Wọ́n Rí Mèsáyà!
“Àwa ti rí Mèsáyà náà.”—JÒH. 1:41.
1. Kí ló fà á tí Áńdérù fi sọ pé: “Àwa ti rí Mèsáyà náà”?
JÒHÁNÙ ONÍBATISÍ wà pẹ̀lú méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Bí Jésù ṣe sún mọ́ wọn, Jòhánù fi ìtara sọ̀rọ̀ pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run!” Áńdérù àti ọmọ ẹ̀yìn kejì tẹ̀ lé Jésù lọ́gán wọ́n sì wà pẹ̀lú rẹ̀ jálẹ̀ ọjọ́ náà. Nígbà tí Áńdérù rí arákùnrin rẹ̀ Símónì Pétérù lẹ́yìn náà, ó fìtara sọ fún un pé: “Àwa ti rí Mèsáyà náà,” ó sì mú un tọ Jésù lọ.—Jòh. 1:35-41.
2. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ṣíṣe àyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Mèsáyà síwájú sí i?
2 Bí àkókò ti ń lọ, Áńdérù, Pétérù àti àwọn míì máa ní àǹfààní tó pọ̀ tó láti túbọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́, èyí sì máa mú kí wọ́n lè fi ìdánilójú polongo pé Jésù ará Násárétì ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Ìgbàgbọ́ tí àwa náà ní nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti Ẹni Àmì Òróró rẹ̀ máa lágbára sí i bí a ó ṣe máa bá a nìṣó láti ṣàyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà.
“Wò Ó! Ọba Rẹ Ń Bọ̀”
3. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo ló ní ìmúṣẹ nígbà tí Jésù wọ Jerúsálẹ́mù tiyì-tẹ̀yẹ?
3 Mèsáyà máa wọ Jerúsálẹ́mù tiyì-tẹ̀yẹ. Sekaráyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Kún fún ìdùnnú gidigidi, ìwọ ọmọbìnrin Síónì. Kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù. Wò ó! Ọba rẹ fúnra rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá. Ó jẹ́ olódodo, bẹ́ẹ̀ ni, ẹni ìgbàlà; onírẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ẹran tí ó ti dàgbà tán, ọmọ abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” (Sek. 9:9) Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Ìbùkún ni fún Ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà.” (Sm. 118:26) Jésù kọ́ ló ní kí àwọn ogunlọ́gọ̀ náà ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ṣe yẹn. Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ náà ní ìmúṣẹ nígbà tí ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn náà ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìdùnnú ké jáde tí wọ́n sì ń hó ìhó ayọ̀. Bó o ṣe ń ka ìtàn náà nìṣó, máa fojú inú yàwòrán ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kó o sì máa gbọ́ ohùn ayọ̀ wọn.—Ka Mátíù 21:4-9.
4. Ṣàlàyé ọ̀nà tí Sáàmù 118:22, 23 gbà ní ìmúṣẹ.
4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa kọ Jésù tí ẹ̀rí fi hàn pé ó jẹ́ Mèsáyà, síbẹ̀ ó ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn tó kọ̀ láti gba ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà ‘tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ wọ́n sì kà á sí aláìjámọ́ nǹkan kan.’ (Aísá. 53:3; Máàkù 9:12) Àmọ́, Ọlọ́run ti mí sí onísáàmù láti sọ pé: “Òkúta tí àwọn akọ́lé kọ̀ tì ti di olórí igun ilé. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá.” (Sm. 118:22, 23) Jésù tọ́ka sí àsọtẹ́lẹ̀ yìí nígbà tó ń bá àwọn ẹlẹ́sìn tó ń ṣàtakò sí i sọ̀rọ̀, Pétérù sì sọ pé Kristi ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣẹ sí lára. (Máàkù 12:10, 11; Ìṣe 4:8-11) Jésù di “òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé” fún ìjọ Kristẹni ní tòótọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run kọ Jésù, ó jẹ́ “àyànfẹ́, tí ó ṣe iyebíye lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”—1 Pét. 2:4-6.
Wọ́n Dà Á, Wọ́n sì Pa Á Tì!
5, 6. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa bí wọ́n ṣe máa da Mèsáyà, báwo sì ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ní ìmúṣẹ?
5 Ìwé Mímọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ọ̀dàlẹ̀ ọ̀rẹ́ kan máa da Mèsáyà. Dáfídì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ẹni tí ó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú mi, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀ lé, ẹni tí ó ti máa ń jẹ oúnjẹ mi, ti gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ ga sí mi.” (Sm. 41:9) Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀rẹ́ èèyàn ni wọ́n máa ń ka ẹni tó bá ń báni jẹun sí. (Jẹ́n. 31:54) Torí náà ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó burú jáì ni Júdásì Ísíkáríótù hù nígbà tó da Jésù. Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ Dáfídì ló ń ní ìmúṣẹ nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó dà á tó sì sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Èmi kò sọ̀rọ̀ nípa gbogbo yín; mo mọ àwọn tí mo ti yàn. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ kí a lè mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ pé, ‘Ẹni tí ó ti ń fi oúnjẹ mi ṣe oúnjẹ jẹ, ti gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.’”—Jòh. 13:18.
6 Ẹni tó máa da Mèsáyà máa gba ọgbọ̀n ẹyọ owó fàdákà, ìyẹn iye owó ẹrú! Mátíù lo ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sekaráyà 11:12, 13 láti ṣàlàyé pé wọ́n da Jésù nítorí iye tí kò tó nǹkan. Ṣùgbọ́n kí nìdí tí Mátíù fi sọ pé a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ èyí “nípasẹ̀ Jeremáyà wòlíì”? Nígbà ayé Mátíù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ojú kan ṣoṣo ni wọ́n to ìwé Jeremáyà, Sekaráyà àtàwọn ìwé Bíbélì míì sí, ṣùgbọ́n kó jẹ́ pé ìwé Jeremáyà ló ṣáájú. (Fi wé Lúùkù 24:44.) Júdásì kò ná owó tó fèrú gbà náà, ńṣe ló da owó náà sínú tẹ́ńpìlì, ó lọ kúrò níbẹ̀, ó sì lọ para rẹ̀.—Mát. 26:14-16; 27:3-10.
7. Báwo ni Sekaráyà 13:7 ṣe ní ìmúṣẹ?
7 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Mèsáyà pàápàá máa tú ká. Sekaráyà sọ pé: “Kọlu olùṣọ́ àgùntàn, kí agbo ẹran sì tú ká.” (Sek. 13:7) Ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Gbogbo yín ni a óò mú kọsẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi ní òru yìí, nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Dájúdájú, èmi yóò kọlu olùṣọ́ àgùntàn, àwọn àgùntàn agbo ni a ó sì tú ká káàkiri.’” Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn, torí pé Mátíù ròyìn pé “gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn pa [Jésù] tì, wọ́n sì sá lọ.”—Mát. 26:31, 56.
Wọ́n Fi Ẹ̀sùn Kàn Án Wọ́n sì Lù Ú
8. Báwo ni Aísáyà 53:8 ṣe ní ìmúṣẹ?
8 Wọ́n máa pe Mèsáyà lẹ́jọ́, wọ́n sì máa dẹ́bi ikú fún un. (Ka Aísáyà 53:8.) Ní òwúrọ̀ Nísàn 14, gbogbo àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn pàdé pọ̀, wọ́n ní kí wọ́n de Jésù, wọ́n sì fà á lé Pọ́ntíù Pílátù tó jẹ́ Gómìnà ìlú Róòmù, lọ́wọ́. Ó fọ̀rọ̀ wá Jésù lẹ́nu wò, ó sì rí i pé kò jẹ̀bí èyíkéyìí lára àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Àmọ́ nígbà tí Pílátù bi wọ́n pé ṣé kóun tú Jésù sílẹ̀, ogunlọ́gọ̀ náà kígbe pé: “Kàn án mọ́gi!” Lẹ́yìn náà ni wọ́n ní kó tú Bárábà tó jẹ́ ọ̀daràn sílẹ̀ fáwọn. Níwọ̀n bí Pílátù sì ti fẹ́ láti tẹ́ ogunlọ́gọ̀ náà lọ́rùn, ó tú Bárábà sílẹ̀ fún wọn, ó na Jésù ní pàṣán, ó sì fi í lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́gi.—Máàkù 15:1-15.
9. Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 35:11, kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jésù?
9 Àwọn ẹlẹ́rìí èké máa jẹ́rìí lòdì sí Mèsáyà. Onísáàmù náà, Dáfídì sọ pé: “Àwọn ẹlẹ́rìí tí ń ṣeni léṣe dìde; ohun tí n kò mọ̀ ni wọ́n ń bi mí.” (Sm. 35:11) Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, “àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo Sànhẹ́dírìn pátá ń wá ẹ̀rí èké lòdì sí Jésù láti fi ikú pa á.” (Mát. 26:59) Kódà, “ọ̀pọ̀ ènìyàn ń jẹ́rìí èké lòdì sí i, ṣùgbọ́n gbólóhùn ẹ̀rí wọn kò bára mu.” (Máàkù 14:56) Àwọn ọ̀tá Jésù kò bìkítà pé àwọn èèyàn ń jẹ́rìí èké lòdì sí i, ikú rẹ̀ ni wọ́n ń wá.
10. Ṣàlàyé bí Aísáyà 53:7 ṣe ní ìmúṣẹ.
10 Mèsáyà máa dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú àwọn olùfisùn rẹ̀. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ni ín lára dé góńgó, ó sì jẹ́ kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́; síbẹ̀síbẹ̀, kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀. A ń mú un bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn fún ìfikúpa; àti bí abo àgùntàn tí ó yadi níwájú àwọn olùrẹ́run rẹ̀, òun kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀ pẹ̀lú.” (Aísá. 53:7) Nígbà tí ‘àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin ń fẹ̀sùn kan Jésù, kò dáhùn.’ Pílátù wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé ìwọ kò gbọ́ bí àwọn ohun tí wọ́n ń jẹ́rìí lòdì sí ọ ti pọ̀ tó ni?” Síbẹ̀, Jésù “kò dá a lóhùn rárá, àní kì í tilẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ kan, tó bẹ́ẹ̀ tí gómìnà fi ṣe kàyéfì gidigidi.” (Mát. 27:12-14) Jésù kò kẹ́gàn àwọn tó fẹ̀sùn kàn án.—Róòmù 12:17-21; 1 Pét. 2:23.
11. Báwo ni Aísáyà 50:6 àti Míkà 5:1 ṣe ní ìmúṣẹ?
11 Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa lu Mèsáyà. Wòlíì Aísáyà sọ pé: “Ẹ̀yìn mi ni mo fi fún àwọn akọluni, mo sì fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irun tu. Ojú mi ni èmi kò fi pa mọ́ fún àwọn ohun tí ń tẹ́ni lógo àti itọ́.” (Aísá. 50:6) Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Wọn yóò fi ọ̀pá lu ẹ̀rẹ̀kẹ́ onídàájọ́ Ísírẹ́lì.” (Míkà 5:1) Láti fi hàn pé òótọ́ làwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ, òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà, Máàkù sọ pé: “Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí tutọ́ sí [Jésù] lára, wọ́n sì bo gbogbo ojú rẹ̀, wọ́n sì ń lù ú ní ẹ̀ṣẹ́, wọ́n sì wí fún un pé: ‘Sọ tẹ́lẹ̀!’ Àti pé, ní gbígbá a lójú, àwọn ẹmẹ̀wà inú kóòtù mú un.” Máàkù sọ pé àwọn ọmọ ogun “a fi ọ̀pá esùsú gbá a ní orí, wọ́n a sì tutọ́ sí i lára àti pé, ní títẹ eékún wọn ba [lọ́nà ìfiniṣẹ̀sín], wọn [á] wárí fún un.” (Máàkù 14:65; 15:19) Àmọ́ ṣá o, Jésù kò ṣe ohunkóhun tó lè mú kí wọ́n ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí i.
Ó Jẹ́ Olóòótọ́ Dójú Ikú
12. Báwo ni Sáàmù 22:16 àti Aísáyà 53:12 ṣe ṣẹ sí Jésù lára?
12 Ìwé Mímọ́ sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa kan Mèsáyà mọ́gi. Onísáàmù náà, Dáfídì sọ pé: “Àpéjọ àwọn aṣebi pàápàá ti ká mi mọ́. Bí kìnnìún, wọ́n wà níbi ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi.” (Sm. 22:16) Nígbà tí òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà, Máàkù ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan táwọn tó ń ka Bíbélì mọ̀ bí ẹní mowó, ó sọ pé: “Ó ti di wákàtí kẹta nísinsìnyí [nǹkan bí agogo mẹ́sàn-án òwúrọ̀], wọ́n sì kàn án mọ́gi.” (Máàkù 15:25) Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú pé wọ́n máa ka Mèsáyà mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Aísáyà sọ pé: “Ó tú ọkàn rẹ̀ jáde àní sí ikú, àwọn olùrélànàkọjá ni a sì kà á mọ́.” (Aísá. 53:12) Bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn, torí pé “àwọn ọlọ́ṣà méjì ni a kàn mọ́gi pẹ̀lú [Jésù], ọ̀kan ní ọ̀tún rẹ̀ àti ọ̀kan ní òsì rẹ̀.”—Mát. 27:38.
13. Báwo ni Sáàmù 22:7, 8 ṣe ṣẹ sí Jésù lára?
13 Dáfídì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa kẹ́gàn Mèsáyà. (Ka Sáàmù 22:7, 8.) Nígbà tí Jésù ń jẹ̀rora lórí òpó igi oró wọ́n kẹ́gàn rẹ̀ torí Mátíù ròyìn pé: “Àwọn tí ń kọjá lọ bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú, wọ́n ń mi orí wọn síwá sẹ́yìn wọ́n sì ń wí pé: ‘Ìwọ tí o máa wó tẹ́ńpìlì palẹ̀, tí o sì máa fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ, gba ara rẹ là! Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òpó igi oró!’” Bákan náà, àwọn olórí àlùfáà, àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbà ọkùnrin fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ń wí pé: “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kò lè gba ara rẹ̀ là! Òun ni Ọba Ísírẹ́lì; kí ó sọ̀ kalẹ̀ nísinsìnyí kúrò lórí òpó igi oró, dájúdájú, àwa yóò sì gbà á gbọ́. Ó ti fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sínú Ọlọ́run; kí Ó gbà á sílẹ̀ nísinsìnyí bí ó bá jẹ́ pé Ó fẹ́ ẹ, nítorí ó wí pé, ‘Ọmọ Ọlọ́run ni èmi.’” (Mát. 27:39-43) Síbẹ̀, Jésù fara da gbogbo èyí láì ṣìwà hù. Àpẹẹrẹ àtàtà mà lèyí jẹ́ fún wa o!
14, 15. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa aṣọ Mèsáyà àti bí wọ́n ṣe fún un ní ọtí kíkan mu ṣe ní ìmúṣẹ?
14 Wọ́n máa ṣẹ́ kèké lé aṣọ Mèsáyà. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Wọ́n pín ẹ̀wù mi láàárín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ kèké lé aṣọ mi.” (Sm. 22:18) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn, torí pé ‘nígbà tí [àwọn ọmọ ogun Róòmù] ti kan Jésù mọ́gi, wọ́n pín ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ nípa ṣíṣẹ́ kèké.’—Mát. 27:35; ka Jòhánù 19:23, 24.
15 Wọ́n máa fún Mèsáyà ní ọtí kíkan àti òróòro mu. Onísáàmù náà sọ pé: “Wọ́n fún mi ní ọ̀gbìn onímájèlé láti fi ṣe oúnjẹ, àti fún òùngbẹ mi, wọ́n gbìyànjú láti mú mi mu ọtí kíkan.” (Sm. 69:21) Mátíù sọ fún wa pé: “Wọ́n fi wáìnì tí a pò pọ̀ mọ́ [òróòro] fún [Jésù] láti mu; ṣùgbọ́n, lẹ́yìn títọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún.” Lẹ́yìn náà, “ọ̀kan lára wọ́n sáré, ó sì mú kànrìnkàn, ó sì rẹ ẹ́ sínú wáìnì kíkan, ó sì fi í sórí ọ̀pá esùsú, ó sì lọ ń fún un mu.”—Mát. 27:34, 48.
16. Ṣàlàyé bí àsọtẹ́lẹ̀ inú Sáàmù 22:1 ṣe ní ìmúṣẹ.
16 Ó máa dà bíi pé Ọlọ́run ti ṣá Mèsáyà tì. (Ka Sáàmù 22:1.) Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀, “ní wákàtí kẹsàn-án [nǹkan bí agogo mẹ́ta ọ̀sán] Jésù ké ní ohùn rara pé: ‘Élì, Élì, làmá sàbákìtanì?’ èyí tí, nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀, ó túmọ̀ sí: ‘Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi ṣá mi tì?’” (Máàkù 15:34) Èyí kò fi hàn pé Jésù kò ní ìgbàgbọ́ nínú Baba rẹ̀ ọ̀rún mọ́. Àmọ́, Ọlọ́run ṣá Jésù tì ní ti pé kò ṣe ohunkóhun láti gbà á kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí wọ́n má bàa pa á, èyí sì fún Kristi láǹfààní láti fi hàn pé òótọ́ lòun jẹ́ adúróṣinṣin. Bí Jésù sì ṣe ké ní ohùn rara yẹn mú àsọtẹ́lẹ̀ inú Sáàmù 22:1 ṣẹ.
17. Báwo ni Sekaráyà 12:10 àti Sáàmù 34:20 ṣe ní ìmúṣẹ?
17 Wọ́n máa gún Mèsáyà, àmọ́ wọn kò ní ṣẹ́ egungun rẹ̀. Àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù yóò “wo Ẹni náà tí wọ́n gún ní àgúnyọ.” (Sek. 12:10) Ìwé Sáàmù 34:20 sì sọ pé: “[Ọlọ́run] ń ṣọ́ gbogbo egungun ẹni yẹn; a kò ṣẹ́ ìkankan nínú wọn.” Àpọ́sítélì Jòhánù jẹ́rìí sí èyí. Ó sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ [ìyẹn Jésù], lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde. Ẹni tí ó sì rí i [ìyẹn Jòhánù] ti jẹ́rìí, òótọ́ sì ni ẹ̀rí rẹ̀ . . . Nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ nítorí kí a lè mú ìwé mímọ́ ṣẹ pé: ‘A kì yóò fọ́ ìkankan nínú egungun rẹ̀.’ Àti, pẹ̀lú, ìwé mímọ́ mìíràn wí pé: ‘Wọn yóò wo Ẹni náà tí wọ́n gún lọ́kọ̀.’”—Jòh. 19:33-37.
18. Báwo ni wọ́n ṣe sin Jésù pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀?
18 Wọ́n máa sin Mèsáyà pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀. (Ka Aísáyà 53:5, 8, 9.) Ní ìrọ̀lẹ́ Nísàn 14, “ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan ará Arimatíà dé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jósẹ́fù,” ó lọ sọ́dọ̀ Pílátù ó sì béèrè fún òkú Jésù, Pílátù sì ní kí wọ́n gbé òkú Jésù fún un. Mátíù wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Jósẹ́fù sì gbé òkú náà, ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà tí ó mọ́ dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì ìrántí rẹ̀ tuntun, èyí tí ó ti gbẹ́ sínú àpáta ràbàtà. Àti pé, lẹ́yìn yíyí òkúta ńlá sí ẹnu ọ̀nà ibojì ìrántí náà, ó lọ.”—Mát. 27:57-60.
Ẹ Yin Mèsáyà Ọba!
19. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 16:10?
19 Ọlọ́run máa jí Mèsáyà dìde. Dáfídì kọ̀wé pé: “Ìwọ [Jèhófà] kì yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ sínú Ṣìọ́ọ̀lù.” (Sm. 16:10) Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún àwọn obìnrin tó wá sí ibojì tí wọ́n tẹ́ òkú Jésù sí nígbà tí wọ́n débẹ̀ tí wọ́n sì rí áńgẹ́lì kan tó gbé ara èèyàn wọ̀. Áńgẹ́lì náà sọ fún wọn pé: “Ẹ dẹ́kun títakìjí. Jésù ará Násárétì ni ẹ ń wá, ẹni tí a kàn mọ́gi. A ti gbé e dìde, kò sí níhìn-ín. Ẹ wò ó! Ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.” (Máàkù 16:6) Àpọ́sítélì Pétérù sọ fún ogunlọ́gọ̀ tó pé jọ sí Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni pé: “[Dáfídì] ti rí i tẹ́lẹ̀, ó sì sọ nípa àjíǹde Kristi, pé a kò ṣá a tì sínú Hédíìsì, bẹ́ẹ̀ ni ẹran ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.” (Ìṣe 2:29-31) Ọlọ́run kò jẹ́ kí ara Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rí ìdíbàjẹ́. Ó sì tún jí i dìde lọ́nà ìyanu sí ìyè ti ẹ̀mí lókè ọ̀run!—1 Pét. 3:18.
20. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣàkóso Mèsáyà ṣe ní ìmúṣẹ?
20 Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Ọlọ́run polongo pé Ọmọ òun ni Jésù. (Ka Sáàmù 2:7; Mátíù 3:17.) Bákan náà, ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn kókìkí Jésù àti Ìjọba rẹ̀ tí ń bọ̀ wá, àwa náà ń fi tayọ̀tayọ̀ sọ̀rọ̀ nípa Jésù àti ìṣàkóso rẹ̀ tó máa ṣe aráyé láǹfààní. (Máàkù 11:7-10) Kristi máa tó pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run bó ṣe ń “gẹṣin lọ nítorí òtítọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo.” (Sm. 2:8, 9; 45:1-6) Ìṣàkóso rẹ̀ á mú kí àlàáfíà àti aásìkí wà kárí ayé. (Sm. 72:1, 3, 12, 16; Aísá. 9:6, 7) Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa polongo fáwọn èèyàn pé ní báyìí, Ọmọ Ọlọ́run ọ̀wọ́n náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lókè ọ̀run gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba!
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ni wọ́n ṣe da Jésù tí wọ́n sì pa á tì?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa kan Jésù Kristi mọ́gi?
• Kí nìdí tó fi dá ẹ lójú pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo ló ní ìmúṣẹ nígbà tí Jésù wọ Jerúsálẹ́mù tiyì-tẹ̀yẹ?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jésù kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àmọ́ ó ti ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba báyìí