Ọlọ́run Kà Wọ́n Sẹ́ni Tó Yẹ Láti Ṣamọ̀nà Lọ Sáwọn Ìsun Omi Ìyè
“Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà . . . yóò máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, yóò sì máa ṣamọ̀nà wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè.”—ÌṢÍ. 7:17.
1. Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, iṣẹ́ wo ni Jésù sì gbé lé wọn lọ́wọ́?
Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN pe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ń bójú tó ohun ìní Kristi lórí ilẹ̀ ayé ní “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Nígbà tí Kristi bẹ “ẹrú” yìí wò lọ́dún 1918, ó rí i pé àwọn ẹni àmì òróró yìí jẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ pípèsè ‘oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.’ Inú Jésù tó jẹ́ Ọ̀gá wọn dùn, ó sì yàn wọ́n sípò “lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Ka Mátíù 24:45-47.) Èyí fi hàn pé, àwọn ẹni àmì òróró yìí ń lo ara wọn fún àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé kí wọ́n tó gba ogún wọn lọ́run.
2. Kí làwọn ohun ìní Jésù?
2 Ọ̀gá láṣẹ láti lo àwọn ohun ìní rẹ̀ bó ṣe fẹ́. Gbogbo ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ohun ìní Jésù Kristi, ẹni tí Jèhófà ti fi jẹ Ọba. Àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nínú ìran sì wà lára àwọn ohun ìní ọ̀gá náà. Bí Jòhánù ṣe ṣàpéjúwe àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà rèé: “Wò ó! ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, wọ́n wọ aṣọ funfun; imọ̀ ọ̀pẹ sì ń bẹ ní ọwọ́ wọn.”—Ìṣí. 7:9.
3, 4. Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ wo làwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ní?
3 Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí jẹ́ ara àwọn tí Jésù pè ní “àgùntàn mìíràn” tóun ní. (Jòh. 10:16) Ohun tí wọ́n ń retí ni láti gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Ó dá wọn lójú pé Jésù yóò “ṣamọ̀nà wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè. Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” Nítorí ohun tí wọ́n ń retí yìí, wọ́n ti “fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣí. 7:14, 17) Wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, nípa bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run ń wò wọ́n bí ẹni tó ní ‘aṣọ funfun.’ A sì polongo wọn ní olódodo àti pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run bíi ti Ábúráhámù.
4 Kò tán síbẹ̀ o, nítorí pé Ọlọ́run ń wo àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àgùntàn mìíràn tí iye wọn ń pọ̀ sí i yìí bí olódodo, wọ́n nírètí pé àwọn máa la ìparun ayé burúkú yìí já nígbà ìpọ́njú ńlá náà. (Ják. 2:23-26) Wọ́n dẹni tó lè sún mọ́ Jèhófà, kí wọ́n sì máa fojú sọ́nà láti la Amágẹ́dọ́nì já gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan. (Ják. 4:8; Ìṣí. 7:15) Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá kò máa dá tara wọn ṣe o, àmọ́ wọ́n ṣe tán láti ṣiṣẹ́ sin Ọba ọ̀run àtàwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù tó wà lórí ilẹ̀ ayé.
5. Ọ̀nà wo làwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ń gbà ti àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi lẹ́yìn?
5 Nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti dojú kọ àtakò, wọn yóò sì máa bá a nìṣó ní dídojúkọ àwọn àtakò tó túbọ̀ gbóná janjan. Ṣùgbọ́n, wọ́n lè gbára lé ìtìlẹ́yìn àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá alábàákẹ́gbẹ́ wọn. Báwọn tó jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró yìí ti ń dín kù, ńṣe làwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún. Kò sì ṣeé ṣe fáwọn ẹni àmì òróró yìí láti wà nínú gbogbo ìjọ Kristẹni tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] jákèjádò ayé kí wọ́n sì máa bójú tó wọn. Nítorí náà, ọ̀kan lára ìtìlẹ́yìn táwọn àgùntàn mìíràn ń ṣe fáwọn ẹni àmì òróró ni pé àwọn ọkùnrin tó kúnjú òṣùwọ̀n lára àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ń di alàgbà nínú ìjọ. Wọ́n ń bójú tó àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristẹni tí Jésù fi síkàáwọ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà.”
6. Báwo ni Aísáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìtìlẹ́yìn táwọn àgùntàn mìíràn ń ṣe fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró?
6 Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa báwọn àgùntàn mìíràn ṣe máa fi tinútinú ṣètìlẹ́yìn fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Ó kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Àwọn lébìrà Íjíbítì tí a kò sanwó fún àti àwọn olówò Etiópíà àti àwọn Sábéà, àwọn ọkùnrin gíga, àní wọn yóò wá bá ìwọ, tìrẹ ni wọn yóò sì dà. Wọn yóò máa rìn lẹ́yìn rẹ.’” (Aísá. 45:14) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni tó ní ìrètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé ń tọ àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ẹgbẹ́ ẹrú náà àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí rẹ̀ lẹ́yìn, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìdarí wọn. Gẹ́gẹ́ bíi “lébìrà tí a kò sanwó fún” àwọn àgùntàn mìíràn ń fi tọkàntọkàn lo okun àti ohun ìní wọn láti fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe jákèjádò ayé, èyí tí Kristi yàn fáwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣe 1:8; Ìṣí. 12:17.
7. Kí nìdí táwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá fi ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nísinsìnyí?
7 Báwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe ń ti àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin wọn lẹ́yìn lọ́nà yìí, ńṣe ni wọ́n ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè di ìpìlẹ̀ àwùjọ ẹ̀dá èèyàn tuntun tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì. Ìpìlẹ̀ náà gbọ́dọ̀ lágbára gan-an, àwọn tó jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run gbọ́dọ̀ múra tán, kí wọ́n sì fẹ́ láti tẹ̀ lé ìdarí Ọ̀gá wọn. Àwa Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láǹfààní láti fi hàn báyìí pé a óò wúlò fún Ọba náà, Kristi Jésù. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́, tá a sì ní ìgbàgbọ́ nísinsìnyí, èyí á fi hàn pé a máa lè ṣe ohunkóhun tí Ọba náà bá darí wa pé ká ṣe nínú ayé tuntun.
Àwọn Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Fi Hàn Pé Àwọn Ní Ìgbàgbọ́
8, 9. Ọ̀nà wo làwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ń gbà fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́?
8 Àwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti fi ìgbàgbọ́ wọn hàn lọ́pọ̀ ọ̀nà. Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n ń ti àwọn ẹni àmì òróró lẹ́yìn nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Ìkejì, wọ́n ń fi tinútinú tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí bá fún wọn.—Héb. 13:17; ka Sekaráyà 8:23.
9 Ìkẹ́ta, àwọn tó jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá ń ti àwọn arákùnrin wọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró lẹ́yìn, ní ti pé wọ́n ń gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó bá ìlànà òdodo Jèhófà mu. Wọ́n ń gbìyànjú láti ní àwọn ànímọ́ bí “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gál. 5:22, 23) Lóde òní, àwọn tó bá ní àwọn ànímọ́ yìí dípò kí wọ́n máa ṣe “àwọn iṣẹ́ tara” kì í sábà gbayì. Síbẹ̀, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ti pinnu pé àwọn ò ní lọ́wọ́ sí “àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò, ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, ìlara, mímu àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo, àti nǹkan báwọ̀nyí.”—Gál. 5:19-21.
10. Kí ni ìpinnu àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá?
10 Nítorí pé a jẹ́ ẹ̀dá aláìpé, kì í rọrùn fún wa láti ní àwọn ànímọ́ Kristẹni, láti yàgò fún àwọn iṣẹ́ ti ara àti láti má ṣe gbà kí ayé Sátánì sún wá ṣe ohun tí kò tọ́. Síbẹ̀, a ti pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì nítorí ibi tá a kù sí, àwọn àṣìṣe tá máa ń ṣe, tàbí àìlera ara sọ ìgbàgbọ́ wa di èyí tí kò lágbára tàbí kó bomi paná ìfẹ́ wa fún Jèhófà. A mọ̀ pé Jèhófà yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn ni ìlérí tó ṣe pé òun á dáàbò bo àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà la ìpọ́njú ńlá já.
11. Àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wo ni Sátánì ti lò bó ṣe ń gbìyànjú láti bomi paná ìgbàgbọ́ àwa Kristẹni?
11 Síbẹ̀síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò ní gbogbo ìgbà, torí a mọ̀ pé Èṣù gan-an ni olórí ọ̀tá wa, kò sì tíì padà lẹ́yìn wa. (Ka 1 Pétérù 5:8.) Ó ti gbìyànjú láti lo àwọn apẹ̀yìndà àtàwọn míì kí wọ́n lè mú ká rò pé ẹ̀kọ́ èké lohun tá a gbà gbọ́. Àmọ́ pàbó ni ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ yìí ń já sí. Bákan náà, inúnibíni lè mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà lọ sílẹ̀ láwọn àkókò kan o, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà ńṣe ló ń mú kí ìgbàgbọ́ àwọn tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí túbọ̀ lágbára. Nítorí náà, Sátánì sábà máa ń lo ohun kan tó rò pé ó lè paná ìgbàgbọ́ wa, ìyẹn ni ìrẹ̀wẹ̀sì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nípa ewu yìí pé: “Ẹ ronú jinlẹ̀-jinlẹ̀ nípa [Kristi] ẹni tí ó ti fara da irúfẹ́ òdì ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ láti ẹnu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lòdì sí ire ara wọn.” Kí nìdí? Ó ní: “Kí ó má bàa rẹ̀ yín, kí ẹ sì rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn yín.”—Héb. 12:3.
12. Báwo ni ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe ń fún àwọn tó ní ìrẹ̀wẹ̀sì lókun?
12 Ǹjẹ́ ó tíì ṣe ọ́ rí bíi pé kó o má sin Jèhófà mọ́? Àbí o máa ń rò ó nígbà míì pé kò sóhun tó o máa ń mọ̀ ọ́n ṣe? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe jẹ́ kí Sátánì lo èrò rẹ yìí láti mú kó o fi Jèhófà sílẹ̀ o. Máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, máa gbàdúrà látọkànwá, máa lọ sí ìpàdé déédéé, kó o sì máa bá àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ kẹ́gbẹ́. Àwọn nǹkan yìí á fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, wọn ò sì ní jẹ́ kó o ‘rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn rẹ.’ Jèhófà ti ṣèlérí fáwọn tó ń sìn ín pé òun yóò mú kí wọ́n jèrè agbára padà, àwọn ìlérí rẹ̀ sì dájú. (Ka Aísáyà 40:30, 31.) Máa kópa déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni. Má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun tí kò ní láárí gba àkókò rẹ, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o máa fi àkókò yìí ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Tó o bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ìrẹ̀wẹ̀sì ò ní lè borí rẹ.—Gál. 6:1, 2.
Wọ́n Tinú Ìpọ́njú Ńlá Bọ́ Sínú Ayé Tuntun
13. Iṣẹ́ wo làwọn tó bá la Amágẹ́dọ́nì já máa ṣe?
13 Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn aláìṣòdodo tó jíǹde yóò ní láti gba ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà. (Ìṣe 24:15) Wọn yóò ní láti mọ̀ nípa ẹbọ ìràpadà Jésù, yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á ní láti kọ́ nípa bí wọ́n á ṣe lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà náà kí wọ́n bàa lè jàǹfààní nínú rẹ̀. Wọ́n á ní láti kọ àwọn ẹ̀kọ́ èké tí wọ́n ti gbà gbọ́ àti irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀ sílẹ̀. Wọ́n ní láti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. (Éfé. 4:22-24; Kól. 3:9, 10) Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ńlá làwọn àgùntàn mìíràn tó bá la Amágẹ́dọ́nì já máa ṣe! Ayọ̀ àwọn àgùntàn mìíràn á mà pọ̀ o bí wọ́n á ṣe ṣiṣẹ́ sin Jèhófà lọ́nà yìí, láìsí pákáǹleke àtohun tá máa pín ọkàn wọn níyà bó ṣe wà nínú ayé burúkú yìí!
14, 15. Ṣàlàyé báwọn olódodo tó jíǹde àtàwọn tó la ìpọ́njú ńlá já ṣe máa kọ́ ara wọn lẹ́kọ̀ọ́.
14 Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó kú ṣáájú ìgbà tí Jésù wá ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé yóò ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti kọ́. Wọn yóò mọ ẹni tí í ṣe Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, tí wọ́n fojú sọ́nà láti rí, àmọ́ tí wọn ò rí kí wọ́n tó kú. Nígbà tí wọ́n wà láyé, wọ́n ti fi hàn pé àwọn ń fẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ àwọn sọ́nà. Ẹ wo bí inú àwọn tó bá la Amágẹ́dọ́nì já yóò ti dùn tó láti ran àwọn èèyàn yìí lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, inú wọn yóò dùn láti ṣàlàyé fún Dáníẹ́lì nípa bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó kọ, àmọ́ tí òun fúnra rẹ̀ kò lóye rẹ̀ ṣe ní ìmúṣẹ!—Dáníẹ́lì 12:8, 9.
15 Dájúdájú, àwọn tó jíǹde yóò rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ lọ́dọ̀ wa, àwa náà yóò sì béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè lọ́wọ́ wọn. Wọn yóò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àmọ́ tí kò ṣàlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ fún wa. Ẹ wo bínú wa yóò ṣe dùn tó láti mọ̀ sí i nípa Jésù, nígbà tí Jòhánù Oníbatisí tó jẹ́ ìbátan rẹ̀ bá ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ fún wa nípa rẹ̀! Àwọn ohun tá a máa kọ́ látọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí olóòótọ́ wọ̀nyí á túbọ̀ jẹ́ ká ní òye tó jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ju ti ìsinsìnyí lọ. Gbogbo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti kú, títí kan àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tó bá kú ní ìkẹyìn ọjọ́ yìí, yóò ní “àjíǹde tí ó sàn jù.” Inú ayé tí Sátánì ń darí yìí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà. Ayọ̀ wọn yóò pọ̀ láti máa sin Jèhófà nìṣó láwọn àyíká ẹlẹ́wà nínú ayé tuntun!—Héb. 11:35; 1 Jòh. 5:19.
16. Bí àsọtẹ́lẹ̀ ṣe sọ, kí làwọn nǹkan tí yóò ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́ Ìdájọ́?
16 Tó bá tákòókò kan ní Ọjọ́ Ìdájọ́, Ọlọ́run yóò ṣí àkájọ ìwé kan sílẹ̀. Ohun tó wà nínú ìwé yìí àti Bíbélì ni yóò lò láti fi ṣèdájọ́ àwọn tó wà láàyè ní ti bóyá wọ́n yẹ láti ní ìyè àìnípẹ̀kun tàbí wọn ò yẹ. (Ka Ìṣípayá 20:12, 13.) Nígbà tí Ọjọ́ Ìdájọ́ bá fi máa parí, ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò ti ní àkókò tó pọ̀ tó láti fi hàn bóyá òun gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ láyé àti lọ́run tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ǹjẹ́ wọ́n á fara wọn sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n sì jẹ́ kí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà darí wọn lọ sí “ìsun omi ìyè”? Àbí wọn yóò kọ̀ láti fi ara wọn sábẹ́ rẹ̀? (Ìṣí. 7:17; Aísá. 65:20) Nígbà yẹn, gbogbo èèyàn tó wà láyé yóò ti láǹfààní láti ṣèpinnu fúnra wọn láìjẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n jogún tàbí ayé burúkú yìí dí wọn lọ́wọ́. Kò ní sí ẹ̀dá kankan táá lè ta ko ìdájọ́ ìkẹyìn tí Jèhófà máa ṣe yìí. Kìkì àwọn ẹni burúkú ni yóò pa run títí láé.—Ìṣí. 20:14, 15.
17, 18. Kí ló ń mú káwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn máa fayọ̀ retí Ọjọ́ Ìdájọ́?
17 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lóde òní ń fojú sọ́nà fún Ọjọ́ Ìdájọ́ nígbà tí wọ́n máa ṣàkóso, nítorí Ọlọ́run ti kà wọ́n yẹ láti gba Ìjọba kan. Àǹfààní ńlá lèyí mà jẹ́ fún wọn o! Ohun tí wọ́n ń retí yìí ló mú kí wọ́n máa ṣe ohun tí Pétérù sọ fáwọn arákùnrin wọn ní ọ̀rúndún kìíní, ó ní: “Ẹ túbọ̀ máa sa gbogbo ipá yín láti mú pípè àti yíyàn yín dájú fún ara yín; nítorí bí ẹ bá ń bá a nìṣó ní ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ kì yóò kùnà lọ́nàkọnà láé. Ní ti tòótọ́, nípa báyìí ni a ó pèsè ìwọlé fún yín lọ́pọ̀ jaburata sínú ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.”—2 Pét. 1:10, 11.
18 Àwọn àgùntàn mìíràn ń bá àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin wọn yọ̀ fún ohun tí wọ́n ń fojú sọ́nà fún yìí. Wọ́n sì ti pinnu láti máa tì wọ́n lẹ́yìn. Nítorí pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run nísinsìnyí, wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Lọ́jọ́ ìdájọ́, inú àwọn àgùntàn mìíràn yóò máa dùn láti fi tinútinú kọ́wọ́ ti àwọn ètò tí Ọlọ́run ń ṣe bí Jésù ṣe ń darí wọn lọ sí ìsun omi ìyè. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọn yóò dẹni tí a kà yẹ láti jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé títí láé!—Róòmù 8:20, 21; Ìṣí. 21:1-7.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun ìní Jésù?
• Báwo làwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe ń ti àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin wọn lẹ́yìn?
• Àǹfààní wo làwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ń gbádùn báyìí, kí ni wọ́n sì ń fojú sọ́nà fún?
• Kí lèrò rẹ nípa Ọjọ́ Ìdájọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Kí lò ń retí láti kọ́ lọ́dọ̀ àwọn olóòótọ́ tó jíǹde?