“Ẹ Wà ní Ìmúratán”
1 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì tí Jésù sọ nípa òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, ó kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe jẹ́ kí àníyàn fún àwọn nǹkan tayé gbà wá lọ́kàn. (Mát. 24:36-39; Lúùkù 21:34, 35) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìpọ́njú ńlá lè bẹ̀rẹ̀ nígbàkigbà, ó pọn dandan pé ká kọbi ara sí ìṣílétí Jésù pé: “Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” (Mát. 24:44) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti wà ní ìmúratán?
2 Ṣíṣàì Gba Àníyàn àti Ìpínyà Ọkàn Láyè: Ọ̀kan lára àwọn ọ̀fìn tẹ̀mí tí a gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra fún ni “àwọn àníyàn ìgbésí ayé.” (Lúùkù 21:34) Ní àwọn ilẹ̀ kan, ipò òṣì, àìríṣẹ́ṣe àti owó ìgbọ́bùkátà tó ń ga sí i ń mú kó ṣòro láti ní àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémánìí nínú ìgbésí ayé. Ní àwọn ilẹ̀ mìíràn, tonílé tàlejò ló ń kó àwọn ohun ìní ti ara jọ. Bí àníyàn fún àwọn ohun ìní ti ara bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbà wá lọ́kàn, kò ní ṣeé ṣe fún wa láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 6:19-24, 31-33) Àwọn ìpàdé Kristẹni máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀. Ṣé góńgó rẹ ni láti máa lọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ?—Héb. 10:24, 25.
3 Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó ń fa ìpínyà ọkàn, tí wọ́n sì lè yára gba àkókò ṣíṣeyebíye mọ́ wa lọ́wọ́, kún inú ayé lónìí. Lílo kọ̀ǹpútà lè di ìdẹkùn béèyàn bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí wíwá ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kíka lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà àti fífèsì irú lẹ́tà bẹ́ẹ̀, ṣíṣe àwọn eré orí kọ̀ǹpútà tàbí àwọn eré mìíràn. A lè pàdánù àìmọye wákàtí nídìí tẹlifíṣọ̀n, sinimá, àwọn ìgbòkègbodò àfipawọ́, ìwé ayé àti eré ìdárayá, débi tí a ò fi ní ní àkókò àti okun tó pọ̀ tó láti máa lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Nígbà tó jẹ́ pé eré ìtura àti fàájì lè mú kí ara tù wá fún ìgbà díẹ̀, kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra ẹni àti pẹ̀lú ìdílé ẹni máa ń mú àǹfààní ayérayé wá. (1 Tím. 4:7, 8) Ǹjẹ́ o máa ń ra àkókò padà láti ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́?—Éfé. 5:15-17.
4 Àfi ká máa dúpẹ́ pé ètò àjọ Jèhófà ti ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìtọ́ni tẹ̀mí tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti “kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan . . . tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn”! (Lúùkù 21:36) Ǹjẹ́ ká máa lo àwọn ìpèsè wọ̀nyí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, ká sì “wà ní ìmúratán” kí ìgbàgbọ́ wa bàa lè jẹ́ “èyí tí a rí gẹ́gẹ́ bí okùnfà fún ìyìn àti ògo àti ọlá nígbà ìṣípayá Jésù Kristi.”—1 Pét. 1:7.