Ohun Tá a Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù
Nípa Àkókò “Òpin”
Kí ló máa dópin?
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: “Kí ni yóò . . . jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mátíù 24:3) Nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè yẹn, Jésù ò sọ pé ilẹ̀ ayé yìí máa pa run. Ó ti sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa “ètò àwọn nǹkan,” ohun tó sì ní lọ́kàn nígbà yẹn ni àwọn ètò tí Sátánì ń darí bí ètò òṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé àtàwọn ìsìn. (Mátíù 13:22, 40, 49) Ètò àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Òpin yóò . . . dé.”—Mátíù 24:14.
Báwo ni Jésù ṣe ṣàpèjúwe àkókò òpin?
“Ìhìn rere” ló jẹ́ láti gbọ́ pé ètò àwọn nǹkan búburú yìí máa dópin. Jésù sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” Nígbà tí Jésù máa ṣàpèjúwe bí ètò búburú yìí ṣe máa dópin, ó ní: “Ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́. Ní ti tòótọ́, láìjẹ́ pé a ké ọjọ́ wọnnì kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là.”—Mátíù 24:14, 21, 22.
Àwọn wo ló máa pa run?
Kìkì àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù, tí wọ́n sì kọ̀ láti sìn wọ́n ló máa pa run. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí. Nítorí bí wọ́n ti wà ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, . . . wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.” (Mátíù 24:36-39) Jésù sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń rìn lójú ọ̀nà tó lọ sí ìparun. Àmọ́, ó jẹ́ kó dá wa lójú pé ọ̀nà “tóóró . . . tí ó lọ sínú ìyè” wà.—Mátíù 7:13, 14.
Ìgbà wo lètò àwọn nǹkan yìí máa dópin?
Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bi í pé kí ló máa jẹ́ àmì wíwà níhìn-ín rẹ̀ “àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan,” Jésù fún wọn lésì pé: “Nítorí orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìsẹ̀lẹ̀ . . . àti nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.” (Mátíù 24:3-12) Nítorí náà, gbogbo àwọn ìròyìn búburú tá à ń gbọ́ lónìí nítumọ̀ kan tó lè múnú wa dùn, ìyẹn ni pé Ìjọba Ọlọ́run máa mú àlàáfíà wá fáwọn èèyàn tó bá jẹ́ onígbọràn. Jésù sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé.”—Lúùkù 21:31.
Kí ló yẹ kó o ṣe?
Jésù sọ pé Ọlọ́run “fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) O ní láti mọ Ọlọ́run àti ọmọ rẹ̀ dáadáa, kó o bàa lè lo ìgbàgbọ́ nínú wọn. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
O gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, kí àníyàn àtàwọn ìṣòro tó kúnnú ayé yìí má bàa dí ẹ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè máa fi hàn pó o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú . . . àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. Nítorí yóò dé.” Tó o bá fetí sí ìmọ̀ràn Jésù wàá “kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀”—Lúùkù 21:34-36.
Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo orí 9 tá a pe àkòrí ẹ̀ ní, “Ṣé ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn’ La Wà Yìí?” nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?a
[Àláyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.