Ìfaradà—Ṣekókó fún Àwọn Kristian
‘Ẹ fi ìfaradà kún ìgbàgbọ́ yín.’—2 PETERU 1:5, 6, NW.
1, 2. Èéṣe tí gbogbo wa fi níláti faradà á títí dé òpin?
ALÁBÒÓJÚTÓ arìnrìn-àjò àti aya rẹ̀ ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn kan tí ó wà nínú àwọn àádọ́rùn-ún ọ̀dún rẹ̀. Ó ti lo ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀, arákùnrin àgbàlagbà náà ronú padà sẹ́yìn nípa díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tí ó ti gbádùn la àwọn ọdún já. “Ṣùgbọ́n,” ni ó fi ìbànújẹ́ sọ bí omijé ti bẹ̀rẹ̀ síí ṣàn sílẹ̀ ní ojú rẹ̀, “nísinsìnyí èmi kò lè ṣe púpọ̀ nínú ohunkóhun mọ́.” Alábòójútó arìnrìn-àjò náà ṣí Bibeli rẹ̀ ó sì ka Matteu 24:13, níbi tí a ti ṣàyọlò ọ̀rọ̀ Jesu Kristi tí ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá forítì í títí dé òpin, òun náà ni a ó gbàlà.” Lẹ́yìn náà ni alábòójútó náà wo arákùnrin ọ̀wọ́n náà tí ó sì wí pé: “Iṣẹ́ àyànfúnni tí ó gbẹ̀yìn tí gbogbo wa ní, láìka bí èyí tí a lè ṣe ti pọ̀ tàbí kéré tó, ni láti faradà títí dé òpin.”
2 Bẹ́ẹ̀ni, gẹ́gẹ́ bíi Kristian gbogbo wa gbọdọ̀ faradà títí dé òpin ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí tàbí dé òpin ìwàláàyè wa. Kò sí ọ̀nà mìíràn tí a lè gbà jèrè ìtẹ́wọ́gbà Jehofa fún ìgbàlà. A wà nínú eré-ìje kan fún ìyè, a sì gbọ́dọ̀ “fi ìfaradà sáré” títí di ìgbà tí a bá tó kọjá ìlà ìparí. (Heberu 12:1, NW) Aposteli Peteru tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì ànímọ́ yìí nígbà tí ó rọ àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: ‘Ẹ fi ìfaradà kún ìgbàgbọ́ yín.’ (2 Peteru 1:5, 6, NW) Ṣùgbọ́n kí ni ìfaradà níti gàsíkíyá?
Ìfaradà—Ohun Tí Ó Túmọ̀sí
3, 4. Kí ni ó túmọ̀sí láti faradà?
3 Kí ni ó túmọ̀sí láti faradà? Ọ̀rọ̀ Griki náà fún “faradà” (hy·po·meʹno) lóréfèé túmọ̀sí “dúró títílọ tàbí wà lábẹ́.” Ó farahàn ní ìgbà mẹ́tàdínlógún nínú Bibeli. Gẹ́gẹ́ bí olùṣètumọ̀-èdè W. Baner, F. W. Gingrich, àti F. Danker ti wí, ó túmọ̀sí “dúró títílọ dípò sísá fún . . . , mú ìdúró ẹni, báa lọ ní kíkojú.” Ọ̀rọ̀-orúkọ Griki náà fún “ìfaradà” (hy·po·mo·neʹ) farahàn ní ìgbà tí ó ju ọgbọ̀n lọ. Nípa rẹ̀, A New Testament Wordbook, láti ọwọ́ William Barclay, sọ pé: “Ó jẹ́ ẹ̀mí náà tí ó lè fàyà rán àwọn nǹkan, kìí wulẹ̀ ṣe pẹ̀lú yíyọwọ́yọsẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrètí gbígbóná janjan . . . Ó jẹ́ ànímọ́ kan èyí tí ń mú ọkùnrin kan dúró ní ìdojúkọ atẹ́gùn. Ó jẹ́ agbára ìtóye náà tí ó lè yí ìrísí àdánwò lílekoko jùlọ padà sí ògo nítorí pé rékọjá ìrora ó ń rí góńgó náà.”
4 Ìfaradà, nígbà náà, ń mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti mú ìdúró wa kí á má sì sọ ìrètí nù ní ojú ìdènà tàbí ìnira. (Romu 5:3-5) Ó ń wo góńgó náà—ẹ̀bùn-eré-ìje, tàbí ẹ̀bùn, ti ìyè ayérayé, yálà ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀-ayé rékọjá ìrora ti ìsinsìnyí.—Jakọbu 1:12.
Ìfaradà—Èéṣe?
5. (a) Èéṣe tí gbogbo àwọn Kristian fi “nílò ìfaradà”? (b) Sí àwọn ìsọ̀rí méjì wo ni a lè pín àwọn àdánwò wa sí?
5 Gẹ́gẹ́ bíi Kristian, gbogbo wa “nílò ìfaradà.” (Heberu 10:36, NW) Èéṣe? Ní ìpìlẹ̀ nítorí pé a ń “bọ́ sínú onírúurú ìdánwò.” Ọ̀rọ̀ ẹsẹ-ìwé èdè Griki níhìn-ín ní Jakọbu 1:2 dámọ̀ràn ìbápàdé tí a kò retí tẹ́lẹ̀ tàbí èyí tí a kò tẹ́wọ́gbà, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí adigunjalè bá ko ẹnìkan lójú. (Fiwé Luku 10:30.) A ń ṣalábàápàdé àwọn àdánwò tí a lè pín sí ìsọ̀rí méjì: ìwọnnì tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti jogúnbá, àti ìwọnnì tí ó gbèrú nítorí ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run wa. (1 Korinti 10:13; 2 Timoteu 3:12) Kí ni díẹ̀ nínú àwọn àdánwò wọ̀nyí?
6. Báwo ni Ẹlẹ́rìí kan ṣe faradà nígbà tí ó ní àmódi onírora kan?
6 Àmódi líléwu. Bíi ti Timoteu, àwọn Kristian kan gbọ́dọ̀ farada “àìlera . . . ìgbàkúùgbà.” (1 Timoteu 5:23) Ní pàtàkì nígbà tí a bá dojúkọ àmódi tí kò sàn bọ̀rọ̀, bóyá tí ó kún fún ìrora gan-an, ni àìní wà fún wa láti lo ìfaradà, láti mú ìdúró wa, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun kí á má sì ṣe gbàgbé ìrètí Kristian wa. Gbé àpẹẹrẹ Ẹlẹ́rìí kan tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn àádọ́ta ọdún rẹ̀ yẹ̀wò ẹni tí ó wọ ṣòkòtò kan-náà pẹ̀lú kókó-ọlọ́yún aburúbògìrì tí ń yára dàgbà kan. La iṣẹ́-abẹ méjì kọjá ó ń báa lọ ní dídúró gbọnyingbọnyin nínú ìgbèròpinnu rẹ̀ láti máṣe gba ìfàjẹ̀sínilára. (Iṣe 15:28, 29) Ṣùgbọ́n kókó-ọlọ́yún náà tún padà farahàn ní abonú rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ síí dàgbà lọ sí ìtòsí ògóóró ẹ̀yìn rẹ̀. Bí ó ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń nírìírí ìrora ti ara tí kò ṣeéronúwòye tí kò sí iye ìtọ́jú ìṣègùn tí ó lè mú un rẹlẹ̀. Síbẹ̀, rékọjá ìrora ìsinsìnyí ó ń wo ẹ̀bùn ìyè nínú ayé titun náà. Ó ń báa lọ láti ṣàjọpín ìrètí rẹ̀ gbígbóná janjan pẹ̀lú àwọn dókítà, nọ́ọ̀sì, àti àwọn olùbẹ̀wò. Ó faradà á títí dé òpin—òpin ìwàláàyè rẹ̀. Ìṣòro ìlera rẹ lè má jẹ̀ èyí tí ń halẹ̀ mọ́ ìwàláàyè tàbí kún fún ìrora tó èyí tí arákùnrin ọ̀wọ́n yẹn nírìírí rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ṣì lè gbé ìdánwò ìfaradà ńláǹlà ka iwájú rẹ.
7. Irú ìrora wo ni ìfaradà ní nínú fún díẹ̀ lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tẹ̀mí?
7 Ìrora ti èrò-ìmọ̀lára. Láti ìgbà dé ìgbà, díẹ̀ lára àwọn ènìyàn Jehofa ń fàyàrán “ìbìnújẹ́ àyà” tí ń yọrísí ‘ọkàn tí a mú rẹ̀wẹ̀sì.’ (Owe 15:13) Ìsoríkọ́ mímúná kò ṣàìwọ́pọ̀ ní “ìgbà ewu” wọ̀nyí. (2 Timoteu 3:1) Ìwé-ìròyìn Science News ti December 5, 1992, róyìn pé: “Iye ìsoríkọ́ mímúná, tí ó sábà máa ń dánilọ́wọ́kọ́ ti pọ̀ síi nínú ìran àtẹ̀lé kọ̀ọ̀kan tí a ń bí láti 1915 wá.” Àwọn okùnfà irú ìkárísọ bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra, láti orí àwọn okùnfà ìṣiṣẹ́-ara sí àwọn ìrírí ríronilára tí kò gbádùnmọ́ni. Fún àwọn Kristian kan, ìfaradà wémọ́ ìjàkadì ojoojúmọ́ láti mú ìdúró wọn lójú èrò-ìmọ̀lára. Síbẹ̀, wọn kò jọ̀gọ̀nù. Wọ́n dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ sí Jehofa láìka àwọn omijé náà sí.—Fiwé Orin Dafidi 126:5, 6.
8. Àdánwò ìṣúnná-owó wo ni a lè ṣalábàápàdé?
8 Àwọn onírúurú àdánwò tí a ń bá pàdé lè ní ìnira ìṣúnná-owó lílekoko nínú. Nígbà tí arákùnrin kan ní New Jersey, U.S.A., dédé bá araarẹ̀ nípò àìníṣẹ́lọ́wọ́, òun lọ́nà tí ó yéni ṣàníyàn nípa bíbọ́ ìdílé rẹ̀ àti láti máṣe di ẹni tí a gba ilé rẹ̀ mọ́ lọ́wọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, òun kò gbàgbé ìrètí Ìjọba náà. Nígbà tí ó ń wá iṣẹ́ mìíràn, ó lo àǹfààní náà láti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó ríṣẹ́.—Matteu 6:25-34.
9. (a) Báwo ni àdánù olólùfẹ́ kan nínú ikú ṣe lè béèrè fún ìfaradà? (b) Àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ wo ni ó fihàn pé kò lódì láti sun ẹkún ìbànújẹ́?
9 Bí o bá ti nírìíri ìpàdánù olólùfẹ́ kan nínú ikú, ìwọ nílò ìfaradà tí ó wà fún ìgbà pípẹ́ lẹ́yìn tí àwọn wọnnì tí wọ́n yí ọ ká bá ti padà sẹ́nu iṣẹ́ ojoojúmọ́ wọn. Ìwọ tilẹ̀ lè rí i pé a máa ṣòro ní pàtàkì fún ọ lọ́dọọdún ní nǹkan bí àkókò tí olólùfẹ́ rẹ yẹn kú. Fífarada irú àdánù bẹ́ẹ̀ kò túmọ̀sí pé kò tọ̀nà láti sọkún ìbànújẹ́. Ó bá ìwà-ẹ̀dá mu láti ṣọ̀fọ̀ ikú ẹnìkan tí a fẹ́ràn, èyí kò sì fi àìní ìgbàgbọ́ nínú ìrètí àjíǹde hàn rárá. (Genesisi 23:2; fiwé Heberu 11:19.) Jesu “sọkún” lẹ́yìn tí Lasaru kú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Òun ti fi ìgboyà sọ fun Marta pé: “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.” Lasaru sì jíǹde nítòótọ́!—Johannu 11:23, 32-35, 41-44.
10. Èéṣe tí àwọn ènìyàn Jehofa fi ní àìní aláìlẹ́gbẹ́ fún ìfaradà?
10 Ní àfikún sí fífarada àwọn àdánwò tí ó wọ́pọ̀ fún gbogbo ènìyàn, àwọn ènìyàn Jehofa ní àìní aláìlẹ́gbẹ́ fún ìfaradà. “A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè nítorí orúkọ mi,” ni Jesu kìlọ̀. (Matteu 24:9) Ó tún sọ pé: “Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn ó ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Johannu 15:20) Èrèdí gbogbo ìkórìíra àti inúnibíni náà? Ìdí ni pé láìka ibi yòówù tí a ń gbé lórí ilẹ̀-ayé yìí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọrun sí, Satani ń gbìyànjú láti ba ìwàtítọ́ wa sí Jehofa jẹ́. (1 Peteru 5:8; fiwé Ìfihàn 12:17.) Nítorí ìdí èyí Satani ti sábà máa ń fẹ́ná mọ́ inúnibíni, ní fífi ìfaradà wa sínú ìdánwò mímúná.
11, 12. (a) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti àwọn ọmọ wọn dojúkọ ìdánwò ìfaradà wo ni àwọn ọdún 1930 àti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940? (b) Èéṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò fi kí ohun ìṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè?
11 Fún àpẹẹrẹ, ní àwọn ọdún 1930 àti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti àwọn ọmọ wọn ní United States àti Canada di àyànṣojú fún inúnibíni nítorí pé wọ́n kò kí ohun ìṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè nítorí ìdí tí ó jẹ́ ti ẹ̀rí-ọkàn. Àwọn Ẹlẹ́rìí ń bọ̀wọ̀ fún ohun ìṣàpẹẹrẹ ti ó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a là kalẹ̀ nínú Òfin Ọlọrun ní Eksodu 20:4, 5 pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ yá ère fún ara rẹ, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ lókè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ni ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ sìn wọ́n: nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mí.” Nígbà tí a lé àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ díẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí jáde kúrò nítorí pé wọ́n fẹ́ láti darí ìjọsìn wọn sí Jehofa Ọlọrun nìkanṣoṣo, àwọn Ẹlẹ́rìí náà dá àwọn Ilé-Ẹ̀kọ́ Ìjọba sílẹ̀ fún ìtọ́ni wọn. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí padà sí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gbogbogbòò nígbà tí Ilé-Ẹjọ́ Gíga Jùlọ ti United States mọ ipò wọn tí ó jẹ́ ti ìsìn ní àmọ̀jẹ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lajú ti ń ṣe lónìí. Bí ó ti wù kí ó rí, ìfaradà onígboyà ti àwọn ọ̀dọ́langba wọ̀nyí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ dídára tayọ pàápàá jùlọ fún àwọn èwe tí wọ́n jẹ́ Kristian tí wọ́n lè dojúkọ ìfiniṣẹlẹ́yà nísinsìnyí nítorí pé wọ́n sakun láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Bibeli.—1 Johannu 5:21.
12 Àwọn onírúurú àdánwò tí a ń ṣalábàápàdé—àwọn wọnnì tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn àti àwọn wọnnì tí a ń dojúkọ nítorí ìgbàgbọ́ Kristian wa—fi ìdí tí a fi nílò ìfaradà hàn. Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè faradà?
Faradà Títí Dé Òpin—Báwo?
13. Báwo ni Jehofa ṣe ń pèsè ìfaradà?
13 Àwọn ènìyàn Ọlọrun ní àǹfààní pàtó kan lórí àwọn wọnnì tí wọn kò jọ́sìn Jehofa. Fún ìrànlọ́wọ́, a lè fọ̀ràn lọ “Ọlọrun tí ń fúnni ní ìfaradà.” (Romu 15:5, NW) Báwo, nígbà náà, ni Jehofa ṣe ń fúnni ní ìfaradà? Ọ̀nà kan tí ó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni nípasẹ̀ àwọn àpẹẹrẹ ìfaradà tí a kọsílẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. (Romu 15:4) Bí a ti ń ronú lórí ìwọ̀nyí, kìí ṣe kìkì pé a fún wa níṣìírí láti faradà nìkan ni ṣùgbọ́n a tún kẹ́kọ̀ọ́ ohun púpọ̀ síi nípa bí a ṣe lè faradà. Gbé àwọn àpẹẹrẹ títayọ méjì yẹ̀wò—ìfaradà onígboyà ti Jobu àti ìfaradà aláìlábùkù ti Jesu Kristi.—Heberu 12:1-3; Jakọbu 5:11.
14, 15. (a) Àwọn àdánwò wo ni Jobu faradà? (b) Báwo ni ó ṣe ṣeéṣe fún Jobu láti farada àwọn àdánwò tí ó dojúkọ?
14 Àwọn ipò wo ni ó fi ìfaradà Jobu sínú ìdánwò? Ó jìyà ìnira ìṣúnná-owó nígbà tí ó pàdánù ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn ohun-ìní rẹ̀. (Jobu 1:14-17; fiwé Jobu 1:3.) Jobu mọ ìrora àdánù náà lára nígbà tí ìjì-ẹ̀fúùfù pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. (Jobu 1:18-21) Ó nírìírí àmódi líléwu, tí ó kún fún ìrora gidigidi. (Jobu 2:7, 8; 7:4, 5) Aya òun fúnraarẹ̀ yọ ọ́ lẹ́nu láìsinmi láti yípadà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun. (Jobu 2:9) Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tímọ́tímọ́ sọ àwọn ohun tí ó jẹ́ èyí tí ń baninínújẹ́, aláìnínúure, àti aláìjóòótọ́. (Fiwé Jobu 16:1-3 àti Jobu 42:7.) Là gbogbo èyí já, bí ó ti wù kí ó rí, Jobu mú ìdúró rẹ̀, ní pípa ìwàtítọ́ mọ́. (Jobu 27:5) Àwọn ohun tí ó faradà dọ́gba pẹ̀lú àwọn àdánwò tí àwọn ènìyàn Jehofa ń bá pàdé lónìí.
15 Báwo ni Jobu ṣe lè farada gbogbo àdánwò wọ̀nyí? Ohun kan ní pàtàkì tí ó gbé Jobu ró ni ìrètí. “Ìrètí wà fún igi pàápàá,” ni ó polongo. “Bí a bá ké e lulẹ̀, yóò tún rú lẹ́ẹ̀kan síi, èéhù-ẹ̀ka rẹ̀ fúnraarẹ̀ kì yóò sì dáwọ́ dúró láti wà.” (Jobu 14:7, NW) Ìrètí wo ni Jobu ní? Gẹ́gẹ́ bi a ti ṣàkíyèsí rẹ̀ ní àwọn ẹsẹ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Bí ọkùnrin abarapá kan bá kú òun ha lè wàláàyè lẹ́ẹ̀kan síi bí? . . . Ìwọ yóò pè, èmi fúnraàmi yóò sì dá ọ lóhùn. Nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni ìwọ yóò ṣàfẹ́rí [tàbí, yánhànhàn fún].” (Jobu 14:14, 15, NW) Bẹ́ẹ̀ni, Jobu ríran rékọjá ìrora rẹ̀ ti lọ́ọ́lọ́ọ́. Ó mọ̀ pé àwọn àdánwò òun kì yóò wà títí láé. Pátápinrá rẹ̀ òun yóò níláti faradà títí dé ojú ikú. Ìfojúsọ́nà rẹ̀ tí ó kún fún ìrètí ni pé Jehofa, ẹni tí ó fi tìfẹ́tìfẹ́ nífẹ̀ẹ́-ọkàn láti jí àwọn òkú dìde, yóò mú òun padà wá sí ìyè.—Iṣe 24:15.
16. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni a kọ́ nípa ìfaradà láti inú àpẹẹrẹ Jobu? (b) Báwo ni ìrètí Ìjọba náà ṣe gbọ́dọ̀ jẹ́ gidi sí wa tó, èésìtiṣe?
16 Kí ni a kọ́ láti inú ìfaradà Jobu? Láti faradà dé òpin, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé ìrètí wa. Rántí, pẹ̀lú, pé ìdánilójú ìrètí Ìjọba náà túmọ̀sí pé ìjìyà èyíkéyìí tí a bá ṣalábàápàdé wà “fún ìgbà kúkúrú” ní ìfiwéra. (2 Korinti 4:16-18) Ìrètí wa ṣíṣeyebíye lọ́nà tí kò lè yẹsẹ̀ ni a gbé karí ìlérí Jehofa nípa àkókò kan ní ọjọ́-ọ̀la tí kò jìnnà nígbà tí “[oun] yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [wa]; kì yóò sì sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ìrora mọ́.” (Ìfihàn 21:3, 4) Ìrètí yẹn, èyí tí “kìí . . . sinni lọ sí ìjákulẹ̀,” gbọ́dọ̀ ṣọ́ ìrònú wa. (Romu 5:4, 5, NW; 1 Tessalonika 5:8) Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ gidi sí wa—kí ó jẹ́ gidi gan-an débi pé nípasẹ̀ ojú ìgbàgbọ́, a lè yàwòrán araawa pé a wà nínú ayé titun—láì wọ̀jàkadì pẹ̀lú àmódi àti ìsoríkọ́ mọ́ ṣùgbọ́n tí a ń jí lójoojúmọ́ pẹ̀lú ìlera dídára àti pẹ̀lú èrò-inú ṣíṣe kedere; láì tún ṣàníyàn nípa àwọn ìkìmọ́lẹ̀ ìṣúnná-owó líléwu mọ́ ṣùgbọ́n gbígbé nínú àìléwu; kò sí ṣíṣọ̀fọ̀ ikú àwọn olólùfẹ́ mọ́ ṣùgbọ́n nínírìírí ayọ̀-amóríyá ti rírí i tí a ń jí wọn dìde. (Heberu 11:1) Láìsí irú ìrètí bẹ́ẹ̀ a lè bò wá mọ́lẹ̀ búrúbúrú nípasẹ̀ àwọn àdánwò wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́ débi pé a lè juwọ́sílẹ̀. Pẹ̀lú ìrètí wa, irú ìṣírí gígadabú wo ni a ní láti máa báa lọ ní jíjà, láti máa báa lọ ní fífaradà títí dé òpin!
17. (a) Àwọn àdánwò wo ni Jesu faradà? (b) Ìjìyà mímúná tí Jesu faradà ni ó ṣeéṣe kí á rí láti inú òtítọ́ wo? (Wo àkíyèsí ẹsẹ̀-ìwé.)
17 Bibeli rọ̀ wá láti “tẹjúmọ́” Jesu kí á sì ‘gbé e yẹ̀wò kínníkínní.’ Àwọn àdánwó wo ni ó faradà? Díẹ̀ nínú wọn jẹ jáde láti inú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé àwọn ẹlòmíràn. Jesu farada kìí ṣe “ọ̀rọ̀ òdì . . . láti ẹnu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀” nìkan ṣùgbọ́n àwọn ìṣòro tí ó dìde láàárín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú, èyí tí ó ní nínú aáwọ̀ léraléra lórí ẹni tí ó tóbi jùlọ. Ju ìyẹn lọ, ó ṣalábàápàdé ìdánwò ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́gbẹ́. Ó “farada òpó-igi ìdálóró.” (Heberu 12:1-3, NW; Luku 9:46; 22:24) Ó ṣòro àní láti ronúwòye ìjìyà ti èrò-orí àti ti ara-ìyára tí ó wémọ́ ìrora ìkànmọ́gi àti ìtìjú jíjẹ́ ẹni ti a fìyà-ikú jẹ gẹ́gẹ́ bí asọ̀rọ̀-òdì.a
18. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ti wí, àwọn nǹkan méjì wo ni ó gbé Jesu ró?
18 Kí ni ó mú kí ó ṣeéṣe fún Jesu láti faradà á títí dé òpin? Aposteli Paulu mẹ́nukan àwọn ohun méjì tí ó gbé Jesu ró: ‘àdúrà-ẹ̀bẹ̀ àti ìbéèrè-ẹ̀bẹ̀’ àti “ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ̀” pẹ̀lú. Jesu, Ọmọkùnrin pípé Ọlọrun, ni ojú kò tì láti béèrè fún ìrànlọ́wọ́. Ó gbàdúrà “pẹ̀lú igbe kíkankíkan àti omijé.” (Heberu 5:7; 12:2, NW) Ní pàtàkì nígbà tí ìgbẹ́jọ́ onípò-àjùlọ rẹ̀ ń súnmọ́tòsí ni ó rí i pé ó pọndandan láti gbàdúrà fún okun léraléra àti pẹ̀lú ìfọkànsí. (Luku 22:39-44) Ní ìdáhùnpadà sí àwọn àdúrà-ẹ̀bẹ̀ Jesu, Jehofa kò mú àdánwò náà kúrò, ṣùgbọ́n ó fokun fún Jesu láti faradà á. Jesu tún faradà nítorí pé rékọjá òpó-igi ìdálóró òun wo èrè rẹ̀—ayọ̀ tí òun yóò ní nínú ṣíṣètìlẹ́yìn fún ìsọdimímọ́ orúkọ Jehofa àti ìràpadà ìdílé ènìyàn kúrò lọ́wọ́ ikú.—Matteu 6:9; 20:28.
19, 20. Báwo ni àpẹẹrẹ Jesu ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti ní ojú-ìwòye tí ó jẹ́ gidi nípa ohun tí ìfaradà ní nínú?
19 Láti inú àpẹẹrẹ Jesu, a kẹ́kọ̀ọ́ iye àwọn ohun tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ojú-ìwòye tí ó jẹ́ gidi nípa ohun tí ìfaradà ní nínú. Ipa-ọ̀nà ìfaradà kìí ṣe ọ̀kan tí ó rọrùn. Bí ó bá ṣòro fún wa láti farada àdánwò kan pàtó, ìtùnú wà nínú mímọ̀ pé ohun kan-náà ni ó jẹ́ òtítọ́ nípa Jesu pàápàá. Láti faradà títí dé òpin, a gbọ́dọ̀ gbàdúrà léraléra fún okun. Nígbà tí a bá wà lábẹ́ àdánwò a lè nímọ̀lára àìtóótun láti gbàdúrà nígbà mìíràn. Ṣùgbọ́n Jehofa ń késí wa láti tú ọkàn-àyà wa jáde fún òun ‘nítorí pé òun ń ṣe ìtọ́jú wa.’ (1 Peteru 5:7) Àti nítorí ohun tí Jehofa fúnraarẹ̀ ti ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, òun ti sọ́ di àìgbọdọ̀máṣe fún araarẹ̀ láti pèsè “ọláńlá agbara” fún àwọn wọnnì tí ń képè é ní ìgbàgbọ́.—2 Korinti 4:7-9.
20 Nígbà mìíràn a gbọ́dọ̀ faradà pẹ̀lú omijé. Fún Jesu ìrora òpó-igi ìdálóró fúnraarẹ̀ ni kìí ṣe ìdí fún yíyọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ayọ̀ náà wà nínú èrè tí a gbé ka iwájú rẹ̀. Nínú ọ̀ràn tiwa kò ní jẹ́ òtítọ́ gidi kan láti reti pé àwa yóò máa fìgbà gbogbo nímọ̀lára ọ̀yàyà tí a ó sì kúnfáyọ̀ nígbà tí a bá wà lábẹ́ àdánwò. (Fiwé Heberu 12:11.) Nípa wíwo iwájú fún èrè náà, bí ó ti wù kí ó rí, yóò lè ṣeéṣe fún wa láti “ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀” àní nígbà tí a bá ṣalábàápàdé àwọn ipò tí ń dánniwò jùlọ pàápàá. (Jakọbu 1:2-4; Iṣe 5:41) Ohun tí ó ṣe pàtàkì náà ni pé kí a dúró títílọ láìyẹsẹ̀—àní bí ó bá tilẹ̀ níláti jẹ́ pẹ̀lú omijé pàápàá. Ó ṣetán, Jesu kò sọ pé, ‘Ẹni tí ó bá sun ẹkún tí ó kéré jùlọ ni a ó gbàlà’ ṣùgbọ́n, “Ẹni tí ó bá forítì í títí dé òpin, òun náà ni a ó gbàlà.”—Matteu 24:13.
21. (a) Ní 2 Peteru 1:5, 6 (NW), a rọ̀ wá láti fi kí ni kún ìfaradà wa? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a ó gbéyẹ̀wò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e?
21 Ìfaradà tipa báyìí ṣekókó fún ìgbàlà. Bí ó ti wù kí ó rí, ní 2 Peteru 1:5, 6, a rọ̀ wá láti fi ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run kún ìfaradà wa. Kí ni ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run? Báwo ni ó ṣe tan mọ́ ìfaradà, báwo sì ni iwọ ṣe lè ní in? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ni a ó gbéyẹ̀wò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìjìyà mímúná tí Jesu faradà ní ó ṣeéṣe kí a rí láti inú òtítọ́ náà pé ẹ̀yà-ara-ẹ̀dá pípé rẹ̀ kú lẹ́yìn kìkì ìwọ̀nba wákàtí díẹ̀ lórí òpó-igi, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn olùṣe-búburú tí a kànmọ́gi lẹ́bàá rẹ̀ ni a níláti fọ́ egungun ẹsẹ wọn láti mú ikú wọn yára kánkán. (Johannu 19:31-33) Wọn kò tíì nírìírí ìjìyà ti èrò-orí àti ti ara-ìyára tí Jesu jìyà rẹ̀ lákòókò àìsùn-àìwo la gbogbo òru tí ó ṣáájú ìkànmọ́gi já, bóyá dé orí ibi tí kò tilẹ̀ ti lè gbé òpó-igi ìdálóró tirẹ̀ fúnraarẹ̀ mọ́ pàápàá.—Marku 15:15, 21.
Báwo ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni ó túmọ̀sí láti faradà?
◻ Èéṣe tí àwọn ènìyàn Jehofa fi ní àìní aláìlẹ́gbẹ́ fún ìfaradà?
◻ Kí ni ó mú kí ó ṣeéṣe fún Jobu láti faradà?
◻ Báwo ni àpẹẹrẹ Jesu ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti ní ojú-ìwòye tí ó jẹ́ gidi nípa ìfaradà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Ilé-Ẹ̀kọ́ Ìjọba ni a dá sílẹ̀ láti kọ́ àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ Kristian tí a lé jáde kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ nítorí dídarí ìjọsìn wọn kìkì sí Jehofa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Bí ó ti pinnu láti bọlá fún Baba rẹ̀, Jesu gbàdúrà fún okun láti faradà