ORÍ 112
Ẹ̀kọ́ Tí Àpèjúwe Wúńdíá Mẹ́wàá Kọ́ Wa
JÉSÙ SỌ ÀPÈJÚWE NÍPA WÚŃDÍÁ MẸ́WÀÁ
Jésù ti ń dáhùn ìbéèrè táwọn àpọ́sítélì ẹ̀ bi í nípa àmì tó máa fi hàn pé ó ti wà níhìn-ín àti àmì ìparí ètò àwọn nǹkan. Orí ọ̀rọ̀ yẹn náà ni wọ́n ṣì wà, ó wá sọ àpèjúwe míì fún wọn láti gbà wọ́n níyànjú. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó bá wà láyé nígbà tí Jésù bá wà níhìn-ín ló máa rí bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ń ṣẹ.
Ó bẹ̀rẹ̀ àpèjúwe náà báyìí, ó ní: “A lè fi Ìjọba ọ̀run wé wúńdíá mẹ́wàá tí wọ́n mú fìtílà wọn, tí wọ́n sì jáde lọ pàdé ọkọ ìyàwó. Márùn-ún nínú wọ́n jẹ́ òmùgọ̀, márùn-ún sì jẹ́ olóye.”—Mátíù 25:1, 2.
Kì í ṣe ohun tí Jésù ń sọ ni pé ìdajì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó máa jogún Ìjọba ọ̀run á ya òmùgọ̀, tí ìdajì tó kù á wá jẹ́ olóye. Àmọ́ ohun tó ń sọ ni pé ọmọ ẹ̀yìn kọ̀ọ̀kan tó bá máa jogún Ìjọba náà máa ní láti pinnu bóyá òun máa wà lójúfò, àbí òun máa jẹ́ kí nǹkan míì gba òun lọ́kàn. Síbẹ̀, ọkàn Jésù balẹ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ òun máa jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀, Baba òun á sì bù kún wọn.
Nínú àpèjúwe yẹn, àwọn wúńdíá mẹ́wẹ̀ẹ̀wá máa lọ pàdé ọkọ ìyàwó náà, kí wọ́n lè kí i káàbọ̀, kí wọ́n sì jọ máa bá ètò ìgbéyàwó lọ. Tí ọkọ ìyàwó náà bá dé, àwọn wúńdíá yẹn máa tan fìtílà wọn kí ojú ọ̀nà lè mọ́lẹ̀, kí wọ́n sì yẹ́ ọkọ ìyàwó sí bó ṣe ń mú ìyàwó rẹ̀ lọ sí yàrá tó ti ṣètò. Àmọ́ kí ló wá ṣẹlẹ̀?
Jésù ṣàlàyé pé: “Àwọn òmùgọ̀ mú fìtílà wọn, àmọ́ wọn ò gbé òróró dání, ṣùgbọ́n àwọn olóye rọ òróró sínú ìgò wọn, wọ́n sì gbé fìtílà wọn dání. Nígbà tí ọkọ ìyàwó ò tètè dé, gbogbo wọn tòògbé, wọ́n sì sùn lọ.” (Mátíù 25:3-5) Ọkọ ìyàwó ò tètè dé bí wọ́n ṣe rò. Ó jọ pé ó pẹ́ gan-an kó tó dé, torí àwọn wúńdíá yẹn sùn lọ níbi tí wọ́n ti ń dúró dè é. Ó ṣeé ṣe kíyẹn rán àwọn àpọ́sítélì létí ohun tí Jésù sọ fún wọn nípa ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní ilé ọlá, tó rìnrìn àjò tó sì “pa dà dé lẹ́yìn tó gba agbára láti jọba.”—Lúùkù 19:11-15.
Jésù wá ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó dé, ó ní: “Ni ariwo bá sọ láàárín òru pé: ‘Ọkọ ìyàwó ti dé! Ẹ jáde lọ pàdé rẹ̀.’” (Mátíù 25:6) Ṣé àwọn wúńdíá yẹn múra sílẹ̀, ṣé wọ́n sì wà lójúfò?
Jésù ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ, ó ní: “Gbogbo àwọn wúńdíá náà bá dìde, wọ́n sì tún fìtílà wọn ṣe. Àwọn òmùgọ̀ sọ fún àwọn olóye pé, ‘Ẹ fún wa ní díẹ̀ nínú òróró yín, torí pé àwọn fìtílà wa ti fẹ́ kú.’ Àwọn olóye dá wọn lóhùn pé: ‘Ó ṣeé ṣe kó má tó àwa àti ẹ̀yin. Torí náà, ẹ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń tà á, kí ẹ sì ra tiyín.’”—Mátíù 25:7-9.
Àwọn wúńdíá márùn-ún tí wọ́n jẹ́ òmùgọ̀ yẹn ò wà lójúfò, wọn ò sì múra sílẹ̀ de ọkọ ìyàwó. Òróró inú fìtílà wọn ò tó, wọ́n máa ní láti lọ wá òróró sí i. Jésù wá sọ pé: “Bí wọ́n ṣe ń lọ rà á, ọkọ ìyàwó dé. Àwọn wúńdíá tí wọ́n ti ṣe tán bá a wọlé síbi àsè ìgbéyàwó náà, a sì ti ilẹ̀kùn. Lẹ́yìn náà, àwọn wúńdíá yòókù dé, wọ́n ní, ‘Ọ̀gá, Ọ̀gá, ṣílẹ̀kùn fún wa!’ Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Kí n sọ òótọ́ fún yín, mi ò mọ̀ yín rí.’” (Mátíù 25:10-12) Ó mà ṣe o, ẹ wo ibi tọ́rọ̀ wọn já sí torí pé wọn ò múra sílẹ̀, wọn ò sì wà lójúfò!
Ó yé àwọn àpọ́sítélì pé Jésù ni ọkọ ìyàwó inú àpèjúwe yẹn dúró fún, torí ó tiẹ̀ ti fi ara ẹ̀ wé ọkọ ìyàwó tẹ́lẹ̀. (Lúùkù 5:34, 35) Àwọn wo wá ni àwọn wúńdíá tó jẹ́ olóye yẹn? Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa “agbo kékeré” tó máa jogún Ìjọba náà, ó sọ pé: “Ẹ múra, kí ẹ sì wà ní sẹpẹ́, kí ẹ jẹ́ kí àwọn fìtílà yín máa jó.” (Lúùkù 12:32, 35) Torí náà, ó yé àwọn àpọ́sítélì pé àwọn ló dúró fún àwọn wúńdíá tí Jésù ń sọ yẹn. Àmọ́ ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fẹ́ fi àpèjúwe yìí kọ́ wọn?
Jésù fẹ́ kí ohun tí òun ń sọ yé wọn. Ó parí àpèjúwe tó ń sọ, ó ní: “Torí náà, ẹ máa ṣọ́nà, torí pé ẹ ò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.”—Mátíù 25:13.
Ó hàn pé Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ olóòótọ́ “máa ṣọ́nà” de ìgbà tí òun máa dé. Wọ́n gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀, kí wọ́n sì wà lójúfò bíi tàwọn wúńdíá márùn-ún tó jẹ́ olóye yẹn, kó lè jẹ́ pé tí Jésù bá dé, ìbùkún tó ṣeyebíye tí wọ́n ń retí á tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́.