ORÍ 113
Ẹ̀kọ́ Tí Àpèjúwe Tálẹ́ńtì Kọ́ Wa
JÉSÙ SỌ ÀPÈJÚWE TÁLẸ́ŃTÌ
Jésù àti mẹ́rin lára àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ ṣì jọ wà lápá ibì kan náà lórí Òkè Ólífì, ó wá sọ àpèjúwe míì fún wọn. Lọ́jọ́ mélòó kan sẹ́yìn, nígbà tó ṣì wà ní Jẹ́ríkò, ó sọ àpèjúwe mínà fún wọn kí wọ́n lè rí i pé Ìjọba yẹn ṣì máa pẹ́ kó tó dé. Àpèjúwe tó sọ lọ́tẹ̀ yìí náà jọra pẹ̀lú èyí tó sọ tẹ́lẹ̀. Àpèjúwe yìí wà lára ohun tó fi dáhùn ìbéèrè táwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bi í nípa àmì tó máa fi hàn pé ó ti wà níhìn-ín àti àmì ìparí ètò àwọn nǹkan. Ó jẹ́ kí wọ́n rí i pé wọ́n gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tóun fẹ́ gbé fún wọn.
Jésù bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ṣe ló dà bí ọkùnrin kan tó fẹ́ rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tó wá pe àwọn ẹrú rẹ̀, tó sì fa àwọn ohun ìní rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́.” (Mátíù 25:14) Nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe tẹ́lẹ̀, ó fi ara ẹ̀ wé ọkùnrin tó rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn “kó lè lọ gba agbára láti jọba,” torí náà, ó tètè yé àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé òun náà tún ni “ọkùnrin” tó ń sọ nínú àpèjúwe yìí.—Lúùkù 19:12.
Kí ọkùnrin inú àpèjúwe yẹn tó rìnrìn àjò, ó fi àwọn ohun ìní rẹ̀ tó ṣeyebíye síkàáwọ́ àwọn ẹrú rẹ̀. Láàárín ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ló gbájú mọ́, ó sì dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe iṣẹ́ yìí. Ní báyìí tí Jésù ti ń lọ, ọkàn ẹ̀ balẹ̀ pé wọ́n á ṣe iṣẹ́ yìí bó ṣe ní kí wọ́n ṣe é.—Mátíù 10:7; Lúùkù 10:1, 8, 9; fi wé Jòhánù 4:38; 14:12.
Báwo ni ọkùnrin inú àpèjúwe yẹn ṣe pín àwọn ohun ìní rẹ̀? Jésù sọ pé: “Ó fún ọ̀kan ní tálẹ́ńtì márùn-ún, ó fún òmíràn ní méjì, òmíràn ní ọ̀kan, ó fún kálukú bí agbára rẹ̀ ṣe mọ, ó sì lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.” (Mátíù 25:15) Kí làwọn ẹrú yìí máa wá fi tálẹ́ńtì náà ṣe? Ṣé wọ́n máa fọwọ́ pàtàkì mú ohun tí ọ̀gá wọn fi síkàáwọ́ wọn? Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé:
“Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹni tó gba tálẹ́ńtì márùn-ún lọ, ó fi ṣòwò, ó sì jèrè márùn-ún sí i. Bákan náà, ẹni tó gba méjì jèrè méjì sí i. Àmọ́ ẹrú tó gba ẹyọ kan ṣoṣo lọ, ó gbẹ́ ilẹ̀, ó sì fi owó ọ̀gá rẹ̀ pa mọ́.” (Mátíù 25:16-18) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí ọ̀gá bá dé?
Jésù ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ, ó ní: “Lẹ́yìn tó ti pẹ́ gan-an, ọ̀gá àwọn ẹrú yẹn dé, wọ́n sì jọ yanjú ọ̀rọ̀ owó.” (Mátíù 25:19) Àwọn ẹrú méjì àkọ́kọ́ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe, ‘bí agbára wọn ṣe mọ.’ Wọ́n ṣiṣẹ́ kára, wọn ò sì ṣọ̀lẹ, kódà wọ́n tún jèrè kún ohun tí ọ̀gá wọn fún wọn. Ẹni tó gba tálẹ́ńtì márùn-ún jèrè márùn-ún sí i, ẹni tó sì gba méjì náà jèrè méjì sí i. (Láyé ìgbà yẹn, nǹkan bí ọdún mọ́kàndínlógún (19) lẹnì kan máa fi ṣiṣẹ́ kó tó lè rí owó tó máa tó tálẹ́ńtì kan.) Ohun kan náà ni ọ̀gá wọn sọ nígbà tó ń yin àwọn méjèèjì, ó ní: “O káre láé, ẹrú rere àti olóòótọ́! O jẹ́ olóòótọ́ lórí ohun díẹ̀. Màá fi ohun tó pọ̀ síkàáwọ́ rẹ. Bọ́ sínú ayọ̀ ọ̀gá rẹ.”—Mátíù 25:21.
Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ fún ẹrú tó gba tálẹ́ńtì kan. Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé: “Ọ̀gá, ẹni tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn ni mo mọ̀ ọ́ sí, o máa ń kárúgbìn níbi tí o ò fúnrúgbìn sí, o sì máa ń kó ọkà jọ níbi tí o ò ti fẹ́ ọkà. Torí náà, ẹ̀rù bà mí, mo sì lọ fi tálẹ́ńtì rẹ pa mọ́ sínú ilẹ̀. Wò ó, gba nǹkan rẹ.” (Mátíù 25:24, 25) Kò tọ́jú owó náà pa mọ́ sí báǹkì kí ọ̀gá ẹ̀ tiẹ̀ lè rí èrè díẹ̀ jẹ lórí ẹ̀. Torí náà, kò wá ire ọ̀gá ẹ̀.
Abájọ tí ọ̀gá ẹ̀ fi pè é ní “ẹrú burúkú tó ń lọ́ra.” Ṣe ni wọ́n gba ohun tó wà lọ́wọ́ rẹ̀, wọ́n sì fún ẹrú míì tó ṣe tán láti fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́. Ọ̀gá náà wá fi ìlànà kan lélẹ̀, ó ní: “Gbogbo ẹni tó bá ní, a máa fi kún èyí tó ní, ó sì máa ní ọ̀pọ̀ yanturu. Àmọ́ ẹni tí kò bá ní, a máa gba èyí tó ní pàápàá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”—Mátíù 25:26, 29.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ló wà fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nínú àpèjúwe kan ṣoṣo tó sọ yìí. Wọ́n rí i pé nǹkan kékeré kọ́ ni àǹfààní tó ṣeyebíye tí Jésù fi síkàáwọ́ wọn, ìyẹn pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Ó sì retí pé kí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú àǹfààní yìí. Jésù ò retí pé ohun kan náà ni gbogbo wọn máa ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù tó ní kí wọ́n ṣe. Bó ṣe sọ nínú àpèjúwe tó ṣe, kálukú máa ṣe “bí agbára rẹ̀ ṣe mọ.” Àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé inú Jésù máa dùn sí èyí tó bá ń “lọ́ra” nínú wọn, tí ò sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti wá ire Ọ̀gá rẹ̀.
Ẹ wo bínú àwọn àpọ́sítélì ṣe máa dùn tó nígbà tí Jésù fi dá wọn lójú pé: “Gbogbo ẹni tó bá ní, a máa fi kún èyí tó ní”!