Jésù Jẹ́ Ká Mọ Bí Ìgbésí Ayé Wa Ṣe Lè Ládùn
‘Máa ṣe gẹ́gẹ́ bí Kristi ti ṣe.’—1 Jòhánù 2:6, Bíbélì Mímọ́.
GẸ́GẸ́ bí a ti sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ìgbé ayé tó ládùn ni Jésù gbé. Tí àwa náà bá fẹ́ kí ìgbésí ayé wa ládùn, ó yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ká sì fetí sí ìmọ̀ràn rẹ̀.
Kódà, ohun tí Jèhófà ń rọ̀ wá pé ká ṣe gan-an nìyẹn, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a fà yọ lókè. Tí a bá fẹ́ máa ṣe bí Jésù ti ṣe, àfi ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wa. Tí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, inú Ọlọ́run máa dùn sí wa, ìgbésí ayé wa á sì dára.
Jésù kọ́ wa ní àwọn ìlànà tó máa jẹ́ ká lè ṣe gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀ ti ṣe. Jésù sọ díẹ̀ lára àwọn ìlànà yìí nígbà tó ń ṣe ìwàásù táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, ìyẹn Ìwàásù Lórí Òkè. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìlànà yẹn, kí a sì tún wo bí a ṣe lè máa fi wọ́n sílò.
ÌLÀNÀ: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—Mátíù 5:3.
BÍ ÌLÀNÀ YÌÍ ṢE LÈ JẸ́ KÍ ÌGBÉSÍ AYÉ WA LÁDÙN:
Jésù fi hàn pé ṣe ni wọ́n bí ìfẹ́ láti mọ Ọlọ́run mọ́ wa. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń wù wá láti mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè bíi: Kí nìdí tí Ọlọrun fi dá wa sí ayé? Kí ló dé tí ìyà fi pọ̀ láyé yìí? Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ wa tiẹ̀ jẹ Ọlọ́run lógún? Tí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè lọ wà láàyè níbòmíì? Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí tí a bá fẹ́ kí ìgbésí ayé wa láyọ̀. Jésù mọ̀ pé inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ibì kan ṣoṣo tó ṣeé fọkàn tán tá a ti lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí. Jésù sọ nínú àdúrà tó gbà sí Baba rẹ̀ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Ǹjẹ́ Bíbélì lè jẹ́ ká mọ Ọlọ́run, ká sì máa láyọ̀?
ÌRÍRÍ KAN RÈÉ:
Ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Esa. Ọ̀gá ẹgbẹ́ akọrin kan tó lókìkí ni. Bó sì ṣe ń bá a lọ nígbà yẹn, kò ní pẹ́ tó fi máa di gbajúmọ̀ òṣèré olórin rọ́ọ̀kì. Pẹ̀lú gbogbo rẹ̀ náà, kò láyọ̀. Ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú mi dùn bí mo ṣe wà nínú ẹgbẹ́ wa, ó ṣì máa ń wù mí pé ki ń wá nǹkan gidi tí màá fi ayé mi ṣe. Nígbà tó yá, ó pàdé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan. Esa sọ pé: “Mo da ìbéèrè bò ó, àmọ́ àwọn ìdáhùn tó fún mi kò lọ́jú pọ̀ rárá, wọ́n sì bá Ìwé Mímọ́ mu, èyí wú mi lórí gan-an. Bí mo ṣe gbà pé kó máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn.” Ohun tí Esa kọ́ láti inú Bíbélì wọ̀ ọ́ lọ́kàn, èyí ló mú kó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ó wá sọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, mo máa ń tinú ìṣòro kan bọ́ sínú òmíràn, wàhálà kì í sì í tán lọ́rùn mi. Àmọ́ ní báyìí, mo ti ní nǹkan gidi tí mo ń fi ayé mi ṣe.”a
ÌLÀNÀ: “Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú.”—Mátíù 5:7.
BÍ ÌLÀNÀ YÌÍ ṢE LÈ JẸ́ KÍ ÌGBÉSÍ AYÉ WA LÁDÙN:
Àánú wé mọ́ fífi ìyọ́nú hàn sí àwọn míì, ká ṣe inúure sí wọ́n, ká sì máa gba tiwọn rò. Jésù ṣàánú àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́. Torí náà, ó máa ń dìídì wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ìyà ń jẹ. (Mátíù 14:14; 20:30-34) Tí a bá ń fara wé Jésù tó jẹ́ aláàánú, ìgbésí ayé wa máa ládùn torí pé àwọn tó bá ń ṣàánú àwọn míì máa ń láyọ̀. (Ìṣe 20:35) A lè jẹ́ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa pé àánú àwọn ẹlòmíì ń ṣe wá, nípa báyìí, a ó máa mú ìtura bá àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ wa. Ṣé òótọ́ ni pé a máa ṣe ara wa láǹfààní tí a bá ń ṣàánú àwọn míì?
ÌRÍRÍ KAN RÈÉ:
Àpẹẹrẹ rere ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Maria àti ọkọ rẹ̀, Carlos jẹ́ ní ti kéèyàn ṣàánú àwọn míì. Ìyàwó bàbá Maria ti kú. Láti ọdún bíi mélòó kan báyìí, àìsàn ò jẹ́ kí bàbá rẹ̀ yìí lè dìde lórí bẹ́ẹ̀dì mọ́. Àmọ́ Maria àti Carlos gbé e wá sí ilé wọn, kí wọ́n lè máa tọ́jú rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn kì í lè sùn lóru, pàápàá tí wàhálà àìsàn àtọ̀gbẹ tó ń ṣe é bá dé sí i, ṣe ni wọ́n máa gbé e dìgbà-dìgbà lọ sí ilé ìwòsàn. Àwọn méjèèjì sọ pé ó máa ń sú àwọn nígbà míì. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù sọ, inú wọn máa ń dùn. Ọkàn wọn sì balẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé àwọn ń ṣe gbogbo ìtọ́jú tó yẹ fún bàbá Maria.
ÌLÀNÀ: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà.”—Mátíù 5:9.
BÍ ÌLÀNÀ YÌÍ ṢE LÈ JẸ́ KÍ ÌGBÉSÍ AYÉ WA LÁDÙN:
Kéèyàn jẹ́ “ẹlẹ́mìí àlàáfíà” túmọ̀ sí pé kéèyàn máa gbìyànjú láti mú kí àlàáfíà wà láàárín òun àti àwọn míì. Báwo ni jíjẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà ṣe lè jẹ́ kí ìgbésí ayé èèyàn ládùn? Ohun kan ni pé, ó máa jẹ́ ká ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ó máa dáa tí a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:18) “Gbogbo ènìyàn” tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ kan àwọn tó wà nínú ìdílé wa àti àwọn míì tí a kò jọ ṣe ẹ̀sìn kan náà. Ṣé òótọ́ ni pé tí a bá jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín àwa àti gbogbo ènìyàn, èyí á mú kí ìgbésí ayé wa ládùn?
ÌRÍRÍ KAN RÈÉ:
Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin kan tó ń jẹ́ Nair. Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àwọn àdánwò tó dé bá a mú kó fẹ́ ṣòro fún un láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, pàápàá nínú ìdílé rẹ̀. Nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn ni ọkọ rẹ̀ ti já a jù sílẹ̀, fúnra rẹ̀ ló wá ń dá tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀. Ọmọkùnrin rẹ̀ kan ti sọ oògùn olóró di bárakú, apá obìnrin yìí kò sì ká a mọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọmọ yìí máa ń halẹ̀ mọ́ ìyá rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ obìnrin. Nair gbà pé ohun tí òun ti kọ́ láti inú Bíbélì ló mú kí òun jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, kódà lábẹ́ ipò tó le koko. Ó máa ń gbìyànjú láti má máa jiyàn tàbí kó máa bá àwọn èèyàn jà sí nǹkan. Ó máa ń sapá láti jẹ́ onínúure, ẹni tó ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn àti ẹni tó máa ń fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn míì ro ara rẹ̀ wò. (Éfésù 4:31, 32) Ó dá obìnrin yìí lójú pé bí òun ṣe jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà ti jẹ́ kí òun ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ìdílé òun àti àwọn míì.
OHUN TÍ YÓÒ ṢẸLẸ̀ SÍ WA LỌ́JỌ́ Ọ̀LA
Tí a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí Jésù fún wa, a máa ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn ní ìgbésí ayé wa. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni a fẹ́ kí ìgbésí ayé wa ládùn, ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́jọ́ ọ̀la. Ó ṣe tán, ire wo ni ìgbésí ayé àwa èèyàn ì bá ní, tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa kò ju pé ká darúgbó, ká ṣàìsàn, ká sì kú? Síbẹ̀, àwọn ohun yìí gan-an ló ń ṣẹlẹ̀ sí wa láyé yìí.
Àmọ́ o, ìròyìn ayọ̀ wà! Ọ̀pọ̀ nǹkan rere ni Jèhófà máa ṣe fún àwọn tó bá ń sapá láti ‘máa ṣe gẹ́gẹ́ bí Kristi ti ṣe.’ Jèhófà ṣèlérí pé tó bá yá, òun máa mú ayé tuntun òdodo wá, níbẹ̀ àwọn olóòótọ́ èèyàn á gbé ìgbé ayé tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún wọn gan-an, ìyẹn ni pé kí wọ́n wà láàyè títí láé pẹ̀lú ìlera pípé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.
Maria, obìnrin ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84] tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí ìlérí tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí máa ní ìmúṣẹ. Ìwọ náà ńkọ́? Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i nípa “ìyè tòótọ́” tí a máa gbádùn lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run? (1 Tímótì 6:19) Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé tó wà lọ́wọ́ rẹ yìí.b
a O lè ka púpọ̀ sí i nípa ìtàn ìgbésí ayé Esa ní ojú ìwé 8 àti 9 nínú ìwé ìròyìn yìí
b Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa onírúurú kókó ọ̀rọ̀.