Ṣiṣiṣẹsin Gẹgẹ Bi Awọn Apẹja Eniyan
“Jesu wi fun Simoni: ‘Dẹ́kun fífòyà. Lati isinsinyi lọ iwọ yoo maa mú awọn eniyan lóòyẹ̀.’”—LUKU 5:10, NW.
1, 2. (a) Ipa wo ni ẹja pípa ti kó ninu ìtàn araye? (b) Iru ẹja pípa titun wo ni a mú wa mọ̀ ni nǹkan bii 2,000 ọdun sẹhin?
FUN ẹgbẹẹgbẹrun ọdun, araye ti ń pẹja ninu awọn òkun, adágún, ati odò ilẹ-aye. Awọn ẹja lati inu odò Naili jẹ́ apá pataki ninu ounjẹ Egipti igbaani. Nigba ti a yí omi Naili pada di ẹ̀jẹ̀ ni ọjọ Mose, awọn ará Egipti jìyà kì í ṣe nitori àìtó omi ti ó yọrisi nikan ni ṣugbọn nitori pe awọn ẹja kú pẹlu, eyi ti ó nípalori ipese ounjẹ wọn. Lẹhin naa, ní Sinai, nigba ti Jehofa fun Israeli ni Ofin, ó sọ fun wọn pe iru awọn ẹja kan ni wọn lè jẹ ṣugbọn pe awọn miiran jẹ́ aláìmọ́, ti wọn kò gbọdọ jẹ. Eyi fihan pe awọn ọmọ Israeli yoo jẹ ẹja nigba ti wọn bá dé Ilẹ Ileri, nitori naa diẹ ninu wọn yoo jẹ́ apẹja ọkunrin.—Eksodu 7:20, 21; Lefitiku 11:9-12.
2 Bi o ti wu ki o ri, ni ohun ti ó fẹrẹẹ tó 2,000 ọdun sẹhin, iru ẹja pípa miiran ni a mú araye mọ̀. Eyi jẹ́ iru ẹja pípa tẹmi kan ti yoo ṣanfaani fun kì í ṣe awọn ọkunrin apẹja nikan ṣugbọn fun awọn ẹja eniyan pẹlu! Iru ẹja pípa yii ni a si ń ṣe bi àṣà sibẹ lonii, pẹlu awọn anfaani gígadabú fun araadọta-ọkẹ yika ayé.
“Mímú Awọn Eniyan Lóòyẹ̀”
3, 4. Awọn ọkunrin apẹja meji wo ni wọn fi ọkan-ifẹ giga hàn ninu Jesu Kristi?
3 Ni ọdun 29 C.E., Jesu, Ẹni naa ti yoo mú iru ẹja pípa titun yii di mímọ̀, ni a rìbọmi ninu odo Jordani lati ọwọ Johannu Arinibọmi. Ni iwọnba ọ̀sẹ̀ diẹ lẹhin naa, Johannu tọka Jesu fun meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ó sì wi pe: “Wò Ọdọ-agutan Ọlọrun!” Ọ̀kan lara awọn ọmọ-ẹhin wọnyi, ẹni ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Anderu, yára sọ fun arakunrin rẹ̀ Simoni Peteru pe: “Awa ti rí Messia”! Lọna ti ó fa ọkàn-ìfẹ́ mọ́ra, ati Anderu ati Simoni jẹ́ ọkunrin olówò ẹja pipa.—Johannu 1:35, 36, 40, 41; Matteu 4:18.
4 Ó pẹ́ diẹ lẹhin naa, Jesu ń waasu fun awọn ogunlọgọ lẹ́bàá Òkun Galili, kò jinna sí ibi ti Peteru ati Anderu ń gbé. Ó ń sọ fun awọn eniyan naa pe: “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ̀.” (Matteu 4:13, 17) A lè finúrò ó pe Peteru ati Anderu ń háragàgà lati gbọ́ ihin-iṣẹ rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, ó ṣeeṣe, ki wọn má mọ̀ pe Jesu ti fẹ́ sọ ohun kan fun wọn ti yoo yí igbesi-aye wọn pada titilae. Ju bẹẹ lọ, ohun ti Jesu ni lati sọ ati lati ṣe ni oju wọn ní itumọ pataki fun gbogbo wa lonii.
5. Bawo ni Peteru ọkunrin apẹja naa ṣe wulo fun Jesu?
5 A kà pe: “Ni akoko kan nigba ti ogunlọgọ eniyan ṣù mọ́ ọn ti wọn sì ń gbọ́ ọrọ Ọlọrun, ó duro lẹ́bàá adágún Genesareti. Ó sì rí ọkọ̀ meji ti wọn gúnlẹ̀ leti adágún naa, ṣugbọn awọn ọkunrin apẹja ti kuro ninu wọn, wọn sì ń fọ àwọ̀n wọn.” (Luku 5:1, 2, NW) Nigba naa lọhun-un, awọn ọkunrin ti ń fi ẹja pípa ṣe iṣẹ ṣe sábà maa ń ṣiṣẹ ní òru, awọn ọkunrin wọnyi sì ń fọ àwọ̀n wọn lẹhin ẹja pípa ni òru. Jesu pinnu lati lo ọ̀kan lara awọn ọkọ̀ wọn kí ó baa lè waasu sii lọna gbigbeṣẹ fun ogunlọgọ naa. “Ó sì wọ ọ̀kan ninu awọn ọkọ̀ naa, ti o jẹ́ ti Simoni, ó sì sọ fun un pe ki ó wa ọkọ̀ sẹhin ni iwọnba kan kuro ni ilẹ. Lẹhin naa ni ó jokoo, lati inu ọkọ̀ ni o sì ti bẹrẹ sii kọ́ awọn ogunlọgọ eniyan lẹkọọ.”—Luku 5:3, NW.
6, 7. Iṣẹ iyanu wo ti ó wémọ́ ẹja pípa ni Jesu ṣe, ti ń ṣamọna si gbolohun-ọrọ wo nipa ẹja pípa?
6 Ṣakiyesi pe Jesu ní ohun kan sii ninu ọkàn ju kíkọ́ awọn ogunlọgọ naa lẹkọọ lọ: “Bi o sì ti dákẹ́ ọrọ sísọ, ó wí fun Simoni pe: ‘Wa ọkọ̀ lọ si ibi ti o jindò, ki ẹyin eniyan sì ju àwọ̀n yin sódò fun àkópọ̀.’” Ranti pe, awọn ọkunrin apẹja wọnyi ti ń ṣiṣẹ ni gbogbo òru. Lọna ti kò yanilẹnu, Peteru fèsì pe: “Olukọni, gbogbo òru ni awa fi ṣe làálàá awa kò sì mu ohunkohun, ṣugbọn gẹgẹ bi o ti paṣẹ emi yoo ju àwọ̀n naa sódò.” Ki lo ṣẹlẹ nigba ti wọn ṣe eyi? “Wọn kó ògìdìgbó ńláǹlà ẹja. Niti tootọ, àwọ̀n wọn bẹrẹ sii fàya. Nitori naa wọn juwọ́ si awọn ẹlẹgbẹ wọn ti wọn wà ninu ọkọ̀ keji lati wá ràn wọn lọ́wọ́; wọn sì wá, wọn sì kún awọn ọkọ̀ mejeeji tobẹẹ ti awọn wọnyi bẹrẹ sii rì.”—Luku 5:4-7, NW.
7 Jesu ti ṣe iṣẹ iyanu kan. Alagbalúgbú omi òkun yẹn ti wà laimu ohunkohun wá ni gbogbo òru; nisinsinyi ó kún fọ́fọ́ fun ẹja. Iṣẹ iyanu yii ni ipa alagbara lori Peteru. “Simoni Peteru wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jesu, ni wiwi pe: ‘Lọ kuro lọdọ mi, nitori ọkunrin ẹlẹṣẹ ni mi, Oluwa.’ Nitori àkópọ̀ ẹja ti wọn kó, iyanu ńlá bá a ati gbogbo awọn wọnni ti wọn wà pẹlu rẹ̀, bẹẹ gẹgẹ sì ni Jakọbu ati Johannu, awọn ọmọkunrin Sebede, ti wọn jẹ́ alájọpín pẹlu Simoni.” Jesu fi ọkàn Peteru balẹ ó sì sọ awọn ọrọ ti yoo yí igbesi-aye Peteru pada lẹhin naa. “Dẹ́kun fífòyà. Lati isinsinyi lọ iwọ yoo maa mú awọn eniyan lóòyẹ̀.”—Luku 5:8-10, NW.
Awọn Apẹja Eniyan
8. Bawo ni awọn ọkunrin mẹrin ti ń fi ẹja pípa ṣe iṣẹ ṣe ṣe dahunpada si ikesini naa lati ‘mú awọn eniyan lóòyẹ̀’?
8 Jesu tipa bayii fi awọn eniyan wé ẹja, ó sì ké sí ọkunrin apẹja onirẹlẹ yii lati fi iṣẹ́-òwò ounjẹ òòjọ́ rẹ̀ silẹ fun iru ẹja pípa titobiju kan—mímú awọn eniyan lóòyẹ̀. Peteru, ati arakunrin rẹ̀ Anderu, tẹwọgba ikesini naa. “Wọn sì fi àwọ̀n silẹ loju kan-naa, wọn sì tọ̀ ọ́ lẹhin.” (Matteu 4:18-20) Jesu képe Jakọbu ati Johanu, ti wọn wà ninu ọkọ̀ wọn ti wọn ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ó ké sí awọn wọnyi pẹlu lati di apẹja eniyan. Bawo ni wọn ṣe dahunpada? “Loju kannaa wọn sì fi ọkọ̀ ati baba wọn silẹ, wọn sì tọ̀ ọ́ lẹhin.” (Matteu 4:21, 22) Jesu fi ìjáfáfá hàn gẹgẹ bi apẹja awọn ọkàn. Ni akoko yii ó mú awọn ọkunrin mẹrin lóòyẹ̀.
9, 10. Igbagbọ wo ni Peteru ati awọn alabaakẹgbẹ rẹ̀ fihan, bawo sì ni a ṣe dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ ninu ẹja pípa tẹmi?
9 Ọkunrin kan ti ń fi ẹja pípa ṣiṣẹṣe ń rí ounjẹ òòjọ́ nipa títa ohun tí ó rí mú, ṣugbọn ọkunrin apẹja tẹmi kan kò lè ṣe iyẹn. Fun idi yii, awọn ọmọ-ẹhin wọnyi fi igbagbọ titobi hàn nigba ti wọn pa ohun gbogbo tì lati tẹle Jesu. Bi o ti wu ki o ri, wọn kò ṣiyemeji rara, pe ẹja pípa tẹmi wọn yoo yọrisirere. O ti ṣeeṣe fun Jesu lati lè sọ omi ti kò mú ohunkohun wá kún fọ́fọ́ fun ẹja gidi. Bakan naa, nigba ti wọn na àwọ̀n wọn sinu omi orilẹ-ede Israeli, awọn ọmọ-ẹhin lè ni idaniloju pe, pẹlu iranlọwọ Ọlọrun, awọn yoo mú awọn eniyan lóòyẹ̀. Iṣẹ ẹja pípa tẹmi tí ó bẹrẹ nigba naa lọhun un ń baa lọ, Jehofa sì ń funni ni ikore jaburata sibẹ.
10 Fun ohun ti o ju ọdun meji lọ, awọn ọmọ-ẹhin wọnni ni Jesu dalẹ́kọ̀ọ́ ninu pípẹja eniyan. Ni akoko kan ó fun wọn ni awọn itọni oniṣọọra ó sì rán wọn ṣiwaju rẹ̀ lati waasu. (Matteu 10:1-7; Luku 10:1-11) Nigba ti a fi Jesu hàn ti a sì pa á, awọn ọmọ-ẹhin ni ẹnu yà. Ṣugbọn iku Jesu ha tumọsi àìpẹja eniyan mọ́ bi? Kò pẹ tí awọn iṣẹlẹ fi funni ni idahun.
Pipẹja Ninu Òkun Araye
11, 12. Lẹhin ajinde rẹ̀, iṣẹ iyanu wo ni Jesu ṣe ti ó nii ṣe pẹlu ẹja pípa?
11 Ni kété lẹhin iku Jesu lẹhin òde Jerusalemu ati ajinde rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin pada si Galili. Ni akoko kan meje ninu wọn wà papọ lẹ́bàá Òkun Galili. Peteru sọ pe oun ń lọ pa ẹja, awọn yooku sì darapọ mọ́ ọn. Gẹgẹ bi ó ti maa ń rí, wọn ṣiṣẹ ẹja pípa ni òru. Niti tootọ, wọn da àwọ̀n wọn sinu òkun lẹẹkan sii ni gbogbo òru láìmú ohunkohun. Lẹhin naa ní àfẹ̀mọ́júmọ́, irisi kan ti wọn rí ti ń duro ni etíkun ké sí wọn lodikeji omi naa: “Ẹyin ọmọ keekeeke, ẹ kò ni ohunkohun lati jẹ, ẹ ní bi?” Awọn ọmọ-ẹhin kigbe pada pe: “Bẹẹkọ!” Nitori naa ẹni naa ti ń duro ni etíkun sọ fun wọn pe: “‘Ẹ ju àwọ̀n sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ọkọ ẹyin yoo sì rí diẹ.’ Nigba naa ni wọn sì jù ú, ṣugbọn wọn kò lagbara mọ́ lati fà á wọkọ̀ nitori ògìdìgbó awọn ẹja naa.”—Johannu 21:5, 6, NW.
12 Iru ìrírí amúniṣeháà wo ni eyi jẹ́! Ó ṣeeṣe ki awọn ọmọ-ẹhin ranti iṣẹ iyanu iṣaaju tí ó wémọ́ ẹja pípa, ó sì kérétán ẹnikan ninu wọn mọ ẹni ti irisi tí ó wà ní etíkun naa jẹ́. “Nitori naa ọmọ-ẹhin yẹn ti Jesu ti maa ń nífẹ̀ẹ́ sí tẹlẹri wi fun Peteru pe: ‘Oluwa ni!’ Nitori bẹẹ Simoni Peteru, nigba ti o gbọ́ pe Oluwa ni, fi ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ di araarẹ̀ lámùrè, nitori ti ó wà ni ìhòòhò, ó sì bẹ́ sinu òkun. Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin yooku bá ọkọ kekere naa wá, nitori wọn kò jinna si ilẹ̀, nǹkan bii ọgọrun-un mẹta ẹsẹ bàtà pere ni sibẹ.”—Johannu 21:7, 8, NW.
13. Lẹhin igoke re ọ̀run Jesu, itolẹsẹẹsẹ ẹja pípa jakejado awọn orilẹ-ede wo ni ó bẹrẹ?
13 Ki ni iṣẹ iyanu yii fihan? Pe iṣẹ pipẹja eniyan kò tíì pari. Otitọ yii ni a tẹnumọ nigba ti Jesu ń baa lọ lati sọ fun Peteru lẹẹmẹta—ati nipasẹ rẹ̀ fun gbogbo awọn ọmọ-ẹhin—lati bọ́ awọn agutan Jesu. (Johannu 21:15-17) Bẹẹni, itolẹsẹẹsẹ ìfoúnjẹ tẹmi bọ́ni wà niwaju. Ṣaaju iku rẹ̀, ó ti sọtẹlẹ pe: “A o sì waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo ayé lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede.” (Matteu 24:14) Nisinsinyi akoko ti tó fun imuṣẹ asọtẹlẹ yẹn ni ọrundun kìn-ín-ní lati bẹrẹ. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ti fẹ́ sọ àwọ̀n wọn sinu òkun araye, àwọ̀n naa kò sì ni wá soke lófo.—Matteu 28:19, 20.
14. Ni ọ̀nà wo ni a gbà bukun ẹja pípa awọn ọmọlẹhin Jesu ni awọn ọdun ṣaaju iparun Jerusalemu?
14 Ṣaaju ki ó tó goke lọ sori ìtẹ́ Baba rẹ̀ ni ọ̀run, Jesu sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe: “Ẹyin yoo gba agbara, nigba ti ẹmi mímọ́ bá bà lé yin: ẹ o sì maa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalemu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ ayé.” (Iṣe 1:8) Nigba ti a tú ẹmi mímọ́ jade sori awọn ọmọ-ẹhin ni Pentekosti 33 C.E., iṣẹ titobi ti ẹja pípa tẹmi bẹrẹ jakejado awọn orilẹ-ede. Ni ọjọ Pentekosti nikan, ẹgbẹẹdogun ọkàn ni a mú lóòyẹ̀, ati lẹhin ìgbà naa “iye awọn ọkunrin naa si tó ẹgbẹẹdọgbọn.” (Iṣe 2:41; 4:4) Ibisi naa ń baa lọ. Akọsilẹ naa sọ fun wa pe: “A sì ń yan awọn ti o gba Oluwa gbọ́ kun wọn si i, ati ọkunrin ati obinrin.” (Iṣe 5:14) Laipẹ, awọn ará Samaria dahunpada si ihinrere, ati ni kété lẹhin ìgbà naa ni awọn Keferi alaikọla naa ṣe bẹẹ. (Iṣe 8:4-8; 10:24, 44-48) Ni nǹkan bii ọdun 27 lẹhin Pentekosti, aposteli Paulu kọwe si awọn Kristian ni Kolosse pe ihinrere ni a ti “waasu rẹ̀ ninu gbogbo ẹ̀dá ti ń bẹ labẹ ọ̀run.” (Kolosse 1:23) Ni kedere, awọn ọmọ-ẹhin Jesu ti pẹja jinna gan-an si omi Galili. Wọn ti dẹ àwọ̀n wọn silẹ laaarin awọn Ju ti wọn fọ́nká yika Ilẹ-Ọba Romu, ati bakan naa ninu òkun awọn eniyan ti wọn kì í ṣe Ju ti o dabi alàìlèkẹ́sẹjárí. Àwọ̀n wọn sì ti wá sókè ni kikun. Fun aini awọn Kristian ọrundun kìn-ín-ní, asọtẹlẹ Jesu ni Matteu 24:14 ni a muṣẹ ṣaaju ki a tó pa Jerusalemu run ni 70 C.E.
Pipẹja Eniyan ni “Ọjọ Oluwa”
15. Ninu iwe Ifihan, iṣẹ ẹja pípa siwaju sii wo ni a sọtẹlẹ, nigba wo sì ni a nilati ṣe é?
15 Bi o ti wu ki o ri, pupọ sii ni ó wà ni iwaju. Ni apa ipari ọrundun kìn-ín-ní, Jehofa fun Johannu, aposteli ti ó wà kẹhin, ni iṣipaya awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ ni “ọjọ Oluwa.” (Ifihan 1:1, 10) Ìhà titayọ kan ni sisọ ihinrere naa yoo jẹ́ yika ayé. A kà pe: “Mo sì rí angẹli miiran ń fò ni agbedemeji ọ̀run, ti oun ti ihinrere ainipẹkun lati waasu fun awọn ti ń gbé ori ilẹ̀-ayé, ati fun gbogbo orilẹ, ati ẹ̀yà, ati èdè, ati eniyan.” (Ifihan 14:6) Labẹ idari angẹli awọn iranṣẹ Ọlọrun yoo waasu ihinrere naa niti gidi ni gbogbo ilẹ̀-ayé ti a ń gbé, ki i wulẹ ṣe jadejado Ilẹ-ọba Romu. Iṣẹ apẹja ọkàn kari ayé ni a nilati dawọle, ọjọ wa sì ti rí imuṣẹ ìran yẹn.
16, 17. Nigba wo ni iṣẹ ẹja pípa ti akoko lọwọlọwọ bẹrẹ, bawo sì ni Jehofa ṣe bukun un?
16 Bawo ni ẹja pípa naa ti rí ni ọrundun lọna 20 yii? Ni ibẹrẹ, awọn ọkunrin apẹja kò tó nǹkan ni ifiwera. Lẹhin ti Ogun Agbaye I pari, kìkì ẹgbẹrun mẹrin awọn oniwaasu ihinrere agbekankanṣiṣẹ, awọn ọkunrin ati obinrin onitara ti ọpọ julọ jẹ́ ẹni ami ororo ni wọn wà. Wọn ju àwọ̀n wọn si ibikibi ti Jehofa bá ti ṣí ọ̀nà silẹ, ọpọlọpọ ọkàn ni wọn sì mú lóòyẹ̀. Tẹle ogun agbaye keji, Jehofa ṣí omi titun fun ẹja pípa silẹ. Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ti wọn ti lọ si Watchtower Bible School of Gilead gbapo iwaju ninu iṣẹ naa ni ọpọlọpọ ilẹ. Awọn orilẹ-ede bii Japan, Italy, ati Spain, ti wọn ti lè jọbi aṣálẹ̀ gan-an ni ibẹrẹ, lẹhin-ọ-rẹhin mú ikore awọn ọkàn jade ni jìngbìnnì. A tun ti mọ̀ lẹnu aipẹ yii bi ẹja pípa naa ti ṣaṣeyọri tó ni Ìhà Ila-oorun Europe.
17 Lonii, ní ọpọlọpọ orilẹ-ede awọn àwọ̀n fẹrẹẹ lè já. Ikore titobi ti awọn ọkàn ti mú ṣiṣeto awọn ijọ ati ayika titun pọndandan. Lati ráàyè fun iwọnyi, awọn Gbọngan Ijọba ati Gbọngan Apejọ titun ni a ń kọ́ nigba gbogbo. Awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ pupọ sii ni a nilo lati bojuto ibisi naa. Iṣẹ pupọ jaburata ni awọn oluṣotitọ wọnni bẹrẹ lẹhin lọhun-un ni 1919. Ni ọ̀nà olówuuru, Isaiah 60:22 ti ní imuṣẹ. ‘Ẹni kekere kan ti di ẹgbẹrun,’ gẹgẹ bi ẹgbẹrun mẹrin awọn apẹja wọnni ti di iye ti ó ju million mẹrin lọ lonii. Opin kò sì tíì dé sibẹ.
18. Bawo ni a ṣe lè ṣafarawe apẹẹrẹ rere awọn apẹja eniyan tẹmi ti ọrundun-kìn-ín-ní?
18 Ki ni gbogbo eyi tumọsi fun wa gẹgẹ bi ẹnikọọkan? Iwe mimọ sọ pe nigba ti a ké sí Peteru, Anderu, Jakọbu, ati Johannu lati di apẹja eniyan, “wọn . . . pa ohun gbogbo tì wọn sì ń tọ [Jesu] lẹhin.” (Luku 5:11, NW) Apẹẹrẹ rere ti igbagbọ ati iyasimimọ wo ni eyi jẹ́! Awa ha lè mú iru ẹmi ifara-ẹni rubọ bẹẹ, iru imuratan kan-naa lati ṣiṣẹsin Jehofa laika ohun ti ó lè ná wa sí dàgbà bi? Araadọta-ọkẹ ti dahun pe awọn lè ṣe bẹẹ. Ni ọrundun kìn-ín-ní, awọn ọmọ-ẹhin pẹja eniyan nibikibi ti Jehofa bá ti yọnda. Yala ó jẹ́ laaarin awọn Ju tabi Keferi, wọn pẹja laida ibikan sí. Ẹ jẹ ki awa pẹlu waasu fun olukuluku eniyan laisi ikalọwọko tabi ẹtanu eyikeyii.
19. Ki ni a gbọdọ ṣe bi omi ibi ti a ti ń pẹja kò bá dabi eyi ti o mesojade?
19 Bi o ti wu ki o ri, ki ni, bi ipinlẹ rẹ̀ ni bayii bá dabi alaimeso jade? Maṣe rẹwẹsi. Ranti pe, Jesu kún àwọ̀n awọn ọmọ-ẹhin lẹhin ti wọn ti ṣiṣẹ ẹja pípa fun gbogbo òru laisi abajade. Ohun kan-naa lè ṣẹlẹ ni ọ̀nà tẹmi. Ni Ireland, fun apẹẹrẹ, Awọn Ẹlẹ́rìí oluṣotitọ ṣiṣẹ kára fun ọpọ ọdun pẹlu aṣeyọri ti kò tó nǹkan. Sibẹ, lẹnu aipẹ yii iyẹn ti yipada. Iwe naa 1991 Yearbook of Jehovah’s Witnesses rohin pe nigba ti ó fi maa di opin ọdun iṣẹ-isin 1990, Ireland ti gbadun gongo 29 tẹleratẹlera! Boya ipinlẹ rẹ yoo mesojade bakan naa ni ọjọ kan. Niwọn ìgbà ti Jehofa bá ti yọnda, maa ba ẹja pípa lọ!
20. Nigba wo ni a nilati lọwọ ninu pípẹja eniyan?
20 Ni Israeli, awọn ọkunrin apẹja ń lọ pẹja ni òru, nigba ti ara olukuluku eniyan ń móorú ti ara sì tù wọn lori ibusun. Wọn jade lọ, kì í ṣe nigba ti ó rọrun fun wọn, ṣugbọn nigba ti wọn lè ri ọpọ julọ ẹja mú. Awa pẹlu gbọdọ mọ ipinlẹ wa daradara ki a baa lè lọ pẹja, gẹgẹ bi a ti ṣe lè sọ ọ́, nigba ti ọpọ julọ awọn eniyan wà ni ile ti wọn sì fẹ́ gbọ́. Eyi lè jẹ́ ni awọn ìrọ̀lẹ́, tabi ipari ọ̀sẹ̀, tabi ni akoko miiran. Nigbakigba ti ó lè jẹ, ẹ jẹ ki a ṣe ohun gbogbo ti a lè ṣe lati wá awọn eniyan ọlọkan rere rí.
21. Ki ni a nilati ranti bi a bá ń ṣe ipinlẹ wa lemọlemọ?
21 Ki ni bi a bá ń kárí ipinlẹ wa lemọlemọ? Awọn ọkunrin ti ń fi ẹja pípa ṣe iṣẹ ninu ayé sábà maa ń ráhùn pe wọn ti ń pẹja jù ni odò ẹja wọn. Ṣugbọn ǹjẹ́ a ha lè pẹja jù ni òdò ẹja tẹmi wa bi? Bẹẹkọ niti gidi! Ọpọlọpọ awọn ipinlẹ ń mú ibisi jade ani nigba ti a bá ń kárí rẹ̀ lemọlemọ paapaa. Awọn kan meso jade lọna didara ju nitori ti a ń ṣe wọn daradara. Bi o tilẹ rí bẹẹ, nigba ti o bá ń ṣe ibẹwo si awọn ile niye ìgbà, rí i daju lọna hán-ún-hán-ún pe gbogbo awọn kò-sí-nílé ni o ṣakọsilẹ ti o sì kàn lara lẹhin naa. Mọ oniruuru awọn akori-ọrọ fun ibanisọrọpọ. Pa á mọ́ sọkan pe ẹnikan yoo ṣebẹwo lẹẹkan sii laipẹ, nitori naa maṣe duro pẹ́ jù tabi di ọ̀tá onile naa láìmọ̀. Sì mú ìjáfáfá rẹ ninu iṣẹ opopona ati ijẹrii aijẹ-bi-aṣa dagba bakan naa. Ju àwọ̀n tẹmi rẹ sódò ni gbogbo akoko ati ni gbogbo ọ̀nà ti ó ṣeeṣe.
22. Anfaani ńláǹlà wo ni a ń gbadun ni akoko yii?
22 Ranti pe, ninu ẹja pípa yii ati awọn apẹja ati ẹja ń janfaani. Bi awọn wọnni ti a rí mú bá foriti i, wọn lè walaaye titilae. Paulu fun Timoteu niṣiiri pe: “Duro laiyẹsẹ ninu nǹkan wọnyi: nitori ni ṣiṣe eyi, iwọ yoo gba araarẹ ati awọn ti ń gbọ́ ọrọ rẹ là.” (1 Timoteu 4:16) Jesu ni ó kọ́kọ́ dá awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẹkọọ ẹja pípa tẹmi, iṣẹ yii ni a sì ń ṣe sibẹ labẹ idari rẹ̀. (Fiwe Ifihan 14:14-16.) Anfaani ńláǹlà wo ni a ní lati ṣiṣẹ labẹ rẹ̀ ní mimu un ṣẹ! Ẹ jẹ ki a maa ju àwọ̀n wa sódò niwọn ìgbà ti Jehofa bá ti yọnda. Iṣẹ titobi wo ni ó ṣeeṣe pe ki ó wà ju mímú awọn ọkàn lóòyẹ̀ lọ?
Iwọ Ha Lè Sọyeranti Bi?
◻ Iṣẹ wo ni Jesu dá awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ lati ṣe?
◻ Bawo ni Jesu ṣe fihan pe iṣẹ ẹja pípa tẹmi kò dopin nipasẹ iku rẹ̀?
◻ Ni ọ̀nà wo ni Jehofa gbà bukun iṣẹ ẹja pípa tẹmi ni ọrundun kìn-ín-ní?
◻ Ikore jìngbìnnì ti ẹja wo ni a ti fi àwọ̀n kó ni “ọjọ Oluwa”?
◻ Bawo ni awa gẹgẹ bi ẹnikọọkan ṣe lè tubọ jẹ́ apẹja eniyan alaṣeyọrisirere?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Lẹhin ajinde Kristi, awọn aposteli rẹ̀ mú iṣẹ atọrunwa ti pípẹja eniyan naa gbooro