Ẹ Yèkooro Ní Ero-inu—Opin ti Sunmọle
“Opin ohun gbogbo ti sunmọle. Nitori naa, ki ẹyin ki o yèkooro ni ero-inu, ki ẹ sì wà lojufo pẹlu èrò gbigba adura.”—1 PETERU 4:7, NW.
1. (a) Ijakulẹ wo ni olori isin kan ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ niriiri? (b) Nitori pe awọn ifojusọna kan kò tii ni imuṣẹ, awọn ibeere wo ni a lè beere?
“MO GBA ìpè kan lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun lakooko adura àgbàkẹ́hìn òru-òní. Ó sọ pe awọn 116,000 eniyan yoo goke lọ si ọrun ti a o sì ṣí sàréè million 3.7 awọn onigbagbọ ti wọn ti kú silẹ siha ofuurufu.” Bẹẹ ni aṣaaju Mission for the Coming Days ṣe sọ ni alẹ́ October 28, 1992, ọjọ ijihin wọn ti wọn sọtẹlẹ. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti ó di October 29, ẹnikanṣoṣo kò tíì goke lọ si ọrun, kò sì sí awọn ibojì òkú ti a tíì ṣí silẹ. Dipo didi ẹni ti a yára gbà lọ ninu ìgbàlọsókè ti ọrun kan, awọn onigbagbọ ọjọ-idajọ-iparun wọnyẹn ni Korea wulẹ rí ìmọ́lẹ̀ ojumọ miiran ti ó mọ́ ni. Ọjọ ti wọn dá gẹgẹ bi ọjọ-idajọ-iparun ti wá ó sì ti lọ, ṣugbọn awọn alasọtẹlẹ idajọ-iparun kò rẹwẹsi. Ki ni awọn Kristian nilati ṣe? Wọn ha nilati jáwọ́ ninu gbigbagbọ pe opin ti ń yára sunmọle bi?
2. Ta ni o bá awọn aposteli sọrọ nipa ọjọ idajọ ọjọ-iwaju, ni abẹ awọn ipo wo si ni wọn ti kọ́ nipa eyi?
2 Lati dahun, ẹ jẹ ki a ranti akoko ìgbà ti Jesu ń bá awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni ijumọsọrọpọ idakọnkọ. Nibẹ, ni agbegbe Kesarea Filippi, ni ìhà ariwa ila-oorun Òkun Galili, ní ayika ibi ti Oke giga Hermoni fífanilọ́kànmọ́ra wà, wọn gbọ́ ọ ti o sọ ni kedere pe a o pa oun. (Matteu 16:21) Awọn ọ̀rọ̀ amúni-ṣe wọ̀ọ̀ ni o nilati tẹlee. Lẹhin ṣiṣalaye fun wọn pe jíjẹ́ ọmọ-ẹhin tumọsi gbigbe igbesi-aye ifara-ẹni-rubọ titi lọ, Jesu kilọ pe: “Nitori Ọmọ eniyan yoo wá ninu ògo Baba rẹ̀ pẹlu awọn angẹli rẹ̀; nigba naa ni yoo san án fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.” (Matteu 16:27) Jesu sọ nipa wíwá ọjọ-ọla kan. Ni asiko yii, bi o ti wu ki o ri, oun yoo jẹ́ Onidaajọ. Ni akoko yẹn ohun gbogbo yoo sinmi lé yala oun yoo ri ẹnikan ti ń fi òdodo tẹle e tabi bẹẹkọ. Idajọ Jesu ni a óò gbekari iwahihu, laika bi ẹni yẹn ti lè ní tabi ṣaini ọrọ̀-ìní ti ayé pupọ tó. Otitọ yii ni awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nilati tẹ̀ mọ́ ọkàn ṣinṣin. (Matteu 16:25, 26) Nipa bayii, Jesu Kristi funraarẹ ni o sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati fojusọna fun wíwá rẹ̀ ológo, pẹlu idajọ rẹ̀.
3. Bawo ni Jesu ṣe ṣapejuwe ijẹpataki wíwá rẹ̀ ọjọ iwaju?
3 Ohun ti Jesu sọ tẹlee ṣapejuwe idaniloju wíwá rẹ̀ ọjọ iwaju. Pẹlu ọla-aṣẹ oun wi pe: “Loootọ ni mo wi fun yin, Ẹlomiran wà ninu awọn ti o duro nihin-in yii, ti kì yoo ri iku, titi wọn o fi ri Ọmọ eniyan ti yoo maa bọ̀ ni ijọba rẹ̀.” (Matteu 16:28) Awọn ọ̀rọ̀ wọnyi ní imuṣẹ ni ọjọ mẹfa lẹhin naa. Iran dídányanran ti Jesu ti a palarada ya awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ti wọn sunmọ ọn pẹkipẹki lẹnu. Niti gidi ni wọn rí oju Jesu ti ń tàn bi oorun ti aṣọ rẹ̀ sì ń kọ mọ̀nà. Ipalarada naa jẹ́ ìwòtẹ́lẹ̀ ògo ati Ijọba Kristi. Ẹ wo iru idaniloju afunnilokun nipa asọtẹlẹ Ijọba naa ti eyi jẹ́! Ẹ wo iru isunniṣe alagbara ti eyi jẹ́ fun awọn ọmọ-ẹhin naa lati yèkooro ni ero-inu!—2 Peteru 1:16-19.
Idi Ti O fi Jẹ́ Kanjukanju Lati Yekooro Ni Ero-Inu
4. Eeṣe ti awọn Kristian fi gbọdọ wà lojufo nipa tẹmi si wíwá rẹ̀?
4 Ni eyi ti o dín si ọdun kan lẹhin naa, a ri Jesu ti o jokoo sori Oke Olifi, lẹẹkan sii ni ìkọ̀kọ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Bi wọn ti bojuwo ilu-nla Jerusalemu, o ṣalaye ohun ti ami wíwàníhìn-ín rẹ̀ ọjọ iwaju yoo jẹ́ o sì kilọ lẹhin naa pe: “Nitori naa ẹ maa ṣọna: nitori ẹyin kò mọ wakati ti Oluwa yin yoo dé.” Awọn ọmọlẹhin rẹ gbọdọ wà lojufo nigba gbogbo nitori a kò mọ akoko wíwá rẹ̀. Wọn gbọdọ wà ni imuratan fun un lọ́jọ́kọ́jọ́.—Matteu 24:42.
5. Bawo ni a ṣe lè ṣapejuwe aini naa fun wíwà lojufo?
5 Ni iru ọ̀nà wíwá rẹ̀, Oluwa dabi olè. Oun ń baa lọ lati wi pe: “Ṣugbọn ki ẹyin ki o mọ eyi pe, baale ile iba mọ wakati naa ti olè yoo wá, iba maa ṣọna, oun kì bá ti jẹ́ ki a rúnlẹ̀ ile rẹ̀.” (Matteu 24:43) Fọ́léfọ́lé kan kìí ṣe ikede lati fi tó onile leti nigba ti oun yoo wá; lajori ohun ija rẹ̀ ni iyalẹnu. Nitori naa, onile gbọdọ wà lojufo nigba gbogbo. Bi o ti wu ki o ri, fun Kristian olódodo naa, iwalojufo alaiṣaarẹ kìí ṣe nitori ifojusọna onibẹru fun ọjọ iwaju kan. Kaka bẹẹ, a ń ru ú soke nipa ifojusọna onitara ti wíwá Kristi ninu ògo lati mú Ẹgbẹrun ọdun iṣakoso ti alaafia wá.
6. Eeṣe ti a fi gbọdọ yèkooro ni ero-inu?
6 Laika gbogbo ìṣọ́nà naa si, kò si ẹni ti yoo méfò ṣaaju lae ọjọ pato naa ti oun yoo wá. Jesu wi pe: “Nitori naa ki ẹyin ki o mura silẹ: nitori ni wakati ti ẹyin kò rò tẹlẹ ni Ọmọ eniyan yoo dé.” (Matteu 24:44) Fun idi yii aini fun ìyèkooro ero-inu wà. Bi Kristian kan bá nilati ronu pe ni ọjọ kan pato, Kristi kì yoo dé, boya iyẹn ni yoo jẹ́ ọjọ naa gan-an ti oun dé! Niti tootọ, awọn Kristian oluṣotitọ, ti wọn jẹ elero rere ni ìgbà ti o ti kọja ti fi ailabosi gbiyanju lati sọ asọtẹlẹ ìgbà ti opin yoo dé. Sibẹ, ikilọ Jesu ni a ti fi ẹ̀rí ijotiitọ rẹ̀ hàn leralera: “Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati naa, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ́n, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ̀ ọ́n, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo.”—Matteu 24:36.
7. Lati jẹ́ ọmọlẹhin Kristi, bawo ni a ṣe gbọdọ gbé igbesi-aye wa?
7 Nigba naa, ki ni a nilati pari ero si? Pe lati jẹ́ ọmọlẹhin Kristi, a nilati maa figba gbogbo gbagbọ ní akoko iwalaaye wa pe opin eto ogbologboo yii ti sunmọle.
8. Ki ni o ti jẹ́ ami ti a fi ń dá Kristian mọ̀ yàtọ̀ lati awọn ọjọ akọkọbẹrẹ isin Kristian?
8 Iru ihuwasi bẹẹ ti sábà maa ń jẹ ami ti a fi ń dá awọn Kristian mọ̀ yàtọ̀, gẹgẹ bi awọn opitan ayé ati awọn akẹkọọ Bibeli ti mọ̀ daju. Fun apẹẹrẹ, awọn olootu iwe The Translator’s New Testament, labẹ ọ̀rọ̀ naa “Day” (Ọjọ́) ninu akọsilẹ àlàyéọ̀rọ̀ wọn, sọ pe: “Awọn Kristian ti akoko ti a kọ M[ajẹmu] T[itun] gbé ni ifojusọna fun Ọjọ́ naa (iyẹn ni akoko naa) nigba ti a o mu ayé isinsinyi pẹlu gbogbo ibi ati iwa buruku rẹ̀ wá sopin ti Jesu yoo sì pada si ayé lati ṣedajọ gbogbo araye, ti yoo fi ayé alalaafia kan sipo ti yoo sì bẹrẹ ipo jíjẹ́ Oluwa rẹ̀ lori gbogbo ayé.” Iwe gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica tọka pe: “Imugbooro alailẹgbẹ kari ayé ti isin Kristian ní ibatan taarata pẹlu ifojusọna Kristian nipa akoko opin, ni iru ọ̀nà ti ifojusọna fun ipadabọ Kristi tí ó sunmọle. Ifojusọna Kristian nipa akoko opin naa kò wulẹ ní iyanhanhan lasan fun Ijọba Ọlọrun ti ń bọ̀ naa ninu.
Ohun Ti O Tumọsi Lati Yekooro Ni Ero-Inu
9. Bi o tilẹ jẹ pe diẹ ninu awọn ifojusọna Peteru nipa Messia kò tọna, eeṣe ti oun fi lè maa tẹsiwaju pẹlu igbẹkẹle?
9 Aposteli Peteru, ní nǹkan bii 30 ọdun lẹhin awọn ijiroro timọtimọ ti Jesu ní pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ti wọn sunmọ ọn julọ, kò rẹwẹsi ni diduro ki opin naa dé. Bi o tilẹ jẹ pe awọn ifojusọna tirẹ̀ ati ti awọn ọmọ-ẹhin ẹlẹgbẹ rẹ̀ lakọọkọ nipa Messia naa kò tọna, oun ní igbẹkẹle pe ifẹ ati agbara Jehofa mú kí imuṣẹ ireti wọn daju. (Luku 19:11; 24:21; Iṣe 1:6; 2 Peteru 3:9, 10) O sọ koko ọ̀rọ̀ kan ti a gbọ́ leralera jalẹ Iwe Mimọ Lede Griki nigba ti o sọ pe: “Opin ohun gbogbo ti sunmọle.” Lẹhin naa ni o rọ awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ pe: “Nitori naa ki ẹyin ki o yèkooro ni ero-inu, ki ẹ sì wà lojufo pẹlu èrò gbigba adura.”—1 Peteru 4:7, NW.
10. (a) Ki ni o tumọsi lati ni ero-inu yíyèkooro? (b) Ki ni riri awọn ọ̀ràn ni ọ̀nà ti wọn gbà bá ifẹ-inu Ọlọrun mu daradara ní ninu?
10 Jijẹ ẹn ti o “yèkooro ni ero-inu” kò tumọsi jíjẹ́ ọjafafa loju-iwoye ti ayé. Jehofa wi pe: “Emi ó pa ọgbọ́n awọn ọlọ́gbọ́n run, emi ó si sọ òye awọn olóye di asan.” (1 Korinti 1:19) Ọ̀rọ̀ naa ti Peteru lò lè tumọsi “lati jẹ́ ọlọ́kàn rírẹlẹ̀.” Ọkàn rírẹlẹ̀ nipa tẹmi yii ni a sopọ mọ́ ijọsin wá. Nitori naa, ni jíjẹ́ ẹni ti ero-inu rẹ̀ duro sojukan, awa ri awọn nǹkan ni ọ̀nà ti wọn gbà bá ifẹ-inu Jehofa tan daradara; a loye awọn ohun tí ó ṣe pataki ati eyi ti kò ṣe bẹẹ. (Matteu 6:33, 34) Bi o tilẹ jẹ pe opin naa sunmọle, a kò gbá wa danu sinu ọ̀nà igbesi-aye ti o kun fun igbokegbodo ẹlẹhanna; bẹẹ ni a kò dagunla si akoko ìgbà ti a ń gbé ninu rẹ̀. (Fiwe Matteu 24:37-39.) Kaka bẹẹ, a ń ṣakoso wa nipasẹ iwọntunwọnsi ati iwadeedee ninu ironu, itẹsi ifẹ-inu, ati ihuwa, eyi ti a fihàn lakọọkọ si Ọlọrun (“wà lojufo pẹlu ero gbigba adura”) ati lẹhin naa si awọn aladuugbo wa (“ni ifẹ ti o gbona laaarin ara yin”).—1 Peteru 4:7, 8.
11. (a) Ki ni o tumọsi lati “di titun ni ẹmi inu” wa? (b) Bawo ni ipá ero-inu titun kan ṣe ń ràn wá lọwọ lati ṣe awọn ipinnu ti o dara?
11 Jijẹ ẹni ti o yèkooro ni ero-inu ni ninu sisọ ti a ti sọ wa “di titun ni ẹmi inu” wa. (Efesu 4:23) Eeṣe ti a fi sọ wa di titun? Niwọn bi a ti jogun aipe a sì ń gbé ninu ayika ẹṣẹ, ero-inu wa ni a ń dari nipa itẹsi ti o tako ipo tẹmi. Ipá yẹn ń ti ironu ati isunniṣe lati ìgbà dé ìgbà si iha ọ̀nà onimọtara-ẹni nikan ati ẹmi ọrọ̀ alumọni. Fun idi yii, nigba ti ẹnikan bá di Kristian, oun nilo ipá titun kan, tabi ero-ori kan ti o gba iwájú, eyi ti yoo ti awọn ironu rẹ̀ si iha títọ́, iha ọ̀nà tẹmi, siha imuratan fun ifara-ẹni-rubọ. Nipa bẹẹ, nigba ti a bá gbé yiyan kan kalẹ, fun apẹẹrẹ, ninu ẹkọ-iwe, iṣẹ igbesi-aye, igbanisiṣẹ, eré-ìnàjú, eré-ìtura, aṣa iwọṣọ, tabi ohunkohun yoowu ki ó lè jẹ́, ìtẹ̀sí-ọkàn rẹ̀ akọkọ yoo jẹ́ lati gbé ọ̀ràn naa yẹwo lati oju-iwoye tẹmi dipo ti ara, ti o jẹ́ onimọtara-ẹni-nikan. Iṣarasihuwa ero-ori yii mú ki o tubọ rọrun lati pinnu awọn ọran pẹlu ero-inu ti o yèkooro ati pẹlu ìmọ̀ pe opin ti sunmọle.
12. Bawo ni a ṣe lè wà ni ipo ‘yíyèkooro ni igbagbọ’?
12 Yíyèkooro ni ero-inu tumọsi pe a wà ni ipo ilera tẹmi daradara. Bawo ni a ṣe lè wà ni ipo ‘yíyèkooro ni igbagbọ’? (Titu 2:2) A nilati fi iru awọn ounjẹ títọ́ bọ́ ero-inu wa. (Jeremiah 3:15) Ounjẹ otitọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti ń lọ deedee ti a fi iṣiṣẹ ẹmi mimọ rẹ̀ ṣetilẹhin fun yoo ṣeranwọ fun wa lati pa iwadeedee wa nipa tẹmi mọ́. Nitori naa, iṣedeedee ninu idakẹkọọ, ati bakan naa ninu iṣẹ-isin papa, adura, ati ibakẹgbẹpọ Kristian, ṣe pataki.
Bi Ero-Inu Yíyèkooro Ṣe Ń Daabobo Wá
13. Bawo ni ero-inu yíyèkooro ṣe ń daabobo wa kuro ninu ṣiṣe awọn aṣiṣe alailọgbọn?
13 Ero-inu yíyèkooro lè daabobo wá kuro lọwọ ṣiṣe aṣiṣe alailọgbọn ti o lè ná wa ní ìyè ainipẹkun wa. Bawo ni eyi ti ṣeeṣe? Aposteli Paulu sọrọ nipa “ofin inu.” Fun eniyan kan ti o ni ilera ninu igbagbọ, ofin ti inu yẹn ni a ń ṣakoso nipa ohun kan ti oun ni inu didun si, àní “ofin Ọlọrun.” Lotiitọ, “ofin ẹ̀ṣẹ̀” ń jagun pẹlu ofin ero-inu. Bi o ti wu ki o ri, Kristian naa lè jẹ aṣẹgun pẹlu iranlọwọ Jehofa.—Romu 7:21-25.
14, 15. (a) Awọn agbara idari meji wo ni wọn ń jijakadi lati dari ero-inu? (b) Bawo ni a ṣe lè bori ogun ero-inu naa?
14 Paulu ń tẹsiwaju nipa fifi iyatọ kan ti o muna hàn laaarin ero-inu tí ẹran-ara ẹlẹṣẹ ń dari, eyi ti ìfojúsùn rẹ̀ wà ninu ikẹra-ẹni-bajẹ, ati ero-inu ti ẹmi Ọlọrun ń dari, eyi ti ìfojúsùn rẹ̀ wà ninu igbesi-aye ifara-ẹni-rubọ ninu iṣẹ-isin Jehofa. Paulu kọwe ninu Romu 8:5-7 pe: “Nitori awọn ti o wà nipa ti ara, wọn a maa ro ohun ti ara; ṣugbọn awọn ti o wà nipa ti Ẹmi, wọn a maa ro ohun ti Ẹmi. Nitori ero ti ara iku ni; ṣugbọn ero ti Ẹmi ni ìyè ati alaafia: Nitori ero ti ara ọ̀tá ni si Ọlọrun: nitori kìí tẹriba fun ofin Ọlọrun, oun kò tilẹ lè ṣe é.”
15 Paulu, ni ẹsẹ 11, lẹhin naa ṣalaye bi ero-inu ti o fọwọsowọpọ pẹlu ẹmi mimọ ṣe bori ogun naa: “Ṣugbọn bi Ẹmi ẹni ti o jí Jesu dide kuro ninu oku bá ń gbé inu yin, ẹni ti o jí Kristi Jesu dide kuro ninu oku yoo fi Ẹmi rẹ̀ ti ń gbé inu yin, sọ ara kíkú yin di ààyè pẹlu.”
16. Ero-inu yíyèkooro ń daabobo wa kuro lọwọ awọn ohun ẹ̀tàn wo?
16 Nitori naa, nipa yíyèkooro ni ero-inu, a kì yoo dẹ wa wò nipa ẹ̀tàn ti o wà nibi gbogbo ni ayé yii, eyi ti o ní ninu iwa ikẹra-ẹni-bajẹ alailonka ninu oniruuru ọ̀nà fàájì, awọn ohun-ìní ti ara, ati iwa aitọ ti ibalopọ takọtabo. Ero-inu wa ti o yèkooro yoo sọ fun wa lati “sá fun agbere” ki a sì bọ́ lọwọ awọn iyọrisi rẹ̀ onijamba. (1 Korinti 6:18) Ero-inu wa yíyèkooro yoo sún wa lati fi ire Ijọba si ipo kìn-ín-ní yoo si daabobo ironu wa nigba ti a bá dán wa wò pẹlu awọn ifilọni iṣẹ igbesi-aye ti o le sọ ibatan wa pẹlu Jehofa di alailera.
17. Bawo ni arabinrin aṣaaju-ọna kan ṣe fi ero-inu yíyèkooro hàn nigba ti awọn ohun aigbọdọmaṣe nipa ọ̀ràn-ìnáwó dojukọ ọ́?
17 Fun apẹẹrẹ, ni orilẹ-ede olooru kan ni iha Guusu-ila-oorun Asia, ni arabinrin ọ̀dọ́ kan wà ẹni ti o fi ire Ijọba si ipo iwaju ninu ero-inu rẹ̀. Oun ti mu ifẹ fun iṣẹ-isin alakooko kikun dagba. Ni orilẹ-ede yẹn ọpọ iṣẹ beere fun ọjọ mẹfa tabi meje ti iṣẹ alakooko kikun. Lẹhin ti o gboyejade ni ile-ẹkọ yunifasiti, baba rẹ̀, ti kìí ṣe ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nigba naa, reti pe ki ó mu owó ti o pọ̀ wọle wá fun idile naa. Ṣugbọn niwọn bi o ti ni ọkàn-ìfẹ́ ti o lagbara lati ṣe aṣaaju-ọna, o ṣawari iṣẹ alaabọ akoko o sì bẹrẹ iṣẹ-isin aṣaaju-ọna. Eyi bí baba rẹ̀ ninu, ẹni ti o fi ìhàlẹ̀ sọ pe oun yoo kó awọn ẹrù rẹ̀ dàsí ìta. Nitori tẹ́tẹ́ títa, oun wà ninu gbèsè nla, ó sì reti pe ki ọmọbınrin rẹ̀ san awọn gbese rẹ̀ kuro nílẹ̀. Aburo rẹ̀ ọkunrin ń kẹkọọ ni ilẹ-ẹkọ yunifasiti, kò sì sí owó lati san owó ile-ẹkọ rẹ̀ nitori awọn gbese naa. Aburo rẹ̀ ọkunrin naa pinnu pe bi ẹgbọn oun obinrin bá ran oun lọwọ, oun yoo bojuto idile wọn nigba ti oun bá rí iṣẹ. Kò mọ eyi ti i bá ṣe nitori ifẹ rẹ̀ fun arakunrin rẹ̀ ati ifẹ rẹ̀ fun iṣẹ-isin aṣaajuọna. Lẹhin gbigbe ọ̀ràn naa yẹwo tiṣọratiṣọra, o pinnu lati maa bá iṣẹ aṣaaju-ọna lọ ki o sì wá iṣẹ miiran. Ni idahun si awọn adura rẹ̀, o rí iṣẹ daradara kan nibi ti kìí ti i ṣe pe oun lè ran idile rẹ̀ ati aburo rẹ ọkunrin lọwọ niti inawo nikan ni ṣugbọn lati tun maa baa lọ pẹlu ifẹ rẹ̀ akọkọ, iṣẹ-isin aṣaaju-ọna.
Wá Iranlọwọ Jehofa Nipa Pipa Ero-Inu Yíyèkooro Mọ́
18. (a) Eeṣe ti awọn eniyan kan fi lè nimọlara irẹwẹsi? (b) Awọn ẹsẹ iwe mimọ wo ni wọn lè tu awọn ti o rẹwẹsi ninu?
18 Ó lè ti jẹ ohun ti o ṣoro fun diẹ ninu awọn ọmọlẹhin Kristi lati di ero-inu yíyèkooro wọn mú. Sùúrù wọn lè maa dinku nitori pe eto-igbekalẹ awọn nǹkan ogbologboo yii ti ń pẹ́ ju bi wọn ti reti lọ. Wọn lè nimọlara irẹwẹsi nipa rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, opin naa yoo dé. Jehofa ṣeleri iyẹn. (Titu 1:2) Bẹẹ sì ni Paradise rẹ̀ ori ilẹ̀-ayé ti a ṣeleri yoo ti ri. Jehofa mu un daniloju. (Ìfihàn 21:1-5) Nigba ti ayé titun bá dé, “igi ìyè” yoo wà fun gbogbo awọn wọnni ti wọn bá pa ero-inu yíyèkooro wọn mọ́.—Owe 13:12.
19. Bawo ni a ṣe lè pa ero-inu yíyèkooro mọ́?
19 Bawo ni a ṣe lè pa ero-inu yíyèkooro mọ́? Wá iranlọwọ Jehofa. (Orin Dafidi 54:4) Sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí. Ẹ wo bi a ti layọ tó pe Jehofa ni ọkàn-ìfẹ́ si isunmọra pẹkipẹki wa! “Ẹ sunmọ Ọlọrun, oun ó sì sunmọ yin.” ni aposteli Jakọbu kọwe. (Jakọbu 4:8) Paulu wi pe: “Ẹ maa yọ̀ ninu Oluwa nigba gbogbo: mo si tun wi, Ẹ maa yọ̀. Ẹ jẹ ki ipamọra yin di mímọ̀ fun gbogbo eniyan. Oluwa ń bẹ nitosi. Ẹ maṣe aniyan ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹ̀bẹ̀ pẹlu idupẹ, ẹ maa fi ibeere yin hàn fun Ọlọrun. Ati alaafia Ọlọrun, ti o ju imọran gbogbo lọ, yoo ṣọ́ ọkàn ati ero yin ninu Kristi Jesu.” (Filippi 4:4-7) Nigba ti ẹrù-ìnira eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti ń ku lọ yii bá sì dabi eyi ti o ga ju lati maa baa niṣo ni gbigbé, jù wọn si ara Jehofa, oun funraarẹ yoo si mu ọ duro.—Orin Dafidi 55:22.
20. Ni awọn ipa-ọna wo ni a gbọdọ maa gbà tẹsiwaju, ni ibamu pẹlu 1 Timoteu 4:10?
20 Bẹẹni, opin ti sunmọle, nitori naa ẹ yèkooro ni ero-inu! Imọran daradara ni ó jẹ́ ní 1,900 ọdun sẹhin; imọran ṣiṣekoko ni lonii. Ẹ jẹ ki a maa tẹsiwaju lati lo ero-ori wa gbigbeṣẹ lati yin Jehofa bi oun ti ń baa lọ lati fi aabo tọ́ wá sọ́nà lọ sinu ayé titun rẹ̀.—1 Timoteu 4:10.
Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Ki ni ero-inu yíyèkooro?
◻ Eeṣe ti o fi jẹ́ kanjukanju to bẹẹ lati yèkooro ni ero-inu?
◻ Bawo ni a ṣe lè sọ wa di titun ninu ipá ti ń dari ero-inu wa?
◻ Ogun titi lọ wo ni awa gbọdọ jà ninu ero-inu wa?
◻ Bawo ni a ṣe lè pa ero-inu yíyèkooro mọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Sisunmọ Ọlọrun ninu adura ń ran wa lọwọ lati pa ero-inu yíyèkooro mọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ni jijẹ ẹni ti o yèkooro ni ero-inu, a kì yoo dẹ wa wò nipa awọn ẹ̀tàn ayé yii