Àkọsílẹ̀ Máàkù
13 Bó ṣe ń jáde nínú tẹ́ńpìlì, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé: “Olùkọ́, wò ó! àwọn òkúta àti ilé yìí mà wuni o!”+ 2 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Ṣé o rí àwọn ilé ńlá yìí? Ó dájú pé wọn ò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta míì níbí, láìwó o palẹ̀.”+
3 Bó ṣe jókòó sórí Òkè Ólífì níbi tó ti lè rí tẹ́ńpìlì náà ní ọ̀ọ́kán, Pétérù, Jémíìsì, Jòhánù àti Áńdérù wá bi í ní òun nìkan pé: 4 “Sọ fún wa, ìgbà wo ni àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, kí ló sì máa jẹ́ àmì ìgbà tí gbogbo nǹkan yìí máa wá sí òpin?”+ 5 Jésù wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra kí ẹnì kankan má ṣì yín lọ́nà.+ 6 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa wá ní orúkọ mi, wọ́n á sọ pé, ‘Èmi ni ẹni náà,’ wọ́n sì máa ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà. 7 Bákan náà, tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn ogun, tí ẹ sì gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ogun, ẹ má bẹ̀rù; àwọn nǹkan yìí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, àmọ́ òpin ò tíì dé.+
8 “Torí orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba;+ ìmìtìtì ilẹ̀ máa wà láti ibì kan dé ibòmíì; àìtó oúnjẹ náà máa wà.+ Àwọn nǹkan yìí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ wàhálà tó ń fa ìrora.+
9 “Ní tiyín, ẹ máa ṣọ́ra yín. Àwọn èèyàn máa fà yín lé àwọn ilé ẹjọ́ àdúgbò lọ́wọ́,+ wọ́n máa lù yín nínú àwọn sínágọ́gù,+ ẹ sì máa dúró níwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.+ 10 Bákan náà, a ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè.+ 11 Tí wọ́n bá sì ń mú yín lọ láti fà yín léni lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn ṣáájú nípa ohun tí ẹ máa sọ; àmọ́ ohunkóhun tí a bá fún yín ní wákàtí yẹn ni kí ẹ sọ, torí kì í ṣe ẹ̀yin lẹ̀ ń sọ̀rọ̀, ẹ̀mí mímọ́ ni.+ 12 Bákan náà, arákùnrin máa fa arákùnrin lé ikú lọ́wọ́, bàbá máa ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọmọ, àwọn ọmọ máa dìde sí àwọn òbí, wọ́n sì máa pa wọ́n.+ 13 Gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.+ Àmọ́ ẹni tó bá fara dà á* dé òpin+ máa rí ìgbàlà.+
14 “Àmọ́ tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro,+ tó dúró ní ibi tí kò yẹ (kí òǹkàwé lo òye), nígbà náà, kí àwọn tó wà ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè.+ 15 Kí ẹni tó wà lórí ilé má sọ̀ kalẹ̀ tàbí kó wọlé lọ mú ohunkóhun kúrò nínú ilé rẹ̀; 16 kí ẹni tó wà ní pápá má sì pa dà sí àwọn ohun tó wà lẹ́yìn láti mú aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀. 17 Ó mà ṣe o, fún àwọn aláboyún àti àwọn tó ń tọ́ ọmọ jòjòló ní àwọn ọjọ́ yẹn o!+ 18 Ẹ máa gbàdúrà kó má lọ bọ́ sí ìgbà òtútù; 19 torí àwọn ọjọ́ yẹn máa jẹ́ àwọn ọjọ́ ìpọ́njú,+ irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá tí Ọlọ́run dá títí di àkókò yẹn, irú rẹ̀ kò sì ní ṣẹlẹ̀ mọ́.+ 20 Kódà, ẹran ara kankan ò ní là á já, àfi tí Jèhófà* bá dín àwọn ọjọ́ náà kù. Àmọ́ nítorí àwọn àyànfẹ́ tó yàn, ó dín àwọn ọjọ́ náà kù.+
21 “Bákan náà, tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín nígbà yẹn pé, ‘Ẹ wò ó! Kristi wà níbí’ tàbí ‘Ẹ wò ó! Òun nìyẹn,’ ẹ má gbà á gbọ́.+ 22 Torí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké máa dìde,+ wọ́n sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu láti kó àwọn àyànfẹ́ pàápàá ṣìnà, tó bá ṣeé ṣe. 23 Torí náà, ẹ ṣọ́ra.+ Mo ti sọ gbogbo nǹkan fún yín ṣáájú.
24 “Àmọ́ nígbà yẹn, lẹ́yìn ìpọ́njú yẹn, oòrùn máa ṣókùnkùn, òṣùpá ò sì ní mọ́lẹ̀,+ 25 àwọn ìràwọ̀ á máa já bọ́ láti ọ̀run, a sì máa mi àwọn agbára tó wà ní ọ̀run. 26 Nígbà náà, wọ́n máa wá rí Ọmọ èèyàn+ tó ń bọ̀ nínú àwọsánmà* pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.+ 27 Ó máa rán àwọn áńgẹ́lì jáde, wọ́n sì máa kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ láti atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun ayé títí dé ìkángun ọ̀run.+
28 “Ní báyìí, ẹ kọ́ àpèjúwe yìí lára igi ọ̀pọ̀tọ́: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ọ̀mùnú, tó sì rúwé, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti sún mọ́lé.+ 29 Bákan náà, tí ẹ bá rí i tí àwọn nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ ẹnu ọ̀nà.+ 30 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ó dájú pé ìran yìí ò ní kọjá lọ títí gbogbo nǹkan yìí fi máa ṣẹlẹ̀.+ 31 Ọ̀run àti ayé máa kọjá lọ,+ àmọ́ ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ mi ò ní kọjá lọ.+
32 “Ní ti ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí yẹn, kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run àti Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àyàfi Baba.+ 33 Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò,+ torí ẹ ò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn jẹ́.+ 34 Ó dà bí ọkùnrin kan tó ń rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, tó sì fún àwọn ẹrú rẹ̀ ní àṣẹ,+ tó yan iṣẹ́ fún kálukú, tó sì pàṣẹ fún aṣọ́nà pé kó máa ṣọ́nà.+ 35 Torí náà, ẹ máa ṣọ́nà, torí pé ẹ ò mọ ìgbà tí baálé ilé náà ń bọ̀,+ bóyá alẹ́ ni àbí ọ̀gànjọ́ òru àbí àfẹ̀mọ́jú* àbí ní àárọ̀ kùtù,+ 36 kó má bàa bá yín lójú oorun tó bá dé lójijì.+ 37 Àmọ́ ohun tí mo sọ fún yín ni mo sọ fún gbogbo èèyàn: Ẹ máa ṣọ́nà.”+