Jehofa Wà Pẹ̀lú Mi
GẸ́GẸ́ BÍ MAX HENNING TI SỌ
Ó jẹ́ ní 1933, Adolf Hitler sì ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí àlééfà ní Germany ni. Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan bíi 500 àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó wà ní agbègbè Berlin kò mikàn. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ènìyàn di aṣáájú ọ̀nà, tàbí àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, àwọn kan pàápàá sì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àyànfúnni láti lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè Europe mìíràn. Èmi àti ọ̀rẹ́ mi, Werner Flatten, máa ń bi ara wa pé: “Èé ṣe tí a fi ń lọ́ tìkọ̀, tí a ń fi àkókò wa ṣòfò? Èé ṣe tí a kò fi jáde, kí a sì ṣe aṣáájú ọ̀nà?”
ỌJỌ́ mẹ́jọ lẹ́yìn tí a bí mi ní 1909, a gbé mi fún àwọn òbí alágbàtọ́ onífẹ̀ẹ́. Ní 1918, ìbànújẹ́ dorí ìdílé wa kodò nígbà tí arábìnrin mi kékeré, ọmọ alágbàtọ́ mi kú lójijì. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, bí a ti ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nígbà náà, ṣe ìbẹ̀wò sí ẹnu ọ̀nà wa, àwọn òbí alágbàtọ́ mi sì fi ìháragàgà tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bibeli. Wọ́n kọ́ mi láti mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí pẹ̀lú.
Mo fara jìn fún ilé ẹ̀kọ́ ti ayé, mo sì di oníṣẹ́ ẹ̀rọ omi. Ṣùgbọ́n ní pàtàkì jù lọ, mo mú ìdúró mi nípa tẹ̀mí. Èmi àti Werner bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú ọ̀nà ní May 5, 1933. A máa ń gun kẹ̀kẹ́ lọ sí ìlú kan tí ó jẹ́ nǹkan bí 100 kìlómítà jìnnà sí Berlin, níbi tí a máa ń dúró sí, tí a sì máa ń wàásù fún ọ̀sẹ̀ méjì. Lẹ́yìn náà, a óò padà sí Berlin láti bójú tó àwọn ọ̀ràn tí ó pọn dandan. Lẹ́yìn ìyẹn, a óò padà lọ sí agbègbè ìpínlẹ̀ ìwàásù wa fún ọ̀sẹ̀ méjì míràn.
A béèrè fún ṣíṣiṣẹ́ sìn ní orílẹ̀-èdè míràn, a sì gba iṣẹ́ àyànfúnni láti lọ sí ibi tí a ń pè ní Yugoslavia nígbà yẹn, ní December 1933. Ṣùgbọ́n, kí á tó gbéra, iṣẹ́ àyànfúnni wa ní a yí padà sí Utrecht ní Netherlands. Láìpẹ́ lẹ́yìn yẹn, mo ṣe batisí. Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn, a kò ka batisí sí pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ; iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni a kà sí pàtàkì. Gbígbára lé Jehofa wá di apá ṣíṣe déédéé nínú ìgbésí ayé mi nísinsìnyí. Mo rí ìtùnú púpọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ onípsalmu nínú Bibeli pé: “Kíyè sí i! Oluwa ni olùrànlọ́wọ́ mi; Oluwa wà [lára, NW] àwọn tí ó gbé ọkàn mi dúró.”—Orin Dafidi 54:4.
Ṣíṣe Aṣáájú Ọ̀nà ní Netherlands
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí a dé Netherlands, a tún iṣẹ́ yàn fún wa láti lọ sí ìlú Rotterdam. Bàbá àti ọmọkùnrin kan nínú ìdílé tí a bá gbélé jẹ́ aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, a ra ilé ńlá kan fún àwọn aṣáájú ọ̀nà láti máa gbé, ní Leersum, ìlú kan tí kò jìnnà sí Utrecht, èmi àti Werner sì kó lọ síbẹ̀.
Nígbà tí a ń gbé nínú ilé aṣáájú ọ̀nà yẹn, a máa ń gun kẹ̀kẹ́ ológeere lọ sí àwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n wà nítòsí, a sì ń lo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ elérò méje fún àwọn agbègbè ìpínlẹ̀ tí wọ́n jìnnà. Ní àkókò náà, kìkì ọgọ́rùn-ún Ẹlẹ́rìí ní ń bẹ ní gbogbo Netherlands. Lónìí, lẹ́yìn 60 ọdún, agbègbè ìpínlẹ̀ náà tí a ń ti ilé aṣáájú ọ̀nà yẹn lọ ṣe, ní ju 4,000 akéde lọ nínú nǹkan bí 50 ìjọ!
A ṣiṣẹ́ kára, a ń lò tó wákàtí 14 nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóòjọ́, ìyẹn sì ń mú wa láyọ̀. Olórí ète wá jẹ́ láti fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. A sábà máa ń fi èyí tí ó ju ọgọ́rùn-ún ìwé pẹlẹbẹ sílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn lóòjọ́. Ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò àti dídarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kì í ṣe ara ìgbòkègbodò déédéé wa nígbà yẹn.
Ní ọjọ́ kan, èmi àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi ń ṣiṣẹ́ ní ìlú Vreeswijk. Bí ó ti ń jẹ́rìí fún ọkùnrin kan ní ẹnubodè ọgbà àwọn ológun, mo ń lo àkókò náà láti ka Bibeli mi. Gàdàgbà gadagba ni mo fi bírò pupa àti búlúù sàmì sínú rẹ̀. Nígbà tí ó yá, káfíńtà kan tí ń ṣiṣẹ́ lórí òrùlé kan nítòsí kìlọ̀ fún ọkùnrin tí ó wà ní ẹnubodè náà pé, ó ṣeé ṣe kí n jẹ́ amí. Nítorí èyí, a fàṣẹ ọba mú mi ní ọjọ́ yẹn gan-an bí mo ti ń wàásù fún òǹtajà kan, a sì gba Bibeli mi.
A mú mi lọ sí ilé ẹjọ́. Níbẹ̀, a fẹ̀sùn kàn mí pé àwọn ìlà tí ń bẹ nínú Bibeli mi jẹ́ ìgbìyànjú láti yàwòrán ọgbà náà. A dá mi lẹ́bi, adájọ́ sì jù mí sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì. Ṣùgbọ́n, a pẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn, a sì dá mi sílẹ̀. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó pé a dá mi sílẹ̀, ṣùgbọ́n mo tún láyọ̀ sí i nígbà tí a dá Bibeli mi pẹ̀lú gbogbo àkọsílẹ̀ rẹ̀ padà!
Nígbà ẹ̀rùn 1936, èmi àti Richard Brauning, ọ̀kan nínú àwọn aṣáájú ọ̀nà tí ń gbé inú ilé náà, lo àkókò ẹ̀rùn náà ní wíwàásù ní àríwá orílẹ̀ èdè náà. Ní oṣù àkọ́kọ́, a lo 240 wákàtí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, a sì fi ọ̀pọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde. A gbé nínú àgọ́ kan, a sì bójú tó gbogbo àìní wa fúnra wa, a ń fọ aṣọ wa, a ń se oúnjẹ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Lẹ́yìn náà, a gbé mi lọ sínú ọkọ̀ ojú omi náà tí ń jẹ́ Lightbearer, èyí tí ó wá gbajúmọ̀ ní àríwá Netherlands. Àwọn aṣáájú ọ̀nà márùn-ún ní ń gbé inú ọkọ̀ ojú omi náà, ó sì ṣeé ṣe fún wa láti dé ọ̀pọ̀ agbègbè ìpínlẹ̀ tí ó wà ní àdádó nípasẹ̀ rẹ̀.
Àǹfààní Púpọ̀ Sí I
Ní 1938, a pínṣẹ́ yàn fún mi láti di ìránṣẹ́ ìpínlẹ̀ agbègbè, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn alábòójútó àyíká ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nígbà náà. Nítorí náà, mo fi Lightbearer sílẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ àwọn ìjọ àti àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ ní àdádó ní ẹkùn ìpínlẹ̀ mẹ́ta ní àríwá wò.
Kẹ̀kẹ́ ológeere nìkan ni ohun ìrìnnà wa. Ó sábà máa ń gba odidi ọjọ́ kan láti rìnrìn àjò láti ìjọ kan, tàbí láti ọ̀dọ̀ àwùjọ àwọn olùfìfẹ́hàn kan sí òmíràn. Lára àwọn ìlú tí mo bẹ̀ wò ni Breda, níbi tí mo ń gbé nísinsìnyí. Ní àkókò náà, kò sí ìjọ ní Breda, kìkì tọkọtaya àgbàlagbà Ẹlẹ́rìí kan ni ó wà níbẹ̀.
Nígbà tí mo ń bẹ àwọn arákùnrin tí ń bẹ ní Limburg wo, a ké sí mi láti dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí awakùsà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Johan Pieper béèrè. Ó mú ìdúróṣinṣin fún òtítọ́ Bibeli, ó sì di oníwàásù onígboyà. Ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà, a fàṣẹ ọba mú un, a sì fi í sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, níbi tí ó ti lo ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀. Lẹ́yìn ìdásílẹ̀ rẹ̀, ó fi tìtaratìtara nawọ́ gán iṣẹ́ ìwàásù lẹ́ẹ̀kan sí i, lónìí, ó ṣì jẹ́ alàgbà olùṣòtítọ́ síbẹ̀. Ìjọ kékeré tí ó ní àwọn Ẹlẹ́rìí 12 yẹn ní Limburg ti dàgbà di ìjọ 17 nísinsìnyí pẹ̀lú nǹkan bíi 1,550 akéde!
Lábẹ́ Ìṣàkóso Nazi
Ní May 1940, ìjọba Nazi gbógun ti Netherlands. Mo gba iṣẹ́ àyànfúnni láti lọ sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society ní Amsterdam. A ní láti máa bá iṣẹ́ wa nìṣó pẹ̀lú ìṣọ́ra gan-an, tí ó mú wa mọrírì òwe Bibeli náà pé: “Ọ̀rẹ́ [tòótọ́ . . . jẹ́ arákùnrin tí, NW] a bí fún ìgbà ìpọ́njú.” (Owe 17:17) Ìdè ìṣọ̀kan fífanimọ́ra tí ó gbèrú ní àkókò másùnmáwo yìí ṣe bẹbẹ nínú ìdàgbàsókè tẹ̀mí mi, ó sì mú mi gbara dì fún àwọn ọjọ́ tí ó túbọ̀ le koko tí ń bẹ níwájú.
Iṣẹ́ àyànfúnni mi jẹ́ láti bójú tó kíkó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ sí àwọn ìjọ, èyí tí àwọn asáréjíṣẹ́ sábà máa ń ṣe. Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ń fìgbà gbogbo wá àwọn ọ̀dọ́kùnrin láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alágbàṣe tipátipá ní Germany, nítorí náà, a lo àwọn arábìnrin Kristian gẹ́gẹ́ bí asáréjíṣẹ́. Láìpẹ́, a rán Wilhelmina Bakker, tí a mọ̀ sí Nonnie, sí wa láti The Hague, mo sì mú un lọ sí ibi tí alábòójútó ẹ̀ka wa, Arthur Winkler, sá pamọ́ sí. Kí wọ́n má baà tètè dá mi mọ̀, mo múra bí àgbẹ̀ ara Netherlands, mo wọ bàtà onígi àti àwọn ohun mìíràn tí àwọn àgbẹ̀ máa ń wọ̀, mo sì wọkọ̀ lọ pẹ̀lú Nonnie. Mo wá mọ̀ lẹ́yìn náà pé, ẹ̀rín ń pa á ṣáá ni, nítorí pé lójú rẹ̀, kò sí ohun tí ó ní kí wọ́n máà dá mi mọ̀.
Ní October 21, 1941, wọ́n táṣìírí ibi àkójọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti bébà ní Amsterdam fún àwọn ọ̀tá. Nígbà tí Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ gbé sùnmọ̀mí wọlé, wọ́n fàṣẹ ọba mu Winkler àti Nonnie. Nígbà tí a jù wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n gbọ́ tí àwọn aṣojú Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ méjì ń sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ti ń lépa “ọkùnrin kólíẹ́ onírun dúdú kan” tí ó pòórá mọ́ wọn lójú ní òpópónà tí ó kún fún èrò. Ó ṣe kedere pé, èmi ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, nítorí náà, Winkler dọ́gbọ́n fi ìròyìn ránṣẹ́ sí àwọn ará. Lọ́gán, a gbé mi lọ sí The Hague.
Níwọ̀n àkókò díẹ̀, a dá Nonnie sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, ó sì padà sí The Hague gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà. Níbẹ̀ ní mo ti tún pàdé rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí a fàṣẹ ọba mú ìránṣẹ́ ìjọ ní Rotterdam, a rán mi lọ láti gba ipò rẹ̀. Lẹ́yìn náà, a fàṣẹ ọba mú ìránṣẹ́ ìjọ ní Ìjọ Gouda, a sì gbé mi lọ síbẹ̀ láti dípò rẹ̀. Ní paríparí rẹ̀, a mú mi ní March 29, 1943. Nígbà tí mo ń ṣàyẹ̀wò ẹrù àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wa, àwọn onísùnmọ̀mí Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan bá mi lábo.
Yàtọ̀ sí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ó wà káàkiri lórí tábìlì, àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin tún wà níbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kọ wọ́n ní àmì àdìtú. Bí làásìgbò ti bá mi, mo gbàdúrà pé kí Jehofa pèsè ọ̀nà kan fún mi láti dáàbò bo àwọn tí ó ṣì wà lómìnira láti wàásù. Láìjẹ́ kí wọ́n fura, mo rọra da ọwọ́ bo àkọsílẹ̀ orúkọ náà, mo sì rún un mọ́ àtẹ́lẹwọ́ mi. Lẹ́yìn náà, mo tọrọ gáfárà láti lọ sí ilé ìtura, níbi tí mo ti ya àkọsílẹ̀ náà tí mo sì fi omi ṣàn án lọ.
Nígbà tí mo bá ti dójú ọ̀gbagadè bẹ́ẹ̀, mo kọ́ láti máa gba okun láti inú ìbálò Jehofa pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ nígbà àtijọ́ àti láti inú àwọn ìlérí rẹ̀ fún ìdáǹdè. Ìdánilójú onímìísí kan tí ó ti máa ń fìgbà gbogbo wà lọ́kàn mi nìyí pé: “Ì bá má ṣe pé Olúwa tí ó ti [wà pẹ̀lú wa nígbà tí àwọn ènìyàn dìde lòdì sí wa, NW]: nígbà náà ni wọn ì bá gbé wa mì láàyè.”—Orin Dafidi 124:2, 3.
Ọgbà Ẹ̀wọ̀n àti Ibùdó Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́
A mú mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọn Rotterdam, níbi tí mo dúpẹ́ pé Bibeli mi wà pẹ̀lú mi. Mo tún ní ìwé Salvation, apá kan lára ìwé Children, àti ọ̀pọ̀ àkókò láti ka ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí. Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà, mo ṣàìsàn gidigidi, mo sì ní láti lọ sí ilé ìwòsàn. Kí n tó kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, mo fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà pamọ́ sábẹ́ ibùsùn mi. Mo gbọ́ lẹ́yìn náà pé, a gbé Ẹlẹ́rìí mìíràn, Piet Broertjes, wá sí ibi yàrá ilé ẹ̀wọ̀n mi, ó sì rí i. Nípa báyìí, a lo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà láti fún àwọn mìíràn tí wọ́n ṣì wà nínú ìgbàgbọ́ lókun.
Nígbà tí mo kọ́fẹ padà, a gbé mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ni The Hague. Nígbà tí mo wà níbẹ̀, mo pàdé Leo C. van der Tas, akẹ́kọ̀ọ́ nípa òfin tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí kíkọ iṣẹ́ Nazi. Kò gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa rí, mo sì ni àǹfààní láti jẹ́rìí fún un. Nígbà míràn, ó máa ń jí mi láàárín òru, tí yóò sì béèrè àwọn ìbéèrè. Kò lè pa ìkansáárá rẹ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́ra, ní pàtàkì lẹ́yìn tí ó mọ̀ pé a lè dá wa sílẹ̀ bí a óò bá wulẹ̀ fọwọ́ sí ìwé kan láti sẹ́ ìgbàgbọ́ wa. Lẹ́yìn ogun, Leo di agbẹjọ́rò, ó sì jà fún Watch Tower Society lórí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀ràn òfin tí ó kan òmìnira ìjọsìn.
Ní April 29, 1944, a mú mi wọkọ̀ ojú irin fún ìrìn àjò tí ń roni lára, tí ó gba ọjọ́ 18 lọ sí Germany. Ní May 18, a fi mí sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ní Buchenwald. Ìgbésí ayé le koko láìṣeé fẹnu sọ títí di ìgbà tí àwọn ọmọ ogun Alájọṣepọ̀ dá wa nídè ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún kú lójú wa kòrókòró. Níwọ̀n bí mo ti kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ tí ó wà nítòsí, tí ń pèsè àwọn ohun èlò ogun, a yàn mí láti ṣiṣẹ́ níbi kòtò tí ń pẹ̀gbin mọ́.
Ní ọjọ́ kan, wọ́n ju àdó olóró sí ilé iṣẹ́ náà. Ọ̀pọ̀ sá jànnàjànnà lọ sí ibùdó àwọn ológun fún ààbò, nígbà tí àwọn mìíràn sì sá lọ sínú igbó. Àdó olóró tí ń fọ́nká kọlu ibùdó àwọn ológun náà, àdó olóró tí ń gbiná sì tanná ran igbó náà. Ó jẹ́ ìran tí ń bani lẹ́rù! Ọ̀pọ̀ jóná láàyè! Mo rí ibi ìsádi kan tí ó láàbò, nígbà tí iná náà sì rọlẹ̀, mo rìn kọjá lára àìlóǹkà òkú padà lọ sí ibùdó.
Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn lónìí mọ̀ nípa ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Nazi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa pé ó fún agbára ìrònú mi lókun, tí ó fi jẹ́ pé ohun ẹ̀rù tí mo nírìírí rẹ̀ kò jọba lé ìrònú mi lórí jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí. Nígbà tí mo bá ronú nípa sáà tí mo lò nínú ẹ̀wọ̀n, ìmọ̀lára mi tí ó gba iwájú jù lọ jẹ́ ayọ̀ pípa ìwà títọ́ sí Jehofa mọ́ fún ògo orúkọ rẹ̀.—Orin Dafidi 124:6-8.
Ìgbòkègbodò Ẹ̀yìn Ogun
Lẹ́yìn ìdáǹdè mi àti pípadà sí Amsterdam, mo lọ tààràtà sí ọ́fíìsì ẹ̀ka fún iṣẹ́ àyànfúnni. Mo háragàgà láti gba ìsọfúnni nípa àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ nígbà tí n kò sí nílé. Nonnie ti ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ní ọdún tí ó gbẹ̀yìn ogun, ó ti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí asáréjíṣẹ́ ní kíkó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ sí àwọn ìjọ. A kò tún fàṣẹ ọba mú un mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ọwọ́ fẹ́ tẹ̀ ẹ́.
Mo ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ìgbà díẹ̀ ní Haarlem, ṣùgbọ́n ní 1946, a sọ fún mi láti lọ sí ẹ̀ka ní Amsterdam láti ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìkówèéránṣẹ́. Ní apá ìparí 1948, èmi àti Nonnie ṣègbéyàwó, a sì fi ẹ̀ka náà sílẹ̀ láti jọ ṣe aṣáájú ọ̀nà. Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà wa jẹ́ ní Assen. Ọdún méjìlá ṣáájú, èmi àti Richard Brauning lo ìgbà ẹ̀rùn níbẹ̀, ní gbígbé inú àgọ́, tí a sì ń wàásù. Mo gbọ́ pé a ti yìnbọn pa Richard nígbà tí ó ń lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan.
Ní kedere, sáà tí mo lò nínú ẹ̀wọ̀n ti kó bá ìlera mi. Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn tí a dá mi sílẹ̀ ní Buchenwald, àìsàn gbé mi dè fún oṣù mẹ́rin. Ní àwọn ọdún lẹ́yìn náà, ní 1957, ikọ́ fée pọ́n mi lójú fún odidi ọdún kan. Okun tán nínú mi, ṣùgbọ́n ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà mi ṣì lágbára síbẹ̀. Nígbà àìsàn mi, mo lo gbogbo àǹfààní láti jẹ́rìí. Mo ronú pé ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà yìí jẹ́ kókó abájọ pàtàkì tí àìsàn mi kò fi dá mi mọ́lẹ̀ pátápátá. Èmi àti Nonnie pinnu láti máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nìṣó títí dé ibi tí ìlera wa bá ti gbà wá láyè dé.
Lẹ́yìn ìkọ́fẹpadà mi, a pínṣẹ́ yàn fún wa láti lọ sí ìlú Breda. Èyí jẹ́ ọdún 21 lẹ́yìn tí mo kọ́kọ́ bẹ ìlú yẹn wò gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ìpínlẹ̀ agbègbè. Nígbà tí a débẹ̀ ní 1959, ìjọ kékeré kan, tí ó ní Ẹlẹ́rìí 34 ni ó wà níbẹ̀. Lónìí, ní ọdún 37 lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó ti di ìjọ mẹ́fà pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó lé ní 500, tí wọ́n ń pàdé pọ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́ta! Ní àwọn ìpàdé àdúgbò àti àpéjọ wa, a rí ọ̀pọ̀ tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ òtítọ́ Bibeli nítorí ìsapá díẹ̀ tí a ṣe. A sábà máa ń nímọ̀lára gẹ́gẹ́ bíi ti aposteli Johannu nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Emi kò ní èrèdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọnyi lọ fún ìṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé awọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn ninu òtítọ́.”—3 Johannu 4.
A ti darúgbó nísinsìnyí. Mo jẹ́ ẹni ọdún 86, tí Nonnie sì jẹ́ ẹni ọdún 78, ṣùgbọ́n mo gbọ́dọ̀ sọ pé, ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà jẹ́ iṣẹ́ onílera. Láti ìgbà tí mo ti wà ní Breda, mo ti borí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ìṣòro ìlera tí mo kéèràn rẹ̀ nígbà tí mo fi wà lẹ́wọ̀n. Mo tún ti gbádùn ọ̀pọ̀ ọdún tí ń méso jáde nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa.
Wíwẹ̀yìn padà sí ọ̀pọ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn tí ń so èso jẹ́ orísun ìdùnnú fún àwa méjèèjì. Àdúrà wa ojoojúmọ́ ni pé Jehofa yóò fún wa ní ẹ̀mí àti okun láti máa bá a nìṣó nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí a bá ṣì ń mí. Pẹ̀lú ìgbọ́kànlé, a sọ èrò ọkàn wa jáde ní àwọn ọ̀rọ̀ onípsalmu náà pé: “Kíyè sí i! Oluwa ni olùrànlọ́wọ́ mi; Oluwa wà [lára, NW] àwọn tí ó gbé ọkàn mi dúró.”—Orin Dafidi 54:4.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Nígbà tí mo dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ àgọ́ tí a lò nígbà tí a ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní àwọn ọdún 1930
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọkọ̀ ojú omi tí a lò láti dé agbègbè ìpínlẹ̀ àdádó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Nígbà tí a ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ ní 1957
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Pẹ̀lú aya mi lónìí