“Sọ Fún Wa, Nígbà Wo Ni Nǹkan Wọ̀nyí Yóò Ṣẹ?”
“Àwọn nǹkan titun ni èmi ń sọ jáde. Kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ síí ṣẹlẹ̀, mo mú kí ẹ̀yin ènìyàn gbọ́ wọn.”—ISAIAH 42:9, NW.
1, 2. (a) Kí ni àwọn aposteli Jesu béèrè nípa ọjọ́-ọ̀la? (b) Báwo ni èsì Jesu nípa àmì alápá púpọ̀ kan ṣe ní ìmúṣẹ?
Ẹ̀ KỌ́ àtọ̀runwá ń pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jehofa Ọlọrun, “ẹni tí ń sọ òpin láti ìpilẹ̀sẹ̀ wá.” (Isaiah 46:10) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú ti fihàn, àwọn aposteli wá irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ Jesu, ní bíbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Sọ fún wa, Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ, kí ni yóò sì jẹ́ àmì ìgbà tí a ti yàntẹ́lẹ̀ pé kí gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá sí ìparí?”—Marku 13:4, NW.
2 Ní ìdáhùn, Jesu ṣàpèjúwe “àmì” alápá púpọ̀ tí ó ní nínú àwọn ẹ̀rí tí yóò fihàn pé ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn Ju ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin. Èyí ní ìmúṣẹ pẹ̀lú ìparun Jerusalemu ní 70 C.E. Ṣùgbọ́n àsọtẹ́lẹ̀ Jesu yóò ní ìmúṣẹ títóbi jù títí dé àkókò ọjọ́ iwájú. Gbàrà tí “àwọn àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” bá ti parí ní 1914, àmì kan ní ìwọ̀n gbígbòòrò yóò wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ní fífihàn pé láìpẹ́ ètò-ìgbékalẹ̀ búburú ìsinsìnyí yóò dópin nínú “ìpọ́njú ńlá” kan.a (Luku 21:24, NW) Àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ tí ń bẹ láàyè lónìí lè jẹ́rìí síi pé àmì yìí ti ní ìmúṣẹ nínú àwọn ogun àgbáyé àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ alájàálù mìíràn ti ọ̀rúndún ogún yìí. Ìwọ̀nyí tún sàmìsí àwọn ìmúṣẹ pàtàkì ti àsọtẹ́lẹ̀ Jesu, ìmúṣẹ òde-òní yìí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ láti 33 sí 70 C.E. ṣàpẹẹrẹ rẹ̀.
3. Ní sísọ̀rọ̀ nípa àmì mìíràn, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni Jesu sọtẹ́lẹ̀ ní àfikún?
3 Lẹ́yìn tí Luku ti mẹ́nukan àwọn àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn àkọsílẹ̀ tí wọ́n bá a dọ́gba rẹ́gí nínú ìwé Matteu, Marku, àti Luku ṣàpèjúwe ọ̀wọ́ àwọn ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ síí farahàn síwájú síi nínú èyí tí àmì kan wà ní àfikún sí ‘àmì’ alápá púpọ̀ ‘ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.’ (Matteu 24:3) (Ní ojú-ìwé 15, kókó yìí nínú àkọsílẹ̀ náà ni a fi àwọn ìlà àpapọ̀ méjì sàmì sí.) Matteu sọ pé: “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú náà ti àwọn ọjọ́ wọnnì oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì jábọ́ láti ọ̀run, àwọn agbára ọ̀run ni a óò sì mì. Nígbà náà sì ni àmì Ọmọkùnrin ènìyàn yóò farahàn ní ọ̀run, nígbà náà sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀-ayé yóò lu ara wọn nínú ìdárò, wọn yóò sì rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. Òun yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ jáde lọ pẹ̀lú ìró ńlá kàkàkí, wọn yóò sì kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun kan àwọn ọ̀run sí ìkángun wọn kejì.”—Matteu 24:29-31, NW.
Ìpọ́njú àti Àwọn Àrà Mérìíyìírí Ojú Ọ̀run
4. Àwọn ìbéèrè wo ni ó dìde nípa àwọn àrà mérìíyìírí ojú ọ̀run tí Jesu mẹ́nukàn?
4 Nígbà wo ni ìyẹn yóò ní ìmúṣẹ? Gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ Ìhìnrere mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà mẹ́nukan ohun ti a lè pè ní àrà mérìíyìírí ojú ọ̀run—oòrùn àti òṣùpá ṣókùnkùn àwọn ìràwọ̀ sì ń jábọ́. Jesu sọ pé ìwọ̀nyí ni yóò tẹ̀lé “ìpọ́njú” náà. Jesu ha ní ìpọ́njú tí ó dé òténté rẹ̀ ní 70 C.E. lọ́kàn bí, tàbí ó ha ń sọ̀rọ̀ nípa ìpọ́njú ńlá tí ó ṣì jẹ́ tí ọjọ́-iwájú ní àkókò òde-òní?—Matteu 24:29; Marku 13:24.
5. Ojú ìwòye wo ni a ti fìgbàkan rí dìmú nípa ìpọ́njú ní àwọn àkókò òde-òní?
5 Láti ìgbà tí àwọn àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè ti dópin ní 1914, àwọn ènìyàn Ọlọrun ti ń háragàgà láti mọ̀ nípa “ìpọ́njú ńlá” náà. (Ìfihàn 7:14) Fún ọ̀pọ̀ ọdún wọ́n ronú pé ìpọ́njú ńlá ti àkókò ìwòyí ní apá ìbẹ̀rẹ̀ kan tí ó dọ́gba pẹ̀lú àkókò Ogun Àgbáyé Kìn-ín-ní, lẹ́yìn náà sáà ìdáwọ́dúró, àti níkẹyìn apá ìparí kan, “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọrun Olodumare.” Bí ìyẹn bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ẹ̀wádún tí ó la “òpin ètò-ìgbékalẹ̀” náà láàárín?—Ìfihàn 16:14; Matteu 13:39, NW; 24:3; 28:20.
6. Kí ni a ti lérò pé ó mú àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ṣẹ nípa àwọn àrà mérìíyìírí ojú ọ̀run?
6 Ó dára, a ronú pé ní sáà tí ó là á láàárín yìí àmì alápá púpọ̀ náà ni a óò rí, títí kan iṣẹ́ ìwàásù tí àwọn ènìyàn Ọlọrun tí a ti kójọ ń ṣe. Ó tún dàbí ẹni pé àrà mérìíyìírí ojú ọ̀run tí a sọtẹ́lẹ̀ náà ni a lè retí ní sáà náà lẹ́yìn ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1914 sí 1918. (Matteu 24:29; Marku 13:24, 25; Luku 21:25) Àfiyèsí dálórí àwọn nǹkan gidi tí ń bẹ lójú ọ̀run—àwọn ẹ̀rọ atàtaré ìsọfúnni láti gbalasa òfuurufú, rọ́kẹ́ẹ̀tì, àwọn ìtànṣán gbalasa òfuurufú tàbí ti olóró gíga, àti ibi ìbalẹ̀sí tàbí ibi ìgbérafò lójú òṣùpá.
7. Òye tí a túnṣebọ̀sípò wo ni a ti fifúnni nípa ìpọ́njú ńlá?
7 Bí ó ti wù kí ó rí, Ilé-Ìṣọ́nà December 15, 1970, tún àsọtẹ́lẹ̀ Jesu gbéyẹ̀wò, ní pàtàkì ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀wá náà. Ó fihàn pé lójú-ìwòye ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, ìpọ́njú òde-òní kò níláti ní apá ìbẹ̀rẹ̀ kan ní 1914 sí 1918, àlàfo àkókò kan tí ó gùn fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, àti lẹ́yìn náà kí ó wá padà bẹ̀rẹ̀. Ìwé-ìròyìn yẹn parí èrò pé: “‘Ìpọ́njú ńlá’ náà irú èyí tí kò tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ wà níwájú síbẹ̀síbẹ̀, nítorí ó túmọ̀sí ìparun ilẹ̀ ọba ìsìn èké (àti Kristẹndọm pẹ̀lú) èyí tí ‘ogun ọjọ́ ńlá Ọlọrun Olodumare’ ní Armageddoni yóò tẹ̀lé.”
8. Pẹ̀lú ojú-ìwòye tí a ti túnṣebọ̀sípò nípa ìpọ́njú òde-òní, báwo ni a ṣe ṣàlàyé Matteu 24:29?
8 Ṣùgbọ́n Matteu 24:29 (NW) sọ pé àrà mérìíyìírí ojú ọ̀run náà wá “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú náà.” Báwo ni ìyẹn ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Ilé-Ìṣọ́nà November 1, 1975, sọ pé níhìn-ín “ìpọ́njú náà” túmọ̀sí èyí tí ó dé òténté lẹ́yìn lọ́hùn-ún ní 70 C.E. Ṣùgbọ́n ní èrò-ìtumọ̀ wo ni a fi lè sọ pé àwọn àrà mérìíyìírí ojú ọ̀run ní àkókò wa ń ṣẹlẹ̀ “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀” tẹ̀lé ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní 70 C.E.? A ronú pé ní ojú Ọlọrun àwọn ọ̀rúndún tí ó là á láàárín yóò kúrú. (Romu 16:20; 2 Peteru 3:8) Bí ó ti wù kí ó rí, àyẹ̀wò tí ó túbọ̀ jinlẹ̀ síi nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí, pàápàá jùlọ ti Matteu 24:29-31, tọ́ka sí àlàyé kan tí ó yàtọ̀ gidigidi. Èyí ṣàpèjúwe bí ìmọ́lẹ̀ ti ń tàn “síwájú àti síwájú títí di ọjọ́ pípé náà.” (Owe 4:18, American Standard Version)b Ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò ìdí tí àlàyé titun, tàbí èyí tí a yípadà fi jẹ́ ohun yíyẹ.
9. Báwo ni àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu ṣe pèsè ìsọfúnni tí ń rannilọ́wọ́ láti lóye àwọn ọ̀rọ̀ Jesu nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nínú àwọn ọ̀run?
9 Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ‘ìṣókùnkùn oòrùn, òṣùpá tí kì yóò fi ìmọ́lẹ̀ hàn, àti àwọn ìràwọ̀ tí yóò jábọ́’ fún mẹ́rin nínú àwọn aposteli rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bíi Ju, wọn yóò lóye irú èdè bẹ́ẹ̀ láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, nínú èyí tí, fún àpẹẹrẹ, a ti pe àkókò ìdájọ́ Ọlọrun nínú Sefaniah 1:15 ní “ọjọ́ òfò àti ìdahoro, ọjọ́ òkùnkùn àti òkùdu, ọjọ́ kùukùu àti òkùnkùn biribiri.” Onírúurú àwọn wòlíì Heberu tún ṣàpèjúwe oòrùn bí èyí tí ó ṣókùnkùn, òṣùpá gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò tànmọ́lẹ̀, àti àwọn ìràwọ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò fi ìmọ́lẹ̀ hàn. Ìwọ yóò rí irú àwọn èdè bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìhìn-iṣẹ́ àtọ̀runwá lòdìsí Babiloni, Edomu, Egipti, àti ìjọba ìhà àríwá Israeli.—Isaiah 13:9, 10; 34:4, 5; Jeremiah 4:28; Esekieli 32:2, 6-8; Amosi 5:20; 8:2, 9.
10, 11. (a) Kí ni Joeli sọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn nǹkan ní òkè ọ̀run? (b) Àwọn apá-ìhà wo ní a múṣẹ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Joeli ní 33 C.E., àwọn wo sì ni wọn kò ní ìmúṣẹ?
10 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí Jesu sọ, ó ṣeéṣe kí Peteru àti àwọn mẹ́ta yòókù ti rántí àsọtẹ́lẹ̀ Joeli tí a lè rí ní Joeli 2:28-31 àti 3:15: “Èmi óò tú ẹ̀mí mi jáde sí ara ènìyàn gbogbo; àti àwọn ọmọ yín ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀. . . . Èmi ó sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọ̀run àti ní ayé, ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọwọ̀n èéfín. A óò sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ẹ̀rù Oluwa tó dé.” “Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn, àti àwọn ìràwọ̀ yóò fa títàn wọn sẹ́yìn.”
11 Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nínú Iṣe 2:1-4 àti 14-21, ní Pentekosti 33 C.E., Ọlọrun tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí 120 àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, àti ọkùnrin àti obìnrin. Aposteli Peteru sọ ọ́ di mímọ̀ pé èyí ni ohun tí Joeli ti sọtẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n, kí ni nípa àwọn ọ̀rọ̀ Joeli nípa ‘oòrùn tí ó ṣókùnkùn àti òṣùpá tí ó di ẹ̀jẹ̀ àti àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n fa títàn wọn sẹ́yìn’? Kò sí ohun kankan tí ó fihàn pé èyí ní ìmúṣẹ ní 33 C.E. tàbí lákòókò ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan Ju tí gígùn rẹ̀ rékọjá 30 ọdún.
12, 13. Báwo ni a ṣe mú àwọn àrà mérìíyìírí ojú-ọ̀run tí Joeli sọtẹ́lẹ̀ ṣẹ?
12 Lọ́nà tí ó ṣe kedere apá tí ó kẹ́yìn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Joeli túbọ̀ ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú dídé “ọjọ́ ńlá àti ẹ̀rù Oluwa”—ìparun Jerusalemu. Ilé-Ìṣọ́nà December 1, 1967, sọ nípa ìpọ́njú tí ó kọlu Jerusalemu ní 70 C.E.: “Dájúdájú èyíinì jẹ́ ‘ọjọ́ Jehofa’ nípa Jerusalemu àti àwọn ọmọ rẹ̀. Àti nípa ọjọ́ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ‘ẹ̀jẹ̀ àti iná àti rírú èéfín’ wà, oòrùn kò tànmọ́lẹ̀ dídán sórí òkùnkùn ìlú náà ní ọ̀sán, tí òṣùpá sì ń fúnni ní èrò nípa àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀, kìí ṣe ìmọ́lẹ̀ òṣùpá alálàáfíà tí ń dán ní òru.”c
13 Bẹ́ẹ̀ni, bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn tí a ti ṣàkíyèsí, àwọn àrà mérìíyìírí ojú ọ̀run tí Joeli sọtẹ́lẹ̀ yẹ kí wọ́n ní ìmúṣẹ wọn nígbà tí Jehofa bá mú ìdájọ́ ṣẹ. Dípò kí wọ́n gbòòrò lọ dé àkókò ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn Ju, ìṣókùnkùn oòrùn, òṣùpá, àti àwọn ìràwọ̀ wáyé nígbà tí àwọn ẹgbẹ́-ogun amúdàájọ́ṣẹ gbéjàko Jerusalemu. Lọ́nà tí ó bá ọgbọ́n ìrònú mu, a lè retí ìmúṣẹ títóbi jù fún apá yẹn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Joeli nígbà tí ìmúṣẹ ìdájọ́ Ọlọrun lórí ètò-ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀.
Ìpọ́njú Wo ni Yóò Wà Ṣáájú Àwọn Àrà Mérìíyìírí Ojú Ọ̀run?
14, 15. Ìyọrísí wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Joeli ní lórí òye wa nípa Matteu 24:29?
14 Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Joeli (ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn tí wọ́n lo èdè tí ó farajọra) ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn ọ̀rọ̀ inú Matteu 24:29. Ní kedere, ohun tí Jesu sọ nípa ‘ìṣókùnkùn oòrùn, òṣùpá tí kò fi ìmọ́lẹ̀ hàn, àti àwọn ìràwọ̀ tí ń jábọ́,’ kò tọ́ka sí àwọn ohun bíi rọ́kẹ́ẹ̀tì gbangba òfuurufú, bíbalẹ̀ sórí òṣùpá, àti irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀, tí ń ṣẹlẹ̀ la ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ètò-ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí já. Bẹ́ẹ̀kọ́, ó tọ́ka sí àwọn nǹkan tí wọ́n ní ìsopọ̀ pẹ̀lú “ọjọ́ ńlá àti ẹ̀rù Oluwa,” ìparun tí ó ṣì ń bọ̀ lọ́nà.
15 Èyí báratan pẹ̀lú òye wa nípa bí àwọn àrà mérìíyìírí ojú ọ̀run yóò ṣe ṣẹlẹ̀ “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú náà.” Kìí ṣe ìpọ́njú tí ó dé ògógóró òpin rẹ̀ ní 70 C.E. ni Jesu ń tọ́ka sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun ń tọ́ka sí ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá tí yóò kọlu ètò-ìgbékalẹ̀ ayé ní ọjọ́ iwájú, tí yóò jẹ́ òténté “wíwàníhìn-ín” rẹ̀ tí ó ṣèlérí. (Matteu 24:3, NW) Ìpọ́njú yẹn ṣì wà ní iwájú wa.
16. Ìpọ́njú wo ni Marku 13:24 ń tọ́kasí, èésìtiṣe tí ó fi rí bẹ́ẹ̀?
16 Kí ni nípa ti àwọn ọ̀rọ̀ tí ń bẹ nínú Marku 13:24: “Ní àwọn ọjọ́ wọnnì, lẹ́yìn ìpọ́njú yẹn, oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn”? Níhìn-ín, “wọnnì” àti “yẹn” ni àwọn méjèèjì jẹ́ irú-oríṣi ọ̀rọ̀ Griki náà e·keiʹnos, ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ aṣàfihàn tí ń tọ́ka ohun kan tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú jíjìnnà. E·keiʹnos ni a lè lò láti tọ́ka ohun kan tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn (tàbí tí a mẹ́nukan ṣáájú) tàbí ohun kan ní ọjọ́ iwájú tí ó jìnnà. (Matteu 3:1; 7:22; 10:19; 24:38; Marku 13:11, 17, 32; 14:25; Luku 10:12; 2 Tessalonika 1:10) Nípa báyìí, Marku 13:24 tọ́ka sí “ìpọ́njú yẹn,” kìí ṣe ìpọ́njú tí àwọn ará Romu ru sókè, bíkòṣe sí àwọn ìṣe alágbára ńlá ti Jehofa ní ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí.
17, 18. Ìmọ́lẹ̀ wo ni Ìfihàn tàn sórí bí ìpọ́njú ńlá náà yóò ṣe bẹ̀rẹ̀ síí farahàn?
17 Orí 17 sí 19 nínú Ìfihàn ṣe wẹ́kú ó sì jẹ́rìí sí òye tí a túnṣebọ̀sípò nípa Matteu 24:29-31, Marku 13:24-27, àti Luku 21:25-28 yìí. Ní ọ̀nà wo? Àwọn Ìhìnrere fihàn pé ìpọ́njú yìí kì yóò bẹ̀rẹ̀ kí ó sì parí lẹ́ẹ̀kan náà. Lẹ́yìn tí ó bá ti bẹ̀rẹ̀, díẹ̀ nínú àwọn aráyé aláìgbọràn yóò ṣì wàláàyè láti rí “àmì Ọmọkùnrin ènìyàn” kí wọ́n sì hùwàpadà—láti kédàárò àti, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nínú Luku 21:26, láti “dákú láti inú ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀-ayé tí a ń gbé.” Ìbẹ̀rù tí ń bonimọ́lẹ̀ yẹn yóò jẹ́ nítorí tí wọ́n rí “àmì” tí ó fi ẹ̀rí ìparun wọn tí ó súnmọ́lé gírígírí hàn.
18 Àkọsílẹ̀ inú Ìfihàn fihàn pé ìpọ́njú ńlá ọjọ́ iwájú yóò bẹ̀rẹ̀ nígbà tí “ìwo” ológun ti “ẹranko ẹhànnà” ọlọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè náà bá yíjú sí “aṣẹ́wó ńlá náà,” Babiloni Ńlá.d (Ìfihàn 17:1, 10-16, NW) Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ṣẹ́kù, nítorí pé àwọn ọba, àwọn oníṣòwò, àwọn ọ̀gákọ̀, àti àwọn mìíràn ṣọ̀fọ̀ òpin ìsìn èké. Kò sí iyèméjì pé àwọn púpọ̀ yóò mọ̀ pé ìdájọ́ tiwọn ni yóò tẹ̀lé e.—Ìfihàn 18:9-19.
Kí Ni Ohun Tí Ń Bọ̀?
19. Kí ni a lè réti nígbà tí ìpọ́njú ńlá náà bá bẹ̀rẹ̀?
19 Àwọn apá àyọkà Ìhìnrere nínú Matteu, Marku, àti Luku darapọ̀ mọ́ Ìfihàn orí 17 sí 19 láti tànmọ́lẹ̀ ńláǹlà sórí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. Ní àkókò tí Ọlọrun ti pinnu, ìpọ́njú ńlá náà yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbéjàkò lòdìsí ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé (Babiloni Ńlá). Èyí yóò gbóná janjan ní pàtàkì fún Kristẹndọm, tí ó dọ́gba pẹ̀lú Jerusalemu aláìṣòótọ́. “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn” ìpele yìí nínú ìpọ́njú náà, “àwọn àmì yóò wà nínú oòrùn àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀, àti lórí ilẹ̀-ayé làásìgbò àwọn orílẹ̀-èdè [tí a kò tíì rí irú rẹ̀ rí].”—Matteu 24:29, NW; Luku 21:25, NW.
20. Àwọn àrà mérìíyìírí ojú ọ̀run wo ni a ṣì lè retí síbẹ̀?
20 Ní èrò-ìtumọ̀ wo ni ‘oòrùn yóò fi ṣókùnkùn, tí òṣùpá kì yóò fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, tí àwọn ìràwọ̀ yóò jábọ́ láti ọ̀run, tí a ó sì mi àwọn agbára ọ̀run’? Láìsí iyèméjì, ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà, ọ̀pọ̀ àwọn orísun ìmọ́lẹ̀—àwọn gbajúgbajà àlùfáà nínú agbo ìsìn—ní a ó ti túfó tí a ó sì ti mú kúrò nípasẹ̀ “ìwo mẹ́wàá” tí a mẹ́nukàn ní Ìfihàn 17:16. Kò sí iyèméjì pé àwọn agbára òṣèlú pẹ̀lú ni a ó ti mì tìtì. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń kó jìnnìjìnnì báni ha lè wà ní àwọn ọ̀run tí ó ṣeéfojúrí pẹ̀lú bí? Ó ṣeéṣe kí ó rí bẹ́ẹ̀, kí ó sì jẹ́ amúni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ ju ìwọ̀nyí tí Josephus ṣàpèjúwe pé ó ṣẹlẹ̀ ní apá ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn Ju. A mọ̀ pé ní àkókò ìgbàanì lọ́hùn-ún, Ọlọrun fi agbára rẹ̀ láti mú kí irú àwọn ìjábá òjijì bẹ́ẹ̀ wáyé hàn, ó sì tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi.—Eksodu 10:21-23; Joṣua 10:12-14; Awọn Onidajọ 5:20; Luku 23:44, 45.
21. Báwo ni “àmì” ọjọ́ iwájú kan yóò ṣe wáyé?
21 Lórí kókó yìí gbogbo àwọn òǹkọ̀wé Ìhìnrere mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lo toʹte (nígbà náà) láti nasẹ̀ àwọn ohun tí yóò bẹ̀rẹ̀ síí farahàn tẹ̀lé e. “Nígbà náà sì ni àmì Ọmọkùnrin ènìyàn yóò farahàn ní ọ̀run.” (Matteu 24:30; Marku 13:26; Luku 21:27) Láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kìn-ín-ní, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tòótọ́ ti fòyemọ àmì alápá púpọ̀ ti wíwàníhìn-ín rẹ̀ tí kò ṣeéfojúrí, nígbà tí ó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò tíì mọ èyí. Ṣùgbọ́n Matteu 24:30 tọ́ka síwájú sí àfikún “àmì” tí yóò farahàn ní ọjọ́ iwájú, ìyẹn ni ti “Ọmọkùnrin ènìyàn,” a ó sì fipá mú gbogbo orílẹ̀-èdè láti kíyèsí i. Nígbà tí Jesu bá wá pẹ̀lú àwọsánmà ti àìṣeéfojúrí, àwọn ènìyàn tí ń ṣàtakò kárí-ayé yóò níláti mọ “bíbọ̀” (Griki, er·khoʹme·non) náà nítorí fífi agbára ọba rẹ̀ lọ́nà tí ó ju ti ẹ̀dá lọ hàn.—Ìfihàn 1:7.
22. Kí ni yóò jẹ́ ìyọrísí rírí “àmì” Matteu 24:30?
22 Matteu 24:30 lo toʹte lẹ́ẹ̀kan síi láti nasẹ̀ ohun tí ó tẹ̀lé e. Ní níní òye-ìmọ̀lára abájáde ipò-ọ̀ràn wọn, nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò lu ara wọn, wọn yóò sì kédàárò, bóyá ní mímọ̀ pé ìparun wọn ti súnmọ́lé. Ẹ wo bí ìyẹn ti yàtọ̀ sí tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun tó, nítorí àwa yóò lè gbé orí wa sókè ní mímọ̀ pé ìdáǹdè wa ti súnmọ́tòsí! (Luku 21:28) Ìfihàn 19:1-6 tún fi àwọn olùjọsìn tòótọ́ hàn ní ọ̀run àti ní ayé tí wọ́n ń yọ̀ nítorí òpin àgbèrè ńlá náà.
23. (a) Ìgbésẹ̀ wo ni Jesu yóò gbé nípa àwọn àyànfẹ́? (b) Kí ni a lè sọ nípa mímú àwọn àṣẹ́kù lọ sí ọ̀run?
23 Àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ń báa lọ láti sọ ní Marku 13:27 (NW) pé: “Nígbà náà [toʹte] ni òun yóò sì rán àwọn angẹli jáde yóò sì kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun ilẹ̀-ayé títí dé ìkángun ọ̀run.” Níhìn-ín Jesu kó àfiyèsí jọ sórí àṣẹ́kù 144,000 ti àwọn “àyànfẹ́” tí wọ́n ṣì wàláàyè lórí ilẹ̀-ayé. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan, àwọn ẹni-àmì-òróró ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wọ̀nyí ni a mú wá sínú ìṣọ̀kan ti ìṣàkóso Ọlọrun. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìbámu pẹ̀lú ìtòtẹ̀léra náà tí wọ́n lò, Marku 13:27 àti Matteu 24:31 (NW) ṣàpèjúwe ohun mìíràn kan. “Pẹ̀lú ìró ńlá kàkàkí,” àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú “àwọn àyànfẹ́” ni a óò kójọ láti àwọn òpin ilẹ̀-ayé. Báwo ni a ó ṣe kó wọn jọ? Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, a ó fi “èdìdì” dì wọ́n, Jehofa yóò sì fi wọ́n hàn yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí apákan ‘àwọn wọnnì tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́.’ Ní àkókò tí Ọlọrun sì yàn, a óò kó wọn jọpọ̀ sí ọ̀run láti jẹ́ ọba àti àlùfáà.e Èyí yóò mú ayọ̀ wá fún wọn àti fún àwọn olùṣòtítọ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn, “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tí a ó sàmì sí àwọn pẹ̀lú fún ‘jíjáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá’ láti gbádùn àwọn ìbùkún lórí paradise ilẹ̀-ayé.—Matteu 24:22; Ìfihàn 7:3, 4, 9-17; 17:14; 20:6; Esekieli 9:4, 6.
24. Ìtòtẹ̀léra wo ni Matteu 24:29-31 ṣípayá níti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bọ̀ níwájú?
24 Nígbà tí àwọn aposteli náà sọ pé, “Sọ fún wa . . . ,” èsì Jesu rékọjá ohun tí wọ́n lè finúmòye. Síbẹ̀, láàárín àkókò ìwàláàyè wọn, wọ́n yọ̀ láti rí àpẹẹrẹ irú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí. Ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a farabalẹ̀ ṣe nípa èsì Jesu ti kó àfiyèsí jọ sórí apá àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí yóò ní ìmúṣẹ ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́. (Matteu 24:29-31; Marku 13:24-27; Luku 21:25-28) Ní báyìí ná a lè ríi pé ìdáǹdè wa túbọ̀ ń kù sí dẹ̀dẹ̀. A lè fojúsọ́nà fún ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà, nígbà náà àmì Ọmọkùnrin ènìyàn, àti nígbà náà kíkó tí Ọlọrun yóò kó àwọn àyànfẹ́ jọpọ̀. Níkẹyìn, gẹ́gẹ́ bí Amúdàájọ́ṣẹ ti Jehofa ní Armageddoni, Ajagun-òun-Ọba wa, Jesu tí a ti gbé gorí ìtẹ́, yóò sì “parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” (Ìfihàn 6:2, NW) Ọjọ́ Jehofa yẹn, nígbà tí òun yóò san ẹ̀san, yóò dé gẹ́gẹ́ bí àṣekágbá pípabambarì fún ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tí ó ti sàmìsí ọjọ́ Oluwa láti 1914 wá.
25. Báwo ni a ṣe lè nípìn-ín nínú ìmúṣẹ Luku 21:28 tí ó ṣì ń bọ̀wá lọ́jọ́ iwájú?
25 Ǹjẹ́ kí ìwọ máa báa lọ láti jàǹfààní láti inú ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá, kí o baà lè dáhùnpadà sí ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ Jesu tí yóò wáyé lọ́jọ́ iwájú pé: “Ṣùgbọ́n bí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ síí ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nàró ṣánṣán kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń súnmọ́lé.” (Luku 21:28, NW) Ẹ sì wo irú ọjọ́-ọ̀la tí ó wà níwájú àwọn àyànfẹ́ àti àwọn ogunlọ́gọ̀ bí Jehofa tí ń bá a lọ ní yíya orúkọ mímọ́ rẹ̀ sí mímọ́!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dùn láti fi ẹ̀rí èyí hàn, ní fífihàn bí àwọn òtítọ́ tí ó ṣeéfojúrí ní ọjọ́ wa ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli ṣẹ.
b Àfikún àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ farahàn ní ojú-ewé 296 sí 323 nínú ìwé God’s Kingdom of a Thousand Years Has Approached, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀jáde ní 1973 àti Ilé-Ìṣọ́nà March 15, 1983, ojú-ìwé 17 sí 22.
c Josephus kọ̀wé nípa àwọn ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ sí farahàn láàárín ìgbà tí àwọn ọmọ-ogun Romu kọ́kọ́ kọlu Jerusalemu (66 C.E.) àti ìparun rẹ̀: “Ní ọ̀gànjọ́ òru, ẹ̀fúùfù aṣèparun fẹ́; ìjì-líle jà, àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò rọ̀, mànàmáná ń kọ yẹ̀rìyẹ̀rì láìdáwọ́dúró, sísán ààrá ń kó ìpayà báni, ilẹ̀-ayé mì tìtì pẹ̀lú ariwo tí ń dinilétí. Ní kedere ìwólulẹ̀ gbogbo ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí jẹ́ òjìji ìṣáájú fún ìjábá fún ìran ènìyàn, ẹnikẹ́ni kò sì lè ṣiyèméjì pé àwọn àmì-àpẹẹrẹ náà ń fúnni ní ìkìlọ̀ nípa àjálù kan tí kò ní àfiwé.”
d Ohun tí Jesu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìpọ́njú ńlá” àti “ìpọ́njú kan” nínú ìfisílò rẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ ìparun ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn Ju. Ṣùgbọ́n nínú àwọn ẹsẹ tí wọ́n ní ìfisílò fún ọjọ́ wa nìkan, ó lo “náà,” ọ̀rọ̀-atọ́ka tí ó ṣe pàtó ní wíwí pé “ìpọ́njú náà.” (Matteu 24:21, 29; Marku 13:19, 24) Ìfihàn 7:14 (NW) pe ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú yìí ní “ìpọ́njú ńlá náà,” lóréfèé “ìpọ́njú náà ńlá náà.”
e Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti August 15, 1990.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Báwo ni a ṣe mú àwọn apá kan nínú Joeli 2:28-31 àti 3:15 ṣẹ ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní?
◻ Ìpọ́njú wo ni Matteu 24:29 ń tọ́kasí, èésìtiṣe tí a fi dé ìparí èrò yẹn?
◻ Àwọn àrà mérìíyìírí ojú ọ̀run wo ni Matteu 24:29 tọ́kasí, báwo sì ni èyí ṣe lè jẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú náà?
◻ Báwo ni Luku 21:26, 28 yóò ṣe ní ìmúṣẹ ní ọjọ́ iwájú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Agbègbè tẹmpili
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.