí kankan tí yóò mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jáwọ́ nínú ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn, bí a tilẹ̀ ń gbé àtakò dìde sí wọn? (b) Báwo ni Sáàmù 41:11 ṣe jẹ́rìí sí òtítọ́ náà pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn Ẹlẹ́rìí?
18 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò máa bá iṣẹ́ yìí lọ, wọn kò ní jẹ́ kí inúnibíni tàbí àtakò dí ìgbòkègbodò wọn lọ́wọ́. Ó pọndandan láti ṣe iṣẹ́ Jèhófà, a óò sì ṣe é. Gbogbo ipá táwọn kan sà ní ọ̀rúndún tó kọjá láti dí àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run láṣeyọrí ti já sí òtúbáńtẹ́, nítorí Jèhófà ṣèlérí pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí ọ nínú ìdájọ́ ni ìwọ yóò dá lẹ́bi. Èyí ni ohun ìní àjogúnbá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ọ̀dọ̀ mi sì ni òdodo wọn ti wá.”—Aísáyà 54:17.
19 Òtítọ́ náà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túbọ̀ ń lágbára sí i, tí iṣẹ́ wọ́n sì túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú nísinsìnyí ju ti ìgbàkigbà rí lọ—lójú inúnibíni jákèjádò ayé—jẹ́ ẹ̀rí pé inú Jèhófà dùn sí ohun tí wọ́n ń ṣe. Dáfídì Ọba sọ pé: “Nípa èyí ni mo mọ̀ pé ìwọ ní inú dídùn sí mi, nítorí pé ọ̀tá mi kò fi ayọ̀ ìṣẹ́gun kígbe lé mi lórí.” (Sáàmù 41:11; 56:9, 11) Àwọn ọ̀tá Ọlọ́run kò ní yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí àwọn ènìyàn Jèhófà láé, nítorí pé Jésù Kristi, tó jẹ́ Aṣáájú wọn ń tẹ̀ síwájú sí ìṣẹ́gun ìkẹyìn!
Ṣé O Lè Dáhùn?
• Àwọn àpẹẹrẹ ìgbàanì wo ló wà ní ti àwọn èèyàn tí Ọlọ́run tì lẹ́yìn?
• Kí ni àwọn àmì kan táa fi ń dá ìsìn tòótọ́ mọ̀?
• Èé ṣe tó fi dá ìwọ alára lójú pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àwọn tó fẹ́ kí Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn gbọ́dọ̀ gbé gbogbo ẹ̀kọ́ wọn karí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìkan ṣoṣo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn Kristẹni alàgbà jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo