ORÍ 123
Jésù Gbàdúrà Nígbà Tí Ẹ̀dùn Ọkàn Bá A
MÁTÍÙ 26:30, 36-46 MÁÀKÙ 14:26, 32-42 LÚÙKÙ 22:39-46 JÒHÁNÙ 18:1
JÉSÙ LỌ SÍNÚ ỌGBÀ GẸ́TÍSÉMÁNÌ
ÒÓGÙN RẸ̀ DÀ BÍ Ẹ̀JẸ̀ TÓ Ń KÁN SÍLẸ̀
Lẹ́yìn tí Jésù gbàdúrà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́, ‘wọ́n kọrin ìyìn, wọ́n sì lọ sí Òkè Ólífì.’ (Máàkù 14:26) Wọ́n lọ sápá ìlà oòrùn, níbi ọgbà kan tí Jésù sábà máa ń lọ, ìyẹn ọgbà Gẹ́tísémánì.
Ọgbà yìí tura gan-an ni, àwọn igi ólífì sì wà níbẹ̀. Nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ débẹ̀, Jésù fi mẹ́jọ lára wọn síbì kan, bóyá níbi àbáwọlé ọgbà náà. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ jókòó síbí, mo fẹ́ lọ sí ọ̀hún yẹn lọ gbàdúrà.” Jésù wá wọnú ọgbà náà, ó mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù dání. Ìdààmú bá a gan-an, ó wá sọ fún àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pé: “Ẹ̀dùn ọkàn bá mi gan-an, àní títí dé ikú. Ẹ dúró síbí, kí ẹ sì máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”—Mátíù 26:36-38.
Jésù wá rìn síwájú díẹ̀, lẹ́yìn náà “ó wólẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà.” Kí ló ń bá Ọlọ́run sọ nírú àkókò tó nira yẹn? Ó gbàdúrà pé: “Bàbá, ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ọ; mú ife yìí kúrò lórí mi. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tí èmi fẹ́, àmọ́ ohun tí ìwọ fẹ́.” (Máàkù 14:35, 36) Kí ló ní lọ́kàn ná? Ṣé kò fẹ́ ra àwa èèyàn pa dà mọ́ ni? Rárá o!
Àtìgbà tí Jésù ti wà lọ́run ló ti ń rí bí ìjọba Róòmù ṣe máa ń fìyà jẹ àwọn èèyàn, tí wọ́n sì ń pa wọ́n nípa ìkà. Ní báyìí tó ti di èèyàn, ó dájú pé ó ti mọ bí ìyà ṣe ń rí lára, ó sì mọ̀ pé ìyà kì í ṣomi ọbẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù ló gbà á lọ́kàn, ohun tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ ló ń rò. Ẹ̀dùn ọkàn bá a bó ṣe ń rò ó pé wọ́n máa pa òun bí ọ̀daràn, ìyẹn sì lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ Baba òun. Ní wákàtí díẹ̀ sígbà yẹn, wọ́n máa fẹ̀sùn kàn án pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, wọ́n sì máa gbé e kọ́ sórí òpó igi.
Lẹ́yìn tí Jésù ti gbàdúrà fún ọ̀pọ̀ àkókò, ó pa dà sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì mẹ́ta náà, ó sì bá wọn tí wọ́n ń sùn. Ó wá sọ fún Pétérù pé: “Ṣé ẹ ò wá lè ṣọ́nà pẹ̀lú mi fún wákàtí kan péré ni? Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.” Àmọ́ Jésù mọ̀ pé ó ti rẹ àwọn àpọ́sítélì yẹn àti pé ilẹ̀ ti ṣú. Torí náà, ó sọ pé: “Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń fẹ́, àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.”—Mátíù 26:40, 41.
Lẹ́yìn tí Jésù bá wọn sọ̀rọ̀ tán, ó tún pa dà lọ gbàdúrà, ó sì ń bẹ Ọlọ́run pé kó mú “ife yìí” kúrò lórí òun. Dípò táwọn àpọ́sítélì yẹn á fi máa gbàdúrà kí wọ́n má bàa kó sínú ìdẹwò, orí oorun ni Jésù tún bá wọn nígbà tó pa dà sọ́dọ̀ wọn. Kódà nígbà tó ń bá wọn sọ̀rọ̀, “wọn ò mọ èsì tí wọ́n máa fún un.” (Máàkù 14:40) Jésù wá pa dà lọ nígbà kẹta, ó wólẹ̀, ó sì ń gbàdúrà.
Ìdààmú bá a gan-an, ó ń ronú nípa bí wọ́n ṣe máa pa òun bí ìgbà tí wọ́n pa ọ̀daràn, tíyẹn sì máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. Àmọ́ Jèhófà ò fi í sílẹ̀, ó gbọ́ àdúrà rẹ̀, kódà ìgbà kan wà tí Jèhófà rán áńgẹ́lì kan sí i kó lè fún un lókun. Síbẹ̀, Jésù ò yéé rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Baba rẹ̀, ṣe ló “túbọ̀ ń gbàdúrà taratara.” Ká sòótọ́, onírúurú nǹkan ló máa wà lọ́kàn Jésù. Ohun tó bá ṣe ló máa pinnu bóyá ó máa pa dà wà láàyè lẹ́yìn tí wọ́n bá pa á, ìyẹn ló sì máa pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹni tó bá gba Ọlọ́run gbọ́. Ìdààmú bá a débi pé ṣe ni ‘òógùn rẹ̀ dà bí ẹ̀jẹ̀ tó ń kán sílẹ̀.’—Lúùkù 22:44.
Nígbà tí Jésù tún máa pa dà sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́ẹ̀kẹta, orí oorun ló tún bá wọn. Ó wá sọ fún wọn pé: “Ní irú àkókò yìí, ẹ̀ ń sùn, ẹ sì ń sinmi! Ẹ wò ó! Wákàtí náà ti dé tán tí wọ́n máa fi Ọmọ èèyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká lọ. Ẹ wò ó! Ẹni tó máa dà mí ti dé tán.”—Mátíù 26:45, 46.