Sísá Àsálà Lọ Sí Ibi Ààbò Kí “Ìpọ́njú Ńlá” Tó Dé
“Nígbà tí ẹ bá rí tí awọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerusalemu ká, . . . kí awọn wọnnì tí ń bẹ ní Judea bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí awọn òkè-ńlá.”—LUKU 21:20, 21.
1. Èé ṣe tí sísá àsálà fi jẹ́ kánjúkánjú fún àwọn tí wọ́n ṣì jẹ́ apá kan ayé síbẹ̀?
SÍSÁ àsálà jẹ́ kánjúkánjú fún gbogbo ènìyàn tí ó ṣì jẹ́ apá kan ayé Satani. Bí a óò bá dá wọn sí nígbà tí a bá nu ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí nù kúrò lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n gbọ́dọ̀ fi ẹ̀rí tí ó dáni lójú hàn pé wọ́n ti mú ìdúró wọn gbọn-ingbọn-in ní ìhà ọ̀dọ̀ Jehofa, àti pé wọn kì í ṣe apá kan ayé tí Satani jẹ́ alákòóso rẹ̀ mọ́.—Jakọbu 4:4; 1 Johannu 2:17.
2, 3. Àwọn ìbéèrè wo ní a óò jíròrò ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Jesu tí a kọ sílẹ̀ nínú Matteu 24:15-22?
2 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pípabambarì nípa ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan, Jesu tẹnu mọ́ bí irú sísá àsálà bẹ́ẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó. A sábà máa ń jíròrò ohun tí a kọ sílẹ̀ ní Matteu 24:4-14; síbẹ̀, ohun tí ó tẹ̀ lé e ṣe pàtàkì lọ́nà kan náà. A rọ̀ ọ́ láti ṣí Bibeli rẹ nísinsìnyí, kí o sì ka ẹsẹ 15 sí 22.
3 Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn túmọ̀ sí? Ní ọ̀rúndún kìíní, kí ni “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro”? Kí ni dídúró rẹ̀ ní “ibi mímọ́” dúró fún? Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ti ṣe pàtàkì fún wa tó?
“Kí Òǹkàwé Lo Ìfòyemọ̀”
4. (a) Kí ni Danieli 9:27 sọ pé yóò tẹ̀ lé kíkọ̀ tí àwọn Júù kọ Messia náà? (b) Nígbà tí ó ń tọ́ka sí èyí, ìdí tí ó ṣe kedere wo ni Jesu fi sọ pé, “Kí òǹkàwé lo ìfòyemọ̀”?
4 Ṣàkíyèsí pé nínú Matteu 24:15, Jesu tọ́ka sí ohun tí a kọ sílẹ̀ nínú ìwé Danieli. Orí 9 nínú ìwé yẹn sọ àsọtẹ́lẹ̀ dídé Messia àti ìdájọ́ tí yóò wá sórí orílẹ̀-èdè Júù fún kíkọ̀ ọ́. Apá ìparí ẹsẹ 27 (NW) sọ pé: “Ẹni tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro yóò sì wà lórí ìyẹ́ apá àwọn ohun ìríra.” Àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ìjímìjí ti àwọn Júù lo apá yẹn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Danieli fún sísọ tí Antiochus Kẹrin sọ tẹ́ḿpìlì Jehofa ní Jerusalemu di aláìmọ́ ní ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n Jesu kìlọ̀ pé: “Kí òǹkàwé lo ìfòyemọ̀.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé sísọ tí Antiochus Kẹrin sọ tẹ́ḿpìlì di aláìmọ́ jẹ́ ohun ìríra, kò yọrí sí ìsọdahoro—Jerusalemu, tẹ́ḿpìlì, tàbí orílẹ̀-èdè àwọn Júù. Nítorí náà, ó hàn gbangba pé Jesu ń kìlọ̀ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé, ìmúṣẹ èyí kì í ṣe ohun tí ó ti kọjá, ṣùgbọ́n ó ṣì wà ní ọjọ́ iwájú.
5. (a) Báwo ni ìfiwéra àwọn àkọsílẹ̀ Ìròyìn Rere ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti mọ “ohun ìríra” ní ọ̀rúndún kìíní? (b) Èé ṣe tí Cestius Gallus fi rán ẹgbẹ́ ológun lọ sí Jerusalemu lójijì ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa?
5 Kí ni “ohun ìríra” náà tí wọ́n ní láti máa ṣọ́ lójú méjèèjì? Ó yẹ fún àfiyèsí pé àkọsílẹ̀ Matteu sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá tajúkán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́.” Ṣùgbọ́n, àkọsílẹ̀ tí ó bá a dọ́gba ní Luku 21:20 kà pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí awọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerusalemu ká, nígbà naa ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti súnmọ́lé.” Ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa, àwọn Kristian tí ń gbé ní Jerusalemu rí ohun tí Jesu ti sọ tẹ́lẹ̀. Ọ̀wọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìforígbárí láàárín àwọn Júù àti àwọn onípò àṣẹ Romu yọrí sí dídì tí Jerusalemu di ibi tí ìṣọ̀tẹ̀ sí Romu ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. Ní ìyọrísí rẹ̀, ìwà ipá bẹ́ sílẹ̀ jákèjádò Judea, Samaria, Galili, Dekapoli, àti Foniṣia, láti àríwá dé Siria àti láti gúúsù dé Egipti. Kí àlàáfíà díẹ̀ lè padà wà ní apá ìhà yẹn nínú Ilẹ̀ Ọba Romu, Cestius Gallus rán ẹgbẹ́ ológun láti Siria lọ sí Jerusalemu lójijì, ibi tí àwọn Júù pè ní “ìlú mímọ́” wọn.—Nehemiah 11:1; Isaiah 52:1.
6. Báwo ni ó ṣe jẹ́ òtítọ́ pé “ohun ìríra” tí ó lè ṣokùnfà ìsọdahoro ń “dúró ní ibi mímọ́”?
6 Ó jẹ́ àṣà àwọn ọmọ ogun Romu láti gbé ọ̀págun, tàbí àsíá, èyí tí wọ́n kà sí ohun mímọ́, ṣùgbọ́n tí àwọn Júù wò gẹ́gẹ́ bí ìbọ̀rìṣà. Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀rọ̀ èdè Heberu náà tí a túmọ̀ sí “ohun ìríra” nínú ìwé Danieli ni a lò ní pàtàkì fún àwọn òrìṣà àti ìbọ̀rìṣà.a (Deuteronomi 29:17) Láìka ìgbéjàkò láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù sí, àwọn ẹgbẹ́ ológun Romu tí wọ́n gbé àsíá olórìṣà wọn lọ́wọ́, wọ Jerusalemu ní November ọdún 66 Sànmánì Tiwa, lẹ́yìn náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wa yàrà yí ògiri tẹ́ḿpìlì náà ká ní ìhà àríwá. Kò sí iyè méjì nípa rẹ̀—“ohun ìríra” tí ó lè fa ìsọdahoro pátápátá fún Jerusalemu ń “dúró ní ibi mímọ́”! Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè sá àsálà?
Sísá Àsálà Jẹ́ Kánjúkánjú!
7. Kí ni àwọn ọmọ ogun Romu ṣe lójijì?
7 Lójijì, láìsí ìdí kan pàtó ní ti ojú ìwòye ẹ̀dá ènìyàn, nígbà tí ó dà bí ẹni pé a lè fi tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn ṣẹ́gun Jerusalemu, àwọn ọmọ ogun Romu fà sẹ́yìn. Àwọn Júù ajàjàgbara lépa ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Romu tí wọ́n sá sẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọn ò kọjá Antipatri, nǹkan bí 50 kìlómítà láti Jerusalemu. Lẹ́yìn náà, wọ́n padà. Bí wọ́n ti padà dé sí Jerusalemu, wọ́n kóra jọ sínú tẹ́ḿpìlì láti wéwèé àwọn ọ̀nà ìgbàgbógun wọn. A kọ́ àwọn ọ̀dọ́ ní iṣẹ́ ológun láti fún ààbò lágbára sí i, kí wọ́n sì lè ṣe iṣẹ́ ológun. Àwọn Kristian yóò ha kó wọnú èyí bí? Bí wọ́n bá tilẹ̀ yẹra fún un, wọn yóò ha ṣì wà ní agbègbè eléwu nígbà tí àwọn ọmọ ogun Romu bá padà bí?
8. Ìgbésẹ̀ kánjúkánjú wo ni àwọn Kristian gbé ní ṣíṣe ìgbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Jesu?
8 Àwọn Kristian ní Jerusalemu àti ní gbogbo Judea gbé ìgbésẹ̀ kíákíá lórí ìkìlọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ tí Jesu Kristi fi fún wọn, wọ́n sì sá kúrò ní agbègbè eléwu náà. Sísá àsálà jẹ́ kánjúkánjú! Láàárín àkókò yẹn, wọ́n sá lọ sí àwọn ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, tí ó ṣeé ṣe kí àwọn díẹ̀ tẹ̀ dó sí Pella, ní agbègbè ìpínlẹ̀ Perea. Àwọn tí wọ́n ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ Jesu kò fi ìwà òmùgọ̀ padà wá láti gbìyànjú láti dáàbò bo àwọn ohun ìní wọn. (Fi wé Luku 14:33.) Ní fífi ibẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò wọ̀nyẹn, àwọn aboyún àti àwọn ìyá ọlọ́mọ rí i dájúdájú pé, ó jẹ́ ìrìn àjò tí ó nira láti fẹsẹ̀ rìn. Ìkálọ́wọ́kò ọjọ́ Sábáàtì kò ṣèdènà fún sísá àsálà wọn, bí ìgbà òtútù sì tilẹ̀ ti sún mọ́lé, kò tí ì dé síbẹ̀. Àwọn tí wọ́n kọbi ara sí ìkìlọ̀ Jesu láti sá ní kánmọ́kánmọ́, láìpẹ́ láìjìnnà wà láìléwu ní ẹ̀yìn òde Jerusalemu àti Judea. Ìwàláàyè wọn sinmi lórí èyí.—Fi wé Jakọbu 3:17.
9. Báwo ni ó ti yá tó tí àwọn ẹgbẹ́ ológun Romu fi padà wá, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀?
9 Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e gan-an, ní ọdún 67 Sànmánì Tiwa, àwọn ará Romu tún bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ológun wọn lòdì sí àwọn Júù lákọ̀tun. Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n ṣẹ́pá Galili. Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e wọ́n pa Judea run. Ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, àwọn ẹgbẹ́ ológun Romu yí Jerusalemu gan-an ká. (Luku 19:43) Ìyàn mú lọ́nà tí ó lékenkà. Àwọn tí a há mọ́ ìlú kọjú ìjà sí ara wọn ní ẹnì kíní kejì. Ẹnì yòówù tí ó gbìdánwò láti sá lọ ni a pa. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn jẹ́, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọ, “ìpọ́njú ńlá.”—Matteu 24:21.
10. Bí a bá kàwé pẹ̀lú ìwòyemọ̀, kí ni nǹkan mìíràn tí a óò kíyè sí?
10 Ìyẹn ha mú ohun tí Jesu sọ tẹ́lẹ̀ ṣẹ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ bí? Rárá, ohun púpọ̀ sí i yóò tún ṣẹlẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Jesu ti gbaninímọ̀ràn, bí a bá ń ka Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú ìfòyemọ̀, a kì yóò kùnà láti kíyè sí ohun tí ó ṣì wà níwájú. A ó sì tún ronú gidigidi lórí bí ó ṣe kan ìgbésí ayé wa.
“Ohun Ìríra” Lóde Òní
11. Nínú ibi méjì míràn wo ni Danieli ti tọ́ka sí “ohun ìríra” náà, sáà àkókò wo ni a sì jíròrò níbẹ̀?
11 Kíyè sí i pé, ní àfikún sí ohun tí a ti rí nínú Danieli 9:27, àwọn ìtọ́ka sí “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro” tún wà síwájú sí i ní Danieli 11:31 àti 12:11. Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn àpẹẹrẹ tí ó kẹ́yìn wọ̀nyí tí a ti jíròrò nípa ìparun Jerusalemu. Ní tòótọ́, ohun tí a sọ nínú Danieli 12:11 fara hàn, kìkì ní ẹsẹ méjì lẹ́yìn títọ́ka sí “ìgbà ìkẹyìn.” (Danieli 12:9) A tí ń gbé ní irú àkókò bẹ́ẹ̀ láti 1914. Nítorí náà, a ní láti wà lójúfò láti dá “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro” lóde òní mọ̀, kí a sì rí i dájú pé, a kúrò ní agbègbè eléwu.
12, 13. Èé ṣe tí ó fi bá a mu wẹ́kú láti ṣàpèjúwe Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gẹ́gẹ́ bí “ohun ìríra” lóde òní?
12 Kí ni “ohun ìríra” yẹn lóde òní? Ẹ̀rí tọ́ka sí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní 1920, kété lẹ́yìn tí ayé wọnú àkókò òpin rẹ̀. Ṣùgbọ́n báwo ni ìyẹn ṣe lè jẹ́ “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro”?
13 Rántí pé, ọ̀rọ̀ Heberu fún “ohun ìríra” ni a lò nínú Bibeli, ní pàtàkì, ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn òrìṣà àti àwọn àṣà olórìṣà. A ha sọ Ìmùlẹ̀ náà di òrìṣà bí? Bẹ́ẹ̀ ni, a sọ ọ́ dà á! Àwùjọ àlùfáà gbé e sí “ibi mímọ́,” àwọn ọmọlẹ́yìn wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i fún un ní ìfọkànsìn onígbòónára. Ìgbìmọ̀ Àpapọ̀ Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Kristi ní America polongo pé, Ìmùlẹ̀ náà yóò jẹ́ “fífi Ìjọba Ọlọrun hàn lọ́nà òṣèlú lórí ilẹ̀ ayé.” Òjò lẹ́tà rọ̀ sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà ti United States láti ọ̀dọ̀ àwùjọ onísìn, tí ń gbà á níyànjú láti fọwọ́ sí Ẹ̀jẹ́ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn onísìn Baptist, àwọn onísìn Congregational, àti ti àwọn onísìn Presbyterian ní Britain kókìkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “irin iṣẹ́ kan ṣoṣo tí ó wà fún níní [àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé].”—Wo Ìṣípayá 13:14, 15.
14, 15. Ní ọ̀nà wo ni Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti lẹ́yìn náà Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, fi wà “ní ibi mímọ́”?
14 Ìjọba Messia Ọlọrun ni a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọ̀run ní 1914, ṣùgbọ́n àwọn orílẹ̀-èdè tẹ̀ síwájú láti jà fún ipò ìdádúró lómìnira tiwọn. (Orin Dafidi 2:1-6) Nígbà tí a dábàá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jà tán nínú Ogun Àgbáyé Kìíní, títí kan àwùjọ àlùfáà tí ó súre fún ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun wọn, ti fi hàn pé wọ́n ti kọ òfin Ọlọrun sílẹ̀. Wọn kò wo Kristi gẹ́gẹ́ bí Ọba. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n gbé ipa ti Ìjọba Ọlọrun fún ètò àjọ ẹ̀dá ènìyàn; wọ́n gbé Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sí “ibi mímọ́,” ibi tí kò tọ́ sí i.
15 Gẹ́gẹ́ bí agbapò lọ́wọ́ Ìmùlẹ̀ náà, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè wá sí ojútáyé ní October 24, 1945. Nígbà tí ó yá, àwọn póòpù Romu kókìkí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gẹ́gẹ́ bí “ìrètí ìkẹyìn fún ìṣọ̀kan àti àlàáfíà” àti “ojúkò gíga jù lọ fún àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo.” Bẹ́ẹ̀ ni, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, pẹ̀lú agbapò rẹ̀, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, di òrìṣà ní tòótọ́, “ohun ìríra” ní ojú Ọlọrun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.
Sá Kúrò Nínú Kí Ni?
16. Nínú kí ni àwọn olùfẹ́ òdodo ti gbọ́dọ̀ sá kúrò lónìí?
16 Ní ‘títajú kán rí’ èyí, ní mímọ ohun tí ètò àjọ àgbáyé yẹn jẹ́ àti bí a ṣe ń sọ ọ́ di òrìṣà, àwọn olùfẹ́ òdodo ní láti sá àsálà. Sá àsálà kúrò nínú kí ni? Kúrò nínú ohun tí ó jẹ́ amápẹẹrẹṣẹ ti òde òní fún Jerusalemu aláìṣòótọ́, ìyẹn ni, Kirisẹ́ńdọ̀mù, àti kúrò nínú gbogbo Babiloni Ńlá, ètò ìsìn èké àgbáyé.—Ìṣípayá 18:4.
17, 18. Ìsọdahoro wo ni “ohun ìríra” lóde òní yóò ṣokùnfà?
17 Rántí, pẹ̀lú, pé, ní ọ̀rúndún kìíní, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Romu pẹ̀lú ọ̀págun olórìṣà wọn, wọ inú ìlú mímọ́ àwọn Júù, wọ́n wá síbẹ̀ láti sọ Jerusalemu àti ètò ìjọsìn rẹ̀ dahoro. Ní ọjọ́ wa, ìsọdahoro náà yóò dé, kò ní jẹ́ sórí kìkì ìlú kan ṣoṣo, tàbí sórí Kirisẹ́ńdọ̀mù nìkan, ṣùgbọ́n sórí gbogbo ètò ìsìn èké àgbáyé.—Ìṣípayá 18:5-8.
18 Nínú Ìṣípayá 17:16, a sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ aláwọ̀ rírẹ̀ dòdò kan, tí ẹ̀rí fi hàn pé ó jẹ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, yóò yíjú padà sí Babiloni Ńlá oníwà bí aṣẹ́wó, yóò sì pa á rún lọ́nà tí ó lágbára. Ní lílo èdè àpèjúwe kedere, ó wí pé: “Ìwo mẹ́wàá tí iwọ sì rí, ati ẹranko ẹhànnà naa, awọn wọnyi yoo kórìíra aṣẹ́wó naa wọn yoo sì sọ ọ́ di ìparundahoro ati ìhòòhò, wọn yoo sì jẹ awọn ibi kìkìdá ẹran-ara rẹ̀ tán wọn yoo sì fi iná sun ún pátápátá.” Láti fọkàn ro ohun tí èyí yóò túmọ̀ sí jẹ́ ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀. Yóò yọrí sí òpin onírúurú ìsìn èké ní gbogbo apá ilẹ̀ ayé. Èyí ní ti gidi yóò fi hàn pé ìpọ́njú ńlá náà ti bẹ̀rẹ̀.
19. Àwọn ẹgbẹ́ wo ni ó ti jẹ́ apa kan Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti ìgbà tí a ti dá a sílẹ̀, èé ṣe tí èyí sì fi gba àfiyèsí?
19 Ó yẹ fún àfiyèsí pé, láti ìgbà tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní 1945, mẹ́ḿbà àwọn ẹgbẹ́ aláìnígbàgbọ́ nínú Ọlọrun, tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá ìsìn, ti ń pọ̀ sí i. Ní onírúurú àkókò, kárí ayé, irú àwọn ẹgbẹ́ ayípìlẹ̀padà bẹ́ẹ̀ ti ṣiṣẹ́ fún mímú kí a dín àwọn àṣà ìsìn kù gidigidi tàbí kí a fi òfin dè é pátápátá. Ṣùgbọ́n, ní àwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn, agbára tí ìjọba ń ní lórí àwọn àwùjọ ìsìn ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ti dín kù. Lójú àwọn kan, ó lè dá bí ẹni pé kò sí ewu èyíkéyìí mọ́ fún ìsìn.
20. Irú orúkọ wo ni àwọn ìsìn ayé ti ṣe fún ara wọn?
20 Àwọn ìsìn Babiloni Ńlá ń bá a nìṣó láti jẹ́ ipa tí ń fi jàgídíjàgan fa ìdàrúdàpọ̀ nínú ayé. Àwọn àkọlé ìròyìn sábà máa ń fi àwọn ẹgbẹ́ tí ń jagun àti àwùjọ akópayàbáni hàn nípa dídárúkọ ìsìn tí wọ́n ń ṣe. Àwọn ọlọ́pàá tí ń pẹ̀tù sí rúgúdù àti sójà ní láti ya wọnú àwọn tẹ́ḿpìlì láti dá ìwà ipá dúró láàárín àwọn ẹ̀ya ìsìn tí wọ́n ń bá ara wọn ṣe orogún. Àwọn ẹgbẹ́ ìsìn ti ṣe onígbọ̀wọ́ yíyí ètò òṣèlú padà pátápátá. Ìkórìíra tí ìsìn ṣokùnfà ti mú ìjákulẹ̀ bá ìsapá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti pa ipò ìbátan oníṣọ̀kan mọ́ láàárín àwọn ẹ̀yà ìbílẹ̀. Ní lílépa góńgó àlàáfíà àti ààbò, àwọn ẹgbẹ́ tí ó wà nínú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè yóò fẹ́ láti rí i pé, a mú agbára ìdarí àwọn ìsìn èyíkéyìí tí ó bá dábùú ọ̀nà wọn kúrò.
21. (a) Ta ni yóò pinnu ìgbà tí a óò pa Babiloni Ńlá run? (b) Kí ni ó jẹ́ kánjúkánjú láti ṣe ṣáájú ìgbà náà?
21 Kókó pàtàkì míràn tún wà láti gbé yẹ̀ wò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìwo ológun láti inú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni a óò lò láti pa Babiloni Ńlá run, ìparun yẹn yóò jẹ́ fífi ìdájọ́ Ọlọrun hàn ní ti gidi. Ìmúdàájọ́ṣẹ yóò wáyé ní àkókò tí Ọlọrun ti yàn. (Ìṣípayá 17:17) Kí ni a ní láti ṣe ní báyìí ná? Ìdáhùn Bibeli ni pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀”—ẹ jáde kúrò nínú Babiloni Ńlá.—Ìṣípayá 18:4.
22, 23. Kí ni irú sísá àsálà bẹ́ẹ̀ ní nínú?
22 Sísá àsálà yìí kì í ṣe ṣíṣí kúrò ní ibì kan sí òmíràn, bí irú èyí tí àwọn Kristian tí wọ́n jẹ́ Júù ṣe nígbà tí wọ́n fi Jerusalemu sílẹ̀. Ó jẹ́ sísá jáde kúrò nínú àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù, bẹ́ẹ̀ ni, kúrò nínú apá èyíkéyìí lára Babiloni Ńlá. Ó túmọ̀ sí yíya ara ẹni sọ́tọ̀ pátápátá, kì í ṣe kúrò nínú àwọn ètò àjọ ìsìn èké nìkan ni, ṣùgbọ́n kúrò nínú àwọn àṣà wọn àti ẹ̀mí tí wọ́n ń gbé jáde pẹ̀lú. Ó jẹ́ sísá àsálà lọ sí ibi ààbò láàárín ètò àjọ ìṣàkóso Jehofa.—Efesu 5:7-11.
23 Nígbà tí àwọn ẹni-àmì-òróró ìránṣẹ́ Jehofa kọ́kọ́ dá ohun ìríra lóde òní, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, mọ̀ yàtọ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, kí ni àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe? Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n ti já àjọṣe wọn pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ṣùgbọ́n kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n wá mọ̀ pé, wọ́n ṣì ń rọ̀ mọ́ àwọn àṣà àti ìṣe kan tí ó jẹ́ ti Kirisẹ́ńdọ̀mù, bíi lílo àgbélébùú àti ṣíṣe ayẹyẹ Kérésìmesì àti àwọn họlidé kèfèrí mìíràn. Nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí, wọ́n gbé ìgbésẹ̀ ní kánmọ́. Wọ́n fi ìmọ̀ràn tí ó wà ní Isaiah 52:11 sọ́kàn pé: “Ẹ fà sẹ́yìn, ẹ fà sẹ́yìn, ẹ jáde kúrò láàárín rẹ̀; ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan: ẹ kúrò láàárín rẹ̀, ẹ jẹ́ mímọ́, ẹ̀yin tí ń gbé ohun èlò Oluwa.”
24. Ní pàtàkì láti 1935, àwọn wo ni ó ti dara pọ̀ nínú sísá àsálà náà?
24 Ní pàtàkì láti 1935 wá, ogunlọ́gọ̀ àwọn mìíràn tí ń pọ̀ sí i, àwọn ènìyàn tí ó tẹ́wọ́ gba ìfojúsọ́nà fún wíwà láàyè títí láé lórí paradise ilẹ̀ ayé kan, bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀ kan náà. Àwọn pẹ̀lú ti ‘tajú kán rí ohun ìríra tí ó dúró ní ibi mímọ́,’ wọ́n sì mọ ohun tí ó túmọ̀ sí. Lẹ́yìn ṣíṣe ìpinnu wọn láti sá àsálà, wọ́n mú kí a yọ orúkọ wọn kúrò nínú mẹ́ḿbà àwọn ètò àjọ tí ó jẹ́ apá kan Babiloni Ńlá.—2 Korinti 6:14-17.
25. Kí ni a béèrè ní àfikún sí jíjá gbogbo àjọṣe èyíkéyìí tí ẹnì kan lè ní pẹ̀lú ìsìn èké?
25 Ṣùgbọ́n, sísá kúrò nínú Babiloni Ńlá ní nínú ju kíkọ ìsìn èké sílẹ̀ lọ. Ó ní nínú ju lílọ sí àwọn ìpàdé mélòó kan nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí jíjáde fún iṣẹ́ ìsìn pápá lẹ́ẹ̀kan tàbí lẹ́ẹ̀mejì lóṣù lọ. Ẹnì kán lè wà lẹ́yìn òde Babiloni Ńlá ní ti gidi, ṣùgbọ́n òún ha ti yọwọ́yọsẹ̀ ní tòótọ́ bí? Òún ha ti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé tí Babiloni Ńlá jẹ́ apá pàtàkì rẹ̀ bí? Òún ha ṣì rọ̀ mọ́ àwọn ohun tí ń fi ẹ̀mí rẹ̀ hàn—ẹ̀mí tí kò ka ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Ọlọrun sí? Òún ha ń fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mu ìwà mímọ́ takọtabo àti ìṣòtítọ́ nínú ìgbéyàwó? Òún ha ń tẹnu mọ́ àwọn ire ti ara ẹni àti ti àlùmọ́nì ju àwọn ire tẹ̀mí? Kò gbọdọ̀ gba ara rẹ̀ láyè láti máa dáṣà ní àfarawé ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí.—Matteu 6:24; 1 Peteru 4:3, 4.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Dènà Sísá Àsálà Rẹ!
26. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe wulẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sísá àsálà ṣùgbọ́n láti parí rẹ̀ pẹ̀lú àṣeyọrí?
26 Nínú sísá àsálà wa lọ sí ibi ààbò, ó ṣe pàtàkì pé, kí a má ṣe yán hànhàn fún àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn. (Luku 9:62) A ní láti pa èrò inú àti ọkàn-àyà wa pọ̀ pátápátá sórí Ìjọba Ọlọrun àti òdodo rẹ̀. Àwá ha ti pinnu láti fi ìgbàgbọ́ wa hàn nípa wíwá ìwọ̀nyí lákọ̀ọ́kọ́, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pé Jehofa yóò bù kún irú ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ bí? (Matteu 6:31-33) Ìdánilójú wa tí a ní, tí a gbé ka orí Ìwé Mímọ́, yẹ kí ó ru wá sókè láti dé orí góńgó yẹn, bí a ti ń fi ìháragàgà dúró de ìṣípayá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì lórí ayé.
27. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti ronú gidigidi nípa àwọn ìbéèrè tí a béèrè níhìn-ín?
27 Ìmúṣẹ ìdájọ́ àtọ̀runwá yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú pípa Babiloni Ńlá run. A óò pa ilẹ̀ ọba ìsìn èké oníwà aṣẹ́wó yẹn run títí láé. Àkókò yẹn ti sún mọ́lé pẹ́kípẹ́kí! Kí ni yóò jẹ ìdúró wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nígbà tí àkókò pàtàkì yẹn yóò dé? Àti ní òtéńté ìpọ́njú ńlá náà, nígbà tí a óò pa ìyókù ayé Satani run, ìhà wo ni a óò ti rí wa? Bí a bá gbé ìgbésẹ̀ tí ó yẹ nísinsìnyí, ààbò wa dájú. Jehofa sọ fún wa pé: “Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá fetí sí mi yóò máa gbé láìléwu.” (Owe 1:33) Nípa bíbá a nìṣó láti máa ṣiṣẹ́ sin Jehofa pẹ̀lú ìdúróṣinṣin àti ìdùnnú-ayọ̀ nígbà ìparí ètò ìgbékalẹ̀ yìí, a lè tóótun láti ṣiṣẹ́ sin Jehofa títí láé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Insight on the Scriptures, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 634 sí 635.
Ìwọ́ Ha Rántí Bí?
◻ Kí ni “ohun ìríra” lóde òní?
◻ Ní èrò ìtumọ̀ wo ni ‘ohun ìríra fi wà ní ibi mímọ́’?
◻ Kí ni sísá àsálà ní nínú nísinsìnyí?
◻ Èé ṣe ti irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ fi jẹ́ kánjúkánjú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Láti là á já, àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu gbọ́dọ̀ sá àsálà láìjáfara